İbrahim suresi çevirisi Yoruba
’Alif lam ro. (Eyi ni) Tira kan ti A sokale fun o nitori ki o le mu awon eniyan kuro lati inu awon okunkun wa sinu imole pelu iyonda Oluwa won. (Won yo si bo) si ona Alagbara, Olope (ti ope to si) |
Allahu, Eni ti O ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile. Egbe ni fun awon alaigbagbo nibi iya lile |
Awon t’o n feran isemi aye ju torun, ti won n seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Allahu, won si n fe ko wo; awon wonyen wa ninu isina t’o jinna |
A o ran Ojise kan nise afi pelu ede ijo re1 nitori ki o le salaye (esin) fun won. Nigba naa, Allahu yoo si enikeni ti O ba fe lona. O si maa to enikeni ti O ba fe sona; Oun ni Alagbara, Ologbon |
A kuku fi awon ayah Wa ran (Anabi) Musa nise pe: “Mu ijo re kuro lati inu awon okunkun bo sinu imole. Ki o si ran won leti awon idera Allahu (lori won).” Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun gbogbo onisuuru, oludupe |
(Ranti) nigba ti (Anabi) Musa so fun ijo re pe e ranti ike Allahu lori yin nigba ti O gba yin la lowo awon eniyan Fir‘aon, ti won n fi iya buruku je yin; won n dunnbu awon omokunrin yin, won si n da awon omobinrin yin si. Adanwo nla wa ninu iyen lati odo Oluwa yin |
(E ranti) nigba ti Oluwa Eledaa yin so o di mimo (fun yin pe): "Dajudaju ti e ba dupe, Emi yoo salekun fun yin. Dajudaju ti e ba si saimoore, dajudaju iya Mi ma le |
(Anabi) Musa so pe: "Ti e ba saimoore, eyin ati awon t’o n be lori ile aye patapata, dajudaju Allahu ni Oloro, Olope |
Se iro awon t’o siwaju yin ko ti i de ba yin ni? Ijo (Anabi) Nuh, ijo ‘Ad, ijo Thamud ati awon t’o wa leyin won; ko si eni ti o mo won afi Allahu. Awon Ojise won mu awon eri t’o yanju wa ba won. Nigba naa, won ti owo won bo enu won (ni ti ibinu), won si wi pe: "Dajudaju awa sai gbagbo ninu nnkan ti Won fi ran yin nise. Ati pe dajudaju awa wa ninu iyemeji t’o gbopon nipa ohun ti e n pe wa si |
Awon Ojise won so pe: “Se iyemeji kan n be nibi (bibe) Allahu, Olupileda awon sanmo ati ile? O n pe yin nitori ki O le fori awon ese yin jin yin ati nitori ki O le lo yin lara di gbedeke akoko kan.” Won wi pe: “Eyin ko je kini kan tayo abara bi iru wa. Eyin si fe se wa lori kuro nibi nnkan ti awon baba wa n josin fun. Nitori naa, e fun wa ni eri ponnbele.” |
Awon Ojise won so fun won pe: “Awa ko je kini kan bi ko se abara bi iru yin. Sugbon Allahu n soore fun eni ti O ba fe ninu awon erusin Re. Ko si letoo fun wa lati fun yin ni eri kan afi pelu iyonda Allahu. Ati pe, Allahu ni ki awon onigbagbo ododo gbarale |
Ki ni o maa se wa ti a o nii gbarale Allahu, O kuku ti fi awon ona wa mo wa. Dajudaju a maa se suuru lori ohun ti e ba fi ko inira ba wa. Allahu si ni ki awon olugbarale gbarale.” |
Awon t’o sai gbagbo wi fun awon Ojise won pe: “Dajudaju awa yoo le yin jade kuro lori ile wa tabi ki e kuku pada sinu esin wa.” Nigba naa, Oluwa won fi imisi ranse si won pe: “Dajudaju A maa pa awon alabosi run |
وَلَنُسْكِنَنَّكُمُ الْأَرْضَ مِن بَعْدِهِمْ ۚ ذَٰلِكَ لِمَنْ خَافَ مَقَامِي وَخَافَ وَعِيدِ(14) Dajudaju A si maa fun yin ni ibugbe lori ile leyin won. ” Iyen wa fun eni ti o ba paya iduro (niwaju) Mi, ti o tun paya ileri Mi |
Won si toro aranse (Allahu lori ijo won). Gbogbo alafojudi, olorikunkun si padanu |
Ina Jahanamo n be leyin (iparun) re; A o si maa fun un ni omi awoyunweje mu |
O maa sare mu un diedie, ko si nii fee le gbe e mi. (Inira) iku yo si maa yo si i ni gbogbo aye, sibe ko nii ku. Iya t’o nipon tun wa fun un leyin re |
Afiwe awon t’o sai gbagbo ninu Oluwa won: awon ise won da bi eeru ti ategun fe danu patapata ni ojo iji ategun. Won ko ni agbara kan lori ohun ti won se nise. Iyen ni isina t’o jinna |
Se o o ri i pe dajudaju Allahu l’O seda awon sanmo ati ile pelu ododo? Ti O ba fe, O maa ko yin kuro. O si maa mu eda titun wa |
Iyen ko si le da Allahu lagara |
Gbogbo eda si maa jade sodo Allahu (lojo Ajinde). Nigba naa, awon alailagbara yoo wi fun awon t’o segberaga pe: “Dajudaju awa je omoleyin fun yin, nje eyin le gbe nnkan kan kuro fun wa ninu iya Allahu?” Won yoo wi pe: “Ti o ba je pe Allahu to wa sona ni, awa iba to yin sona. Bakan naa si ni fun wa, yala a kaya soke tabi a satemora (iya); ko si ibusasi kan fun wa.” |
Esu yo si wi nigba ti A ba sedajo (eda) tan, pe: “Dajudaju Allahu se adehun fun yin ni adehun ododo. Emi naa se adehun fun yin. Mo si yapa adehun ti mo se fun yin. Emi ko si ni agbara kan lori yin bi ko se pe mo pe yin e si jepe mi. Nitori naa, e ma se bu mi; ara yin ni ki e bu. Emi ko le ran yin lowo (nibi iya), Eyin naa ko si le ran mi lowo (nibi iya). Dajudaju emi ti lodi si ohun ti e fi so mi di akegbe Allahu siwaju.” Dajudaju awon alabosi, iya eleta-elero wa fun won |
Won si maa mu awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere wo inu awon Ogba Idera, eyi ti awon odo n san ni isale re. Olusegbere ni won ninu re pelu ase Oluwa won. Ikini won ninu re ni ‘alaafia’ |
Se o o ri bi Allahu ti sakawe oro daadaa pelu igi daadaa, ti gbongbo re fidi mule sinsin, ti eka re si wa ninu sanmo |
to si n so eso (jije) re ni gbogbo igba pelu iyonda Oluwa re? Allahu n fun awon eniyan ni awon akawe nitori ki won le lo iranti |
Akawe oro ti ko dara si da bi igi ti ko dara, ti won fa tu lati oke lori ile, ti ko si ni aye kan lori ile |
Allahu yoo maa fi awon t’o gbagbo ni ododo rinle pelu oro t’o rinle ninu isemi aye ati ni Ojo Ikeyin. O si maa si awon alabosi lona. Ati pe Allahu n se ohun ti O ba fe |
Se o o ri awon t’o yi idera Allahu pada si aigbagbo, ti won si mu ijo won gunle si ile iparun |
Ina Jahanamo ni won yoo gunle si; ibugbe naa si buru |
Won so (awon kan di) akegbe fun Allahu nitori ki won le seri awon eniyan kuro ninu esin Re. So pe: “E maa gbadun nso, nitori pe dajudaju abo yin ni Ina.” |
So fun awon erusin Mi pe ki won kirun, ki won si na ninu ohun ti A pese fun won ni ikoko ati ni gbangba siwaju ki ojo kan to de, ti ko nii si tita-rira kan ati yiyan ore kan ninu re |
Allahu ni Eni ti O seda awon sanmo ati ile. O n so omi kale lati sanmo. O si fi n mu awon eso jade; (o je) arisiki fun yin. O si ro oko oju-omi fun yin ki o le rin loju omi pelu ase Re. O tun ro awon odo fun yin |
وَسَخَّرَ لَكُمُ الشَّمْسَ وَالْقَمَرَ دَائِبَيْنِ ۖ وَسَخَّرَ لَكُمُ اللَّيْلَ وَالنَّهَارَ(33) O ro oorun ati osupa fun yin, ti mejeeji n rin lai sinmi. O tun ro oru ati osan fun yin |
Ati pe O n fun yin ninu gbogbo nnkan ti e toro lodo Re. Ti e ba se onka idera Allahu, e ko le ka a tan. Dajudaju eniyan ni alabosi alaimoore |
(Ranti) nigba ti (Anabi) ’Ibrohim so pe: "Oluwa mi, se ilu yii ni ilu ifayabale. Ki O si mu emi ati awon omo mi jinna si jijosin fun awon orisa |
Oluwa mi, dajudaju awon orisa ti ko opolopo ninu awon eniyan sonu. Nitori naa, enikeni ti o ba tele mi, dajudaju oun ni eni mi. Enikeni ti o ba si yapa mi, dajudaju Iwo ni Alaforijin, Asake |
Oluwa wa, dajudaju emi wa ibugbe fun aromodomo mi si ile afonifoji, ile ti ko ni eso, nitosi Ile Re Olowo. Oluwa wa, nitori ki won le kirun ni. Nitori naa, je ki okan awon eniyan fa sodo won. Ki O si pese awon eso fun won nitori ki won le dupe (fun O) |
Oluwa wa, dajudaju Iwo l’O mo ohun ti a n fi pamo ati ohun ti a n se afihan re. Ko si si kini kan ninu ile ati ninu sanmo t’o pamo fun Allahu |
Gbogbo ope n je ti Allahu, Eni ti O fun mi ni ’Ismo‘il ati ’Ishaƙ nigba ti mo ti darugbo. Dajudaju, Oluwa mi ni Olugbo adua |
رَبِّ اجْعَلْنِي مُقِيمَ الصَّلَاةِ وَمِن ذُرِّيَّتِي ۚ رَبَّنَا وَتَقَبَّلْ دُعَاءِ(40) Oluwa mi, se emi ati ninu aromodomo mi ni olukirun. Oluwa wa, ki O si gba adua mi |
رَبَّنَا اغْفِرْ لِي وَلِوَالِدَيَّ وَلِلْمُؤْمِنِينَ يَوْمَ يَقُومُ الْحِسَابُ(41) Oluwa mi, saforijin fun emi ati awon obi mi mejeeji ati awon onigbagbo ododo ni ojo ti isiro-ise yoo sele |
Ma se lero pe Allahu gbagbe nnkan ti awon alabosi n se nise. O kan n lo won lara di ojo kan ti awon oju yoo yo sita rangandan |
مُهْطِعِينَ مُقْنِعِي رُءُوسِهِمْ لَا يَرْتَدُّ إِلَيْهِمْ طَرْفُهُمْ ۖ وَأَفْئِدَتُهُمْ هَوَاءٌ(43) Won yoo ma sare (lo sibi akojo fun isiro-ise), won yoo gbe ori won soke, ipenpeju won ko si nii pada sodo won, awon okan won yo si pa sofo patapata (fun iberu) |
Kilo fun awon eniyan nipa ojo ti iya yoo de ba won, awon t’o sabosi yo si wi pe: “Oluwa wa, lo wa lara fun asiko die si i, a maa jepe Re, a si maa tele awon Ojise.” Se eyin ko ti bura siwaju pe eyin ko nii kuro nile aye ni |
E si gbe ninu ibugbe awon t’o sabosi si emi ara won. O si han si yin bi A ti se pelu won. A tun fun yin ni awon akawe |
Won kuku ti da ete won, odo Allahu si ni ete won wa, bi o tile je pe (pelu) ete won apata fee le ye lule |
فَلَا تَحْسَبَنَّ اللَّهَ مُخْلِفَ وَعْدِهِ رُسُلَهُ ۗ إِنَّ اللَّهَ عَزِيزٌ ذُو انتِقَامٍ(47) Nitori naa, ma se lero pe Allahu yoo yapa adehun Re ti O se fun awon Ojise Re. Dajudaju Allahu ni Alagbara, Olugbesan |
Ni ojo ti A maa yi ile aye pada si nnkan miiran. (A maa yi) awon sanmo naa (pada. Awon eda) si maa jade (siwaju) Allahu, Okan soso, Olubori |
وَتَرَى الْمُجْرِمِينَ يَوْمَئِذٍ مُّقَرَّنِينَ فِي الْأَصْفَادِ(49) O si maa ri awon elese ni ojo yen, ti won yoo so won papo mora won sinu sekeseke |
سَرَابِيلُهُم مِّن قَطِرَانٍ وَتَغْشَىٰ وُجُوهَهُمُ النَّارُ(50) Oje Ina ni awon ewu won. Ina yo si bo oju won mole bamubamu |
لِيَجْزِيَ اللَّهُ كُلَّ نَفْسٍ مَّا كَسَبَتْ ۚ إِنَّ اللَّهَ سَرِيعُ الْحِسَابِ(51) nitori ki Allahu le san esan ohun ti emi kookan se nise. Dajudaju Allahu ni Oluyara nibi isiro-ise |
Eyi ni ise-jije fun awon eniyan nitori ki won le fi se ikilo, ki won si le mo pe (Allahu) Oun nikan ni Olohun ti ijosin to si, Okan soso, ati nitori ki awon onilaakaye le lo iranti |
Yoruba diğer sureler:
En ünlü okuyucuların sesiyle İbrahim Suresi indirin:
Surah Ibrahim mp3: yüksek kalitede dinlemek ve indirmek için okuyucuyu seçerek
Ahmed El Agamy
Saad Al Ghamdi
Saud Al Shuraim
Abdul Basit
Abdullah Basfar
Abdullah Al Juhani
Ali Al Hudhaifi
Fares Abbad
Maher Al Muaiqly
Muhammad Jibril
Al Minshawi
Al Hosary
Mishari Al-afasi
Nasser Al Qatami
Yasser Al Dosari
Bizim için dua et, teşekkürler