سورة الأحزاب باليوربا
Iwo Anabi, beru Allahu. Ma si tele awon alaigbagbo ati awon sobe-selu musulumi. Dajudaju Allahu n je Onimo, Ologbon |
وَاتَّبِعْ مَا يُوحَىٰ إِلَيْكَ مِن رَّبِّكَ ۚ إِنَّ اللَّهَ كَانَ بِمَا تَعْمَلُونَ خَبِيرًا(2) Tele ohun ti A n mu wa fun o ni imisi lati odo Oluwa re. Dajudaju Allahu n je Alamotan nipa ohun ti e n se nise |
Ki o si gbarale Allahu. Allahu si to ni Oluso |
Allahu ko fun eniyan kan ni okan meji ninu ikun re. (Allahu) ko si so awon iyawo yin, ti e n fi eyin won we eyin iya yin, di iya yin. Ati pe (Allahu) ko so awon omo-olomo ti e n pe ni omo yin di omo yin. Iyen ni oro enu yin. Allahu n so ododo. Ati pe Oun l’O n fi (eda) mona |
E pe won pelu oruko baba won. Ohun l’o se deede julo lodo Allahu, sugbon ti e o ba mo (oruko) baba won, omo iya yin ninu esin ati eru yin kuku ni won. Ko si ese fun yin nipa ohun ti e ba sasise re, sugbon (ese wa nibi) ohun ti okan yin moomo se. Allahu si n je Alaforijin, Asake-orun |
Anabi ni eto si awon onigbagbo ododo ju emi ara won lo (nipa ife re ati idajo re). Awon aya re si ni iya won. Ninu Tira Allahu, awon ebi, apa kan won ni eto si ogun jije ju apa kan lo. (Awon ebi tun ni eto si ogun jije) ju awon onigbagbo ododo ati awon t’o kuro ninu ilu Mokkah fun aabo esin, afi ti e ba maa se daadaa kan si awon ore yin (wonyi ni ogun le fi kan won pelu asoole). Iyen wa ninu Tira (Laohul-Mahfuth) ni akosile |
(Ranti) nigba ti A gba adehun ni owo awon Anabi ati ni owo re, ati ni owo (Anabi) Nuh, ’Ibrohim, Musa ati ‘Isa omo Moryam. A gba adehun ni owo won ni adehun t’o nipon |
لِّيَسْأَلَ الصَّادِقِينَ عَن صِدْقِهِمْ ۚ وَأَعَدَّ لِلْكَافِرِينَ عَذَابًا أَلِيمًا(8) nitori ki (Allahu) le beere (ododo) awon olododo nipa ododo won. O si pese iya eleta-elero sile de awon alaigbagbo |
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ranti idera Allahu lori yin, nigba ti awon omo ogun (onijo) de ba yin. A si ran ategun ati awon omo ogun ti e o foju ri si won. Allahu si ni Oluriran nipa ohun ti e n se |
(E ranti) nigba ti won de ba yin lati oke yin ati isale yin, ati nigba ti awon oju ye (sotun-un sosi), ti awon okan si de ona-ofun (ni ti ipaya). E si n ro awon ero kan nipa Allahu |
هُنَالِكَ ابْتُلِيَ الْمُؤْمِنُونَ وَزُلْزِلُوا زِلْزَالًا شَدِيدًا(11) Nibe yen ni won ti fi adanwo kan awon onigbagbo ododo. Won si mile mo won lese ni imititi lile |
(E ranti) nigba ti awon sobe-selu musulumi ati awon ti aisan wa ninu okan won n wi pe: “Allahu ati Ojise Re ko se adehun kan fun wa bi ko se etan.” |
(E ranti) nigba ti igun kan ninu won wi pe: “Eyin ara Yethrib, ko si aye (isegun) fun yin, nitori naa, e seri pada (lodo Ojise).” Apa kan ninu won si n toro iyonda lowo Anabi, won n wi pe: “Dajudaju ile wa da paroparo ni.” (Ile won) ko si da paroparo. Won ko si gbero ohun kan tayo sisagun |
Ati pe ti o ba je pe (omo ogun onijo) wole to won wa lati awon iloro ilu (Modinah), leyin naa, ki won pe (awon sobe-selu musulumi) sinu ebo sise, won iba sebo. Won ko si nii gbe ninu ilu mo tayo igba die (ti won yoo fi pare) |
Dajudaju won ti ba Allahu se adehun siwaju pe awon ko nii peyinda (lati sagun). Adehun Allahu si je ohun ti won maa beere (lowo won) |
So pe: “Sisagun yin ko le se yin ni anfaani, ti e ba sa fun iku tabi pipa (si oju ogun esin. Ti e ba si sagun) nigba naa, A o nii fun yin ni igbadun aye bi ko se fun igba die |
So pe: “Ta ni eni ti o le da aabo bo yin lodo Allahu ti O ba fe fi aburu kan yin tabi ti O ba fe ke yin?” Won ko si le ri alaabo tabi alaranse kan leyin Allahu |
Dajudaju Allahu ti mo awon t’o n fa eniyan seyin ninu yin ati awon t’o n wi fun awon arakunrin won pe: “E maa bo wa si odo wa.” Won ko si nii lo si oju ogun esin afi (ogun) die |
Won ni ahun si yin (lati se iranlowo). Nigba ti iberu (ogun) ba de, o maa ri won ti won yoo maa wo o. Oju won yo si maa yi kiri rakorako (ni ti iberu) bi eni ti o fe daku, sugbon nigba ti iberu (ogun) ba lo, (ti ikogun ba de), won yoo maa fi awon ahon kan t’o mu berebere ba yin soro ni ti sise okanjua si oore naa. Awon wonyen ko gbagbo ni ododo. Nitori naa, Allahu ba awon ise won je. Iyen si n je irorun fun Allahu |
Won n lero pe awon omo ogun onijo ko ti i lo, (won si ti tuka). Ti awon omo ogun onijo ba (si pada) de, dajudaju (awon sobe-selu musulumi) yoo fe ki awon ti wa ni oko laaarin awon Larubawa oko, ki won maa beere nipa awon iro yin (pe se e ti ku tan tabi e si wa laye). Ti o ba si je pe won wa laaarin yin, won ko nii jagun bi ko se fun igba die |
Dajudaju awokose rere wa fun yin lara Ojise Allahu fun enikeni ti o ba n reti (esan) Allahu ati Ojo Ikeyin, ti o si ranti Allahu ni opolopo (igba) |
Nigba ti awon onigbagbo ododo ri awon omo ogun onijo, won so pe: “Eyi ni ohun ti Allahu ati Ojise Re se ni adehun fun wa. Allahu ati Ojise Re ti so ododo oro.” (Riri won) ko se alekun kan fun won bi ko se (alekun) igbagbo ododo ati ijuwo-juse-sile (fun ase Allahu) |
O wa ninu awon onigbagbo ododo, awon okunrin kan ti won je olododo nipa adehun ti won ba Allahu se; o wa ninu won eni ti o pe adehun re (t’o si ku soju ogun esin), o si wa ninu won eni t’o n reti (iku tire). Won ko si yi (adehun) pada rara |
(Iwonyi ri bee) nitori ki Allahu le fi (ododo) awon olododo san won ni esan ododo won, ati nitori ki O le je awon sobe-selu musulumi ni iya ti O ba fe tabi nitori ki O le gba ironupiwada won. Dajudaju Allahu, O n je Alaforijin, Asake-orun |
Allahu si da awon t’o sai gbagbo pada tohun ti ibinu won; owo won ko si te oore kan. Allahu si to awon onigbagbo ododo nibi ogun naa. Allahu si n je Alagbara, Olubori |
(Allahu) si mu awon t’o seranlowo fun (awon omo ogun onijo) ninu awon ahlul-kitab sokale kuro ninu awon odi won. O si ju eru sinu okan won. E n pa igun kan (ninu won), e si n ko igun kan leru |
(Allahu) si jogun ile won, ile won, dukia won ati ile ti e o te ri fun yin. Allahu si n je Alagbara lori gbogbo nnkan |
Iwo Anabi, so fun awon iyawo re pe: “Ti e ba fe isemi aye yii ati oso re, e wa nibi ki ng fun yin ni ebun ikosile, ki ng si fi yin sile ni ifisile t’o rewa |
Ti e ba si fe ti Allahu ati ti Ojise Re ati ile Ikeyin, dajudaju Allahu ti pese esan nla sile de awon oluse-rere lobinrin ninu yin.” |
Eyin iyawo Anabi, enikeni ninu yin ti o ba se ibaje t’o foju han, A maa di adipele iya ilopo meji fun un. Iyen si n je irorun fun Allahu |
Enikeni ti o ba n tele ti Allahu ati ti Ojise Re ninu yin, ti o si n se ise rere, A maa fun un ni esan ilopo meji. A si ti pese ije-imu alapon-onle sile de e.” |
Eyin iyawo Anabi, e o da bi eni kan kan ninu awon obinrin, ti e ba ti beru (Allahu). E ma se dinhun (si awon okunrin leti) nitori ki eni ti arun wa ninu okan re ma baa jerankan. Ki e si maa so oro t’o dara |
E fidi mole yin. E ma se fi ara ati oso han nita gege bi ti ifara-foso-han igba aimokan akoko (iyen, siwaju ki e t’o di musulumi). E kirun. E yo Zakah. Ki e si tele (ase) Allahu ati (ase) Ojise Re. Allahu kan n gbero lati mu egbin kuro lara yin, eyin ara ile (Anabi). Ati pe O (kan n gbero lati) fo yin mo tonitoni ni |
E ranti ohun ti won n ke ninu ile yin ninu awon ayah Allahu ati ijinle oye (iyen, sunnah Anabi). Dajudaju Allahu n je Alaaanu, Onimo-ikoko. ti Larubawa ba n d’oju oro ko okunrin tabi nnkan ako tabi o n soro nipa okunrin tabi nnkan ako ede Larubawa ti ni ihun ako fun ako. Bakan naa |
Dajudaju awon musulumi lokunrin ati musulumi lobinrin, awon onigbagbo ododo lokunrin ati awon onigbagbo ododo lobinrin, awon olutele-ase Allahu lokunrin ati awon olutele-ase Allahu lobinrin, awon olododo lokunrin ati awon olododo lobinrin, awon onisuuru lokunrin ati awon onisuuru lobinrin, awon olupaya Allahu lokunrin ati awon olupaya Allahu lobinrin, awon olutore lokunrin ati awon olutore lobinrin, awon alaawe lokunrin ati awon alaawe lobinrin, awon t’o n so abe won lokunrin ati awon t’o n so abe won lobinrin, awon oluranti Allahu ni opolopo lokunrin ati awon oluranti Allahu (ni opolopo) lobinrin; Allahu ti pese aforijin ati esan nla sile de won |
Ko to fun onigbagbo ododo lokunrin ati onigbagbo ododo lobinrin, nigba ti Allahu ati Ojise Re ba ti pari oro kan, lati ni esa (oro miiran) fun oro ara won. Ati pe enikeni ti o ba yapa (ase) Allahu ati (ase) Ojise Re, dajudaju o ti sina ni isina ponnbele |
(Ranti) nigba ti o n so fun eni ti Allahu sedera fun, ti iwo naa sedera fun1 pe: “Mu iyawo re dani, ki o si beru Allahu.” O si n fi pamo sinu emi re ohun ti Allahu yo safi han re. Ati pe o n paya awon eniyan. Allahu l’O si letoo julo pe ki o paya Re. Nigba ti Zaed ti pari bukata re lodo re (ti o si ti ko o sile), A ti se e ni iyawo fun o nitori ki o ma baa je laifi fun awon onigbagbo ododo lati fe iyawo omo-olomo ti won n pe ni omo won nigba ti won ba ti pari bukata won lodo won (ti won si ti ko won sile). Ase Allahu si gbodo se |
Ko si laifi fun Anabi (sollalahu alayhi wa sallam) nipa ohun ti Allahu se ni eto fun un. (O je) ilana Allahu lori awon t’o ti lo siwaju. Ati pe ase Allahu je akoole kan t’o gbodo se |
(Kose awon t’o ti lo siwaju ninu awon Ojise) awon t’o n je ise Allahu, ti won n paya Re, ti won ko si paya eni kan ayafi Allahu. Allahu si to ni Olusiro |
(Anabi) Muhammad ki i se baba eni kan kan ninu awon okunrin yin, sugbon (o je) Ojise Allahu ati opin awon Anabi. Allahu si n je Onimo nipa gbogbo nnkan. opuro asookun sesin wule ni oun. Iro enu re ti po ju. Alagbari ponnbele si ni pelu. Iru ise aburu ti seeu Ahmada Tijani se fun ’Islam gele naa ni mirza ghulam Ahmad se. Awon mejeeji ni Poolu laaarin awa musulumi. E wo die ninu iro nla re. Mirza ghulam Ahmad so pe: ""Allahu so fun mi ni ede Larubawa pe bi omo Mi lo se wa si Mi."" (Tadhkirah “Ti o ba je pe Anabi Muhammad (sollalahu alayhi wa sallam) ni opin awon Anabi Olohun ko ye fun Anabi ‘Isa omo Moryam (’alaehi-ssolatu wa-ssalam) lati pada wa saye mo lopin aye.” Won tun so pe Anabi Muhammad (sollalahu alayhi wa sallam) ni opin awon Anabi Olohun amo isoro tiwon ni pe |
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا اذْكُرُوا اللَّهَ ذِكْرًا كَثِيرًا(41) Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ranti Allahu ni iranti pupo |
E safomo fun Allahu ni aaro ati ni irole |
(Allahu) Oun ni Eni t’O n ke yin, awon molaika Re (si n toro aforijin fun yin), nitori ki Allahu le mu yin kuro lati inu awon okunkun wa sinu imole. Ati pe O n je Asake-orun fun awon onigbagbo ododo |
تَحِيَّتُهُمْ يَوْمَ يَلْقَوْنَهُ سَلَامٌ ۚ وَأَعَدَّ لَهُمْ أَجْرًا كَرِيمًا(44) Ikini won ni ojo ti won yoo pade Re ni "alaafia." O si ti pese esan alapon-onle sile de won |
يَا أَيُّهَا النَّبِيُّ إِنَّا أَرْسَلْنَاكَ شَاهِدًا وَمُبَشِّرًا وَنَذِيرًا(45) Iwo Anabi, dajudaju Awa ran o nise (pe ki o je) olujerii, oniroo-idunnu, olukilo |
وَدَاعِيًا إِلَى اللَّهِ بِإِذْنِهِ وَسِرَاجًا مُّنِيرًا(46) olupepe si odo Allahu pelu iyonda Re ati atupa imole |
وَبَشِّرِ الْمُؤْمِنِينَ بِأَنَّ لَهُم مِّنَ اللَّهِ فَضْلًا كَبِيرًا(47) Fun awon onigbagbo ododo ni iro idunnu pe dajudaju oore ajulo nla wa fun won lodo Allahu |
Ma se tele awon alaigbagbo ati awon sobe-selu musulumi. Fi bi won se n ko inira ba o sile. Ki o si gbarale Allahu. Allahu si n to ni Alamojuuto |
Eyin ti e gbagbo ni ododo lokunrin, nigba ti e ba fe awon onigbagbo ododo lobinrin, leyin naa ti e ko won sile siwaju ki e to ba won ni asepo loko-laya, ko si opo sise kan ti won yoo se fun yin. Nitori naa, e fun won ni ebun ikosile. Ki e si fi won sile ni ifisile t’o rewa |
Iwo Anabi, dajudaju Awa se e ni eto fun o awon iyawo re, ti o fun ni owo-ori won, ati awon eru ninu awon ti Allahu fi se ikogun fun o ati awon omobinrin arakunrin baba re ati awon omobinrin arabinrin baba re, ati awon omobinrin arakunrin iya re, ati awon omobinrin arabinrin iya re, awon t’o fi ilu Mokkah sile wa si ilu Modinah pelu re, ati onigbagbo ododo lobinrin, ti o ba fi ara re tore fun Anabi, ti Anabi naa si fe fi se iyawo. Iwo nikan ni (eyi) wa fun, ko si fun awon onigbagbo ododo lokunrin. A ti mo ohun ti A se ni oran-anyan fun won nipa awon iyawo won ati awon eru won. (Eyi ri bee) nitori ki o ma baa si laifi fun o. Allahu si n je Alaforijin, Asake-orun |
Lora lati sunmo eni ti o ba fe ninu won. Fa eni ti o ba fe mora. Ati pe eni keni ti o ba tun wa (lati sunmo) ninu awon ti o o pin oorun fun, ko si ese fun o (lati se bee). Iyen sunmo julo lati mu oju won tutu idunnu. Won ko si nii banuje. Gbogbo won yo si yonu si ohunkohun ti o ba fun won. Allahu mo ohun ti n be ninu okan yin. Allahu si n je Onimo, Alafarada |
Ko letoo fun o (lati fe) awon obinrin (miiran) leyin (isori awon ti A se ni eto fun o, ko si letoo fun o) lati fi awon obinrin (miiran) paaro won, koda ki daadaa won jo o loju, afi awon eru re (nikan l’o le ko sile ninu awon iyawo re). Allahu si n je Oluso lori gbogbo nnkan |
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se wo awon inu ile Anabi afi ti won ba yonda fun yin lati wole jeun lai nii je eni ti yoo maa reti ki ounje jinna, sugbon ti won ba pe yin (fun ounje) e wo inu ile nigba naa. Nigba ti e ba si jeun tan, e tuka, e ma se jokoo kale tira yin fun oro kan mo (ninu ile re). Dajudaju iyen n ko inira ba Anabi (sollalahu alayhi wa sallam). O si n tiju yin. Allahu ko si nii tiju nibi ododo. Nigba ti e ba si fe beere nnkan ni odo awon iyawo re, e beere re ni odo won ni eyin gaga. Iyen je afomo julo fun okan yin ati okan won. Ko to fun yin lati ko inira ba Ojise Allahu. (Ko si to fun yin) lati fe awon iyawo re leyin (iku) re laelae. Dajudaju iyen je nnkan nla ni odo Allahu |
إِن تُبْدُوا شَيْئًا أَوْ تُخْفُوهُ فَإِنَّ اللَّهَ كَانَ بِكُلِّ شَيْءٍ عَلِيمًا(54) Ti e ba safi han kini kan tabi e fi pamo, dajudaju Allahu n je Onimo nipa gbogbo nnkan |
Ko si ese fun awon iyawo Anabi nipa awon baba won ati awon omokunrin won ati awon arakunrin won ati awon omokunrin arakunrin won ati awon omokunrin arabinrin won ati awon obinrin (egbe) won ati awon erukunrin won (lati wole ti won.) E beru Allahu. Dajudaju Allahu n je Arinu-rode gbogbo nnkan |
Dajudaju Allahu ati awon molaika Re n ke Anabi (sollalahu alayhi wa sallam). Eyin ti e gbagbo ni ododo, e toro ike fun un, ki e si ki i ni kiki alaafia. awon Sohabah naa (r.ahm) maa n se bee. Eyin naa e wo bi awon aafa sunnah se n se asolatu fun Anabi ninu awon oro isaaju ninu awon tira won. Ko si aburu ninu eyi rara. Sugbon musulumi yoo se agbekale ihun asolatu daran ti o ba fi le ko sinu okan ninu awon nnkan mefa kan. Ikini: Lilo awon oro ti o lodi si ofin ati adisokan ’Islam ninu awon gbolohun asolatu naa. Ikeji: Siso gbolohun asolatu yen gan-angan di ilana ti won yoo maa pepe si ti irufe gbolohun naa yoo fi wa da bi eni pe hadith kan l’o gba a wa |
Dajudaju awon t’o n fi inira kan Allahu ati Ojise Re, Allahu ti sebi le won nile aye ati ni orun. O si ti pese iya t’o n yepere eda sile de won |
Awon t’o n fi inira kan awon onigbagbo ododo lokunrin ati onigbagbo ododo lobinrin nipa nnkan ti won ko se, dajudaju won ti ru eru (oran) iparomoni ati ese ponnbele |
Iwo Anabi so fun awon iyawo re, awon omobinrin re ati awon obinrin onigbagbo ododo pe ki won maa gbe awon aso jilbab won wo si ara won bamubamu. Iyen sunmo julo lati fi mo won (ni oluberu Allahu). Nipa bee, won ko nii fi inira kan won. Allahu si n je Alaforijin, Asake-orun |
Ti awon sobe-selu musulumi, ati awon ti aisan n be ninu okan won ati awon tuletule ninu ilu Modinah ko ba jawo (nibi aburu), dajudaju A maa de o si won, (o si maa bori won). Leyin naa, won ko si nii ba o gbe adugbo po mo afi fun igba die |
مَّلْعُونِينَ ۖ أَيْنَمَا ثُقِفُوا أُخِذُوا وَقُتِّلُوا تَقْتِيلًا(61) Won di eni-isebile nibikibi ti owo ba ti ba won; won maa mu won, won si maa pa won taara |
سُنَّةَ اللَّهِ فِي الَّذِينَ خَلَوْا مِن قَبْلُ ۖ وَلَن تَجِدَ لِسُنَّةِ اللَّهِ تَبْدِيلًا(62) (O je) ise Allahu lori awon t’o ti lo siwaju. O o si nii ri iyipada kan fun ise Allahu |
Awon eniyan n bi o leere nipa Akoko naa. So pe: “Odo Allahu nikan soso ni imo nipa re wa. Ati pe ki l’o maa fi mo o pe o see se ki Akoko naa ti sunmo!” |
إِنَّ اللَّهَ لَعَنَ الْكَافِرِينَ وَأَعَدَّ لَهُمْ سَعِيرًا(64) Dajudaju Allahu sebi le awon alaigbagbo. O si pese Ina t’o n jo fofo sile de won |
خَالِدِينَ فِيهَا أَبَدًا ۖ لَّا يَجِدُونَ وَلِيًّا وَلَا نَصِيرًا(65) Olusegbere ni won ninu re titi laelae; won ko nii ri oluso tabi alaranse kan |
Ni ojo ti A oo yi oju won pada ninu Ina, won yo si wi pe: “Yee! Awa iba tele ti Allahu, awa iba si tele ti Ojise.” |
وَقَالُوا رَبَّنَا إِنَّا أَطَعْنَا سَادَتَنَا وَكُبَرَاءَنَا فَأَضَلُّونَا السَّبِيلَا(67) Won wi pe: “Oluwa wa! Dajudaju awa tele awon asiwaju wa ati awon agbaagba wa. Won si si wa lona |
رَبَّنَا آتِهِمْ ضِعْفَيْنِ مِنَ الْعَذَابِ وَالْعَنْهُمْ لَعْنًا كَبِيرًا(68) Oluwa wa! Fun won ni ilopo meji ninu iya. Ki O si sebi le won ni isebi t’o tobi.” |
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se da bi awon t’o fi inira kan (Anabi) Musa. Allahu si safomo re ninu ohun ti won wi. O si je eni abiyi lodo Allahu |
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا اتَّقُوا اللَّهَ وَقُولُوا قَوْلًا سَدِيدًا(70) Eyin ti e gbagbo ni ododo, e beru Allahu. Ki e si so oro ododo |
(Allahu) maa satunse awon ise yin fun yin, O si maa saforijin awon ese yin fun yin. Ati pe eni ti o ba tele ti Allahu ati Ojise Re, o kuku ti jere ni erenje nla |
Dajudaju Awa fi ise laada lo awon sanmo ati ile ati apata. Won ko lati gbe e; won paya re. Eniyan si gbe e. Dajudaju (eniyan) je alabosi, alaimokan |
(Eniyan teri gba esin asegbalaada) nitori ki Allahu le fi iya je awon sobe-selu musulumi lokunrin, awon sobe-selu musulumi lobinrin, awon osebo lokunrin ati awon osebo lobinrin ati nitori ki Allahu le gba ironupiwada fun awon onigbagbo ododo lokunrin ati awon onigbagbo ododo lobinrin. Allahu si n je Alaforijin, Asake-orun |
المزيد من السور باللغة اليوربا:
تحميل سورة الأحزاب بصوت أشهر القراء :
قم باختيار القارئ للاستماع و تحميل سورة الأحزاب كاملة بجودة عالية
أحمد العجمي
خالد الجليل
سعد الغامدي
سعود الشريم
عبد الباسط
عبد الله الجهني
علي الحذيفي
فارس عباد
ماهر المعيقلي
محمد جبريل
المنشاوي
الحصري
مشاري العفاسي
ناصر القطامي
ياسر الدوسري
Sunday, December 22, 2024
لا تنسنا من دعوة صالحة بظهر الغيب