Surah Al-Anfal with Yoruba

  1. Surah mp3
  2. More
  3. Yoruba
The Holy Quran | Quran translation | Language Yoruba | Surah Anfal | الأنفال - Ayat Count 75 - The number of the surah in moshaf: 8 - The meaning of the surah in English: The Spoils of War.

يَسْأَلُونَكَ عَنِ الْأَنفَالِ ۖ قُلِ الْأَنفَالُ لِلَّهِ وَالرَّسُولِ ۖ فَاتَّقُوا اللَّهَ وَأَصْلِحُوا ذَاتَ بَيْنِكُمْ ۖ وَأَطِيعُوا اللَّهَ وَرَسُولَهُ إِن كُنتُم مُّؤْمِنِينَ(1)

 Won n bi o leere nipa oro ogun. So pe: “Oro ogun je ti Allahu ati ti Ojise. Nitori naa, e beru Allahu. Ki e si se atunse nnkan ti n be laaarin yin. E tele ti Allahu ati Ojise Re ti e ba je onigbagbo ododo

إِنَّمَا الْمُؤْمِنُونَ الَّذِينَ إِذَا ذُكِرَ اللَّهُ وَجِلَتْ قُلُوبُهُمْ وَإِذَا تُلِيَتْ عَلَيْهِمْ آيَاتُهُ زَادَتْهُمْ إِيمَانًا وَعَلَىٰ رَبِّهِمْ يَتَوَكَّلُونَ(2)

 Awon onigbagbo ododo ni awon t’o je pe nigba ti won ba fi (iya) Allahu se iranti (fun won), okan won yoo wariri, nigba ti won ba si ke awon ayah Re fun won, won yoo lekun ni igbagbo ododo. Oluwa won si ni won n gbarale

الَّذِينَ يُقِيمُونَ الصَّلَاةَ وَمِمَّا رَزَقْنَاهُمْ يُنفِقُونَ(3)

 (Awon ni) awon t’o n kirun, ti won si n na ninu ohun ti A pese fun won

أُولَٰئِكَ هُمُ الْمُؤْمِنُونَ حَقًّا ۚ لَّهُمْ دَرَجَاتٌ عِندَ رَبِّهِمْ وَمَغْفِرَةٌ وَرِزْقٌ كَرِيمٌ(4)

 Ni ododo, awon wonyen ni onigbagbo ododo. Awon ipo giga, aforijin ati arisiki alapon-onle n be fun won lodo Oluwa won

كَمَا أَخْرَجَكَ رَبُّكَ مِن بَيْتِكَ بِالْحَقِّ وَإِنَّ فَرِيقًا مِّنَ الْمُؤْمِنِينَ لَكَارِهُونَ(5)

 Gege bi Oluwa re se mu o jade (lo si oju ogun) lati inu ile re pelu ododo, dajudaju igun kan ninu awon onigbagbo ni emi won ko o

يُجَادِلُونَكَ فِي الْحَقِّ بَعْدَمَا تَبَيَّنَ كَأَنَّمَا يُسَاقُونَ إِلَى الْمَوْتِ وَهُمْ يَنظُرُونَ(6)

 Won si n tako o nibi ododo leyin ti o ti foju han (si won) afi bi eni pe won n wa won lo si odo iku, ti won si n wo o (bayii)

وَإِذْ يَعِدُكُمُ اللَّهُ إِحْدَى الطَّائِفَتَيْنِ أَنَّهَا لَكُمْ وَتَوَدُّونَ أَنَّ غَيْرَ ذَاتِ الشَّوْكَةِ تَكُونُ لَكُمْ وَيُرِيدُ اللَّهُ أَن يُحِقَّ الْحَقَّ بِكَلِمَاتِهِ وَيَقْطَعَ دَابِرَ الْكَافِرِينَ(7)

 (Ranti) nigba ti Allahu sadehun okan ninu awon ijo mejeeji fun yin pe o maa je tiyin, eyin si n fe ki ijo ti ko dira ogun je tiyin. Allahu si fe mu ododo se pelu awon oro Re, O si (fe) pa awon alaigbagbo run patapata

لِيُحِقَّ الْحَقَّ وَيُبْطِلَ الْبَاطِلَ وَلَوْ كَرِهَ الْمُجْرِمُونَ(8)

 nitori ki (Allahu) le fi ododo (’Islam) rinle ni ododo, ki O si le pana iro (iborisa), awon elese (osebo) ibaa korira re

إِذْ تَسْتَغِيثُونَ رَبَّكُمْ فَاسْتَجَابَ لَكُمْ أَنِّي مُمِدُّكُم بِأَلْفٍ مِّنَ الْمَلَائِكَةِ مُرْدِفِينَ(9)

 (Ranti) nigba ti e n wa iranlowo Oluwa yin, O si da yin lohun pe dajudaju Emi yoo ran yin lowo pelu egberun kan ninu awon molaika t’o maa wa ni telentele

وَمَا جَعَلَهُ اللَّهُ إِلَّا بُشْرَىٰ وَلِتَطْمَئِنَّ بِهِ قُلُوبُكُمْ ۚ وَمَا النَّصْرُ إِلَّا مِنْ عِندِ اللَّهِ ۚ إِنَّ اللَّهَ عَزِيزٌ حَكِيمٌ(10)

 Allahu ko si se (iranlowo awon molaika) lasan bi ko se nitori ki o le je iro idunnu ati nitori ki okan yin le bale pelu re. Ko si aranse kan afi lati odo Allahu. Dajudaju Allahu ni Alagbara, Ologbon

إِذْ يُغَشِّيكُمُ النُّعَاسَ أَمَنَةً مِّنْهُ وَيُنَزِّلُ عَلَيْكُم مِّنَ السَّمَاءِ مَاءً لِّيُطَهِّرَكُم بِهِ وَيُذْهِبَ عَنكُمْ رِجْزَ الشَّيْطَانِ وَلِيَرْبِطَ عَلَىٰ قُلُوبِكُمْ وَيُثَبِّتَ بِهِ الْأَقْدَامَ(11)

 (Ranti) nigba ti (Allahu) ta yin ni oogbe lo (ki o le je) ifokanbale (fun yin) lati odo Re. O tun so omi kale fun yin lati sanmo nitori ki O fi le fo yin mo (pelu iwe oran-anyan), ati nitori ki O fi le mu erokero Esu (bi ala ibalopo oju oorun) kuro fun yin ati nitori ki O le ki yin lokan ati nitori ki O le mu ese yin duro sinsin

إِذْ يُوحِي رَبُّكَ إِلَى الْمَلَائِكَةِ أَنِّي مَعَكُمْ فَثَبِّتُوا الَّذِينَ آمَنُوا ۚ سَأُلْقِي فِي قُلُوبِ الَّذِينَ كَفَرُوا الرُّعْبَ فَاضْرِبُوا فَوْقَ الْأَعْنَاقِ وَاضْرِبُوا مِنْهُمْ كُلَّ بَنَانٍ(12)

 (Ranti) nigba ti Oluwa re fi mo awon molaika pe dajudaju Emi n be pelu yin. Nitori naa, e fi ese awon t’o gbagbo ni ododo rinle. Emi yoo ju eru sinu okan awon t’o sai gbagbo. Nitori naa, e maa ge (won) loke orun. Ki e si maa ge gbogbo omo ika won

ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمْ شَاقُّوا اللَّهَ وَرَسُولَهُ ۚ وَمَن يُشَاقِقِ اللَّهَ وَرَسُولَهُ فَإِنَّ اللَّهَ شَدِيدُ الْعِقَابِ(13)

 Iyen nitori pe won tako (oro) Allahu ati Ojise Re. Enikeni ti o ba si tako (oro) Allahu ati Ojise Re, dajudaju Allahu le (nibi) iya

ذَٰلِكُمْ فَذُوقُوهُ وَأَنَّ لِلْكَافِرِينَ عَذَابَ النَّارِ(14)

 Iyen (niya taye). Nitori naa, e to o wo. Ati pe dajudaju iya Ina n be fun awon alaigbagbo

يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا إِذَا لَقِيتُمُ الَّذِينَ كَفَرُوا زَحْفًا فَلَا تُوَلُّوهُمُ الْأَدْبَارَ(15)

 Eyin ti e gbagbo ni ododo, nigba ti e ba pade awon t’o sai gbagbo, ti won n wo jade niko niko, eyin ko gbodo peyin da si won (lati sagun)

وَمَن يُوَلِّهِمْ يَوْمَئِذٍ دُبُرَهُ إِلَّا مُتَحَرِّفًا لِّقِتَالٍ أَوْ مُتَحَيِّزًا إِلَىٰ فِئَةٍ فَقَدْ بَاءَ بِغَضَبٍ مِّنَ اللَّهِ وَمَأْوَاهُ جَهَنَّمُ ۖ وَبِئْسَ الْمَصِيرُ(16)

 Enikeni ti o ba si peyin da si won ni ojo yen, yato si eni t’o ye si egbe kan (lati tunra mu) fun ogun tabi eni t’o fe darapo mo iko (musulumi lati fun won ni iro otele-muye), dajudaju (asagun) ti pada wale pelu ibinu lati odo Allahu. Ina Jahanamo si ni ibugbe re. Ikangun naa si buru

فَلَمْ تَقْتُلُوهُمْ وَلَٰكِنَّ اللَّهَ قَتَلَهُمْ ۚ وَمَا رَمَيْتَ إِذْ رَمَيْتَ وَلَٰكِنَّ اللَّهَ رَمَىٰ ۚ وَلِيُبْلِيَ الْمُؤْمِنِينَ مِنْهُ بَلَاءً حَسَنًا ۚ إِنَّ اللَّهَ سَمِيعٌ عَلِيمٌ(17)

 Eyin ko l’e pa won, sugbon Allahu l’O pa won. Ati pe iwo ko l’o juko nigba ti o juko, amo dajudaju Allahu l’O juko nitori ki (Allahu) le fi amiwo daadaa kan awon onigbagbo ododo lati odo Re ni. Dajudaju Allahu ni Olugbo, Onimo

ذَٰلِكُمْ وَأَنَّ اللَّهَ مُوهِنُ كَيْدِ الْكَافِرِينَ(18)

 Iyen (bayen). Dajudaju Allahu maa so ete awon alaigbagbo di lile

إِن تَسْتَفْتِحُوا فَقَدْ جَاءَكُمُ الْفَتْحُ ۖ وَإِن تَنتَهُوا فَهُوَ خَيْرٌ لَّكُمْ ۖ وَإِن تَعُودُوا نَعُدْ وَلَن تُغْنِيَ عَنكُمْ فِئَتُكُمْ شَيْئًا وَلَوْ كَثُرَتْ وَأَنَّ اللَّهَ مَعَ الْمُؤْمِنِينَ(19)

 Ti eyin (alaigbagbo) ba n wa idajo, dajudaju idajo ti ko le yin lori. Ti e ba jawo (nibi ogun), o si dara julo fun yin. Ti e ba tun pada (sibi ogun), A maa pada (ran awon onigbagbo ododo lowo); akojo yin ko si nii ro yin loro kan kan, ibaa po. Dajudaju Allahu n be pelu awon onigbagbo ododo

يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا أَطِيعُوا اللَّهَ وَرَسُولَهُ وَلَا تَوَلَّوْا عَنْهُ وَأَنتُمْ تَسْمَعُونَ(20)

 Eyin ti e gbagbo ni ododo, e tele ti Allahu ati Ojise Re. E ma se gbunri kuro ni odo re nigba ti e ba n gbo (ayah) lowo

وَلَا تَكُونُوا كَالَّذِينَ قَالُوا سَمِعْنَا وَهُمْ لَا يَسْمَعُونَ(21)

 E ma se da bi awon ti won wi pe: “A gbo.” Won ko si gbo

۞ إِنَّ شَرَّ الدَّوَابِّ عِندَ اللَّهِ الصُّمُّ الْبُكْمُ الَّذِينَ لَا يَعْقِلُونَ(22)

 Dajudaju eda abemi t’o buru julo ni odo Allahu ni awon aditi, ayaya ti ko se laakaye

وَلَوْ عَلِمَ اللَّهُ فِيهِمْ خَيْرًا لَّأَسْمَعَهُمْ ۖ وَلَوْ أَسْمَعَهُمْ لَتَوَلَّوا وَّهُم مُّعْرِضُونَ(23)

 Ti o ba je pe Allahu mo oore kan lara won ni, iba je ki won gbo. Ti (Allahu) ba si fun won gbo ni, dajudaju won maa peyin da, won yo si maa gbunri

يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا اسْتَجِيبُوا لِلَّهِ وَلِلرَّسُولِ إِذَا دَعَاكُمْ لِمَا يُحْيِيكُمْ ۖ وَاعْلَمُوا أَنَّ اللَّهَ يَحُولُ بَيْنَ الْمَرْءِ وَقَلْبِهِ وَأَنَّهُ إِلَيْهِ تُحْشَرُونَ(24)

 Eyin ti e gbagbo ni ododo, e jepe ti Allahu ati ti Ojise, nigba ti o ba pe yin sibi nnkan ti o maa mu yin semi. Ki e si mo pe dajudaju Allahu n sediwo laaarin eniyan ati okan re. Dajudaju odo Re si ni won maa ko yin jo si

وَاتَّقُوا فِتْنَةً لَّا تُصِيبَنَّ الَّذِينَ ظَلَمُوا مِنكُمْ خَاصَّةً ۖ وَاعْلَمُوا أَنَّ اللَّهَ شَدِيدُ الْعِقَابِ(25)

 E sora fun adanwo kan ti ko nii mo lori awon t’o sabosi ninu yin nikan. Ki e si mo pe dajudaju Allahu le nibi iya

وَاذْكُرُوا إِذْ أَنتُمْ قَلِيلٌ مُّسْتَضْعَفُونَ فِي الْأَرْضِ تَخَافُونَ أَن يَتَخَطَّفَكُمُ النَّاسُ فَآوَاكُمْ وَأَيَّدَكُم بِنَصْرِهِ وَرَزَقَكُم مِّنَ الطَّيِّبَاتِ لَعَلَّكُمْ تَشْكُرُونَ(26)

 E ranti pe nigba ti eyin kere, ti won n foju tinrin yin lori ile, ti e si n paya pe awon eniyan maa ji yin gbe lo, nigba naa (Allahu) se ibugbe fun yin (ninu ilu Modinah Onimoole), O si fi aranse Re se ikunlowo fun yin. O tun pese fun yin ninu awon nnkan daadaa nitori ki e le dupe

يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا تَخُونُوا اللَّهَ وَالرَّسُولَ وَتَخُونُوا أَمَانَاتِكُمْ وَأَنتُمْ تَعْلَمُونَ(27)

 Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se janba (oran-anyan) Allahu ati (sunnah) Ojise; e ma se janba awon agbafipamo yin, e si mo (ijanba)

وَاعْلَمُوا أَنَّمَا أَمْوَالُكُمْ وَأَوْلَادُكُمْ فِتْنَةٌ وَأَنَّ اللَّهَ عِندَهُ أَجْرٌ عَظِيمٌ(28)

 Ki e si mo pe dajudaju ifooro ni awon dukia yin ati awon omo yin, ati pe dajudaju Allahu ni esan nla wa ni odo Re

يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا إِن تَتَّقُوا اللَّهَ يَجْعَل لَّكُمْ فُرْقَانًا وَيُكَفِّرْ عَنكُمْ سَيِّئَاتِكُمْ وَيَغْفِرْ لَكُمْ ۗ وَاللَّهُ ذُو الْفَضْلِ الْعَظِيمِ(29)

 Eyin ti e gbagbo ni ododo, ti e ba beru Allahu, O maa fun yin ni ona abayo. O maa pa awon asise yin re fun yin. O si maa forijin yin. Allahu si ni Olola t’o tobi

وَإِذْ يَمْكُرُ بِكَ الَّذِينَ كَفَرُوا لِيُثْبِتُوكَ أَوْ يَقْتُلُوكَ أَوْ يُخْرِجُوكَ ۚ وَيَمْكُرُونَ وَيَمْكُرُ اللَّهُ ۖ وَاللَّهُ خَيْرُ الْمَاكِرِينَ(30)

 (Ranti) nigba ti awon t’o sai gbagbo n dete si o lati de o mole tabi lati pa o tabi lati yo o kuro ninu ilu; won n dete, Allahu si n dete. Allahu si loore julo ninu awon adete

وَإِذَا تُتْلَىٰ عَلَيْهِمْ آيَاتُنَا قَالُوا قَدْ سَمِعْنَا لَوْ نَشَاءُ لَقُلْنَا مِثْلَ هَٰذَا ۙ إِنْ هَٰذَا إِلَّا أَسَاطِيرُ الْأَوَّلِينَ(31)

 Nigba ti A ba n ke awon ayah Wa fun won, won a wi pe: “A kuku ti gbo. Ti o ba je pe a ba fe ni. awa naa iba so iru eyi. Ki ni eyi bi ko se akosile alo awon eni akoko.”

وَإِذْ قَالُوا اللَّهُمَّ إِن كَانَ هَٰذَا هُوَ الْحَقَّ مِنْ عِندِكَ فَأَمْطِرْ عَلَيْنَا حِجَارَةً مِّنَ السَّمَاءِ أَوِ ائْتِنَا بِعَذَابٍ أَلِيمٍ(32)

 (Ranti) nigba ti won wi pe: “Allahu, ti o ba je pe eyi ni ododo lati odo Re, ro ojo okuta le wa lori lati sanmo tabi ki O mu iya eleta-elero kan wa ba wa.”

وَمَا كَانَ اللَّهُ لِيُعَذِّبَهُمْ وَأَنتَ فِيهِمْ ۚ وَمَا كَانَ اللَّهُ مُعَذِّبَهُمْ وَهُمْ يَسْتَغْفِرُونَ(33)

 Allahu ko nii je won niya nigba ti iwo si n be laaarin won. Allahu ko si nii je won niya nigba ti won si n toro aforijin

وَمَا لَهُمْ أَلَّا يُعَذِّبَهُمُ اللَّهُ وَهُمْ يَصُدُّونَ عَنِ الْمَسْجِدِ الْحَرَامِ وَمَا كَانُوا أَوْلِيَاءَهُ ۚ إِنْ أَوْلِيَاؤُهُ إِلَّا الْمُتَّقُونَ وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَهُمْ لَا يَعْلَمُونَ(34)

 Ko si idi ti Allahu ko fi nii je won niya niwon igba ti won ba n se awon eniyan lori kuro ninu Mosalasi Haram. Ati pe awon osebo ko ni alamojuuto re. Ko si alamojuuto kan fun un bi ko se awon oluberu (Allahu), sugbon opolopo won ni ko mo

وَمَا كَانَ صَلَاتُهُمْ عِندَ الْبَيْتِ إِلَّا مُكَاءً وَتَصْدِيَةً ۚ فَذُوقُوا الْعَذَابَ بِمَا كُنتُمْ تَكْفُرُونَ(35)

 Ijosin awon osebo ni Ile (Kaabah) ko si tayo sisu ife ati pipa atewo. Nitori naa, e to Iya wo nitori pe e je alaigbagbo

إِنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا يُنفِقُونَ أَمْوَالَهُمْ لِيَصُدُّوا عَن سَبِيلِ اللَّهِ ۚ فَسَيُنفِقُونَهَا ثُمَّ تَكُونُ عَلَيْهِمْ حَسْرَةً ثُمَّ يُغْلَبُونَ ۗ وَالَّذِينَ كَفَرُوا إِلَىٰ جَهَنَّمَ يُحْشَرُونَ(36)

 Dajudaju awon t’o sai gbagbo, won n na dukia won nitori ki won le seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Allahu. Won si n na a lo (bee). Leyin naa, o maa di abamo fun won. Leyin naa, A si maa bori won. Ati pe awon t’o sai gbagbo, inu ina Jahanamo ni A maa ko won jo si

لِيَمِيزَ اللَّهُ الْخَبِيثَ مِنَ الطَّيِّبِ وَيَجْعَلَ الْخَبِيثَ بَعْضَهُ عَلَىٰ بَعْضٍ فَيَرْكُمَهُ جَمِيعًا فَيَجْعَلَهُ فِي جَهَنَّمَ ۚ أُولَٰئِكَ هُمُ الْخَاسِرُونَ(37)

 nitori ki Allahu le ya awon eni ibi soto kuro lara awon eni ire ati nitori ki O le ko awon eni ibi papo; apa kan won mo apa kan, ki O si le ro gbogbo won papo patapata (soju kan naa), O si maa fi won sinu ina Jahanamo. Awon wonyen, awon ni eni ofo

قُل لِّلَّذِينَ كَفَرُوا إِن يَنتَهُوا يُغْفَرْ لَهُم مَّا قَدْ سَلَفَ وَإِن يَعُودُوا فَقَدْ مَضَتْ سُنَّتُ الْأَوَّلِينَ(38)

 So fun awon t’o sai gbagbo pe ti won ba jawo (ninu aigbagbo), A maa saforijin ohun t’o ti re koja fun won. Ti won ba tun pada (sibe, apejuwe) iparun awon eni akoko kuku ti re koja (ni ikilo fun won)

وَقَاتِلُوهُمْ حَتَّىٰ لَا تَكُونَ فِتْنَةٌ وَيَكُونَ الدِّينُ كُلُّهُ لِلَّهِ ۚ فَإِنِ انتَهَوْا فَإِنَّ اللَّهَ بِمَا يَعْمَلُونَ بَصِيرٌ(39)

 E ja won logun titi ko fi nii si ifooro (iborisa) mo, gbogbo esin yo si le je ti Allahu. Nitori naa, ti won ba jawo (ninu aigbagbo), dajudaju Allahu ni Oluriran nipa ohun ti won n se nise

وَإِن تَوَلَّوْا فَاعْلَمُوا أَنَّ اللَّهَ مَوْلَاكُمْ ۚ نِعْمَ الْمَوْلَىٰ وَنِعْمَ النَّصِيرُ(40)

 Ti won ba si gbunri (kuro ninu igbagbo), e mo pe dajudaju Allahu ni Alafeyinti yin. O dara ni Alafeyinti. O si dara ni Alaranse

۞ وَاعْلَمُوا أَنَّمَا غَنِمْتُم مِّن شَيْءٍ فَأَنَّ لِلَّهِ خُمُسَهُ وَلِلرَّسُولِ وَلِذِي الْقُرْبَىٰ وَالْيَتَامَىٰ وَالْمَسَاكِينِ وَابْنِ السَّبِيلِ إِن كُنتُمْ آمَنتُم بِاللَّهِ وَمَا أَنزَلْنَا عَلَىٰ عَبْدِنَا يَوْمَ الْفُرْقَانِ يَوْمَ الْتَقَى الْجَمْعَانِ ۗ وَاللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ(41)

 E mo pe ohunkohun ti e ba ko ni oro ogun, dajudaju ti Allahu ni ida marun-un re. O si wa fun Ojise ati ebi (re) ati awon omo orukan, awon mekunnu ati onirin-ajo (ti agara da), ti e ba je eni t’o gbagbo ninu Allahu ati nnkan ti A sokale fun erusin Wa ni Ojo ipinya, ojo ti ijo meji pade (loju ogun Badr). Allahu si ni Alagbara lori gbogbo nnkan

إِذْ أَنتُم بِالْعُدْوَةِ الدُّنْيَا وَهُم بِالْعُدْوَةِ الْقُصْوَىٰ وَالرَّكْبُ أَسْفَلَ مِنكُمْ ۚ وَلَوْ تَوَاعَدتُّمْ لَاخْتَلَفْتُمْ فِي الْمِيعَادِ ۙ وَلَٰكِن لِّيَقْضِيَ اللَّهُ أَمْرًا كَانَ مَفْعُولًا لِّيَهْلِكَ مَنْ هَلَكَ عَن بَيِّنَةٍ وَيَحْيَىٰ مَنْ حَيَّ عَن بَيِّنَةٍ ۗ وَإِنَّ اللَّهَ لَسَمِيعٌ عَلِيمٌ(42)

 (E ranti) nigba ti eyin wa ni eti koto t’o sunmo (ilu Modinah), awon (keferi) si wa ni eti koto t’o jinna si (ilu Modinah), awon keferi kan t’o n gun nnkan igun (bo lati irin-ajo okowo), won si wa ni isale odo tiyin. Ti o ba je pe eyin ati awon keferi jo mu ojo fun ogun naa ni, eyin iba yapa adehun naa, sugbon (ogun naa sele bee) nitori ki Allahu le mu oro kan ti o gbodo se wa si imuse; nitori ki eni ti o maa parun (sinu aigbagbo) le parun nipase eri t’o yanju, ki eni t’o si maa ye (ninu igbagbo ododo) le ye nipase eri t’o yanju. Ati pe dajudaju Allahu kuku ni Olugbo, Onimo

إِذْ يُرِيكَهُمُ اللَّهُ فِي مَنَامِكَ قَلِيلًا ۖ وَلَوْ أَرَاكَهُمْ كَثِيرًا لَّفَشِلْتُمْ وَلَتَنَازَعْتُمْ فِي الْأَمْرِ وَلَٰكِنَّ اللَّهَ سَلَّمَ ۗ إِنَّهُ عَلِيمٌ بِذَاتِ الصُّدُورِ(43)

 (Ranti) nigba ti Allahu fi won han o ninu ala re (pe won) kere. Ti o ba je pe O fi won han o (pe won) po ni, eyin iba sojo, eyin iba si sariyanjiyan nipa oro naa. Sugbon Allahu ko (yin) yo. Dajudaju Oun ni Onimo nipa nnkan ti n be ninu igba-aya eda

وَإِذْ يُرِيكُمُوهُمْ إِذِ الْتَقَيْتُمْ فِي أَعْيُنِكُمْ قَلِيلًا وَيُقَلِّلُكُمْ فِي أَعْيُنِهِمْ لِيَقْضِيَ اللَّهُ أَمْرًا كَانَ مَفْعُولًا ۗ وَإِلَى اللَّهِ تُرْجَعُ الْأُمُورُ(44)

 (Ranti) nigba ti O n fi won han yin pe won kere loju yin - nigba ti e pade (loju ogun) – O si mu eyin naa kere loju tiwon naa, nitori ki Allahu le mu oro kan ti o gbodo se wa si imuse. Odo Allahu si ni won maa seri awon oro eda pada si

يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا إِذَا لَقِيتُمْ فِئَةً فَاثْبُتُوا وَاذْكُرُوا اللَّهَ كَثِيرًا لَّعَلَّكُمْ تُفْلِحُونَ(45)

 Eyin ti e gbagbo ni ododo, nigba ti e ba pade ijo (ogun) kan, e duro sinsin, ki e si se (gbolohun) iranti Allahu ni (onka) pupo nitori ki e le jere

وَأَطِيعُوا اللَّهَ وَرَسُولَهُ وَلَا تَنَازَعُوا فَتَفْشَلُوا وَتَذْهَبَ رِيحُكُمْ ۖ وَاصْبِرُوا ۚ إِنَّ اللَّهَ مَعَ الصَّابِرِينَ(46)

 E tele ti Allahu ati Ojise Re. E ma se jara yin niyan (nipa ogun esin) nitori ki e ma baa sojo ati nitori ki agbara yin ma baa kuro lowo yin. E se suuru, dajudaju Allahu wa pelu awon onisuuru

وَلَا تَكُونُوا كَالَّذِينَ خَرَجُوا مِن دِيَارِهِم بَطَرًا وَرِئَاءَ النَّاسِ وَيَصُدُّونَ عَن سَبِيلِ اللَّهِ ۚ وَاللَّهُ بِمَا يَعْمَلُونَ مُحِيطٌ(47)

 E ma se da bi awon t’o jade kuro ninu ile won pelu faaari ati sekarimi. Won si n seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Allahu. Allahu si ni Alamotan nipa ohun ti won n se nise

وَإِذْ زَيَّنَ لَهُمُ الشَّيْطَانُ أَعْمَالَهُمْ وَقَالَ لَا غَالِبَ لَكُمُ الْيَوْمَ مِنَ النَّاسِ وَإِنِّي جَارٌ لَّكُمْ ۖ فَلَمَّا تَرَاءَتِ الْفِئَتَانِ نَكَصَ عَلَىٰ عَقِبَيْهِ وَقَالَ إِنِّي بَرِيءٌ مِّنكُمْ إِنِّي أَرَىٰ مَا لَا تَرَوْنَ إِنِّي أَخَافُ اللَّهَ ۚ وَاللَّهُ شَدِيدُ الْعِقَابِ(48)

 (Ranti) nigba ti Esu se ise won ni oso fun won, o si wi pe: “Ko si eni ti o maa bori yin lonii ninu awon eniyan. Dajudaju emi ni aladuugbo yin.” Sugbon nigba ti awon ijo ogun mejeeji foju kanra won, o pada seyin, o si fese fee, o wi pe: "Dajudaju emi ti yowo-yose ninu oro yin. Dajudaju emi n ri ohun ti eyin ko ri. Emi n paya Allahu. Allahu si le nibi iya

إِذْ يَقُولُ الْمُنَافِقُونَ وَالَّذِينَ فِي قُلُوبِهِم مَّرَضٌ غَرَّ هَٰؤُلَاءِ دِينُهُمْ ۗ وَمَن يَتَوَكَّلْ عَلَى اللَّهِ فَإِنَّ اللَّهَ عَزِيزٌ حَكِيمٌ(49)

 (Ranti) nigba ti awon sobe-selu musulumi ati awon ti arun n be ninu okan won wi pe: “Esin awon wonyi tan won je.” Enikeni t’o ba gbarale Allahu, dajudaju Allahu ni Alagbara, Ologbon

وَلَوْ تَرَىٰ إِذْ يَتَوَفَّى الَّذِينَ كَفَرُوا ۙ الْمَلَائِكَةُ يَضْرِبُونَ وُجُوهَهُمْ وَأَدْبَارَهُمْ وَذُوقُوا عَذَابَ الْحَرِيقِ(50)

 Ti o ba je pe iwo ri i nigba ti awon molaika ba n gba emi awon t’o sai gbagbo ni, ti won n lu oju won ati eyin won, (won si maa so fun won pe), “E to iya Ina jonijoni wo.”

ذَٰلِكَ بِمَا قَدَّمَتْ أَيْدِيكُمْ وَأَنَّ اللَّهَ لَيْسَ بِظَلَّامٍ لِّلْعَبِيدِ(51)

 Iyen nitori ohun ti owo yin ti siwaju. Ati pe dajudaju Allahu ko nii se abosi fun awon eru (Re)

كَدَأْبِ آلِ فِرْعَوْنَ ۙ وَالَّذِينَ مِن قَبْلِهِمْ ۚ كَفَرُوا بِآيَاتِ اللَّهِ فَأَخَذَهُمُ اللَّهُ بِذُنُوبِهِمْ ۗ إِنَّ اللَّهَ قَوِيٌّ شَدِيدُ الْعِقَابِ(52)

 (Isesi awon alaigbagbo) da bi isesi awon eniyan Fir‘aon ati awon t’o siwaju won - won sai gbagbo ninu awon ayah Allahu. - Nitori naa, Allahu mu won nitori ese won. Dajudaju Allahu ni Alagbara, O le nibi iya

ذَٰلِكَ بِأَنَّ اللَّهَ لَمْ يَكُ مُغَيِّرًا نِّعْمَةً أَنْعَمَهَا عَلَىٰ قَوْمٍ حَتَّىٰ يُغَيِّرُوا مَا بِأَنفُسِهِمْ ۙ وَأَنَّ اللَّهَ سَمِيعٌ عَلِيمٌ(53)

 Iyen nitori pe dajudaju Allahu ko nii se iyipada idera ti O se fun ijo kan titi won yoo fi se iyipada nnkan ti n be lodo ara won. Dajudaju Allahu si ni Olugbo, Onimo

كَدَأْبِ آلِ فِرْعَوْنَ ۙ وَالَّذِينَ مِن قَبْلِهِمْ ۚ كَذَّبُوا بِآيَاتِ رَبِّهِمْ فَأَهْلَكْنَاهُم بِذُنُوبِهِمْ وَأَغْرَقْنَا آلَ فِرْعَوْنَ ۚ وَكُلٌّ كَانُوا ظَالِمِينَ(54)

 (Isesi awon alaimoore) da bi isesi awon eniyan Fir‘aon ati awon t’o siwaju won, ti won pe awon ayah Oluwa won niro. Nitori naa, A pa won run nitori ese won; A si te awon eniyan Fir‘aon ri sinu agbami. Gbogbo won si je alabosi

إِنَّ شَرَّ الدَّوَابِّ عِندَ اللَّهِ الَّذِينَ كَفَرُوا فَهُمْ لَا يُؤْمِنُونَ(55)

 Dajudaju eda abemi t’o buru julo lodo Allahu ni awon t’o sai gbagbo. Nitori naa, won ko nii gbagbo

الَّذِينَ عَاهَدتَّ مِنْهُمْ ثُمَّ يَنقُضُونَ عَهْدَهُمْ فِي كُلِّ مَرَّةٍ وَهُمْ لَا يَتَّقُونَ(56)

 Awon ti o ba se adehun ninu won, leyin naa ti won n tu adehun won ni gbogbo igba, ti won ko si beru (Allahu)

فَإِمَّا تَثْقَفَنَّهُمْ فِي الْحَرْبِ فَشَرِّدْ بِهِم مَّنْ خَلْفَهُمْ لَعَلَّهُمْ يَذَّكَّرُونَ(57)

 yala ti owo yin ba ba won loju ogun, (e pa won) ki e si (fi ogun) tu awon omoleyin won ka nitori ki won le lo iranti

وَإِمَّا تَخَافَنَّ مِن قَوْمٍ خِيَانَةً فَانبِذْ إِلَيْهِمْ عَلَىٰ سَوَاءٍ ۚ إِنَّ اللَّهَ لَا يُحِبُّ الْخَائِنِينَ(58)

 tabi ti o ba si n paya iwa ijanba lati odo ijo kan, ju adehun won sile fun won ki e di jo mo pe ko si adehun kan mo laaarin eyin mejeeji. Dajudaju Allahu ko nifee awon onijanba

وَلَا يَحْسَبَنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا سَبَقُوا ۚ إِنَّهُمْ لَا يُعْجِزُونَ(59)

 Ki awon t’o sai gbagbo ma se lero pe awon ti gbawaju. Dajudaju won ko le mori bo (ninu iya)

وَأَعِدُّوا لَهُم مَّا اسْتَطَعْتُم مِّن قُوَّةٍ وَمِن رِّبَاطِ الْخَيْلِ تُرْهِبُونَ بِهِ عَدُوَّ اللَّهِ وَعَدُوَّكُمْ وَآخَرِينَ مِن دُونِهِمْ لَا تَعْلَمُونَهُمُ اللَّهُ يَعْلَمُهُمْ ۚ وَمَا تُنفِقُوا مِن شَيْءٍ فِي سَبِيلِ اللَّهِ يُوَفَّ إِلَيْكُمْ وَأَنتُمْ لَا تُظْلَمُونَ(60)

 E pese sile de won nnkan ija ti agbara yin ka ninu nnkan amusagbara ati awon esin ori iso, ti eyin yoo fi maa deru ba ota Allahu ati ota yin pelu awon miiran yato si won, ti eyin ko mo won – Allahu si mo won. – Ohunkohun ti e ba na loju ona (esin) Allahu, A oo san an pada fun yin ni kikun; A o si nii se abosi fun yin

۞ وَإِن جَنَحُوا لِلسَّلْمِ فَاجْنَحْ لَهَا وَتَوَكَّلْ عَلَى اللَّهِ ۚ إِنَّهُ هُوَ السَّمِيعُ الْعَلِيمُ(61)

 Ti won ba te sibi (eto) alaafia (fun dida ogun duro), iwo naa te sibe, ki o si gbarale Allahu. Dajudaju Oun ma ni Olugbo, Onimo

وَإِن يُرِيدُوا أَن يَخْدَعُوكَ فَإِنَّ حَسْبَكَ اللَّهُ ۚ هُوَ الَّذِي أَيَّدَكَ بِنَصْرِهِ وَبِالْمُؤْمِنِينَ(62)

 Ti won ba tun fe tan o je, dajudaju Allahu a to o. Oun ni Eni ti O fi aranse Re ati awon onigbagbo ododo ran o lowo

وَأَلَّفَ بَيْنَ قُلُوبِهِمْ ۚ لَوْ أَنفَقْتَ مَا فِي الْأَرْضِ جَمِيعًا مَّا أَلَّفْتَ بَيْنَ قُلُوبِهِمْ وَلَٰكِنَّ اللَّهَ أَلَّفَ بَيْنَهُمْ ۚ إِنَّهُ عَزِيزٌ حَكِيمٌ(63)

 Allahu pa okan won po mora won. Ti o ba je pe o na gbogbo nnkan ti n be lori ile patapata, iwo ko le pa okan won po mora won. Sugbon Allahu pa okan won po mora won, dajudaju Oun ni Alagbara, Ologbon

يَا أَيُّهَا النَّبِيُّ حَسْبُكَ اللَّهُ وَمَنِ اتَّبَعَكَ مِنَ الْمُؤْمِنِينَ(64)

 Iwo Anabi, Allahu ti to iwo ati awon t’o tele o ninu awon onigbagbo ododo

يَا أَيُّهَا النَّبِيُّ حَرِّضِ الْمُؤْمِنِينَ عَلَى الْقِتَالِ ۚ إِن يَكُن مِّنكُمْ عِشْرُونَ صَابِرُونَ يَغْلِبُوا مِائَتَيْنِ ۚ وَإِن يَكُن مِّنكُم مِّائَةٌ يَغْلِبُوا أَلْفًا مِّنَ الَّذِينَ كَفَرُوا بِأَنَّهُمْ قَوْمٌ لَّا يَفْقَهُونَ(65)

 Iwo Anabi, gba awon onigbagbo ododo ni iyanju lori ogun esin. Ti ogun onisuuru ba wa ninu yin, won yoo bori igba. Ti ogorun-un ba si wa ninu yin, won yoo bori egberun ninu awon t’o sai gbagbo nitori pe dajudaju won je ijo ti ko gbo agboye

الْآنَ خَفَّفَ اللَّهُ عَنكُمْ وَعَلِمَ أَنَّ فِيكُمْ ضَعْفًا ۚ فَإِن يَكُن مِّنكُم مِّائَةٌ صَابِرَةٌ يَغْلِبُوا مِائَتَيْنِ ۚ وَإِن يَكُن مِّنكُمْ أَلْفٌ يَغْلِبُوا أَلْفَيْنِ بِإِذْنِ اللَّهِ ۗ وَاللَّهُ مَعَ الصَّابِرِينَ(66)

 Nisisin yii, Allahu ti se e ni fifuye fun yin. O si mo pe dajudaju ailagbara n be fun yin. Nitori naa, ti ogorun-un onisuuru ba wa ninu yin, won yoo bori igba. Ti egberun kan ba si wa ninu yin, won yoo bori egberun meji pelu ase Allahu. Allahu si wa pelu awon onisuuru

مَا كَانَ لِنَبِيٍّ أَن يَكُونَ لَهُ أَسْرَىٰ حَتَّىٰ يُثْخِنَ فِي الْأَرْضِ ۚ تُرِيدُونَ عَرَضَ الدُّنْيَا وَاللَّهُ يُرِيدُ الْآخِرَةَ ۗ وَاللَّهُ عَزِيزٌ حَكِيمٌ(67)

 Ko letoo fun Anabi kan lati ni eru ogun (ki o si tu won sile pelu owo itusile) titi o fi maa segun (won) tan patapata lori ile. Eyin n fe igbadun aye, Allahu si n fe orun. Allahu si ni Alagbara, Ologbon

لَّوْلَا كِتَابٌ مِّنَ اللَّهِ سَبَقَ لَمَسَّكُمْ فِيمَا أَخَذْتُمْ عَذَابٌ عَظِيمٌ(68)

 Ti ki i ba se ti akosile kan t’o ti gbawaju lati odo Allahu ni, owo iya nla ko ba te yin nipa nnkan ti e gba (ni owo itusile)

فَكُلُوا مِمَّا غَنِمْتُمْ حَلَالًا طَيِّبًا ۚ وَاتَّقُوا اللَّهَ ۚ إِنَّ اللَّهَ غَفُورٌ رَّحِيمٌ(69)

 Nitori naa, e je ninu ohun ti e ko ni oro ogun (ti o je) eto (ati) nnkan daadaa. Ki e si beru Allahu. Dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun

يَا أَيُّهَا النَّبِيُّ قُل لِّمَن فِي أَيْدِيكُم مِّنَ الْأَسْرَىٰ إِن يَعْلَمِ اللَّهُ فِي قُلُوبِكُمْ خَيْرًا يُؤْتِكُمْ خَيْرًا مِّمَّا أُخِذَ مِنكُمْ وَيَغْفِرْ لَكُمْ ۗ وَاللَّهُ غَفُورٌ رَّحِيمٌ(70)

 Iwo Anabi, so fun awon t’o n be lowo yin ninu awon eru ogun pe, “Ti Allahu ba mo daadaa kan ninu okan yin, O maa fun yin ni ohun t’o dara ju ohun ti won gba lowo yin. O si maa forijin yin. Allahu si ni Alaforijin, Onikee.”

وَإِن يُرِيدُوا خِيَانَتَكَ فَقَدْ خَانُوا اللَّهَ مِن قَبْلُ فَأَمْكَنَ مِنْهُمْ ۗ وَاللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٌ(71)

 Ti won ba si n gbero ijanba si o, won kuku ti janba Allahu siwaju. O si fun o lagbara lori won. Allahu si ni Onimo, Ologbon

إِنَّ الَّذِينَ آمَنُوا وَهَاجَرُوا وَجَاهَدُوا بِأَمْوَالِهِمْ وَأَنفُسِهِمْ فِي سَبِيلِ اللَّهِ وَالَّذِينَ آوَوا وَّنَصَرُوا أُولَٰئِكَ بَعْضُهُمْ أَوْلِيَاءُ بَعْضٍ ۚ وَالَّذِينَ آمَنُوا وَلَمْ يُهَاجِرُوا مَا لَكُم مِّن وَلَايَتِهِم مِّن شَيْءٍ حَتَّىٰ يُهَاجِرُوا ۚ وَإِنِ اسْتَنصَرُوكُمْ فِي الدِّينِ فَعَلَيْكُمُ النَّصْرُ إِلَّا عَلَىٰ قَوْمٍ بَيْنَكُمْ وَبَيْنَهُم مِّيثَاقٌ ۗ وَاللَّهُ بِمَا تَعْمَلُونَ بَصِيرٌ(72)

 Dajudaju awon t’o gbagbo ni ododo, ti won gbe ilu won ju sile, ti won si fi dukia won ati emi won jagun loju ona (esin) Allahu, ati awon t’o gba won sodo (ninu ilu), ti won si ran won lowo; awon wonyen, apa kan won l’ore apa kan (t’o le jogun ara won). Awon t’o gbagbo, ti won ko si gbe ilu won ju sile, ko letoo fun yin lati mu won loree nibi kan kan (t’o le mu yin jogun ara yin), titi won yoo fi gbe ilu won ju sile. Ti won ba si wa iranlowo yin (lori ota) nipa esin, iranlowo naa di dandan fun yin ayafi lori ijo kan ti adehun n be laaarin eyin ati awon. Allahu si ni Oluriran nipa ohun ti e n se nise

وَالَّذِينَ كَفَرُوا بَعْضُهُمْ أَوْلِيَاءُ بَعْضٍ ۚ إِلَّا تَفْعَلُوهُ تَكُن فِتْنَةٌ فِي الْأَرْضِ وَفَسَادٌ كَبِيرٌ(73)

 Awon alaigbagbo; apa kan won ni alatileyin apa kan. Afi ki eyin naa se bee ni ifooro ati ibaje t’o tobi ko fi nii wa lori ile

وَالَّذِينَ آمَنُوا وَهَاجَرُوا وَجَاهَدُوا فِي سَبِيلِ اللَّهِ وَالَّذِينَ آوَوا وَّنَصَرُوا أُولَٰئِكَ هُمُ الْمُؤْمِنُونَ حَقًّا ۚ لَّهُم مَّغْفِرَةٌ وَرِزْقٌ كَرِيمٌ(74)

 Awon t’o gbagbo ni ododo, ti won gbe ilu won ju sile, ti won si jagun l’oju ona (esin) Allahu ati awon t’o gba won sodo (ninu ilu), ti won si ran won lowo; ni ti ododo awon wonyen, awon ni onigbagbo ododo. Aforijin ati arisiki alapon-onle si wa fun won

وَالَّذِينَ آمَنُوا مِن بَعْدُ وَهَاجَرُوا وَجَاهَدُوا مَعَكُمْ فَأُولَٰئِكَ مِنكُمْ ۚ وَأُولُو الْأَرْحَامِ بَعْضُهُمْ أَوْلَىٰ بِبَعْضٍ فِي كِتَابِ اللَّهِ ۗ إِنَّ اللَّهَ بِكُلِّ شَيْءٍ عَلِيمٌ(75)

 Awon t’o gbagbo ni ododo leyin (won), ti won gbe ilu won ju sile, ti won si jagun esin pelu yin, awon wonyen naa wa lara yin. Ati pe awon ibatan, apa kan won ni eto julo si apa kan (nipa ogun jije) ninu Tira Allahu. Dajudaju Allahu ni Onimo nipa gbogbo nnkan


More surahs in Yoruba:


Al-Baqarah Al-'Imran An-Nisa'
Al-Ma'idah Yusuf Ibrahim
Al-Hijr Al-Kahf Maryam
Al-Hajj Al-Qasas Al-'Ankabut
As-Sajdah Ya Sin Ad-Dukhan
Al-Fath Al-Hujurat Qaf
An-Najm Ar-Rahman Al-Waqi'ah
Al-Hashr Al-Mulk Al-Haqqah
Al-Inshiqaq Al-A'la Al-Ghashiyah

Download surah Al-Anfal with the voice of the most famous Quran reciters :

surah Al-Anfal mp3 : choose the reciter to listen and download the chapter Al-Anfal Complete with high quality
surah Al-Anfal Ahmed El Agamy
Ahmed Al Ajmy
surah Al-Anfal Bandar Balila
Bandar Balila
surah Al-Anfal Khalid Al Jalil
Khalid Al Jalil
surah Al-Anfal Saad Al Ghamdi
Saad Al Ghamdi
surah Al-Anfal Saud Al Shuraim
Saud Al Shuraim
surah Al-Anfal Abdul Basit Abdul Samad
Abdul Basit
surah Al-Anfal Abdul Rashid Sufi
Abdul Rashid Sufi
surah Al-Anfal Abdullah Basfar
Abdullah Basfar
surah Al-Anfal Abdullah Awwad Al Juhani
Abdullah Al Juhani
surah Al-Anfal Fares Abbad
Fares Abbad
surah Al-Anfal Maher Al Muaiqly
Maher Al Muaiqly
surah Al-Anfal Muhammad Siddiq Al Minshawi
Al Minshawi
surah Al-Anfal Al Hosary
Al Hosary
surah Al-Anfal Al-afasi
Mishari Al-afasi
surah Al-Anfal Yasser Al Dosari
Yasser Al Dosari


Thursday, November 21, 2024

لا تنسنا من دعوة صالحة بظهر الغيب