📖 0/604 oju-iwe ti a ka
📄 17
Al-Baqarah

Al-Baqarah

2:106
۞ مَا نَنسَخۡ مِنۡ ءَايَةٍ أَوۡ نُنسِهَا نَأۡتِ بِخَيۡرٍ مِّنۡهَآ أَوۡ مِثۡلِهَآۗ أَلَمۡ تَعۡلَمۡ أَنَّ ٱللَّهَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٍ قَدِيرٌ ١٠٦
A o nii fi ayah kan pa ayah kan re tabi ki A fi sile (bee ni ohun kike nikan), A maa mu eyi t’o dara ju u lo tabi iru re wa. Se iwo ko mo pe dajudaju Allahu ni Alagbara lori gbogbo nnkan
2:107
أَلَمۡ تَعۡلَمۡ أَنَّ ٱللَّهَ لَهُۥ مُلۡكُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۗ وَمَا لَكُم مِّن دُونِ ٱللَّهِ مِن وَلِيٍّ وَلَا نَصِيرٍ ١٠٧
Se iwo ko mo pe dajudaju ti Allahu ni ijoba awon sanmo ati ile? Ko si si alaabo ati alaranse kan fun yin leyin Allahu
2:108
أَمۡ تُرِيدُونَ أَن تَسۡـَٔلُواْ رَسُولَكُمۡ كَمَا سُئِلَ مُوسَىٰ مِن قَبۡلُۗ وَمَن يَتَبَدَّلِ ٱلۡكُفۡرَ بِٱلۡإِيمَٰنِ فَقَدۡ ضَلَّ سَوَآءَ ٱلسَّبِيلِ ١٠٨
Tabi e fe maa beere (orokoro) lowo Ojise yin ni gege bi won se beere (orokoro) lowo (Anabi) Musa siwaju? Enikeni ti o ba fi aigbagbo ropo igbagbo, dajudaju o ti sina (kuro) l’oju ona taara
2:109
وَدَّ كَثِيرٌ مِّنۡ أَهۡلِ ٱلۡكِتَٰبِ لَوۡ يَرُدُّونَكُم مِّنۢ بَعۡدِ إِيمَٰنِكُمۡ كُفَّارًا حَسَدًا مِّنۡ عِندِ أَنفُسِهِم مِّنۢ بَعۡدِ مَا تَبَيَّنَ لَهُمُ ٱلۡحَقُّۖ فَٱعۡفُواْ وَٱصۡفَحُواْ حَتَّىٰ يَأۡتِيَ ٱللَّهُ بِأَمۡرِهِۦٓۗ إِنَّ ٱللَّهَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٍ قَدِيرٌ ١٠٩
Opolopo ninu awon ti A fun ni Tira n fe lati da yin pada sipo keferi leyin ti e ti ni igbagbo ododo, ni ti keeta lati inu emi won, (ati) leyin ti ododo (’Islam) ti foju han si won. Nitori naa, e forijin won, ki e samoju kuro fun won (nipa inira ti won n fi kan yin) titi Allahu yo fi mu ase Re wa (lati ja won logun). Dajudaju Allahu ni Alagbara lori gbogbo nnkan
2:110
وَأَقِيمُواْ ٱلصَّلَوٰةَ وَءَاتُواْ ٱلزَّكَوٰةَۚ وَمَا تُقَدِّمُواْ لِأَنفُسِكُم مِّنۡ خَيۡرٍ تَجِدُوهُ عِندَ ٱللَّهِۗ إِنَّ ٱللَّهَ بِمَا تَعۡمَلُونَ بَصِيرٌ ١١٠
E kirun, e yo Zakah; ohunkohun ti e ba si ti siwaju fun emi ara yin ni rere, e maa ba a lodo Allahu. Dajudaju Allahu ni Oluriran nipa ohun ti e n se nise
2:111
وَقَالُواْ لَن يَدۡخُلَ ٱلۡجَنَّةَ إِلَّا مَن كَانَ هُودًا أَوۡ نَصَٰرَىٰۗ تِلۡكَ أَمَانِيُّهُمۡۗ قُلۡ هَاتُواْ بُرۡهَٰنَكُمۡ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ ١١١
Won wi pe: “Eni kan ko nii wo inu Ogba Idera afi eni ti o ba je yehudi tabi nasara.” Iyen ni ife-okan won. So pe: “E mu eri oro yin wa ti e ba je olododo
2:112
بَلَىٰۚ مَنۡ أَسۡلَمَ وَجۡهَهُۥ لِلَّهِ وَهُوَ مُحۡسِنٌ فَلَهُۥٓ أَجۡرُهُۥ عِندَ رَبِّهِۦ وَلَا خَوۡفٌ عَلَيۡهِمۡ وَلَا هُمۡ يَحۡزَنُونَ ١١٢
Bee ko (won ko nii wo inu Ogba Idera afi) eni ti o ba ju ara re sile (ninu ’Islam) fun Allahu, ti o si je oluse rere. Nitori naa, esan (ise) re n be fun un lodo Oluwa re. Ko nii si iberu fun won. Won ko si nii banuje
العربيةEnglishBahasa IndonesiaTürkçeРусскийفارسیFrançaisاردوবাংলাDeutschEspañol中文हिन्दीPortuguêsItalianoภาษาไทยPolskiNederlandsShqipKiswahiliO'zbekதமிழ்MelayuBosanskiSoomaaliAzərbaycanکوردی한국어日本語SvenskaDanskNorskپښتوമലയാളംසිංහලTamazightHausaአማርኛБългарскиТоҷикӣҚазақшаFilipinoسنڌيYorùbáFulfuldeТатарчаئۇيغۇرچەКыргызчаਪੰਜਾਬੀJawaతెలుగుမြန်မာગુજરાતીOromoमराठीTiếng ViệtMalagasyНохчийнWolofދިވެހިಕನ್ನಡУкраїнськаΕλληνικάქართულიខ្មែរدریQafar afMaranaoनेपाली
Al-Kur'an
Wednesday, August 19, 2026
Don't forget us in your sincere prayers







