سوره احزاب به زبان یوروبا

  1. گوش دادن به سوره
  2. سورهای دیگر
  3. ترجمه سوره
قرآن کریم | ترجمه معانی قرآن | زبان یوروبا | سوره احزاب | الأحزاب - تعداد آیات آن 73 - شماره سوره در مصحف: 33 - معنی سوره به انگلیسی: Confederates - The Combined Forces.

يَا أَيُّهَا النَّبِيُّ اتَّقِ اللَّهَ وَلَا تُطِعِ الْكَافِرِينَ وَالْمُنَافِقِينَ ۗ إِنَّ اللَّهَ كَانَ عَلِيمًا حَكِيمًا(1)

 Iwo Anabi, beru Allahu. Ma si tele awon alaigbagbo ati awon sobe-selu musulumi. Dajudaju Allahu n je Onimo, Ologbon

وَاتَّبِعْ مَا يُوحَىٰ إِلَيْكَ مِن رَّبِّكَ ۚ إِنَّ اللَّهَ كَانَ بِمَا تَعْمَلُونَ خَبِيرًا(2)

 Tele ohun ti A n mu wa fun o ni imisi lati odo Oluwa re. Dajudaju Allahu n je Alamotan nipa ohun ti e n se nise

وَتَوَكَّلْ عَلَى اللَّهِ ۚ وَكَفَىٰ بِاللَّهِ وَكِيلًا(3)

 Ki o si gbarale Allahu. Allahu si to ni Oluso

مَّا جَعَلَ اللَّهُ لِرَجُلٍ مِّن قَلْبَيْنِ فِي جَوْفِهِ ۚ وَمَا جَعَلَ أَزْوَاجَكُمُ اللَّائِي تُظَاهِرُونَ مِنْهُنَّ أُمَّهَاتِكُمْ ۚ وَمَا جَعَلَ أَدْعِيَاءَكُمْ أَبْنَاءَكُمْ ۚ ذَٰلِكُمْ قَوْلُكُم بِأَفْوَاهِكُمْ ۖ وَاللَّهُ يَقُولُ الْحَقَّ وَهُوَ يَهْدِي السَّبِيلَ(4)

 Allahu ko fun eniyan kan ni okan meji ninu ikun re. (Allahu) ko si so awon iyawo yin, ti e n fi eyin won we eyin iya yin, di iya yin. Ati pe (Allahu) ko so awon omo-olomo ti e n pe ni omo yin di omo yin. Iyen ni oro enu yin. Allahu n so ododo. Ati pe Oun l’O n fi (eda) mona

ادْعُوهُمْ لِآبَائِهِمْ هُوَ أَقْسَطُ عِندَ اللَّهِ ۚ فَإِن لَّمْ تَعْلَمُوا آبَاءَهُمْ فَإِخْوَانُكُمْ فِي الدِّينِ وَمَوَالِيكُمْ ۚ وَلَيْسَ عَلَيْكُمْ جُنَاحٌ فِيمَا أَخْطَأْتُم بِهِ وَلَٰكِن مَّا تَعَمَّدَتْ قُلُوبُكُمْ ۚ وَكَانَ اللَّهُ غَفُورًا رَّحِيمًا(5)

 E pe won pelu oruko baba won. Ohun l’o se deede julo lodo Allahu, sugbon ti e o ba mo (oruko) baba won, omo iya yin ninu esin ati eru yin kuku ni won. Ko si ese fun yin nipa ohun ti e ba sasise re, sugbon (ese wa nibi) ohun ti okan yin moomo se. Allahu si n je Alaforijin, Asake-orun

النَّبِيُّ أَوْلَىٰ بِالْمُؤْمِنِينَ مِنْ أَنفُسِهِمْ ۖ وَأَزْوَاجُهُ أُمَّهَاتُهُمْ ۗ وَأُولُو الْأَرْحَامِ بَعْضُهُمْ أَوْلَىٰ بِبَعْضٍ فِي كِتَابِ اللَّهِ مِنَ الْمُؤْمِنِينَ وَالْمُهَاجِرِينَ إِلَّا أَن تَفْعَلُوا إِلَىٰ أَوْلِيَائِكُم مَّعْرُوفًا ۚ كَانَ ذَٰلِكَ فِي الْكِتَابِ مَسْطُورًا(6)

 Anabi ni eto si awon onigbagbo ododo ju emi ara won lo (nipa ife re ati idajo re). Awon aya re si ni iya won. Ninu Tira Allahu, awon ebi, apa kan won ni eto si ogun jije ju apa kan lo. (Awon ebi tun ni eto si ogun jije) ju awon onigbagbo ododo ati awon t’o kuro ninu ilu Mokkah fun aabo esin, afi ti e ba maa se daadaa kan si awon ore yin (wonyi ni ogun le fi kan won pelu asoole). Iyen wa ninu Tira (Laohul-Mahfuth) ni akosile

وَإِذْ أَخَذْنَا مِنَ النَّبِيِّينَ مِيثَاقَهُمْ وَمِنكَ وَمِن نُّوحٍ وَإِبْرَاهِيمَ وَمُوسَىٰ وَعِيسَى ابْنِ مَرْيَمَ ۖ وَأَخَذْنَا مِنْهُم مِّيثَاقًا غَلِيظًا(7)

 (Ranti) nigba ti A gba adehun ni owo awon Anabi ati ni owo re, ati ni owo (Anabi) Nuh, ’Ibrohim, Musa ati ‘Isa omo Moryam. A gba adehun ni owo won ni adehun t’o nipon

لِّيَسْأَلَ الصَّادِقِينَ عَن صِدْقِهِمْ ۚ وَأَعَدَّ لِلْكَافِرِينَ عَذَابًا أَلِيمًا(8)

 nitori ki (Allahu) le beere (ododo) awon olododo nipa ododo won. O si pese iya eleta-elero sile de awon alaigbagbo

يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا اذْكُرُوا نِعْمَةَ اللَّهِ عَلَيْكُمْ إِذْ جَاءَتْكُمْ جُنُودٌ فَأَرْسَلْنَا عَلَيْهِمْ رِيحًا وَجُنُودًا لَّمْ تَرَوْهَا ۚ وَكَانَ اللَّهُ بِمَا تَعْمَلُونَ بَصِيرًا(9)

 Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ranti idera Allahu lori yin, nigba ti awon omo ogun (onijo) de ba yin. A si ran ategun ati awon omo ogun ti e o foju ri si won. Allahu si ni Oluriran nipa ohun ti e n se

إِذْ جَاءُوكُم مِّن فَوْقِكُمْ وَمِنْ أَسْفَلَ مِنكُمْ وَإِذْ زَاغَتِ الْأَبْصَارُ وَبَلَغَتِ الْقُلُوبُ الْحَنَاجِرَ وَتَظُنُّونَ بِاللَّهِ الظُّنُونَا(10)

 (E ranti) nigba ti won de ba yin lati oke yin ati isale yin, ati nigba ti awon oju ye (sotun-un sosi), ti awon okan si de ona-ofun (ni ti ipaya). E si n ro awon ero kan nipa Allahu

هُنَالِكَ ابْتُلِيَ الْمُؤْمِنُونَ وَزُلْزِلُوا زِلْزَالًا شَدِيدًا(11)

 Nibe yen ni won ti fi adanwo kan awon onigbagbo ododo. Won si mile mo won lese ni imititi lile

وَإِذْ يَقُولُ الْمُنَافِقُونَ وَالَّذِينَ فِي قُلُوبِهِم مَّرَضٌ مَّا وَعَدَنَا اللَّهُ وَرَسُولُهُ إِلَّا غُرُورًا(12)

 (E ranti) nigba ti awon sobe-selu musulumi ati awon ti aisan wa ninu okan won n wi pe: “Allahu ati Ojise Re ko se adehun kan fun wa bi ko se etan.”

وَإِذْ قَالَت طَّائِفَةٌ مِّنْهُمْ يَا أَهْلَ يَثْرِبَ لَا مُقَامَ لَكُمْ فَارْجِعُوا ۚ وَيَسْتَأْذِنُ فَرِيقٌ مِّنْهُمُ النَّبِيَّ يَقُولُونَ إِنَّ بُيُوتَنَا عَوْرَةٌ وَمَا هِيَ بِعَوْرَةٍ ۖ إِن يُرِيدُونَ إِلَّا فِرَارًا(13)

 (E ranti) nigba ti igun kan ninu won wi pe: “Eyin ara Yethrib, ko si aye (isegun) fun yin, nitori naa, e seri pada (lodo Ojise).” Apa kan ninu won si n toro iyonda lowo Anabi, won n wi pe: “Dajudaju ile wa da paroparo ni.” (Ile won) ko si da paroparo. Won ko si gbero ohun kan tayo sisagun

وَلَوْ دُخِلَتْ عَلَيْهِم مِّنْ أَقْطَارِهَا ثُمَّ سُئِلُوا الْفِتْنَةَ لَآتَوْهَا وَمَا تَلَبَّثُوا بِهَا إِلَّا يَسِيرًا(14)

 Ati pe ti o ba je pe (omo ogun onijo) wole to won wa lati awon iloro ilu (Modinah), leyin naa, ki won pe (awon sobe-selu musulumi) sinu ebo sise, won iba sebo. Won ko si nii gbe ninu ilu mo tayo igba die (ti won yoo fi pare)

وَلَقَدْ كَانُوا عَاهَدُوا اللَّهَ مِن قَبْلُ لَا يُوَلُّونَ الْأَدْبَارَ ۚ وَكَانَ عَهْدُ اللَّهِ مَسْئُولًا(15)

 Dajudaju won ti ba Allahu se adehun siwaju pe awon ko nii peyinda (lati sagun). Adehun Allahu si je ohun ti won maa beere (lowo won)

قُل لَّن يَنفَعَكُمُ الْفِرَارُ إِن فَرَرْتُم مِّنَ الْمَوْتِ أَوِ الْقَتْلِ وَإِذًا لَّا تُمَتَّعُونَ إِلَّا قَلِيلًا(16)

 So pe: “Sisagun yin ko le se yin ni anfaani, ti e ba sa fun iku tabi pipa (si oju ogun esin. Ti e ba si sagun) nigba naa, A o nii fun yin ni igbadun aye bi ko se fun igba die

قُلْ مَن ذَا الَّذِي يَعْصِمُكُم مِّنَ اللَّهِ إِنْ أَرَادَ بِكُمْ سُوءًا أَوْ أَرَادَ بِكُمْ رَحْمَةً ۚ وَلَا يَجِدُونَ لَهُم مِّن دُونِ اللَّهِ وَلِيًّا وَلَا نَصِيرًا(17)

 So pe: “Ta ni eni ti o le da aabo bo yin lodo Allahu ti O ba fe fi aburu kan yin tabi ti O ba fe ke yin?” Won ko si le ri alaabo tabi alaranse kan leyin Allahu

۞ قَدْ يَعْلَمُ اللَّهُ الْمُعَوِّقِينَ مِنكُمْ وَالْقَائِلِينَ لِإِخْوَانِهِمْ هَلُمَّ إِلَيْنَا ۖ وَلَا يَأْتُونَ الْبَأْسَ إِلَّا قَلِيلًا(18)

 Dajudaju Allahu ti mo awon t’o n fa eniyan seyin ninu yin ati awon t’o n wi fun awon arakunrin won pe: “E maa bo wa si odo wa.” Won ko si nii lo si oju ogun esin afi (ogun) die

أَشِحَّةً عَلَيْكُمْ ۖ فَإِذَا جَاءَ الْخَوْفُ رَأَيْتَهُمْ يَنظُرُونَ إِلَيْكَ تَدُورُ أَعْيُنُهُمْ كَالَّذِي يُغْشَىٰ عَلَيْهِ مِنَ الْمَوْتِ ۖ فَإِذَا ذَهَبَ الْخَوْفُ سَلَقُوكُم بِأَلْسِنَةٍ حِدَادٍ أَشِحَّةً عَلَى الْخَيْرِ ۚ أُولَٰئِكَ لَمْ يُؤْمِنُوا فَأَحْبَطَ اللَّهُ أَعْمَالَهُمْ ۚ وَكَانَ ذَٰلِكَ عَلَى اللَّهِ يَسِيرًا(19)

 Won ni ahun si yin (lati se iranlowo). Nigba ti iberu (ogun) ba de, o maa ri won ti won yoo maa wo o. Oju won yo si maa yi kiri rakorako (ni ti iberu) bi eni ti o fe daku, sugbon nigba ti iberu (ogun) ba lo, (ti ikogun ba de), won yoo maa fi awon ahon kan t’o mu berebere ba yin soro ni ti sise okanjua si oore naa. Awon wonyen ko gbagbo ni ododo. Nitori naa, Allahu ba awon ise won je. Iyen si n je irorun fun Allahu

يَحْسَبُونَ الْأَحْزَابَ لَمْ يَذْهَبُوا ۖ وَإِن يَأْتِ الْأَحْزَابُ يَوَدُّوا لَوْ أَنَّهُم بَادُونَ فِي الْأَعْرَابِ يَسْأَلُونَ عَنْ أَنبَائِكُمْ ۖ وَلَوْ كَانُوا فِيكُم مَّا قَاتَلُوا إِلَّا قَلِيلًا(20)

 Won n lero pe awon omo ogun onijo ko ti i lo, (won si ti tuka). Ti awon omo ogun onijo ba (si pada) de, dajudaju (awon sobe-selu musulumi) yoo fe ki awon ti wa ni oko laaarin awon Larubawa oko, ki won maa beere nipa awon iro yin (pe se e ti ku tan tabi e si wa laye). Ti o ba si je pe won wa laaarin yin, won ko nii jagun bi ko se fun igba die

لَّقَدْ كَانَ لَكُمْ فِي رَسُولِ اللَّهِ أُسْوَةٌ حَسَنَةٌ لِّمَن كَانَ يَرْجُو اللَّهَ وَالْيَوْمَ الْآخِرَ وَذَكَرَ اللَّهَ كَثِيرًا(21)

 Dajudaju awokose rere wa fun yin lara Ojise Allahu fun enikeni ti o ba n reti (esan) Allahu ati Ojo Ikeyin, ti o si ranti Allahu ni opolopo (igba)

وَلَمَّا رَأَى الْمُؤْمِنُونَ الْأَحْزَابَ قَالُوا هَٰذَا مَا وَعَدَنَا اللَّهُ وَرَسُولُهُ وَصَدَقَ اللَّهُ وَرَسُولُهُ ۚ وَمَا زَادَهُمْ إِلَّا إِيمَانًا وَتَسْلِيمًا(22)

 Nigba ti awon onigbagbo ododo ri awon omo ogun onijo, won so pe: “Eyi ni ohun ti Allahu ati Ojise Re se ni adehun fun wa. Allahu ati Ojise Re ti so ododo oro.” (Riri won) ko se alekun kan fun won bi ko se (alekun) igbagbo ododo ati ijuwo-juse-sile (fun ase Allahu)

مِّنَ الْمُؤْمِنِينَ رِجَالٌ صَدَقُوا مَا عَاهَدُوا اللَّهَ عَلَيْهِ ۖ فَمِنْهُم مَّن قَضَىٰ نَحْبَهُ وَمِنْهُم مَّن يَنتَظِرُ ۖ وَمَا بَدَّلُوا تَبْدِيلًا(23)

 O wa ninu awon onigbagbo ododo, awon okunrin kan ti won je olododo nipa adehun ti won ba Allahu se; o wa ninu won eni ti o pe adehun re (t’o si ku soju ogun esin), o si wa ninu won eni t’o n reti (iku tire). Won ko si yi (adehun) pada rara

لِّيَجْزِيَ اللَّهُ الصَّادِقِينَ بِصِدْقِهِمْ وَيُعَذِّبَ الْمُنَافِقِينَ إِن شَاءَ أَوْ يَتُوبَ عَلَيْهِمْ ۚ إِنَّ اللَّهَ كَانَ غَفُورًا رَّحِيمًا(24)

 (Iwonyi ri bee) nitori ki Allahu le fi (ododo) awon olododo san won ni esan ododo won, ati nitori ki O le je awon sobe-selu musulumi ni iya ti O ba fe tabi nitori ki O le gba ironupiwada won. Dajudaju Allahu, O n je Alaforijin, Asake-orun

وَرَدَّ اللَّهُ الَّذِينَ كَفَرُوا بِغَيْظِهِمْ لَمْ يَنَالُوا خَيْرًا ۚ وَكَفَى اللَّهُ الْمُؤْمِنِينَ الْقِتَالَ ۚ وَكَانَ اللَّهُ قَوِيًّا عَزِيزًا(25)

 Allahu si da awon t’o sai gbagbo pada tohun ti ibinu won; owo won ko si te oore kan. Allahu si to awon onigbagbo ododo nibi ogun naa. Allahu si n je Alagbara, Olubori

وَأَنزَلَ الَّذِينَ ظَاهَرُوهُم مِّنْ أَهْلِ الْكِتَابِ مِن صَيَاصِيهِمْ وَقَذَفَ فِي قُلُوبِهِمُ الرُّعْبَ فَرِيقًا تَقْتُلُونَ وَتَأْسِرُونَ فَرِيقًا(26)

 (Allahu) si mu awon t’o seranlowo fun (awon omo ogun onijo) ninu awon ahlul-kitab sokale kuro ninu awon odi won. O si ju eru sinu okan won. E n pa igun kan (ninu won), e si n ko igun kan leru

وَأَوْرَثَكُمْ أَرْضَهُمْ وَدِيَارَهُمْ وَأَمْوَالَهُمْ وَأَرْضًا لَّمْ تَطَئُوهَا ۚ وَكَانَ اللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرًا(27)

 (Allahu) si jogun ile won, ile won, dukia won ati ile ti e o te ri fun yin. Allahu si n je Alagbara lori gbogbo nnkan

يَا أَيُّهَا النَّبِيُّ قُل لِّأَزْوَاجِكَ إِن كُنتُنَّ تُرِدْنَ الْحَيَاةَ الدُّنْيَا وَزِينَتَهَا فَتَعَالَيْنَ أُمَتِّعْكُنَّ وَأُسَرِّحْكُنَّ سَرَاحًا جَمِيلًا(28)

 Iwo Anabi, so fun awon iyawo re pe: “Ti e ba fe isemi aye yii ati oso re, e wa nibi ki ng fun yin ni ebun ikosile, ki ng si fi yin sile ni ifisile t’o rewa

وَإِن كُنتُنَّ تُرِدْنَ اللَّهَ وَرَسُولَهُ وَالدَّارَ الْآخِرَةَ فَإِنَّ اللَّهَ أَعَدَّ لِلْمُحْسِنَاتِ مِنكُنَّ أَجْرًا عَظِيمًا(29)

 Ti e ba si fe ti Allahu ati ti Ojise Re ati ile Ikeyin, dajudaju Allahu ti pese esan nla sile de awon oluse-rere lobinrin ninu yin.”

يَا نِسَاءَ النَّبِيِّ مَن يَأْتِ مِنكُنَّ بِفَاحِشَةٍ مُّبَيِّنَةٍ يُضَاعَفْ لَهَا الْعَذَابُ ضِعْفَيْنِ ۚ وَكَانَ ذَٰلِكَ عَلَى اللَّهِ يَسِيرًا(30)

 Eyin iyawo Anabi, enikeni ninu yin ti o ba se ibaje t’o foju han, A maa di adipele iya ilopo meji fun un. Iyen si n je irorun fun Allahu

۞ وَمَن يَقْنُتْ مِنكُنَّ لِلَّهِ وَرَسُولِهِ وَتَعْمَلْ صَالِحًا نُّؤْتِهَا أَجْرَهَا مَرَّتَيْنِ وَأَعْتَدْنَا لَهَا رِزْقًا كَرِيمًا(31)

 Enikeni ti o ba n tele ti Allahu ati ti Ojise Re ninu yin, ti o si n se ise rere, A maa fun un ni esan ilopo meji. A si ti pese ije-imu alapon-onle sile de e.”

يَا نِسَاءَ النَّبِيِّ لَسْتُنَّ كَأَحَدٍ مِّنَ النِّسَاءِ ۚ إِنِ اتَّقَيْتُنَّ فَلَا تَخْضَعْنَ بِالْقَوْلِ فَيَطْمَعَ الَّذِي فِي قَلْبِهِ مَرَضٌ وَقُلْنَ قَوْلًا مَّعْرُوفًا(32)

 Eyin iyawo Anabi, e o da bi eni kan kan ninu awon obinrin, ti e ba ti beru (Allahu). E ma se dinhun (si awon okunrin leti) nitori ki eni ti arun wa ninu okan re ma baa jerankan. Ki e si maa so oro t’o dara

وَقَرْنَ فِي بُيُوتِكُنَّ وَلَا تَبَرَّجْنَ تَبَرُّجَ الْجَاهِلِيَّةِ الْأُولَىٰ ۖ وَأَقِمْنَ الصَّلَاةَ وَآتِينَ الزَّكَاةَ وَأَطِعْنَ اللَّهَ وَرَسُولَهُ ۚ إِنَّمَا يُرِيدُ اللَّهُ لِيُذْهِبَ عَنكُمُ الرِّجْسَ أَهْلَ الْبَيْتِ وَيُطَهِّرَكُمْ تَطْهِيرًا(33)

 E fidi mole yin. E ma se fi ara ati oso han nita gege bi ti ifara-foso-han igba aimokan akoko (iyen, siwaju ki e t’o di musulumi). E kirun. E yo Zakah. Ki e si tele (ase) Allahu ati (ase) Ojise Re. Allahu kan n gbero lati mu egbin kuro lara yin, eyin ara ile (Anabi). Ati pe O (kan n gbero lati) fo yin mo tonitoni ni

وَاذْكُرْنَ مَا يُتْلَىٰ فِي بُيُوتِكُنَّ مِنْ آيَاتِ اللَّهِ وَالْحِكْمَةِ ۚ إِنَّ اللَّهَ كَانَ لَطِيفًا خَبِيرًا(34)

 E ranti ohun ti won n ke ninu ile yin ninu awon ayah Allahu ati ijinle oye (iyen, sunnah Anabi). Dajudaju Allahu n je Alaaanu, Onimo-ikoko. ti Larubawa ba n d’oju oro ko okunrin tabi nnkan ako tabi o n soro nipa okunrin tabi nnkan ako ede Larubawa ti ni ihun ako fun ako. Bakan naa

إِنَّ الْمُسْلِمِينَ وَالْمُسْلِمَاتِ وَالْمُؤْمِنِينَ وَالْمُؤْمِنَاتِ وَالْقَانِتِينَ وَالْقَانِتَاتِ وَالصَّادِقِينَ وَالصَّادِقَاتِ وَالصَّابِرِينَ وَالصَّابِرَاتِ وَالْخَاشِعِينَ وَالْخَاشِعَاتِ وَالْمُتَصَدِّقِينَ وَالْمُتَصَدِّقَاتِ وَالصَّائِمِينَ وَالصَّائِمَاتِ وَالْحَافِظِينَ فُرُوجَهُمْ وَالْحَافِظَاتِ وَالذَّاكِرِينَ اللَّهَ كَثِيرًا وَالذَّاكِرَاتِ أَعَدَّ اللَّهُ لَهُم مَّغْفِرَةً وَأَجْرًا عَظِيمًا(35)

 Dajudaju awon musulumi lokunrin ati musulumi lobinrin, awon onigbagbo ododo lokunrin ati awon onigbagbo ododo lobinrin, awon olutele-ase Allahu lokunrin ati awon olutele-ase Allahu lobinrin, awon olododo lokunrin ati awon olododo lobinrin, awon onisuuru lokunrin ati awon onisuuru lobinrin, awon olupaya Allahu lokunrin ati awon olupaya Allahu lobinrin, awon olutore lokunrin ati awon olutore lobinrin, awon alaawe lokunrin ati awon alaawe lobinrin, awon t’o n so abe won lokunrin ati awon t’o n so abe won lobinrin, awon oluranti Allahu ni opolopo lokunrin ati awon oluranti Allahu (ni opolopo) lobinrin; Allahu ti pese aforijin ati esan nla sile de won

وَمَا كَانَ لِمُؤْمِنٍ وَلَا مُؤْمِنَةٍ إِذَا قَضَى اللَّهُ وَرَسُولُهُ أَمْرًا أَن يَكُونَ لَهُمُ الْخِيَرَةُ مِنْ أَمْرِهِمْ ۗ وَمَن يَعْصِ اللَّهَ وَرَسُولَهُ فَقَدْ ضَلَّ ضَلَالًا مُّبِينًا(36)

 Ko to fun onigbagbo ododo lokunrin ati onigbagbo ododo lobinrin, nigba ti Allahu ati Ojise Re ba ti pari oro kan, lati ni esa (oro miiran) fun oro ara won. Ati pe enikeni ti o ba yapa (ase) Allahu ati (ase) Ojise Re, dajudaju o ti sina ni isina ponnbele

وَإِذْ تَقُولُ لِلَّذِي أَنْعَمَ اللَّهُ عَلَيْهِ وَأَنْعَمْتَ عَلَيْهِ أَمْسِكْ عَلَيْكَ زَوْجَكَ وَاتَّقِ اللَّهَ وَتُخْفِي فِي نَفْسِكَ مَا اللَّهُ مُبْدِيهِ وَتَخْشَى النَّاسَ وَاللَّهُ أَحَقُّ أَن تَخْشَاهُ ۖ فَلَمَّا قَضَىٰ زَيْدٌ مِّنْهَا وَطَرًا زَوَّجْنَاكَهَا لِكَيْ لَا يَكُونَ عَلَى الْمُؤْمِنِينَ حَرَجٌ فِي أَزْوَاجِ أَدْعِيَائِهِمْ إِذَا قَضَوْا مِنْهُنَّ وَطَرًا ۚ وَكَانَ أَمْرُ اللَّهِ مَفْعُولًا(37)

 (Ranti) nigba ti o n so fun eni ti Allahu sedera fun, ti iwo naa sedera fun1 pe: “Mu iyawo re dani, ki o si beru Allahu.” O si n fi pamo sinu emi re ohun ti Allahu yo safi han re. Ati pe o n paya awon eniyan. Allahu l’O si letoo julo pe ki o paya Re. Nigba ti Zaed ti pari bukata re lodo re (ti o si ti ko o sile), A ti se e ni iyawo fun o nitori ki o ma baa je laifi fun awon onigbagbo ododo lati fe iyawo omo-olomo ti won n pe ni omo won nigba ti won ba ti pari bukata won lodo won (ti won si ti ko won sile). Ase Allahu si gbodo se

مَّا كَانَ عَلَى النَّبِيِّ مِنْ حَرَجٍ فِيمَا فَرَضَ اللَّهُ لَهُ ۖ سُنَّةَ اللَّهِ فِي الَّذِينَ خَلَوْا مِن قَبْلُ ۚ وَكَانَ أَمْرُ اللَّهِ قَدَرًا مَّقْدُورًا(38)

 Ko si laifi fun Anabi (sollalahu alayhi wa sallam) nipa ohun ti Allahu se ni eto fun un. (O je) ilana Allahu lori awon t’o ti lo siwaju. Ati pe ase Allahu je akoole kan t’o gbodo se

الَّذِينَ يُبَلِّغُونَ رِسَالَاتِ اللَّهِ وَيَخْشَوْنَهُ وَلَا يَخْشَوْنَ أَحَدًا إِلَّا اللَّهَ ۗ وَكَفَىٰ بِاللَّهِ حَسِيبًا(39)

 (Kose awon t’o ti lo siwaju ninu awon Ojise) awon t’o n je ise Allahu, ti won n paya Re, ti won ko si paya eni kan ayafi Allahu. Allahu si to ni Olusiro

مَّا كَانَ مُحَمَّدٌ أَبَا أَحَدٍ مِّن رِّجَالِكُمْ وَلَٰكِن رَّسُولَ اللَّهِ وَخَاتَمَ النَّبِيِّينَ ۗ وَكَانَ اللَّهُ بِكُلِّ شَيْءٍ عَلِيمًا(40)

 (Anabi) Muhammad ki i se baba eni kan kan ninu awon okunrin yin, sugbon (o je) Ojise Allahu ati opin awon Anabi. Allahu si n je Onimo nipa gbogbo nnkan. opuro asookun sesin wule ni oun. Iro enu re ti po ju. Alagbari ponnbele si ni pelu. Iru ise aburu ti seeu Ahmada Tijani se fun ’Islam gele naa ni mirza ghulam Ahmad se. Awon mejeeji ni Poolu laaarin awa musulumi. E wo die ninu iro nla re. Mirza ghulam Ahmad so pe: ""Allahu so fun mi ni ede Larubawa pe bi omo Mi lo se wa si Mi."" (Tadhkirah “Ti o ba je pe Anabi Muhammad (sollalahu alayhi wa sallam) ni opin awon Anabi Olohun ko ye fun Anabi ‘Isa omo Moryam (’alaehi-ssolatu wa-ssalam) lati pada wa saye mo lopin aye.” Won tun so pe Anabi Muhammad (sollalahu alayhi wa sallam) ni opin awon Anabi Olohun amo isoro tiwon ni pe

يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا اذْكُرُوا اللَّهَ ذِكْرًا كَثِيرًا(41)

 Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ranti Allahu ni iranti pupo

وَسَبِّحُوهُ بُكْرَةً وَأَصِيلًا(42)

 E safomo fun Allahu ni aaro ati ni irole

هُوَ الَّذِي يُصَلِّي عَلَيْكُمْ وَمَلَائِكَتُهُ لِيُخْرِجَكُم مِّنَ الظُّلُمَاتِ إِلَى النُّورِ ۚ وَكَانَ بِالْمُؤْمِنِينَ رَحِيمًا(43)

 (Allahu) Oun ni Eni t’O n ke yin, awon molaika Re (si n toro aforijin fun yin), nitori ki Allahu le mu yin kuro lati inu awon okunkun wa sinu imole. Ati pe O n je Asake-orun fun awon onigbagbo ododo

تَحِيَّتُهُمْ يَوْمَ يَلْقَوْنَهُ سَلَامٌ ۚ وَأَعَدَّ لَهُمْ أَجْرًا كَرِيمًا(44)

 Ikini won ni ojo ti won yoo pade Re ni "alaafia." O si ti pese esan alapon-onle sile de won

يَا أَيُّهَا النَّبِيُّ إِنَّا أَرْسَلْنَاكَ شَاهِدًا وَمُبَشِّرًا وَنَذِيرًا(45)

 Iwo Anabi, dajudaju Awa ran o nise (pe ki o je) olujerii, oniroo-idunnu, olukilo

وَدَاعِيًا إِلَى اللَّهِ بِإِذْنِهِ وَسِرَاجًا مُّنِيرًا(46)

 olupepe si odo Allahu pelu iyonda Re ati atupa imole

وَبَشِّرِ الْمُؤْمِنِينَ بِأَنَّ لَهُم مِّنَ اللَّهِ فَضْلًا كَبِيرًا(47)

 Fun awon onigbagbo ododo ni iro idunnu pe dajudaju oore ajulo nla wa fun won lodo Allahu

وَلَا تُطِعِ الْكَافِرِينَ وَالْمُنَافِقِينَ وَدَعْ أَذَاهُمْ وَتَوَكَّلْ عَلَى اللَّهِ ۚ وَكَفَىٰ بِاللَّهِ وَكِيلًا(48)

 Ma se tele awon alaigbagbo ati awon sobe-selu musulumi. Fi bi won se n ko inira ba o sile. Ki o si gbarale Allahu. Allahu si n to ni Alamojuuto

يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا إِذَا نَكَحْتُمُ الْمُؤْمِنَاتِ ثُمَّ طَلَّقْتُمُوهُنَّ مِن قَبْلِ أَن تَمَسُّوهُنَّ فَمَا لَكُمْ عَلَيْهِنَّ مِنْ عِدَّةٍ تَعْتَدُّونَهَا ۖ فَمَتِّعُوهُنَّ وَسَرِّحُوهُنَّ سَرَاحًا جَمِيلًا(49)

 Eyin ti e gbagbo ni ododo lokunrin, nigba ti e ba fe awon onigbagbo ododo lobinrin, leyin naa ti e ko won sile siwaju ki e to ba won ni asepo loko-laya, ko si opo sise kan ti won yoo se fun yin. Nitori naa, e fun won ni ebun ikosile. Ki e si fi won sile ni ifisile t’o rewa

يَا أَيُّهَا النَّبِيُّ إِنَّا أَحْلَلْنَا لَكَ أَزْوَاجَكَ اللَّاتِي آتَيْتَ أُجُورَهُنَّ وَمَا مَلَكَتْ يَمِينُكَ مِمَّا أَفَاءَ اللَّهُ عَلَيْكَ وَبَنَاتِ عَمِّكَ وَبَنَاتِ عَمَّاتِكَ وَبَنَاتِ خَالِكَ وَبَنَاتِ خَالَاتِكَ اللَّاتِي هَاجَرْنَ مَعَكَ وَامْرَأَةً مُّؤْمِنَةً إِن وَهَبَتْ نَفْسَهَا لِلنَّبِيِّ إِنْ أَرَادَ النَّبِيُّ أَن يَسْتَنكِحَهَا خَالِصَةً لَّكَ مِن دُونِ الْمُؤْمِنِينَ ۗ قَدْ عَلِمْنَا مَا فَرَضْنَا عَلَيْهِمْ فِي أَزْوَاجِهِمْ وَمَا مَلَكَتْ أَيْمَانُهُمْ لِكَيْلَا يَكُونَ عَلَيْكَ حَرَجٌ ۗ وَكَانَ اللَّهُ غَفُورًا رَّحِيمًا(50)

 Iwo Anabi, dajudaju Awa se e ni eto fun o awon iyawo re, ti o fun ni owo-ori won, ati awon eru ninu awon ti Allahu fi se ikogun fun o ati awon omobinrin arakunrin baba re ati awon omobinrin arabinrin baba re, ati awon omobinrin arakunrin iya re, ati awon omobinrin arabinrin iya re, awon t’o fi ilu Mokkah sile wa si ilu Modinah pelu re, ati onigbagbo ododo lobinrin, ti o ba fi ara re tore fun Anabi, ti Anabi naa si fe fi se iyawo. Iwo nikan ni (eyi) wa fun, ko si fun awon onigbagbo ododo lokunrin. A ti mo ohun ti A se ni oran-anyan fun won nipa awon iyawo won ati awon eru won. (Eyi ri bee) nitori ki o ma baa si laifi fun o. Allahu si n je Alaforijin, Asake-orun

۞ تُرْجِي مَن تَشَاءُ مِنْهُنَّ وَتُؤْوِي إِلَيْكَ مَن تَشَاءُ ۖ وَمَنِ ابْتَغَيْتَ مِمَّنْ عَزَلْتَ فَلَا جُنَاحَ عَلَيْكَ ۚ ذَٰلِكَ أَدْنَىٰ أَن تَقَرَّ أَعْيُنُهُنَّ وَلَا يَحْزَنَّ وَيَرْضَيْنَ بِمَا آتَيْتَهُنَّ كُلُّهُنَّ ۚ وَاللَّهُ يَعْلَمُ مَا فِي قُلُوبِكُمْ ۚ وَكَانَ اللَّهُ عَلِيمًا حَلِيمًا(51)

 Lora lati sunmo eni ti o ba fe ninu won. Fa eni ti o ba fe mora. Ati pe eni keni ti o ba tun wa (lati sunmo) ninu awon ti o o pin oorun fun, ko si ese fun o (lati se bee). Iyen sunmo julo lati mu oju won tutu idunnu. Won ko si nii banuje. Gbogbo won yo si yonu si ohunkohun ti o ba fun won. Allahu mo ohun ti n be ninu okan yin. Allahu si n je Onimo, Alafarada

لَّا يَحِلُّ لَكَ النِّسَاءُ مِن بَعْدُ وَلَا أَن تَبَدَّلَ بِهِنَّ مِنْ أَزْوَاجٍ وَلَوْ أَعْجَبَكَ حُسْنُهُنَّ إِلَّا مَا مَلَكَتْ يَمِينُكَ ۗ وَكَانَ اللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ رَّقِيبًا(52)

 Ko letoo fun o (lati fe) awon obinrin (miiran) leyin (isori awon ti A se ni eto fun o, ko si letoo fun o) lati fi awon obinrin (miiran) paaro won, koda ki daadaa won jo o loju, afi awon eru re (nikan l’o le ko sile ninu awon iyawo re). Allahu si n je Oluso lori gbogbo nnkan

يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا تَدْخُلُوا بُيُوتَ النَّبِيِّ إِلَّا أَن يُؤْذَنَ لَكُمْ إِلَىٰ طَعَامٍ غَيْرَ نَاظِرِينَ إِنَاهُ وَلَٰكِنْ إِذَا دُعِيتُمْ فَادْخُلُوا فَإِذَا طَعِمْتُمْ فَانتَشِرُوا وَلَا مُسْتَأْنِسِينَ لِحَدِيثٍ ۚ إِنَّ ذَٰلِكُمْ كَانَ يُؤْذِي النَّبِيَّ فَيَسْتَحْيِي مِنكُمْ ۖ وَاللَّهُ لَا يَسْتَحْيِي مِنَ الْحَقِّ ۚ وَإِذَا سَأَلْتُمُوهُنَّ مَتَاعًا فَاسْأَلُوهُنَّ مِن وَرَاءِ حِجَابٍ ۚ ذَٰلِكُمْ أَطْهَرُ لِقُلُوبِكُمْ وَقُلُوبِهِنَّ ۚ وَمَا كَانَ لَكُمْ أَن تُؤْذُوا رَسُولَ اللَّهِ وَلَا أَن تَنكِحُوا أَزْوَاجَهُ مِن بَعْدِهِ أَبَدًا ۚ إِنَّ ذَٰلِكُمْ كَانَ عِندَ اللَّهِ عَظِيمًا(53)

 Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se wo awon inu ile Anabi afi ti won ba yonda fun yin lati wole jeun lai nii je eni ti yoo maa reti ki ounje jinna, sugbon ti won ba pe yin (fun ounje) e wo inu ile nigba naa. Nigba ti e ba si jeun tan, e tuka, e ma se jokoo kale tira yin fun oro kan mo (ninu ile re). Dajudaju iyen n ko inira ba Anabi (sollalahu alayhi wa sallam). O si n tiju yin. Allahu ko si nii tiju nibi ododo. Nigba ti e ba si fe beere nnkan ni odo awon iyawo re, e beere re ni odo won ni eyin gaga. Iyen je afomo julo fun okan yin ati okan won. Ko to fun yin lati ko inira ba Ojise Allahu. (Ko si to fun yin) lati fe awon iyawo re leyin (iku) re laelae. Dajudaju iyen je nnkan nla ni odo Allahu

إِن تُبْدُوا شَيْئًا أَوْ تُخْفُوهُ فَإِنَّ اللَّهَ كَانَ بِكُلِّ شَيْءٍ عَلِيمًا(54)

 Ti e ba safi han kini kan tabi e fi pamo, dajudaju Allahu n je Onimo nipa gbogbo nnkan

لَّا جُنَاحَ عَلَيْهِنَّ فِي آبَائِهِنَّ وَلَا أَبْنَائِهِنَّ وَلَا إِخْوَانِهِنَّ وَلَا أَبْنَاءِ إِخْوَانِهِنَّ وَلَا أَبْنَاءِ أَخَوَاتِهِنَّ وَلَا نِسَائِهِنَّ وَلَا مَا مَلَكَتْ أَيْمَانُهُنَّ ۗ وَاتَّقِينَ اللَّهَ ۚ إِنَّ اللَّهَ كَانَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ شَهِيدًا(55)

 Ko si ese fun awon iyawo Anabi nipa awon baba won ati awon omokunrin won ati awon arakunrin won ati awon omokunrin arakunrin won ati awon omokunrin arabinrin won ati awon obinrin (egbe) won ati awon erukunrin won (lati wole ti won.) E beru Allahu. Dajudaju Allahu n je Arinu-rode gbogbo nnkan

إِنَّ اللَّهَ وَمَلَائِكَتَهُ يُصَلُّونَ عَلَى النَّبِيِّ ۚ يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا صَلُّوا عَلَيْهِ وَسَلِّمُوا تَسْلِيمًا(56)

 Dajudaju Allahu ati awon molaika Re n ke Anabi (sollalahu alayhi wa sallam). Eyin ti e gbagbo ni ododo, e toro ike fun un, ki e si ki i ni kiki alaafia. awon Sohabah naa (r.ahm) maa n se bee. Eyin naa e wo bi awon aafa sunnah se n se asolatu fun Anabi ninu awon oro isaaju ninu awon tira won. Ko si aburu ninu eyi rara. Sugbon musulumi yoo se agbekale ihun asolatu daran ti o ba fi le ko sinu okan ninu awon nnkan mefa kan. Ikini: Lilo awon oro ti o lodi si ofin ati adisokan ’Islam ninu awon gbolohun asolatu naa. Ikeji: Siso gbolohun asolatu yen gan-angan di ilana ti won yoo maa pepe si ti irufe gbolohun naa yoo fi wa da bi eni pe hadith kan l’o gba a wa

إِنَّ الَّذِينَ يُؤْذُونَ اللَّهَ وَرَسُولَهُ لَعَنَهُمُ اللَّهُ فِي الدُّنْيَا وَالْآخِرَةِ وَأَعَدَّ لَهُمْ عَذَابًا مُّهِينًا(57)

 Dajudaju awon t’o n fi inira kan Allahu ati Ojise Re, Allahu ti sebi le won nile aye ati ni orun. O si ti pese iya t’o n yepere eda sile de won

وَالَّذِينَ يُؤْذُونَ الْمُؤْمِنِينَ وَالْمُؤْمِنَاتِ بِغَيْرِ مَا اكْتَسَبُوا فَقَدِ احْتَمَلُوا بُهْتَانًا وَإِثْمًا مُّبِينًا(58)

 Awon t’o n fi inira kan awon onigbagbo ododo lokunrin ati onigbagbo ododo lobinrin nipa nnkan ti won ko se, dajudaju won ti ru eru (oran) iparomoni ati ese ponnbele

يَا أَيُّهَا النَّبِيُّ قُل لِّأَزْوَاجِكَ وَبَنَاتِكَ وَنِسَاءِ الْمُؤْمِنِينَ يُدْنِينَ عَلَيْهِنَّ مِن جَلَابِيبِهِنَّ ۚ ذَٰلِكَ أَدْنَىٰ أَن يُعْرَفْنَ فَلَا يُؤْذَيْنَ ۗ وَكَانَ اللَّهُ غَفُورًا رَّحِيمًا(59)

 Iwo Anabi so fun awon iyawo re, awon omobinrin re ati awon obinrin onigbagbo ododo pe ki won maa gbe awon aso jilbab won wo si ara won bamubamu. Iyen sunmo julo lati fi mo won (ni oluberu Allahu). Nipa bee, won ko nii fi inira kan won. Allahu si n je Alaforijin, Asake-orun

۞ لَّئِن لَّمْ يَنتَهِ الْمُنَافِقُونَ وَالَّذِينَ فِي قُلُوبِهِم مَّرَضٌ وَالْمُرْجِفُونَ فِي الْمَدِينَةِ لَنُغْرِيَنَّكَ بِهِمْ ثُمَّ لَا يُجَاوِرُونَكَ فِيهَا إِلَّا قَلِيلًا(60)

 Ti awon sobe-selu musulumi, ati awon ti aisan n be ninu okan won ati awon tuletule ninu ilu Modinah ko ba jawo (nibi aburu), dajudaju A maa de o si won, (o si maa bori won). Leyin naa, won ko si nii ba o gbe adugbo po mo afi fun igba die

مَّلْعُونِينَ ۖ أَيْنَمَا ثُقِفُوا أُخِذُوا وَقُتِّلُوا تَقْتِيلًا(61)

 Won di eni-isebile nibikibi ti owo ba ti ba won; won maa mu won, won si maa pa won taara

سُنَّةَ اللَّهِ فِي الَّذِينَ خَلَوْا مِن قَبْلُ ۖ وَلَن تَجِدَ لِسُنَّةِ اللَّهِ تَبْدِيلًا(62)

 (O je) ise Allahu lori awon t’o ti lo siwaju. O o si nii ri iyipada kan fun ise Allahu

يَسْأَلُكَ النَّاسُ عَنِ السَّاعَةِ ۖ قُلْ إِنَّمَا عِلْمُهَا عِندَ اللَّهِ ۚ وَمَا يُدْرِيكَ لَعَلَّ السَّاعَةَ تَكُونُ قَرِيبًا(63)

 Awon eniyan n bi o leere nipa Akoko naa. So pe: “Odo Allahu nikan soso ni imo nipa re wa. Ati pe ki l’o maa fi mo o pe o see se ki Akoko naa ti sunmo!”

إِنَّ اللَّهَ لَعَنَ الْكَافِرِينَ وَأَعَدَّ لَهُمْ سَعِيرًا(64)

 Dajudaju Allahu sebi le awon alaigbagbo. O si pese Ina t’o n jo fofo sile de won

خَالِدِينَ فِيهَا أَبَدًا ۖ لَّا يَجِدُونَ وَلِيًّا وَلَا نَصِيرًا(65)

 Olusegbere ni won ninu re titi laelae; won ko nii ri oluso tabi alaranse kan

يَوْمَ تُقَلَّبُ وُجُوهُهُمْ فِي النَّارِ يَقُولُونَ يَا لَيْتَنَا أَطَعْنَا اللَّهَ وَأَطَعْنَا الرَّسُولَا(66)

 Ni ojo ti A oo yi oju won pada ninu Ina, won yo si wi pe: “Yee! Awa iba tele ti Allahu, awa iba si tele ti Ojise.”

وَقَالُوا رَبَّنَا إِنَّا أَطَعْنَا سَادَتَنَا وَكُبَرَاءَنَا فَأَضَلُّونَا السَّبِيلَا(67)

 Won wi pe: “Oluwa wa! Dajudaju awa tele awon asiwaju wa ati awon agbaagba wa. Won si si wa lona

رَبَّنَا آتِهِمْ ضِعْفَيْنِ مِنَ الْعَذَابِ وَالْعَنْهُمْ لَعْنًا كَبِيرًا(68)

 Oluwa wa! Fun won ni ilopo meji ninu iya. Ki O si sebi le won ni isebi t’o tobi.”

يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا تَكُونُوا كَالَّذِينَ آذَوْا مُوسَىٰ فَبَرَّأَهُ اللَّهُ مِمَّا قَالُوا ۚ وَكَانَ عِندَ اللَّهِ وَجِيهًا(69)

 Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se da bi awon t’o fi inira kan (Anabi) Musa. Allahu si safomo re ninu ohun ti won wi. O si je eni abiyi lodo Allahu

يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا اتَّقُوا اللَّهَ وَقُولُوا قَوْلًا سَدِيدًا(70)

 Eyin ti e gbagbo ni ododo, e beru Allahu. Ki e si so oro ododo

يُصْلِحْ لَكُمْ أَعْمَالَكُمْ وَيَغْفِرْ لَكُمْ ذُنُوبَكُمْ ۗ وَمَن يُطِعِ اللَّهَ وَرَسُولَهُ فَقَدْ فَازَ فَوْزًا عَظِيمًا(71)

 (Allahu) maa satunse awon ise yin fun yin, O si maa saforijin awon ese yin fun yin. Ati pe eni ti o ba tele ti Allahu ati Ojise Re, o kuku ti jere ni erenje nla

إِنَّا عَرَضْنَا الْأَمَانَةَ عَلَى السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَالْجِبَالِ فَأَبَيْنَ أَن يَحْمِلْنَهَا وَأَشْفَقْنَ مِنْهَا وَحَمَلَهَا الْإِنسَانُ ۖ إِنَّهُ كَانَ ظَلُومًا جَهُولًا(72)

 Dajudaju Awa fi ise laada lo awon sanmo ati ile ati apata. Won ko lati gbe e; won paya re. Eniyan si gbe e. Dajudaju (eniyan) je alabosi, alaimokan

لِّيُعَذِّبَ اللَّهُ الْمُنَافِقِينَ وَالْمُنَافِقَاتِ وَالْمُشْرِكِينَ وَالْمُشْرِكَاتِ وَيَتُوبَ اللَّهُ عَلَى الْمُؤْمِنِينَ وَالْمُؤْمِنَاتِ ۗ وَكَانَ اللَّهُ غَفُورًا رَّحِيمًا(73)

 (Eniyan teri gba esin asegbalaada) nitori ki Allahu le fi iya je awon sobe-selu musulumi lokunrin, awon sobe-selu musulumi lobinrin, awon osebo lokunrin ati awon osebo lobinrin ati nitori ki Allahu le gba ironupiwada fun awon onigbagbo ododo lokunrin ati awon onigbagbo ododo lobinrin. Allahu si n je Alaforijin, Asake-orun


سورهای بیشتر به زبان یوروبا:

سوره البقره آل عمران سوره نساء
سوره مائده سوره يوسف سوره ابراهيم
سوره حجر سوره کهف سوره مریم
سوره حج سوره قصص سوره عنکبوت
سوره سجده سوره یس سوره دخان
سوره فتح سوره حجرات سوره ق
سوره نجم سوره رحمن سوره واقعه
سوره حشر سوره ملک سوره حاقه
سوره انشقاق سوره أعلى سوره غاشية

دانلود سوره احزاب با صدای معروف‌ترین قراء:

انتخاب خواننده برای گوش دادن و دانلود کامل سوره احزاب با کیفیت بالا.
سوره احزاب را با صدای احمد العجمی
أحمد العجمي
سوره احزاب را با صدای ابراهيم الاخضر
ابراهيم الاخضر
سوره احزاب را با صدای بندر بليلة
بندر بليلة
سوره احزاب را با صدای خالد الجليل
خالد الجليل
سوره احزاب را با صدای حاتم فريد الواعر
حاتم فريد الواعر
سوره احزاب را با صدای خليفة الطنيجي
خليفة الطنيجي
سوره احزاب را با صدای سعد الغامدي
سعد الغامدي
سوره احزاب را با صدای سعود الشريم
سعود الشريم
سوره احزاب را با صدای الشاطري
الشاطري
سوره احزاب را با صدای صلاح ابوخاطر
صلاح بوخاطر
سوره احزاب را با صدای عبد الباسط عبد الصمد
عبد الباسط
سوره احزاب را با صدای عبد الرحمن العوسي
عبدالرحمن العوسي
سوره احزاب را با صدای عبد الرشيد صوفي
عبد الرشيد صوفي
سوره احزاب را با صدای عبد العزيز الزهراني
عبدالعزيز الزهراني
سوره احزاب را با صدای عبد الله بصفر
عبد الله بصفر
سوره احزاب را با صدای عبد الله عواد الجهني
عبد الله الجهني
سوره احزاب را با صدای علي الحذيفي
علي الحذيفي
سوره احزاب را با صدای علي جابر
علي جابر
سوره احزاب را با صدای غسان الشوربجي
غسان الشوربجي
سوره احزاب را با صدای فارس عباد
فارس عباد
سوره احزاب را با صدای ماهر المعيقلي
ماهر المعيقلي
سوره احزاب را با صدای محمد أيوب
محمد أيوب
سوره احزاب را با صدای محمد المحيسني
محمد المحيسني
سوره احزاب را با صدای محمد جبريل
محمد جبريل
سوره احزاب را با صدای محمد صديق المنشاوي
المنشاوي
سوره احزاب را با صدای الحصري
الحصري
سوره احزاب را با صدای العفاسي
مشاري العفاسي
سوره احزاب را با صدای ناصر القطامي
ناصر القطامي
سوره احزاب را با صدای وديع اليمني
وديع اليمني
سوره احزاب را با صدای ياسر الدوسري
ياسر الدوسري


Sunday, December 22, 2024

به قرآن کریم چنگ بزنید