Surah Al-Qalam ni Arabic ati Yorùbá

Ka Surah Al-Qalam pẹlu itumọ pipe ni Yorùbá ati iṣẹ́-ohun. Itumọ ẹsẹ kọọkan. (52 Ẹsẹ — مكية). Al-Qalam Gbọ, Al-Qalam Itumọ, Al-Qalam mp3, Al-Qalam pdf.

Ka ati Gbọ Surah Al-Qalam

🎧 Ẹsẹ
M Mishary Rashid Alafasy
M Mahmoud Khalil Al-Husary
A Abdurrahman As-Sudais
M Mohamed Siddiq Al-Minshawi
A Abdul Basit Abdul Samad
A Ali Al-Hudhaify
A Ahmed ibn Ali al-Ajamy
A Abu Bakr Ash-Shaatree
M Muhammad Ayyoub
A Abdullah Basfar
A Abdullah Al-Juhani
M Maher Al Muaiqly
x1
ن ۚ وَالْقَلَمِ وَمَا يَسْطُرُونَ ۝١
📖 Itumọ Ẹsẹ 1
Nun. (Allahu bura pelu) gege ikowe ati ohun ti awon molaika n ko sile
مَا أَنتَ بِنِعْمَةِ رَبِّكَ بِمَجْنُونٍ ۝٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 2
Iwo ki i se were nipa idera Oluwa re
وَإِنَّ لَكَ لَأَجْرًا غَيْرَ مَمْنُونٍ ۝٣
📖 Itumọ Ẹsẹ 3
Ati pe dajudaju esan ti ko nii dawo duro ti wa fun o
وَإِنَّكَ لَعَلَىٰ خُلُقٍ عَظِيمٍ ۝٤
📖 Itumọ Ẹsẹ 4
Dajudaju iwo si wa lori iwa aponle
فَسَتُبْصِرُ وَيُبْصِرُونَ ۝٥
📖 Itumọ Ẹsẹ 5
Laipe iwo yoo ri i, awon naa yo si ri i
بِأَييِّكُمُ الْمَفْتُونُ ۝٦
📖 Itumọ Ẹsẹ 6
ewo ninu yin ni were
إِنَّ رَبَّكَ هُوَ أَعْلَمُ بِمَن ضَلَّ عَن سَبِيلِهِ وَهُوَ أَعْلَمُ بِالْمُهْتَدِينَ ۝٧
📖 Itumọ Ẹsẹ 7
Dajudaju Oluwa re, O nimo julo nipa eni t’o sina kuro loju ona Re. O si nimo julo nipa awon olumona
فَلَا تُطِعِ الْمُكَذِّبِينَ ۝٨
📖 Itumọ Ẹsẹ 8
Nitori naa, ma se tele awon olupe-ododo-niro
وَدُّوا لَوْ تُدْهِنُ فَيُدْهِنُونَ ۝٩
📖 Itumọ Ẹsẹ 9
Ati pe won fe ki o dewo, ki awon naa si dewo
وَلَا تُطِعْ كُلَّ حَلَّافٍ مَّهِينٍ ۝١٠
📖 Itumọ Ẹsẹ 10
Ma se tele gbogbo eni ti ibura re po, eni yepere
هَمَّازٍ مَّشَّاءٍ بِنَمِيمٍ ۝١١
📖 Itumọ Ẹsẹ 11
abuni, alarinka t’o n sofofo kiri
مَّنَّاعٍ لِّلْخَيْرِ مُعْتَدٍ أَثِيمٍ ۝١٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 12
oludena ise rere, alakoyo, elese
عُتُلٍّ بَعْدَ ذَٰلِكَ زَنِيمٍ ۝١٣
📖 Itumọ Ẹsẹ 13
odaju. Leyin iyen, asawo ni
أَن كَانَ ذَا مَالٍ وَبَنِينَ ۝١٤
📖 Itumọ Ẹsẹ 14
Nitori pe o ni dukia ati awon omokunrin
إِذَا تُتْلَىٰ عَلَيْهِ آيَاتُنَا قَالَ أَسَاطِيرُ الْأَوَّلِينَ ۝١٥
📖 Itumọ Ẹsẹ 15
nigba ti won ba n ke awon ayah Wa fun un, o maa wi pe: “Akosile alo awon eni akoko (niwonyi)”
سَنَسِمُهُ عَلَى الْخُرْطُومِ ۝١٦
📖 Itumọ Ẹsẹ 16
A maa fi ami si i ni gongori imu
إِنَّا بَلَوْنَاهُمْ كَمَا بَلَوْنَا أَصْحَابَ الْجَنَّةِ إِذْ أَقْسَمُوا لَيَصْرِمُنَّهَا مُصْبِحِينَ ۝١٧
📖 Itumọ Ẹsẹ 17
Dajudaju Awa dan won wo gege bi A se dan awon ologba wo nigba ti won bura pe dajudaju awon yoo ka gbogbo eso ogba naa ni owuro kutukutu
وَلَا يَسْتَثْنُونَ ۝١٨
📖 Itumọ Ẹsẹ 18
Won ko si se ayafi pe "ti Allahu ba fe
فَطَافَ عَلَيْهَا طَائِفٌ مِّن رَّبِّكَ وَهُمْ نَائِمُونَ ۝١٩
📖 Itumọ Ẹsẹ 19
Adanwo t’o n yi nnkan po lati odo Oluwa re si yi ogba naa po, nigba ti won sun lo
فَأَصْبَحَتْ كَالصَّرِيمِ ۝٢٠
📖 Itumọ Ẹsẹ 20
O si da bi oko agedanu (ti won ti resun)
فَتَنَادَوْا مُصْبِحِينَ ۝٢١
📖 Itumọ Ẹsẹ 21
Won n pera won ni owuro kutukutu
أَنِ اغْدُوا عَلَىٰ حَرْثِكُمْ إِن كُنتُمْ صَارِمِينَ ۝٢٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 22
pe e ji lo si oko yin ti e ba fe ka eso
فَانطَلَقُوا وَهُمْ يَتَخَافَتُونَ ۝٢٣
📖 Itumọ Ẹsẹ 23
Won lo, won si n fi ohun jeeje bara won soro
أَن لَّا يَدْخُلَنَّهَا الْيَوْمَ عَلَيْكُم مِّسْكِينٌ ۝٢٤
📖 Itumọ Ẹsẹ 24
pe ni oni mekunnu kan ko gbodo wonu re wa ba yin
وَغَدَوْا عَلَىٰ حَرْدٍ قَادِرِينَ ۝٢٥
📖 Itumọ Ẹsẹ 25
Won ji lo lori ero-okan kan (pe) awon lagbara
فَلَمَّا رَأَوْهَا قَالُوا إِنَّا لَضَالُّونَ ۝٢٦
📖 Itumọ Ẹsẹ 26
Nigba ti won ri i, won wi pe: "Dajudaju awa ti sina
بَلْ نَحْنُ مَحْرُومُونَ ۝٢٧
📖 Itumọ Ẹsẹ 27
Rara o, won se ikore oko leewo fun wa ni
قَالَ أَوْسَطُهُمْ أَلَمْ أَقُل لَّكُمْ لَوْلَا تُسَبِّحُونَ ۝٢٨
📖 Itumọ Ẹsẹ 28
Eni t’o duro deede julo ninu won so pe: "Se emi ko so fun yin pe eyin ko se safomo fun Allahu (pe "a maa kore oko wa, ’in sa ’Allahu)
قَالُوا سُبْحَانَ رَبِّنَا إِنَّا كُنَّا ظَالِمِينَ ۝٢٩
📖 Itumọ Ẹsẹ 29
Won wi pe: "Mimo ni fun Oluwa wa, dajudaju awa je alabosi
فَأَقْبَلَ بَعْضُهُمْ عَلَىٰ بَعْضٍ يَتَلَاوَمُونَ ۝٣٠
📖 Itumọ Ẹsẹ 30
Apa kan won koju si apa kan; won si n dara won lebi
قَالُوا يَا وَيْلَنَا إِنَّا كُنَّا طَاغِينَ ۝٣١
📖 Itumọ Ẹsẹ 31
Won wi pe: "Egbe wa o! Dajudaju awa je olutayo-enu ala
عَسَىٰ رَبُّنَا أَن يُبْدِلَنَا خَيْرًا مِّنْهَا إِنَّا إِلَىٰ رَبِّنَا رَاغِبُونَ ۝٣٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 32
O see se ki Oluwa wa fi eyi t’o dara ju eyi lo paaro re fun wa. Dajudaju odo Oluwa wa ni awa n rokan oore si
كَذَٰلِكَ الْعَذَابُ ۖ وَلَعَذَابُ الْآخِرَةِ أَكْبَرُ ۚ لَوْ كَانُوا يَعْلَمُونَ ۝٣٣
📖 Itumọ Ẹsẹ 33
Bayen ni iya naa se ri (fun won). Iya orun si tobi julo, ti o ba je pe won mo
إِنَّ لِلْمُتَّقِينَ عِندَ رَبِّهِمْ جَنَّاتِ النَّعِيمِ ۝٣٤
📖 Itumọ Ẹsẹ 34
Dajudaju awon Ogba Idera wa fun awon oluberu lodo Oluwa won
أَفَنَجْعَلُ الْمُسْلِمِينَ كَالْمُجْرِمِينَ ۝٣٥
📖 Itumọ Ẹsẹ 35
Se A maa se awon musulumi bi (A se maa se) awon elese bi
مَا لَكُمْ كَيْفَ تَحْكُمُونَ ۝٣٦
📖 Itumọ Ẹsẹ 36
Ki l’o n se yin ti e fi n dajo bayii na
أَمْ لَكُمْ كِتَابٌ فِيهِ تَدْرُسُونَ ۝٣٧
📖 Itumọ Ẹsẹ 37
Tabi tira kan wa fun yin ti e n kekoo ninu re
إِنَّ لَكُمْ فِيهِ لَمَا تَخَيَّرُونَ ۝٣٨
📖 Itumọ Ẹsẹ 38
pe dajudaju eyin le ni ohun ti e ba n sa lesa ninu idajo
أَمْ لَكُمْ أَيْمَانٌ عَلَيْنَا بَالِغَةٌ إِلَىٰ يَوْمِ الْقِيَامَةِ ۙ إِنَّ لَكُمْ لَمَا تَحْكُمُونَ ۝٣٩
📖 Itumọ Ẹsẹ 39
Nje e ni awon adehun kan lodo wa ti o maa wa titi di Ojo Ajinde pe: "Dajudaju tiyin ni idajo ti e ba ti mu wa
سَلْهُمْ أَيُّهُم بِذَٰلِكَ زَعِيمٌ ۝٤٠
📖 Itumọ Ẹsẹ 40
Bi won leere wo pe ewo ninu won l’o le fowo iyen soya
أَمْ لَهُمْ شُرَكَاءُ فَلْيَأْتُوا بِشُرَكَائِهِمْ إِن كَانُوا صَادِقِينَ ۝٤١
📖 Itumọ Ẹsẹ 41
Tabi won ni awon orisa kan? Ki won mu awon orisa won wa nigba naa ti won ba je olododo
يَوْمَ يُكْشَفُ عَن سَاقٍ وَيُدْعَوْنَ إِلَى السُّجُودِ فَلَا يَسْتَطِيعُونَ ۝٤٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 42
Ni ojo ti A maa si ojugun sile, A si maa pe won sibi iforikanle, won ko si nii le se e
خَاشِعَةً أَبْصَارُهُمْ تَرْهَقُهُمْ ذِلَّةٌ ۖ وَقَدْ كَانُوا يُدْعَوْنَ إِلَى السُّجُودِ وَهُمْ سَالِمُونَ ۝٤٣
📖 Itumọ Ẹsẹ 43
Oju won yoo wale. Iyepere maa bo won mole. Won kuku ti pe won sibi iforikanle nigba ti won ni alaafia (won ko si kirun)
فَذَرْنِي وَمَن يُكَذِّبُ بِهَٰذَا الْحَدِيثِ ۖ سَنَسْتَدْرِجُهُم مِّنْ حَيْثُ لَا يَعْلَمُونَ ۝٤٤
📖 Itumọ Ẹsẹ 44
Nitori naa, fi Emi ati eni t’o n pe oro yii niro sile. A oo maa de won leke lati je won niya ni aye ti won ko mo
وَأُمْلِي لَهُمْ ۚ إِنَّ كَيْدِي مَتِينٌ ۝٤٥
📖 Itumọ Ẹsẹ 45
Mo n lora fun won ni. Dajudaju ete Mi lagbara
أَمْ تَسْأَلُهُمْ أَجْرًا فَهُم مِّن مَّغْرَمٍ مُّثْقَلُونَ ۝٤٦
📖 Itumọ Ẹsẹ 46
Tabi o n beere owo-oya kan lodo won, ni gbese fi wo won lorun
أَمْ عِندَهُمُ الْغَيْبُ فَهُمْ يَكْتُبُونَ ۝٤٧
📖 Itumọ Ẹsẹ 47
Tabi lodo won ni (walaa) ikoko wa ni won ba n ko o (sita)
فَاصْبِرْ لِحُكْمِ رَبِّكَ وَلَا تَكُن كَصَاحِبِ الْحُوتِ إِذْ نَادَىٰ وَهُوَ مَكْظُومٌ ۝٤٨
📖 Itumọ Ẹsẹ 48
Nitori naa, se suuru fun idajo Oluwa re. Ki iwo ma si se da bi eleja (iyen, Anabi Yunus) nigba ti o pe (Allahu) pelu ibanuje
لَّوْلَا أَن تَدَارَكَهُ نِعْمَةٌ مِّن رَّبِّهِ لَنُبِذَ بِالْعَرَاءِ وَهُوَ مَذْمُومٌ ۝٤٩
📖 Itumọ Ẹsẹ 49
Ti ko ba je pe ike kan lati odo Oluwa re le e ba, won iba ju u sori ile gbansasa (lati inu eja) ni eni-eebu
فَاجْتَبَاهُ رَبُّهُ فَجَعَلَهُ مِنَ الصَّالِحِينَ ۝٥٠
📖 Itumọ Ẹsẹ 50
Nitori naa, Oluwa re sa a lesa. O si se e ni ara awon eni rere
وَإِن يَكَادُ الَّذِينَ كَفَرُوا لَيُزْلِقُونَكَ بِأَبْصَارِهِمْ لَمَّا سَمِعُوا الذِّكْرَ وَيَقُولُونَ إِنَّهُ لَمَجْنُونٌ ۝٥١
📖 Itumọ Ẹsẹ 51
Awon t’o sai gbagbo fee fi oju won gbe o subu nigba ti won gbo iranti naa. Won si n wi pe: "Dajudaju were ma ni
وَمَا هُوَ إِلَّا ذِكْرٌ لِّلْعَالَمِينَ ۝٥٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 52
Ki si ni al-Ƙur’an bi ko se iranti fun gbogbo eda
← 67 Al-Qalam (68/114) 69 →
Kika Surah Al-Qalam ni Yorùbá – Itumọ ati Ohun

68القلم Al-Qalam 📚 52 Ẹsẹ مكية

Ẹsẹ kọọkan – Surah Al-Qalam — 52 Ẹsẹ




Al-Kur'an


Tuesday, August 18, 2026

Don't forget us in your sincere prayers