PDF —
30 Ẹsẹ Meccan PDF
Built right in your browser — download starts automatically

Surah Al-Mulk pdf — Gbà (Yorùbá)

Surah Al-Mulk pdf Yorùbá — Gbà Surah Al-Mulk Itumọ. Surah Al-Mulk (Meccan) 30 Ẹsẹ.



30 Ẹsẹ · Meccan · Yorùbá
bismillah
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚ
67:1 Ibukun ni fun Eni ti ijoba wa ni Owo Re. Oun si ni Alagbara lori gbogbo nnkan
ﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧ
67:2 Eni ti O da iku ati isemi nitori ki o le dan yin wo; ewo ninu yin l’o maa se ise rere julo. Oun si ni Alagbara, Alaforijin
ﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼ
67:3 Eni ti O da awon sanmo meje ni ipele ipele. O o le ri aigunrege kan lara eda Ajoke-aye. Nitori naa, wo o pada, nje o ri oju sisan kan (lara sanmo)
ﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇ
67:4 Leyin naa, wo o pada ni ee meji, ki oju re pada si odo re pelu iyepere. O si maa kaaare
ﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕ
67:5 Dajudaju A ti fi (awon irawo t’o n tanmole bi) atupa se sanmo ile aye ni oso. A tun se won ni eta-irawo ti won n ju mo awon esu. A si pese iya Ina t’o n jo fofo sile de won
ﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞ
67:6 Iya ina Jahanamo si wa fun awon t’o sai gbagbo. Ikangun naa si buru
ﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧ
67:7 Nigba ti won ba ju won sinu re, won yoo maa gbo kikun re, ti o si maa ru soke
ﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗ
67:8 Ina maa fee pinra re lati ara ibinu. Igbakigba ti won ba ju ijo kan sinu re, awon eso Ina yoo maa bi won leere pe: "Nje olukilo kan ko wa ba yin bi
ﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪ
67:9 Won yoo wi pe: "Rara, dajudaju olukilo kan ti wa ba wa, sugbon a pe e ni opuro. A si wi pe Allahu ko so nnkan kan kale. Ki ni eyin bi ko se pe e wa ninu isina t’o tobi
ﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶ
67:10 Won tun wi pe: "Ti o ba je pe a gboran ni tabi pe a se laakaye ni, awa ko nii wa ninu ero inu Ina jijo
ﯷﯸﯹﯺﯻﯼ
67:11 Won si jewo ese won. Nitori naa, ijinna si ike Allahu yo wa fun awon ero inu Ina t’o n jo fofo
ﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆ
67:12 Dajudaju awon t’o n paya Oluwa won ni ikoko, aforijin ati esan t’o tobi n be fun won
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛ
67:13 E wi oro yin ni jeeje tabi e wi i soke, dajudaju Oun ni Onimo nipa ohun t’o wa ninu awon igba-aya eda
ﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣ
67:14 Se (Allahu) ko mo eni t’O da ni? Oun si ni Alaaanu, Alamotan
ﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳ
67:15 Oun ni Eni ti O ro ile fun yin. Nitori naa, e rin ni awon agbegbe re kaakiri, ki e si je ninu arisiki Re. Odo Re si ni ajinde eda wa
ﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿ
67:16 Se e fokanbale si Eni ti O wa ni (oke) sanmo pe ko le je ki ile gbe yin mi? Nigba naa, ile yo si maa mi titi
ﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍ
67:17 Tabi e fokanbale si Eni ti O wa ni (oke) sanmo pe ko le fi okuta ina ranse si yin ni? Nigba naa, e si maa mo bi ikilo Mi ti ri
ﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖ
67:18 Awon t’o siwaju won kuku pe ododo niro. Bawo si ni bi Mo se (fi iya) ko (aburu fun won) ti ri
ﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨ
67:19 Se won ko ri awon eye ti o wa ni oke won, ti (won) n na iye apa (won), ti won si n pa a mora? Kini kan ko mu won duro (sinu ofurufu) afi Ajoke-aye. Dajudaju Oun si ni Oluriran nipa gbogbo nnkan
ﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚ
67:20 Ta ni eni ti o maa je omo ogun fun yin, ti o maa ran yin lowo leyin Ajoke-aye? (Ninu) ki ni awon alaigbagbo wa bi ko se ninu etan
ﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨ
67:21 Ta ni eni ti o maa pese fun yin ti O ba da arisiki Re duro? Nse ni won n sori kunkun si i ninu igberaga ati sisa fun ododo
ﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵ
67:22 Nje eni t’o n rin ni idojubole l’o mona julo ni tabi eni t’o n rin san an loju ona taara
ﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃ
67:23 So pe: "Oun ni Eni ti O seda yin. O si se igboro, iriran ati awon okan fun yin. Ope ti e n da si kere pupo
ﰄﰅﰆﰇﰈﰉﰊﰋﰌ
67:24 So pe: "Oun ni Eni ti O da yin si ori ile. Odo Re si ni won yoo ko yin jo si
ﰍﰎﰏﰐﰑﰒﰓﰔ
67:25 Won n wi pe: "Igba wo ni adehun yii yoo se ti e ba je olododo
ﰕﰖﰗﰘﰙﰚﰛﰜﰝﰞ
67:26 So pe: "Odo Allahu nikan ni imo (nipa) re wa. Emi kan je olukilo ponnbele ni
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞ
67:27 Nigba ti won ba ri i t’o sunmo, oju awon t’o sai gbagbo yoo koro wa fun ibanuje. A o si so fun won pe: "Eyi ni ohun ti e n pe
ﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮ
67:28 So pe: " E so fun mi, ti Allahu ba pa emi ati awon t’o wa pelu mi re, tabi ti O ba ke wa (se e le di I lowo ni?) Nitori naa, ta ni o maa gba awon alaigbagbo la ninu iya eleta-elero
ﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽ
67:29 So pe: "Oun ni Ajoke-aye. Awa gba A gbo. Oun si la gbarale. Laipe e maa mo ta ni o wa ninu isina ponnbele
ﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈ
67:30 So pe: " E so fun mi, ti omi yin ba gbe wa, ta ni eni ti o maa mu omi iseleru wa ba yin

Al-Kur'an


Wednesday, September 9, 2026

Don't forget us in your sincere prayers