Перевод суры Аш-Шуара на Йоруба язык
طسم(1) To sin mim |
Iwonyi ni awon ayah Tira t’o n yanju oro eda |
Nitori ki ni o se maa para re pe won ko je onigbagbo ododo |
إِن نَّشَأْ نُنَزِّلْ عَلَيْهِم مِّنَ السَّمَاءِ آيَةً فَظَلَّتْ أَعْنَاقُهُمْ لَهَا خَاضِعِينَ(4) Ti A ba fe, A maa so ami kan kale fun won lati sanmo. Awon orun won ko si nii ye teriba fun un |
وَمَا يَأْتِيهِم مِّن ذِكْرٍ مِّنَ الرَّحْمَٰنِ مُحْدَثٍ إِلَّا كَانُوا عَنْهُ مُعْرِضِينَ(5) Ko si iranti kan ti o maa de ba won ni titun lati odo Ajoke-aye afi ki won je olugbunri kuro nibe |
فَقَدْ كَذَّبُوا فَسَيَأْتِيهِمْ أَنبَاءُ مَا كَانُوا بِهِ يَسْتَهْزِئُونَ(6) Dajudaju won ti pe (ayah Wa) niro. Nitori naa, awon iro ohun ti won n fi se yeye n bo wa ba won |
أَوَلَمْ يَرَوْا إِلَى الْأَرْضِ كَمْ أَنبَتْنَا فِيهَا مِن كُلِّ زَوْجٍ كَرِيمٍ(7) Se won ko ri ile pe meloo meloo ninu gbogbo orisirisi nnkan alapon-onle ti A mu hu jade lati inu re |
إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً ۖ وَمَا كَانَ أَكْثَرُهُم مُّؤْمِنِينَ(8) Dajudaju ami wa ninu iyen. Sibesibe opolopo won ko je onigbagbo ododo |
Dajudaju Oluwa re, Oun ma ni Alagbara, Asake-orun |
وَإِذْ نَادَىٰ رَبُّكَ مُوسَىٰ أَنِ ائْتِ الْقَوْمَ الظَّالِمِينَ(10) (Ranti) nigba ti Oluwa re pe (Anabi) Musa pe: "Lo ba ijo alabosi |
ijo Fir‘aon (ki o si so fun won) pe Se won ko nii beru (Allahu) ni |
O so pe: "Oluwa mi, dajudaju emi n beru pe won maa pe mi ni opuro |
وَيَضِيقُ صَدْرِي وَلَا يَنطَلِقُ لِسَانِي فَأَرْسِلْ إِلَىٰ هَارُونَ(13) O si maa je inira fun mi (ti won ba pe mi ni opuro). Ahon mi ko si ja gaaraga. Nitori naa, ranse si Harun |
Ati pe mo ni ese kan lorun lodo won. Nitori naa, mo n beru pe won maa pa mi |
قَالَ كَلَّا ۖ فَاذْهَبَا بِآيَاتِنَا ۖ إِنَّا مَعَكُم مُّسْتَمِعُونَ(15) (Allahu) so pe: "Rara (won ko le pa o). Nitori naa, ki eyin mejeeji mu awon ami (ise iyanu) Wa lo (ba won). Dajudaju Awa n be pelu yin; A n gbo (oro yin) |
فَأْتِيَا فِرْعَوْنَ فَقُولَا إِنَّا رَسُولُ رَبِّ الْعَالَمِينَ(16) Eyin mejeeji, e lo ba Fir‘aon. Ki e so fun un pe: Dajudaju awa ni Ojise Oluwa gbogbo eda |
(A n so fun o) pe ki o je ki awon omo ’Isro’il maa ba wa lo |
قَالَ أَلَمْ نُرَبِّكَ فِينَا وَلِيدًا وَلَبِثْتَ فِينَا مِنْ عُمُرِكَ سِنِينَ(18) (Fir‘aon) wi pe: “Se ki i se ni aarin wa ni a ti to o ni kekere ni, ti o si gbe ni odo wa fun odun pupo ninu isemi aye re |
وَفَعَلْتَ فَعْلَتَكَ الَّتِي فَعَلْتَ وَأَنتَ مِنَ الْكَافِرِينَ(19) O si se ise owo re ti o se (si wa). Iwo si wa ninu awon alaimoore.” |
(Anabi Musa) so pe: "Mo se e nigba naa nigba ti mo wa ninu awon alaimokan ni |
فَفَرَرْتُ مِنكُمْ لَمَّا خِفْتُكُمْ فَوَهَبَ لِي رَبِّي حُكْمًا وَجَعَلَنِي مِنَ الْمُرْسَلِينَ(21) Mo si sa fun yin nigba ti mo beru yin. Nitori naa, Allahu ti ta mi lore ipo Anabi. O si se mi ni (okan) ninu awon Ojise |
وَتِلْكَ نِعْمَةٌ تَمُنُّهَا عَلَيَّ أَنْ عَبَّدتَّ بَنِي إِسْرَائِيلَ(22) Ati pe iyen ni idera ti o n se iregun re le mi lori. Pe o so awon omo ’Isro’il di eru (nko) |
Fir‘aon wi pe: “Ki ni Oluwa gbogbo eda?” |
قَالَ رَبُّ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَمَا بَيْنَهُمَا ۖ إِن كُنتُم مُّوقِنِينَ(24) (Anabi Musa) so pe: “(Allahu ni) |
(Fir‘aon) wi fun awon t’o wa ni ayika re pe: “Se e e gbo oro (t’o n so ni)?” |
(Anabi Musa) so pe: “(Allahu ni) Oluwa yin ati Oluwa awon baba yin, awon eni akoko.” |
قَالَ إِنَّ رَسُولَكُمُ الَّذِي أُرْسِلَ إِلَيْكُمْ لَمَجْنُونٌ(27) (Fir‘aon) wi pe: “Dajudaju Ojise yin eyi ti won ran si yin, were ma ni.” |
قَالَ رَبُّ الْمَشْرِقِ وَالْمَغْرِبِ وَمَا بَيْنَهُمَا ۖ إِن كُنتُمْ تَعْقِلُونَ(28) (Anabi Musa) so pe: “(Allahu ni) Oluwa ibuyo oorun, ibuwo oorun ati ohunkohun t’o n be laaarin awon mejeeji, ti e ba maa n se laakaye.” |
قَالَ لَئِنِ اتَّخَذْتَ إِلَٰهًا غَيْرِي لَأَجْعَلَنَّكَ مِنَ الْمَسْجُونِينَ(29) (Fir‘aon) wi pe: “Dajudaju ti o ba fi le josin fun olohun kan yato si mi, dajudaju mo maa so o di ara awon elewon.” |
(Anabi Musa) so pe: “Ti o ba je pe mo mu kini kan t’o yanju wa fun o nko?” |
(Fir‘aon) wi pe: “Mu un wa nigba naa ti iwo ba wa ninu awon olododo.” |
Nitori naa, o ju opa re sile, o si di ejo ponnbele |
O tun fa owo re yo sita, o si di funfun fun awon oluworan |
قَالَ لِلْمَلَإِ حَوْلَهُ إِنَّ هَٰذَا لَسَاحِرٌ عَلِيمٌ(34) (Fir‘aon) wi fun awon ijoye ti won wa ni ayika re pe: “Dajudaju eyi ni onimo nipa idan pipa |
يُرِيدُ أَن يُخْرِجَكُم مِّنْ أَرْضِكُم بِسِحْرِهِ فَمَاذَا تَأْمُرُونَ(35) O fe ko yin kuro lori ile yin ni. Ki ni ohun ti e maa mu wa ni imoran?” |
قَالُوا أَرْجِهْ وَأَخَاهُ وَابْعَثْ فِي الْمَدَائِنِ حَاشِرِينَ(36) Won wi pe: "Da oun ati arakunrin re duro na, ki o si ran awon akonijo si awon ilu |
(pe) ki gbogbo onimo nipa idan pipa wa ba o |
Won si ko awon opidan jo ni asiko ti won fi adehun si ni ojo ti (gbogbo ilu) ti mo |
Won si wi fun awon eniyan pe: "Se eyin maa ko jo (sibe) bi |
لَعَلَّنَا نَتَّبِعُ السَّحَرَةَ إِن كَانُوا هُمُ الْغَالِبِينَ(40) Nitori ki a le tele awon opidan ti o ba je pe awon ni olubori |
Nigba ti awon opidan de, won wi fun Fir‘aon pe: “Nje owo-oya kan wa fun wa, ti o ba je pe awa gan-an la je olubori?” |
(Fir‘aon) wi pe: “Bee ni, dajudaju nigba naa e maa wa ninu awon alasun-unmo (mi).” |
(Anabi) Musa so fun won pe: “E ju ohun ti e fe ju sile.” |
فَأَلْقَوْا حِبَالَهُمْ وَعِصِيَّهُمْ وَقَالُوا بِعِزَّةِ فِرْعَوْنَ إِنَّا لَنَحْنُ الْغَالِبُونَ(44) Won si ju awon okun won ati opa won sile. Won wi pe: “Pelu ogo Fir‘aon, dajudaju awa, awa ni olubori.” |
فَأَلْقَىٰ مُوسَىٰ عَصَاهُ فَإِذَا هِيَ تَلْقَفُ مَا يَأْفِكُونَ(45) Nigba naa, (Anabi) Musa ju opa re sile. O si n gbe ohun ti won pa niro kale mi kalokalo |
Nitori naa, ise iyanu (Anabi Musa) mu awon opidan wo lule, ti won fori kanle (fun Allahu) |
Won so pe: "A gbagbo ninu Oluwa gbogbo eda |
Oluwa (Anabi) Musa ati Harun |
Fir‘aon wi pe: “E gba A gbo siwaju ki ng to yonda fun yin! Dajudaju oun ni agba yin ti o ko yin ni idan pipa. Laipe e n bo wa mo. Dajudaju mo maa ge owo yin ati ese yin ni ipasipayo. Leyin naa, dajudaju mo maa kan gbogbo yin mogi.” |
قَالُوا لَا ضَيْرَ ۖ إِنَّا إِلَىٰ رَبِّنَا مُنقَلِبُونَ(50) (Awon opidan) so pe: “Ko si inira fun wa! Dajudaju awa yo si fabo si odo Oluwa wa |
إِنَّا نَطْمَعُ أَن يَغْفِرَ لَنَا رَبُّنَا خَطَايَانَا أَن كُنَّا أَوَّلَ الْمُؤْمِنِينَ(51) Dajudaju awa n reti pe Oluwa wa yoo se aforijin awon asise wa fun wa nitori pe awa je eni akoko (ti o je) onigbagbo ododo.” |
۞ وَأَوْحَيْنَا إِلَىٰ مُوسَىٰ أَنْ أَسْرِ بِعِبَادِي إِنَّكُم مُّتَّبَعُونَ(52) A fi imisi ranse si (Anabi) Musa pe: “Mu awon erusin Mi rin ni oru (nitori pe) dajudaju won yoo lepa yin.” |
Fir‘aon si ran awon akonijo sinu awon ilu (lati so pe) |
Dajudaju awon (omo ’Isro’il) wonyi, ijo perete die ni won |
Ati pe dajudaju won ti se ohun t’o n bi wa ninu |
Dajudaju gbogbo wa ni ki a si wa tifura-tifura |
Nitori naa, A mu (ijo Fir‘aon) jade kuro ninu awon ogba oko ati iseleru omi |
ati awon apoti-oro ati ibujokoo aponle |
Bayen (loro ri). A si jogun re fun awon omo ’Isro’il |
Won si lepa won ni asiko ti oorun yo |
فَلَمَّا تَرَاءَى الْجَمْعَانِ قَالَ أَصْحَابُ مُوسَىٰ إِنَّا لَمُدْرَكُونَ(61) Nigba ti ijo mejeeji rira won, awon ijo (Anabi) Musa so pe: “Dajudaju won yoo le wa ba.” |
(Anabi) Musa so pe: “Rara, dajudaju Oluwa mi n be pelu mi. O si maa fi ona mo mi.” |
A si fi imisi ranse si (Anabi) Musa pe: “Fi opa re na agbami okun.” (O fi na a). O si pin (si ona mejila). Ipin kookan si da bi apata nla |
A si mu ijo keji (iyen, ijo Fir‘aon) sunmo ibe yen |
A gba (Anabi) Musa ati gbogbo awon t’o n be pelu re la patapata |
Leyin naa, A te ijo keji ri (sinu agbami) |
إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً ۖ وَمَا كَانَ أَكْثَرُهُم مُّؤْمِنِينَ(67) Dajudaju ami wa ninu iyen. Sibesibe opolopo won ko je onigbagbo ododo |
Dajudaju Oluwa re, Oun ma ni Alagbara, Asake-orun |
Ka iroyin (Anabi) ’Ibrohim fun won |
Nigba ti o so fun baba re ati awon eniyan re pe: “Ki ni nnkan ti e n josin fun na?” |
Won wi pe: “A n josin fun awon ere kan ni. A o si nii ye taku ti won lorun.” |
(Anabi ’Ibrohim) so pe: “Nje won n gbo oro yin nigba ti e ba n pe won |
Tabi (se) won le se yin ni oore tabi won le fi inira kan yin?” |
Won wi pe: “Rara o! A ba awon baba wa, ti won n se bee ni” |
(Anabi ’Ibrohim) so pe: " E so fun mi, ki ni nnkan ti e n josin fun |
eyin ati awon baba yin isaaju |
Dajudaju awon ni ota fun mi ayafi Oluwa gbogbo eda |
(Oun ni) Eni ti O seda mi. Nitori naa, O maa fi ona mo mi |
Eni t’O n fun mi ni jije, t’O n fun mi ni mimu |
Ati pe nigba ti ara mi ko ba ya, Oun l’O n wo mi san |
Eni ti O maa pa mi, leyin naa, O maa so mi di alaaye |
وَالَّذِي أَطْمَعُ أَن يَغْفِرَ لِي خَطِيئَتِي يَوْمَ الدِّينِ(82) Eni ti mo ni ireti si pe O maa fori awon asise mi jin mi ni Ojo Esan |
Oluwa mi, ta mi ni ore ipo Anabi. Da mi po mo awon eni rere |
Je ki awon t’o n bo leyin (mi) maa soro mi pelu daadaa |
Se mi ni okan ninu awon olujogun Ogba Idera |
Ki O si forijin baba mi. Dajudaju o je okan ninu awon olusina |
Ma se doju ti mi ni ojo ti won yoo gbe eda dide |
Ojo ti dukia kan tabi awon omo ko nii sanfaani |
Ayafi eni ti o ba de odo Allahu pelu okan mimo |
A maa mu Ogba Idera sunmo awon oluberu (Allahu) |
Won si maa fi ina Jehim han awon olusina |
won yo si so fun won pe: “Nibo ni nnkan ti e n josin fun wa?” |
(Nnkan ti e n josin fun) leyin Allahu, se won le ran yin lowo tabi se won le ran ara won lowo |
Won si maa taari gbogbo won sinu Ina; awon ati esu won |
ati awon omo ogun ’Iblis patapata |
(Awon alaigbagbo), nigba ti won ba n ba ara won jiyan ninu Ina, won a wi pe |
A fi Allahu bura, dajudaju awa kuku ti wa ninu isina ponnbele |
nigba ti a fi yin se akegbe fun Oluwa gbogbo eda |
Ko si ohun ti o si wa lona bi ko se awon (esu) elese |
Ko si si awon olusipe kan fun wa |
Ko tun si ore imule kan (fun wa) |
فَلَوْ أَنَّ لَنَا كَرَّةً فَنَكُونَ مِنَ الْمُؤْمِنِينَ(102) Ti o ba je pe ipada si ile aye wa fun wa ni, nigba naa awa iba wa ninu awon onigbagbo ododo |
إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً ۖ وَمَا كَانَ أَكْثَرُهُم مُّؤْمِنِينَ(103) Dajudaju ami wa ninu iyen. Sibesibe opolopo won ni ko si je onigbagbo ododo |
Dajudaju Oluwa re, Oun ma ni Alagbara, Asake-orun |
Ijo (Anabi) Nuh pe awon Ojise ni opuro |
Nigba ti arakunrin won, (Anabi) Nuh, so pe: “Se e o nii beru (Allahu) ni |
Dajudaju emi ni Ojise olufokantan fun yin |
Nitori naa, e beru Allahu, ki e si tele mi |
وَمَا أَسْأَلُكُمْ عَلَيْهِ مِنْ أَجْرٍ ۖ إِنْ أَجْرِيَ إِلَّا عَلَىٰ رَبِّ الْعَالَمِينَ(109) Emi ko si beere owo-oya kan ni owo yin lori re. Ko si esan mi lodo eni kan afi lodo Oluwa gbogbo eda |
Nitori naa, e beru Allahu, ki e si tele mi.” |
Won wi pe: “Se ki a gba o gbo nigba ti o je pe awon eniyan yepere l’o n tele o!?” |
O so pe: “Emi ko nimo si ohun ti won n se (leyin mi) |
إِنْ حِسَابُهُمْ إِلَّا عَلَىٰ رَبِّي ۖ لَوْ تَشْعُرُونَ(113) Ko si isiro-ise won lodo eni kan bi ko se lodo Oluwa mi, ti o ba je pe e ba fura |
Emi ko si nii le awon onigbagbo ododo danu |
Emi ko si je kini kan bi ko se olukilo ponnbele.” |
قَالُوا لَئِن لَّمْ تَنتَهِ يَا نُوحُ لَتَكُونَنَّ مِنَ الْمَرْجُومِينَ(116) Won wi pe: “Dajudaju ti iwo Nuh ko ba jawo (nibi ipepe re) dajudaju o maa wa ninu awon ti a maa ju loko.” |
O so pe: “Oluwa mi, dajudaju awon eniyan mi ti pe mi ni opuro |
فَافْتَحْ بَيْنِي وَبَيْنَهُمْ فَتْحًا وَنَجِّنِي وَمَن مَّعِيَ مِنَ الْمُؤْمِنِينَ(118) Nitori naa, sedajo taara laaarin emi ati awon. Ki o si la emi ati awon t’o wa pelu mi ninu awon onigbagbo ododo.” |
فَأَنجَيْنَاهُ وَمَن مَّعَهُ فِي الْفُلْكِ الْمَشْحُونِ(119) A la oun ati awon t’o wa pelu re ninu oko oju-omi t’o kun keke |
Leyin naa, A te awon t’o seku ri sinu omi |
إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً ۖ وَمَا كَانَ أَكْثَرُهُم مُّؤْمِنِينَ(121) Dajudaju ami wa ninu iyen. Opolopo won ni ko si je onigbagbo ododo |
Dajudaju Oluwa re, Oun ma ni Alagbara, Asake-orun |
Awon iran ‘Ad pe awon Ojise ni opuro |
Nigba ti arakunrin won, (Anabi) Hud, so pe: “Se e o nii beru (Allahu) ni |
Dajudaju emi ni Ojise olufokantan fun yin |
Nitori naa, e beru Allahu, ki e si tele mi |
وَمَا أَسْأَلُكُمْ عَلَيْهِ مِنْ أَجْرٍ ۖ إِنْ أَجْرِيَ إِلَّا عَلَىٰ رَبِّ الْعَالَمِينَ(127) Emi ko si beere owo-oya kan ni owo yin lori re. Ko si esan mi lodo eni kan afi lodo Oluwa gbogbo eda |
Se e oo maa ko ile nla nla si awon aye giga (ki e le) maa fi awon olurekoja sefe |
E si n ko awon ile nla nla bi eni pe e maa se gbere (nile aye yii) |
Nigba ti e ba si gba (eniyan mu lati fiya je won), e n gba won mu ni igbamu alailoju-aanu |
Nitori naa, e beru Allahu, ki e si tele mi |
E beru Eni ti O ran yin lowo pelu ohun ti e mo |
O ran yin lowo pelu awon eran-osin ati awon omo |
وَجَنَّاتٍ وَعُيُونٍ(134) ati awon ogba oko pelu awon iseleru omi |
Dajudaju emi n paya iya ojo nla fun yin.” |
قَالُوا سَوَاءٌ عَلَيْنَا أَوَعَظْتَ أَمْ لَمْ تَكُن مِّنَ الْوَاعِظِينَ(136) Won wi pe: “Bakan naa ni fun wa; yala o kilo fun wa tabi o o si ninu awon olukilo |
Eyi ko je kini kan bi ko se iwa awon eni akoko |
Won ko si nii je wa niya.” |
فَكَذَّبُوهُ فَأَهْلَكْنَاهُمْ ۗ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً ۖ وَمَا كَانَ أَكْثَرُهُم مُّؤْمِنِينَ(139) Nitori naa, won pe e ni opuro. A si pa won run. Dajudaju ami wa ninu iyen. Opolopo won ni ko si je onigbagbo ododo |
Dajudaju Oluwa re, Oun ma ni Alagbara, Asake-orun |
Awon iran Thamud pe awon Ojise ni opuro |
Nigba ti arakunrin won, (Anabi) Solih, so pe: “Se e o nii beru (Allahu) ni |
Dajudaju emi ni Ojise olufokantan fun yin |
Nitori naa, e beru Allahu, ki e si tele mi |
وَمَا أَسْأَلُكُمْ عَلَيْهِ مِنْ أَجْرٍ ۖ إِنْ أَجْرِيَ إِلَّا عَلَىٰ رَبِّ الْعَالَمِينَ(145) Emi ko si beere owo-oya kan ni owo yin lori re. Ko si esan mi lodo eni kan afi lodo Oluwa gbogbo eda |
Se ki won fi yin sile sibi nnkan ti o wa (nile aye) nibi yii (ninu igbadun aye, ki e je) olufokanbale |
ninu awon ogba oko ati iseleru omi |
ati oko irugbin pelu igi dabinu ti ogomo re tutu |
E si n gbe awon ile sinu awon apata (gege bi) akose-mose |
Nitori naa, e beru Allahu, ki e si tele mi |
Ki e si ma se tele ase awon alaseju |
awon t’o n sebaje lori ile, ti won ko si se rere.” |
Won wi pe: “Iwo kuku wa ninu awon eleedi |
مَا أَنتَ إِلَّا بَشَرٌ مِّثْلُنَا فَأْتِ بِآيَةٍ إِن كُنتَ مِنَ الصَّادِقِينَ(154) Iwo ko si je kini kan bi ko se abara bi iru wa. Nitori naa, mu ami kan wa ti o ba wa ninu awon olododo.” |
قَالَ هَٰذِهِ نَاقَةٌ لَّهَا شِرْبٌ وَلَكُمْ شِرْبُ يَوْمٍ مَّعْلُومٍ(155) O so pe: “Eyi ni abo rakunmi kan. Omi wa fun ohun, omi si wa fun eyin naa ni ojo ti a ti mo |
وَلَا تَمَسُّوهَا بِسُوءٍ فَيَأْخُذَكُمْ عَذَابُ يَوْمٍ عَظِيمٍ(156) E ma se fi aburu kan kan an nitori ki iya ojo nla ma baa je yin.” |
Won si gun un pa. Nitori naa, won si di alabaamo |
فَأَخَذَهُمُ الْعَذَابُ ۗ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً ۖ وَمَا كَانَ أَكْثَرُهُم مُّؤْمِنِينَ(158) Iya naa je won. Dajudaju ami wa ninu iyen. Opolopo won ni ko si je onigbagbo ododo |
Dajudaju Oluwa re, Oun ma ni Alagbara, Asake-orun |
Ijo Lut pe awon Ojise ni opuro |
Nigba ti arakunrin won, (Anabi) Lut, so pe: “Se e o nii beru (Allahu) ni |
Dajudaju emi ni Ojise olufokantan fun yin |
Nitori naa, e beru Allahu, ki e si tele mi |
وَمَا أَسْأَلُكُمْ عَلَيْهِ مِنْ أَجْرٍ ۖ إِنْ أَجْرِيَ إِلَّا عَلَىٰ رَبِّ الْعَالَمِينَ(164) Emi ko si beere owo-oya kan ni owo yin lori re. Ko si esan mi lodo eni kan afi lodo Oluwa gbogbo eda |
Se awon okunrin ninu eda ni eyin okunrin yoo lo maa ba (fun adun ibalopo) |
وَتَذَرُونَ مَا خَلَقَ لَكُمْ رَبُّكُم مِّنْ أَزْوَاجِكُم ۚ بَلْ أَنتُمْ قَوْمٌ عَادُونَ(166) E si n pa ohun ti Oluwa yin da fun yin ti ninu awon iyawo yin! Ani se, ijo alakoyo ni eyin.” |
قَالُوا لَئِن لَّمْ تَنتَهِ يَا لُوطُ لَتَكُونَنَّ مِنَ الْمُخْرَجِينَ(167) Won wi pe: “Ti iwo Lut ko ba jawo (nibi ipepe re) dajudaju o maa wa ninu awon ti a maa le jade kuro ninu ilu.” |
O so pe: "Dajudaju emi wa ninu awon olubinu si ise (aburu) owo yin |
Oluwa mi, la emi ati awon eniyan mi nibi ohun ti won n se nise (aburu) |
Nitori naa, A la oun ati awon eniyan re patapata |
Afi arugbobinrin kan ti o wa ninu awon t’o se ku leyin (laaarin awon ti A pare) |
Leyin naa, A pa awon yooku run |
وَأَمْطَرْنَا عَلَيْهِم مَّطَرًا ۖ فَسَاءَ مَطَرُ الْمُنذَرِينَ(173) A ro ojo le won lori taara. Ojo awon ti A kilo fun si buru |
إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً ۖ وَمَا كَانَ أَكْثَرُهُم مُّؤْمِنِينَ(174) Dajudaju ami wa ninu iyen. Opolopo won ni ko si je onigbagbo ododo |
Dajudaju Oluwa re, Oun ma ni Alagbara, Asake-orun |
Awon ara ’Aekah pe awon Ojise ni opuro |
Nigba ti arakunrin won, (Anabi) Su‘aeb, so pe: “Se eyin ko nii beru (Allahu) ni |
Dajudaju emi ni Ojise olufokantan fun yin |
Nitori naa, e beru Allahu, ki e si tele mi |
وَمَا أَسْأَلُكُمْ عَلَيْهِ مِنْ أَجْرٍ ۖ إِنْ أَجْرِيَ إِلَّا عَلَىٰ رَبِّ الْعَالَمِينَ(180) Emi ko si beere owo-oya kan ni owo yin lori re. Ko si esan mi lodo eni kan afi lodo Oluwa gbogbo eda |
۞ أَوْفُوا الْكَيْلَ وَلَا تَكُونُوا مِنَ الْمُخْسِرِينَ(181) E won osuwon kun. Ki e si ma se wa ninu awon oludosuwonku |
E fi iwon t’o to won nnkan |
وَلَا تَبْخَسُوا النَّاسَ أَشْيَاءَهُمْ وَلَا تَعْثَوْا فِي الْأَرْضِ مُفْسِدِينَ(183) E ma se din nnkan awon eniyan ku. Ki e si ma se huwa aburu lori ile ni ti obileje |
وَاتَّقُوا الَّذِي خَلَقَكُمْ وَالْجِبِلَّةَ الْأَوَّلِينَ(184) Ki e si beru Eni ti O da yin ati awon iran akoko.” |
Won wi pe: “Iwo kuku wa ninu awon eleedi |
وَمَا أَنتَ إِلَّا بَشَرٌ مِّثْلُنَا وَإِن نَّظُنُّكَ لَمِنَ الْكَاذِبِينَ(186) Iwo ko si je kini kan bi ko se abara bi iru wa. Ati pe a o ro o si kini kan bi ko se pe o wa ninu awon opuro |
فَأَسْقِطْ عَلَيْنَا كِسَفًا مِّنَ السَّمَاءِ إِن كُنتَ مِنَ الصَّادِقِينَ(187) Nitori naa, je ki apa kan ninu sanmo ya lu wa mole, ti o ba wa ninu awon olododo.” |
O so pe: “Oluwa mi nimo julo nipa ohun ti e n se nise |
فَكَذَّبُوهُ فَأَخَذَهُمْ عَذَابُ يَوْمِ الظُّلَّةِ ۚ إِنَّهُ كَانَ عَذَابَ يَوْمٍ عَظِيمٍ(189) Won si pe e ni opuro. Nitori naa, iya ojo esujo si je won. Dajudaju o je iya ojo nla |
إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً ۖ وَمَا كَانَ أَكْثَرُهُم مُّؤْمِنِينَ(190) Dajudaju ami wa ninu iyen. Opolopo won ni ko si je onigbagbo ododo |
Dajudaju Oluwa re, Oun ma ni Alagbara, Asake-orun |
Dajudaju al-Ƙur’an, won so o kale ni lati odo Oluwa gbogbo eda |
Molaika Jibril, olufokantan l’o so o kale |
sinu okan re nitori ki o le wa ninu awon olukilo |
pelu ede Larubawa ponnbele |
Dajudaju (oro nipa re) ti wa ninu ipin-ipin Tira awon eni akoko |
أَوَلَمْ يَكُن لَّهُمْ آيَةً أَن يَعْلَمَهُ عُلَمَاءُ بَنِي إِسْرَائِيلَ(197) Se ko je ami kan fun won pe awon onimo (ninu) awon omo ’Isro’il nimo (si asoole nipa) re (ninu tira owo won) |
Ti o ba je pe A so o kale fun apa kan awon elede miiran ni |
ti o si ke e fun won, won ko nii gba a gbo ni ododo |
Bayen ni A se mu (atako) wo inu okan awon elese |
لَا يُؤْمِنُونَ بِهِ حَتَّىٰ يَرَوُا الْعَذَابَ الْأَلِيمَ(201) Won ko nii gba a gbo ni ododo titi won yoo fi ri iya eleta-elero |
(Iya naa) yoo de ba won ni ojiji; won ko si nii fura |
Nigba naa ni won yoo wi pe: "Nje won le lo wa lara bi |
Se iya Wa ni won n wa pelu ikanju |
So fun Mi ti A ba fun won ni igbadun aye fun odun gbooro |
Leyin naa, ki ohun ti A n se ni adehun fun won de ba won |
Ohun ti A se ni igbadun fun won ko si nii ro won loro |
A o si pa ilu kan run afi ki won ti ni awon olukilo |
Iranti (de fun won se). Ati pe Awa ki i se alabosi |
Ki i se awon esu ni won so (al-Ƙur’an) kale |
Ko ye fun won. Won ko si lagbara re |
Dajudaju A ti mu won takete si gbigbo re (lati oju sanmo) |
فَلَا تَدْعُ مَعَ اللَّهِ إِلَٰهًا آخَرَ فَتَكُونَ مِنَ الْمُعَذَّبِينَ(213) Nitori naa, ma se pe olohun miiran mo Allahu, nitori ki iwo ma baa wa ninu awon ti A maa je niya |
Ki o si kilo fun awon ebi re, t’o sunmo julo |
وَاخْفِضْ جَنَاحَكَ لِمَنِ اتَّبَعَكَ مِنَ الْمُؤْمِنِينَ(215) Ki o si re apa re nile fun awon t’o tele o ninu awon onigbagbo ododo |
فَإِنْ عَصَوْكَ فَقُلْ إِنِّي بَرِيءٌ مِّمَّا تَعْمَلُونَ(216) Ti won ba si yapa (ase) re, so pe: “Dajudaju emi yowo yose ninu ohun ti e n se (nise aburu).” |
Ki o si gbarale Alagbara, Asake-orun |
Eni t’O n ri o nigba ti o n dide naro (fun irun kiki) |
ati iyirapada re (fun rukuu ati iforikanle) laaarin awon oluforikanle |
Dajudaju Oun ma ni Olugbo, Onimo |
Se ki ng so eni ti awon esu n sokale wa ba |
Won n sokale wa ba gbogbo awon opuro, elese |
(Awon esu) n deti (si iro sanmo). Opolopo won si ni opuro |
Awon elewi, awon olusina l’o n tele won |
Se o o ri i pe gbogbo ogbun oro ni won n tenu bo ni |
Ati pe dajudaju won n so ohun ti won ko nii se |
Afi awon t’o gbagbo ni ododo, ti won se ise rere, ti won ranti Allahu ni opolopo, ti won si jaja gbara leyin ti won ti sabosi si won. Awon t’o sabosi si maa mo iru ikangun ti won maa gunle si |
Больше сур в Йоруба:
Скачать суру Ash-Shuara с голосом самых известных рекитаторов Корана:
Сура Ash-Shuara mp3: выберите рекитатора, чтобы прослушать и скачать главу Ash-Shuara полностью в высоком качестве
Ahmed Al Ajmy
Bandar Balila
Khalid Al Jalil
Saad Al Ghamdi
Saud Al Shuraim
Abdul Basit
Abdul Rashid Sufi
Abdullah Basfar
Abdullah Al Juhani
Fares Abbad
Maher Al Muaiqly
Al Minshawi
Al Hosary
Mishari Al-afasi
Yasser Al Dosari
Помолитесь за нас хорошей молитвой