Kasas suresi çevirisi Yoruba

  1. Suresi mp3
  2. Başka bir sure
  3. Yoruba
Kuranı Kerim türkçe meali | Kur'an çevirileri | Yoruba dili | Kasas Suresi | القصص - Ayet sayısı 88 - Moshaf'taki surenin numarası: 28 - surenin ingilizce anlamı: The Stories.

طسم(1)

 To sin mim

تِلْكَ آيَاتُ الْكِتَابِ الْمُبِينِ(2)

 Iwonyi ni awon ayah Tira t’o n yanju oro eda

نَتْلُو عَلَيْكَ مِن نَّبَإِ مُوسَىٰ وَفِرْعَوْنَ بِالْحَقِّ لِقَوْمٍ يُؤْمِنُونَ(3)

 A n ke ninu iro (Anabi) Musa ati Fir‘aon fun o pelu ododo nitori ijo t’o gbagbo lododo

إِنَّ فِرْعَوْنَ عَلَا فِي الْأَرْضِ وَجَعَلَ أَهْلَهَا شِيَعًا يَسْتَضْعِفُ طَائِفَةً مِّنْهُمْ يُذَبِّحُ أَبْنَاءَهُمْ وَيَسْتَحْيِي نِسَاءَهُمْ ۚ إِنَّهُ كَانَ مِنَ الْمُفْسِدِينَ(4)

 Dajudaju Fir‘aon segberaga lori ile. O se awon eniyan re ni ijo-ijo. O n da igun kan ninu won lagara; o n pa awon omokunrin won, o si n da awon obinrin won si. Dajudaju o wa ninu awon obileje

وَنُرِيدُ أَن نَّمُنَّ عَلَى الَّذِينَ اسْتُضْعِفُوا فِي الْأَرْضِ وَنَجْعَلَهُمْ أَئِمَّةً وَنَجْعَلَهُمُ الْوَارِثِينَ(5)

 A si fe sedera fun awon ti won foju tinrin lori ile, A (fe) se won ni asiwaju. A si (fe) ki won jogun (ile)

وَنُمَكِّنَ لَهُمْ فِي الْأَرْضِ وَنُرِيَ فِرْعَوْنَ وَهَامَانَ وَجُنُودَهُمَا مِنْهُم مَّا كَانُوا يَحْذَرُونَ(6)

 A (fe) gba won laaye lori ile. Lati ara won, A si (fe) fi han Fir‘aon ati Hamon pelu awon omo ogun awon mejeeji ohun ti won n sora fun lara won

وَأَوْحَيْنَا إِلَىٰ أُمِّ مُوسَىٰ أَنْ أَرْضِعِيهِ ۖ فَإِذَا خِفْتِ عَلَيْهِ فَأَلْقِيهِ فِي الْيَمِّ وَلَا تَخَافِي وَلَا تَحْزَنِي ۖ إِنَّا رَادُّوهُ إِلَيْكِ وَجَاعِلُوهُ مِنَ الْمُرْسَلِينَ(7)

 A si ranse si iya (Anabi) Musa pe: “Fun un ni omu mu. Ti o ba si n paya lori re, ju u sinu agbami odo. Ma se beru. Ma si se banuje. Dajudaju Awa maa da a pada si odo re. A o si se e ni ara awon Ojise

فَالْتَقَطَهُ آلُ فِرْعَوْنَ لِيَكُونَ لَهُمْ عَدُوًّا وَحَزَنًا ۗ إِنَّ فِرْعَوْنَ وَهَامَانَ وَجُنُودَهُمَا كَانُوا خَاطِئِينَ(8)

 Nigba naa, awon eniyan Fir‘aon ri i he nitori ki o le je ota ati ibanuje fun won. Dajudaju Fir‘aon, Hamon ati awon omo ogun awon mejeeji, won je alasise

وَقَالَتِ امْرَأَتُ فِرْعَوْنَ قُرَّتُ عَيْنٍ لِّي وَلَكَ ۖ لَا تَقْتُلُوهُ عَسَىٰ أَن يَنفَعَنَا أَوْ نَتَّخِذَهُ وَلَدًا وَهُمْ لَا يَشْعُرُونَ(9)

 Iyawo Fir‘aon wi pe: “Itutu-oju ni (omo yii) fun emi ati iwo. E ma se pa a. O le je pe o maa se wa ni anfaani tabi ki a fi se omo.” Won ko si fura

وَأَصْبَحَ فُؤَادُ أُمِّ مُوسَىٰ فَارِغًا ۖ إِن كَادَتْ لَتُبْدِي بِهِ لَوْلَا أَن رَّبَطْنَا عَلَىٰ قَلْبِهَا لِتَكُونَ مِنَ الْمُؤْمِنِينَ(10)

 Okan iya (Anabi) Musa pami (lori oro Musa, ko si ri nnkan miiran ro mo tayo re) o kuku fee safi han re (pe omo oun ni nigba ti won pe e de odo Fir‘aon) ti ko ba je pe A ki i lokan nitori ki o le wa ninu awon onigbagbo ododo

وَقَالَتْ لِأُخْتِهِ قُصِّيهِ ۖ فَبَصُرَتْ بِهِ عَن جُنُبٍ وَهُمْ لَا يَشْعُرُونَ(11)

 O si so fun arabinrin re pe: “Topa re lo.” O si n wo o lati ibi t’o jinna. Won ko si fura (si i)

۞ وَحَرَّمْنَا عَلَيْهِ الْمَرَاضِعَ مِن قَبْلُ فَقَالَتْ هَلْ أَدُلُّكُمْ عَلَىٰ أَهْلِ بَيْتٍ يَكْفُلُونَهُ لَكُمْ وَهُمْ لَهُ نَاصِحُونَ(12)

 A ko si je ki o mu oyan (miiran) siwaju (tiya re.) Arabinrin re si wi pe: “Se ki ng fi ara ile kan han yin, ti o maa gba a to fun yin? Won yo si je olutoju re.”

فَرَدَدْنَاهُ إِلَىٰ أُمِّهِ كَيْ تَقَرَّ عَيْنُهَا وَلَا تَحْزَنَ وَلِتَعْلَمَ أَنَّ وَعْدَ اللَّهِ حَقٌّ وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَهُمْ لَا يَعْلَمُونَ(13)

 A si da a pada si odo iya re nitori ki oju re le tutu (fun idunnu) ati nitori ki o ma baa banuje. Ati pe nitori ki o le mo pe dajudaju adehun Allahu, ododo ni, sugbon opolopo won ni ko mo

وَلَمَّا بَلَغَ أَشُدَّهُ وَاسْتَوَىٰ آتَيْنَاهُ حُكْمًا وَعِلْمًا ۚ وَكَذَٰلِكَ نَجْزِي الْمُحْسِنِينَ(14)

 Nigba t’o dagba, t’o di gende, A fun un ni ogbon ati imo. Bayen ni A se n san awon oluse-rere ni esan

وَدَخَلَ الْمَدِينَةَ عَلَىٰ حِينِ غَفْلَةٍ مِّنْ أَهْلِهَا فَوَجَدَ فِيهَا رَجُلَيْنِ يَقْتَتِلَانِ هَٰذَا مِن شِيعَتِهِ وَهَٰذَا مِنْ عَدُوِّهِ ۖ فَاسْتَغَاثَهُ الَّذِي مِن شِيعَتِهِ عَلَى الَّذِي مِنْ عَدُوِّهِ فَوَكَزَهُ مُوسَىٰ فَقَضَىٰ عَلَيْهِ ۖ قَالَ هَٰذَا مِنْ عَمَلِ الشَّيْطَانِ ۖ إِنَّهُ عَدُوٌّ مُّضِلٌّ مُّبِينٌ(15)

 O wo inu ilu nigba ti awon ara ilu ti gbagbe (nipa oro re). O ri awon okunrin meji kan ti won n ja. Eyi wa lati inu iran re. Eyi si wa lati (inu iran) ota re. Eyi ti o wa lati inu iran re wa iranlowo re lori eyi ti o wa lati (inu iran) ota re. Musa kan an ni ese. O si pa a. O so pe: “Eyi wa ninu ise Esu. Dajudaju (esu) ni ota asini-lona ponnbele.”

قَالَ رَبِّ إِنِّي ظَلَمْتُ نَفْسِي فَاغْفِرْ لِي فَغَفَرَ لَهُ ۚ إِنَّهُ هُوَ الْغَفُورُ الرَّحِيمُ(16)

 O so pe: “Oluwa mi, dajudaju emi ti sabosi si emi ara mi. Nitori naa, forijin mi.” O si forijin in. Dajudaju Allahu, Oun ni Alaforijin, Asake-orun

قَالَ رَبِّ بِمَا أَنْعَمْتَ عَلَيَّ فَلَنْ أَكُونَ ظَهِيرًا لِّلْمُجْرِمِينَ(17)

 O so pe: “Oluwa mi, fun wi pe O ti se ike fun mi, emi ko nii je oluranlowo fun awon elese.”

فَأَصْبَحَ فِي الْمَدِينَةِ خَائِفًا يَتَرَقَّبُ فَإِذَا الَّذِي اسْتَنصَرَهُ بِالْأَمْسِ يَسْتَصْرِخُهُ ۚ قَالَ لَهُ مُوسَىٰ إِنَّكَ لَغَوِيٌّ مُّبِينٌ(18)

 Nitori naa, o di eni t’o n beru ninu ilu, o si n reti (ehonu iran Fir‘aon). Nigba naa ni eni ti o wa iranlowo re ni ana tun n logun re fun iranlowo re. Musa so fun un pe: “Dajudaju iwo ni olusina ponnbele.”

فَلَمَّا أَنْ أَرَادَ أَن يَبْطِشَ بِالَّذِي هُوَ عَدُوٌّ لَّهُمَا قَالَ يَا مُوسَىٰ أَتُرِيدُ أَن تَقْتُلَنِي كَمَا قَتَلْتَ نَفْسًا بِالْأَمْسِ ۖ إِن تُرِيدُ إِلَّا أَن تَكُونَ جَبَّارًا فِي الْأَرْضِ وَمَا تُرِيدُ أَن تَكُونَ مِنَ الْمُصْلِحِينَ(19)

 Amo nigba ti o fe gba eni ti o je ota fun awon mejeeji mu, eni naa wi pe: “Musa, se o fe pa mi bi o se pa eni kan ni ana? O o gbero kan tayo ki o je alailoju-aanu lori ile; o o si gbero lati wa ninu awon alatun-unse.”

وَجَاءَ رَجُلٌ مِّنْ أَقْصَى الْمَدِينَةِ يَسْعَىٰ قَالَ يَا مُوسَىٰ إِنَّ الْمَلَأَ يَأْتَمِرُونَ بِكَ لِيَقْتُلُوكَ فَاخْرُجْ إِنِّي لَكَ مِنَ النَّاصِحِينَ(20)

 Okunrin kan sare de lati opin ilu naa, o wi pe: “Musa, dajudaju awon ijoye n da imoran lori re lati pa o. Nitori naa, jade (kuro ninu ilu), dajudaju emi wa ninu awon onimoran rere fun o.”

فَخَرَجَ مِنْهَا خَائِفًا يَتَرَقَّبُ ۖ قَالَ رَبِّ نَجِّنِي مِنَ الْقَوْمِ الظَّالِمِينَ(21)

 O si jade kuro ninu (ilu) pelu ipaya, ti o n reti (ehonu won), o si so pe: “Oluwa mi, la mi lowo ijo alabosi.”

وَلَمَّا تَوَجَّهَ تِلْقَاءَ مَدْيَنَ قَالَ عَسَىٰ رَبِّي أَن يَهْدِيَنِي سَوَاءَ السَّبِيلِ(22)

 Nigba ti o si doju ko okankan ilu Modyan, o so pe: “O sunmo ki Oluwa mi fona taara (si ilu Modyan) mo mi.”

وَلَمَّا وَرَدَ مَاءَ مَدْيَنَ وَجَدَ عَلَيْهِ أُمَّةً مِّنَ النَّاسِ يَسْقُونَ وَوَجَدَ مِن دُونِهِمُ امْرَأَتَيْنِ تَذُودَانِ ۖ قَالَ مَا خَطْبُكُمَا ۖ قَالَتَا لَا نَسْقِي حَتَّىٰ يُصْدِرَ الرِّعَاءُ ۖ وَأَبُونَا شَيْخٌ كَبِيرٌ(23)

 Nigba ti o de ibi (kannga) omi (ilu) Modyan, o ba ijo eniyan kan nibe ti won n fun awon eran-osin won ni omi mu. Leyin won, o tun ri awon obinrin meji kan ti won n fa seyin (pelu eran-osin won). O so pe: “Ki l’o se eyin mejeeji?” Won so pe: “A o le fun awon eran-osin wa ni omi mu titi awon adaran ba to ko awon eran-osin won lo. Agbalagba arugbo si ni baba wa.”

فَسَقَىٰ لَهُمَا ثُمَّ تَوَلَّىٰ إِلَى الظِّلِّ فَقَالَ رَبِّ إِنِّي لِمَا أَنزَلْتَ إِلَيَّ مِنْ خَيْرٍ فَقِيرٌ(24)

 O si ba won fun (eran-osin) won ni omi mu. Leyin naa, o pada sibi iboji, o si so pe: “Oluwa mi, dajudaju emi bukata si ohun ti O ba sokale fun mi ninu oore.”

فَجَاءَتْهُ إِحْدَاهُمَا تَمْشِي عَلَى اسْتِحْيَاءٍ قَالَتْ إِنَّ أَبِي يَدْعُوكَ لِيَجْزِيَكَ أَجْرَ مَا سَقَيْتَ لَنَا ۚ فَلَمَّا جَاءَهُ وَقَصَّ عَلَيْهِ الْقَصَصَ قَالَ لَا تَخَفْ ۖ نَجَوْتَ مِنَ الْقَوْمِ الظَّالِمِينَ(25)

 Okan ninu awon mejeeji wa ba a, o si n rin pelu itiju, o so pe: “Dajudaju baba mi n pe o nitori ki o le san o ni esan omi ti o fun (awon eran-osin) wa mu.” Nigba ti o de odo re, o so itan (ara re) fun un. (Baba naa) so pe: “Ma beru. O ti la lowo ijo alabosi.”

قَالَتْ إِحْدَاهُمَا يَا أَبَتِ اسْتَأْجِرْهُ ۖ إِنَّ خَيْرَ مَنِ اسْتَأْجَرْتَ الْقَوِيُّ الْأَمِينُ(26)

 Okan ninu (awon omobinrin) mejeeji so pe: “Baba mi o, gba a sise. Dajudaju eni t’o dara julo ti o le gba sise ni alagbara, olufokantan.”

قَالَ إِنِّي أُرِيدُ أَنْ أُنكِحَكَ إِحْدَى ابْنَتَيَّ هَاتَيْنِ عَلَىٰ أَن تَأْجُرَنِي ثَمَانِيَ حِجَجٍ ۖ فَإِنْ أَتْمَمْتَ عَشْرًا فَمِنْ عِندِكَ ۖ وَمَا أُرِيدُ أَنْ أَشُقَّ عَلَيْكَ ۚ سَتَجِدُنِي إِن شَاءَ اللَّهُ مِنَ الصَّالِحِينَ(27)

 O so pe: “Dajudaju mo fe fi okan ninu awon omobinrin mi mejeeji wonyi fun o ni aya lori (adehun) pe o maa ba mi sise fun odun mejo. Sugbon ti o ba se e pe odun mewaa, lati odo re niyen. Emi ko si fe ko inira ba o. Ti Allahu ba fe, o maa ri i pe mo wa ninu awon eni rere.”

قَالَ ذَٰلِكَ بَيْنِي وَبَيْنَكَ ۖ أَيَّمَا الْأَجَلَيْنِ قَضَيْتُ فَلَا عُدْوَانَ عَلَيَّ ۖ وَاللَّهُ عَلَىٰ مَا نَقُولُ وَكِيلٌ(28)

 (Musa) so pe: “(Adehun) yii wa laaarin emi ati iwo. Eyikeyii ti mo ba mu se ninu adehun mejeeji naa, iwo ko gbodo sabosi si mi. Allahu si ni Elerii lori ohun ti a n so (yii).”

۞ فَلَمَّا قَضَىٰ مُوسَى الْأَجَلَ وَسَارَ بِأَهْلِهِ آنَسَ مِن جَانِبِ الطُّورِ نَارًا قَالَ لِأَهْلِهِ امْكُثُوا إِنِّي آنَسْتُ نَارًا لَّعَلِّي آتِيكُم مِّنْهَا بِخَبَرٍ أَوْ جَذْوَةٍ مِّنَ النَّارِ لَعَلَّكُمْ تَصْطَلُونَ(29)

 Nigba ti Musa pari akoko naa, o mu ara ile re rin (irin-ajo). O si ri ina kan ni eba apata. O so fun ara ile re pe: “E duro (sibi na). Emi ri ina kan. O se e se ki ng mu iro kan wa ba yin lati ibe tabi (ki ng mu) ogunna kan wa nitori ki e le ri ohun yena.”

فَلَمَّا أَتَاهَا نُودِيَ مِن شَاطِئِ الْوَادِ الْأَيْمَنِ فِي الْبُقْعَةِ الْمُبَارَكَةِ مِنَ الشَّجَرَةِ أَن يَا مُوسَىٰ إِنِّي أَنَا اللَّهُ رَبُّ الْعَالَمِينَ(30)

 Nigba ti o de ibe, A pe e lati egbe afonifoji ni owo otun (re) ni aye ibukun lati ibi igi naa. (A so pe): “Musa, dajudaju Emi ni Allahu, Oluwa gbogbo eda

وَأَنْ أَلْقِ عَصَاكَ ۖ فَلَمَّا رَآهَا تَهْتَزُّ كَأَنَّهَا جَانٌّ وَلَّىٰ مُدْبِرًا وَلَمْ يُعَقِّبْ ۚ يَا مُوسَىٰ أَقْبِلْ وَلَا تَخَفْ ۖ إِنَّكَ مِنَ الْآمِنِينَ(31)

 Ju opa re sile.” (O si ju u sile). Nigba ti o ri i t’o n mira bi eni pe ejo ni, Musa peyin da, o n sa lo, ko si pada. (Allahu so pe): “Musa, maa bo pada, ma si se paya. Dajudaju iwo wa ninu awon olufayabale

اسْلُكْ يَدَكَ فِي جَيْبِكَ تَخْرُجْ بَيْضَاءَ مِنْ غَيْرِ سُوءٍ وَاضْمُمْ إِلَيْكَ جَنَاحَكَ مِنَ الرَّهْبِ ۖ فَذَانِكَ بُرْهَانَانِ مِن رَّبِّكَ إِلَىٰ فِرْعَوْنَ وَمَلَئِهِ ۚ إِنَّهُمْ كَانُوا قَوْمًا فَاسِقِينَ(32)

 Ti owo re bo (abiya lati ibi) orun ewu re, o si maa jade ni funfun ti ki i se ti aburu. Pa owo re mora si (abiya re) nibi eru. Nitori naa, awon eri meji niwonyi lati odo Oluwa re si Fir‘aon ati awon ijoye re. Dajudaju won je ijo obileje.”

قَالَ رَبِّ إِنِّي قَتَلْتُ مِنْهُمْ نَفْسًا فَأَخَافُ أَن يَقْتُلُونِ(33)

 (Anabi Musa) so pe: “Oluwa mi, dajudaju emi pa eni kan ninu won. Nitori naa, mo n beru pe won maa pa mi

وَأَخِي هَارُونُ هُوَ أَفْصَحُ مِنِّي لِسَانًا فَأَرْسِلْهُ مَعِيَ رِدْءًا يُصَدِّقُنِي ۖ إِنِّي أَخَافُ أَن يُكَذِّبُونِ(34)

 Ati pe arakunrin mi, Harun, o da lahon ju mi lo. Nitori naa, ran an nise pelu mi, ki o je oluranlowo ti yoo maa jerii si ododo oro mi. Dajudaju emi n beru pe won maa pe mi ni opuro.”

قَالَ سَنَشُدُّ عَضُدَكَ بِأَخِيكَ وَنَجْعَلُ لَكُمَا سُلْطَانًا فَلَا يَصِلُونَ إِلَيْكُمَا ۚ بِآيَاتِنَا أَنتُمَا وَمَنِ اتَّبَعَكُمَا الْغَالِبُونَ(35)

 (Allahu) so pe: “A maa fi arakunrin re kun o lowo. A o si fun eyin mejeeji ni agbara, won ko si nii le de odo eyin mejeeji. Pelu awon ami Wa, eyin mejeeji ati awon t’o ba tele eyin mejeeji l’o maa bori.”

فَلَمَّا جَاءَهُم مُّوسَىٰ بِآيَاتِنَا بَيِّنَاتٍ قَالُوا مَا هَٰذَا إِلَّا سِحْرٌ مُّفْتَرًى وَمَا سَمِعْنَا بِهَٰذَا فِي آبَائِنَا الْأَوَّلِينَ(36)

 Nigba ti (Anabi) Musa de ba won pelu awon ami Wa, won wi pe: “Ki ni eyi bi ko se idan adahun. A ko si gbo eyi (ri) laaarin awon baba wa, awon eni akoko.”

وَقَالَ مُوسَىٰ رَبِّي أَعْلَمُ بِمَن جَاءَ بِالْهُدَىٰ مِنْ عِندِهِ وَمَن تَكُونُ لَهُ عَاقِبَةُ الدَّارِ ۖ إِنَّهُ لَا يُفْلِحُ الظَّالِمُونَ(37)

 (Anabi) Musa si so pe: “Oluwa mi nimo julo nipa eni ti o mu imona wa lati odo Re ati eni ti atubotan ile (ike) maa je tire. Dajudaju awon alabosi ko nii jere.”

وَقَالَ فِرْعَوْنُ يَا أَيُّهَا الْمَلَأُ مَا عَلِمْتُ لَكُم مِّنْ إِلَٰهٍ غَيْرِي فَأَوْقِدْ لِي يَا هَامَانُ عَلَى الطِّينِ فَاجْعَل لِّي صَرْحًا لَّعَلِّي أَطَّلِعُ إِلَىٰ إِلَٰهِ مُوسَىٰ وَإِنِّي لَأَظُنُّهُ مِنَ الْكَاذِبِينَ(38)

 Fir‘aon wi pe: “Eyin ijoye, emi ko mo pe olohun kan tun wa leyin mi! Nitori naa, Hamon, da ina fun mi, ki o fi mo amo, ki o si ko ile giga kan fun mi nitori ki emi le yoju wo Olohun Musa. (Nitori pe) dajudaju mo n ro o si ara awon opuro.”

وَاسْتَكْبَرَ هُوَ وَجُنُودُهُ فِي الْأَرْضِ بِغَيْرِ الْحَقِّ وَظَنُّوا أَنَّهُمْ إِلَيْنَا لَا يُرْجَعُونَ(39)

 Oun ati awon omo ogun re si segberaga lori ile lai letoo. Won si ro pe dajudaju A o nii da won pada si odo Wa

فَأَخَذْنَاهُ وَجُنُودَهُ فَنَبَذْنَاهُمْ فِي الْيَمِّ ۖ فَانظُرْ كَيْفَ كَانَ عَاقِبَةُ الظَّالِمِينَ(40)

 Nitori naa, A gba oun ati awon omo ogun re mu; A ju won sinu agbami odo. Wo bi atubotan awon alabosi ti ri

وَجَعَلْنَاهُمْ أَئِمَّةً يَدْعُونَ إِلَى النَّارِ ۖ وَيَوْمَ الْقِيَامَةِ لَا يُنصَرُونَ(41)

 A se won ni asiwaju t’o n pepe sinu Ina. Ti o ba si di Ojo Ajinde, A o nii ran won lowo

وَأَتْبَعْنَاهُمْ فِي هَٰذِهِ الدُّنْيَا لَعْنَةً ۖ وَيَوْمَ الْقِيَامَةِ هُم مِّنَ الْمَقْبُوحِينَ(42)

 Ati pe A fi egun topa won ni ile aye yii. Ni Ojo Ajinde, won yo si wa ninu awon eni iparun

وَلَقَدْ آتَيْنَا مُوسَى الْكِتَابَ مِن بَعْدِ مَا أَهْلَكْنَا الْقُرُونَ الْأُولَىٰ بَصَائِرَ لِلنَّاسِ وَهُدًى وَرَحْمَةً لَّعَلَّهُمْ يَتَذَكَّرُونَ(43)

 Dajudaju A ti fun (Anabi) Musa ni Tira leyin igba ti A ti pa awon ijo akoko re. (Tira naa je) ariwoye fun awon eniyan, imona ati ike nitori ki won le lo iranti

وَمَا كُنتَ بِجَانِبِ الْغَرْبِيِّ إِذْ قَضَيْنَا إِلَىٰ مُوسَى الْأَمْرَ وَمَا كُنتَ مِنَ الشَّاهِدِينَ(44)

 Iwo ko si ni eba iwo-oorun nigba ti A fi oro naa ranse si (Anabi) Musa. Ati pe iwo ko si ninu awon t’o wa nibe

وَلَٰكِنَّا أَنشَأْنَا قُرُونًا فَتَطَاوَلَ عَلَيْهِمُ الْعُمُرُ ۚ وَمَا كُنتَ ثَاوِيًا فِي أَهْلِ مَدْيَنَ تَتْلُو عَلَيْهِمْ آيَاتِنَا وَلَٰكِنَّا كُنَّا مُرْسِلِينَ(45)

 Sugbon A seda awon iran kan ti emi won gun. O o kuku gbe laaarin ara ilu Modyan, ti o n ke awon ayah Wa fun won, sugbon Awa l’a n ran awon Ojise nise

وَمَا كُنتَ بِجَانِبِ الطُّورِ إِذْ نَادَيْنَا وَلَٰكِن رَّحْمَةً مِّن رَّبِّكَ لِتُنذِرَ قَوْمًا مَّا أَتَاهُم مِّن نَّذِيرٍ مِّن قَبْلِكَ لَعَلَّهُمْ يَتَذَكَّرُونَ(46)

 (Iwo ko si si ni eba apata, nigba ti A pepe, sugbon o je ike kan lati odo Oluwa re nitori ki o le sekilo fun awon eniyan ti olukilo kan ko wa ba ri siwaju re nitori ki won le lo iranti. 16:36 ati surah Fatir 35:24) bee naa l’a ri awon ayah miiran t’o n fi rinle pe Allahu ko ran Ojise tabi Anabi kan ri si awon Larubawa (gege bi o se rinle ninu surah al-Ƙosos ko si Ojise kan ti Allahu gbe dide laaarin won si gbogbo iran won ni apapo. Bi o tile je pe awon Larubawa ni anfaani lati gbo nipa Anabi ’Ibrohim ati omo re Anabi ’Ismo‘il pe Allahu ran won nise si awon eniyan kan amo ko si oye atinuwa fun imo nipa bi won maa se josin fun Allahu Eledaa won afi ki won ni Ojise kan t’o maa je asiwaju fun won gege bi olukoni rere. Idi niyi ti Allahu (subhanahu wa ta’ala) fi gbe Anabi Muhammad (sollalahu alayhi wa sallam) dide ni ara oto. Itumo “ni ara oto” ni pe

وَلَوْلَا أَن تُصِيبَهُم مُّصِيبَةٌ بِمَا قَدَّمَتْ أَيْدِيهِمْ فَيَقُولُوا رَبَّنَا لَوْلَا أَرْسَلْتَ إِلَيْنَا رَسُولًا فَنَتَّبِعَ آيَاتِكَ وَنَكُونَ مِنَ الْمُؤْمِنِينَ(47)

 Ti o ba je pe adanwo kan kan won nitori ohun ti won fi owo won ti siwaju, won iba wi pe: “Oluwa wa, ti O ba je pe O ran Ojise kan si wa ni, a a ba tele awon ayah Re, a a ba si wa ninu awon onigbagbo ododo.”

فَلَمَّا جَاءَهُمُ الْحَقُّ مِنْ عِندِنَا قَالُوا لَوْلَا أُوتِيَ مِثْلَ مَا أُوتِيَ مُوسَىٰ ۚ أَوَلَمْ يَكْفُرُوا بِمَا أُوتِيَ مُوسَىٰ مِن قَبْلُ ۖ قَالُوا سِحْرَانِ تَظَاهَرَا وَقَالُوا إِنَّا بِكُلٍّ كَافِرُونَ(48)

 Sugbon nigba ti ododo de ba won lati odo Wa, won wi pe: "Ki ni ko je ki Won fun un ni iru ohun ti Won fun (Anabi) Musa?" Se won ko si sai gbagbo ninu ohun ti A fun (Anabi) Musa siwaju bi? Won wi pe: “Opidan meji t’o n ranra won lowo (ni won).” Won si tun wi pe: “Dajudaju awa je alaigbagbo ninu ikookan (won).”

قُلْ فَأْتُوا بِكِتَابٍ مِّنْ عِندِ اللَّهِ هُوَ أَهْدَىٰ مِنْهُمَا أَتَّبِعْهُ إِن كُنتُمْ صَادِقِينَ(49)

 So pe: “Nitori naa, e mu tira kan wa lati odo Allahu, t’o n to ni si ona ju ti awon mejeeji lo, mo si maa tele e, ti e ba je olododo.”

فَإِن لَّمْ يَسْتَجِيبُوا لَكَ فَاعْلَمْ أَنَّمَا يَتَّبِعُونَ أَهْوَاءَهُمْ ۚ وَمَنْ أَضَلُّ مِمَّنِ اتَّبَعَ هَوَاهُ بِغَيْرِ هُدًى مِّنَ اللَّهِ ۚ إِنَّ اللَّهَ لَا يَهْدِي الْقَوْمَ الظَّالِمِينَ(50)

 Ti won ko ba jepe re, mo pe won kan n tele ife-inu won ni. Ta l’o si sina ju eni t’o tele ife-inu re, lai si imona (fun un) lati odo Allahu! Dajudaju Allahu ko nii fi ona mo ijo alabosi

۞ وَلَقَدْ وَصَّلْنَا لَهُمُ الْقَوْلَ لَعَلَّهُمْ يَتَذَكَّرُونَ(51)

 Ati pe dajudaju A ti se alaye oro naa fun won nitori ki won le lo iranti

الَّذِينَ آتَيْنَاهُمُ الْكِتَابَ مِن قَبْلِهِ هُم بِهِ يُؤْمِنُونَ(52)

 Awon ti A fun ni Tira siwaju re, won gba al-Ƙur’an gbo

وَإِذَا يُتْلَىٰ عَلَيْهِمْ قَالُوا آمَنَّا بِهِ إِنَّهُ الْحَقُّ مِن رَّبِّنَا إِنَّا كُنَّا مِن قَبْلِهِ مُسْلِمِينَ(53)

 Ati pe nigba ti won ba n ke e fun won, won a so pe: “A gba a gbo. Dajudaju ododo ni lati odo Oluwa wa. Dajudaju awa ti je musulumi siwaju re.”

أُولَٰئِكَ يُؤْتَوْنَ أَجْرَهُم مَّرَّتَيْنِ بِمَا صَبَرُوا وَيَدْرَءُونَ بِالْحَسَنَةِ السَّيِّئَةَ وَمِمَّا رَزَقْنَاهُمْ يُنفِقُونَ(54)

 Awon wonyen ni A maa fun won ni esan won ni ee meji nitori pe won se suuru, won si n fi daadaa ti aidaa danu. Ati pe won n na ninu ohun ti A pese fun won

وَإِذَا سَمِعُوا اللَّغْوَ أَعْرَضُوا عَنْهُ وَقَالُوا لَنَا أَعْمَالُنَا وَلَكُمْ أَعْمَالُكُمْ سَلَامٌ عَلَيْكُمْ لَا نَبْتَغِي الْجَاهِلِينَ(55)

 Ati pe nigba ti won ba gbo oro buruku, won a seri kuro nibe, won a si so pe: “Tiwa ni awon ise wa. Tiyin si ni awon ise yin. Ki alaafia maa ba yin. A ko wa awon alaimokan (ni alabaasepo).”

إِنَّكَ لَا تَهْدِي مَنْ أَحْبَبْتَ وَلَٰكِنَّ اللَّهَ يَهْدِي مَن يَشَاءُ ۚ وَهُوَ أَعْلَمُ بِالْمُهْتَدِينَ(56)

 Dajudaju iwo ko le fi ona mo eni ti o feran, sugbon Allahu l’O n fi ona mo eni ti O ba fe. Ati pe O nimo julo nipa awon olumona

وَقَالُوا إِن نَّتَّبِعِ الْهُدَىٰ مَعَكَ نُتَخَطَّفْ مِنْ أَرْضِنَا ۚ أَوَلَمْ نُمَكِّن لَّهُمْ حَرَمًا آمِنًا يُجْبَىٰ إِلَيْهِ ثَمَرَاتُ كُلِّ شَيْءٍ رِّزْقًا مِّن لَّدُنَّا وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَهُمْ لَا يَعْلَمُونَ(57)

 Won wi pe: “Ti a ba (fi le) tele imona pelu re, awon osebo yoo ko wa kuro lori ile wa.” Se A o fun won ni ibugbe (ti o je) aye owo ifokanbale, ti won si n ko awon eso gbogbo ilu wa sibe, ti o je ese lati odo Wa? Sugbon opolopo won ni ko mo

وَكَمْ أَهْلَكْنَا مِن قَرْيَةٍ بَطِرَتْ مَعِيشَتَهَا ۖ فَتِلْكَ مَسَاكِنُهُمْ لَمْ تُسْكَن مِّن بَعْدِهِمْ إِلَّا قَلِيلًا ۖ وَكُنَّا نَحْنُ الْوَارِثِينَ(58)

 Meloo meloo ninu ilu ti A pare, ti won yo ayoporo aye-jije ninu ilu. Iwonyen ni awon ibugbe won, ti A ko je ki eni kan kan gbe ibe leyin won bi ko se fun igba die. Awa si je Olujogun

وَمَا كَانَ رَبُّكَ مُهْلِكَ الْقُرَىٰ حَتَّىٰ يَبْعَثَ فِي أُمِّهَا رَسُولًا يَتْلُو عَلَيْهِمْ آيَاتِنَا ۚ وَمَا كُنَّا مُهْلِكِي الْقُرَىٰ إِلَّا وَأَهْلُهَا ظَالِمُونَ(59)

 Oluwa re ko si nii pa awon ilu run (ni asiko tire yii) titi O fi maa gbe Ojise kan dide ninu Olu-ilu-aye (iyen, ilu Mokkah, eni ti) yoo maa ke awon ayah Wa fun won. (O si ti se bee.) A o si nii pa awon ilu (yii) run se afi ki awon ara ibe je alabosi

وَمَا أُوتِيتُم مِّن شَيْءٍ فَمَتَاعُ الْحَيَاةِ الدُّنْيَا وَزِينَتُهَا ۚ وَمَا عِندَ اللَّهِ خَيْرٌ وَأَبْقَىٰ ۚ أَفَلَا تَعْقِلُونَ(60)

 Ko si ohun ti A fun yin bi ko se nitori igbadun aye ati oso re. Ohun t’o n be lodo Allahu loore julo, o si maa wa titi laelae. Nitori naa, se e o nii se laakaye ni

أَفَمَن وَعَدْنَاهُ وَعْدًا حَسَنًا فَهُوَ لَاقِيهِ كَمَن مَّتَّعْنَاهُ مَتَاعَ الْحَيَاةِ الدُّنْيَا ثُمَّ هُوَ يَوْمَ الْقِيَامَةِ مِنَ الْمُحْضَرِينَ(61)

 Nje eni ti A ba sadehun ni adehun t’o dara, ti o si maa pade re, da bi eni ti A fun ni igbadun isemi aye bi, leyin naa ni Ojo Ajinde ti o maa wa ninu awon ti won yoo mu wa (fun iya Ina)

وَيَوْمَ يُنَادِيهِمْ فَيَقُولُ أَيْنَ شُرَكَائِيَ الَّذِينَ كُنتُمْ تَزْعُمُونَ(62)

 (Ranti) ojo ti (Allahu) yoo pe won, O si maa so pe: “Nibo ni awon akegbe Mi ti e n so nipa won lai ni eri lowo wa?”

قَالَ الَّذِينَ حَقَّ عَلَيْهِمُ الْقَوْلُ رَبَّنَا هَٰؤُلَاءِ الَّذِينَ أَغْوَيْنَا أَغْوَيْنَاهُمْ كَمَا غَوَيْنَا ۖ تَبَرَّأْنَا إِلَيْكَ ۖ مَا كَانُوا إِيَّانَا يَعْبُدُونَ(63)

 Awon ti oro naa ko le lori wi pe: “Oluwa wa, awon wonyi ti a ko sina, a ko won sina gege bi awa naa se sina. A yowo yose (ninu oro won) niwaju Re (bayii); ki i se awa ni won n josin fun.”

وَقِيلَ ادْعُوا شُرَكَاءَكُمْ فَدَعَوْهُمْ فَلَمْ يَسْتَجِيبُوا لَهُمْ وَرَأَوُا الْعَذَابَ ۚ لَوْ أَنَّهُمْ كَانُوا يَهْتَدُونَ(64)

 A so (fun won) pe: “E pe awon orisa yin.” Won si pe won, sugbon won ko da won lohun. Won ti ri Ina. Ti o ba je pe dajudaju won je olumona ni (iya iba ti je won)

وَيَوْمَ يُنَادِيهِمْ فَيَقُولُ مَاذَا أَجَبْتُمُ الْمُرْسَلِينَ(65)

 (Ranti) ojo ti (Allahu) yoo pe won, O si maa so pe: “Ki ni e fo ni esi fun awon Ojise?”

فَعَمِيَتْ عَلَيْهِمُ الْأَنبَاءُ يَوْمَئِذٍ فَهُمْ لَا يَتَسَاءَلُونَ(66)

 Esi oro yo si foju po mo won lowo ni ojo yen; won ko si nii bira won leere ibeere

فَأَمَّا مَن تَابَ وَآمَنَ وَعَمِلَ صَالِحًا فَعَسَىٰ أَن يَكُونَ مِنَ الْمُفْلِحِينَ(67)

 Sugbon ni ti eni ti o ba ronu piwada, ti o gbagbo ni ododo, ti o si se ise rere, o sunmo pe o maa wa ninu awon olujere

وَرَبُّكَ يَخْلُقُ مَا يَشَاءُ وَيَخْتَارُ ۗ مَا كَانَ لَهُمُ الْخِيَرَةُ ۚ سُبْحَانَ اللَّهِ وَتَعَالَىٰ عَمَّا يُشْرِكُونَ(68)

 Oluwa re l’O n seda ohun ti O ba fe. O si n sa (ohun ti O ba fe) ni esa. Sisa esa ko to si won. Mimo ni fun Allahu. O si ga tayo nnkan ti won n fi sebo si I

وَرَبُّكَ يَعْلَمُ مَا تُكِنُّ صُدُورُهُمْ وَمَا يُعْلِنُونَ(69)

 Oluwa re si mo ohun ti igba-aya won n fi pamo ati ohun ti won n se afihan re

وَهُوَ اللَّهُ لَا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ ۖ لَهُ الْحَمْدُ فِي الْأُولَىٰ وَالْآخِرَةِ ۖ وَلَهُ الْحُكْمُ وَإِلَيْهِ تُرْجَعُونَ(70)

 Oun si ni Allahu. Ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. TiRe ni ope ni ile aye yii ati ni orun. TiRe si ni idajo. Odo Re si ni won yoo da yin pada si

قُلْ أَرَأَيْتُمْ إِن جَعَلَ اللَّهُ عَلَيْكُمُ اللَّيْلَ سَرْمَدًا إِلَىٰ يَوْمِ الْقِيَامَةِ مَنْ إِلَٰهٌ غَيْرُ اللَّهِ يَأْتِيكُم بِضِيَاءٍ ۖ أَفَلَا تَسْمَعُونَ(71)

 So pe: " E so fun mi, ti Allahu ba so oru di ohun ti o maa wa titi laelae fun yin di Ojo Ajinde, olohun wo leyin Allahu l’o maa fun yin ni imole? Se e o gboro ni?”

قُلْ أَرَأَيْتُمْ إِن جَعَلَ اللَّهُ عَلَيْكُمُ النَّهَارَ سَرْمَدًا إِلَىٰ يَوْمِ الْقِيَامَةِ مَنْ إِلَٰهٌ غَيْرُ اللَّهِ يَأْتِيكُم بِلَيْلٍ تَسْكُنُونَ فِيهِ ۖ أَفَلَا تُبْصِرُونَ(72)

 So pe: " E so fun mi, ti Allahu ba so osan di ohun ti o maa wa titi laelae fun yin di Ojo Ajinde, olohun wo leyin Allahu l’o maa fun yin ni ale ti e oo maa sinmi ninu re? Se e o riran ni?”

وَمِن رَّحْمَتِهِ جَعَلَ لَكُمُ اللَّيْلَ وَالنَّهَارَ لِتَسْكُنُوا فِيهِ وَلِتَبْتَغُوا مِن فَضْلِهِ وَلَعَلَّكُمْ تَشْكُرُونَ(73)

 Ninu ike Re (ni pe) O se oru ati osan fun yin; nitori ki e le sinmi ninu (oru) ati nitori ki e le wa ninu oore Re (ni osan) ati nitori ki e le dupe

وَيَوْمَ يُنَادِيهِمْ فَيَقُولُ أَيْنَ شُرَكَائِيَ الَّذِينَ كُنتُمْ تَزْعُمُونَ(74)

 (Ranti) ojo ti (Allahu) yoo pe won, O si maa so pe: “Nibo ni awon akegbe Mi ti e n so nipa won lai ni eri lowo wa?”

وَنَزَعْنَا مِن كُلِّ أُمَّةٍ شَهِيدًا فَقُلْنَا هَاتُوا بُرْهَانَكُمْ فَعَلِمُوا أَنَّ الْحَقَّ لِلَّهِ وَضَلَّ عَنْهُم مَّا كَانُوا يَفْتَرُونَ(75)

 A si maa mu elerii kan jade ninu ijo kookan. A maa so pe: “E mu idi oro yin wa.” Nigba naa, won yoo mo pe dajudaju ododo n je ti Allahu. Ohun ti won si n da ni adapa iro yo si dofo mo won lowo

۞ إِنَّ قَارُونَ كَانَ مِن قَوْمِ مُوسَىٰ فَبَغَىٰ عَلَيْهِمْ ۖ وَآتَيْنَاهُ مِنَ الْكُنُوزِ مَا إِنَّ مَفَاتِحَهُ لَتَنُوءُ بِالْعُصْبَةِ أُولِي الْقُوَّةِ إِذْ قَالَ لَهُ قَوْمُهُ لَا تَفْرَحْ ۖ إِنَّ اللَّهَ لَا يُحِبُّ الْفَرِحِينَ(76)

 Dajudaju Ƙorun wa ninu ijo (Anabi) Musa, sugbon o segberaga si won. A si fun un ni awon apoti-oro eyi ti awon kokoro re wuwo lati gbe fun opo eniyan, awon alagbara. (Ranti) nigba ti awon eniyan re so fun un pe: "Ma se yo ayo ayoju. Dajudaju Allahu ko feran awon alayoju

وَابْتَغِ فِيمَا آتَاكَ اللَّهُ الدَّارَ الْآخِرَةَ ۖ وَلَا تَنسَ نَصِيبَكَ مِنَ الدُّنْيَا ۖ وَأَحْسِن كَمَا أَحْسَنَ اللَّهُ إِلَيْكَ ۖ وَلَا تَبْغِ الْفَسَادَ فِي الْأَرْضِ ۖ إِنَّ اللَّهَ لَا يُحِبُّ الْمُفْسِدِينَ(77)

 Fi nnkan ti Allahu fun o wa ile Ikeyin. Ma se gbagbe ipin re ni ile aye. Se daadaa gege bi Allahu ti se daadaa fun o. Ma si se wa ibaje se lori ile. Dajudaju Allahu ko feran awon obileje

قَالَ إِنَّمَا أُوتِيتُهُ عَلَىٰ عِلْمٍ عِندِي ۚ أَوَلَمْ يَعْلَمْ أَنَّ اللَّهَ قَدْ أَهْلَكَ مِن قَبْلِهِ مِنَ الْقُرُونِ مَنْ هُوَ أَشَدُّ مِنْهُ قُوَّةً وَأَكْثَرُ جَمْعًا ۚ وَلَا يُسْأَلُ عَن ذُنُوبِهِمُ الْمُجْرِمُونَ(78)

 O wi pe: "Dajudaju won fun mi pelu imo t’o n be lodo mi ni." Se ko mo pe dajudaju Allahu ti parun ninu awon iran t’o siwaju re, eni ti o lagbara ju u lo, ti o si ni akojo oro ju u lo? A o si nii bi awon arufin leere (ese won. O kuku ti wa ni akosile)

فَخَرَجَ عَلَىٰ قَوْمِهِ فِي زِينَتِهِ ۖ قَالَ الَّذِينَ يُرِيدُونَ الْحَيَاةَ الدُّنْيَا يَا لَيْتَ لَنَا مِثْلَ مَا أُوتِيَ قَارُونُ إِنَّهُ لَذُو حَظٍّ عَظِيمٍ(79)

 O jade si awon eniyan re pelu oso re. Awon t’o n fe isemi aye yii si wi pe: “Haa! Ki a si ni iru ohun ti won fun Ƙorun. Dajudaju o ni ipin nla ninu oore.”

وَقَالَ الَّذِينَ أُوتُوا الْعِلْمَ وَيْلَكُمْ ثَوَابُ اللَّهِ خَيْرٌ لِّمَنْ آمَنَ وَعَمِلَ صَالِحًا وَلَا يُلَقَّاهَا إِلَّا الصَّابِرُونَ(80)

 Awon ti A fun ni imo so pe: “Egbe ni fun yin! Esan Allahu loore julo fun eni t’o ba gbagbo ni ododo, ti o si se ise rere. Ko si si eni ti o maa ri (esan naa) gba afi awon onisuuru.”

فَخَسَفْنَا بِهِ وَبِدَارِهِ الْأَرْضَ فَمَا كَانَ لَهُ مِن فِئَةٍ يَنصُرُونَهُ مِن دُونِ اللَّهِ وَمَا كَانَ مِنَ الْمُنتَصِرِينَ(81)

 Nitori naa, A je ki ile gbe oun ati ile re mi. Ko ni ijo kan ti o le ran an lowo leyin Allahu. Ko si si ninu awon t’o le ran ara re lowo

وَأَصْبَحَ الَّذِينَ تَمَنَّوْا مَكَانَهُ بِالْأَمْسِ يَقُولُونَ وَيْكَأَنَّ اللَّهَ يَبْسُطُ الرِّزْقَ لِمَن يَشَاءُ مِنْ عِبَادِهِ وَيَقْدِرُ ۖ لَوْلَا أَن مَّنَّ اللَّهُ عَلَيْنَا لَخَسَفَ بِنَا ۖ وَيْكَأَنَّهُ لَا يُفْلِحُ الْكَافِرُونَ(82)

 Awon t’o n rankan ipo re ni ana si bere si wi pe: “Se e ri i pe dajudaju Allahu l’O n te oro sile fun eni ti O ba fe ninu awon erusin Re. O si n diwon re (fun elomiiran). Ti ko ba je pe Allahu ke wa ni, iba je ki ile gbe awa naa mi ni. Se e ri i pe awon alaimoore ko nii jere.”

تِلْكَ الدَّارُ الْآخِرَةُ نَجْعَلُهَا لِلَّذِينَ لَا يُرِيدُونَ عُلُوًّا فِي الْأَرْضِ وَلَا فَسَادًا ۚ وَالْعَاقِبَةُ لِلْمُتَّقِينَ(83)

 Ile Ikeyin yen, A maa fi fun awon ti ko fe maa se igberaga ati ibaje lori ile. Igbeyin rere si wa fun awon oluberu (Allahu)

مَن جَاءَ بِالْحَسَنَةِ فَلَهُ خَيْرٌ مِّنْهَا ۖ وَمَن جَاءَ بِالسَّيِّئَةِ فَلَا يُجْزَى الَّذِينَ عَمِلُوا السَّيِّئَاتِ إِلَّا مَا كَانُوا يَعْمَلُونَ(84)

 Enikeni ti o ba mu ise rere wa, tire ni rere t’o loore julo si eyi t’o mu wa. Enikeni ti o ba si mu ise aburu wa, A o si nii san awon t’o se ise aburu ni esan kan afi ohun ti won n se nise

إِنَّ الَّذِي فَرَضَ عَلَيْكَ الْقُرْآنَ لَرَادُّكَ إِلَىٰ مَعَادٍ ۚ قُل رَّبِّي أَعْلَمُ مَن جَاءَ بِالْهُدَىٰ وَمَنْ هُوَ فِي ضَلَالٍ مُّبِينٍ(85)

 Dajudaju Eni ti O se al-Ƙur’an ni oran-anyan fun o, O si maa da o pada si ebute kan. So pe: “Oluwa mi nimo julo nipa eni ti o mu imona wa ati ta ni o wa ninu isina ponnbele.”

وَمَا كُنتَ تَرْجُو أَن يُلْقَىٰ إِلَيْكَ الْكِتَابُ إِلَّا رَحْمَةً مِّن رَّبِّكَ ۖ فَلَا تَكُونَنَّ ظَهِيرًا لِّلْكَافِرِينَ(86)

 Iwo ko si reti pe A oo so tira al-Ƙur’an kale fun o (tele), amo o je ike kan lati odo Oluwa re. Nitori naa, o o gbodo je alatileyin fun awon alaigbagbo

وَلَا يَصُدُّنَّكَ عَنْ آيَاتِ اللَّهِ بَعْدَ إِذْ أُنزِلَتْ إِلَيْكَ ۖ وَادْعُ إِلَىٰ رَبِّكَ ۖ وَلَا تَكُونَنَّ مِنَ الْمُشْرِكِينَ(87)

 Ma se je ki won se o lori kuro nibi awon ayah Allahu leyin igba ti A ti so o kale fun o. Pepe si odo Oluwa re. Iwo ko si gbodo wa ninu awon osebo

وَلَا تَدْعُ مَعَ اللَّهِ إِلَٰهًا آخَرَ ۘ لَا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ ۚ كُلُّ شَيْءٍ هَالِكٌ إِلَّا وَجْهَهُ ۚ لَهُ الْحُكْمُ وَإِلَيْهِ تُرْجَعُونَ(88)

 Ma se pe olohun miiran mo Allahu. Ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. Gbogbo nnkan l’o maa parun afi Oju Re (afi Oun). TiRe ni idajo. Odo Re si ni won yoo da yin pada si


Yoruba diğer sureler:

Bakara suresi Âl-i İmrân Nisâ suresi
Mâide suresi Yûsuf suresi İbrâhîm suresi
Hicr suresi Kehf suresi Meryem suresi
Hac suresi Kasas suresi Ankebût suresi
As-Sajdah Yâsîn suresi Duhân suresi
fetih suresi Hucurât suresi Kâf suresi
Necm suresi Rahmân suresi vakıa suresi
Haşr suresi Mülk suresi Hâkka suresi
İnşikâk suresi Alâ suresi Gâşiye suresi

En ünlü okuyucuların sesiyle Kasas Suresi indirin:

Surah Al-Qasas mp3: yüksek kalitede dinlemek ve indirmek için okuyucuyu seçerek
Kasas Suresi Ahmed El Agamy
Ahmed El Agamy
Kasas Suresi Saad Al Ghamdi
Saad Al Ghamdi
Kasas Suresi Saud Al Shuraim
Saud Al Shuraim
Kasas Suresi Abdul Basit Abdul Samad
Abdul Basit
Kasas Suresi Abdullah Basfar
Abdullah Basfar
Kasas Suresi Abdullah Awwad Al Juhani
Abdullah Al Juhani
Kasas Suresi Ali Al Hudhaifi
Ali Al Hudhaifi
Kasas Suresi Fares Abbad
Fares Abbad
Kasas Suresi Maher Al Muaiqly
Maher Al Muaiqly
Kasas Suresi Muhammad Jibril
Muhammad Jibril
Kasas Suresi Muhammad Siddiq Al Minshawi
Al Minshawi
Kasas Suresi Al Hosary
Al Hosary
Kasas Suresi Al-afasi
Mishari Al-afasi
Kasas Suresi Nasser Al Qatami
Nasser Al Qatami
Kasas Suresi Yasser Al Dosari
Yasser Al Dosari


Wednesday, January 22, 2025

Bizim için dua et, teşekkürler