PDF —
69 Ẹsẹ Meccan PDF
Built right in your browser — download starts automatically

Surah Al-'Ankabut pdf — Gbà (Yorùbá)

Surah Al-'Ankabut pdf Yorùbá — Gbà Surah Al-'Ankabut Itumọ. Surah Al-'Ankabut (Meccan) 69 Ẹsẹ.

← Al-QasasSurah Al-'Ankabut Ar-Rum →


69 Ẹsẹ · Meccan · Yorùbá
bismillah
ﮡﮢ
29:1 ’Alif lam mim
ﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭ
29:2 Nje awon eniyan lero pe A oo fi won sile ki won maa so pe: “A gbagbo”, ti A o si nii dan won wo
ﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛ
29:3 A kuku ti dan awon t’o siwaju won wo. Nitori naa, dajudaju Allahu maa safi han awon t’o so ododo. Dajudaju O si maa safi han awon opuro
ﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧ
29:4 Abi awon t’o n se ise aburu lero pe awon maa mori bo mo Wa lowo ni? Ohun ti won n da lejo buru
ﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵ
29:5 Enikeni ti o ba n reti ipade Allahu, dajudaju akoko Allahu kuku n bo. Oun si ni Olugbo, Onimo
ﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁ
29:6 Enikeni ti o ba gbiyanju, o n gbiyanju fun emi ara re ni. Dajudaju Allahu ni Oloro ti ko bukata si gbogbo eda
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝ
29:7 Awon t’o ba gbagbo ni ododo, ti won si se ise rere, dajudaju A maa ha awon ise aburu won danu fun won. Dajudaju A o si san won lesan pelu eyi t’o dara ju ohun ti won n se
ﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵ
29:8 A pa a ni ase fun eniyan lati se daadaa si awon obi re mejeeji. Ti awon mejeeji ba si ja o logun pe ki o fi ohun ti iwo ko ni imo nipa re sebo si Mi, ma se tele awon mejeeji. Odo Mi ni ibupadasi yin. Nitori naa, Mo maa fun yin ni iro ohun ti e n se nise
ﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽ
29:9 Awon t’o ba gbagbo ni ododo, ti won si se ise rere, dajudaju A maa fi won sinu awon eni rere
ﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟ
29:10 O n be ninu awon eniyan, eni t’o n wi pe: “A gba Allahu gbo.” Nigba ti won ba si fi inira kan won ninu esin Allahu, o maa so inira eniyan da bi iya ti Allahu. Ti aranse kan lati odo Oluwa re ba si de, dajudaju won yoo wi pe: “Dajudaju awa wa pelu yin.” Se Allahu ko l’O nimo julo nipa ohun ti n be ninu igba-aya gbogbo eda ni
ﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦ
29:11 Dajudaju Allahu maa safi han awon t’o gbagbo ni ododo. O si maa safi han awon sobe-selu musulumi
ﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛ
29:12 Awon t’o sai gbagbo wi fun awon t’o gbagbo ni ododo pe: “E tele oju ona tiwa nitori ki a le ru awon ese yin.” Won ko si le ru kini kan ninu ese won. Dajudaju opuro ma ni won
ﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨ
29:13 Dajudaju won yoo ru eru ese tiwon ati awon eru ese kan mo eru ese tiwon. Ati pe dajudaju A oo bi won leere ni Ojo Ajinde nipa ohun ti won n da ni adapa iro
ﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹ
29:14 Dajudaju A ran (Anabi) Nuh nise si ijo re. O gbe laaarin won fun egberun odun afi aadota odun. Ekun-omi si gba won mu nigba ti won je alabosi
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗ
29:15 A si la oun ati awon ero inu oko oju-omi. A si se won ni ami fun gbogbo eda
ﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦ
29:16 (Ranti Anabi) ’Ibrohim. Nigba ti o so fun ijo re pe: “E josin fun Allahu. Ki e si paya Re. Iyen loore julo fun yin ti e ba mo.”
ﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄ
29:17 E kan n josin fun awon orisa leyin Allahu. E si n da adapa iro. Dajudaju awon ti e n josin fun leyin Allahu, won ko ni ikapa arisiki kan fun yin. E wa arisiki si odo Allahu. Ki e josin fun Un. Ki e si dupe fun Un. Odo Re ni won yoo da yin pada si
ﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓ
29:18 Ti e ba si pe (ododo) niro, awon ijo kan t’o siwaju yin kuku ti pe (ododo) niro. Ko si si ojuse kan fun Ojise bi ko se ise-jije ponnbele
ﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢ
29:19 Tabi won ko ri bi Allahu ti se bere eda ni? Leyin naa, O maa da a pada (si odo Re). Dajudaju iyen rorun fun Allahu
ﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙ
29:20 So pe: “E rin kiri lori ile, ki e wo bi O se bere eda (ni ipile). Leyin naa, Allahu l’O maa mu iseda ikeyin wa (fun ajinde). Dajudaju Allahu ni Alagbara lori gbogbo nnkan.”
ﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣ
29:21 O n je eni ti O ba fe niya. O si n ke eni ti O ba fe. Odo Re si ni won yoo da yin pada si. o je ohun ti Allahu fe bee fun eda naa ninu kadara re nitori pe tibi-tire ni kadara eda. Fifebee yii ni a n pe ni ""mosi’atu-llahi al-kaoniyyah"" “fifebee Allahu taye”. Bi apeere lagbaja fe di olowo lona eto o je ohun ti Allahu fe bee fun eda ninu ofin ati ilana Re. Allahu ko si nii fe ofin ati ilana kan bee ninu Tira Re t’o sokale fun wa afi ki o je rere ponnbele tabi ki rere re tewon ju aburu re lo. Fifebee yii ni a n pe ni ""mosi’atu-llahi as-ser‘iyyah"" “fifebee Allahu tofin”. Bi apeere lagbaja fe di musulumi mejeeji l’o duro sori “ ‘adl” ati “ fodl” – deede ati ola. Alaye eyi ni pe ti iya ba je lagbaja nile aye tabi ni orun lai je onigbagbo ododo enu eni keni ko gba a lati fi esun kan Allahu lori fifebee Re lori eda re. Sebi nile aye yii gan-an
ﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶ
29:22 Ati pe eyin ko nii mori bo mo Allahu lowo lori ile ati ninu sanmo. Ko si si alaabo ati alaranse kan fun yin leyin Allahu
ﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄ
29:23 Awon t’o sai gbagbo ninu awon ayah Allahu ati ipade Re (lorun), awon wonyen ti soreti nu ninu ike Mi. Awon wonyen ni iya eleta-elero n be fun
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦ
29:24 Esi ijo re ko je kini kan tayo pe won wi pe: “E pa a tabi ki e sun un nina.” Allahu si la a ninu ina. Dajudaju awon ami kuku wa ninu iyen fun ijo t’o gbagbo lododo
ﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃ
29:25 O si so pe: “E kan mu awon orisa leyin Allahu, ni ohun ti e nifee si (lati josin fun) laaarin ara yin ninu isemi aye (yii). Leyin naa, ni Ojo Ajinde apa kan yin yoo tako apa kan. Apa kan yin yo si sebi le apa kan. Ina si ni ibugbe yin. Ko si nii si awon alaranse kan fun yin.”
ﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓ
29:26 (Anabi) Lut si gba a gbo. (Anabi ’Ibrohim) so pe: “Dajudaju emi yoo fi ilu yii sile nitori ti Oluwa mi. Dajudaju Oun ni Alagbara, Ologbon
ﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧ
29:27 A fi ’Ishaƙ ati Ya‘ƙub (omoomo re) ta a lore. A si se jije Anabi ati fifunni ni tira sinu aromodomo re. A fun un ni esan re ni aye yii. Dajudaju ni orun, o tun wa ninu awon eni rere
ﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗ
29:28 (Ranti Anabi) Lut. Nigba ti o so fun ijo re pe: “Dajudaju eyin n se ibaje ti ko si eni kan ninu eda ti o se e ri siwaju yin
ﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰ
29:29 Se dajudaju eyin (okunrin) yoo maa to awon okunrin (egbe yin) lo (fun adun ibalopo), e tun n dana, e tun n se ohun buruku ninu akojo yin? Esi ijo re ko je kini kan afi ki won wi pe : “Mu iya Allahu wa fun wa ti o ba wa ninu awon olododo.”
ﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷ
29:30 O so pe: “Oluwa mi, saranse fun mi lori ijo obileje.”
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡ
29:31 Nigba ti awon Ojise Wa si mu iro idunnu de ba (Anabi) ’Ibrohim, won so pe: “Dajudaju awa maa pa awon ara ilu yii run. Dajudaju awon ara ilu naa je alabosi.”
ﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴ
29:32 O so pe: “Dajudaju (Anabi) Lut wa nibe! Won so pe: “Awa nimo julo nipa awon t’o wa nibe. Dajudaju awa yoo la oun ati awon ara ile re afi iyawo re ti o maa wa ninu awon t’o maa seku leyin sinu iparun.”
ﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍ
29:33 Nigba ti awon Ojise Wa de odo (Anabi) Lut, o banuje nitori won. Agbara re ko si ka oro won mo. Won si so fun un pe: “Ma beru, ma si se banuje. Dajudaju a maa la iwo ati awon ara ile re afi iyawo re ti o maa wa ninu awon oluseku-leyin sinu iparun.”
ﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚ
29:34 Dajudaju a maa so iya kan kale le awon ara ilu yii lori lati inu sanmo nitori pe won je obileje
ﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢ
29:35 Dajudaju A ti fi ami kan t’o foju han lele ninu re fun ijo t’o ni laakaye
ﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔ
29:36 A tun ranse si ara ilu Modyan. (A ran) arakunrin won, (Anabi) Su‘aeb (nise si won). O si so pe: “Eyin ijo mi, e josin fun Allahu. E reti Ojo Ikeyin, ki e si ma sebaje lori ile ni ti obileje.”
ﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜ
29:37 Won pe e ni opuro. Nitori naa, ohun igbe lile t’o mi ile titi gba won mu. Won si di eni t’o da lule, ti won ti doku sinu ilu won
ﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮ
29:38 (A tun ranse si awon) ara ‘Ad ati ara Thamud. (Iparun won) si kuku ti foju han kedere si yin ninu awon ibugbe won. Esu se awon ise won ni oso fun won. O si seri won kuro ninu esin (Allahu). Won si je oluriran (nipa oro aye)
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟ
29:39 (A tun ranse si awon) Ƙorun, Fir‘aon ati Hamon. Dajudaju (Anabi) Musa mu awon eri t’o yanju wa ba won. Won si segberaga lori ile. Won ko si le mori bo ninu iya
ﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾ
29:40 A si mu ikookan won nipa ese re. O wa ninu won, eni ti A fi okuta ina ranse si. O wa ninu won eni ti igbe lile gba mu. O wa ninu won eni ti A je ki ile gbemi. O si wa ninu won eni ti A teri sinu omi. Allahu ko si nii sabosi si won, sugbon emi ara won ni won n sabosi si
ﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔ
29:41 Apejuwe awon t’o mu awon (orisa) ni alatileyin leyin Allahu, o da bi apejuwe alantaakun ti o ko ile kan. Dajudaju ile ti o yepere julo ni ile alantaakun, ti won ba mo
ﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢ
29:42 Dajudaju Allahu mo ohunkohun ti won n pe leyin Re. Oun si ni Alagbara, Ologbon
ﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬ
29:43 Awon akawe wonyi, ti A n fun awon eniyan, ko si si eni ti o maa se laakaye nipa re afi awon onimo
ﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙ
29:44 Allahu seda awon sanmo ati ile pelu ododo. Dajudaju ami kan wa ninu iyen fun awon onigbagbo ododo
ﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲ
29:45 Ke ohun ti A fi ranse si o ninu Tira. Ki o si kirun. Dajudaju irun kiki n ko iwa ibaje ati aburu. Ati pe iranti Allahu tobi julo. Allahu si mo ohun ti e n se. bi irun kiki se ni esan bee naa lo tun je ohun t’o n mu olukirun jinna si iwa aburu aawe gbigba ati bee bee lo. Enikeni ti o ba pa irun kiki ati aawe gbigba ti nipase fifun gbolohun yii ni itumo odi o ti ko iparun ba emi ara re ni ibamu si surah al-Muddaththir; 74: 42-43. Ki Allahu (subhanahu wa ta’ala) la wa ninu eyi
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬ
29:46 E ma se ba ahlul-kitab sariyan jiyan afi ni ona t’o dara julo (eyi ni lilo al-Ƙur’an ati hadith. E ma si se ja won logun) afi awon t’o ba sabosi ninu won. Ki e si so pe: “A gbagbo ninu ohun ti Won sokale fun awa ati ohun ti Won sokale fun eyin. Olohun wa ati Olohun yin, (Allahu) Okan soso ni. Awa si ni musulumi (olujuwo-juse-sile) fun Un.”
ﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃ
29:47 Bayen ni A se so Tira kale fun o. Nitori naa, awon ti A fun ni Tira, won gba a gbo. O si wa ninu awon wonyi (iyen, awon ara Mokkah), eni t’o gba a gbo. Ko si si eni t’o n tako awon ayah Wa afi awon alaigbagbo
ﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒ
29:48 Iwo ko ke tira kan ri siwaju al-Ƙur’an, iwo ko si fi owo otun re ko nnkan ri. Bi bee ko nigba naa, ki awon opuro seyemeji (si al-Ƙur’an)
ﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢ
29:49 Rara (ko ri bi won se ro o. al-Ƙur’an), ohun ni awon ayah t’o yanju ninu igba-aya awon ti A fun ni imo-esin. Ko si si eni t’o n tako awon ayah Wa afi awon alabosi
ﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕ
29:50 Won si wi pe: “Nitori ki ni Won ko se so awon ami (iyanu) kan kale fun un lati odo Oluwa re?” So pe: “Allahu nikan ni awon ami (iyanu) wa lodo Re. Ati pe olukilo ponnbele ni emi.”
ﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦ
29:51 Se ko to fun won (ni ami iyanu) pe A so tira (al-Ƙur’an) kale fun o, ti won n ke e fun won? Dajudaju ike ati isiti wa ninu iyen fun ijo t’o gbagbo
ﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼ
29:52 So pe: “Allahu to ni Elerii laaarin emi ati eyin. O mo ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ile. Awon t’o gba iro gbo, ti won si sai gbagbo ninu Allahu; awon wonyen, awon ni eni ofo
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞ
29:53 Won si n kan o loju nipa iya! Ti ko ba je pe o ti ni gbedeke akoko kan ni, iya naa iba kuku de ba won. (Iya) iba de ba won ni ojiji se, won ko si nii fura
ﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥ
29:54 Won n kan o loju nipa iya! Dajudaju ina Jahanamo kuku maa yi awon alaigbagbo po
ﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳ
29:55 (Ranti) ojo ti iya yoo bo won mole lati oke won ati isale ese won, (Allahu) si maa so pe: “E to (iya) ohun ti e n se nise wo.”
ﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼ
29:56 Eyin erusin Mi, ti e gbagbo ni ododo, dajudaju ile Mi gbooro. Nitori naa, Emi nikan ni ki e josin fun
ﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅ
29:57 Gbogbo emi l’o maa to iku wo. Leyin naa, odo Wa ni won yoo da yin pada si
ﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘ
29:58 Awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere, dajudaju A maa fi won sinu awon ile peteesi giga kan ninu Ogba Idera, ti odo n san ni isale re. Olusegbere ni won ninu re. Esan awon oluse-rere si dara
ﮙﮚﮛﮜﮝﮞ
29:59 (Awon ni) awon t’o se suuru. Oluwa won si ni won n gbarale
ﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬ
29:60 Meloo meloo ninu awon eranko ti ko le da bukata ije-imu re gbe, ti Allahu si n se ije-imu fun awon ati eyin. Oun si ni Olugbo, Onimo
ﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜ
29:61 Ti o ba bi won leere pe: “Ta ni O da awon sanmo ati ile, ti O si ro oorun ati osupa?”, dajudaju won a wi pe: “Allahu ni.” Nitori naa, bawo ni won se n seri won kuro nibi ododo
ﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬ
29:62 Allahu l’O n te oro sile fun eni ti O ba fe ninu awon erusin Re. O si n diwon re fun elomiiran. Dajudaju Allahu ni Onimo nipa gbogbo nnkan
ﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅ
29:63 Ti o ba bi won leere pe: “Ta ni O so omi kale lati sanmo, ti O fi ta ile ji leyin ti o ti ku?”, dajudaju won a wi pe: “Allahu ni.” So pe: “Gbogbo ope n je ti Allahu, sugbon opolopo won ni ko se laakaye.”
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢ
29:64 Ki ni isemi aye yii bi ko se iranu ati ere sise. Ati pe dajudaju Ile Ikeyin si ni isemi gbere ti won ba mo
ﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳ
29:65 Nigba ti won ba gun oko oju-omi, won yoo pe Allahu (gege bi) olusafomo-adua fun Un. Amo nigba ti O ba ko won yo si ori ile, nigba naa ni won yoo maa sebo
ﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻ
29:66 nitori ki won le sai moore si nnkan ti A fun won ati nitori ki won le jayekaye. Nitori naa, laipe won maa mo
ﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌ
29:67 Se won ko ri i pe dajudaju Awa se Haram (Mokkah) ni aye ifayabale, ti won si n ji awon eniyan gbe lo ni ayika won? Se iro ni won yoo gbagbo, ti won yo si sai moore si idera Allahu
ﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟ
29:68 Ta l’o sabosi ju eni t’o da adapa iro mo Allahu, tabi t’o pe ododo ni iro nigba ti o de ba a? Se inu ina Jahanamo ko ni ibugbe fun awon alaigbagbo ni
ﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪ
29:69 Awon t’o gbiyanju nipa Wa, dajudaju A maa fi won mo awon ona Wa. Ati pe dajudaju Allahu wa pelu awon oluse-rere

Al-Kur'an


Wednesday, September 9, 2026

Don't forget us in your sincere prayers