PDF —
96 Ẹsẹ Meccan PDF
Built right in your browser — download starts automatically

Surah Al-Waqi'ah pdf — Gbà (Yorùbá)

Surah Al-Waqi'ah pdf Yorùbá — Gbà Surah Al-Waqi'ah Itumọ. Surah Al-Waqi'ah (Meccan) 96 Ẹsẹ.

← Ar-RahmanSurah Al-Waqi'ah Al-Hadid →


96 Ẹsẹ · Meccan · Yorùbá
bismillah
ﮃﮄﮅﮆ
56:1 Nigba ti Isele (Ajinde) ba sele
ﮇﮈﮉﮊ
56:2 ko si iro kan nipa isele re-E
ﮋﮌﮍ
56:3 o maa mu (awon kan) wale (sinu Ina), o si maa gbe (awon kan) soke (ninu Ogba Idera)
ﮎﮏﮐﮑﮒ
56:4 Nigba ti won ba mi ile titi ni mimititi
ﮓﮔﮕﮖ
56:5 ati nigba ti Won ba fo awon apata ni fifo womuwomu
ﮗﮘﮙﮚ
56:6 won si maa di eruku afedanu - E
ﮛﮜﮝﮞ
56:7 eyin si maa je orisi meta
ﮟﮠﮡﮢﮣﮤ
56:8 ijo osi ati ijo asiwaju. Amo ninu surah al-Balad; 90:18-19 ati surah az-Zalzalah; 99:6-8 Allahu (subhanahu wa ta’ala) pin won si ijo meji. Ijo meji kuku ni gbogbo eda ni orun 8 Awon ero owo otun, ki ni (o maa ti dara to fun) awon ero owo otun
ﮥﮦﮧﮨﮩﮪ
56:9 Awon ero owo osi, ki ni (o maa ti buru to fun) awon ero owo osi
ﮫﮬﮭ
56:10 Awon asiwaju si ni awon asiwaju
ﮮﮯﮰ
56:11 Awon wonyen ni alasun-unmo (Allahu)
ﮱﯓﯔﯕ
56:12 ninu Ogba Idera
ﯖﯗﯘﯙ
56:13 Won po ninu awon eni akoko
ﯚﯛﯜﯝ
56:14 Won si kere ninu awon eni Ikeyin
ﯞﯟﯠﯡ
56:15 (Won yoo wa) lori ite ti won fi goolu hun
ﯢﯣﯤﯥ
56:16 Won yoo rogboku sori re, won si maa doju kora won
ﭑﭒﭓﭔﭕ
56:17 Awon odokunrin ti ko nii darugbo yo si maa lo bo laaarin won
ﭖﭗﭘﭙﭚﭛ
56:18 pelu awon ife omi, ohun iromi fenfe ati ife oti aladun
ﭜﭝﭞﭟﭠﭡ
56:19 Ko nii fo won lori; ko si nii mu won hunrira
ﭢﭣﭤﭥ
56:20 Eso ti won yoo maa sesa ninu re (tun wa fun won)
ﭦﭧﭨﭩﭪ
56:21 Ati eran eye, eyi ti won n fe (yo wa fun won)
ﭫﭬﭭ
56:22 Awon obinrin eleyinju ege (tun wa fun won)
ﭮﭯﭰﭱ
56:23 Won da bi okuta olowo-iyebiye ti won fi pamo
ﭲﭳﭴﭵﭶ
56:24 (Iwonyi ni) esan fun ohun ti won n se nise
ﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽ
56:25 Won ko nii gbo isokuso ati oro ese ninu Ogba Idera
ﭾﭿﮀﮁﮂ
56:26 Ayafi oro alaafia, alaafia
ﮃﮄﮅﮆﮇﮈ
56:27 Awon ero owo otun, ki ni (o maa ti dara to fun) awon ero owo otun
ﮉﮊﮋﮌ
56:28 (Won yoo wa) ni idi igi ti ko ni egun
ﮍﮎﮏ
56:29 ati ogede t’o so jigbinni
ﮐﮑﮒ
56:30 ati iboji t’o gbooro
ﮓﮔﮕ
56:31 ati omi t’o n san lai dawo duro
ﮖﮗﮘ
56:32 ati opolopo eso
ﮙﮚﮛﮜﮝ
56:33 ti ko nii ja (ni odo won), ko si nii deewo (fun won)
ﮞﮟﮠ
56:34 (Won maa wa lori) ite ti won gbe soke
ﮡﮢﮣﮤ
56:35 Dajudaju Awa tun (awon obinrin won) da ni eda otun
ﮥﮦﮧ
56:36 A si se won ni wundia
ﮨﮩﮪ
56:37 ololufe oko. Won si dogba ni ojo ori
ﮫﮬﮭ
56:38 (Won wa) fun awon ero owo otun
ﮮﮯﮰﮱ
56:39 Won po ninu awon eni akoko
ﯓﯔﯕﯖ
56:40 Won tun po ninu awon eni Ikeyin
ﯗﯘﯙﯚﯛﯜ
56:41 Awon ero owo osi, ki ni (o maa ti buru to fun) awon ero owo osi
ﯝﯞﯟﯠ
56:42 (Won yoo wa) ninu ategun gbigbona ati omi gbigbona
ﯡﯢﯣﯤ
56:43 ati ni abe iboji eleeefin dudu
ﯥﯦﯧﯨﯩ
56:44 ko tutu, ko si dara
ﯪﯫﯬﯭﯮﯯ
56:45 Dajudaju won ti je onigbedemuke siwaju iyen
ﯰﯱﯲﯳﯴﯵ
56:46 Won si maa n sorikunkun lori ese nla
ﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿ
56:47 Won si maa n wi pe: "Se nigba ti a ba di oku, ti a si di erupe ati egungun, nje Won yoo tun gbe wa dide ni
ﰀﰁﰂ
56:48 Se ati awon baba wa, awon eni akoko
ﰃﰄﰅﰆﰇ
56:49 So pe: "Dajudaju awon eni akoko ati awon eni Ikeyin
ﰈﰉﰊﰋﰌﰍ
56:50 dajudaju A oo ko won jo papo ni akoko ojo kan ti A ti mo
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖ
56:51 Leyin naa, dajudaju eyin olusina, olupe-ododo-niro
ﭗﭘﭙﭚﭛﭜ
56:52 dajudaju eyin maa je ninu igi zaƙƙum (igi iwo)
ﭝﭞﭟﭠ
56:53 Ikun yin si maa kun bamubamu fun (jije) igi naa
ﭡﭢﭣﭤﭥ
56:54 Eyin yo si maa mu omi gbigbona le e lori
ﭦﭧﭨﭩ
56:55 Eyin yoo maa mu un ni imumi rakunmi ti ongbe n gbe
ﭪﭫﭬﭭﭮ
56:56 Eyi ni nnkan alejo won ni Ojo esan
ﭯﭰﭱﭲﭳ
56:57 Awa l’A seda yin. Ki ni ko je ki e gbagbo lododo
ﭴﭵﭶﭷ
56:58 E so fun Mi nipa ato ti e n da jade (sinu apoluke)
ﭸﭹﭺﭻﭼﭽ
56:59 se eyin le seda re ni tabi Awa l’A seda re
ﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅ
56:60 Awa l’A yan kadara (ojo) iku fun gbogbo yin. Awa ko si le kagara
ﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏ
56:61 lati fi iru yin paaro yin, ki a si tun yin da sinu ohun ti e ko mo
ﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖ
56:62 E kuku mo iseda akoko, e o se lo iranti
ﮗﮘﮙﮚ
56:63 E so fun Mi nipa nnkan ti e n gbin sinu ile
ﮛﮜﮝﮞﮟﮠ
56:64 se eyin l’e n je ki o hu jade ni tabi Awa l’A n je ki o hu jade
ﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧ
56:65 Ti A ba fe ni, Awa iba so o di gbigbe, eyin yo si maa seemo (ti e oo maa ka abamo)
ﮨﮩﮪ
56:66 (Eyin yo si wi pe:) "Dajudaju awa ti di onigbese
ﮫﮬﮭﮮ
56:67 (Awon miiran yo si wi pe:) "Rara o! Won se ikore oko ni eewo fun wa ni
ﮯﮰﮱﯓﯔ
56:68 E so fun mi nipa omi ti e n mu
ﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜ
56:69 se eyin l’e n so o kale lati inu esujo ni tabi Awa l’A n so o kale
ﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣ
56:70 Ti A ba fe ni, Awa iba se e ni omi t’o moro. E o se maa dupe
ﯤﯥﯦﯧﯨ
56:71 E so fun Mi nipa ina ti e n da
ﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯ
56:72 se eyin l’e seda igi re ni tabi Awa ni Aseda
ﯰﯱﯲﯳﯴﯵ
56:73 Awa se ina aye ni iranti (fun Ina orun) ati nnkan elo fun awon onirin-ajo
ﯶﯷﯸﯹﯺ
56:74 Nitori naa, safomo fun oruko Oluwa re, Atobi
ﯻﯼﯽﯾﯿﰀ
56:75 Mo n bura pelu awon ibuso irawo
ﰁﰂﰃﰄﰅﰆ
56:76 Dajudaju ibura nla ni, ti e ba mo
ﭑﭒﭓﭔ
56:77 Dajudaju (al-Ƙur’an) ni nnkan kike alapon-onle
ﭕﭖﭗﭘ
56:78 (t’o wa) ninu Tira aabo (ninu Laohul-Mahfuth)
ﭙﭚﭛﭜﭝ
56:79 Ko si eni to le fowo kan an (ni odo Allahu) afi awon eni mimo (iyen, awon molaika)
ﭞﭟﭠﭡﭢ
56:80 Won so al-Ƙur’an kale lati odo Oluwa gbogbo eda
ﭣﭤﭥﭦﭧ
56:81 Nitori naa, se oro (al-Ƙur’an) yii l’e n pe niro
ﭨﭩﭪﭫﭬ
56:82 E si n so idupe arisiki yin di pe dajudaju e n pe ododo niro
ﭭﭮﭯﭰﭱ
56:83 Ki ni o maa ti ri (fun yin) nigba ti emi (yin) ba de ona ofun
ﭲﭳﭴﭵ
56:84 ti eyin yo si maa woran nigba yen
ﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽ
56:85 Awa si sunmo on ju eyin lo, sugbon eyin ko riran
ﭾﭿﮀﮁﮂﮃ
56:86 Eyin ko se je eni ti A o nii gbesan lara re
ﮄﮅﮆﮇﮈ
56:87 ki e si da (emi ti o fe bo) pada, ti e ba je olododo
ﮉﮊﮋﮌﮍﮎ
56:88 Ni ti eni ti o ba wa ninu awon alasun-unmo (Wa)
ﮏﮐﮑﮒﮓ
56:89 isinmi, ese t’o dara ati Ogba Idera (ni tire)
ﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚ
56:90 Ni ti eni ti o ba wa ninu awon ero owo otun
ﮛﮜﮝﮞﮟﮠ
56:91 alaafia ni fun o laaarin awon ero owo otun
ﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧ
56:92 Ni ti eni ti o ba wa ninu awon olupe-ododo-niro, awon olusina
ﮨﮩﮪﮫ
56:93 nnkan alejo (won) ni omi gbigbona
ﮬﮭﮮ
56:94 ati wiwo inu ina Jehim
ﮯﮰﮱﯓﯔﯕ
56:95 Dajudaju eyi, ohun ni ododo t’o daju
ﯖﯗﯘﯙﯚ
56:96 Nitori naa, safomo fun oruko Oluwa re, Atobi

Al-Kur'an


Wednesday, September 9, 2026

Don't forget us in your sincere prayers