Surah Al-Hijr pdf — Gbà (Yorùbá)
Surah Al-Hijr pdf Yorùbá — Gbà Surah Al-Hijr Itumọ. Surah Al-Hijr (Meccan) 99 Ẹsẹ.
Related
- Surah Al-Hijr ItumọYorùbá
- Surah Al-Hijr mp3Gbọ
- Quran Index Yorùbá114
More Surah PDF
Surah Al-Hijr

ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘ
15:1
’Alif lam ro. Iwonyi ni awon ayah Tira naa ati (awon ayah) al-Ƙur’an t’o n yanju oro eda
ﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠ
15:2
O see se ki awon t’o sai gbagbo nifee si pe awon iba si ti je musulumi (nile aye)
ﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩ
15:3
Fi won sile, ki won je, ki won gbadun, ki ireti (emi gigun) ko airoju raaye ba won (lati sesin); laipe won maa mo
ﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲ
15:4
A ko pa ilu kan run ri afi ki o ni akosile ti A ti mo
ﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺ
15:5
Ko si ijo kan (ti o parun) siwaju akoko re (ninu Laohul-Mahfuuth); won ko si nii sun un siwaju fun won
ﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃ
15:6
Won wi pe: “Iwo ti Won so al-Ƙur’an kale fun, dajudaju were ni e
ﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌ
15:7
Ki ni ko je ki iwo mu awon molaika wa ba wa, ti iwo ba wa ninu awon olododo?”
ﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖ
15:8
A o nii so molaika kale bi ko se pelu ododo. Won ko si nii lo won lara mo nigba naa (ti awon molaika ba sokale)
ﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞ
15:9
Dajudaju Awa l’A so Tira Iranti kale (iyen al-Ƙur’an). Dajudaju Awa si ni Oluso re
ﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦ
15:10
Dajudaju siwaju re A ti ran (awon Ojise) nise si awon ijo, awon eni akoko
ﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯ
15:11
Ojise kan ko si nii de ba won afi ki won fi se yeye
ﮰﮱﯓﯔﯕﯖ
15:12
Bayen ni A se n fi (aisan) sinu okan awon elese
ﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞ
15:13
Won ko nii gba Anabi (sollalahu alayhi wa sallam) gbo; ise (Allahu lori) awon eni akoko kuku ti re koja
ﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨ
15:14
Ti o ba je pe A si ilekun kan sile fun won lati inu sanmo, ti won ko si ye gbabe gunke lo (sinu sanmo)
ﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱ
15:15
dajudaju won a wi pe: “Won kuku lo isiju fun wa ni. Nse ni won n dan wa.”
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘ
15:16
A kuku fi awon ibuso (irawo) sinu sanmo (aye). A si se e ni oso fun awon oluworan
ﭙﭚﭛﭜﭝﭞ
15:17
A si fi aabo bo imisi sanmo lodo gbogbo esu, eni eko
ﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦ
15:18
Afi (esu) ti o ba ji oro gbo. Nigba naa si ni ogunna ponnbele yo tele e lati eyin
ﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲ
15:19
Ile, A te e perese. A si ju awon apata t’o duro gbagidi sinu re. A si mu gbogbo nnkan ti o ni odiwon hu jade lati inu re
ﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻ
15:20
A se ona ije-imu sinu (ile aye) fun eyin ati awon ti eyin ko le pese fun
ﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇ
15:21
Ko si si kini kan afi ki ile-oro re wa lodo Wa. Awa ko si nii so o kale afi pelu odiwon ti A ti mo
ﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔ
15:22
Ati pe A ran ategun lati ko esujo jo. A si so omi kale lati sanmo. Nitori naa, A fun yin mu. Eyin si ko ni e ko omi ojo jo (soju sanmo)
ﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛ
15:23
Dajudaju Awa, Awa ma l’A n so (eda) di alaaye. A si n so o di oku. Awa si ni A oo jogun (eda)
ﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣ
15:24
Ati pe dajudaju A mo awon olugbawaju ninu yin. Dajudaju A si mo awon olugbeyin
ﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬ
15:25
Dajudaju Oluwa re, Oun l’O maa ko won jo. Dajudaju Oun ni Ologbon, Onimo
ﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖ
15:26
Dajudaju A seda eniyan lati ara amo t’o n dun koko, t’o ti pawoda
ﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞ
15:27
Ati pe alujannu, A seda re siwaju (eniyan) lati ara ina alategun gbigbona ti ko ni eefin
ﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫ
15:28
(Ranti) nigba ti Oluwa re so fun awon molaika pe: “Dajudaju Emi yoo se eda abara kan lati ara amo t’o n dun koko, t’o ti pawoda
ﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵ
15:29
Nigba ti Mo ba se e t’o gun rege tan, ti Mo fe emi si i (lara) ninu emi Mi (ti Mo da), nigba naa e doju bole fun un ni oluforikanle-kini
ﯶﯷﯸﯹﯺ
15:30
Nitori naa, awon molaika, gbogbo won patapata si fori kanle ki i
ﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂ
15:31
Ayafi ’Iblis. O ko lati wa ninu awon oluforikanle naa
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙ
15:32
(Allahu) so pe: "’Iblis, ki l’o di o lowo lati wa ninu awon oluforikanle
ﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥ
15:33
O wi pe: "Emi ko nii fori kanle ki abara kan ti O seda re lati ara amo t’o n dun koko, t’o ti pawoda
ﭦﭧﭨﭩﭪﭫ
15:34
(Allahu) so pe: "Nitori naa, jade kuro ninu re. Dajudaju, iwo ni eni-eko
ﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲ
15:35
Ati pe, dajudaju egun n be lori re titi di Ojo esan
ﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹ
15:36
O wi pe: “Oluwa mi, lo mi lara titi di Ojo Ajinde.”
ﭺﭻﭼﭽﭾ
15:37
(Allahu) so pe: "Dajudaju iwo wa lara awon ti A oo lo lara
ﭿﮀﮁﮂﮃ
15:38
titi di ojo akoko ti A ti mo
ﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎ
15:39
O wi pe: "Oluwa mi, fun wi pe O ti se mi ni eni anu, dajudaju emi yoo se (aburu) ni oso fun won lori ile. Dajudaju emi yo si ko gbogbo won sinu anu
ﮏﮐﮑﮒﮓ
15:40
afi awon erusin Re, awon eni esa ninu won
ﮔﮕﮖﮗﮘﮙ
15:41
(Allahu) so pe: "(Idurosinsin loju) ona taara, Owo Mi ni eyi wa
ﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥ
15:42
Dajudaju awon erusin Mi, ko si agbara kan fun o lori won, ayafi eni ti o ba tele o ninu awon eni anu
ﮦﮧﮨﮩﮪ
15:43
Ati pe dajudaju ina Jahanamo ni adehun fun gbogbo won
ﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔ
15:44
Awon oju ona meje n be fun (ina). Atunpin tun wa fun oju-ona kookan
ﯕﯖﯗﯘﯙﯚ
15:45
Dajudaju awon oluberu (Allahu) maa wa ninu awon Ogba Idera pelu awon odo (t’o n san nisale re)
ﯛﯜﯝﯞ
15:46
(A maa so pe): “E wo inu re pelu alaafia ni olufayabale.”
ﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩ
15:47
A si maa yo ohun ti n be ninu okan won t’o je inunibini kuro; (won yoo di) omo-iya (ara won. Won yoo wa) lori ibusun, ti won yoo koju sira won
ﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲ
15:48
Wahala kan ko nii ba won ninu re. Won ko si nii mu won jade kuro ninu re
ﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺ
15:49
Fun awon erusin Mi ni iro pe dajudaju Emi ni Alaforijin, Asake-orun
ﯻﯼﯽﯾﯿﰀ
15:50
Ati pe dajudaju iya Mi ni iya eleta-elero
ﰁﰂﰃﰄﰅ
15:51
Fun won ni iro nipa alejo (Anabi) ’Ibrohim
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚ
15:52
(Ranti) nigba ti won wole to o, won si so pe: “Alaafia”. O so pe: “Dajudaju eru yin n ba awa.”
ﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢ
15:53
Won so pe: "Ma se beru. Dajudaju awa yoo fun o ni iro idunnu (nipa bibi) omokunrin onimimo kan
ﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫ
15:54
O so pe: "Se e n fun mi ni iro idunnu (nipa bibi omo) nigba ti ogbo ti de si mi? Iro idunnu wo ni e n fun mi na
ﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳ
15:55
Won so pe: “A n fun o ni iro idunnu pelu ododo. Nitori naa, ma se wa lara awon olujakanmuna.”
ﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼ
15:56
O so pe: “Ko ma si eni ti o maa jakanmuna ninu ike Oluwa Re bi ko se awon olusina.”
ﭽﭾﭿﮀﮁﮂ
15:57
O so pe: “Ki tun ni oro ti e ba wa, eyin Ojise?”
ﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉ
15:58
Won so pe: "Dajudaju Won ran wa nise si ijo elese ni
ﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐ
15:59
Afi ara ile (Anabi) Lut. Dajudaju awa yoo gba won la patapata
ﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗ
15:60
Afi iyawo re; A ti ko kadara re (pe) dajudaju o maa wa ninu awon t’o maa seku leyin sinu iparun
ﮘﮙﮚﮛﮜﮝ
15:61
Nigba ti awon Ojise de odo ara ile (Anabi) Lut
ﮞﮟﮠﮡﮢ
15:62
(Anabi Lut) so pe: “Dajudaju eyin je ajoji eniyan.”
ﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪ
15:63
Won so pe: “Rara, a wa sodo re nitori ohun ti won n seyemeji nipa re
ﮫﮬﮭﮮﮯ
15:64
A mu ododo wa ba o ni. Ati pe dajudaju olododo ni awa
ﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟ
15:65
Nitori naa, mu ara ile re jade ni apa kan oru. Ki o si tele won leyin. Eni kan ninu yin ko si gbodo siju wo eyin wo. Ki e si lo si aye ti won n pa lase fun yin
ﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩ
15:66
A si je ki idajo oro yii han si i pe dajudaju A maa pa awon (elese) wonyi run patapata nigba ti won ba mojumo
ﯪﯫﯬﯭﯮ
15:67
Awon ara ilu naa de, won si n yo sese
ﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵ
15:68
(Anabi Lut) so pe: “Dajudaju awon wonyi ni alejo mi. Nitori naa, e ma se doju ti mi
ﯶﯷﯸﯹﯺ
15:69
Ki e beru Allahu. Ki e si ma se yepere mi
ﯻﯼﯽﯾﯿﰀ
15:70
Won wi pe: “Nje awa ko ti ko fun o (nipa gbigba alejo) awon eda?”
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗ
15:71
O so pe: “Awon omobinrin mi niwonyi, ti e ba ni nnkan ti e fe (fi won) se.”
ﭘﭙﭚﭛﭜﭝ
15:72
(Allahu so pe): “Mo fi isemi iwo (Anabi Muhammad) bura; dajudaju won kuku wa ninu idaamu opolo, ti won n pa ridarida.”
ﭞﭟﭠﭡ
15:73
Nitori naa, ohun igbe mu won nigba ti oorun owuro yo si won
ﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪ
15:74
A si so oke ilu won di isale re (ilu won doju bole). A tun ro ojo okuta amo (sisun) le won lori
ﭫﭬﭭﭮﭯﭰ
15:75
Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun awon alariiwoye
ﭱﭲﭳﭴ
15:76
Dajudaju (ilu naa) kuku wa loju ona (ti e n to lo to bo)
ﭵﭶﭷﭸﭹﭺ
15:77
Dajudaju ami wa ninu iyen fun awon onigbagbo ododo
ﭻﭼﭽﭾﭿﮀ
15:78
Awon ara ’Aekah naa je alabosi
ﮁﮂﮃﮄﮅﮆ
15:79
A si gbesan lara won. Dajujaju awon ilu mejeeji l’o kuku wa loju ona gbangba (ti e n to lo to bo)
ﮇﮈﮉﮊﮋﮌ
15:80
Dajudaju awon ara Iho apata pe awon Ojise ni opuro
ﮍﮎﮏﮐﮑﮒ
15:81
A si fun won ni awon ami Wa. Amo won gbunri kuro nibe
ﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙ
15:82
Won maa n gbe awon ile igbe ifayabale sinu awon apata
ﮚﮛﮜﮝ
15:83
Ohun igbe si mu won nigba ti won mojumo
ﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤ
15:84
Ohun ti won n se nise ko si ro won loro (nibi iya)
ﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖ
15:85
A ko seda awon sanmo, ile ati nnkan t’o wa laaarin awon mejeeji bi ko se pelu ododo. Dajudaju Akoko naa maa de. Nitori naa, samojukuro ni amojukuro t’o rewa
ﯗﯘﯙﯚﯛﯜ
15:86
Dajudaju Oluwa re ni Eledaa, Onimo
ﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤ
15:87
Dajudaju A fun o ni Sab‘u Mothani (iyen, surah al-Fatihah) ati al-Ƙur’an t’o tobi
ﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴ
15:88
Iwo ko gbodo siju re wo ohun ti A fi se igbadun aye lorisirisi fun awon kan ninu won. Ma se banuje nitori won. Ki o si re apa re nile fun awon onigbagbo ododo
ﯵﯶﯷﯸﯹﯺ
15:89
Ki o si so pe: “Dajudaju emi ni olukilo ponnbele.”
ﯻﯼﯽﯾﯿ
15:90
Gege bi A se so (iya) kale fun awon t’o n pin ododo mo iro
ﭑﭒﭓﭔﭕ
15:91
awon ti won so al-Ƙur’an di ipinkupin-in
ﭖﭗﭘﭙ
15:92
Oluwa re fi Ara Re bura fun o pe, A maa bi gbogbo won ni ibeere
ﭚﭛﭜﭝ
15:93
nipa ohun ti won n se nise
ﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤ
15:94
Nitori naa, kede nnkan ti A pa lase fun o. Ki o si seri kuro lodo awon osebo
ﭥﭦﭧﭨ
15:95
Dajudaju Awa yoo to o (nibi aburu) awon oniyeye
ﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲ
15:96
awon t’o n mu olohun miiran mo Allahu. Laipe won maa mo
ﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺ
15:97
Awa kuku ti mo pe dajudaju ohun ti won n wi n ko inira ba o
ﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁ
15:98
Nitori naa, se afomo pelu idupe fun Oluwa re. Ki o si wa ninu awon oluforikanle (fun Un)
ﮂﮃﮄﮅﮆﮇ
15:99
Josin fun Oluwa re titi amodaju (iyen, iku) yoo fi de ba o
Al-Kur'an
Wednesday, September 9, 2026
Don't forget us in your sincere prayers







