Surah Maryam pdf — Gbà (Yorùbá)
Surah Maryam pdf Yorùbá — Gbà Surah Maryam Itumọ. Surah Maryam (Meccan) 98 Ẹsẹ.
Related
- Surah Maryam ItumọYorùbá
- Surah Maryam mp3Gbọ
- Quran Index Yorùbá114
More Surah PDF
Surah Maryam

ﭑﭒ
19:1
Kaf ha ya ‘aen sod. iya ‘Isa (’alaehi-ssolatu wa-ssalam) Oun l’O sa a lesa. Tohun ti bee naa iba ti so awon ododo wonyen nipa Moryam iya Jesu. Sebi won kuku fi enu abuku kan Moryam eda ni awon miiran ti Allahu fi sori awon surah oro Re. A kuku ri surah Muhammad gege bi a se ri surah Moryam. Amo iya ‘Isa so surah l’o maa so ‘Isa tabi iya re di oluwa ati olugbala? Tabi se nitori pe won fi oruko Moryam iya ‘Isa so surah l’o so ‘Isa tabi iya re di olohun omo? Tabi se nitori pe won fi oruko Moryam sise ti Allahu (subhanahu wa ta’ala) se Moryam ni esa eniyan amo ti Allahu ko se iya ati baba Anabi wa bee ti Allahu fi sori ebi Moryam a kuku ri surah Ƙuraes
ﭓﭔﭕﭖﭗﭘ
19:2
(Eyi ni) iranti nipa ike ti Oluwa Re se fun erusin Re, (Anabi) Zakariyya
ﭙﭚﭛﭜﭝﭞ
19:3
(Ranti) nigba ti o pe Oluwa re ni ipe ikoko
ﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭ
19:4
O so pe: "Oluwa mi, dajudaju eegun ara mi ti le, ori (mi) ti kun fun ewu, emi ko si nii pasan nipa bi mo se n pe O, Oluwa mi
ﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻ
19:5
Ati pe dajudaju mo n paya awon ibatan mi leyin (iku) mi. Iyawo mi si je agan. Nitori naa, ta mi lore lati odo Re omo rere kan
ﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅ
19:6
(ti) o maa jogun mi, ti o si maa jogun awon ebi (Anabi) Ya‘ƙub. Ki O si se e ni eni ti O yonu si, Oluwa mi
ﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒ
19:7
Zakariyya, dajudaju Awa maa fun o ni iro idunnu (nipa bibi) omokunrin kan, oruko re ni Yahya. A o fun eni kan ni (iru) oruko (yii) ri siwaju (re)
ﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡ
19:8
O so pe: "Oluwa mi, bawo ni mo se maa ni omo nigba ti iyawo mi je agan, ti mo si ti di agbalagba gan-an
ﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰ
19:9
(Molaika) so pe: “Bayen ni (o maa ri).” Oluwa re so pe: “O rorun fun Mi. Mo kuku da iwo naa siwaju (re), nigba ti iwo ko ti i je nnkan kan.”
ﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠ
19:10
(Zakariyya) so pe: “Oluwa mi, fun mi ni ami kan.” (Molaika) so pe: "Ami re ni pe, o o nii le ba eniyan soro fun ojo meta, ki i se ti amodi
ﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬ
19:11
Nigba naa, o jade si awon eniyan re lati inu ile ijosin. O si toka si won pe ki won maa se afomo (fun Allahu) ni owuro ati ni asale
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙ
19:12
Yahya, mu Tira naa dani daradara. A si fun un ni agboye esin lati kekere
ﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡ
19:13
(Anabi Yahya je) ike ati eni mimo kan lati odo Wa. O si je oluberu (Allahu)
ﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨ
19:14
(O tun je) oniwa rere si awon obi re mejeeji. Ko si je ajeninipa, oluyapa
ﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲ
19:15
Alaafia ni fun un ni ojo ti won bi i, ati ni ojo ti o maa ku ati ni ojo ti A oo gbe e dide laaye (ni Ojo Ajinde)
ﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽ
19:16
So itan Moryam ti o wa ninu al-Ƙur’an. (Ranti) nigba ti o yera kuro lodo awon eniyan re si aye kan ni ila oorun
ﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉ
19:17
O mu gaga kan (lati fi ara re pamo) fun won. A si ran molaika Wa si i. O si fara han an ni aworan abara pipe
ﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒ
19:18
(Moryam) so pe: “Emi sa di Ajoke-aye kuro lodo re, ti o ba je oluberu (Allahu).”
ﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜ
19:19
(Molaika) so pe: “Emi ni Ojise Oluwa re, (O ran mi si o) pe ki ng fun o ni omokunrin mimo kan.”
ﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨ
19:20
O so pe: "Bawo ni mo se maa ni omo nigba ti abara kan ko fowo kan mi, ti emi ko si je alagbere
ﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛ
19:21
(Molaika) so pe: “Bayen l’o maa ri.” Oluwa re so pe: “O rorun fun mi. Ati pe nitori ki A le se e ni ami fun awon eniyan ni. O si je ike lati odo Wa. O tun je oro ti A ti pari.”
ﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢ
19:22
Nitori naa, o loyun re. O si yera pelu re si aye kan t’o jinna
ﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰ
19:23
Irobi omo si mu un wa si idi igi dabinu. O so pe: “Haa! Ki ng ti ku siwaju eyi, ki ng si ti di eni ti won ti gbagbe patapata.”
ﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻ
19:24
Nigba naa, (molaika) pe e lati isale odo re pe: "Ma se banuje. Dajudaju Oluwa re ti se odo kekere kan si isale odo re
ﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄ
19:25
Mi igi dabinu naa sodo re, ki dabinu tutu, to to ka je si maa jabo sile fun o
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤ
19:26
Nitori naa, je, mu ki oju re si tutu. Ti o ba si ri eni kan ninu abara, so fun un pe: "Dajudaju mo jejee ikenuro fun Ajoke-aye. Nitori naa, mi o nii ba eniyan kan soro ni oni
ﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰ
19:27
O si mu omo naa wa ba awon eniyan re (ni eni ti) o gbe e dani. Won so pe: "Moryam, dajudaju o ti gbe nnkan aburu nla wa
ﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼ
19:28
Arabinrin Harun, baba re ki i se eniyan buruku. Ati pe iya re ki i se alagbere
ﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈ
19:29
O si toka si omo naa. Won so pe: “Bawo ni a o se ba eni t’o wa lori ite, t’o je omo oponlo soro?”
ﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑ
19:30
(Omo naa) soro pe: "Dajudaju eru Allahu ni emi. (Allahu) fun mi ni Tira. O si se mi ni Anabi. eda ti o n bowo fun ilana ati ofin Olohun eda ti o juwo juse sile fun ilana ati ofin Olohun ati eda ti o n josin fun Olohun labe ilana ati ofin Olohun. Eda naa ko si nii yonu si ilana ati ofin miiran t’o yato si ti Olohun.” Eni ti o ba n se iwonyen fun ohun miiran tabi elomiiran but with my flesh I am a slave to the law of sin.” Itumo: “Nitori naa nigba naa pelu emi mi pelu okan ati ara wa ni a fi gba lati wa labe ofin Re. Iwonba asise ti a ba si fi ara se gege bi adamo eniyan ironupiwada ati itoro aforijin ni odo Allahu ni ona abayo lori re. Alaforijin
ﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝ
19:31
O se mi ni eni ibukun ni ibikibi ti mo ba wa. O pa mi lase irun kiki ati Zakah yiyo lodiwon igba ti mo ba wa nipo alaaye (lori ile aye)
ﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤ
19:32
(O se mi ni) oniwa rere si iya mi. Ko si se mi ni ajeninipa, olori buruku
ﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮ
19:33
Alaafia ni fun mi ni ojo ti won bi mi, ati ni ojo ti mo maa ku ati ni ojo ti Won a gbe mi dide ni alaaye (ni Ojo Ajinde)
ﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚ
19:34
Iyen ni (Anabi) ‘Isa omo Moryam. (Eyi je) oro ododo ti awon (yehudi ati nasara) n seyemeji nipa re
ﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭ
19:35
Ko ye fun Allahu lati so eni kan kan di omo. Mimo ni fun Un. Nigba ti O ba pebubu kini kan, O kan maa so fun un pe: "Je bee." O si maa je bee
ﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷ
19:36
Ati pe dajudaju Allahu ni Oluwa mi ati Oluwa yin. Nitori naa, e josin fun Un. Eyi ni ona taara
ﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄ
19:37
Awon ijo (yehudi ati nasara) si yapa enu (si eyi) laaarin ara won. Nitori naa, egbe ni fun awon t’o sai gbagbo (ni asiko) ijerii gbangba lojo nla (Ojo Ajinde)
ﰅﰆﰇﰈﰉﰊﰋﰌﰍﰎﰏﰐﰑ
19:38
Ki ni won ko nii gbo, ki si ni won ko nii ri ni ojo ti won yoo wa ba Wa! Sugbon awon alabosi ni ojo naa ti wa ninu isina ponnbele
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝ
19:39
Sekilo ojo abamo fun won nigba ti A ba pari oro, (pe ko nii si iku mo, amo) won wa ninu igbagbera bayii na, won ko si gbagbo
ﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦ
19:40
Dajudaju Awa l’A maa jogun ile ati awon t’o n be lori re. Odo Wa si ni won yoo da yin pada si
ﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰ
19:41
Mu (itan) ’Ibrohim wa si iranti (bi o se) wa ninu al-Ƙur’an. Dajudaju o je olododo ponnbele, (o si je) Anabi
ﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀ
19:42
Ranti nigba ti o so fun baba re pe: "Baba mi, nitori ki ni o fi n josin fun ohun ti ko gboro, ti ko riran, ti ko si le ro o loro kan kan
ﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎ
19:43
Baba mi, dajudaju imo ti iwo ko ni ti de ba mi. Nitori naa, tele mi, ki ng fi ona taara mo o
ﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙ
19:44
Baba mi, ma se bo Esu. Dajudaju Esu je oluyapa ase Ajoke-aye
ﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥ
19:45
Baba mi, dajudaju emi n paya pe ki iya kan lati odo Ajoke-aye ma fowo ba o nitori ki iwo ma baa di ore Esu (ninu Ina)
ﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕ
19:46
(Baba re) wi pe: “Se iwo yoo ko awon olohun mi sile ni, ’Ibrohim? Dajudaju ti o o ba jawo (ninu ohun ti o n so), dajudaju mo maa le o loko pa. Tie yera fun mi woorowo na.”
ﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢ
19:47
(’Ibrohim) so pe: "Alaafia ki o maa ba o. Mo maa ba o toro aforijin lodo Oluwa mi. Dajudaju O je Oloore mi
ﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱ
19:48
Ati pe mo maa yera fun eyin ati nnkan ti e n josin fun leyin Allahu. Emi yo si maa pe Oluwa mi. O si sunmo pe emi ko nii pasan pelu adua mi si Oluwa mi
ﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁ
19:49
Nigba ti o yera fun awon ati nnkan ti won n josin fun leyin Allahu, A si ta a lore (omo), ’Ishaƙ ati Ya‘ƙub (omoomo). A si se okookan won ni Anabi
ﰂﰃﰄﰅﰆﰇﰈﰉﰊﰋ
19:50
Ati pe A ta won lore lati inu ike Wa. A si ni ki won maa soro won ni daadaa
ﰌﰍﰎﰏﰐﰑﰒﰓﰔﰕﰖﰗ
19:51
So itan (Anabi) Musa ti o wa ninu al-Ƙur’an. Dajudaju o je eni-esa, o je Ojise, (o tun je) Anabi
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘ
19:52
A pe e ni eba apata ni apa owo otun (Musa). A si mu un sunmo tosi lati ba a soro
ﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠ
19:53
Lati inu ike Wa A si fi arakunrin re, Harun, (ti o je) Anabi, ta a lore
ﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭ
19:54
So itan (Anabi) ’Ismo‘il ti o wa ninu al-Ƙur’an. Dajudaju o je olumu-adehun-se, o je Ojise, (o tun je) Anabi
ﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷ
19:55
O maa n pa ara ile re ni ase irun kiki ati Zakah yiyo. O si je eni iyonu lodo Oluwa re
ﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁ
19:56
So itan (Anabi) ’Idris ti o wa ninu al-Ƙur’an. Dajudaju o je olododo ponnbele, (o si je) Anabi
ﮂﮃﮄﮅ
19:57
A si gbe e si aye giga (ninu sanmo)
ﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥ
19:58
Awon wonyen ni awon ti Allahu se idera fun ninu awon Anabi, ninu awon aromodomo (Anabi) Adam ati ninu awon ti A gbe gun oko oju-omi pelu (Anabi) Nuh ati ninu aromodomo (Anabi) ’Ibrohim ati ’Isro’il ati ninu awon ti A ti fi mona, ti A si sa lesa. Nigba ti won ba n ke awon ayah Ajoke-aye fun won, won maa doju bole; ti won a forikanle, ti won a si maa sunkun
ﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔ
19:59
Awon arole kan si role leyin won, ti won ra irun kiki lare, ti won tele awon yodoyindin emi. Laipe won maa pade iparun (ninu Ina)
ﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡ
19:60
Ayafi eni ti o ba ronu piwada, ti o gbagbo ni ododo, ti o si se ise rere. Awon wonyen ni won yoo wo inu Ogba Idera. A o si nii sabosi kan kan si won
ﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮ
19:61
(Won yoo wo inu) awon Ogba Idera gbere ti Ajoke-aye se ni adehun si ipamo fun awon erusin Re. Dajudaju (Allahu), adehun Re n bo wa se
ﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻ
19:62
Won ko nii gbo isokuso ninu re afi alaafia. Ije-imu won wa ninu re ni owuro ati ni asale
ﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅ
19:63
Iyen ni Ogba Idera ti A oo jogun re fun eni ti o je oluberu (Mi) ninu awon erusin Wa
ﰆﰇﰈﰉﰊﰋﰌﰍﰎﰏﰐﰑﰒﰓﰔﰕﰖﰗﰘﰙﰚ
19:64
Awa (molaika) ki i sokale ayafi pelu ase Oluwa re. TiRe ni ohun ti n be niwaju wa, ohun ti n be ni eyin wa ati ohun ti n be laaarin (mejeeji) yii. Oluwa re ki i si se onigbagbe
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞ
19:65
Oluwa awon sanmo ati ile ati ohun ti n be laaarin awon mejeeji. Nitori naa, josin fun Un, ki o si se suuru lori ijosin Re. Nje o mo eni ti o tun n je oruko Re
ﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧ
19:66
Eniyan n wi pe: “Se nigba ti mo ba ku, Won yoo tun mu mi jade laipe ni alaaye?”
ﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲ
19:67
Se eniyan ko ranti pe dajudaju Awa ni A seda re teletele nigba ti ko ti i je nnkan kan
ﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻ
19:68
Nitori naa, mo fi Oluwa re bura; dajudaju A maa ko awon ati awon esu jo. Leyin naa, dajudaju A maa mu won wa si ayika ina Jahanamo lori ikunle
ﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆ
19:69
Leyin naa, dajudaju A maa mu jade ninu ijo kookan eyikeyii ninu won ti o le julo ni ese dida si Ajoke-aye
ﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏ
19:70
Leyin naa, dajudaju Awa nimo julo nipa awon t’o letoo si wiwo inu Ina
ﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚ
19:71
Ko si eni kan ninu yin afi ki o debe. O je isele dandan lodo Oluwa re. 74:30-31. Bakan naa, kalmoh “warid” t’o jeyo ninu ayah 71 je oro-oruko ti won seda lati ara oro-ise “warada”. Ninu al-Ƙur’an, itumo meji pere l’o wa fun “warada”. “Warada” tumo si “o de si ibi ti kini kan wa, o si wo inu nnkan naa”, gege bi itumo yii se wa ninu surah Hud 11:98 ati surah al-’Anbiya’
ﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣ
19:72
igun kiini keji maa wa labe akorin awon molaika kan ni. Iyen ni pe awon molaika kan l’o maa ko gbogbo eda lo sori afara Ina nitori pe
ﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕ
19:73
Nigba ti won ba n ke awon ayah Wa t’o yanju fun won, awon t’o sai gbagbo yoo so fun awon t’o gbagbo ni ododo pe: “Ewo ninu ijo mejeeji (awa tabi eyin) l’o loore julo ni ibugbe, l’o si dara julo ni ijokoo?”
ﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟ
19:74
Ati pe meloo meloo ninu awon iran ti A ti pare siwaju won, ti won dara julo ni oro (aye) ati ni irisi
ﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺ
19:75
So pe: “Eni ti o ba wa ninu isina, Ajoke-aye yo si fe (isina) loju fun un taara, titi di igba ti won maa ri ohun ti won n se ni adehun fun won, yala iya tabi Akoko naa. Nigba naa, won yoo mo eni ti o buru julo ni ipo, ti o si le julo ni omo ogun
ﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆﰇﰈﰉ
19:76
Allahu yo si salekun imona fun awon t’o mona. Awon ise rere elesan gbere loore julo ni esan, o si loore julo ni ibudesi lodo Oluwa re
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙ
19:77
So fun mi nipa eni t’o sai gbagbo ninu awon ayah Wa, ti o si wi pe: “Dajudaju won yoo fun mi ni dukia ati omo!”
ﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡ
19:78
Se o ri ikoko ni tabi o ri adehun kan gba lodo Ajoke-aye
ﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬ
19:79
Rara. A maa sakosile ohun t’o n wi. A si maa fe iya loju fun un taara
ﭭﭮﭯﭰﭱﭲ
19:80
A o si jogun ohun t’o n wi fun un. O si maa wa ba Wa ni oun nikan
ﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻ
19:81
Won so awon kan di olohun leyin Allahu nitori ki won le fun won ni agbara
ﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃ
19:82
Rara. Won maa tako ijosin won, won si maa di ota won
ﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍ
19:83
Se o o ri i pe dajudaju Awa n ran awon esu si awon alaigbagbo ni, ti won si n ti won ni itikuti (sibi ese)
ﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖ
19:84
Nitori naa, ma se kanju nipa (iya) won. A kuku n ka (ojo) fun won ni kika taara
ﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝ
19:85
(Ranti) ojo ti A oo ko awon oluberu (Allahu) jo sodo Ajoke-aye lori nnkan igun
ﮞﮟﮠﮡﮢﮣ
19:86
A si maa da awon elese lo sinu ina Jahanamo witiwiti
ﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭ
19:87
Won ko nii ni ikapa isipe afi eni ti o ba gba adehun lati odo Ajoke-aye
ﮮﮯﮰﮱﯓ
19:88
Won wi pe: "Ajoke-aye fi eni kan se omo
ﯔﯕﯖﯗﯘ
19:89
Dajudaju e ti mu nnkan aburu wa
ﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢ
19:90
Awon sanmo fere faya perepere nitori re, ile fere faya perepere, awon apata si fere da wo lule gbi
ﯣﯤﯥﯦﯧ
19:91
fun wi pe won pe eni kan ni omo Ajoke-aye
ﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮ
19:92
Ko si ye fun Ajoke-aye lati fi eni kan se omo
ﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹ
19:93
Ko si eni kan ninu awon sanmo ati ile ayafi ki o wa ba Ajoke-aye ni ipo erusin
ﯺﯻﯼﯽﯾ
19:94
Dajudaju (Allahu) mo won. O si ka onka won taara
ﯿﰀﰁﰂﰃﰄ
19:95
Gbogbo won yo si wa ba A ni Ojo Ajinde ni ikookan
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚ
19:96
Dajudaju awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se ise rere, Ajoke-aye yoo fi ife saaarin won
ﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥ
19:97
Nitori naa, A kuku se kike al-Ƙur’an ni irorun (fun o) pelu ede abinibi re nitori ki o le fi se iro idunnu fun awon oluberu (Allahu) ati nitori ki o le fi se ikilo fun ijo oniyan-jija
ﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴ
19:98
Meloo meloo ninu iran ti A ti pare siwaju won! Nje o gbo iro eni kan kan ninu won mo tabi (nje) o gbo ohun kelekele kan lati odo won bi
Al-Kur'an
Wednesday, September 9, 2026
Don't forget us in your sincere prayers







