Surah As-Sajdah
PDF —
Built right in your browser — download starts automatically
Surah As-Sajdah pdf — Gbà (Yorùbá)
Surah As-Sajdah pdf Yorùbá — Gbà Surah As-Sajdah Itumọ. As-Sajdah (Meccan) 30 Ẹsẹ.
Related
- As-Sajdah ItumọYorùbá
- As-Sajdah mp3Gbọ
- Quran Index Yorùbá114
More Surah PDF
Surah As-Sajdah

ﭑﭒ
’Alif lam mim
ﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛ
Isokale Tira naa, ko si iyemeji ninu re (pe o wa) lati odo Oluwa gbogbo eda
ﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯ
Tabi won n wi pe: “O da adapa iro re ni.” Rara o! Ododo ni lati odo Oluwa re nitori ki o le fi sekilo fun awon eniyan kan, ti olukilo kan ko wa ba won ri siwaju re, nitori ki won le mona
ﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊ
Allahu ni Eni ti O seda awon sanmo, ile ati nnkan t’o wa laaarin mejeeji laaarin ojo mefa. Leyin naa, O gunwa sori Ite-ola. Ko si alaabo ati olusipe kan fun yin leyin Re. Se e o nii lo iranti ni
ﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜ
O n seto oro (eda) lati sanmo wa sori ile. Leyin naa, (abo oro eda) yoo gunke to O lo laaarin ojo kan ti odiwon re to egberun odun ninu onka ti e n ka
ﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣ
Iyen ni Onimo-ikoko ati gbangba, Alagbara, Asake-orun
ﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯ
Eni t’o se gbogbo nnkan ti O da ni daadaa. O si bere iseda eniyan lati inu erupe amo
ﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙ
Leyin naa, O se awon aromodomo re lati ara ohun ti A mu jade lati ara omi lile yepere
ﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪ
Leyin naa, O to (orikeerikee) re dogba. O si fe (emi) si i lara ninu emi Re (ti O da). O tun se igboro, iriran ati okan fun yin. Die ni ope ti e n da
ﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺ
Won si wi pe: “Nje nigba ti a ba ti poora sinu ile, nje awa tun le wa ni eda titun mo? Ani se, awon ni alaigbagbo ninu ipade Oluwa won
ﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆﰇ
So pe: “Molaika iku eyi ti A fi ti yin maa gba emi yin. Leyin naa, odo Oluwa yin ni won maa da yin pada si.” gege bi O se je Eledaa ohun gbogbo. Ko si eda kan ti o maa to isemi wo afi pelu iyonda Allahu (subhanahu wa ta’ala). Ko si si eda kan ti o maa to iku wo afi pelu iyonda Allahu (subhanahu wa ta’ala). Nipa eyi Allahu l’O n fi ase Re gba emi kuro lara eda Re ni akoko ti O ti ko mo on ninu kadara. Iyen ni o jeyo ninu surah az-Zumor; 39:42. Bakan naa
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡ
(Iwo iba ri eemo) ti o ba je pe o ri awon elese nigba ti won ba sori ko ni odo Oluwa won, (won si maa wi pe): “Oluwa wa, a ti riran, a si ti gboran (bayii), nitori naa, da wa pada (si ile aye) nitori ki a le lo se ise rere; dajudaju awa ni alamodaju.”
ﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲ
Ti o ba je pe A ba fe ni, dajudaju A iba fun gbogbo emi kookan ni imona re, sugbon oro naa ti se lati odo Mi (bayii pe): “Dajudaju Mo maa mu ninu awon alujannu ati eniyan ni apapo kun inu ina Jahanamo.”
ﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂ
Nitori naa, e to iya wo nitori pe e ti gbagbe ipade ojo yin (oni) yii. Dajudaju Awa naa yoo gbagbe yin sinu Ina. E to iya gbere wo nitori ohun ti e n se nise
ﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓ
Awon t’o gbagbo ninu awon ayah Wa ni awon ti o je pe nigba ti won ba fi se isiti fun won, won yoo doju bole ni oluforikanle, won yo si se afomo pelu idupe fun Oluwa won. Won ko si nii segberaga
ﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟ
Won n gbe egbe won kuro lori ibusun. Won si n pe Oluwa won ni ti ipaya ati ireti. Won si n na ninu ohun ti A pese fun won
ﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭ
Ko si emi kan ti o mo ohun ti A fi pamo fun won ninu awon nnkan itutu oju. (O je) esan ohun ti won n se nise (rere)
ﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘ
Nje eni t’o je onigbagbo ododo da bi eni t’o je obileje bi? Won ko dogba
ﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥ
Ni ti awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se ise rere, awon ibugbe (ninu) Ogba Idera n be fun won. (O je) ohun ti A pese sile (de won) nitori ohun ti won n se nise (rere)
ﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼ
Ni ti awon t’o baleje, Ina ni ibugbe won. Igbakigba ti won ba fe jade kuro ninu re, A o si maa da won pada sinu re. A si maa so fun won pe: “E to iya Ina ti e n pe niro wo.”
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚ
Dajudaju A maa fun won to wo ninu iya t’o kere julo (nile aye) yato si iya t’o tobi julo (lorun) nitori ki won le seri pada (sibi ododo siwaju iku won)
ﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩ
Ati pe ta l’o se abosi t’o tayo eni ti won fi awon ayah Wa se isiti fun, leyin naa, ti o gbunri kuro nibe? Dajudaju Awa maa gbesan lara awon elese
ﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹ
Dajudaju A fun (Anabi) Musa ni Tira. Nitori naa, ma se wa ninu iyemeji nipa bi o se pade re (iyen, ninu irin-ajo oru ati gigun sanmo). A si se Tira naa ni imona fun awon omo ’Isro’il
ﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅ
Ati pe A se awon asiwaju kan ninu won ni afinimona pelu ase Wa nigba ti won se suuru. Won si n ni amodaju nipa awon ayah Wa
ﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑ
Dajudaju Oluwa re, O maa se idajo laaarin won ni Ojo Ajinde nipa ohun ti won n yapa enu si
ﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦ
Se ko foju han si won pe, meloo meloo ninu awon iran ti A ti pare siwaju won. Awon naa si n rin koja ninu awon ibugbe won! Dajudaju awon ami wa ninu iyen. Nitori naa, se won ko nii teti gboro (ododo ni)
ﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚ
Tabi won ko ri i pe dajudaju Awa l’A n wa omi ojo lo sori ile gbigbe, ti A si n fi mu irugbin jade? Awon eran-osin won ati awon naa si n je ninu re. Nitori naa, se won ko riran ni
ﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢ
Won si n wi pe: “Igba wo ni Idajo yii ti e ba je olododo?”
ﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮ
So pe: “Ni Ojo Idajo, igbagbo won ko nii sanfaani fun awon t’o sai gbagbo (ninu Allahu). A o si nii fun won ni isinmi (ninu Ina).”
ﯯﯰﯱﯲﯳﯴ
Nitori naa, seri kuro lodo won, ki o si maa reti (Ojo Idajo). Dajudaju awon naa n reti (re)
Al-Kur'an
Tuesday, August 18, 2026
Don't forget us in your sincere prayers







