PDF —
62 Ẹsẹ Meccan PDF
Built right in your browser — download starts automatically

Surah An-Najm pdf — Gbà (Yorùbá)

Surah An-Najm pdf Yorùbá — Gbà Surah An-Najm Itumọ. Surah An-Najm (Meccan) 62 Ẹsẹ.

← At-TurSurah An-Najm Al-Qamar →


62 Ẹsẹ · Meccan · Yorùbá
bismillah
ﭑﭒﭓﭔ
53:1 (Allahu bura pelu) irawo nigba ti o ba jabo
ﭕﭖﭗﭘﭙﭚ
53:2 Eni yin ko sina, ko si sonu
ﭛﭜﭝﭞﭟ
53:3 Ati pe ko nii soro ife-inu
ﭠﭡﭢﭣﭤﭥ
53:4 Ko nii so ohun kan tayo imisi ti A fi ranse si i
ﭦﭧﭨﭩ
53:5 Alagbara (iyen, molaika Jibril) l’o ko o ni imo (al-Ƙur’an)
ﭪﭫﭬﭭ
53:6 O ni alaafia t’o peye. Nitori naa, o duro wamuwamu
ﭮﭯﭰﭱ
53:7 nigba ti o wa ninu ofurufu loke patapata
ﭲﭳﭴﭵ
53:8 Leyin naa, o sun mo (Anabi). O si sokale (to o wa)
ﭶﭷﭸﭹﭺﭻ
53:9 (Alafo aarin awon mejeeji) si to iwon orun ofa meji, tabi ki o kere (si iyen)
ﭼﭽﭾﭿﮀﮁ
53:10 Allahu si fun erusin Re ni imisi t’O fun un
ﮂﮃﮄﮅﮆﮇ
53:11 Okan (Anabi) ko paro ohun t’o ri
ﮈﮉﮊﮋﮌ
53:12 Se e oo ja a niyan nipa ohun t’o ri ni
ﮍﮎﮏﮐﮑ
53:13 Ati pe dajudaju o ri i nigba keji Allahu (subhanahu wa ta’ala) ni o ri bi o tile je pe igun yii fi kun un pe okan l’o fi ri Allahu bii oro ti o todo Omo ‘Abbas (rodiyallahu anhu) wa pe “Anabi (sollalahu alayhi wa sallam) fi okan re ri Allahu ni.” Iyen ni pe
ﮒﮓﮔﮕ
53:14 nibi igi sidirah al-Muntaha
ﮖﮗﮘﮙ
53:15 nitosi re ni Ogba Ibugbe (gbere) wa
ﮚﮛﮜﮝﮞﮟ
53:16 (Ranti) nigba ti ohun t’o bo igi Sidirah bo o mole
ﮠﮡﮢﮣﮤﮥ
53:17 Oju (Anabi) ko ye, ko si tayo enu-ala
ﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬ
53:18 Dajudaju o ri ninu awon ami Oluwa re, t’o tobi julo
ﮭﮮﮯﮰ
53:19 E so fun mi nipa orisa Lat ati orisa ‘Uzza
ﮱﯓﯔﯕ
53:20 ati Monah, orisa keta miiran
ﯖﯗﯘﯙﯚ
53:21 Se omokunrin ni tiyin, omobinrin si ni tiRe
ﯛﯜﯝﯞﯟ
53:22 Ipin abosi niyen nigba naa
ﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻ
53:23 (Awon oruko orisa wonyen) ko si je kini kan bi ko se awon oruko kan ti eyin ati awon baba yin fi so (awon orisa yin funra yin). Allahu ko si so eri oro kan kale nipa re. Won ko si tele kini kan bi ko se aroso ati ohun ti emi (won) n fe. Imona kuku ti de ba won lati odo Oluwa won
ﯼﯽﯾﯿﰀ
53:24 Tabi ti eniyan ni nnkan t’o ba n fe
ﰁﰂﰃﰄ
53:25 Ti Allahu si ni orun ati aye
ﰅﰆﰇﰈﰉﰊﰋﰌﰍﰎﰏﰐﰑﰒﰓﰔﰕﰖﰗﰘ
53:26 Ati pe meloo meloo ninu awon molaika t’o wa ninu awon sanmo, ti isipe won ko nii ro won loro kini kan ayafi leyin igba ti Allahu ba yonda fun eni ti O ba fe, ti O si yonu si
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚ
53:27 Dajudaju awon ti ko ni igbagbo ododo ninu Ojo Ikeyin, awon ni won n fun awon molaika ni oruko obinrin
ﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭ
53:28 Ko si imo kan fun won nipa re. Won ko si tele kini kan bi ko se aroso. Dajudaju aroso ko si nii roro kini kan lara ododo
ﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹ
53:29 Nitori naa, seri kuro ni odo eni t’o keyin si iranti Wa, ti ko si gbero kini kan afi isemi aye
ﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋ
53:30 Iyen ni odiwon (ati opin) imo won. Dajudaju Oluwa re, O nimo julo nipa eni t’o sina kuro loju ona Re. O si nimo julo nipa eni t’o mona
ﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜ
53:31 Ti Allahu ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile nitori ki O le san awon t’o se ise aburu ni esan ohun ti won se nise ati nitori ki O le san awon t’o se ise rere ni esan rere
ﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡ
53:32 Awon t’o n jinna si ese nla nla ati iwa ibaje ayafi awon ese peepeepe, dajudaju Oluwa re gbooro ni aforijin. O nimo julo nipa yin nigba ti O seda yin lati inu ile ati nigba ti e wa ni ole ninu awon ikun iya yin. Nitori naa, e ma se fora yin mo. O nimo julo nipa eni t’o beru (Re)
ﯢﯣﯤﯥ
53:33 So fun mi nipa eni t’o gbunri (kuro nibi ododo)
ﯦﯧﯨﯩ
53:34 ti o fi die tore, ti o si di iyoku mowo
ﯪﯫﯬﯭﯮﯯ
53:35 Se imo ikoko wa ni odo re, ti o si n ri i (pe elomiiran l’o ma ba oun jiya lorun)
ﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷ
53:36 Tabi won ko fun un ni iro ohun t’o wa ninu tira (Anabi) Musa ni
ﯸﯹﯺﯻ
53:37 ati (tira Anabi) ’Ibrohim, eni t’o mu (ofin Allahu) se
ﯼﯽﯾﯿﰀﰁ
53:38 pe dajudaju eleru-ese kan ko nii ru eru-ese elomiiran
ﰂﰃﰄﰅﰆﰇﰈ
53:39 Ati pe ko si kini kan fun eniyan afi ohun t’o se nise
ﰉﰊﰋﰌﰍ
53:40 Ati pe dajudaju ise re, laipe won maa fi han an
ﰎﰏﰐﰑﰒ
53:41 Leyin naa, won maa san an ni esan re, ni esan t’o kun julo
ﰓﰔﰕﰖﰗ
53:42 Ati pe dajudaju odo Oluwa re ni opin (irin-ajo eda)
ﰘﰙﰚﰛﰜ
53:43 Dajudaju Oun l’O n pa (eda) ni erin. O si n pa (eda) ni ekun
ﰝﰞﰟﰠﰡ
53:44 Dajudaju Oun l’O n so (eda) di oku. O si n so (eda) di alaaye
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖ
53:45 Dajudaju Oun l’O da eda ni orisi meji, okunrin ati obinrin
ﭗﭘﭙﭚﭛ
53:46 lati ara ato nigba ti won ba da a sinu apoluke
ﭜﭝﭞﭟﭠ
53:47 Dajudaju Oun l’O maa se iseda ikeyin fun ajinde
ﭡﭢﭣﭤﭥ
53:48 Dajudaju Oun l’O n se pupo, O si n se kekere (oore fun eda)
ﭦﭧﭨﭩﭪ
53:49 Dajudaju Oun si ni Oluwa irawo Si‘ro (ti won so di orisa)
ﭫﭬﭭﭮﭯ
53:50 Dajudaju Oun l’O pa iran ‘Ad re, awon eni akoko
ﭰﭱﭲﭳ
53:51 ati iran Thamud, ko si se won ku
ﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾ
53:52 ati ijo Nuh t’o siwaju (won), dajudaju won je alabosi julo, won si tayo enu-ala julo
ﭿﮀﮁ
53:53 ati ilu ti won dawo (ilu Anabi Lut) t’O ye lule (lati oke)
ﮂﮃﮄﮅ
53:54 Ohun t’o bo won mole bo won mole
ﮆﮇﮈﮉﮊ
53:55 Nitori naa, ewo ninu idera Oluwa re ni iwo (eniyan) n ja niyan
ﮋﮌﮍﮎﮏﮐ
53:56 Eyi ni ikilo kan ninu awon ikilo akoko
ﮑﮒﮓ
53:57 Ohun t’o sunmo sunmo
ﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚ
53:58 Leyin Allahu, ko si eni t’o le safi han (Akoko naa)
ﮛﮜﮝﮞﮟ
53:59 Se oro yii l’o n se yin ni kayefi
ﮠﮡﮢﮣ
53:60 E n rerin-in, e o si sunkun
ﮤﮥﮦ
53:61 Afonu-fora ni yin
ﮧﮨﮩﮪﮫ
53:62 Nitori naa, e fori kanle fun Allahu, ki e josin (fun Un)

Al-Kur'an


Wednesday, September 9, 2026

Don't forget us in your sincere prayers