Surah Al-Hajj
78 Ẹsẹ · Medinan · Yorùbá
bismillah
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛ
Eyin eniyan, e beru Oluwa yin. Dajudaju imi titi Akoko naa, nnkan nla ni
ﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲ
(Akoko naa ni) ojo ti e maa ri i ti gbogbo obinrin t’o n fun omo lomu mu yoo gbagbe omo ti won n fun lomu ati pe gbogbo aboyun yo si maa bi oyun won. Iwo yo si ri awon eniyan ti oti yoo maa pa won. Oti ko si pa won, sugbon iya Allahu (t’o) le (l’o fa a)
ﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿ
O si n be ninu awon eniyan eni t’o n jiyan nipa (esin) Allahu lai ni imo. O si n tele gbogbo esu olori kunkun
ﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋ
Won ko o le (Esu) lori pe dajudaju enikeni ti o ba tele e, o maa si i lona. O si maa to o si ona iya Ina t’o n jo fofo
ﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵ
Eyin eniyan, ti e ba wa ninu iyemeji nipa ajinde, dajudaju Awa seda yin lati inu erupe, leyin naa lati inu ato, leyin naa lati inu eje didi, leyin naa lati inu baasi eran ti o pe ni eda ati eyi ti ko pe ni eda nitori ki A le salaye (agbara Wa) fun yin. A si n mu ohun ti A ba fe duro sinu apo ibimo titi di gbedeke akoko kan. Leyin naa, A oo mu yin jade ni oponlo. Leyin naa, (e oo maa semi lo) nitori ki e le sanngun dopin agbara yin. Eni ti o maa ku (ni kekere) wa ninu yin. O si wa ninu yin eni ti A oo da (isemi) re si di asiko ogbo kujokujo nitori ki o ma le mo nnkan kan mo leyin ti o ti mo on. Ati pe o maa ri ile ni gbigbe. Nigba ti A ba si so ojo kale le e lori, o maa yira pada. O maa gberu. O si maa mu gbogbo orisirisi irugbin t’o dara jade
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞ
Iyen nitori pe dajudaju Allahu, Oun ni Ododo. Dajudaju Oun l’O n so awon oku di alaaye. Dajudaju Oun si ni Alagbara lori gbogbo nnkan
ﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫ
Ati pe dajudaju Akoko naa n bo. Ko si iyemeji ninu re. Dajudaju Allahu yoo gbe awon t’o n be ninu saree dide
ﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹ
O n be ninu awon eniyan eni t’o n jiyan nipa (esin) Allahu lai ni imo (al-Ƙur’an) ati imona (sunnah Anabi) ati tira (onimo-esin) t’o n tan imole (soro esin)
ﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋ
O n yi orun re ka ni ti igberaga nitori ki o le ko isina ba awon eniyan loju ona (esin) Allahu. Abuku n be fun un nile aye. Ni Ojo Ajinde, A si maa fun un ni iya Ina jonijoni to wo
ﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕ
Iyen nitori ohun ti owo re ti siwaju. Dajudaju Allahu ko nii sabosi si awon erusin Re
ﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓ
O tun wa ninu awon eniyan eni t’o n josin fun Allahu lori ahon. Ti rere ba sele si i, o maa fi okan bale (sinu esin). Ti ifooro ba si sele si i, o maa yiju re pada kuro ninu esin. O sofo laye ati lorun. Iyen ni ofo ponnbele
ﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣ
O n pe leyin Allahu ohun ti ko le ko inira ba a, ti ko si le se e ni oore; iyen ni isina t’o jinna (si imona)
ﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯ
O n pe ohun ti inira re sunmo ju anfaani re lo. Dajudaju (orisa) buru ni oluranlowo, o si buru ni alasun-unmo
ﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂ
Dajudaju Allahu yoo mu awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere wo inu Ogba Idera ti awon odo n san ni isale re. Dajudaju Allahu n se ohun ti O ba fe
ﰃﰄﰅﰆﰇﰈﰉﰊﰋﰌﰍﰎﰏﰐﰑﰒﰓﰔﰕﰖﰗﰘﰙ
Enikeni ti o ba lero pe Allahu ko nii ran (Anabi) lowo laye ati lorun, ki o na okun si sanmo leyin naa ki o ge e (iyen ni pe, ki o pokun so). Ki o wo o nigba naa boya ete re le mu (aranse) t’o n binu si kuro (lodo Anabi s.a.w)
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚ
Bayen ni A se so o kale ni awon ayah t’o yanju. Dajudaju Allahu n to eni ti O ba fe si ona
ﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲ
Dajudaju awon t’o gbagbo ni ododo ati awon t’o di yehudi, awon sobi’un, awon kristieni, awon mojus ati awon t’o sebo, dajudaju Allahu yoo sedajo laaarin won ni Ojo Ajinde. Dajudaju Allahu ni Arinu-rode gbogbo nnkan
ﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜ
Se o o ri i pe dajudaju Allahu ni awon t’o n be ninu awon sanmo ati awon t’o n be lori ile, ati oorun, osupa, awon irawo, awon apata, awon igi, awon nnkan elemii ati opolopo ninu awon eniyan n fori kanle fun? Opolopo si tun ni iya ti ko le lori. Enikeni ti Allahu ba fi abuku kan, ko si eni kan ti o maa se aponle re. Dajudaju Allahu n se ohun ti O ba fe
ﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰ
Awon onija meji (kan) niyi, won n tako ara won nipa Oluwa won. Nitori naa, awon t’o sai gbagbo, won maa ge aso Ina fun won, won si maa da omi gbigbona le won lori lati oke ori won
ﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘ
Won maa fi yo ohun ti n be ninu ikun won ati awo ara won
ﯙﯚﯛﯜﯝ
Awon oduro irin (iya) si wa fun won pelu
ﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪ
Igbakigba ti won ba fe jade kuro ninu re latara ibanuje, won a da won pada sinu re. (A oo so pe): “E to iya Ina jonijoni wo.”
ﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂ
Dajudaju Allahu yoo fi awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere wo inu awon Ogba Idera, ti awon odo n san ni isale re. A oo se won ni oso ninu re pelu egba wura ati aluuluu. Aso alaari si ni aso won ninu re
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚ
A fun won ni imona sibi ohun t’o dara ninu oro. A si to won si ona Eleyin
ﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵ
Dajudaju awon t’o sai gbagbo, ti won n seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Allahu ati Mosalasi Haram, eyi ti A se ni dogbadogba fun awon eniyan, olugbe-inu re ati alejo (fun ijosin sise), enikeni ti o ba ni ero lati se iyipada kan nibe pelu abosi, A maa mu un to iya eleta-elero wo
ﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆ
(E ranti) nigba ti A safi han aye ile naa fun (Anabi) ’Ibrohim (A si pa a lase) pe o o gbodo so kini kan di akegbe fun Mi. Ati pe ki o se ile Mi ni mimo fun awon oluyipo re, olukirun, oludawote-orunkun ati oluforikanle
ﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕ
Ki o si pe ipe fun awon eniyan fun ise Hajj. Won yoo wa ba o pelu irin ese. Won yo si maa gun awon rakunmi wa lati awon ona jijin
ﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫ
nitori ki won le ri awon anfaani t’o n be fun won ati nitori ki won le seranti oruko Allahu fun awon ojo ti won ti mo lori nnkan ti Allahu pa lese fun won ninu awon eran-osin. Nitori naa, e je ninu re, ki e si fi bo alailera, talika
ﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕ
Leyin naa, ki won pari ise Hajj won, ki won mu awon eje won se, ki won si yipo Ile Laelae
ﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱ
Iyen (niyen). Enikeni ti o ba si pataki awon nnkan ti Allahu fi se arisami fun esin ’Islam, o loore julo fun un lodo Oluwa re. Won si se awon eran-osin ni eto fun yin ayafi awon ti won n ka (ni eewo) fun yin. Nitori naa, e jinna si egbin orisa. Ki e si jinna si oro iro
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧ
(E je) oluduro-deede-ninu-esin fun Allahu, lai nii je osebo si I. Enikeni ti o ba sebo si Allahu, o da bi eni t’o jabo lati oju sanmo, ti eye si gbe e lo tabi (ti) ategun ju u sinu aye t’o jinna
ﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲ
Iyen (niyen). Enikeni ti o ba si pataki awon nnkan ti Allahu fi se arisami fun esin ’Islam, dajudaju o wa lara nini iberu Allahu ninu okan
ﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾ
Awon anfaani wa fun yin lara awon eran-osin titi di gbedeke akoko kan. Leyin naa, Ile Laelae ni ibupa awon eran naa
ﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕ
Ikookan ijo (musulumi t’o siwaju) ni A yan eran pipa fun nitori ki won le daruko Allahu lori ohun ti O pese fun won ninu awon eran-osin. Nitori naa, Olohun yin, Olohun Okan soso ni. Oun ni ki e je musulumi fun. Ki o si fun awon olokan irele, awon olufokanbale sodo Allahu ni iro idunnu
ﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥ
(Awon ni) awon ti o je pe ti A ba daruko Allahu (fun won), okan won maa gbon riri. (Won je) onisuuru lori ohun ti o ba sele si won. (Won je) olukirun. Won si n na ninu ohun ti A pa lese fun won
ﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥ
Awon rakunmi, A se won ninu awon nnkan arisami fun esin Allahu fun yin. Oore wa lara won fun yin. Nitori naa, e daruko Allahu le won lori (ki e si gun won) ni iduro. Nigba ti won ba fi egbe lele, e je ninu re. E fi bo oniteelorun ati atoroje. Bayen ni A se ro won fun yin nitori ki e le dupe (fun Un)
ﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼ
Eran (ti e pa) ati eje re ko nii de odo Allahu. Sugbon iberu Allahu lati odo yin l’o maa de odo Re. Bayen ni (Allahu) se ro won fun yin nitori ki e le se igbetobi fun Allahu nipa bi O se fi ona mo yin. Ki o si fun awon oluse-rere ni iro idunnu
ﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆﰇﰈﰉﰊﰋﰌ
Dajudaju Allahu n ti aburu kuro fun awon t’o gbagbo ni ododo. Dajudaju Allahu ko nifee gbogbo awon onijanba, alaigbagbo
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜ
A yonda (ogun esin jija) fun awon (musulumi) ti (awon keferi) n gbogun ti nitori pe (awon keferi) ti se abosi si won. Dajudaju Allahu ni Alagbara lori aranse won
ﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃ
(Awon ni) awon ti won le jade kuro ninu ile won ni ona aito afi (nitori pe) won n so pe: “Allahu ni Oluwa wa.” Ti ko ba je pe Allahu n dena (aburu) fun awon eniyan ni, ti O n fi apa kan won dena (aburu) fun apa kan, won iba ti wo ile isin awon fada, soosi, sinagogu ati awon mosalasi ti won ti n daruko Allahu ni opolopo.1 Dajudaju Allahu yoo se aranse fun enikeni t’o n ran (esin ’Islam) Re lowo. Dajudaju Allahu ma ni Alagbara, Olubori
ﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖ
(Awon naa ni) awon ti o je pe ti A ba fun won ni ipo lori ile, won yoo kirun, won yoo yo Zakah, won yoo pase ohun rere, won yo si ko ohun buruku. Ti Allahu si ni ikangun awon oro eda
ﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠ
Ti won ba pe o ni opuro, awon ijo Nuh, ijo ‘Ad ati ijo Thamud kuku ti pe awon Ojise won ni opuro siwaju won
ﮡﮢﮣﮤﮥ
Ati pe ijo ’Ibrohim ati ijo (Anabi) Lut
ﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕ
ati awon ara ilu Modyan (awon naa se bee). Won tun pe (Anabi) Musa ni opuro. Mo si lo awon alaigbagbo lara. Leyin naa, Mo gba won mu. Bawo si ni bi Mo se (fi iya) ko (aburu fun won) ti ri
ﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤ
Nitori naa, meloo meloo ninu ilu ti A ti pare nigba ti won je alabosi; awon ile won dawo lule pelu orule re. (Meloo meloo ninu) kannga ti won ti pati (nipase iparun) ati ile peteesi onibiriki (t’o ti dahoro)
ﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽ
Se won ko rin kiri lori ile ki won si ni awon okan ti won maa fi se laakaye tabi awon eti ti won maa fi gboro? Dajudaju awon oju ko fo, sugbon awon okan t’o wa ninu igba-aya l’o n fo
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠ
Won si n kan o loju fun iya naa. Allahu ko si nii yapa adehun Re. Dajudaju ojo kan lodo Oluwa re da bi egberun odun ninu ohun ti e n ka (ni onka). Allahu (subhanahu wa ta’ala) n so nipa idi ti iya ko fi tete sokale le awon alaigbagbo lori pe ti Oun ba so fun won pe aaro ola ni ojo iya won (bi apeere) dipo egberun odun. Kiye si i ninu ayah ojo kan elegberun odun o tun le je oke meji aabo odun yala nile yii tabi lojo Ajinde
ﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬ
Meloo meloo ninu ilu ti Mo lo lara, ti won je alabosi. Leyin naa, Mo gba won mu. Odo Mi si ni abo eda
ﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵ
So pe: "Eyin eniyan, emi ma ni olukilo ponnbele fun yin
ﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾ
Nitori naa, awon t’o ba gbagbo ni ododo, ti won si se ise rere, aforijin ati arisiki alapon-onle n be fun won
ﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇ
Awon t’o se ise buruku nipa awon ayah Wa, (ti won lero pe) awon mori bo ninu iya; awon wonyen ni ero inu ina Jehim
ﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤ
A ko ran Ojise kan tabi Anabi kan nise siwaju re afi ki o je pe nigba ti o ba soro, Esu maa ju (nnkan) sinu oro re. Nitori naa, Allahu yoo pa ohun ti Esu n ju sinu re re. Leyin naa, O maa fi ododo awon ayah Re rinle. Allahu si ni Onimo, Ologbon. won ko ni imo oloookan nipa al-Ƙur’an ati hadith sugbon won mo iro funfun balau pa mo esin ’Islam. Ise won yii si se weku oro ti Allahu (subhanahu wa ta’ala) so nipa won ninu surah al-Baƙorah; 2: 78. eni ti Esu ba n gbenu re soro bi ko je were ti ko se e fi se eri afi hadith eyo kan pere. Iyen ni pe gbogbo hadith t’o n so nipa pe Anabi (sollalahu alayhi wa sallam) so pe “Iwonyen ni awon eye agba. Ati pe ireti wa ninu isipe ti won maa se.” je hadith t’o le patapata. Amo eyi ti o fese rinle ninu won ko tayo eyi ti o wa ninu sohihu-l-Bukoriy egbawa Bukoriy ti yanju oro naa. Ko si si oro “awon eye agba meta” kan kan ninu re. Nitori naa hadith ko baa le ni igba lori oro kan naa
ﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗ
(Eyi n sele) nitori ki (Allahu) le fi ohun ti Esu n ju (sinu re) se adanwo fun awon ti aisan n be ninu okan won ati awon ti okan won le. Dajudaju awon alabosi si wa ninu iyapa t’o jinna (si ododo)
ﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮ
(Eyi n sele) nitori ki awon ti A fun ni imo le mo pe dajudaju al- Ƙur’an je ododo lati odo Oluwa re. Nitori naa, won yo si gbagbo ninu re, okan won yo si bale si i. Dajudaju Allahu l’O n fi ese awon t’o gbagbo ni ododo rinle soju ona taara (’Islam)
ﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿ
Awon t’o sai gbagbo ko si nii ye wa ninu iyemeji nipa re titi Akoko naa yoo fi de ba won ni ojiji tabi (titi) iya ojo iparun yoo fi de ba won
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞ
Gbogbo ijoba ojo yen n je ti Allahu ti O maa sedajo laaarin won. Nitori naa, awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere, (won yoo wa) ninu awon Ogba Idera
ﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧ
Awon t’o si sai gbagbo, ti won tun pe awon ayah Wa niro; awon wonyen ni iya ti i yepere eda si wa fun
ﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻ
Awon ti won gbe ilu won ju sile nitori esin Allahu, leyin naa, ti won pa won tabi ti won ku; dajudaju Allahu yoo pese fun won ni ipese t’o dara. Dajudaju Allahu, O ma l’oore julo ninu awon olupese
ﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄ
Dajudaju (Allahu) yoo fi won si aye kan ti won yoo yonu si. Dajudaju Allahu ma ni Onimo, Alafarada
ﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘ
Iyen (niyen). Enikeni ti o ba si gbesan iru iya ti won fi je e, leyin naa ti won ba tun sabosi si i, dajudaju Allahu yoo saranse fun un. Dajudaju Allahu ma ni Alamojuukuro, Alaforijin
ﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨ
Iyen nitori pe dajudaju Allahu n fi oru bo inu osan, O si n fi osan bo inu oru. Allahu si ni Olugbo, Oluriran
ﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛ
Iyen nitori pe dajudaju Allahu, Oun ni Ododo. Ati pe dajudaju ohun ti won n pe leyin Re ni iro. Dajudaju Allahu, Oun ni O ga, O tobi
ﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬ
Se o o ri i pe dajudaju Allahu n so omi kale lati sanmo, ile si maa loraa wa? Dajudaju Allahu ni Alaaanu, Alamotan
ﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺ
TiRe ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile. Dajudaju Allahu, Oun ma ni Oloro, Olope
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭ
Se o o ri i pe dajudaju Allahu ro ohunkohun t’o wa ninu ile fun yin, ati oko oju-omi t’o n rin ninu agbami odo pelu iyonda Re, O n mu sanmo dani ti ko fi jabo ayafi pelu iyonda Re? Dajudaju Allahu ma ni Alaaanu, Onikee fun awon eniyan
ﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹ
Oun si ni Eni t’O se yin ni alaaye, leyin naa O n so yin di oku, leyin naa O maa so yin di alaaye. Dajudaju eniyan ma ni alaimoore
ﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎ
Ijo kookan l’A fun ni ilana ti won maa lo. Nitori naa, ki won ma se ja o niyan nipa oro naa. Ki o si pepe sodo Oluwa re. Dajudaju o kuku wa loju ona taara
ﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖ
Ti won ba si ja o niyan, so nigba naa pe: "Allahu nimo julo nipa ohun ti e n se nise
ﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠ
Allahu maa sedajo laaarin yin ni Ojo Ajinde nipa ohun ti e n yapa enu si
ﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖ
Se o o mo pe dajudaju Allahu l’O mo ohun ti n be ninu sanmo ati ile? Dajudaju (akosile) iyen wa ninu tira kan. Dajudaju iyen rorun fun Allahu
ﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪ
Dipo (ki won josin fun) Allahu, won n josin fun ohun ti (Allahu) ko so eri kan kale fun ati ohun ti ko si imo kan fun won lori re. Ko si nii si alaranse kan fun awon alabosi
ﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆﰇﰈﰉﰊﰋﰌ
Nigba ti won ba n ke awon ayah Wa t’o yanju fun won, o maa ri ikoro-oju ninu oju awon t’o sai gbagbo; won yo si fee fowo inira kan awon ti n ke awon ayah Wa fun won. So pe: "Se ki ng fun yin ni iro ohun t’o buru ju iyen? Ina ti Allahu seleri re fun awon t’o sai gbagbo ni. Ikangun naa si buru
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰ
Eyin eniyan, Won fi akawe kan lele. Nitori naa, e teti si i. Dajudaju awon ti e n pe leyin Allahu, won ko le da esinsin kan, won ibaa para po lati se bee. Ti esinsin ba si gba kini kan mo won lowo, won ko le gba a pada lowo re. Ole ni eni ti n wa nnkan (lodo orisa) ati (orisa) ti won n wa nnkan lodo re
ﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻ
Won ko bu owo fun Allahu ni owo ti o to si I. Dajudaju Allahu ma ni Alagbara, Olubori
ﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈ
Allahu l’O n sa awon kan lesa (lati je) Ojise ninu awon molaika ati ninu awon eniyan. Dajudaju Allahu ni Olugbo, Oluriran
ﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔ
O mo ohun ti n be niwaju won ati ni eyin won. Odo Allahu si ni won maa seri awon oro eda pada si
ﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e dawo te orunkun (lori irun), e fori kanle, e josin fun Oluwa yin, ki e si se rere nitori ki e le jere
ﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴ
E jagun fun esin Allahu ni ona eto ti e le gba jagun fun Un. Oun l’O sa yin lesa, ko si ko idaamu kan kan ba yin ninu esin. (E tele) esin baba yin (Anabi) ’Ibrohim. (Allahu) l’O so yin ni musulumi siwaju (asiko yii) ati ninu (al-Ƙur’an) yii nitori ki Ojise le je elerii fun yin ati nitori ki eyin naa le je elerii fun awon eniyan. Nitori naa, e kirun, e yo Zakah, ki e si ba Allahu duro. Oun ni Alaabo yin. O dara ni Alaabo. O si dara ni Alaranse

Al-Kur'an


Tuesday, August 18, 2026

Don't forget us in your sincere prayers