La sourate Maryam en Yoruba
كهيعص(1) Kaf ha ya ‘aen sod. iya ‘Isa (’alaehi-ssolatu wa-ssalam) Oun l’O sa a lesa. Tohun ti bee naa iba ti so awon ododo wonyen nipa Moryam iya Jesu. Sebi won kuku fi enu abuku kan Moryam eda ni awon miiran ti Allahu fi sori awon surah oro Re. A kuku ri surah Muhammad gege bi a se ri surah Moryam. Amo iya ‘Isa so surah l’o maa so ‘Isa tabi iya re di oluwa ati olugbala? Tabi se nitori pe won fi oruko Moryam iya ‘Isa so surah l’o so ‘Isa tabi iya re di olohun omo? Tabi se nitori pe won fi oruko Moryam sise ti Allahu (subhanahu wa ta’ala) se Moryam ni esa eniyan amo ti Allahu ko se iya ati baba Anabi wa bee ti Allahu fi sori ebi Moryam a kuku ri surah Ƙuraes |
(Eyi ni) iranti nipa ike ti Oluwa Re se fun erusin Re, (Anabi) Zakariyya |
(Ranti) nigba ti o pe Oluwa re ni ipe ikoko |
O so pe: "Oluwa mi, dajudaju eegun ara mi ti le, ori (mi) ti kun fun ewu, emi ko si nii pasan nipa bi mo se n pe O, Oluwa mi |
Ati pe dajudaju mo n paya awon ibatan mi leyin (iku) mi. Iyawo mi si je agan. Nitori naa, ta mi lore lati odo Re omo rere kan |
يَرِثُنِي وَيَرِثُ مِنْ آلِ يَعْقُوبَ ۖ وَاجْعَلْهُ رَبِّ رَضِيًّا(6) (ti) o maa jogun mi, ti o si maa jogun awon ebi (Anabi) Ya‘ƙub. Ki O si se e ni eni ti O yonu si, Oluwa mi |
يَا زَكَرِيَّا إِنَّا نُبَشِّرُكَ بِغُلَامٍ اسْمُهُ يَحْيَىٰ لَمْ نَجْعَل لَّهُ مِن قَبْلُ سَمِيًّا(7) Zakariyya, dajudaju Awa maa fun o ni iro idunnu (nipa bibi) omokunrin kan, oruko re ni Yahya. A o fun eni kan ni (iru) oruko (yii) ri siwaju (re) |
O so pe: "Oluwa mi, bawo ni mo se maa ni omo nigba ti iyawo mi je agan, ti mo si ti di agbalagba gan-an |
قَالَ كَذَٰلِكَ قَالَ رَبُّكَ هُوَ عَلَيَّ هَيِّنٌ وَقَدْ خَلَقْتُكَ مِن قَبْلُ وَلَمْ تَكُ شَيْئًا(9) (Molaika) so pe: “Bayen ni (o maa ri).” Oluwa re so pe: “O rorun fun Mi. Mo kuku da iwo naa siwaju (re), nigba ti iwo ko ti i je nnkan kan.” |
قَالَ رَبِّ اجْعَل لِّي آيَةً ۚ قَالَ آيَتُكَ أَلَّا تُكَلِّمَ النَّاسَ ثَلَاثَ لَيَالٍ سَوِيًّا(10) (Zakariyya) so pe: “Oluwa mi, fun mi ni ami kan.” (Molaika) so pe: "Ami re ni pe, o o nii le ba eniyan soro fun ojo meta, ki i se ti amodi |
فَخَرَجَ عَلَىٰ قَوْمِهِ مِنَ الْمِحْرَابِ فَأَوْحَىٰ إِلَيْهِمْ أَن سَبِّحُوا بُكْرَةً وَعَشِيًّا(11) Nigba naa, o jade si awon eniyan re lati inu ile ijosin. O si toka si won pe ki won maa se afomo (fun Allahu) ni owuro ati ni asale |
يَا يَحْيَىٰ خُذِ الْكِتَابَ بِقُوَّةٍ ۖ وَآتَيْنَاهُ الْحُكْمَ صَبِيًّا(12) Yahya, mu Tira naa dani daradara. A si fun un ni agboye esin lati kekere |
(Anabi Yahya je) ike ati eni mimo kan lati odo Wa. O si je oluberu (Allahu) |
(O tun je) oniwa rere si awon obi re mejeeji. Ko si je ajeninipa, oluyapa |
وَسَلَامٌ عَلَيْهِ يَوْمَ وُلِدَ وَيَوْمَ يَمُوتُ وَيَوْمَ يُبْعَثُ حَيًّا(15) Alaafia ni fun un ni ojo ti won bi i, ati ni ojo ti o maa ku ati ni ojo ti A oo gbe e dide laaye (ni Ojo Ajinde) |
وَاذْكُرْ فِي الْكِتَابِ مَرْيَمَ إِذِ انتَبَذَتْ مِنْ أَهْلِهَا مَكَانًا شَرْقِيًّا(16) So itan Moryam ti o wa ninu al-Ƙur’an. (Ranti) nigba ti o yera kuro lodo awon eniyan re si aye kan ni ila oorun |
O mu gaga kan (lati fi ara re pamo) fun won. A si ran molaika Wa si i. O si fara han an ni aworan abara pipe |
قَالَتْ إِنِّي أَعُوذُ بِالرَّحْمَٰنِ مِنكَ إِن كُنتَ تَقِيًّا(18) (Moryam) so pe: “Emi sa di Ajoke-aye kuro lodo re, ti o ba je oluberu (Allahu).” |
قَالَ إِنَّمَا أَنَا رَسُولُ رَبِّكِ لِأَهَبَ لَكِ غُلَامًا زَكِيًّا(19) (Molaika) so pe: “Emi ni Ojise Oluwa re, (O ran mi si o) pe ki ng fun o ni omokunrin mimo kan.” |
قَالَتْ أَنَّىٰ يَكُونُ لِي غُلَامٌ وَلَمْ يَمْسَسْنِي بَشَرٌ وَلَمْ أَكُ بَغِيًّا(20) O so pe: "Bawo ni mo se maa ni omo nigba ti abara kan ko fowo kan mi, ti emi ko si je alagbere |
(Molaika) so pe: “Bayen l’o maa ri.” Oluwa re so pe: “O rorun fun mi. Ati pe nitori ki A le se e ni ami fun awon eniyan ni. O si je ike lati odo Wa. O tun je oro ti A ti pari.” |
Nitori naa, o loyun re. O si yera pelu re si aye kan t’o jinna |
Irobi omo si mu un wa si idi igi dabinu. O so pe: “Haa! Ki ng ti ku siwaju eyi, ki ng si ti di eni ti won ti gbagbe patapata.” |
فَنَادَاهَا مِن تَحْتِهَا أَلَّا تَحْزَنِي قَدْ جَعَلَ رَبُّكِ تَحْتَكِ سَرِيًّا(24) Nigba naa, (molaika) pe e lati isale odo re pe: "Ma se banuje. Dajudaju Oluwa re ti se odo kekere kan si isale odo re |
وَهُزِّي إِلَيْكِ بِجِذْعِ النَّخْلَةِ تُسَاقِطْ عَلَيْكِ رُطَبًا جَنِيًّا(25) Mi igi dabinu naa sodo re, ki dabinu tutu, to to ka je si maa jabo sile fun o |
Nitori naa, je, mu ki oju re si tutu. Ti o ba si ri eni kan ninu abara, so fun un pe: "Dajudaju mo jejee ikenuro fun Ajoke-aye. Nitori naa, mi o nii ba eniyan kan soro ni oni |
فَأَتَتْ بِهِ قَوْمَهَا تَحْمِلُهُ ۖ قَالُوا يَا مَرْيَمُ لَقَدْ جِئْتِ شَيْئًا فَرِيًّا(27) O si mu omo naa wa ba awon eniyan re (ni eni ti) o gbe e dani. Won so pe: "Moryam, dajudaju o ti gbe nnkan aburu nla wa |
يَا أُخْتَ هَارُونَ مَا كَانَ أَبُوكِ امْرَأَ سَوْءٍ وَمَا كَانَتْ أُمُّكِ بَغِيًّا(28) Arabinrin Harun, baba re ki i se eniyan buruku. Ati pe iya re ki i se alagbere |
فَأَشَارَتْ إِلَيْهِ ۖ قَالُوا كَيْفَ نُكَلِّمُ مَن كَانَ فِي الْمَهْدِ صَبِيًّا(29) O si toka si omo naa. Won so pe: “Bawo ni a o se ba eni t’o wa lori ite, t’o je omo oponlo soro?” |
قَالَ إِنِّي عَبْدُ اللَّهِ آتَانِيَ الْكِتَابَ وَجَعَلَنِي نَبِيًّا(30) (Omo naa) soro pe: "Dajudaju eru Allahu ni emi. (Allahu) fun mi ni Tira. O si se mi ni Anabi. eda ti o n bowo fun ilana ati ofin Olohun eda ti o juwo juse sile fun ilana ati ofin Olohun ati eda ti o n josin fun Olohun labe ilana ati ofin Olohun. Eda naa ko si nii yonu si ilana ati ofin miiran t’o yato si ti Olohun.” Eni ti o ba n se iwonyen fun ohun miiran tabi elomiiran but with my flesh I am a slave to the law of sin.” Itumo: “Nitori naa nigba naa pelu emi mi pelu okan ati ara wa ni a fi gba lati wa labe ofin Re. Iwonba asise ti a ba si fi ara se gege bi adamo eniyan ironupiwada ati itoro aforijin ni odo Allahu ni ona abayo lori re. Alaforijin |
وَجَعَلَنِي مُبَارَكًا أَيْنَ مَا كُنتُ وَأَوْصَانِي بِالصَّلَاةِ وَالزَّكَاةِ مَا دُمْتُ حَيًّا(31) O se mi ni eni ibukun ni ibikibi ti mo ba wa. O pa mi lase irun kiki ati Zakah yiyo lodiwon igba ti mo ba wa nipo alaaye (lori ile aye) |
وَبَرًّا بِوَالِدَتِي وَلَمْ يَجْعَلْنِي جَبَّارًا شَقِيًّا(32) (O se mi ni) oniwa rere si iya mi. Ko si se mi ni ajeninipa, olori buruku |
وَالسَّلَامُ عَلَيَّ يَوْمَ وُلِدتُّ وَيَوْمَ أَمُوتُ وَيَوْمَ أُبْعَثُ حَيًّا(33) Alaafia ni fun mi ni ojo ti won bi mi, ati ni ojo ti mo maa ku ati ni ojo ti Won a gbe mi dide ni alaaye (ni Ojo Ajinde) |
ذَٰلِكَ عِيسَى ابْنُ مَرْيَمَ ۚ قَوْلَ الْحَقِّ الَّذِي فِيهِ يَمْتَرُونَ(34) Iyen ni (Anabi) ‘Isa omo Moryam. (Eyi je) oro ododo ti awon (yehudi ati nasara) n seyemeji nipa re |
Ko ye fun Allahu lati so eni kan kan di omo. Mimo ni fun Un. Nigba ti O ba pebubu kini kan, O kan maa so fun un pe: "Je bee." O si maa je bee |
وَإِنَّ اللَّهَ رَبِّي وَرَبُّكُمْ فَاعْبُدُوهُ ۚ هَٰذَا صِرَاطٌ مُّسْتَقِيمٌ(36) Ati pe dajudaju Allahu ni Oluwa mi ati Oluwa yin. Nitori naa, e josin fun Un. Eyi ni ona taara |
فَاخْتَلَفَ الْأَحْزَابُ مِن بَيْنِهِمْ ۖ فَوَيْلٌ لِّلَّذِينَ كَفَرُوا مِن مَّشْهَدِ يَوْمٍ عَظِيمٍ(37) Awon ijo (yehudi ati nasara) si yapa enu (si eyi) laaarin ara won. Nitori naa, egbe ni fun awon t’o sai gbagbo (ni asiko) ijerii gbangba lojo nla (Ojo Ajinde) |
Ki ni won ko nii gbo, ki si ni won ko nii ri ni ojo ti won yoo wa ba Wa! Sugbon awon alabosi ni ojo naa ti wa ninu isina ponnbele |
وَأَنذِرْهُمْ يَوْمَ الْحَسْرَةِ إِذْ قُضِيَ الْأَمْرُ وَهُمْ فِي غَفْلَةٍ وَهُمْ لَا يُؤْمِنُونَ(39) Sekilo ojo abamo fun won nigba ti A ba pari oro, (pe ko nii si iku mo, amo) won wa ninu igbagbera bayii na, won ko si gbagbo |
إِنَّا نَحْنُ نَرِثُ الْأَرْضَ وَمَنْ عَلَيْهَا وَإِلَيْنَا يُرْجَعُونَ(40) Dajudaju Awa l’A maa jogun ile ati awon t’o n be lori re. Odo Wa si ni won yoo da yin pada si |
وَاذْكُرْ فِي الْكِتَابِ إِبْرَاهِيمَ ۚ إِنَّهُ كَانَ صِدِّيقًا نَّبِيًّا(41) Mu (itan) ’Ibrohim wa si iranti (bi o se) wa ninu al-Ƙur’an. Dajudaju o je olododo ponnbele, (o si je) Anabi |
Ranti nigba ti o so fun baba re pe: "Baba mi, nitori ki ni o fi n josin fun ohun ti ko gboro, ti ko riran, ti ko si le ro o loro kan kan |
Baba mi, dajudaju imo ti iwo ko ni ti de ba mi. Nitori naa, tele mi, ki ng fi ona taara mo o |
يَا أَبَتِ لَا تَعْبُدِ الشَّيْطَانَ ۖ إِنَّ الشَّيْطَانَ كَانَ لِلرَّحْمَٰنِ عَصِيًّا(44) Baba mi, ma se bo Esu. Dajudaju Esu je oluyapa ase Ajoke-aye |
يَا أَبَتِ إِنِّي أَخَافُ أَن يَمَسَّكَ عَذَابٌ مِّنَ الرَّحْمَٰنِ فَتَكُونَ لِلشَّيْطَانِ وَلِيًّا(45) Baba mi, dajudaju emi n paya pe ki iya kan lati odo Ajoke-aye ma fowo ba o nitori ki iwo ma baa di ore Esu (ninu Ina) |
(Baba re) wi pe: “Se iwo yoo ko awon olohun mi sile ni, ’Ibrohim? Dajudaju ti o o ba jawo (ninu ohun ti o n so), dajudaju mo maa le o loko pa. Tie yera fun mi woorowo na.” |
قَالَ سَلَامٌ عَلَيْكَ ۖ سَأَسْتَغْفِرُ لَكَ رَبِّي ۖ إِنَّهُ كَانَ بِي حَفِيًّا(47) (’Ibrohim) so pe: "Alaafia ki o maa ba o. Mo maa ba o toro aforijin lodo Oluwa mi. Dajudaju O je Oloore mi |
Ati pe mo maa yera fun eyin ati nnkan ti e n josin fun leyin Allahu. Emi yo si maa pe Oluwa mi. O si sunmo pe emi ko nii pasan pelu adua mi si Oluwa mi |
Nigba ti o yera fun awon ati nnkan ti won n josin fun leyin Allahu, A si ta a lore (omo), ’Ishaƙ ati Ya‘ƙub (omoomo). A si se okookan won ni Anabi |
وَوَهَبْنَا لَهُم مِّن رَّحْمَتِنَا وَجَعَلْنَا لَهُمْ لِسَانَ صِدْقٍ عَلِيًّا(50) Ati pe A ta won lore lati inu ike Wa. A si ni ki won maa soro won ni daadaa |
وَاذْكُرْ فِي الْكِتَابِ مُوسَىٰ ۚ إِنَّهُ كَانَ مُخْلَصًا وَكَانَ رَسُولًا نَّبِيًّا(51) So itan (Anabi) Musa ti o wa ninu al-Ƙur’an. Dajudaju o je eni-esa, o je Ojise, (o tun je) Anabi |
وَنَادَيْنَاهُ مِن جَانِبِ الطُّورِ الْأَيْمَنِ وَقَرَّبْنَاهُ نَجِيًّا(52) A pe e ni eba apata ni apa owo otun (Musa). A si mu un sunmo tosi lati ba a soro |
وَوَهَبْنَا لَهُ مِن رَّحْمَتِنَا أَخَاهُ هَارُونَ نَبِيًّا(53) Lati inu ike Wa A si fi arakunrin re, Harun, (ti o je) Anabi, ta a lore |
وَاذْكُرْ فِي الْكِتَابِ إِسْمَاعِيلَ ۚ إِنَّهُ كَانَ صَادِقَ الْوَعْدِ وَكَانَ رَسُولًا نَّبِيًّا(54) So itan (Anabi) ’Ismo‘il ti o wa ninu al-Ƙur’an. Dajudaju o je olumu-adehun-se, o je Ojise, (o tun je) Anabi |
وَكَانَ يَأْمُرُ أَهْلَهُ بِالصَّلَاةِ وَالزَّكَاةِ وَكَانَ عِندَ رَبِّهِ مَرْضِيًّا(55) O maa n pa ara ile re ni ase irun kiki ati Zakah yiyo. O si je eni iyonu lodo Oluwa re |
وَاذْكُرْ فِي الْكِتَابِ إِدْرِيسَ ۚ إِنَّهُ كَانَ صِدِّيقًا نَّبِيًّا(56) So itan (Anabi) ’Idris ti o wa ninu al-Ƙur’an. Dajudaju o je olododo ponnbele, (o si je) Anabi |
A si gbe e si aye giga (ninu sanmo) |
Awon wonyen ni awon ti Allahu se idera fun ninu awon Anabi, ninu awon aromodomo (Anabi) Adam ati ninu awon ti A gbe gun oko oju-omi pelu (Anabi) Nuh ati ninu aromodomo (Anabi) ’Ibrohim ati ’Isro’il ati ninu awon ti A ti fi mona, ti A si sa lesa. Nigba ti won ba n ke awon ayah Ajoke-aye fun won, won maa doju bole; ti won a forikanle, ti won a si maa sunkun |
Awon arole kan si role leyin won, ti won ra irun kiki lare, ti won tele awon yodoyindin emi. Laipe won maa pade iparun (ninu Ina) |
Ayafi eni ti o ba ronu piwada, ti o gbagbo ni ododo, ti o si se ise rere. Awon wonyen ni won yoo wo inu Ogba Idera. A o si nii sabosi kan kan si won |
(Won yoo wo inu) awon Ogba Idera gbere ti Ajoke-aye se ni adehun si ipamo fun awon erusin Re. Dajudaju (Allahu), adehun Re n bo wa se |
لَّا يَسْمَعُونَ فِيهَا لَغْوًا إِلَّا سَلَامًا ۖ وَلَهُمْ رِزْقُهُمْ فِيهَا بُكْرَةً وَعَشِيًّا(62) Won ko nii gbo isokuso ninu re afi alaafia. Ije-imu won wa ninu re ni owuro ati ni asale |
تِلْكَ الْجَنَّةُ الَّتِي نُورِثُ مِنْ عِبَادِنَا مَن كَانَ تَقِيًّا(63) Iyen ni Ogba Idera ti A oo jogun re fun eni ti o je oluberu (Mi) ninu awon erusin Wa |
Awa (molaika) ki i sokale ayafi pelu ase Oluwa re. TiRe ni ohun ti n be niwaju wa, ohun ti n be ni eyin wa ati ohun ti n be laaarin (mejeeji) yii. Oluwa re ki i si se onigbagbe |
Oluwa awon sanmo ati ile ati ohun ti n be laaarin awon mejeeji. Nitori naa, josin fun Un, ki o si se suuru lori ijosin Re. Nje o mo eni ti o tun n je oruko Re |
وَيَقُولُ الْإِنسَانُ أَإِذَا مَا مِتُّ لَسَوْفَ أُخْرَجُ حَيًّا(66) Eniyan n wi pe: “Se nigba ti mo ba ku, Won yoo tun mu mi jade laipe ni alaaye?” |
أَوَلَا يَذْكُرُ الْإِنسَانُ أَنَّا خَلَقْنَاهُ مِن قَبْلُ وَلَمْ يَكُ شَيْئًا(67) Se eniyan ko ranti pe dajudaju Awa ni A seda re teletele nigba ti ko ti i je nnkan kan |
فَوَرَبِّكَ لَنَحْشُرَنَّهُمْ وَالشَّيَاطِينَ ثُمَّ لَنُحْضِرَنَّهُمْ حَوْلَ جَهَنَّمَ جِثِيًّا(68) Nitori naa, mo fi Oluwa re bura; dajudaju A maa ko awon ati awon esu jo. Leyin naa, dajudaju A maa mu won wa si ayika ina Jahanamo lori ikunle |
ثُمَّ لَنَنزِعَنَّ مِن كُلِّ شِيعَةٍ أَيُّهُمْ أَشَدُّ عَلَى الرَّحْمَٰنِ عِتِيًّا(69) Leyin naa, dajudaju A maa mu jade ninu ijo kookan eyikeyii ninu won ti o le julo ni ese dida si Ajoke-aye |
ثُمَّ لَنَحْنُ أَعْلَمُ بِالَّذِينَ هُمْ أَوْلَىٰ بِهَا صِلِيًّا(70) Leyin naa, dajudaju Awa nimo julo nipa awon t’o letoo si wiwo inu Ina |
وَإِن مِّنكُمْ إِلَّا وَارِدُهَا ۚ كَانَ عَلَىٰ رَبِّكَ حَتْمًا مَّقْضِيًّا(71) Ko si eni kan ninu yin afi ki o debe. O je isele dandan lodo Oluwa re. 74:30-31. Bakan naa, kalmoh “warid” t’o jeyo ninu ayah 71 je oro-oruko ti won seda lati ara oro-ise “warada”. Ninu al-Ƙur’an, itumo meji pere l’o wa fun “warada”. “Warada” tumo si “o de si ibi ti kini kan wa, o si wo inu nnkan naa”, gege bi itumo yii se wa ninu surah Hud 11:98 ati surah al-’Anbiya’ |
ثُمَّ نُنَجِّي الَّذِينَ اتَّقَوا وَّنَذَرُ الظَّالِمِينَ فِيهَا جِثِيًّا(72) igun kiini keji maa wa labe akorin awon molaika kan ni. Iyen ni pe awon molaika kan l’o maa ko gbogbo eda lo sori afara Ina nitori pe |
Nigba ti won ba n ke awon ayah Wa t’o yanju fun won, awon t’o sai gbagbo yoo so fun awon t’o gbagbo ni ododo pe: “Ewo ninu ijo mejeeji (awa tabi eyin) l’o loore julo ni ibugbe, l’o si dara julo ni ijokoo?” |
وَكَمْ أَهْلَكْنَا قَبْلَهُم مِّن قَرْنٍ هُمْ أَحْسَنُ أَثَاثًا وَرِئْيًا(74) Ati pe meloo meloo ninu awon iran ti A ti pare siwaju won, ti won dara julo ni oro (aye) ati ni irisi |
So pe: “Eni ti o ba wa ninu isina, Ajoke-aye yo si fe (isina) loju fun un taara, titi di igba ti won maa ri ohun ti won n se ni adehun fun won, yala iya tabi Akoko naa. Nigba naa, won yoo mo eni ti o buru julo ni ipo, ti o si le julo ni omo ogun |
Allahu yo si salekun imona fun awon t’o mona. Awon ise rere elesan gbere loore julo ni esan, o si loore julo ni ibudesi lodo Oluwa re |
أَفَرَأَيْتَ الَّذِي كَفَرَ بِآيَاتِنَا وَقَالَ لَأُوتَيَنَّ مَالًا وَوَلَدًا(77) So fun mi nipa eni t’o sai gbagbo ninu awon ayah Wa, ti o si wi pe: “Dajudaju won yoo fun mi ni dukia ati omo!” |
أَطَّلَعَ الْغَيْبَ أَمِ اتَّخَذَ عِندَ الرَّحْمَٰنِ عَهْدًا(78) Se o ri ikoko ni tabi o ri adehun kan gba lodo Ajoke-aye |
كَلَّا ۚ سَنَكْتُبُ مَا يَقُولُ وَنَمُدُّ لَهُ مِنَ الْعَذَابِ مَدًّا(79) Rara. A maa sakosile ohun t’o n wi. A si maa fe iya loju fun un taara |
A o si jogun ohun t’o n wi fun un. O si maa wa ba Wa ni oun nikan |
وَاتَّخَذُوا مِن دُونِ اللَّهِ آلِهَةً لِّيَكُونُوا لَهُمْ عِزًّا(81) Won so awon kan di olohun leyin Allahu nitori ki won le fun won ni agbara |
كَلَّا ۚ سَيَكْفُرُونَ بِعِبَادَتِهِمْ وَيَكُونُونَ عَلَيْهِمْ ضِدًّا(82) Rara. Won maa tako ijosin won, won si maa di ota won |
أَلَمْ تَرَ أَنَّا أَرْسَلْنَا الشَّيَاطِينَ عَلَى الْكَافِرِينَ تَؤُزُّهُمْ أَزًّا(83) Se o o ri i pe dajudaju Awa n ran awon esu si awon alaigbagbo ni, ti won si n ti won ni itikuti (sibi ese) |
فَلَا تَعْجَلْ عَلَيْهِمْ ۖ إِنَّمَا نَعُدُّ لَهُمْ عَدًّا(84) Nitori naa, ma se kanju nipa (iya) won. A kuku n ka (ojo) fun won ni kika taara |
يَوْمَ نَحْشُرُ الْمُتَّقِينَ إِلَى الرَّحْمَٰنِ وَفْدًا(85) (Ranti) ojo ti A oo ko awon oluberu (Allahu) jo sodo Ajoke-aye lori nnkan igun |
A si maa da awon elese lo sinu ina Jahanamo witiwiti |
لَّا يَمْلِكُونَ الشَّفَاعَةَ إِلَّا مَنِ اتَّخَذَ عِندَ الرَّحْمَٰنِ عَهْدًا(87) Won ko nii ni ikapa isipe afi eni ti o ba gba adehun lati odo Ajoke-aye |
Won wi pe: "Ajoke-aye fi eni kan se omo |
Dajudaju e ti mu nnkan aburu wa |
تَكَادُ السَّمَاوَاتُ يَتَفَطَّرْنَ مِنْهُ وَتَنشَقُّ الْأَرْضُ وَتَخِرُّ الْجِبَالُ هَدًّا(90) Awon sanmo fere faya perepere nitori re, ile fere faya perepere, awon apata si fere da wo lule gbi |
fun wi pe won pe eni kan ni omo Ajoke-aye |
Ko si ye fun Ajoke-aye lati fi eni kan se omo |
إِن كُلُّ مَن فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ إِلَّا آتِي الرَّحْمَٰنِ عَبْدًا(93) Ko si eni kan ninu awon sanmo ati ile ayafi ki o wa ba Ajoke-aye ni ipo erusin |
Dajudaju (Allahu) mo won. O si ka onka won taara |
Gbogbo won yo si wa ba A ni Ojo Ajinde ni ikookan |
إِنَّ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ سَيَجْعَلُ لَهُمُ الرَّحْمَٰنُ وُدًّا(96) Dajudaju awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se ise rere, Ajoke-aye yoo fi ife saaarin won |
فَإِنَّمَا يَسَّرْنَاهُ بِلِسَانِكَ لِتُبَشِّرَ بِهِ الْمُتَّقِينَ وَتُنذِرَ بِهِ قَوْمًا لُّدًّا(97) Nitori naa, A kuku se kike al-Ƙur’an ni irorun (fun o) pelu ede abinibi re nitori ki o le fi se iro idunnu fun awon oluberu (Allahu) ati nitori ki o le fi se ikilo fun ijo oniyan-jija |
Meloo meloo ninu iran ti A ti pare siwaju won! Nje o gbo iro eni kan kan ninu won mo tabi (nje) o gbo ohun kelekele kan lati odo won bi |
Plus de sourates en Yoruba :
Téléchargez la sourate avec la voix des récitants du Coran les plus célèbres :
Téléchargez le fichier mp3 de la sourate Maryam : choisissez le récitateur pour écouter et télécharger la sourate Maryam complète en haute qualité.
Ahmed Al Ajmy
Bandar Balila
Khalid Al Jalil
Saad Al Ghamdi
Saud Al Shuraim
Abdul Basit
Abdul Rashid Sufi
Abdullah Basfar
Abdullah Al Juhani
Fares Abbad
Maher Al Muaiqly
Al Minshawi
Al Hosary
Mishari Al-afasi
Yasser Al Dosari
Donnez-nous une invitation valide