Surah An-Nahl with Yoruba
أَتَىٰ أَمْرُ اللَّهِ فَلَا تَسْتَعْجِلُوهُ ۚ سُبْحَانَهُ وَتَعَالَىٰ عَمَّا يُشْرِكُونَ(1) Ase Allahu de tan. E ma wule wa a pelu ikanju. Mimo ni fun Un. O si ga tayo nnkan ti won n fi sebo si I |
(Allahu) n fi ase Re so molaika (Jibril) kale lati maa mu imisi wa diedie fun enikeni ti O ba fe (bee fun) ninu awon erusin Re nitori ki e le fi se ikilo pe: “Dajudaju ko si olohun kan ti ijosin to si afi Emi. Nitori naa, e beru Mi.” |
خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ بِالْحَقِّ ۚ تَعَالَىٰ عَمَّا يُشْرِكُونَ(3) O seda awon sanmo ati ile pelu ododo. O ga tayo nnkan ti won n fi sebo si I |
خَلَقَ الْإِنسَانَ مِن نُّطْفَةٍ فَإِذَا هُوَ خَصِيمٌ مُّبِينٌ(4) O da eniyan lati inu ato. (Eniyan) si di olujiyan ponnbele (nipa Ajinde) |
وَالْأَنْعَامَ خَلَقَهَا ۗ لَكُمْ فِيهَا دِفْءٌ وَمَنَافِعُ وَمِنْهَا تَأْكُلُونَ(5) Awon eran-osin, O seda won. Aso otutu ati awon anfaani (miiran) n be fun yin lara won. Ati pe e n je ninu won |
وَلَكُمْ فِيهَا جَمَالٌ حِينَ تُرِيحُونَ وَحِينَ تَسْرَحُونَ(6) Oso tun n be fun yin lara won nigba ti e ba n da won lo (si ile won) ati nigba ti e ba n ko won jade lo jeko |
Won si n ru awon eru yin t’o wuwo lo si ilu kan ti e o le de afi pelu wahala emi. Dajudaju Oluwa yin ma ni Alaaanu, Onikee |
وَالْخَيْلَ وَالْبِغَالَ وَالْحَمِيرَ لِتَرْكَبُوهَا وَزِينَةً ۚ وَيَخْلُقُ مَا لَا تَعْلَمُونَ(8) (O seda) esin, ibaaka ati ketekete nitori ki e le gun won. (Won tun je) oso. O tun n seda ohun ti e o mo |
وَعَلَى اللَّهِ قَصْدُ السَّبِيلِ وَمِنْهَا جَائِرٌ ۚ وَلَوْ شَاءَ لَهَدَاكُمْ أَجْمَعِينَ(9) Allahu l’O n salaye (’Islam) ona taara. Awon ona esin wiwo tun wa (loto) . Ti O ba fe bee ni, iba to gbogbo yin si ona (esin ’Islam) |
هُوَ الَّذِي أَنزَلَ مِنَ السَّمَاءِ مَاءً ۖ لَّكُم مِّنْهُ شَرَابٌ وَمِنْهُ شَجَرٌ فِيهِ تُسِيمُونَ(10) Oun ni Eni t’O n so omi kale lati sanmo. Mimu wa fun yin ninu re. Igi eweko tun n wu jade lati inu re. E si n fi bo awon eran-osin |
(Allahu) tun n fi (omi yii) hu awon irugbin, igi ororo zaetun, igi dabinu, igi ajara ati gbogbo awon eso (yooku) jade fun yin. Dajudaju ami wa ninu iyen fun ijo t’o ni arojinle |
O ro oru, osan, oorun, osupa ati awon irawo fun yin pelu ase Re. Dajudaju ami wa ninu iyen fun ijo t’o ni laakaye |
Ati ohun ti O tun seda re fun yin lori ile, ti awon awo re je orisirisi. Dajudaju ami wa ninu iyen fun ijo t’o n lo iranti |
Oun ni Eni ti O ro agbami odo nitori ki e le je eran (eja) tutu ati nitori ki e le mu nnkan oso ti e oo maa wo sara jade lati inu (odo), - o si maa ri awon oko oju-omi ti yoo maa la oju omi koja lo bo – ati nitori ki e le wa ninu awon ajulo oore Re ati nitori ki e le dupe (fun Allahu) |
O si fi awon apata t’o duro gbagidi sori ile ki o ma fi le mi mo yin lese ati awon odo ati awon oju-ona nitori ki e le da oju ona mo |
ati awon ami opopona (fun itosona irin osan). Won tun n fi irawo da oju ona mo (lale) |
أَفَمَن يَخْلُقُ كَمَن لَّا يَخْلُقُ ۗ أَفَلَا تَذَكَّرُونَ(17) Nje Eni ti O da eda da bi eni ti ko da eda bi? Nitori naa, se e o nii lo iranti ni |
وَإِن تَعُدُّوا نِعْمَةَ اللَّهِ لَا تُحْصُوهَا ۗ إِنَّ اللَّهَ لَغَفُورٌ رَّحِيمٌ(18) Ti e ba sonka idera Allahu, e ko le ka a tan. Dajudaju Allahu ma ni Alaforijin, Onikee |
Ati pe Allahu mo ohun ti e n fi pamo ati ohun ti e n se afihan re |
وَالَّذِينَ يَدْعُونَ مِن دُونِ اللَّهِ لَا يَخْلُقُونَ شَيْئًا وَهُمْ يُخْلَقُونَ(20) Awon (orisa) ti won n pe leyin Allahu; won ko le da kini kan. Allahu l’O si seda won |
أَمْوَاتٌ غَيْرُ أَحْيَاءٍ ۖ وَمَا يَشْعُرُونَ أَيَّانَ يُبْعَثُونَ(21) Oku (ni won), won ki i se alaaye. Won ko si mo akoko ti A oo gbe won dide. won ki i se alaaye.” ko so iku Anabi ‘Isa omo Moryam (’alaehi-ssolatu wa-ssalam) di ohun t’o ti sele. Sebi awon molaika kan wa lara nnkan ti awon eniyan n josin fun leyin Allahu. Se oku ni awon molaika naa ni tabi alaaye? A o kuku ti i gbo iku molaika kan kan ri. Bakan naa as-Saton ar-Rojim je okan pataki ninu ohun ti awon eniyan n josin fun. Se oku ni Saeton naa ni tabi alaaye? Rara bi Allahu se fe.” Ko wa si eri taara kan kan t’o fi rinle pe Anabi ‘Isa omo Moryam (’alaehi-ssolatu wa-ssalam) ti ku bi ko se ayah oniponna eyi ti a ti se alaye lori re siwaju ninu itose-oro fun surah ali-’Imron 3:55. Dipo ki a ri ayah kan tabi hadith kan taara lori iku Anabi ‘Isa omo Moryam (’alaehi-ssolatu wa-ssalam) hadith t’o n fi ipadabo re rinle l’a n ri. Eni ti ko i ku l’o si le pada wa sile aye. ” ninu ayah naa ki i se itumo adamo. Idi ni pe ere ti ko si emi lara re ni awon orisa naa. Ipo oku eni ti ko le soro |
Olohun yin, Olohun Okan soso ni. Amo awon ti ko ni igbagbo ninu Ojo Ikeyin ni okan won tako o, ti won si n segberaga |
Ko si tabi-sugbon, dajudaju Allahu mo ohun ti won n fi pamo ati ohun ti won n se afihan re. Ati pe dajudaju (Allahu) ko nifee awon onigbeeraga |
وَإِذَا قِيلَ لَهُم مَّاذَا أَنزَلَ رَبُّكُمْ ۙ قَالُوا أَسَاطِيرُ الْأَوَّلِينَ(24) Nigba ti won ba so fun won pe: “Ki ni Oluwa yin sokale? Won a wi pe: “Akosile alo awon eni akoko ni.” |
(Won so bee) nitori ki won le ru eru ese tiwon ni pipe perepere ni Ojo Ajinde ati (nitori ki won le ru) ninu eru ese awon ti won n si lona pelu ainimo. Gbo, ohun ti won yoo ru ni ese, o buru |
Awon t’o siwaju won kuku dete. Allahu si da ile won wo lati ipile. Orule si wo lu won mole lati oke won. Ati pe iya de ba won ni aye ti won ko ti fura |
Leyin naa, ni Ojo Ajinde (Allahu) yoo yepere won. O si maa so pe: “Ibo ni awon (ti e so di) akegbe Mi wa, awon ti e ti tori won yapa (Mi)?” Awon ti A fun ni imo esin yo si so pe: “Dajudaju abuku ati aburu ojo oni wa fun awon alaigbagbo.” |
(Awon ni) awon ti molaika n pa nigba ti won n sabosi si emi ara won lowo. Ni asiko yii ni won juwo juse sile (won si wi pe): “Awa ko se ise aburu kan kan.” Rara (e sise aburu)! Dajudaju Allahu ni Onimo nipa ohun ti e n se nise |
فَادْخُلُوا أَبْوَابَ جَهَنَّمَ خَالِدِينَ فِيهَا ۖ فَلَبِئْسَ مَثْوَى الْمُتَكَبِّرِينَ(29) Nitori naa, e wo awon enu ona Ina lo, olusegbere ni yin ninu re. Ibugbe awon onigbeeraga si buru |
Won so fun awon t’o beru (Allahu) pe: “Ki ni Oluwa yin sokale? Won a wi pe: “Rere ni.” Rere ti wa fun awon t’o se rere ni ile aye yii. Dajudaju Ile Ikeyin loore julo. Ati pe dajudaju ile awon oluberu (Allahu) dara |
Awon Ogba Idera gbere ni won yoo wo inu re. Awon odo yo si maa san ni isale re. Ohunkohun ti won ba n fe maa wa fun won ninu re. Bayen ni Allahu se n san esan rere fun awon oluberu (Re) |
Awon ti molaika n pa, nigba ti won n se rere lowo, (awon molaika) n so pe: “Alaafia fun yin. E wo inu Ogba Idera nitori ohun ti e n se nise.” |
Se won n reti ohun kan yato si pe ki awon molaika wa ba won tabi ki ase Oluwa re de? Bayen ni awon t’o siwaju won ti se. Allahu ko si se abosi si won, sugbon emi ara won ni won n sabosi si |
فَأَصَابَهُمْ سَيِّئَاتُ مَا عَمِلُوا وَحَاقَ بِهِم مَّا كَانُوا بِهِ يَسْتَهْزِئُونَ(34) Nitori naa, awon aburu ohun ti won se nise sele si won. Ati pe ohun ti won n fi se yeye si diya t’o yi won po |
Awon ti won ba Allahu wa akegbe yo si wi pe: “Ti o ba je pe Allahu fe ni awa iba ti josin fun kini kan leyin Re, awa ati awon baba wa. Bakan naa, awa iba ti se kini kan ni eewo leyin Re.” Bayen ni awon t’o siwaju won ti se. Nje ojuse kan wa fun awon Ojise bi ko se ise-jije ponnbele |
Dajudaju A ti gbe Ojise dide ninu ijo kookan (lati jise) pe: “E josin fun Allahu. Ki e si jinna si awon orisa.” Nitori naa, o wa ninu won, eni ti Allahu to si ona. O si wa ninu won, eni ti isina ko le lori. Nitori naa, e rin kiri lori ile, ki e si woye si bi atubotan awon t’o pe awon Ojise ni opuro se ri |
إِن تَحْرِصْ عَلَىٰ هُدَاهُمْ فَإِنَّ اللَّهَ لَا يَهْدِي مَن يُضِلُّ ۖ وَمَا لَهُم مِّن نَّاصِرِينَ(37) Ti o ba n soju kokoro si imona won, eni ti Allahu ba si lona, dajudaju ko nii fi mona, ko si nii si awon alaranse kan kan fun won |
Won si fi Allahu bura ti ibura won si lagbara gan-an pe: “Allahu ko nii gbe eni ti o ku dide.” Ko ri bee, (ajinde je) adehun lodo Allahu. Ododo si ni, sugbon opolopo eniyan ko mo |
(Allahu yoo gbe eda dide) nitori ki O le salaye ohun ti won n yapa enu si fun won ati nitori ki awon t’o sai gbagbo le mo pe dajudaju awon ni won je opuro |
إِنَّمَا قَوْلُنَا لِشَيْءٍ إِذَا أَرَدْنَاهُ أَن نَّقُولَ لَهُ كُن فَيَكُونُ(40) Oro Wa fun kini kan nigba ti A ba gbero re ni pe, A maa so fun un pe: "Je bee." O si maa je bee.” |
Awon t’o gbe ilu won ju sile nitori ti Allahu, leyin ti awon alaigbagbo ti sabosi si won, dajudaju Awa yoo wa ibugbe rere fun won. Esan Ojo Ikeyin si tobi julo, ti o ba je pe (awon ti ko se hijrah) mo |
(Awon ni) awon t’o se suuru, won si n gbarale Oluwa won |
A o ran eni kan ni ise-ojise siwaju re afi awon okunrin ti A n fi imisi ranse si. Nitori naa, e beere lodo awon oniran-anti ti eyin ko ba mo. ki i se awon sufi. Idi ni pe okunfa ayah mejeeji yii ni pe |
(A fi) awon eri t’o yanju ati ipin-ipin Tira (ran won nise). Ati pe A so tira Iranti (iyen, al-Ƙur’an) kale fun o nitori ki o le salaye fun awon eniyan ohun ti A sokale fun won ati nitori ki won le ronu jinle |
Se awon t’o da ete aburu fi okan bale pe Allahu ko le mu ile ri mo won lese ni, tabi pe iya ko le de ba won lati aye ti won ko ti nii fura |
أَوْ يَأْخُذَهُمْ فِي تَقَلُّبِهِمْ فَمَا هُم بِمُعْجِزِينَ(46) Tabi (Allahu) ko le gba won mu lori irinke-rindo won ni? Won ko si nii mori bo |
أَوْ يَأْخُذَهُمْ عَلَىٰ تَخَوُّفٍ فَإِنَّ رَبَّكُمْ لَرَءُوفٌ رَّحِيمٌ(47) Tabi (Allahu) ko le maa gba won mu diedie ni? Nitori naa, dajudaju Oluwa yin ma ni Alaaanu, Onikee |
Ati pe se won ko ri gbogbo nnkan ti Allahu seda re, ti ooji re n pada yo lati otun ati osi ni oluforikanle fun Allahu; ti won si n yepere ara won (fun Un) |
Allahu si ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile ni nnkan abemi ati awon molaika n fori kanle fun. Won ko si segberaga |
يَخَافُونَ رَبَّهُم مِّن فَوْقِهِمْ وَيَفْعَلُونَ مَا يُؤْمَرُونَ ۩(50) Won n paya Oluwa won t’O n be loke won. Won si n se ohun ti A n pa lase fun won |
Allahu so pe: “E ma se josin fun olohun meji. Oun nikan ni Olohun Okan soso ti ijosin to si. Nitori naa, Emi (nikan) ni ki e beru.” |
وَلَهُ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَلَهُ الدِّينُ وَاصِبًا ۚ أَفَغَيْرَ اللَّهِ تَتَّقُونَ(52) TiRe si ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ile. TiRe si ni esin titi laelae Nitori naa, se (nnkan miiran) yato si Allahu ni eyin yoo maa beru ni |
وَمَا بِكُم مِّن نِّعْمَةٍ فَمِنَ اللَّهِ ۖ ثُمَّ إِذَا مَسَّكُمُ الضُّرُّ فَإِلَيْهِ تَجْأَرُونَ(53) Ohunkohun ti e ni ninu idera, lati odo Allahu ni. Leyin naa, ti owo inira ba te yin, Oun ni ki e maa pe (fun idande) |
ثُمَّ إِذَا كَشَفَ الضُّرَّ عَنكُمْ إِذَا فَرِيقٌ مِّنكُم بِرَبِّهِمْ يُشْرِكُونَ(54) Leyin naa, nigba ti O ba si mu inira naa kuro fun yin tan, nigba naa ni apa kan ninu yin yo si maa sebo si Oluwa won |
لِيَكْفُرُوا بِمَا آتَيْنَاهُمْ ۚ فَتَمَتَّعُوا ۖ فَسَوْفَ تَعْلَمُونَ(55) nitori ki won le sai moore si nnkan ti A fun won. Nitori naa, e maa gbadun nso. Laipe e maa mo |
Won n fi ipin kan ninu ohun ti A pese fun won lele fun ohun ti won ko mo. Mo fi Allahu bura, dajudaju won yoo bi yin leere nipa ohun ti e n da ni adapa iro |
وَيَجْعَلُونَ لِلَّهِ الْبَنَاتِ سُبْحَانَهُ ۙ وَلَهُم مَّا يَشْتَهُونَ(57) Won tun n fi (bibi) awon omobinrin lele fun Allahu - Mimo ni fun Un (ko bimo). – Won si n fi ohun ti won n fe lele fun tiwon |
وَإِذَا بُشِّرَ أَحَدُهُم بِالْأُنثَىٰ ظَلَّ وَجْهُهُ مُسْوَدًّا وَهُوَ كَظِيمٌ(58) Nigba ti won ba fun okan ninu won ni iro idunnu (pe o bi) omobinrin, oju re yoo sokunkun, o si maa kun fun ibanuje |
O si maa fi ara pamo fun awon eniyan nitori iro aburu ti won fun un. Se o maa gba a ni nnkan abuku ni tabi o maa bo o mole laaye? E gbo, ohun ti won n da lejo buru |
Ti awon ti ko gba Ojo Ikeyin gbo ni akawe aburu. Ti Allahu si ni akawe t’o ga julo. Ati pe Oun ni Alagbara, Ologbon |
Ti o ba je pe Allahu n gba awon eniyan mu nitori abosi owo won, iba ti se abemi kan kan ku sori ile. Sugbon O n lo won lara di gbedeke akoko kan. Nigba ti akoko naa ba de, won ko nii sun un siwaju di igba kan, won ko si nii fa a seyin.” |
Won n fi (omobinrin) nnkan ti won korira lele fun Allahu. Ahon won si n royin iro pe dajudaju rere ni tawon. Ko si tabi-sugbon, dajudaju Ina ni tiwon. Ati pe dajudaju won maa pa won ti sinu re ni |
Mo fi Allahu bura, dajudaju A ti ran awon Ojise nise si awon ijo kan siwaju re. Nigba naa, Esu se ise won ni oso fun won; oun si ni ore won lonii. Iya eleta-elero si wa fun won |
A ko so Tira naa kale fun o bi ko se pe ki o le salaye fun won ohun ti won n yapa enu si; o si je imona ati ike fun ijo onigbagbo ododo |
Allahu l’O n so omi kale lati sanmo. O si n fi ji ile leyin ti o ti ku. Dajudaju ami wa ninu iyen fun ijo t’o n gboro (ododo) |
Dajudaju ariwoye wa fun yin lara awon eran-osin, ti A n fun yin mu ninu nnkan t’o wa ninu re, (eyi) ti o n jade wa lati aarin boto inu agbedu ati eje. (O si n di) wara mimo t’o n lo tinrin ni ofun awon t’o n mu un |
Ati pe lati ara awon eso dabinu ati eso ajara ni e ti n se oti ati ohun amu-soro t’o dara. Dajudaju ami wa ninu iyen fun ijo t’o ni laakaye |
Oluwa re si fi mo kokoro oyin pe: "Mu ile sinu apata, igi ati ohun ti (awon eniyan) mo ga |
Leyin naa, je lara gbogbo eso, ki o si to awon oju ona Oluwa re pelu iteriba." Ohun mimu ti awo re yato sira won yoo maa jade lati inu kokoro oyin. Iwosan ni fun awon eniyan. Dajudaju ami wa ninu iyen fun ijo t’o ni arojinle |
Allahu l’O seda yin. Leyin naa, O n gba emi yin. O si wa ninu yin eni ti A oo da pada si ogbo kujokujo nitori ki o ma le mo nnkan kan mo leyin ti o ti mo on. Dajudaju Allahu ni Onimo, Alagbara |
Allahu l’O soore ajulo fun apa kan yin lori apa kan ninu arisiki. Awon ti A fun ni oore ajulo, ki won fun awon eru won ni arisiki won, ki won si jo pin in ni dogbadogba! Nitori naa, se idera Allahu ni won yoo maa tako |
Ati pe Allahu se awon iyawo fun yin lati ara yin. O fun yin ni awon omo ati omoomo lati ara awon iyawo yin. O si pese arisiki fun yin ninu awon nnkan daadaa. Se iro (iyen, orisa) ni won yoo gbagbo, won yo si sai gbagbo ninu idera Allahu |
Dipo (ki won josin fun) Allahu, won n josin fun ohun ti ko ni ikapa arisiki kan kan fun won ninu sanmo ati ile; won ko si lagbara (lati se nnkan kan) |
فَلَا تَضْرِبُوا لِلَّهِ الْأَمْثَالَ ۚ إِنَّ اللَّهَ يَعْلَمُ وَأَنتُمْ لَا تَعْلَمُونَ(74) Nitori naa, e ma se fi awon akawe naa lele nipa Allahu. Dajudaju Allahu nimo; eyin ko si nimo |
Allahu fi akawe kan lele (nipa) eru kan ti o wa labe oga, ti ko si le da nnkan kan se ati eni ti A fun ni arisiki t’o dara lati odo wa, ti o si n na ninu re ni ikoko ati ni gbangba. Se won dogba bi? Gbogbo ope n je ti Allahu. Sugbon opolopo won ni ko mo |
Allahu tun fi akawe kan lele (nipa) okunrin meji kan, ti okan ninu won je odi, ti ko le da nnkan kan se, ti o tun je wahala fun oga re (nitori pe) ibikibi ti o ba ran an lo, ko nii mu oore kan bo (fun un lati ibe). Se o dogba pelu eni ti O n pase sise eto, ti o si wa loju ona taara |
Ti Allahu ni ikoko awon sanmo ati ile. Oro Akoko naa ko kuku tayo iseju tabi ki o tun sunmo julo. Dajudaju Allahu ni Alagbara lori gbogbo nnkan |
Allahu l’O mu yin jade lati inu ikun awon iya yin nigba ti eyin ko ti i da nnkan kan mo. O si se igboro, awon iriran ati awon okan fun yin nitori ki e le dupe (fun Un) |
Se won ko woye si awon eye ti A ro (fun fifo) ninu ofurufu (labe) sanmo? Ko si eni t’o n mu won duro (sinu ofurufu) bi ko se Allahu. Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun ijo onigbagbo ododo |
Allahu se ibusinmi fun yin sinu ile yin. Lati ara awo eran-osin, O tun se awon ile (atibaba) kan t’o fuye fun yin lati gbe rin ni ojo irin-ajo yin ati ni ojo ti e ba wa ninu ilu. Lati ara irun agutan, irun rakunmi ati irun ewure, e tun n ri awon nnkan oso ati nnkan igbadun lo titi fun igba die. aso eyi ti won ba fi irun agutan hun maa n je aso t’o roju julo ni rira. Nitori eyi aso irun agutan je aso awon mekunnu. Awon olowo ki i si fe ra a fun wiwo sorun nitori pe olufokansin eni esa onpero kookan ninu awon aafa onibidiah wonyen ba tun bere si fi oruko ara re pero dipo lilo oruko agbelero ti won dijo se adadaale re. Nigba naa ni aye won ba di ilana / toriko “at-tasowuffu al-kodiriyyah” ti okunrin kan ko ba ti ri ise halal se ni ise oojo o maa di “seeu” |
Allahu se awon iboji fun yin lati ara nnkan ti O da. O se awon ibugbe fun yin lati ara awon apata. O tun se awon aso fun yin t’o n daabo bo yin lowo ooru ati awon aso t’o n daabo bo yin loju ogun yin. Bayen l’O se n pe idera Re le yin lori nitori ki e le je musulumi |
فَإِن تَوَلَّوْا فَإِنَّمَا عَلَيْكَ الْبَلَاغُ الْمُبِينُ(82) Nitori naa, ti won ba gbunri, ise-jije ponnbele lojuse tire |
يَعْرِفُونَ نِعْمَتَ اللَّهِ ثُمَّ يُنكِرُونَهَا وَأَكْثَرُهُمُ الْكَافِرُونَ(83) Won mo idera Allahu, leyin naa won n tako o. Opolopo won si ni alaimoore |
(Ranti) ojo ti A oo gbe elerii kan dide ninu gbogbo ijo (awon Anabi), leyin naa, A o nii yonda (aroye sise) fun awon t’o sai gbagbo. Won ko si nii fun won ni aye lati pada se ohun ti won yoo fi ri iyonu Allahu |
وَإِذَا رَأَى الَّذِينَ ظَلَمُوا الْعَذَابَ فَلَا يُخَفَّفُ عَنْهُمْ وَلَا هُمْ يُنظَرُونَ(85) Nigba ti awon t’o sabosi ba ri Iya, nigba naa, A o nii se iya won ni fifuye, A o si nii fun won ni isinmi (ninu Ina) |
Nigba ti awon t’o ba Allahu wa akegbe ba ri awon orisa won, won a wi pe: “Oluwa wa, awon wonyi ni awon orisa wa ti a n pe leyin Re.” Nigba naa (awon orisa) yoo ju oro naa pada si won pe: “Dajudaju opuro ma ni eyin.” |
وَأَلْقَوْا إِلَى اللَّهِ يَوْمَئِذٍ السَّلَمَ ۖ وَضَلَّ عَنْهُم مَّا كَانُوا يَفْتَرُونَ(87) Won si maa jura won sile fun Allahu ni ojo yen. Ohun ti won n da ni adapa iro yo si di ofo mo won lowo |
Awon t’o sai gbagbo, ti won si seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Allahu, A o se alekun iya lori iya fun won nitori pe won n sebaje |
(Ranti) Ojo ti A oo gbe elerii dide fun ijo kookan laaarin ara won, A si maa mu iwo wa ni elerii fun awon wonyi. A so Tira kale fun o; (o je) alaye fun gbogbo nnkan, imona, ike ati iro idunnu fun awon musulumi |
Dajudaju Allahu n pase sise deede, sise rere ati fifun ebi (ni nnkan). O si n ko iwa ibaje, ohun buruku ati rukerudo. O n se waasi fun yin nitori ki e le lo iranti |
Ki e si mu adehun Allahu se nigba ti e ba se adehun. E ma se tu ibura leyin ifirinle re. E si kuku ti fi Allahu se Elerii lori ara yin. Dajudaju Allahu mo ohun ti e n se nise |
Ki e si ma se da bi (obinrin) eyi ti o tu owu didi re pale leyin ti o ti di i le. Nse ni e n lo ibura yin fun etan laaarin ara yin nitori pe iran kan po ju iran kan lo. Dajudaju Allahu n dan yin wo pelu re ni. Ati pe ni Ojo Ajinde O kuku maa salaye fun yin ohun ti e n yapa enu si |
Ati pe ti o ba je pe Allahu ba fe, iba se yin ni ijo kan soso (sinu ’Islam), sugbon O n si eni ti O ba fe lona, O si n to eni ti O ba fe sona. Dajudaju Won maa bi yin leere nipa ohun ti e n se nise |
E ma se lo ibura yin fun etan laaarin ara yin, nitori ki ese yin ma baa ye gere leyin idurosinsin re, ati nitori ki e ma baa to iya buruku wo nipa bi e se seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Allahu. Iya nla yo si wa fun yin |
E ma se ta adehun Allahu ni owo pooku. Ohun ti n be lodo Allahu, o loore julo fun yin ti e ba mo |
Ohun t’o n be lodo yin maa tan. Ohun t’o n be lodo Allahu si maa wa titi laelae. Dajudaju A si maa fi eyi t’o dara julo si ohun ti won n se nise san awon t’o se suuru lesan won |
Enikeni ti o ba se ise rere, okunrin ni tabi obinrin, o si je onigbagbo ododo, dajudaju A oo je ki o lo igbesi aye t’o dara. Dajudaju A o si fi eyi t’o dara julo si ohun ti won n se nise san won ni esan won |
فَإِذَا قَرَأْتَ الْقُرْآنَ فَاسْتَعِذْ بِاللَّهِ مِنَ الشَّيْطَانِ الرَّجِيمِ(98) Nigba ti o ba (fe) ke al-Ƙur’an, sa di Allahu nibi (aburu) Esu, eni eko |
إِنَّهُ لَيْسَ لَهُ سُلْطَانٌ عَلَى الَّذِينَ آمَنُوا وَعَلَىٰ رَبِّهِمْ يَتَوَكَّلُونَ(99) Dajudaju ko si agbara kan fun un lori awon t’o gbagbo, ti won si n gbarale Oluwa won |
إِنَّمَا سُلْطَانُهُ عَلَى الَّذِينَ يَتَوَلَّوْنَهُ وَالَّذِينَ هُم بِهِ مُشْرِكُونَ(100) Eni t’o lagbara lori re ni awon t’o n mu un ni ore ati awon t’o so o di akegbe Allahu |
Nigba ti A ba paaro ayah kan si aye ayah kan, Allahu l’O si nimo julo nipa ohun t’O n sokale, won a wi pe: “Iwo kan je aladapa iro ni.” Amo opolopo won ni ko nimo |
So pe: “Emi mimo (molaika Jibril) l’o so o kale lati odo Oluwa re ni ti ododo nitori ki o le mu ese awon t’o gbagbo lododo rinle. (Ki o si le je) imona ati iro idunnu fun awon musulumi |
A si kuku ti mo pe dajudaju won n wi pe: “Sebi abara kan l’o n ko o (ni al-Ƙur’an).” Ede eni ti won n ye si (ti won n toka si pe o n ko o) ki i se elede Larubawa. Ede Larubawa ponnbele si ni (al-Ƙur’an) yii |
إِنَّ الَّذِينَ لَا يُؤْمِنُونَ بِآيَاتِ اللَّهِ لَا يَهْدِيهِمُ اللَّهُ وَلَهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ(104) Dajudaju awon ti ko gbagbo ninu awon ayah Allahu, Allahu ko nii to won sona. Iya eleta-elero si wa fun won |
Awon ti ko gbagbo ninu awon ayah Allahu l’o n da adapa iro (mo Allahu). Awon wonyen si ni opuro |
Enikeni ti o ba sai gbagbo ninu Allahu leyin igbagbo re, yato si eni ti won je nipa, ti okan re si bale pelu igbagbo ododo, sugbon enikeni ti aigbagbo ba te lorun, ibinu lati odo Allahu n be lori won. Iya nla si wa fun won |
Iyen nitori pe won feran isemi aye ju orun. Allahu ko nii fi ona mo ijo alaigbagbo |
Awon wonyen ni awon ti Allahu ti fi edidi bo okan won, igboro won ati iriran won. Awon wonyen si ni afonufora |
Ko si tabi-sugbon, dajudaju awon ni olofo ni orun |
Leyin naa, dajudaju Oluwa re - nipa awon t’o gbe ilu won ju sile leyin ti awon alaigbagbo ti ko ifooro ba won, leyin naa, ti won jagun esin, ti won si se suuru - dajudaju Oluwa re ni Alaforijin, Asake-orun (fun won) leyin (ifooro ti won ri lodo awon alaigbagbo) |
(Ranti) Ojo ti emi kookan yoo de lati du ori ara re. A o si san emi kookan ni esan ohun ti o se nise; won ko si nii sabosi si won |
Allahu fi akawe lele nipa ilu kan, ti o je (ilu) aabo ati ifayabale, ti arisiki re n te e lowo ni pupo ni gbogbo aye. Amo (won) se aimoore si awon idera Allahu. Nitori naa, Allahu fun won ni iya ebi ati ipaya to wo nitori ohun ti won n se nise |
وَلَقَدْ جَاءَهُمْ رَسُولٌ مِّنْهُمْ فَكَذَّبُوهُ فَأَخَذَهُمُ الْعَذَابُ وَهُمْ ظَالِمُونَ(113) Ojise kuku ti de ba won laaarin ara won. Won si pe e ni opuro. Nitori naa, owo iya ba won. Alabosi si ni won |
E je ninu ohun ti Allahu pa lese fun yin ni nnkan eto, t’o dara. Ki e si dupe oore Allahu ti o ba je pe Oun nikan soso ni e n josin fun |
Ohun ti (Allahu) se ni eewo fun yin ni eran okunbete, eje, eran elede ati eyi ti won pa pelu oruko t’o yato si “Allahu”. Nitori naa, enikeni ti won ba fi inira ebi kan, yato si eni t’o n wa eewo kiri ati olutayo-enu-ala, dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun |
E ma se so nipa ohun ti ahon yin royin ni iro pe: “Eyi ni eto, eyi si ni eewo” nitori ki e le da adapa iro mo Allahu. Dajudaju awon t’o n da adapa iro mo Allahu, won ko nii jere |
Igbadun aye bin-intin (le wa fun won, amo) iya eleta-elero wa fun won (ni orun) |
Ati pe A se ohun ti A so fun o siwaju ni eewo fun awon t’o di yehudi. A o si sabosi si won, sugbon awon ni won n sabosi si emi ara won |
Leyin naa, dajudaju Oluwa re - nipa awon t’o se aburu pelu aimokan, leyin naa, ti won ronu piwada leyin iyen, ti won si se atunse leyin re dajudaju Oluwa re ma ni Alaforijin, Asake-orun |
إِنَّ إِبْرَاهِيمَ كَانَ أُمَّةً قَانِتًا لِّلَّهِ حَنِيفًا وَلَمْ يَكُ مِنَ الْمُشْرِكِينَ(120) Dajudaju (Anabi) ’Ibrohim je asiwaju-awokose-rere, olutele-ase Allahu, oluduro-deede-ninu-esin. Ko si je ara awon osebo |
شَاكِرًا لِّأَنْعُمِهِ ۚ اجْتَبَاهُ وَهَدَاهُ إِلَىٰ صِرَاطٍ مُّسْتَقِيمٍ(121) O maa n dupe awon idera Allahu. Allahu sa a lesa. O si to o si ona taara (’Islam) |
وَآتَيْنَاهُ فِي الدُّنْيَا حَسَنَةً ۖ وَإِنَّهُ فِي الْآخِرَةِ لَمِنَ الصَّالِحِينَ(122) A se ohun rere fun un nile aye. Ati pe ni orun dajudaju o maa wa ninu awon eni rere |
Leyin naa, A fi imisi ranse si o pe ki o tele esin (Anabi) ’Ibrohim, oluduro-deede-ninu-esin. Ko si wa lara awon osebo |
Awon ti won se (agbega) ojo Sabt fun ni awon t’o yapa enu nipa re. Dajudaju Oluwa re yoo kuku se idajo laaarin won ni Ojo Ajinde nipa ohun ti won n yapa enu si |
Pepe si oju ona Oluwa re pelu ogbon ijinle (iyen, al-Ƙur’an ati sunnah Anabi s.a.w.) ati waasi rere. Ki o si ja won niyan pelu eyi t’o dara julo. Dajudaju Oluwa re, O nimo julo nipa eni ti o sina kuro loju ona Re (’Islam). O si nimo julo nipa awon olumona (awon musulumi) |
Ti e (ba fe) gbesan (iya), e gbesan iru iya ti won fi je yin. Dajudaju ti e ba si se suuru, o ma si loore julo fun awon onisuuru |
Se suuru. Iwo ko si le ri suuru se afi pelu (iranlowo) Allahu. Ma se banuje nitori won. Ma si se wa ninu ibanuje nitori ohun ti won n da ni ete |
إِنَّ اللَّهَ مَعَ الَّذِينَ اتَّقَوا وَّالَّذِينَ هُم مُّحْسِنُونَ(128) Dajudaju Allahu wa pelu awon t’o beru (Re) ati awon t’o n se rere |
More surahs in Yoruba:
Download surah An-Nahl with the voice of the most famous Quran reciters :
surah An-Nahl mp3 : choose the reciter to listen and download the chapter An-Nahl Complete with high quality
Ahmed Al Ajmy
Bandar Balila
Khalid Al Jalil
Saad Al Ghamdi
Saud Al Shuraim
Abdul Basit
Abdul Rashid Sufi
Abdullah Basfar
Abdullah Al Juhani
Fares Abbad
Maher Al Muaiqly
Al Minshawi
Al Hosary
Mishari Al-afasi
Yasser Al Dosari
لا تنسنا من دعوة صالحة بظهر الغيب