📖 0/604 oju-iwe ti a ka
📄 262
Surah Al-Hijr

Surah Al-Hijr

15:1
الٓرۚ تِلۡكَ ءَايَٰتُ ٱلۡكِتَٰبِ وَقُرۡءَانٍ مُّبِينٍ ١
’Alif lam ro. Iwonyi ni awon ayah Tira naa ati (awon ayah) al-Ƙur’an t’o n yanju oro eda
15:2
رُّبَمَا يَوَدُّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ لَوۡ كَانُواْ مُسۡلِمِينَ ٢
O see se ki awon t’o sai gbagbo nifee si pe awon iba si ti je musulumi (nile aye)
15:3
ذَرۡهُمۡ يَأۡكُلُواْ وَيَتَمَتَّعُواْ وَيُلۡهِهِمُ ٱلۡأَمَلُۖ فَسَوۡفَ يَعۡلَمُونَ ٣
Fi won sile, ki won je, ki won gbadun, ki ireti (emi gigun) ko airoju raaye ba won (lati sesin); laipe won maa mo
15:4
وَمَآ أَهۡلَكۡنَا مِن قَرۡيَةٍ إِلَّا وَلَهَا كِتَابٌ مَّعۡلُومٌ ٤
A ko pa ilu kan run ri afi ki o ni akosile ti A ti mo
15:5
مَّا تَسۡبِقُ مِنۡ أُمَّةٍ أَجَلَهَا وَمَا يَسۡتَـٔۡخِرُونَ ٥
Ko si ijo kan (ti o parun) siwaju akoko re (ninu Laohul-Mahfuuth); won ko si nii sun un siwaju fun won
15:6
وَقَالُواْ يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِي نُزِّلَ عَلَيۡهِ ٱلذِّكۡرُ إِنَّكَ لَمَجۡنُونٌ ٦
Won wi pe: “Iwo ti Won so al-Ƙur’an kale fun, dajudaju were ni e
15:7
لَّوۡمَا تَأۡتِينَا بِٱلۡمَلَٰٓئِكَةِ إِن كُنتَ مِنَ ٱلصَّٰدِقِينَ ٧
Ki ni ko je ki iwo mu awon molaika wa ba wa, ti iwo ba wa ninu awon olododo?”
15:8
مَا نُنَزِّلُ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةَ إِلَّا بِٱلۡحَقِّ وَمَا كَانُوٓاْ إِذًا مُّنظَرِينَ ٨
A o nii so molaika kale bi ko se pelu ododo. Won ko si nii lo won lara mo nigba naa (ti awon molaika ba sokale)
15:9
إِنَّا نَحۡنُ نَزَّلۡنَا ٱلذِّكۡرَ وَإِنَّا لَهُۥ لَحَٰفِظُونَ ٩
Dajudaju Awa l’A so Tira Iranti kale (iyen al-Ƙur’an). Dajudaju Awa si ni Oluso re
15:10
وَلَقَدۡ أَرۡسَلۡنَا مِن قَبۡلِكَ فِي شِيَعِ ٱلۡأَوَّلِينَ ١٠
Dajudaju siwaju re A ti ran (awon Ojise) nise si awon ijo, awon eni akoko
15:11
وَمَا يَأۡتِيهِم مِّن رَّسُولٍ إِلَّا كَانُواْ بِهِۦ يَسۡتَهۡزِءُونَ ١١
Ojise kan ko si nii de ba won afi ki won fi se yeye
15:12
كَذَٰلِكَ نَسۡلُكُهُۥ فِي قُلُوبِ ٱلۡمُجۡرِمِينَ ١٢
Bayen ni A se n fi (aisan) sinu okan awon elese
15:13
لَا يُؤۡمِنُونَ بِهِۦ وَقَدۡ خَلَتۡ سُنَّةُ ٱلۡأَوَّلِينَ ١٣
Won ko nii gba Anabi (sollalahu alayhi wa sallam) gbo; ise (Allahu lori) awon eni akoko kuku ti re koja
15:14
وَلَوۡ فَتَحۡنَا عَلَيۡهِم بَابًا مِّنَ ٱلسَّمَآءِ فَظَلُّواْ فِيهِ يَعۡرُجُونَ ١٤
Ti o ba je pe A si ilekun kan sile fun won lati inu sanmo, ti won ko si ye gbabe gunke lo (sinu sanmo)
15:15
لَقَالُوٓاْ إِنَّمَا سُكِّرَتۡ أَبۡصَٰرُنَا بَلۡ نَحۡنُ قَوۡمٌ مَّسۡحُورُونَ ١٥
dajudaju won a wi pe: “Won kuku lo isiju fun wa ni. Nse ni won n dan wa.”
العربيةEnglishBahasa IndonesiaTürkçeРусскийفارسیFrançaisاردوবাংলাDeutschEspañol中文हिन्दीPortuguêsItalianoภาษาไทยPolskiNederlandsShqipKiswahiliO'zbekதமிழ்MelayuBosanskiSoomaaliAzərbaycanکوردی한국어日本語SvenskaDanskNorskپښتوമലയാളംසිංහලTamazightHausaአማርኛБългарскиТоҷикӣҚазақшаFilipinoسنڌيYorùbáFulfuldeТатарчаئۇيغۇرچەКыргызчаਪੰਜਾਬੀJawaతెలుగుမြန်မာગુજરાતીOromoमराठीTiếng ViệtMalagasyНохчийнWolofދިވެހިಕನ್ನಡУкраїнськаΕλληνικάქართულიខ្មែរدریQafar afMaranaoनेपाली
Al-Kur'an
Tuesday, August 25, 2026
Don't forget us in your sincere prayers







