Surah Yunus
PDF —
Built right in your browser — download starts automatically
Surah Yunus pdf — Gbà (Yorùbá)
Surah Yunus pdf Yorùbá — Gbà Surah Yunus Itumọ. Yunus (Meccan) 109 Ẹsẹ.
Related
- Yunus ItumọYorùbá
- Yunus mp3Gbọ
- Quran Index Yorùbá114
More Surah PDF
Surah Yunus

ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗ
’Alif Lam Ro. Iwonyi ni awon ayah Tira ogbon
ﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳ
Se o je kayefi fun awon eniyan pe A fi imisi ranse si arakunrin kan ninu won, pe: “Se ikilo fun awon eniyan, ki o si fun awon t’o gbagbo ni iro idunnu pe esan rere (ise ti won se) siwaju ti wa ni odo Oluwa won.”? Awon alaigbagbo wi pe: “Dajudaju opidan ponnbele ma ni (Anabi) yii.”
ﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕ
Dajudaju Oluwa yin ni Allahu, Eni ti O seda awon sanmo ati ile fun ojo mefa. Leyin naa, O gunwa si ori Ite-ola. O n seto oro (eda). Ko si olusipe kan afi leyin iyonda Re. Iyen ni Allahu, Oluwa yin. Nitori naa, e josin fun Un. Se e o nii lo iranti ni
ﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖ
Odo Re ni ibupadasi gbogbo yin. (O je) adehun Allahu ni ododo. Dajudaju Oun l’O n pile dida eda. Leyin naa, O maa da a pada (sodo Re) nitori ki O le fi deede san esan fun awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se ise rere. Awon t’o si sai gbagbo, ohun mimu gbigbona ati iya eleta-elero n be fun won nitori pe won sai gbagbo
ﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰ
(Allahu) Oun ni Eni ti O se oorun ni itansan. (O se) osupa ni imole. O si diwon (irisi) re sinu awon ibuso nitori ki e le mo onka awon odun ati isiro (ojo). Allahu ko da iyen bi ko se pelu ododo. O n salaye awon ayah fun ijo t’o nimo
ﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿ
Dajudaju awon ami wa ninu itelentele ati iyato oru ati osan ati ohun ti Allahu da sinu awon sanmo ati ile; (ami wa ninu won) fun ijo t’o n beru (Allahu)
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠ
Dajudaju awon ti ko reti ipade Wa (ni orun), ti won yonu si isemi aye, ti okan won si bale dodo si (isemi aye yii) ati awon afonu-fora nipa awon ayah Wa
ﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧ
awon wonyen, ibugbe won ni Ina nitori ohun ti won n se nise
ﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸ
Dajudaju awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere, Oluwa won yoo fi igbagbo ododo won to won sona. Awon odo yo si maa san ni isale odo won ninu Ogba Idera
ﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈ
Adua won ninu re ni “mimo ni fun O, Allahu”. Ikini won ninu re ni “alaafia”. Ipari adua won si ni pe “gbogbo ope n je ti Allahu, Oluwa gbogbo eda”
ﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝ
Ti o ba je pe Allahu n kanju mu aburu ba awon eniyan (nipase epe enu won, gege bi O se n) tete mu oore ba won (nipase adua), A iba ti mu opin ba isemi won. Nitori naa, A maa fi awon ti ko reti ipade Wa sile sinu agbere won, ti won yoo maa pa ridarida
ﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛ
Nigba ti inira ba kan eniyan, o maa pe Wa lori idubule re tabi ni ijokoo tabi ni inaro. Nigba ti A ba mu inira re kuro fun un, o maa te siwaju (ninu aigbagbo) bi eni pe ko pe Wa si inira ti o mu un. Bayen ni won se ni oso fun awon alakoyo ohun ti won n se nise
ﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮ
A kuku ti pa awon iran kan re siwaju yin nigba ti won se abosi. Awon Ojise won mu awon eri t’o yanju wa ba won. Won ko si gbagbo. Bayen ni A se n san ijo elese ni esan
ﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹ
Leyin naa, A se yin ni arole lori ile leyin won nitori ki A le wo bi eyin naa yoo se maa se
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻ
Nigba ti won ba n ke awon ayah Wa, t’o yanju fun won, awon ti ko reti ipade Wa (ni orun) yoo maa wi pe: “Mu Ƙur’an kan wa yato si eyi tabi ki o yi i pada.” So pe: “Ko letoo fun mi lati yi i pada lati odo ara mi. Emi ko tele kini kan ayafi ohun ti Won fi ranse si mi ni imisi. Dajudaju emi n paya iya Ojo nla ti mo ba fi le yapa Oluwa mi.”
ﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐ
So pe: “Ti o ba je pe Allahu ba fe ni, emi iba ti le ke al-Ƙur’an fun yin, ati pe Allahu iba ti fi imo re mo yin. Mo kuku ti lo awon odun kan laaarin yin siwaju (isokale) re, se e o se laakaye ni?”
ﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠ
Nitori naa, ta l’o sabosi ju eni t’o da adapa iro mo Allahu tabi t’o pe awon ayah Re niro? Dajudaju awon odaran ko nii jere
ﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡ
Won n josin fun ohun ti ko le ko inira ba won, ti ko si le se won ni anfaani leyin Allahu. Won si n wi pe: “Awon wonyi ni olusipe wa lodo Allahu.” So pe: “Se e maa fun Allahu ni iro ohun ti ko mo ninu awon sanmo ati ile ni?” Mimo ni fun Un, O ga tayo nnkan ti won n fi sebo si I
ﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴ
Ki ni awon eniyan je (ni ipile) bi ko se ijo eyo kan (ijo ’Islam). Leyin naa ni won yapa enu. Ti ko ba je pe oro kan t’o ti siwaju lodo Oluwa re, Awa iba ti yanju ohun ti won n yapa enu si laaarin ara won
ﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆ
Won n wi pe: “Ki ni ko je ki ami kan sokale fun un lati odo Oluwa re?” Nitori naa, so pe: “Ti Allahu ni ikoko. Nitori naa, e maa reti. Dajudaju emi naa wa pelu yin ninu awon olureti.”
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩ
Nigba ti A ba fun awon eniyan ni idera kan towo leyin ti inira ti fowo ba won, nigba naa ni won maa dete si awon ayah Wa. So pe: “Allahu yara julo nibi ete. Dajudaju awon Ojise Wa n se akosile ohun ti e n da lete.”
ﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔ
(Allahu) Oun ni Eni ti O mu yin rin lori ile ati ni oju omi, titi di igba ti e ba wa ninu oko oju-omi, ti ategun t’o dara si n tuko won lo, inu won yo si maa dun si i. (Amo) ategun lile ko lu u, igbi omi de ba won ni gbogbo aye, won si lero pe dajudaju won ti fi (adanwo) yi awon po, won si pe Allahu pelu sise afomo-adua fun Un pe: “Dajudaju ti O ba fi le gba wa la nibi eyi, dajudaju a maa wa ninu awon oludupe.”
ﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱ
Sugbon nigba ti O gba won la tan igba naa ni won tun n se ibaje kiri lori ile lai letoo. Eyin eniyan, dajudaju ibaje yin n be lori yin. (Ibaje yin si je) igbadun isemi aye. Leyin naa, odo Wa ni ibupadasi yin. A si maa fun yin ni iro ohun ti e n se nise
ﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿ
Apejuwe isemi aye da bi omi kan ti A sokale lati sanmo, ti awon irugbin ninu ohun ti eniyan ati awon eran-osin n je si gba a sara, titi di igba ti ile yoo fi loraa. O si mu oso (ara) re jade. Awon t’o ni i si lero pe awon ni alagbara lori re, (nigba naa ni) ase Wa de ba a ni oru tabi ni osan. A si so o di oko ti won fa tu danu bi eni pe ko si nibe rara ri ni ana. Bayen ni A se n salaye awon ayah fun ijo alarojinle
ﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆﰇﰈﰉﰊﰋ
Allahu n pepe si ile Alaafia. O si n to eni ti O ba fe si ona taara (’Islam)
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥ
Rere ati alekun (oore) wa fun awon t’o se rere. Eruku tabi iyepere kan ko nii bo won loju mole. Awon wonyen ni ero inu Ogba Idera. Olusegbere ni won ninu re
ﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅ
Awon t’o si s’ise aburu, esan aburu bi iru re (ni esan won). Iyepere si maa bo won mole. Ko si alaabo kan fun won lodo Allahu. (Won maa da bi) eni pe won fi apa kan oru t’o sokunkun bo won loju pa. Awon wonyen ni ero inu Ina. Olusegbere ni won ninu re
ﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚ
Ati pe (ranti) Ojo ti A oo ko gbogbo won jo, leyin naa A oo so fun awon t’o ba Allahu wa akegbe pe: “E duro pa si aye yin, eyin ati awon orisa yin.” Nitori naa, A ya won si otooto. Awon orisa won si wi pe: “Awa ko ni e n josin fun
ﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥ
Nitori naa, Allahu to ni Elerii laaarin awa ati eyin pe awa je alaimo nipa ijosin yin (ti e se fun wa).”
ﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙ
Nibe yen, emi kookan maa da ohun t’o se siwaju mo. Won yo si da won pada sodo Allahu, Oluwa won, Ododo. Ohun ti won si n da ni adapa iro si maa dofo mo won lowo
ﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷ
So pe: “Ta ni O n pese fun yin lati inu sanmo ati ile? Ta ni O ni ikapa lori igboro ati iriran? Ta ni O n mu alaaye jade lati ara oku, ti O tun n mu oku jade lati ara alaaye? Ta si ni O n se eto oro (eda)?” Won yoo wi pe: "Allahu" Nigba naa, so pe: "Se e o nii beru (Re) ni
ﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅ
Iyen ni Allahu, Oluwa yin, Ododo. Ki si ni o n be leyin Ododo bi ko se isina? Nitori naa, bawo ni won se n seri yin kuro nibi ododo
ﰆﰇﰈﰉﰊﰋﰌﰍﰎﰏﰐ
Bayen ni oro Oluwa re se wa si imuse lori awon t’o sebaje pe dajudaju won ko nii gbagbo
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤ
So pe: "Nje o wa ninu awon orisa yin eni ti o le pile dida eda, leyin naa, ti o maa da a pada (si ipile re leyin iku)?" So pe: "Allahu l’O n pile dida eda. Leyin naa, O maa da a pada (si ipile re leyin iku). Nitori naa, bawo ni won se n seri yin kuro nibi ododo
ﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅ
So pe: "Nje o wa ninu awon orisa yin eni t’o n fini mona sibi ododo?" So pe: “Allahu l’O n fini mona sibi ododo. Nigba naa, se Eni t’O n fini mona sibi ododo l’o letoo julo si pe ki won maa tele ni tabi eni ti ko le da ona mo funra re afi ti A ba fi mona?” Nitori naa, ki l’o n se yin ti e fi n dajo bayii
ﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙ
Opolopo won ko si ri kini kan tele bi ko se aroso. Dajudaju aroso ko si le roro kini kan niwaju ododo. Dajudaju Allahu ni Onimo nipa ohun ti won n se nise
ﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰ
Al-Ƙur’an yii ki i se nnkan ti o se e dahun (lati odo elomiiran) leyin Allahu, sugbon o n jerii si eyi t’o je ododo ninu eyi t’o siwaju re, o n se alaye (awon) Tira naa. Ko si iyemeji ninu re. (O wa) lati odo Oluwa gbogbo eda
ﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣ
Tabi won n wi pe: "O hun un ni? So pe: "E mu surah kan bi iru re wa. Ki e si pe enikeni ti e ba le pe leyin Allahu, ti e ba je olododo
ﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹ
Ko ri bee, won pe ohun ti won ko ni imo re niro ni. Ati pe imuse oro Re ko ti i de ba won (ni won fi pe e niro). Bayen ni awon t’o siwaju won se pe (oro Allahu) niro. Nitori naa, wo bi atubotan awon alabosi se ri
ﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆﰇ
O si n be ninu won eni t’o gba a gbo ni ododo. O tun n be ninu won eni ti ko gba a gbo. Oluwa re si ni Onimo-julo nipa awon obileje
ﰈﰉﰊﰋﰌﰍﰎﰏﰐﰑﰒﰓﰔﰕﰖﰗﰘ
Ti won ba pe o ni opuro, so pe: “Temi ni ise mi. Tiyin ni ise yin. Eyin yowo yose ninu ohun ti mo n se nise. Emi naa si yowo yose ninu ohun ti e n se nise.”
ﰙﰚﰛﰜﰝﰞﰟﰠﰡﰢﰣﰤﰥ
O si wa ninu won, awon t’o n teti si o. Se iwo l’o maa mu aditi gboro ni, bi o tile je pe won ki i se laakaye
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝ
O tun n be ninu won eni t’o n wo o. Se iwo l’o maa fi afoju mona ni, bi o tile je pe won ki i riran
ﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨ
Dajudaju Allahu ko nii fi kini kan sabosi si eniyan. Sugbon eniyan n sabosi si emi ara won
ﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾ
Ati pe (ranti) Ojo ti (Allahu) yoo ko won jo afi bi eni pe won ko gbe ile aye ju akoko kan ninu osan. Won yo si dara won mo. Dajudaju awon t’o pe ipade Allahu niro ti sofo; won ko si je olumona
ﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎ
O see se ki A fi apa kan eyi ti A se ni ileri fun won han o tabi ki A ti gba emi re (siwaju asiko naa), odo Wa kuku ni ibupadasi won. Leyin naa, Allahu ni Arinu-rode ohun ti won n se nise
ﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜ
Ojise ti wa fun ijo kookan. Nitori naa, nigba ti Ojise won ba de, A oo sedajo laaarin won pelu deede; A o si nii sabosi si won
ﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤ
Won n wi pe: “Igba wo ni adehun yii yoo se ti e ba je olododo?”
ﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞ
So pe: “Emi ko ni ikapa inira tabi oore kan fun emi ara mi afi ohun ti Allahu ba fe. Gbedeke akoko ti wa fun ijo kookan. Nigba ti akoko naa ba de, won ko nii sun un siwaju di akoko kan, won ko si nii fa a seyin.”
ﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫ
So pe: "E so fun mi, ti iya Re ba de ba yin ni oru tabi ni osan? Ewo ninu re ni awon elese n wa pelu ikanju?”
ﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸ
Se leyin igba ti o ba sele tan ni e maa gba a gbo? Se nisinsin yii (ni e oo gba a gbo), ti e si kuku ti n wa a pelu ikanju
ﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆ
Leyin naa, A oo so fun awon t’o sabosi pe: “E to iya gbere wo.” Se A oo san yin ni esan kan bi ko se ohun ti e n se nise
ﰇﰈﰉﰊﰋﰌﰍﰎﰏﰐﰑﰒﰓﰔﰕ
Won si n beere fun iro re lodo re pe, “se ododo ni?” So pe: “Bee ni. Mo fi Oluwa mi bura. Dajudaju ododo ni. Eyin ko si nii mori bo.”
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨ
Ati pe ti o ba je pe gbogbo nnkan ti n be lori ile je ti emi kookan t’o sabosi, iba fi serapada (fun emi ara won nibi iya). Won yoo fi igbe abamo pamo nigba ti won ba ri Iya. A o se idajo laaarin won pelu deede; Won ko si nii sabosi si won
ﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺ
Gbo, dajudaju ti Allahu ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ile. Gbo! Dajudaju adehun Allahu ni ododo, sugbon opolopo won ko nimo
ﭻﭼﭽﭾﭿﮀ
O n so eda di alaaye. O si n so eda di oku. Odo Re si ni won yoo da yin pada si
ﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏ
Eyin eniyan, isiti kan lati odo Oluwa yin ti de ba yin. Iwosan ni fun nnkan t’o wa ninu awon igba-aya eda. Imona ati ike ni fun awon onigbagbo ododo
ﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚ
So pe: “Pelu ajulo oore Allahu (iyen, al-Ƙur’an) ati aanu Re (iyen, ’Islam), nitori iyen ni ki won maa fi dunnu; o si loore julo si ohun ti awon (alaigbagbo) n ko jo (ninu oore aye).”
ﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰ
So pe: “E so fun mi nipa awon nnkan ti Allahu sokale fun yin ninu arisiki, ti eyin funra yin se awon kan ni eewo ati eto. Se Allahu l’O yonda fun yin ni tabi e n da adapa iro mo Allahu?”
ﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦ
Ki ni ero-okan awon t’o n da adapa iro mo Allahu ni Ojo Ajinde na? Dajudaju Allahu ni Olola-julo lori awon eniyan, sugbon opolopo won ni ki i dupe (fun Un)
ﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆﰇﰈﰉﰊﰋﰌﰍﰎﰏﰐﰑﰒ
Iwo ko nii wa ninu ise kan, iwo ko si nii ke (ayah kan) ninu al-Ƙur’an, eyin ko nii se ise kan afi ki Awa je Elerii lori yin nigba ti e ba n se e. Kini kan ko pamo fun Oluwa re; ti o mo ni odiwon ina-igun ninu ile ati ninu sanmo, ki o tun kere ju iyen lo tabi ki o tobi ju u lo afi ki o wa ninu akosile t’o yanju
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛ
Gbo, dajudaju awon ore Allahu, ko nii si iberu (iya orun) fun won, won ko si nii banuje (lori oore aye)
ﭜﭝﭞﭟﭠ
(Awon ni) awon t’o gbagbo lododo, won si maa n beru (Allahu)
ﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲ
Ti won ni iro idunnu ninu isemi aye (yii) ati ni Ojo Ikeyin. Ko si iyipada kan fun awon oro Allahu. Iyen, ohun ni erenje nla
ﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿ
Ma se je ki oro (enu) won ba o ninu je. Dajudaju gbogbo agbara patapata n je ti Allahu. Oun ni Olugbo, Onimo
ﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛ
Gbo, dajudaju ti Allahu ni enikeni t’o n be ninu awon sanmo ati enikeni t’o n be lori ile. Ki ni awon t’o n pe awon orisa leyin Allahu n tele na? Won ko tele (kini kan) bi ko se aroso. Won ko si se kini kan bi ko se pe won n paro
ﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬ
Oun ni Eni t’O se oru fun yin nitori ki e le sinmi ninu re. (O se) osan ni (asiko) ti e oo riran (kedere). Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun ijo t’o n gboro (ododo)
ﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬ
Won wi pe: “Allahu so eda di omo.” - Mimo ni fun Un. Oun ni Oluroro. TiRe ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile. – Ko si eri kan lodo yin fun eyi. Se e fe safiti ohun ti e o nimo nipa re sodo Allahu ni
ﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶ
So pe: “Dajudaju awon t’o n da adapa iro mo Allahu, won ko nii jere.”
ﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄ
Igbadun bin-intin (le wa fun won) nile aye. Leyin naa, odo Wa ni ibupadasi won. Leyin naa, A oo fun won ni iya lile to wo nitori pe won n sai gbagbo
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳ
Ka iroyin (Anabi) Nuh fun won. Nigba ti o so fun ijo re pe: “Eyin eniyan mi, ti o ba je pe iduro mi (pelu yin) ati bi mo se n fi awon ayah Allahu se isiti fun yin ba lagbara lara yin, nigba naa Allahu ni mo gbarale. Nitori naa, e pa imoran yin po, (ki e si ke pe) awon orisa yin. Leyin naa, ki ipinnu oro yin ma se wa ni bonkele laaarin yin. Leyin naa, ki e yanju oro mi. Ki e si ma se lo mi lara mo
ﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆ
Ti e ba si koyin (si iranti), emi ko kuku toro owo-oya kan lowo yin. Ko si esan kan fun mi (nibi kan) bi ko se lodo Allahu. Won si ti pa mi lase pe ki ng wa ninu awon musulumi.”
ﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙ
Nigba naa, won pe e ni opuro. Nitori naa, A gba a la, oun ati awon t’o n be pelu re ninu oko oju-omi. A si se won ni arole (lori ile). A si te awon t’o pe ayah Wa niro ri sinu agbami. Nitori naa, wo bi ikangun awon eni-akilo-fun se ri
ﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱ
Leyin naa, A gbe awon Ojise kan dide si awon ijo won. Won si mu awon eri t’o yanju wa ba won. Awon naa ko kuku gbagbo ninu ohun ti (ijo Anabi Nuh) pe niro siwaju (won, iyen ni pe, iru kan-un ni won). Bayen ni A se n fi edidi bo okan awon alakoyo
ﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡ
Leyin naa, leyin won A fi awon ami Wa ran (Anabi) Musa ati Harun nise si Fir‘aon ati awon ijoye re. Nigba naa, won segberaga. Won si je ijo elese
ﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬ
Nigba ti ododo de ba won lati odo Wa, won wi pe: “Dajudaju eyi ni idan ponnbele.”
ﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹ
(Anabi) Musa so pe: "Se nnkan ti eyin yoo maa wi nipa ododo ni pe idan ni nigba ti o de ba yin? Se idan si ni eyi bi? Awon opidan ko si nii jere
ﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆﰇﰈﰉﰊ
Won wi pe: “Se o wa ba wa nitori ki o le seri wa kuro nibi ohun ti a ba awon baba wa lori re (ninu iborisa) ati nitori ki titobi si le je teyin mejeeji lori ile? Awa ko si nii gba eyin mejeeji gbo.”
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗ
Fir‘aon wi pe: “E lo mu gbogbo awon onimo nipa idan pipa wa fun mi.”
ﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢ
Nigba ti awon opidan si de, (Anabi) Musa so fun won pe: “E ju ohun ti e maa ju sile.”
ﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵ
Nigba ti won ju u sile, (Anabi) Musa so pe: “Idan ni ohun ti e mu wa. Dajudaju Allahu si maa ba a je. Dajudaju Allahu ko si nii satunse ise awon obileje
ﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽ
Allahu si maa mu ododo se pelu awon oro Re, awon elese ibaa korira re
ﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕ
Nitori naa, ko si eni t’o gba (Anabi) Musa gbo afi awon aromodomo kan ninu awon eniyan re pelu iberu-bojo (won) si Fir‘aon ati awon ijoye won pe o maa fooro awon. Dajudaju Fir‘aon kuku segberaga lori ile. Ati pe, dajudaju o wa ninu awon alakoyo
ﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢ
(Anabi) Musa so pe: “Eyin eniyan mi, ti e ba je eni t’o gbagbo ninu Allahu, Oun naa ni ki e gbarale ti e ba je musulumi.”
ﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭ
Nitori naa, won so pe: "Allahu la gbarale. Oluwa wa, ma se wa ni adanwo fun ijo alabosi
ﮮﮯﮰﮱﯓﯔ
Ki O si fi aanu Re gba wa la lowo ijo alaigbagbo
ﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦ
A si ranse si (Anabi) Musa ati arakunrin re pe: “Ki eyin mejeeji mu awon ibugbe fun awon eniyan yin si ilu Misro. Ki e si so ibugbe yin di ibukirun. Ki e si maa kirun. Ati pe, fun awon onigbagbo ododo ni iro idunnu.”
ﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅ
(Anabi) Musa so pe: "Oluwa wa, dajudaju Iwo l’O fun Fir‘aon ati awon ijoye re ni oso ati dukia ninu isemi aye. Oluwa wa, (O fun won) nitori ki won le seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Re. Oluwa wa, pa dukia won re, ki O si mu okan won le, ki won ma gbagbo mo titi won fi maa ri iya eleta-elero
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜ
(Allahu) so pe: "Dajudaju Mo ti gba adua eyin mejeeji. Nitori naa, ki eyin mejeeji duro sinsin. E ma se tele oju ona awon ti ko nimo
ﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺ
A mu awon omo ’Isro’il la agbami odo ja. Fir‘aon ati awon omo ogun re si gba to won leyin, ni ti abosi ati itayo enu-ala, titi iteri sinu agbami okun fi ba a. O si wi pe: “Mo gbagbo pe dajudaju ko si olohun ti ijosin to si afi Eni ti awon omo ’Isro’il gbagbo. Mo si wa ninu awon musulumi.”
ﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂ
Se nisinsin yii, ti iwo ti yapa siwaju, ti o si wa ninu awon obileje
ﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒ
Nitori naa, ni oni ni A oo gbe oku re jade si ori ile tente nitori ki o le je ami (feyikogbon) fun awon t’o n bo leyin re. Dajudaju opolopo ninu awon eniyan ma ni afonu-fora nipa awon ayah Wa
ﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬ
A kuku se ibugbe fun awon omo ’Isro’il ni ibugbe alapon-onle. A si pese fun won ninu awon nnkan daadaa. Nigba naa, won ko yapa enu (si ’Islam) titi imo fi de ba won. Dajudaju Oluwa re yoo sedajo laaarin won ni Ojo Ajinde nipa ohun ti won n yapa enu si
ﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥ
Ti o ba wa ninu iyemeji nipa nnkan ti A sokale fun o (pe oruko re ati asotele nipa re wa ninu Taorat ati ’Injil), bi awon t’o n ka Tira siwaju re leere wo. Dajudaju ododo ti de ba o lati odo Oluwa re. Nitori naa, o o gbodo wa lara awon oniyemeji
ﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰ
O o gbodo wa lara awon t’o pe awon ayah Allahu niro, nitori ki o ma baa wa lara awon eni ofo
ﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹ
Dajudaju awon ti oro Oluwa re ti ko le lori, won ko nii gbagbo
ﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂ
gbogbo ayah ibaa de ba won, titi won maa fi ri iya eleta-elero
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦ
Ko kuku si ilu kan, t’o gbagbo (lasiko iya), ti igbagbo re si se e ni anfaani afi ijo (Anabi) Yunus. Nigba ti won gbagbo, A mu abuku iya kuro fun won ninu isemi aye. A si je ki won je igbadun aye fun igba die
ﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷ
Ti o ba je pe Oluwa re ba fe, awon ti n be lori ile iba gbagbo, gbogbo won patapata. Nitori naa, se iwo l’o maa je won nipa ni titi won yoo fi di onigbagbo ododo
ﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇ
Emi kan ko le gbagbo afi pelu ase Allahu. O si maa fi iya je awon ti ko se laakaye
ﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗ
So pe: "E woye si nnkan ti n be ninu sanmo ati ile. Awon ayah ati ikilo ko si nii ro ijo alaigbagbo loro
ﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨ
Nitori naa, se won tun n reti (nnkan miiran) ni bi ko se (iparun) iru ti igba awon t’o re koja lo siwaju won. So pe: “E maa reti nigba naa. Dajudaju emi naa wa pelu yin ninu awon olureti.”
ﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕ
Leyin naa, A oo gba awon Ojise Wa ati awon t’o gbagbo la. Bayen ni o se je ojuse Wa lati gba awon onigbagbo ododo la
ﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱ
So pe: “Eyin eniyan, ti e ba wa ninu iyemeji nipa esin mi. Nigba naa, emi ko nii josin fun awon ti e n josin fun leyin Allahu. Sugbon emi yoo maa josin fun Allahu, Eni ti O maa gba emi yin. Won si pa mi ni ase pe ki ng wa ninu awon onigbagbo ododo
ﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻ
(Won tun pa mi lase pe): “Doju re ko esin naa, (ki o je) oluduro-deede-ninu-esin. Iwo ko si gbodo wa ninu awon osebo
ﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆﰇﰈﰉﰊﰋﰌﰍ
Ati pe ma se pe leyin Allahu nnkan ti ko le se o ni anfaani, ti ko si le ko inira ba o. Ti o ba se bee nigba naa, dajudaju iwo ti wa ninu awon alabosi.”
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬ
Ti Allahu ba mu inira ba o, ko si eni ti o le mu un kuro afi Oun. Ti O ba si gbero oore kan pelu re, ko si eni ti o le da oore Re pada. O n soore fun eni ti O ba fe ninu awon erusin Re. Oun ni Alaforijin, Asake-orun
ﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆ
So pe: "Eyin eniyan, dajudaju ododo ti de ba yin lati odo Oluwa yin. Nitori naa, enikeni ti o ba mona, o mona fun emi ara re. Enikeni ti o ba si sina, o sina fun emi ara re. Emi si ko ni oluso fun yin
ﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓ
Tele ohun ti A fi ranse si o ninu imisi. Ki o si se suuru titi Allahu yoo fi se idajo. Oun si loore julo ninu awon oludajo
Al-Kur'an
Tuesday, August 18, 2026
Don't forget us in your sincere prayers







