Surah Hud pdf — Gbà (Yorùbá)
Surah Hud pdf Yorùbá — Gbà Surah Hud Itumọ. Hud (Meccan) 123 Ẹsẹ.
Related
- Hud ItumọYorùbá
- Hud mp3Gbọ
- Quran Index Yorùbá114
More Surah PDF
Surah Hud

ﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟ
’Alif lam ro. (Eyi ni) Tira ti won ti to awon ayah inu re ni atogun rege, leyin naa won salaye re yekeyeke lati odo Ologbon, Alamotan
ﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪ
(A ti salaye re) pe e ma josin fun kini kan afi Allahu. Dajudaju emi ni olukilo ati oniroo idunnu fun yin lati odo Re
ﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦ
(A ti salaye re) pe ki e toro aforijin lodo Oluwa yin. Leyin naa, ki e ronu piwada sodo Re. O maa fun yin ni igbadun daadaa titi di gbedeke akoko kan. O maa fun onise-asegbore ni esan ise asegbore re. Ti e ba si peyin da, dajudaju emi n paya iya Ojo nla fun yin
ﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰ
Odo Allahu ni ibupadasi yin. Oun si ni Alagbara lori gbogbo nnkan
ﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆ
Gbo, dajudaju awon sobe-selu musulumi n bo ohun ti n be ninu igba-aya won lati le fara pamo fun Allahu. Kiye si i, nigba ti won n yiso won bora, Allahu mo nnkan ti won n fi pamo ati nnkan ti won n safi han re. Dajudaju Oun ni Onimo nipa nnkan ti n be ninu igba-aya eda
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣ
Ko si eda abemi kan t’o wa lori ile afi ki arisiki re wa lodo Allahu. O si mo ibugbe re (nile aye) ati ile ti o maa ku si. Gbogbo re ti wa ninu akosile t’o yanju
ﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄ
Oun ni Eni ti O seda awon sanmo ati ile fun ojo mefa - Ite ola Re si wa lori omi (siwaju eyi) – nitori ki O le dan yin wo pe, ewo ninu yin l’o dara julo (nibi) ise rere. Ti o ba kuku so pe dajudaju won yoo gbe yin dide leyin iku, dajudaju awon t’o sai gbagbo yoo wi pe: “Eyi ko je kini kan bi ko se idan ponnbele.”
ﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜ
Dajudaju ti A ba sun iya siwaju fun won di igba t’o ni onka, dajudaju won yoo wi pe: “Ki l’o n da a duro na?” Gbo, ni ojo ti iya yoo de ba won, ko nii se e gbe kuro fun won. Ati pe ohun ti won n fi se yeye si maa diya t’o maa yi won po
ﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨ
Ati pe dajudaju ti A ba fi ike kan to eniyan lenu wo lati odo Wa, leyin naa, ti A ba gba a kuro lowo re, dajudaju o maa di olusoretinu, alaimoore
ﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘ
Dajudaju ti A ba si fun un ni idera towo leyin inira t’o fowo ba a, dajudaju o maa wi pe: “Awon aburu ti kuro lodo mi.” Dajudaju o maa di alayoporo, onifaari
ﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣ
Ayafi awon t’o ba se suuru, ti won si se awon ise rere. Awon wonyen, ti won ni aforijin ati esan t’o tobi
ﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁ
Boya o fe gbe apa kan ohun ti A fi ranse si o sile, ki irewesi si ba okan re nipa re (ni ti ipaya pe) won n wi pe: "Ki ni ko je ki apoti-oro kan sokale fun un, tabi ki molaika kan ba a wa?” Olukilo ni iwo. Allahu si ni Oluso lori gbogbo nnkan
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤ
Tabi won n wi pe: “O hun un ni.” So pe: “E mu surah mewaa adahun bi iru re wa, ki e si ke si eni ti e ba le ke si leyin Allahu ti e ba je olododo.”
ﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶ
Nigba naa ti won ko ba da yin lohun, ki e mo pe dajudaju won so (al-Ƙur’an) kale pelu imo Allahu. Ati pe ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. Nitori naa, se eyin yoo di musulumi
ﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅ
Enikeni ti o ba n fe isemi aye ati oso re, A oo san won ni esan ise won nile aye. A o si nii din kini kan ku fun won nile aye
ﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗ
Awon wonyen ni awon ti ko nii si kini kan fun mo ni Ojo Ikeyin afi Ina. Nnkan ti won gbele aye si maa baje. Ofo si ni ohun ti won n se nise
ﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤ
Nje eni t’o n be lori eri t’o yanju lati odo Oluwa re (iyen, Anabi s.a.w.), ti olujerii kan (iyen, molaika Jibril) si n ke al-Ƙur’an (fun un) lati odo Allahu, ti tira (Anabi) Musa si ti wa siwaju re, ti o je tira ti won n tele, o si je ike (fun won), (nje Anabi yii jo olusina bi?) Awon (musulumi) wonyi ni won si gba a gbo ni ododo. Enikeni t’o ba sai gba a gbo ninu awon ijo (nasara, yehudi ati osebo), nigba naa Ina ni adehun re. Nitori naa, ma se wa ninu iyemeji nipa al-Ƙur’an. Dajudaju ododo ni lati odo Oluwa re, sugbon opolopo eniyan ni ko gbagbo
ﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾ
Ati pe ta ni o sabosi ju eni t’o da adapa iro mo Allahu? Awon wonyen ni won yoo ko wa siwaju Oluwa won. Awon elerii (iyen, awon molaika) yo si maa so pe: "Awon wonyi ni awon t’o paro mo Oluwa won." Gbo, ibi dandan Allahu ki o maa ba awon alabosi
ﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆﰇﰈﰉﰊ
awon t’o n seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Allahu, ti won si n fe ko wo. Awon si ni alaigbagbo ninu Ojo Ikeyin
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫ
Awon wonyen ko le mori bo ninu iya Allahu lori ile ati pe ko si alaabo kan fun won leyin Allahu. A o si se adipele iya fun won. Won ko le gbo. Ati pe won ki i riran (ri ododo)
ﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵ
Awon wonyen ni awon t’o se emi ara won lofo. Ohun ti won si n da ni adapa iro ti di ofo mo won lowo
ﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽ
Ni ti ododo, dajudaju awon gan-an ni eni ofo julo ni Ojo Ikeyin
ﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍ
Dajudaju awon t’o gbagbo ni ododo, ti won se awon ise rere, ti won si dunni mo ironupiwada sodo Oluwa won, awon wonyen ni ero inu Ogba Idera. Olusegbere ni won ninu re
ﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜ
Afiwe ijo mejeeji da bi afoju ati aditi pelu oluriran ati olugboro. Nje awon mejeeji dogba ni afiwe bi? Se e o nii lo iranti ni
ﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦ
A si kuku ti ran (Anabi) Nuh si ijo re (lati so pe) dajudaju olukilo ponnbele ni mo je fun yin
ﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔ
(Mo n kilo) pe ki e ma se josin fun eni kan afi Allahu. Dajudaju emi n paya iya ojo eleta-elero fun yin
ﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲ
Awon asiwaju t’o sai gbagbo ninu ijo re si wi pe: "Awa ko mo o si eni kan tayo abara bi iru wa. Awa ko si mo awon t’o tele o si eni kan kan tayo awon eni yepere ninu wa, olopolo bin-intin. Ati pe awa ko ri yin si eni t’o fi ona kan kan ni ajulo lori wa, sugbon a ka yin kun opuro
ﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆ
(Anabi Nuh) so pe: "Eyin ijo mi, e so fun mi, ti mo ba wa lori eri t’o yanju lati odo Oluwa mi, ti O si fun mi ni ike kan lati odo Re, ti won ko si je ki e riran ri (ododo naa), nje a oo fi dandan mu yin bi, nigba ti emi yin ko o
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪ
Eyin ijo mi, emi ko bi yin leere owo kan lori re. Ko si esan mi nibi kan bi ko se lodo Allahu. Emi ko si nii le awon t’o gbagbo danu. Dajudaju won yoo pade Oluwa won, sugbon dajudaju emi n ri yin si ijo alaimokan
ﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵ
Eyin ijo mi, ta ni o maa ran mi lowo nibi (iya) Allahu ti mo ba le won danu? Se e o nii lo iranti ni
ﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖ
Emi ko si so fun yin pe awon ile-owo Allahu n be lodo mi. Emi ko si mo ikoko. Emi ko si so pe molaika ni mi. Emi ko si le so fun awon ti e n foju bin-intin wo pe, Allahu ko nii soore fun won. Allahu nimo julo nipa nnkan t’o n be ninu emi won. Bi bee ko nigba naa, dajudaju mo ti wa ninu awon alabosi
ﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤ
Won wi pe: "Iwo Nuh, O ma kuku ti ja wa niyan. O si se ariyanjiyan pupo pelu wa. Nitori naa, mu ohun ti o se ni ileri fun wa wa ti o ba wa lara awon olododo
ﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯ
(Anabi Nuh) so pe: "Allahu l’O maa mu un wa ba yin ti O ba fe. Eyin ko si nii mori bo
ﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤ
Imoran mi ko si le se yin ni anfaani ti mo ba fe gba yin nimoran, ti Allahu ba fe pa yin run. Oun ni Oluwa yin. Odo Re si ni won yoo da yin pada si
ﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲ
Tabi won n wi pe: "O hun un ni." So pe: "Ti mo ba hun un, emi ni mo ni ese mi. Emi si yowo yose ninu ohun ti e n da lese
ﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄ
A si fi imisi ranse si (Anabi) Nuh pe dajudaju ko si eni kan ti o maa gbagbo mo ninu ijo re afi eni t’o ti gbagbo tele. Nitori naa, ma se banuje nipa nnkan ti won n se nise
ﰅﰆﰇﰈﰉﰊﰋﰌﰍﰎﰏﰐ
Ki o si kan oko oju-omi naa loju Wa (bayii) pelu imisi Wa. Ma si se ba Mi soro nipa awon t’o sabosi. Dajudaju A maa te won ri ni
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥ
O si n kan oko oju-omi naa lo. Nigbakigba ti awon otokulu ninu ijo re ba koja lodo re, won yo si maa fi se yeye. (Anabi Nuh) si so pe: "Ti e ba fi wa se yeye, dajudaju awa naa yoo fi yin se yeye gege bi e se n fi wa se yeye
ﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰ
Nitori naa, laipe e maa mo eni ti iya maa de ba, ti o maa yepere re, ti iya gbere si maa ko le lori
ﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌ
(Bayii ni oro wa) titi di igba ti ase Wa de, omi si seyo gbuu lati oju-aro (ti won ti n se buredi). A so pe: "Ko gbogbo nnkan ni orisi meji tako-tabo ati ara ile re sinu oko oju-omi - ayafi eni ti oro naa ti ko le lori (fun iparun) - ati enikeni t’o gbagbo ni ododo. Ko si si eni t’o ni igbagbo ododo pelu re afi awon die
ﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚ
(Anabi Nuh) so pe: "E wo inu oko oju-omi naa. O maa rin, o si maa gunle ni oruko Allahu. Dajudaju Oluwa mi ni Alaforijin, Asake-orun
ﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮ
O si n gbe won lo ninu igbi omi t’o da bi apata. (Anabi Nuh) si ke si omokunrin re, ti o ti yara re soto: "Omokunrin mi, gun oko oju-omi pelu wa. Ma si se wa pelu awon alaigbagbo
ﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩ
O wi pe: “Emi yoo fori pamo sibi apata kan ti o maa la mi nibi omi.” (Anabi Nuh) so pe: "Ko si alaabo kan ni oni nibi ase Allahu afi eni ti Allahu ba saanu." Igbi omi si la awon mejeeji laaarin. O si di ara awon oluteri sinu omi
ﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼ
A so pe: "Ile, fa omi re mu. Sanmo, dawo (ojo) duro." Won si din omi ku. Oro iparun won si wa si imuse. (Oko oju-omi) si gunle sori apata Judi. A si so pe: “Ijinna rere si ike Allahu ni ti ijo alabosi.”
ﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆﰇﰈﰉﰊﰋﰌ
(Anabi) Nuh pe Oluwa re, o si so pe: “Oluwa mi, dajudaju omo mi wa ninu ara ile mi. Ati pe dajudaju adehun Re, ododo ni. Iwo l’O si mo ejo da julo ninu awon adajo
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫ
Allahu so pe: “Nuh, dajudaju ko si ninu ara ile re (ni ti esin). Dajudaju ise ti ko dara ni. Nitori naa, o o gbodo bi Mi leere nnkan ti o o ni imo nipa re. Dajudaju Emi n kilo fun o nitori ki o ma baa di ara awon alaimokan.”
ﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀ
O so pe: "Oluwa mi, dajudaju emi n sa di O nibi ki ng bi O leere nnkan ti emi ko ni imo re. Ti O o ba forijin mi, ki O si saanu mi, emi yoo wa lara awon eni ofo
ﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔ
A so pe: "Nuh, sokale pelu alaafia lati odo Wa. Ati pe ki ibukun wa pelu re ati awon ijo ninu awon t’o n be pelu re. Awon ijo kan (tun n bo), ti A oo fun won ni igbadun (oore aye). Leyin naa, iya eleta-elero yo si fowo ba won lati odo Wa
ﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫ
Iwonyi wa ninu iro ikoko ti A n fi (imisi re) ranse si o. Iwo ati ijo re ko nimo re siwaju eyi (ti A sokale fun o). Nitori naa, se suuru. Dajudaju ikangun rere wa fun awon oluberu (Allahu)
ﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠ
(Eni ti A ran nise) si iran ‘Ad ni arakunrin won, (Anabi) Hud. O so pe: “Eyin ijo mi, e josin fun Allahu. E e ni olohun miiran leyin Re. Eyin ko si je kini kan bi ko se aladaapa iro
ﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰ
Eyin ijo mi, emi ko bi yin leere owo-oya kan lori re. Ko si esan mi nibi kan bi ko se lodo Eni ti O pile iseda mi. Se e o nii se laakaye ni
ﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂ
Eyin ijo mi, e toro aforijin lodo Oluwa Eledaa yin, leyin naa, ki e ronu piwada sodo Re nitori ki O le rojo fun yin ni pupo lati sanmo ati nitori ki O le se alekun agbara kun agbara yin. E ma se peyin da lati di elese (sinu aigbagbo)
ﰃﰄﰅﰆﰇﰈﰉﰊﰋﰌﰍﰎﰏﰐﰑﰒ
Won wi pe: "Hud, o o mu eri kan t’o yanju wa fun wa. Awa ko si nii gbe awon orisa wa ju sile nitori oro (enu) re. Ati pe awa ko ni igbagbo ninu re
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢ
nkan ti a n so fun o ni pe awon kan ninu awon orisa wa ti fi inira kan o (l’o fi n so isokuso nipa won)." O so pe: "Dajudaju emi n fi Allahu se Elerii ati pe ki eyin naa jerii pe dajudaju emi yowo yose ninu ohun ti e n fi sebo
ﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫ
dipo jijosin fun Allahu. Nitori naa, e parapo dete si mi. Leyin naa, ki e ma se lo mi lara
ﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀ
Dajudaju emi gbarale Allahu, Oluwa mi ati Oluwa yin. Ko si eda kan afi ki (o je pe) Oun l’O maa fi aaso ori re mu un. Dajudaju Oluwa mi wa lori ona taara
ﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘ
Nitori naa, ti e ba peyin da (nibi ododo), mo kuku ti fi ohun ti Won fi ran mi nise jise fun yin, Oluwa mi yo si fi ijo kan t’o maa yato si eyin ropo yin. E o si le ko inira kan kan ba A. Dajudaju Oluwa mi ni Oluso lori gbogbo nnkan
ﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧ
Nigba ti ase Wa de, A gba (Anabi) Hud ati awon t’o gbagbo pelu re la pelu ike lati odo Wa; A gba won la ninu iya t’o nipon
ﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖ
Iran ‘Ad niyen; won tako awon ayah Oluwa won. Won si yapa awon Ojise won. Won si tele ase gbogbo awon alafojudi alatako-ododo
ﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪ
A fi egun tele won nile aye yii ati ni Ojo Ajinde. Gbo, dajudaju iran ‘Ad sai gbagbo ninu Oluwa won. Kiye si i, ijinna rere si ike n be fun iran ‘Ad, ijo (Anabi) Hud
ﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆﰇﰈﰉﰊ
(Eni ti A ran nise) si iran Thamud ni arakunrin won, (Anabi) Solih. O so pe: “Eyin ijo mi, e josin fun Allahu. E e ni olohun miiran leyin Re. Oun l’O pile iseda yin lati ara (erupe) ile. O si fun yin ni isemi lo lori re. Nitori naa, e toro aforijin lodo Re. Leyin naa, e ronu piwada sodo Re. Dajudaju Oluwa mi ni Olusunmo, Olujepe (eda).”
ﰋﰌﰍﰎﰏﰐﰑﰒﰓﰔﰕﰖﰗﰘﰙﰚﰛﰜﰝﰞﰟﰠﰡ
Won wi pe: “Solih, o ti wa laaarin wa ni eni ti a ni ireti si (pe o maa sanjo) siwaju (oro ti o so) yii. Se o maa ko fun wa lati josin fun ohun ti awon baba wa n josin fun ni? Dajudaju awa ma wa ninu iyemeji t’o gbopon nipa nnkan ti o n pe wa si.”
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨ
O so pe: "Eyin ijo mi, e so fun mi, ti o ba je pe emi wa lori eri t’o yanju lati odo Oluwa mi, ti ike kan si de ba mi lati odo Re, ta ni eni ti o maa ran mi lowo ninu (iya) Allahu ti mo ba yapa Re? Ko si kini kan ti e le fi se alekun re fun mi yato si iparun
ﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼ
Eyin ijo mi, eyi ni abo rakunmi Allahu. O je ami fun yin. Nitori naa, e fi sile, ki o maa je kiri lori ile Allahu. E ma se fi inira kan an nitori ki iya t’o sunmo ma baa je yin
ﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉ
Won si gun un pa. O so pe: “E jegbadun ninu ile yin fun ojo meta (ki iya yin to de). Iyen ni adehun ti ki i se iro.”
ﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝ
Nigba ti ase Wa de, A gba (Anabi) Solih ati awon t’o gbagbo pelu re la pelu ike lati odo Wa. (A tun gba won la) ninu abuku ojo yen. Dajudaju Oluwa Re, Oun ni Alagbara, Olubori (eda)
ﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦ
Ohun igbe lile gba awon t’o sabosi mu. Won si di eni t’o da lule, ti won ti doku sinu ilu won
ﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖ
Afi bi eni pe won ko gbenu ilu naa ri. Gbo, dajudaju iran Thamud sai gbagbo ninu Oluwa won. Kiye si i, ijinna rere si ike n be fun ijo Thamud
ﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨ
Dajudaju awon Ojise Wa ti mu iro idunnu wa ba (Anabi) ’Ibrohim. Won so pe: “Alaafia (fun o).” O so pe: “Alaafia (fun yin).” Ko si pe rara t’o fi gbe omo maalu ayangbe wa
ﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼ
Nigba ti o ri owo won pe ko kan ounje, o f’oju odi wo (aijeun) won. Iberu won si wa ninu okan re. Won so pe: “Ma se beru. Dajudaju awon eniyan (Anabi) Lut ni Won ran awa si.”
ﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆ
Iyawo re wa ni iduro, o rerin-in. A si fun un ni iro idunnu (pe o maa bi) ’Ishaƙ. Ati pe leyin ’Ishaƙ ni Ya‘ƙub (iyen, omoomo)
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞ
O so pe: “Hen-en! Se pe mo maa bimo? Arugbobinrin ni mi, baale mi yii si ti dagbalagba! Dajudaju eyi ni nnkan iyanu.”
ﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯ
Won so pe: “Se o maa seemo nipa ase Allahu ni? Ike Allahu ati ibukun Re ki o maa be fun yin, eyin ara ile (yii). Dajudaju Allahu ni Olope, Eleyin.”
ﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻ
Nigba ti iberu kuro lara (Anabi) ’Ibrohim, ti iro idunnu si ti de ba a, o si n parowa fun (awon Ojise) Wa nipa ijo (Anabi) Lut
ﭼﭽﭾﭿﮀﮁ
Dajudaju (Anabi) ’Ibrohim ni alafarada, oluraworase, oluronupiwada
ﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒ
(Anabi) ’Ibrohim, seri kuro nibi eyi. Dajudaju ase Oluwa re ti de. Ati pe dajudaju awon ni iya ti ko se e da pada yoo de ba
ﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠ
Nigba ti awon Ojise Wa de ba (Anabi) Lut, o banuje nitori won. Agbara re ko si ka oro won mo. O si so pe: “Eyi ni ojo t’o le pupo.”
ﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟ
Awon eniyan re wa ba a, ti won n sare gbon wa si odo re. Teletele won si ti n se ise aburu (bii ibalopo laaarin okunrin ati okunrin). O so pe: "Eyin eniyan mi, awon wonyen ni omobinrin mi, won mo julo fun yin (lati fi saya). Nitori naa, e beru Allahu. Ki e si ma se doju ti mi lodo alejo mi. Se ko si okunrin olumona kan ninu yin ni
ﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭ
Won wi pe: “Iwo kuku ti mo pe awa ko letoo kan si awon omobinrin re. O si ti mo nnkan ti a n fe.”
ﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹ
O so pe: "Ti o ba je pe dajudaju agbara kan wa fun mi lori yin ni, tabi (pe) mo le darapo mo ebi kan t’o lagbara ni, (emi iba di yin lowo nibi aburu yin)
ﯺﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆﰇﰈﰉﰊﰋﰌﰍﰎﰏﰐﰑﰒﰓﰔﰕﰖﰗﰘﰙﰚﰛﰜﰝ
(Awon molaika) so pe: “(Anabi) Lut, dajudaju Ojise Oluwa re ni awa. Won ko le (fowo aburu) kan o. Nitori naa, mu awon ara ile re jade ni abala kan ninu oru. Ki eni kan ninu yin ma si se siju weyin wo, afi iyawo re, dajudaju adanwo re ni ohun ti o maa sele si won. Dajudaju akoko (adanwo) won ni owuro. Se owuro ko sunmo ni
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝ
Nigba ti ase Wa de, A so oke ilu won di isale re (ilu won si doju bole). A tun ro ojo okuta amo (sisun) le won lori ni telentele
ﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧ
(Awon okuta naa) ti ni ami (oruko eni kookan won lara) lati odo Oluwa re. Won ko si jinna si awon alabosi
ﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆ
(Eni ti A ran nise) si iran Modyan ni arakunrin won, (Anabi) Sua‘eb. O so pe: "Eyin ijo mi, e josin fun Allahu. E e ni olohun miiran leyin Re. E ma se din kongo ati osuwon ku. Mo ri yin pelu daadaa (ti Allahu se fun yin). Dajudaju emi si n paya iya ojo kan ti o maa yi yin po
ﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖ
Eyin ijo mi, e won kongo ati osuwon kun ni dogbadogba. E ma se din nnkan awon eniyan ku. Ki e si ma se bale je ni ti obileje
ﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣ
Ohun ti Allahu ba seku fun yin (ninu halal) loore julo fun yin ti e ba je onigbagbo ododo. Emi ki i si se oluso lori yin
ﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚ
Won wi pe: "Su‘aeb, se irun re l’o n pa o lase pe ki a gbe ohun ti awon baba wa n josin fun ju sile, tabi (irun re lo n ko fun wa) lati se ohun ti a ba fe ninu dukia wa? Dajudaju iwo ma ni alafarada, olumona (loju ara re niyen)
ﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂ
O so pe: “Eyin ijo mi, e so fun mi, ti o ba je pe mo wa lori eri t’o yanju lati odo Oluwa mi, ti (Oluwa mi) si fun mi ni arisiki lati odo Re ni arisiki t’o dara (se ki ng maa je haramu pelu re ni?). Emi ko si fe yapa yin nipa nnkan ti mo n ko fun yin (iyen ni pe, emi naa n lo ohun ti mo n so fun yin). Ko si ohun ti mo fe bi ko se atunse pelu bi mo se lagbara mo. Ko si konge imona kan fun mi bi ko se pelu (iyonda) Allahu. Oun ni mo gbarale. Odo Re si ni mo maa seri si (fun ironupiwada)
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨ
Eyin ijo mi, e ma se je ki (bi) e se n yapa mi mu yin lugbadi iru ohun ti o sele si ijo (Anabi) Nuh tabi ijo (Anabi) Hud tabi ijo (Anabi) Solih. Ijo (Anabi) Lut ko si jinna si yin
ﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳ
Ki e si toro aforijin lodo Oluwa yin. Leyin naa, ki e ronu piwada sodo Re. Dajudaju Oluwa mi ni Alaaanu, Ololufe (eda).”
ﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈ
Won wi pe: "Su‘aeb, a o gbo agboye opolopo ninu ohun ti o n so. Dajudaju awa si n ri o ni ole laaarin wa. Ti ko ba je pe nitori ti ebi re ni, a iba ti ku o loko pa; iwo ko si nii lagbara kan lori wa
ﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙ
O so pe: “Eyin ijo mi, se ebi mi lo lagbara loju yin ju Allahu? E si so Allahu di Eni ti e koyin kopako si! Dajudaju Oluwa mi ni Alamotan nipa ohun ti e n se nise
ﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯ
Eyin ijo mi, e maa se bi e ti fe ninu esin yin, dajudaju emi yoo maa ba esin mi lo. Laipe eyin yoo mo eni ti iya maa de ba, ti o maa yepere re, (eyin yo si mo) ta ni opuro. Nitori naa, e maa reti. Dajudaju emi naa wa pelu yin ti mo n reti (ikangun oro yin).”
ﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣ
Nigba ti ase Wa de, A gba (Anabi) Su‘aeb ati awon t’o gbagbo pelu re la pelu ike lati odo Wa. Ohun igbe lile t’o mi ile titi gba won mu. Won si di eni t’o da lule, ti won ti doku sinu ilu won
ﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯ
Afi bi eni pe won ko gbe inu ilu naa ri. Gbo, ijinna si ike n be fun iran Modyan gege bi iran Thamud se jinna si ike
ﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶ
Dajudaju A fi awon ami Wa ati eri ponnbele ran (Anabi) Musa
ﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂ
si Fir‘aon ati awon ijoye re. Awon eniyan si tele ase Fir‘aon. Ase Fir‘aon ko si je imona
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛ
O maa siwaju ijo re ni Ojo Ajinde. O si maa ko won wo inu Ina. Wiwo Ina naa si buru
ﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦ
A fi egun tele won nile aye yii ati ni Ojo Ajinde. Ebun egun ti A fun won si buru
ﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱ
Iyen wa ninu awon iro ilu ti A n so itan re fun o. O wa ninu awon ilu naa eyi ti o si n je ilu ati eyi ti o ti pare
ﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌ
A o sabosi si won, sugbon won sabosi si emi ara won. Nitori naa, awon orisa won, ti won n pe leyin Allahu, ko ro won loro nigba ti ase Oluwa re de. Won ko se alekun kan fun won bi ko se iparun
ﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚ
Bayen ni igbamu Oluwa re. Nigba ti O ba gba awon ilu alabosi mu, dajudaju O maa gba a mu pelu iya eleta-elero t’o le
ﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬ
Dajudaju ami wa ninu iyen fun enikeni t’o paya iya Ojo Ikeyin. Iyen ni ojo ti A oo ko awon eniyan jo. Ati pe iyen ni ojo ti gbogbo eda yoo foju ri
ﮭﮮﮯﮰﮱﯓ
A o si fi fale bi ko se di akoko t’o lojo
ﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟ
Ni ojo t’o ba de, emi kan ko nii soro afi pelu iyonda Allahu. Olori buruku ati olori ire yo si wa ninu awon eda (ni ojo naa)
ﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩ
Ni ti awon t’o ba sori buruku, won yoo wa ninu Ina. Won yoo maa gbin too, won yo si maa ke too
ﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺ
Olusegbere ni won ninu re ni odiwon igba ti awon sanmo ati ile fi n be, afi ohun ti Oluwa re ba fe . Dajudaju Oluwa ni Aseyi-o-wuu
ﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆﰇﰈﰉﰊﰋﰌﰍﰎﰏ
Ni ti awon ti A ba se ni olori-ire, won maa wa ninu Ogba Idera. Olusegbere ni won ninu re ni odiwon igba ti awon sanmo ati ile fi n be,1 afi ohun ti Oluwa re ba fe.2 (Ogba Idera je) ore ailopin
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧ
Nitori naa, ma se wa ninu royiroyi nipa ohun ti awon wonyi n josin fun. Won ko josin fun kini kan bi ko se bi awon baba won naa se n josin (fun awon orisa) ni isaaju. Dajudaju Awa yoo san won ni esan ipin (iya) won lai nii ku sibi kan
ﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼ
A kuku fun (Anabi) Musa ni Tira. Won si yapa enu nipa re. Ati pe ti ki i ba se oro kan ti o ti gbawaju lati odo Oluwa re ni, Awa iba ti sedajo laaarin won. Dajudaju won kuku wa ninu iyemeji t’o gbopon nipa al-Ƙur’an
ﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈ
Dajudaju eni kookan won ni Oluwa re yoo san ni esan ise won. Dajudaju Oun ni Alamotan nipa ohun ti won n se nise
ﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖ
Duro sinsin gege bi A se pa iwo ati enikeni ti o ba ronu piwada pelu re lase. E ma se tayo enu-ala. Dajudaju Oun ni Oluriran nipa ohun ti e n se nise
ﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨ
E ma se te sodo awon t’o sabosi nitori ki Ina ma baa fowo ba yin. Ko si nii si awon alaabo fun yin leyin Allahu. Leyin naa, A o nii ran yin lowo
ﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚ
Kirun ni ibere ati ipari osan (iyen, irun Subh, Thuhr ati ‘Asr) ati ni ibere oru (iyen, irun Mogrib ati ‘Isa’). Dajudaju awon ise rere n pa awon ise aburu re. Iyen ni iranti fun awon oluranti (Allahu)
ﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢ
Se suuru. Dajudaju Allahu ko nii fi esan awon oluse-rere rare
ﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾ
Ki o si je pe awon onilaakaye kan wa ninu awon iran t’o siwaju yin (ninu awon ti A pare) ki won maa ko ibaje lori ile – afi eniyan die lara awon ti A gbala ninu won. - Awon t’o sabosi si tele nnkan ti A fi se gbedemuke fun won. Won si je elese
ﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆﰇ
Oluwa re ko nii pa awon ilu run lona abosi, nigba ti awon eniyan re ba je olusatun-unse
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜ
Ti o ba je pe Oluwa re ba fe, iba se awon eniyan ni ijo elesin kan soso. (Amo) won ko nii ye yapa enu (si ’Islam)
ﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮ
afi eni ti Oluwa re ba ke. Nitori iyen l’O fi seda won. Oro Oluwa re si ti se (bayii pe): “Dajudaju Emi yoo mu ninu awon alujannu ati eniyan ni apapo kunnu ina Jahanamo.”
ﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁ
Gbogbo (nnkan ti) A n so itan re fun o ninu awon iro awon Ojise ni eyi ti A fi n fi o lokan bale. Ododo tun de ba o ninu (surah) yii. Waasi ati iranti tun ni fun awon onigbagbo ododo
ﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋ
Ki o si so fun awon ti ko gbagbo pe: "E maa se bi e ti fe ninu esin yin. Dajudaju awa naa yoo maa ba esin wa lo
ﮌﮍﮎﮏ
E maa reti, dajudaju Awa naa n reti
ﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡ
Ti Allahu ni ikoko awon sanmo ati ile. Odo Re si ni won maa seri gbogbo oro eda pada si. Nitori naa, josin fun Un, ki o si gbarale E. Oluwa re ki i si se onigbagbera nipa nnkan ti e n se nise
Al-Kur'an
Tuesday, August 18, 2026
Don't forget us in your sincere prayers







