54 Ẹsẹ · Meccan · Yorùbá
bismillah
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣ
34:1 Gbogbo ope n je ti Allahu, Eni ti ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile n je tiRe. Ati pe tiRe ni gbogbo ope ni orun. Oun si ni Ologbon, Alamotan
ﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷ
34:2 O mo ohunkohun t’o n wonu ile ati ohunkohun t’o n jade latinu re. (O mo) ohunkohun t’o n sokale latinu sanmo ati ohunkohun t’o n gunke lo sinu re. Oun si ni Asake-orun, Alaforijin
ﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚ
34:3 Awon alaigbagbo wi pe: “Akoko naa ko nii de ba wa.” So pe: “Bee ko. Emi fi Oluwa mi bura. Dajudaju o maa de ba yin (lati odo) Onimo-ikoko (Eni ti) odiwon omo ina-igun ko pamo fun ninu sanmo ati ninu ile. (Ko si nnkan ti o) kere si iyen tabi ti o tobi (ju u lo) afi ki o wa ninu akosile t’o yanju.”
ﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦ
34:4 (O maa sele) nitori ki Allahu le san esan fun awon t’o gbagbo ni ododo, ti won tun se ise rere. Awon wonyen ni aforijin ati ese alapon-onle n be fun
ﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓ
34:5 Ati pe awon t’o se ise buruku nipa awon ayah Wa, (ti won lero pe) awon mori bo ninu iya; awon wonyen ni iya eleta-elero t’o buru n be fun
ﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤ
34:6 Awon ti A fun ni imo ri i pe eyi ti won sokale fun o lati odo Oluwa re, ohun ni ododo, ati pe o n se itosona si ona Alagbara, Eleyin
ﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵ
34:7 Awon t’o sai gbagbo wi pe: “Se ki a toka yin si okunrin kan ti o maa fun yin ni iro pe nigba ti won ba fon yin ka tan patapata (sinu erupe), pe dajudaju e maa pada wa ni eda titun
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢ
34:8 Se o da adapa iro mo Allahu ni tabi alujannu n be lara re ni?” Rara o! Awon ti ko gba Ojo Ikeyin gbo ti wa ninu iya ati isina t’o jinna
ﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂ
34:9 Se won ko ri ohun t’o n be niwaju won ati ohun t’o n be leyin won ni sanmo ati ile? Ti A ba fe, Awa iba je ki ile ri mo won lese, tabi ki A ja apa kan sanmo lule le won lori mole. Dajudaju ami kan wa ninu iyen fun gbogbo erusin, oluronupiwada
ﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒ
34:10 Dajudaju A ti fun (Anabi) Dawud ni oore ajulo lati odo Wa; Eyin apata, e se afomo pelu re. (A pe) awon eye naa (pe ki won se bee.) A si ro irin fun un
ﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡ
34:11 (A so fun un) pe se awon ewu irin t’o maa bo ara, se oruka-orun fun ewu irin naa niwon-niwon. Ki e si se rere. Dajudaju Emi ni Oluriran nipa ohun ti e n se nise
ﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡ
34:12 Ati pe (A te) ategun lori ba fun (Anabi) Sulaemon, irin osu kan ni irin owuro re, irin osu kan si ni irin irole re . A si mu ki odo ide maa san ninu ile fun un. O si wa ninu awon alujannu, eyi t’o n sise (fun un) niwaju re pelu iyonda Oluwa re. Ati pe eni ti o ba gbunri kuro nibi ase Wa ninu won, A maa fun un ni iya ina t’o n jo fofo to wo
ﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷ
34:13 Won n se ise ti o ba fe fun un nipa mimo awon ile t’o dara, awon ere, awo koto fife bi abata ati awon ikoko t’o ridii mule. Eyin eniyan (Anabi) Dawud, e sise idupe (fun Allahu). Die ninu awon erusin Mi si ni oludupe
ﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆﰇﰈﰉﰊﰋﰌﰍﰎﰏﰐﰑﰒﰓﰔ
34:14 Nigba ti A pase pe ki iku pa (Anabi) Sulaemon, ko si ohun ti o mu awon alujannu mo pe o ti ku bi ko se kokoro inu ile kan ti o je opa re. Nigba ti o wo lule, o han kedere si awon alujannu pe ti o ba je pe awon ni imo ikoko ni, awon iba ti wa ninu (ise) iya t’o n yepere eda
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨ
34:15 Dajudaju ami kan wa fun awon Saba’ ninu ibugbe won; (ohun ni) ogba oko meji t’o wa ni otun ati ni osi. “E je ninu arisiki Oluwa yin. Ki e si dupe fun Un.” Ilu t’o dara ni (ile Saba’. Allahu si ni) Oluwa Alaforijin
ﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹ
34:16 Won gbunri (nibi esin). Nitori naa, A ran adagun odo ti won mo odi yika si won. A si paaro oko won mejeeji fun won pelu oko meji miiran ti o je oko eleso kikoro, oko igi elegun-un ati kini kan die ninu igi sidir
ﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃ
34:17 Iyen ni A fi san won ni esan nitori pe won sai moore. Nje A maa san eni kan lesan iya bi ko se alaimoore
ﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖ
34:18 A si fi awon ilu kan t’o han si aarin ilu ti A ran adagun odo si ati awon ilu ti A fi ibukun si. A si seto ibuso niwon-niwon fun irin-ajo sise sinu awon ilu naa. E rin lo sinu won ni oru ati ni oju ojo pelu ifayabale
ﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫ
34:19 (Awon ara ilu Saba’) wi pe: “Oluwa wa, mu awon irin-ajo wa lati ilu kan si ilu miiran jinna sira won.” Won se abosi si emi ara won. A si so won di itan. A si fon won ka patapata. Dajudaju awon ami kan wa ninu iyen fun gbogbo onisuuru, oludupe
ﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗ
34:20 Dajudaju ’Iblis ti so aba re di ododo le won lori. Won si tele e afi igun kan ninu awon onigbagbo ododo
ﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮ
34:21 (’Iblis) ko si ni agbara kan lori won bi ko se pe ki A le safi han eni t’o gba Ojo Ikeyin gbo kuro lara eni t’o wa ninu iyemeji nipa re. Oluso si ni Oluwa re lori gbogbo nnkan
ﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆﰇﰈﰉ
34:22 So pe: “E pe awon ti e so pe (won je oluwa) leyin Allahu.” Won ko ni ikapa odiwon omo-ina igun ninu sanmo tabi ninu ile. Won ko si ni ipin kan ninu mejeeji. Ati pe ko si oluranlowo kan fun Allahu laaarin won
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪ
34:23 Isipe ko si nii sanfaani lodo Allahu afi fun eni ti O ba yonda fun. (Inufu-ayafu ni awon olusipe ati awon olusipe-fun maa wa) titi A oo fi yo ijaya kuro ninu okan won. Won si maa so (fun awon molaika) pe: “Ki ni Oluwa yin so (ni esi isipe)?” Won maa so pe: “Ododo l’O so (isipe yin ti wole. Allahu) Oun l’O ga, O tobi
ﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿ
34:24 So pe: “Ta ni O n pese fun yin lati inu awon sanmo ati ile?” So pe: “Allahu ni.” Dajudaju awa tabi eyin wa ninu imona tabi ninu isina ponnbele
ﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉ
34:25 So pe: “Won ko nii bi yin leere nipa ese ti a da; won ko si nii bi awa naa nipa ohun ti e n se nise.”
ﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕ
34:26 So pe: “Oluwa wa yoo ko wa jo papo. Leyin naa, O maa fi ododo sedajo laaarin wa. Oun si ni Onidaajo, Onimo.”
ﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤ
34:27 So pe: “E fi han mi na awon orisa ti e dapo mo Allahu.” Rara (ko ni akegbe). Rara se, Oun ni Alagbara, Ologbon
ﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱ
34:28 A o ran o nise afi si gbogbo eniyan patapata; (o je) oniroo-idunnu ati olukilo sugbon opolopo awon eniyan ko mo
ﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚ
34:29 Won si n wi pe: “Igba wo ni adehun yii yoo se ti e ba je olododo?”
ﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥ
34:30 So pe: “Adehun ojo kan n be fun yin, ti eyin ko le sun siwaju di igba kan, e o si le fa a seyin.”
ﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆﰇ
34:31 Awon t’o sai gbagbo wi pe: “A o nii ni igbagbo ninu al-Ƙur’an yii ati eyi t’o wa siwaju re.” Ti o ba je pe o ba ri won ni nigba ti won ba da awon alabosi duro niwaju Oluwa won, (o maa ri won ti) apa kan won yoo da oro naa pada si apa kan; awon ti won so di ole (ninu won) yoo wi fun awon t’o segberaga (ninu won) pe: “Ti ki i ba se eyin ni, awa iba je onigbagbo ododo.”
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡ
34:32 Awon t’o segberaga yo si wi fun awon ti won so di ole pe: “Se awa l’a se yin lori kuro ninu imona leyin ti o de ba yin? Rara o! Odaran ni yin ni.”
ﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇ
34:33 Awon ti won so di ole yo si wi fun awon t’o segberaga pe: “Rara! Ete oru ati osan (lati odo yin loko ba wa) nigba ti e n pa wa ni ase pe ki a sai gbagbo ninu Allahu, ki a si so (awon kan) di egbe Re.” Won fi abamo won pamo nigba ti won ri iya. A si ko ewon si orun awon t’o sai gbagbo. Se A oo san won ni esan kan bi ko se ohun ti won n se nise
ﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖ
34:34 Ati pe A o ran olukilo kan si ilu kan ayafi ki awon onigbedemuke ilu naa wi pe: “Dajudaju awa sai gbagbo ninu ohun ti Won fi ran yin nise.”
ﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟ
34:35 Won tun wi pe: “Awa ni dukia ati omo ju (yin lo); won ko si nii je wa niya.”
ﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭ
34:36 So pe: “Dajudaju Oluwa mi, O n te arisiki sile fun eni ti O ba fe. O si n diwon re (fun elomiiran), sugbon opolopo awon eniyan ko mo
ﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦ
34:37 Ki i se awon dukia yin, ki i si se awon omo yin ni nnkan ti o maa mu yin sunmo Wa pekipeki afi eni ti o ba gbagbo ni ododo, ti o si se ise rere. Awon wonyen ni esan ilopo wa fun nipa ohun ti won se nise. Won yo si wa ninu awon ipo giga (ninu Ogba Idera) pelu ifayabale
ﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰ
34:38 Awon t’o n se ise aburu nipa awon ayah Wa, (ti won lero pe) awon mori bo ninu iya; awon wonyen ni won maa mu wa sinu Ina.”
ﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆﰇ
34:39 So pe: “Dajudaju Oluwa mi, O n te arisiki sile fun eni ti O ba fe. O si n diwon re fun elomiiran. Ati pe ohunkohun ti e ba na, Oun l’O maa fi (omiran) ropo re. O si l’oore julo ninu awon olupese.”
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛ
34:40 Ni ojo ti Allahu yoo ko gbogbo won jo patapata, leyin naa O maa so fun awon molaika pe: “Se eyin ni won n josin fun?”
ﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫ
34:41 Won a so pe: “Mimo fun O! Iwo ni Alaabo wa, ki i se awon. Rara (won ko josin fun wa). Awon alujannu ni won n josin fun; opolopo won ni won gba alujannu gbo
ﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾ
34:42 Nitori naa, ni oni apa kan yin ko ni ikapa anfaani, ko si ni ikapa inira fun apa kan. A si maa so fun awon t’o sabosi pe: “E to iya Ina ti e n pe niro wo.”
ﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢ
34:43 Ati pe nigba ti won ba n ke awon ayah Wa t’o yanju fun won, won a wi pe: “Ki ni eyi bi ko se okunrin kan ti o fe se yin lori kuro nibi nnkan ti awon baba yin n josin fun.” Won tun wi pe: “Ki ni eyi bi ko se adapa iro.” Ati pe awon t’o sai gbagbo wi nipa ododo nigba ti o de ba won pe: “Ki ni eyi bi ko se idan ponnbele.”
ﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯ
34:44 A o fun won ni awon tira kan kan ti won n ko eko ninu re, A o si ran olukilo kan kan si won siwaju re
ﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠ
34:45 Awon t’o siwaju won naa pe ododo niro. (Owo awon wonyi) ko si ti i te ida kan ida mewaa ninu ohun ti A fun (awon t’o siwaju). Sibesibe won pe awon Ojise Mi ni opuro. Bawo si ni bi Mo se (fi iya) ko (aburu fun won) ti ri
ﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽ
34:46 So pe: “Ohun kan soso ni mo n se waasi re fun yin pe, e duro nitori ti Allahu ni meji ati ni eyo kookan. Leyin naa, ki e ronu jinle. Ko si alujannu kan lara eni yin. Ko si je kini kan bi ko se olukilo fun yin siwaju iya lile kan.”
ﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆﰇﰈﰉﰊﰋﰌﰍﰎﰏﰐﰑ
34:47 So pe: “Emi ko bi yin leere owo-oya kan, eyin le kuku lowo yin. Ko si owo oya mi (lodo eni kan) afi lodo Allahu. Oun si ni Arinu-rode gbogbo nnkan.”
ﰒﰓﰔﰕﰖﰗﰘﰙ
34:48 So pe: “Dajudaju Oluwa mi, Onimo-ikoko l’O n mu ododo wa.”
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙ
34:49 So pe: “Ododo ti de. Iro (esu) ko le mu nnkan be, ko si le da nnkan pada (leyin to ti ku).”
ﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬ
34:50 So pe: “Ti mo ba sina, mo sina fun emi ara mi ni. Ti mo ba si mona, nipa ohun ti Oluwa mi fi ranse si mi ni imisi ni. Dajudaju Oun ni Olugbo, Alasun-unmo eda.”
ﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷ
34:51 Ti o ba je pe o le ri (esin won ni) nigba ti eru ba de ba won (ni Ojo Ajinde, o maa ri i pe), ko nii si imoribo kan (fun won). A si maa gba won mu lati aye t’o sunmo
ﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁ
34:52 Won yoo wi pe: “A gbagbo ninu (al-Ƙur’an bayii).” Bawo ni owo won se le te igbagbo ododo lati aye t’o jinna (iyen, orun).”
ﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍ
34:53 Won kuku ti sai gbagbo ninu re siwaju (nile aye). Won si n soro nipa ikoko lati aye t’o jinna (iyen, ile aye)
ﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞ
34:54 A si fi gaga si aarin awon ati ohun ti won n soju kokoro re gege bi A ti se fun awon egbe won ni isaaju. Dajudaju won wa ninu iyemeji t’o gbopon (nipa Ojo Ajinde)

Al-Kur'an


Wednesday, September 9, 2026

Don't forget us in your sincere prayers