PDF —
13 Ẹsẹ Medinan PDF
Built right in your browser — download starts automatically

Surah Al-Mumtahanah pdf — Gbà (Yorùbá)

Surah Al-Mumtahanah pdf Yorùbá — Gbà Surah Al-Mumtahanah Itumọ. Al-Mumtahanah (Medinan) 13 Ẹsẹ.



13 Ẹsẹ · Medinan · Yorùbá
bismillah
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se mu ota Mi ati ota yin ni ore ti e oo maa fi ife han si. Won kuku ti sai gbagbo ninu ohun ti o de ba yin ninu ododo. Won yo Ojise ati eyin naa kuro ninu ilu nitori pe, e gbagbo ninu Allahu, Oluwa yin. Ti eyin ba jade fun ogun nitori esin Mi ati nitori wiwa iyonu Mi, (se) eyin yoo tun maa ni ife koro si won ni! Emi si nimo julo nipa ohun ti e fi pamo ati ohun ti e fi han. Enikeni ti o ba se bee ninu yin, dajudaju o ti sina kuro loju ona taara
ﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑ
Ti owo won ba ba yin, won maa di ota fun yin. Won yo si fi owo won ati ahon won nawo aburu si yin. Won si maa fe ki o je pe e di alaigbagbo
ﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡ
Awon ebi yin ati awon omo yin ko le se yin ni anfaani; ni Ojo Ajinde ni Allahu maa sepinya laaarin yin. Allahu si ni Oluriran nipa ohun ti e n se nise
ﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸ
Dajudaju awokose rere ti wa fun yin ni ara (Anabi) ’Ibrohim ati awon t’o wa pelu re. Nigba ti won so fun ijo won pe: "Dajudaju awa yowo-yose kuro ninu oro yin ati ohun ti e n josin fun leyin Allahu. A tako yin. Ota ati ikorira si ti han laaarin wa titi laelae ayafi igba ti e ba to gbagbo ninu Allahu nikan soso. - Afi oro ti (Anabi) ’Ibrohim so fun baba re pe: "Dajudaju mo maa toro aforijin fun o, emi ko si ni ikapa kini kan fun o lodo Allahu. - Oluwa wa, Iwo l’a gbarale. Odo Re l’a seri pada si (nipa ironupiwada). Odo Re si ni abo eda
ﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆﰇ
Oluwa wa, ma se wa ni adanwo fun awon t’o sai gbagbo. Forijin wa, Oluwa wa. Dajudaju Iwo ni Alagbara, Ologbon
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥ
Dajudaju awokose rere ti wa fun yin ni ara won fun eni t’o n reti (esan) Allahu ati Ojo Ikeyin. Enikeni ti o ba peyin da, dajudaju Allahu, Oun ni Oloro, Eleyin
ﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸ
O le je pe Allahu yoo fi ife si aarin eyin ati awon ti e mu ni ota ninu won (iyen, nigba ti won ba di musulumi). Allahu ni Alagbara. Allahu si ni Alaforijin, Asake-orun
ﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏ
Allahu ko ko fun yin nipa awon ti ko gbe ogun ti yin nipa esin, ti won ko si le yin jade kuro ninu ilu yin, pe ki e se daadaa si won, ki e si se deede si won. Dajudaju Allahu feran awon oluse-deede
ﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦ
Ohun ti Allahu ko fun yin nipa awon t’o gbogun ti yin ninu esin, ti won si le yin jade kuro ninu ilu yin, ti won tun se iranlowo (fun awon ota yin) lati le yin jade, ni pe (O ko fun yin) lati mu won ni ore. Enikeni ti o ba mu won ni ore, awon wonyen, awon ni alabosi
ﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆﰇﰈ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, nigba ti awon onigbagbo ododo lobinrin ba wa ba yin, ti won gbe ilu awon alaigbagbo ju sile fun aabo esin won, e bi won ni ibeere. Allahu nimo julo nipa igbagbo won. Nitori naa, ti e ba mo won si onigbagbo ododo, e ma se da won pada si odo awon alaigbagbo. Awon onigbagbo ododo lobinrin ko letoo si won. Awon alaigbagbo lokunrin ko si letoo si won. E fun (awon alaigbagbo lokunrin) ni owo ti won na (ni owo-ori obinrin naa). Ko si si ese fun eyin naa pe ki e fe won nigba ti e ba ti fun (awon obinrin wonyi) ni owo-ori won. E ma se fi owo-ori awon obinrin yin ti won je alaigbagbo mu won mole (gege bi iyawo yin lai je pe won gba ’Islam pelu yin). E beere ohun ti e na (ni owo-ori won lowo alaigbagbo lokunrin ti won sa lo ba). Ki awon (alaigbagbo lokunrin naa) beere ohun ti awon naa na (ni owo-ori won lowo eyin ti onigbagbo ododo lobinrin sa wa ba). Iyen ni idajo Allahu. O si n dajo laaarin yin. Allahu si ni Onimo, Ologbon
ﰉﰊﰋﰌﰍﰎﰏﰐﰑﰒﰓﰔﰕﰖﰗﰘﰙﰚﰛﰜﰝﰞﰟ
Ti kini kan lati odo awon iyawo yin ba bo mo yin lowo si odo awon alaigbagbo, ti e si kore ogun, e fun awon ti iyawo won sa lo ni iru odiwon ohun ti won na (ni owo-ori). Ki e si beru Allahu, Eni ti eyin ni igbagbo ododo ninu Re
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸ
Iwo Anabi, nigba ti awon onigbagbo ododo lobinrin ba wa ba o, ti won n se adehun fun o pe awon ko nii fi kini kan sebo si Allahu, awon ko nii jale, awon ko nii se sina, awon ko nii pa omo won, awon ko nii mu adapa iro wa, adapa iro ti won n mu wa laaarin owo won ati ese won (iyen ni gbigbe oyun oloyun fun oko won), awon ko si nii yapa re nibi nnkan daadaa, nigba naa ba won se adehun, ki o si ba won toro aforijin lodo Allahu. Dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun
ﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se mu ijo kan ti Allahu ti binu si ni ore. Dajudaju won ti soreti nu nipa orun, gege bi awon alaigbagbo t’o wa ninu saree (se soreti nu nipa ike)

Al-Kur'an


Tuesday, August 18, 2026

Don't forget us in your sincere prayers