Перевод суры Ан-Ниса на Йоруба язык
Eyin eniyan, e beru Oluwa yin, Eni ti O seda yin lati ara emi eyo kan (iyen, Anabi Adam). O si seda aya re (Hawa’) lati ara re. O fon opolopo okunrin ati obinrin jade lati ara awon mejeeji. Ki e si beru Allahu, Eni ti e n fi be ara yin. (E so) okun-ibi. Dajudaju Allahu n je Oluso lori yin |
E fun awon omo orukan ni dukia won. E ma se fi nnkan buruku paaro nnkan daadaa. E si ma se je dukia won mo dukia yin; dajudaju o je ese nla |
Ti e ba paya pe e o nii se deede nipa (fife) omo orukan, e fe eni t’o letoo si yin ninu awon obinrin; meji tabi meta tabi merin. Sugbon ti e ba paya pe e o nii se deede, (e fe) eyo kan tabi erubinrin yin. Iyen sunmo julo pe e o nii sabosi |
E fun awon obinrin ni sodaaki won ni tokan-tokan. Ti won ba si fi inu didun yonda kini kan fun yin ninu re, e je e pelu irorun ati igbadun |
E ma se ko dukia yin ti Allahu fi se gbemiiro fun yin le awon alailoye lowo. E pese ije-imu fun won ninu re, ki e si raso fun won. Ki e si maa soro daadaa fun won |
E maa sagbeyewo (oye) awon omo orukan titi won yoo fi to igbeyawo se. Ti e ba si ti ri oye lara won, ki e da dukia won pada fun won. E o gbodo je dukia won ni ije apa ati ijekuje ki won to dagba. Eni ti o ba je oloro, ki o moju kuro (nibe). Eni ti o ba je alaini, ki o je ninu re ni ona t’o dara. Nitori naa, ti e ba fe da dukia won pada fun won, e pe awon elerii si won. Allahu si to ni Olusiro |
Awon okunrin ni ipin ninu ohun ti obi mejeeji ati ebi fi sile. Ati pe awon obinrin naa ni ipin ninu ohun ti obi mejeeji ati ebi fi sile. Ninu ohun t’o kere ninu re tabi t’o po; (o je) ipin ti won ti pin (fun won) |
Nigba ti awon ebi, awon omo orukan ati awon mekunnu ba wa ni (ijokoo) ogun pipin, e fun won ninu re (siwaju ki e to pin ogun), ki e si soro daadaa fun won |
Awon (olupingun ati alagbawo omo orukan) ti o ba je pe awon naa maa fi omo wewe sile, ti won si n paya lori won, ki won yaa beru Allahu. Ki won si maa soro daadaa (fun omo orukan) |
Dajudaju awon t’o n je dukia omo orukan pelu abosi, Ina kuku ni won n je sinu ikun won. Won si maa wo inu Ina t’o n jo |
Allahu n pase fun yin nipa (ogun ti e maa pin fun) awon omo yin; ti okunrin ni iru ipin ti obinrin meji. Ti won ba si je obinrin (nikan) meji soke, tiwon ni ida meji ninu ida meta ohun ti (oku) fi sile. Ti o ba je obinrin kan soso, idaji ni tire. Ti obi re mejeeji, ida kan ninu ida mefa ni ti ikookan awon mejeeji ninu ohun ti oku fi sile, ti o ba ni omo laye. Ti ko ba si ni omo laye, ti o si je pe awon obi re mejeeji l’o maa jogun re, ida kan ninu ida meta ni ti iya re. Ti o ba ni arakunrin (tabi arabinrin), ida kan ninu ida mefa ni ti iya re, (gbogbo re) leyin asoole ti o so tabi gbese. Awon baba yin ati awon omokunrin yin; eyin ko mo ewo ninu won lo maa mu anfaani ba yin julo. (Ipin) oran-anyan ni lati odo Allahu. Dajudaju Allahu n je Onimo, Ologbon |
Tiyin ni ilaji ohun ti awon iyawo yin fi sile, ti won ko ba ni omo. Ti won ba si ni omo, tiyin ni ida kan ninu ida merin ohun ti won fi sile, leyin asoole ti won so tabi gbese. Tiwon si ni ida kan ninu ida merin ohun ti e fi sile, ti eyin ko ba ni omo laye. Ti e ba ni omo laye, ida kan ninu ida mejo ni tiwon ninu ohun ti e fi sile leyin asoole ti e so tabi gbese. Ti okunrin kan tabi obinrin kan ti won fe jogun re ko ba ni obi ati omo, ti o si ni arakunrin kan tabi arabinrin kan, ida kan ninu ida mefa ni ti ikookan awon mejeeji. Ti won ba si po ju bee lo, won yoo dijo pin ida kan ninu ida meta, leyin asoole ti won so tabi gbese, ti ko nii je ipalara. Ofin kan ni lati odo Allahu. Allahu si ni Onimo, Alafarada |
Iyen ni awon enu-ala (ti) Allahu (gbekale fun ogun pipin). Enikeni ti o ba si tele ti Allahu ati Ojise Re, (Allahu) yoo mu un wo inu awon Ogba Idera kan ti awon odo n san ni isale re. Olusegbere ni won ninu re. Iyen si ni erenje nla |
Enikeni ti o ba si yapa (ase) Allahu ati Ojise Re, ti o si n tayo awon enu-ala ti Allahu gbekale, (Allahu) yoo mu un wo inu Ina kan. Olusegbere ni ninu re. Iya ti i yepere eda si n be fun un |
Awon t’o n se sina ninu awon obinrin yin, e wa elerii merin ninu yin ti o maa jerii le won lori. Ti won ba jerii le won lori, ki e de won mo inu ile titi iku yoo fi pa won tabi (titi) Allahu yoo fi fun won ni ona (miiran) |
Awon meji ti won se (sina) ninu yin, ki e (fenu) ba won wi. Ti won ba si ronu piwada, ti won satunse, ki e moju kuro lara won. Dajudaju Allahu n je Olugba-ironupiwada, Asake-orun |
Ironupiwada ti Allahu yoo gba ni ti awon t’o n se ise aburu pelu aimokan. Leyin naa, won ronu piwada laipe. Awon wonyi ni Allahu yoo gba ironupiwada won. Allahu si n je Onimo, Ologbon |
Ko si ironupiwada fun awon t’o n se aburu titi iku fi de ba okan ninu won, ki o wa wi pe: “Dajudaju emi ronu piwada nisinsin yii.” (Ko tun si ironupiwada) fun awon t’o ku sipo alaigbagbo. Awon wonyen, A ti pese iya eleta elero sile de won |
Eyin ti e gbagbo ni ododo, ko letoo fun yin lati je awon obinrin mogun pelu ipa (bii sisu obinrin lopo.) E ma si di won lowo lati ko apa kan nnkan ti e fun won lo ayafi ti won ba huwa ibaje ponnbele. E ba won lopo pelu daadaa. Ti e ba korira won, o le je pe e korira kini kan, ki Allahu si ti fi opolopo oore sinu re |
Ti e ba si fe fi iyawo kan paaro aye iyawo kan, ti e si ti fun okan ninu won ni opolopo dukia, e o gbodo gba nnkan kan ninu re mo. Se eyin yoo gba a ni ti adapa iro (ti e n pa mo won) ati ese to foju han (ti e n da nipa won) |
Bawo ni eyin se le gba a pada nigba ti o je pe e ti wole to’ra yin, ti won si ti gba adehun t’o nipon lowo yin |
E ma se fe eni ti awon baba yin ti fe ninu awon obinrin ayafi eyi ti o ti re koja. Dajudaju o je iwa ibaje ati ohun ikorira. O si buru ni ona |
A se e ni eewo fun yin (lati fe) awon iya yin ati awon omobinrin yin ati awon arabinrin yin ati awon arabinrin baba yin ati awon arabinrin iya yin ati awon omobinrin arakunrin yin ati awon omobinrin arabinrin yin ati awon iya yin ti o fun yin ni oyan mu ati arabinrin yin nipase oyan ati awon iya iyawo yin ati awon omobinrin iyawo yin ti e gba to, eyi t’o wa ninu ile yin, ti e si ti wole to awon iya won, - ti eyin ko ba si ti i wole to won, ko si ese fun yin (lati fe omobinrin won), - ati awon iyawo omo yin, eyi ti o ti ibadi yin jade. (O tun je eewo) lati fe tegbon taburo papo ayafi eyi ti o ti re koja. Dajudaju Allahu, O n je Alaforijin Asake-orun |
(O tun je eewo lati fe) awon abileko ninu awon obinrin ayafi awon erubinrin yin. Ofin Allahu niyi lori yin. Won si se eni t’o n be leyin awon wonyen ni eto fun yin pe ki e wa won fe pelu dukia yin; e fe won ni fife iyawo, lai nii ba won se sina (siwaju yigi siso). Eni ti e ba si fe ni fife iyawo, ti e si ti je igbadun oorun ife lara won fun igba die (amo ti e fe ko won sile), e fun won ni sodaaki won. Oran-anyan ni. Ko si si ese fun yin nipa ohun ti e jo yonu si (lati foju fo laaarin ara yin) leyin sodaaki (t’o je oran-anyan). Dajudaju Allahu n je Onimo, Ologbon |
Eni ti ko ba lagbara oro ninu yin lati fe awon olominira onigbagbo ododo lobinrin, ki o fe ninu awon erubinrin yin, onigbagbo ododo lobinrin. Allahu nimo julo nipa igbagbo yin, ara kan naa (si) ni yin. Nitori naa, e fe won pelu iyonda awon olowo won. Ki e si fun won ni sodaaki won ni ona t’o dara, (iyen) awon omoluabi (erubinrin), yato si awon asewo ati odoko. Nigba ti won ba si di abileko, ti won ba (tun) lo se sina, ilaji iya ti n be fun awon olominira ni iya ti n be fun won. (Fife erubinrin), iyen wa fun eni t’o n paya inira (sina) ninu yin. Ati pe ki e se suuru loore julo fun yin. Allahu si ni Alaforijin, Asake-orun |
Allahu fe salaye (ofin) fun yin, O fe to yin si ona awon t’o siwaju yin, O si fe gba ironupiwada yin. Allahu si ni Onimo, Ologbon |
Ati pe Allahu fe gba ironupiwada yin. Awon t’o si n tele ife-adun aye si n fe ki e ye kuro (ninu esin) ni yiye t’o tobi |
يُرِيدُ اللَّهُ أَن يُخَفِّفَ عَنكُمْ ۚ وَخُلِقَ الْإِنسَانُ ضَعِيفًا(28) Allahu fe se irorun fun yin; A si seda eniyan ni ole |
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se fi eru je dukia yin laaarin ara yin ayafi ki o je owo sise pelu iyonu laaarin ara yin. E ma se para yin. Dajudaju Allahu n je Alaaanu si yin |
Enikeni ti o ba si se iyen lati fi tayo enu-ala ati lati fi se abosi, laipe A maa mu un wo inu Ina. Irorun si ni iyen je fun Allahu |
Ti e ba jinna si awon ese nlanla ti A ko fun yin, A maa pa awon iwa aidaa yin re fun yin, A si maa mu yin wo aye alapon-onle |
E ma se jerankan ohun ti Allahu fi s’oore ajulo fun apa kan yin lori apa kan. Ipin (esan) n be fun awon okunrin nipa ohun ti won se nise, ipin (esan) si n be fun awon obinrin nipa ohun ti won se nise. Ki e si toro lodo Allahu alekun oore Re. Dajudaju Allahu n je Onimo nipa gbogbo nnkan |
Ikookan (awon dukia) ni A ti se adayanri re fun awon ti o maa jogun re ninu ohun ti awon obi ati ebi fi sile. Awon ti e si bura fun (pe e maa fun ni nnkan), e fun won ni ipin won. Dajudaju Allahu n je Elerii lori gbogbo nnkan |
Awon okunrin ni opomulero (alase) fun awon obinrin nitori pe Allahu s’oore ajulo fun apa kan won lori apa kan ati nitori ohun ti won n na ninu dukia won. Awon obinrin rere ni awon olutele-ase (Allahu ati ase oko), awon oluso-eto oko ni koro fun wi pe Allahu so (eto tiwon naa fun won lodo oko won). Awon ti e si n paya orikunkun won, e se waasi fun won, e takete si ibusun won, e lu won. Ti won ba si tele ase yin, e ma se fi ona kan wa won nija. Dajudaju Allahu ga, O tobi |
Ti e ba si mo pe iyapa wa laaarin awon mejeeji, e gbe oloye kan dide lati inu ebi oko ati oloye kan lati inu ebi iyawo. Ti awon (toko tiyawo) mejeeji ba n fe atunse, Allahu yoo fi awon (oloye mejeeji) se konge atunse lori oro aarin won. Dajudaju Allahu n je Onimo, Alamotan |
E josin fun Allahu, e ma se fi nnkan kan sebo si I. E se daadaa si awon obi mejeeji ati ebi ati awon omo orukan ati awon mekunnu ati aladuugbo t’o sunmo ati aladuugbo t’o jinna ati ore alabaarin ati eni ti agara da lori irin-ajo ati awon eru yin. Dajudaju Allahu ko nifee onigbeeraga, afonnu |
Awon t’o n sahun, (awon) t’o n pa eniyan lase ahun sise ati (awon) t’o n fi ohun ti Allahu fun won ninu oore ajulo Re pamo; A ti pese iya ti i yepere eda sile de awon alaigbagbo |
Awon t’o n na owo won pelu sekarimi, ti won ko si gbagbo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin; enikeni ti Esu ba je ore fun, o buru ni ore |
Ki ni ipalara ti o maa se fun won ti won ba gbagbo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin, ti won si na ninu ohun ti Allahu se ni arisiki fun won? Allahu si je Onimo nipa won |
Dajudaju Allahu ko nii sabosi odiwon omo ina-igun. Ti o ba je ise rere, O maa sadipele (esan) re. O si maa fun (oluse rere) ni esan nla lati odo Re |
فَكَيْفَ إِذَا جِئْنَا مِن كُلِّ أُمَّةٍ بِشَهِيدٍ وَجِئْنَا بِكَ عَلَىٰ هَٰؤُلَاءِ شَهِيدًا(41) Bawo ni oro won yoo ti ri nigba ti A ba mu elerii jade ninu ijo kookan, ti A si mu iwo jade ni elerii lori awon wonyi |
Ni ojo yen, awon t’o sai gbagbo, ti won si yapa Ojise, won a fe ki awon ba ile dogba (ki won di erupe). Won ko si le fi oro kan pamo fun Allahu |
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se sunmo irun kiki nigba ti oti ba n pa yin titi e maa fi mo ohun ti e n so ati awon onijannaba, afi awon olukoja ninu mosalasi, titi e maa fi we (iwe jannaba). Ti e ba si je alaisan tabi e wa lori irin-ajo tabi okan ninu yin de lati ibi igbonse tabi e sunmo obinrin (yin), ti e ko ri omi, e fi erupe t’o dara se tayamomu; e fi pa oju yin ati owo yin. Dajudaju Allahu n je Alamoojukuro, Alaforijin |
Se o o ri awon ti A fun ni ipin kan ninu tira, ti won n ra isina, ti won si fe ki e sina |
وَاللَّهُ أَعْلَمُ بِأَعْدَائِكُمْ ۚ وَكَفَىٰ بِاللَّهِ وَلِيًّا وَكَفَىٰ بِاللَّهِ نَصِيرًا(45) Allahu si nimo julo nipa awon ota yin. Allahu to ni Alaabo. Allahu si to ni Alaranse |
O n be ninu awon yehudi, awon t’o n yi oro pada kuro ni awon aye re, won si n wi pe: “A gbo, a si yapa. Gbo, a o gba tire. Omugo wa.” Won n fi ahon won yi oro sodi ati pe won n bu enu-ate lu esin. ti o ba je pe won so pe: “A gbo, a si tele e. Gbo, ki o si kiye si wa”, iba dara fun won, iba si tona julo. Sugbon Allahu fi won gegun-un nitori aigbagbo won. Nitori naa, won ko nii gbagbo afi die (ninu won) |
Eyin ti A fun ni tira, e gbagbo ninu ohun ti A sokale, ti o n fi ohun t’o je ododo rinle nipa eyi t’o wa pelu yin, siwaju ki A to fo awon oju kan, A si maa da a pada si (ipako) leyin won, tabi ki A sebi le won gege bi A se sebi le ijo Sabt. Ati pe ase Allahu maa se |
Dajudaju Allahu ko nii forijin (eni ti) o ba n sebo si I. O si maa saforijin fun ohun miiran yato si iyen fun eni ti O ba fe. Eni ti o ba n sebo si Allahu, dajudaju o ti da adapa iro (ti o je) ese nla |
Se o o ri awon t’o n safomo ara won ni? Ko si ri bee, Allahu l’O n safomo eni ti O ba fe. Ko si nii sabosi bin-intin si won |
انظُرْ كَيْفَ يَفْتَرُونَ عَلَى اللَّهِ الْكَذِبَ ۖ وَكَفَىٰ بِهِ إِثْمًا مُّبِينًا(50) Wo bi won se n da adapa iro mo Allahu. O si to ni ese ponnbele |
Se o o ri awon ti A fun ni ipin kan ninu tira, ti won n gbagbo ninu idan ati orisa, won si n wi fun awon alaigbagbo pe: “Awon (osebo) wonyi mona ju awon t’o gbagbo lododo.” |
أُولَٰئِكَ الَّذِينَ لَعَنَهُمُ اللَّهُ ۖ وَمَن يَلْعَنِ اللَّهُ فَلَن تَجِدَ لَهُ نَصِيرًا(52) Awon wonyen ni awon ti Allahu sebi le. Enikeni ti Allahu ba si sebi le, o o nii ri alaranse kan fun un |
أَمْ لَهُمْ نَصِيبٌ مِّنَ الْمُلْكِ فَإِذًا لَّا يُؤْتُونَ النَّاسَ نَقِيرًا(53) Tabi ipin kan n be fun won ninu ijoba (Wa) ni? Ti o ba ri bee won ko nii fun awon eniyan ni eekan koro dabinu |
Tabi won n se ilara awon eniyan lori ohun ti Allahu fun won ninu oore ajulo Re ni? Dajudaju A fun awon ebi (Anabi) ’Ibrohim ni Tira ati ijinle oye (sunnah). A si fun won ni ijoba t’o tobi |
فَمِنْهُم مَّنْ آمَنَ بِهِ وَمِنْهُم مَّن صَدَّ عَنْهُ ۚ وَكَفَىٰ بِجَهَنَّمَ سَعِيرًا(55) Nitori naa, o n be ninu won eni t’o gbagbo ninu re. O si n be ninu won eni t’o seri kuro nibe. Jahanamo si to ni ina t’o n jo |
Dajudaju awon t’o sai gbagbo ninu awon ayah Wa, laipe A maa mu won wo inu Ina. Igbakigba ti awo ara won ba jona, A oo maa paaro awo ara miiran fun won ki won le maa to iya wo lo. Dajudaju Allahu n je Alagbara, Ologbon |
Awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere, A oo mu won wo inu awon Ogba Idera kan, ti awon odo n san ni isale re. Olusegbere ni won ninu re titi laelae. Awon iyawo mimo n be fun won ninu re. A si maa fi won si abe iboji t’o maa siji bo won daradara |
Dajudaju Allahu n pa yin ni ase pe ki e da agbafipamo pada fun awon olowo won. Ati pe nigba ti e ba n dajo laaarin awon eniyan, e dajo pelu deede. Dajudaju Allahu n fi nnkan t’o dara se waasi fun yin. Dajudaju Allahu n je Olugbo, Oluriran |
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e tele (ase) Allahu, e tele (ase) Ojise naa ati awon alase ninu yin. Nitori naa, ti e ba yapa enu si kini kan, e seri re si odo Allahu ati Ojise (sollalahu alayhi wa sallam), ti e ba gbagbo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin. Iyen loore julo, o si dara julo fun ikangun oro |
Se o o ri awon t’o n soro (ti ko si ri bee) pe dajudaju awon gbagbo ninu ohun ti A sokale fun o ati ohun ti A sokale siwaju re, ti won si n gbero lati gbe ejo lo ba orisa, A si ti pa won lase pe ki won lodi si i. Esu si fe si won lona ni isina t’o jinna |
Nigba ti won ba so fun won pe: “E wa sibi ohun ti Allahu sokale, e wa ba Ojise.”, o maa ri awon munaafiki ti won yoo maa seri kuro lodo re taara |
Bawo ni o se je pe nigba ti adanwo kan ba kan won nipase ohun ti owo won ti siwaju, leyin naa won maa wa ba o, won yo si maa fi Allahu bura pe ko si ohun ti a gba lero bi ko se daadaa ati irepo |
Awon wonyen ni awon ti Allahu mo ohun ti n be ninu okan won. Nitori naa, seri kuro lodo won. Se waasi fun won, ki o si ba won so oro t’o lagbara nipa ara won |
A o ran Ojise kan nise afi nitori ki won le tele e pelu iyonda Allahu. Ti o ba je pe nigba ti won sabosi si emi ara won, won wa ba o, won si toro aforijin Allahu, ti Ojise si tun ba won toro aforijin, won iba kuku ri Allahu ni Olugba-ironupiwada, Asake-orun |
Rara, Emi fi Oluwa re bura pe won ko ti i gbagbo ni ododo titi won yoo fi gba o ni oludajo lori ohun ti o ba da yanponyanrin sile laaarin won. Leyin naa, won ko nii ni ehonu kan si idajo ti o ba da. Won si maa gba patapata |
Ti o ba je pe A se e ni oran-anyan fun won pe: "E para yin tabi e jade kuro ninu ilu yin," won ko nii se e afi die ninu won. Ti o ba tun je pe won se ohun ti A fi n se waasi fun won ni, iba je oore ati idurosinsin to lagbara julo fun won |
Nigba naa, dajudaju Awa iba fun won ni esan nla lati odo Wa |
Ati pe dajudaju Awa iba to won si ona taara |
Enikeni ti o ba tele (ase) Allahu ati (ase) Ojise naa, awon wonyen maa wa (ninu Ogba Idera) pelu awon ti Allahu sedera fun ninu awon Anabi, awon olododo, awon t’o ku s’oju ogun esin ati awon eni rere. Awon wonyen si dara ni alabaarin |
ذَٰلِكَ الْفَضْلُ مِنَ اللَّهِ ۚ وَكَفَىٰ بِاللَّهِ عَلِيمًا(70) Oore ajulo yen maa wa lati odo Allahu; Allahu si to ni Onimo |
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا خُذُوا حِذْرَكُمْ فَانفِرُوا ثُبَاتٍ أَوِ انفِرُوا جَمِيعًا(71) Eyin ti e gbagbo ni ododo, e mu ohun isora yin lowo, ki e si tu jade s’oju ogun esin nikoniko tabi ki e tu jade ni apapo |
Dajudaju o n be ninu yin eni t’o n fa seyin. Ti adanwo kan ba kan yin, o maa wi pe: "Allahu kuku ti se idera fun mi nitori pe emi ko si nibe pelu won |
Dajudaju ti oore ajulo kan lati odo Allahu ba si te yin lowo, dajudaju o maa soro - bi eni pe ko si ife laaarin eyin ati oun (teletele) - pe: “Yee! Emi iba wa pelu won, emi iba je ere nla.” |
Nitori naa, ki awon t’o n fi aye ra orun maa jagun fun esin Allahu. Enikeni ti o ba si jagun nitori esin Allahu, yala won pa a tabi o segun, laipe A maa fun un ni esan nla |
Ki l’o se yin ti e o nii jagun fun esin Allahu, nigba ti awon alailagbara ninu awon okunrin, awon obinrin ati awon omode (si n be lori ile), awon t’o n so pe: “Oluwa wa, mu wa jade kuro ninu ilu yii, ilu awon alabosi. Fun wa ni alaabo kan lati odo Re. Ki O si fun wa ni alaranse kan lati odo Re.” |
Awon t’o gbagbo ni ododo n jagun fun esin Allahu. Awon t’o sai gbagbo si n jagun fun esin orisa. Nitori naa, e ja awon ore Esu logun. Dajudaju ete Esu, o je ohun ti o le |
Se o o ri awon ti A so fun pe: “E da’wo ogun esin duro, e maa kirun (lo na), ki e si maa yo Zakah.” Sugbon nigba ti A se ogun esin jija ni oran-anyan le won lori, igba naa ni apa kan ninu won n beru awon eniyan bi eni ti n beru Allahu tabi ti iberu re le koko julo. Won si wi pe: "Oluwa wa, nitori ki ni O fi se ogun esin jija ni oran-anyan le wa lori? Kuku lo wa lara di igba die si i." So pe: “Bin-intin ni igbadun aye, orun loore julo fun eni t’o ba beru Allahu. A o si nii sabosi bin-intin si yin.” |
Ibikibi ti e ba wa, iku yoo pade yin, eyin ibaa wa ninu odi ile giga fiofio. Ti oore (ikogun) kan ba te won lowo, won a wi pe: “Eyi wa lati odo Allahu.” Ti aburu (ifogun) kan ba si sele si won, won a wi pe: “Eyi wa lati odo re.” So pe: “Gbogbo re wa lati odo Allahu.” Ki l’o n se awon eniyan wonyi na, ti won ko fee gbo agboye oro kan |
Ohunkohun t’o ba te o lowo ninu oore, lati odo Allahu ni. Ohunkohun ti o ba si sele si o ninu aburu, lati odo ara re ni. A ran o nise pe ki o je Ojise fun awon eniyan. Allahu si to ni Elerii |
Enikeni t’o ba tele Ojise naa, o ti tele (ase) Allahu. Enikeni t’o ba si peyinda, A o ran o nise oluso lori won |
Won n wi pe: “A tele ase re.” Sugbon nigba ti won ba jade kuro lodo re, igun kan ninu won maa gbimo nnkan ti o yato si eyi ti n so (losan-an). Allahu si n se akosile ohun ti won n gbimo loru. Nitori naa, seri kuro lodo won, ki o si gbarale Allahu. Allahu si to Alaabo |
Se won ko ronu nipa al-Ƙur’an ni? Ti o ba je pe o wa lati odo elomiiran yato si Allahu, won iba ri opolopo itakora ninu re |
Nigba ti oro ifayabale tabi ipaya kan ba de ba won, won si maa tan an kale. Ti o ba je pe won seri re si (oro) Ojise ati awon alase (iyen, awon onimo esin) ninu won, awon t’o n yo ododo jade ninu oro ninu won iba mo on. Ti ki i ba se oore ajulo Allahu ati aanu Re lori yin ni, eyin iba tele Esu afi iba die (ninu yin) |
Nitori naa, jagun fun esin Allahu. Won ko la a bo eni kan lorun afi iwo. Ki o si gbe awon onigbagbo ododo longbe ogun esin jija. O see se ki Allahu ka owoja awon t’o sai gbagbo duro. Ati pe Allahu le julo (nibi) ija. O si le julo nibi ijeni-niya |
Enikeni ti o ba sipe isipe rere, o maa ri ipin esan ninu re. Enikeni ti o ba si sipe isipe aburu, o maa ri ipin ese ninu re. Allahu si je Oluso lori gbogbo nnkan |
Nigba ti won ba ki yin ni kiki kan, e ki won (pada) pelu eyi t’o dara ju u lo tabi ki e da a pada (pelu bi won se ki yin). Dajudaju Allahu n je Olusiro lori gbogbo nnkan |
Allahu, ko si olohun kan ti ijosin to si afi Oun. Dajudaju O maa ko yin jo ni Ojo Ajinde, ti ko si iyemeji ninu re. Ta si ni o so ododo ju Allahu lo |
Ki ni o maa mu yin pin si ijo meji nipa awon sobe-selu musulumi! Allahu l’O da won pada seyin nitori ohun ti won se nise. Se e fe fi eni ti Allahu si lona mona ni? Enikeni ti Allahu ba si lona, o o nii ri ona kan fun un |
Won fe ki e sai gbagbo gege bi won se sai gbagbo, ki e le jo di egbe kan naa. Nitori naa, e ma se mu ore ayo ninu won titi won fi maa si kuro ninu ilu ebo wa si ilu ’Islam fun aabo esin Allahu. Ti won ba keyin (si sise hijrah naa), e mu won, ki e si pa won nibikibi ti e ba ti ri won. Ki e si ma se mu ore ayo ati oluranlowo kan ninu won |
Ayafi awon t’o ba dara po mo ijo kan ti adehun n be laaarin eyin ati awon. Tabi won wa ba yin, ti okan won ti pami lati ba yin ja tabi lati ba awon eniyan won ja. Ati pe ti o ba je pe Allahu ba fe, iba fun won lagbara (akin-okan) lori yin, won iba si ja yin logun. Nitori naa, ti won ba yera fun yin, ti won ko si ja yin logun, ti won si juwo juse sile fun yin, nigba naa Allahu ko fun yin ni ona lori won (lati ja won logun) |
E maa ri awon elomiiran ti won fe fi yin lokan bale, won si fe fi awon eniyan won lokan bale (pe) nigbakigba ti won ba da won pada sinu ifooro (iborisa) ni won n pada sinu re. Ti won ko ba yera fun yin, ti won ko juwo juse sile fun yin, ti won ko si dawo jija yin logun duro, nigba naa e mu won, ki e si pa won nibikibi ti owo yin ba ti ba won. Awon wonyen ni Allahu si fun yin ni agbara t’o yanju lori won (lati ja won logun) |
Ko letoo fun onigbagbo ododo kan lati pa onigbagbo ododo kan ayafi ti o ba seesi. Eni ti o ba si seesi pa onigbagbo ododo kan, o maa tu eru onigbagbo ododo kan sile loko eru. O si maa san owo emi fun awon eniyan oku afi ti won ba fi tore (fun un). Ti o ba si wa ninu awon eniyan kan ti o je ota fun yin, onigbagbo ododo si ni (eni ti won seesi pa), o maa tu eru onigbagbo ododo kan sile loko eru. Ti o ba je ijo ti adehun n be laaarin eyin ati awon, o maa san owo emi fun won. O si maa tu eru onigbagbo ododo kan sile loko eru. Eni ti ko ba ri eru onigbagbo ododo, o maa gba aawe osu meji ni telentele. (Ona) ironupiwada kan lati odo Allahu (niyi). Allahu n je Onimo, Ologbon |
Enikeni ti o ba moomo pa onigbagbo ododo kan, ina Jahanamo ni esan re. Olusegbere ni ninu re. Allahu yoo binu si i. O maa fi sebi le e. O si ti pese iya t’o tobi sile de e |
Eyin ti e gbagbo ni ododo, nigba ti e ba wa lori irin-ajo ogun esin Allahu, e se pelepele ki e fi mo ododo (nipa awon eniyan). E si ma se so fun eni ti o ba salamo si yin pe ki i se onigbagbo ododo nitori pe eyin n wa dukia isemi aye. Ni odo Allahu kuku ni opolopo oro ogun wa. Bayen ni eyin naa se wa tele, Allahu si se idera (esin) fun yin. Nitori naa, e se pelepele ki e fi mo ododo (nipa awon eniyan naa). Dajudaju Allahu n je Onimo-ikoko ohun ti e n se nise |
Awon olujokoo sinu ile ninu awon onigbagbo ododo, yato si awon alailera, ati awon olujagun fun esin Allahu pelu dukia won ati emi won, won ko dogba. Allahu fi ipo kan soore ajulo fun awon olujagun fun esin Allahu pelu dukia won ati emi won lori awon olujokoo sinu ile. Olukuluku (won) ni Allahu se adehun ohun rere (Ogba Idera) fun. Allahu gbola fun awon olujagun esin lori awon olujokoo sinu ile pelu esan nla |
دَرَجَاتٍ مِّنْهُ وَمَغْفِرَةً وَرَحْمَةً ۚ وَكَانَ اللَّهُ غَفُورًا رَّحِيمًا(96) awon ipo kan, aforijin ati aanu lati odo Re. Allahu si n je Alaforijin Asake-orun |
Dajudaju awon ti molaika gba emi won, (lasiko) ti won n sabosi si emi ara won, (awon molaika) so pe: “Ki ni e n se (ninu esin)?” Won wi pe: “Won da wa lagara lori ile ni.” (Awon molaika) so pe: “Se ile Allahu ko fe to (fun yin) lati gbe esin yin sa lori ile?” Awon wonyen, ina Jahanamo ni ibugbe won. O si buru ni ikangun |
Ayafi awon alailagbara ninu awon okunrin, awon obinrin ati awon omode ti ko ni ikapa ogbon kan, ti won ko si da ona mo (de ilu Modinah) |
فَأُولَٰئِكَ عَسَى اللَّهُ أَن يَعْفُوَ عَنْهُمْ ۚ وَكَانَ اللَّهُ عَفُوًّا غَفُورًا(99) Nitori naa, awon wonyen, o sunmo ki Allahu samojukuro fun won. Allahu si n je Alamojuukuro, Alaforijin |
Enikeni ti o ba gbe ilu re ju sile nitori esin Allahu, o maa ri opolopo ibusasi ati igbalaaye lori ile. Enikeni ti o ba jade kuro ninu ile re (ti o je) olufilu-sile nitori esin Allahu ati Ojise Re, leyin naa ti iku ba a (loju ona), esan re kuku ti wa lodo Allahu. Allahu si n je Alaforijin, Asake-orun |
Nigba ti e ba se irin-ajo lori ile, ko si ese fun yin lati din irun ku, ti eyin ba n beru pe awon t’o sai gbagbo yoo fooro yin. Dajudaju awon alaigbagbo, won je ota ponnbele fun yin |
Nigba ti o ba wa laaarin won, gbe irun duro fun won. Ki igun kan ninu won kirun pelu re, ki won mu nnkan ijagun won lowo. Nigba ti won ba si fori kanle (ti won pari irun), ki won bo seyin yin, ki igun miiran ti ko ti i kirun wa kirun pelu re. Ki won mu isora won ati nnkan ijagun won lowo. Awon t’o sai gbagbo fe ki e gbagbe awon nnkan ijagun yin ati nnkan igbadun yin, ki won le kolu yin ni ee kan naa. Ko si ese fun yin ti o ba je pe ipalara kan n be fun yin latara ojo tabi (pe) e je alaisan, pe ki e fi nnkan ijagun yin sile (lori irun). E mu nnkan isora yin lowo. Dajudaju Allahu ti pese iya ti i yepere eda sile de awon alaigbagbo |
Nigba ti e ba pari irun, ki e se (gbolohun) iranti Allahu ni iduro, ijokoo ati idubule yin. Nigba ti e ba si fokan bale (iyen nigba ti e ba wonu ilu), ki e kirun (ni pipe). Dajudaju irun kiki je oran-anyan ti A fi akoko si fun awon onigbagbo ododo |
E ma se kaaare nipa wiwa awon eniyan naa (lati ja won logun). Ti eyin ba n je irora (ogbe), dajudaju awon naa n je irora (ogbe) gege bi eyin naa se n je irora. Eyin si n reti ohun ti awon ko reti lodo Allahu. Allahu si n je Onimo, Ologbon |
Dajudaju Awa so Tira (al-Ƙur’an) kale fun o pelu ododo nitori ki o le baa sedajo laaarin awon eniyan pelu ohun ti Allahu fi han o. Ma se je olugbeja fun awon onijanba |
وَاسْتَغْفِرِ اللَّهَ ۖ إِنَّ اللَّهَ كَانَ غَفُورًا رَّحِيمًا(106) Toro aforijin lodo Allahu, dajudaju Allahu, O n je Alaforijin, Asake-orun |
Ma se ba awon t’o n janba emi ara won wa awijare. Dajudaju Allahu ko feran enikeni ti o je onijanba, elese |
Won n fi ara pamo fun awon eniyan, won ko si le fara pamo fun Allahu (nitori pe) O wa pelu won (pelu imo Re) nigba ti won n gbimo ohun ti (Allahu) ko yonu si ninu oro siso. Allahu si n je Alamotan nipa ohun ti won n se nise |
Kiye si i, eyin wonyi ni e n ba won mu awijare wa nile aye. Ta ni o maa ba won mu awijare wa ni odo Allahu ni Ojo Ajinde? Tabi ta ni o maa je alaabo fun won |
Enikeni ti o ba sise aburu kan tabi ti o sabosi si emi ara re, leyin naa ti o toro aforijin lodo Allahu, o maa ba Allahu ni Alaforijin, Alaaanu |
وَمَن يَكْسِبْ إِثْمًا فَإِنَّمَا يَكْسِبُهُ عَلَىٰ نَفْسِهِ ۚ وَكَانَ اللَّهُ عَلِيمًا حَكِيمًا(111) Enikeni ti o ba da ese kan, o da a fun emi ara re. Allahu si n je Onimo, Ologbon |
Enikeni ti o ba se asise kan tabi ese kan, leyin naa, o di i ru alaimowo-mese, o ti da oran iparomoni ati ese ponnbele |
Ti ki i ba se ti oore ajulo Allahu ati aanu Re ti n be lori re ni, igun kan ninu won iba ti fe si o lona. Won ko si nii si eni kan lona afi ara won. Won ko si le fi nnkan kan ko inira ba o. Allahu si so Tira ati ijinle oye (iyen, sunnah) kale fun o. O tun fi ohun ti iwo ko mo tele mo o; oore ajulo Allahu lori re je ohun t’o tobi |
Ko si oore ninu opolopo oro ikoko won afi eni ti o ba pase ore tita tabi ise rere tabi atunse laaarin awon eniyan. Enikeni ti o ba se iyen lati fi wa iyonu Allahu, laipe A maa fun un ni esan t’o tobi |
Enikeni ti o ba lodi si Ojise naa leyin ti imona ti foju han si i kedere, ti o tun tele ona t’o yato si ti awon onigbagbo ododo, A oo doju re ko ohun ti o doju ara re ko (ninu isina), A o si mu un wo inu ina Jahanamo. O si buru ni ikangun |
Dajudaju Allahu ko nii forijin (eni ti) o ba n sebo si I. O si maa saforijin fun ese miiran yato si iyen fun eni ti O ba fe. Enikeni ti o ba n sebo si Allahu, dajudaju o ti sina ni isina t’o jinna |
إِن يَدْعُونَ مِن دُونِهِ إِلَّا إِنَاثًا وَإِن يَدْعُونَ إِلَّا شَيْطَانًا مَّرِيدًا(117) Won ko pe kini kan leyin Allahu bi ko se awon abo orisa. Won ko si pe kini kan bi ko se Esu oluyapa |
لَّعَنَهُ اللَّهُ ۘ وَقَالَ لَأَتَّخِذَنَّ مِنْ عِبَادِكَ نَصِيبًا مَّفْرُوضًا(118) Allahu sebi le Esu. O si wi pe: "Dajudaju mo maa mu ipin ti won pin fun mi ninu awon erusin Re |
Dajudaju mo maa si won lona. Mo maa fi erokero sinu okan won. Mo maa pa won lase, won yo si maa ge eti eran-osin (lati ya a soto fun orisa). Mo maa pa won lase, won yo si maa yi eda Allahu pada." Enikeni ti o ba mu Esu ni ore leyin Allahu, dajudaju o ti sofo ni ofo ponnbele |
يَعِدُهُمْ وَيُمَنِّيهِمْ ۖ وَمَا يَعِدُهُمُ الشَّيْطَانُ إِلَّا غُرُورًا(120) Esu n sadehun fun won, o si n fi ife-iro sinu okan won. Esu ko si sadehun kan fun won bi ko se etan |
أُولَٰئِكَ مَأْوَاهُمْ جَهَنَّمُ وَلَا يَجِدُونَ عَنْهَا مَحِيصًا(121) Awon wonyen, ina Jahanamo ni ibugbe won; won ko si nii ri ibusasi kan |
Awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si sise rere, A maa mu won wo inu awon Ogba Idera kan, ti odo n san ni isale re. Olusegbere ni won ninu re titi laelae. (O je) adehun ti Allahu se ni ti ododo. Ta si ni o so ododo ju Allahu lo |
Ki i se ife-okan yin, bee ni ki i se ife-okan awon ahlu-l-kitab (ni osuwon idajo orun. Amo,) enikeni ti o ba sise aburu kan, A oo san an ni esan re; ko si nii ri alafeyinti tabi alaranse kan leyin Allahu |
Enikeni ti o ba sise rere, yala okunrin tabi obinrin, onigbagbo ododo si ni, awon wonyen l’o maa wo inu Ogba Idera. A o si nii sabosi eekan koro dabinu fun won |
Ta l’o dara ni esin ju eni ti o jura re sile fun Allahu, oluse-rere si tun ni, o tun tele esin (Anabi) ’Ibrohim, oluduro-deede-ninu-’Islam? Allahu si mu (Anabi) ’Ibrohim ni ayanfe |
وَلِلَّهِ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ ۚ وَكَانَ اللَّهُ بِكُلِّ شَيْءٍ مُّحِيطًا(126) Ti Allahu ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile. Allahu si n je Alamotan nipa gbogbo nnkan |
Won n bi o leere idajo nipa awon obinrin. So pe: “Allahu l’O n so idajo won fun yin. Ohun ti won n ke fun yin ninu Tira (al-Ƙur’an naa n so idajo fun yin) nipa awon omo-orukan lobinrin ti e ki i fun ni ohun ti won ko fun won (ninu ogun), ti e tun n soju-kokoro lati fe won ati nipa awon alailagbara ninu awon omode (ti e n je ogun won mole.) ati nipa pe ki e duro ti awon omo orukan pelu deede. Ohunkohun ti e ba si se ni rere, dajudaju Allahu n je Onimo nipa re |
Ti obinrin kan ba paya ise orikunkun tabi ikeyinsi lati odo oko re, ko si ese fun awon mejeeji pe ki won se atunse laaarin ara won. Atunse si dara ju lo. Won si ti fi ahun ati okanjua sise sinu emi eniyan. Ti e ba se rere, ti e si beru (Allahu), dajudaju Allahu ni Alamotan nipa ohun ti e n se nise |
E o le se deede (ninu ife) laaarin awon obinrin, e o baa jerankan re. Nitori naa, e ma se fi sibi kan tan raurau, ki e ma lo pa (eni kan) ti bi ohun agbeko. Ti e ba satunse, ti e si beru (Allahu), dajudaju Allahu n je Alaforijin, Asake-orun |
وَإِن يَتَفَرَّقَا يُغْنِ اللَّهُ كُلًّا مِّن سَعَتِهِ ۚ وَكَانَ اللَّهُ وَاسِعًا حَكِيمًا(130) Ti awon mejeeji ba si pinya, Allahu yoo ro ikini keji loro ninu ola Re t’o gbooro. Allahu si n je Olugbooro (ninu oro), Ologbon |
Ti Allahu ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile. Dajudaju A ti pa a lase fun awon ti A fun ni tira siwaju yin ati eyin naa pe ki e beru Allahu. Ti e ba si sai gbagbo, dajudaju ti Allahu ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile. Allahu si n je Oloro, Eleyin (ti eyin to si) |
وَلِلَّهِ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ ۚ وَكَفَىٰ بِاللَّهِ وَكِيلًا(132) Ti Allahu ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile. Allahu si to ni Oluso |
Ti (Allahu) ba fe, O maa ko yin kuro lori ile, eyin eniyan. O si maa mu awon miiran wa. Allahu si n je Alagbara lori iyen |
Enikeni ti o ba n fe esan nile aye, sebi lodo Allahu ni esan aye ati orun wa. Allahu si n je Olugbo, Oluriran |
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e je oluduro sinsin lori ododo nigba ti e ba n jerii nitori ti Allahu, koda ki (eri jije naa) tako eyin funra yin tabi awon obi mejeeji ati awon ebi; yala o je oloro tabi alaini. Allahu sunmo (yin) ju awon mejeeji lo. Nitori naa, e ma se tele ife-inu lati ma se deede. Ti e ba yi oju-oro sodi tabi ti e ba gbunri kuro (nibi deede), dajudaju Allahu n je Alamotan nipa ohun ti e n se nise |
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e gbagbo daadaa ninu Allahu ati Ojise Re, ati Tira ti (Allahu) sokale fun Ojise Re, ati Tira ti O sokale siwaju. Enikeni ti o ba sai gbagbo ninu Allahu, awon molaika Re, awon Tira Re, awon Ojise Re ati Ojo Ikeyin, dajudaju o ti sina ni isina t’o jinna tefetefe |
Dajudaju awon t’o gbagbo, leyin naa won sai gbagbo, leyin naa won gbagbo, leyin naa won sai gbagbo, leyin naa won si lekun si i ninu aigbagbo, Allahu ko nii fori jin won, ko si nii fi ona mo won |
بَشِّرِ الْمُنَافِقِينَ بِأَنَّ لَهُمْ عَذَابًا أَلِيمًا(138) Fun awon sobe-selu musulumi ni iro pe dajudaju iya eleta elero n be fun won |
(Awon ni) awon t’o n mu awon alaigbagbo ni ore ayo leyin awon onigbagbo ododo. Se e n wa agbara lodo won ni? Dajudaju ti Allahu ni gbogbo agbara patapata |
(Allahu) kuku ti so o kale fun yin ninu Tira pe nigba ti e ba gbo nipa awon ayah Allahu pe won n sai gbagbo ninu re, won si n fi se efe, e ma se jokoo ti won nigba naa titi won yoo fi bo sinu oro miiran, bi bee ko dajudaju eyin yoo da bi iru won. Dajudaju Allahu yoo pa awon sobe-selu musulumi po mo gbogbo awon alaigbagbo ninu ina Jahanamo |
(Awon ni) awon t’o fe yo yin; ti isegun kan lati odo Allahu ba je tiyin, won a wi pe: “Se awa ko wa pelu yin bi?” Ti ipin kan ba si wa fun awon alaigbagbo, (awon munaafiki) a wi pe: “Se awa ko ti ni ikapa lati je gaba le yin lori (amo ti awa ko se bee), se awa ko si daabo bo yin to lowo awon onigbagbo ododo (titi owo yin fi ba oro-ogun, nitori naa ki ni ipin tiwa ti e fe fun wa?)” Nitori naa, Allahu yoo sedajo laaarin yin ni Ojo Ajinde. Allahu ko si nii fun awon alaigbagbo ni ona (isegun) kan lori awon onigbagbo ododo |
Dajudaju awon sobe-selu musulumi n tan Allahu, Oun naa si maa tan won. Nigba ti won ba duro lati kirun, won a duro (ni iduro) oroju, won yo si maa se sekarimi (lori irun). Won ko si nii se (gbolohun) iranti Allahu (lori irun) afi die |
Won n se balabala sihin-in sohun-un, won ko je ti awon wonyi, won ko si je ti awon wonyi. Enikeni ti Allahu ba si lona, o o si nii ri ona kan fun un |
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se mu awon alaigbagbo ni ore ayo leyin awon onigbagbo ododo (egbe yin). Se e fe se nnkan ti Allahu yoo fi ni eri ponnbele lowo lati je yin niya ni |
إِنَّ الْمُنَافِقِينَ فِي الدَّرْكِ الْأَسْفَلِ مِنَ النَّارِ وَلَن تَجِدَ لَهُمْ نَصِيرًا(145) Dajudaju awon sobe-selu musulumi yoo wa ninu aja isale patapata ninu Ina. O o si nii ri alaranse kan fun won |
Ayafi awon t’o ronu piwada, ti won se atunse, ti won duro sinsin ti Allahu, ti won si se afomo esin won fun Allahu. Nitori naa, awon wonyen maa wa pelu awon onigbagbo ododo. Laipe Allahu maa fun awon onigbagbo ododo ni esan nla |
مَّا يَفْعَلُ اللَّهُ بِعَذَابِكُمْ إِن شَكَرْتُمْ وَآمَنتُمْ ۚ وَكَانَ اللَّهُ شَاكِرًا عَلِيمًا(147) Ki ni Allahu maa fi iya yin se, ti e ba dupe, ti e si gbagbo ni ododo? Allahu si n je Olumoore, Onimo |
Allahu ko nifee si ariwo epe sise (lati odo enikeni) ayafi eni ti won ba se abosi si. Allahu si n je Olugbo, Onimo |
إِن تُبْدُوا خَيْرًا أَوْ تُخْفُوهُ أَوْ تَعْفُوا عَن سُوءٍ فَإِنَّ اللَّهَ كَانَ عَفُوًّا قَدِيرًا(149) Ti e ba safi han rere tabi e fi pamo tabi e samoju kuro nibi aburu, dajudaju Allahu n je Alamojuukuro, Alagbara |
Dajudaju awon t’o n sai gbagbo ninu Allahu ati awon Ojise Re, ti won fe sopinya laaarin Allahu ati awon Ojise Re, ti won si n wi pe: “A gbagbo ninu apa kan, a si sai gbagbo ninu apa kan,” won si fe mu ona kan to (lesin) laaarin iyen |
أُولَٰئِكَ هُمُ الْكَافِرُونَ حَقًّا ۚ وَأَعْتَدْنَا لِلْكَافِرِينَ عَذَابًا مُّهِينًا(151) Ni ododo, awon wonyen, awon ni alaigbagbo. A si ti pese Iya ti i yepere eda sile de awon alaigbagbo |
Awon t’o gbagbo ninu Allahu ati awon Ojise Re, ti won ko si ya eni kan soto ninu won, laipe awon wonyen, (Allahu) maa fun won ni esan won. Allahu si n je Alaforijin, Asake-orun |
Awon ahlul-kitab n bi o leere pe ki o so tira kan kale lati inu sanmo. Won kuku bi (Anabi) Musa ni ohun ti o tobi ju iyen lo. Won wi pe: “Fi Allahu han wa ni gbangba.” Nitori naa, ohun igbe lati inu sanmo gba won mu nipase abosi owo won. Leyin naa, won tun so oborogidi omo maalu di nnkan ti won josin fun leyin ti awon eri t’o yanju ti de ba won. A tun samoju kuro nibi iyen. A si fun (Anabi) Musa ni eri ponnbele |
A gbe apata soke ori won nitori majemu won. A si so fun won pe: “E gba enu-ona ilu wole ni oluteriba.” A tun so fun won pe: “E ma se tayo enu-ala ni ojo Sabt.” A si gba adehun t’o nipon lowo won |
Nitori yiye ti won funra won ye adehun won, sisaigbagbo won ninu awon oro Allahu, pipa ti won n pa awon Anabi lai letoo ati wiwi ti won n wi pe: “Okan wa ti di.” – rara, Allahu ti fi edidi di okan won ni nitori aigbagbo won. – Nitori naa, won ko nii gbagbo afi die (ninu won) |
وَبِكُفْرِهِمْ وَقَوْلِهِمْ عَلَىٰ مَرْيَمَ بُهْتَانًا عَظِيمًا(156) Ati nitori aigbagbo won ati oro won lori Moryam ni ti ibanilorukoje t’o tobi (Allahu tun fi edidi di okan won) |
Ati nitori oro won (yii): “Dajudaju awa pa Mosih, ‘Isa omo Moryam, Ojise Allahu.” Won ko pa a, won ko si kan an mo agbelebuu, sugbon A gbe aworan re wo elomiiran fun won ni. Dajudaju awon t’o yapa-enu nipa re, kuku wa ninu iyemeji ninu re; ko si imo kan fun won nipa re afi titele erokero. Won ko pa a ni amodaju. surah ali ‘Imron; 3:7 surah al-’Ani‘am; 6: 99 ati |
بَل رَّفَعَهُ اللَّهُ إِلَيْهِ ۚ وَكَانَ اللَّهُ عَزِيزًا حَكِيمًا(158) Rara o, Allahu gbe e wa soke lodo Re ni. Allahu si n je Alagbara, Ologbon |
Ko si nii si eni kan ninu awon ahlul-kitab (laye nigba ti ‘Isa ba sokale pada lati oju sanmo) afi ki o gba a gbo ni ododo siwaju iku re. Ni Ojo Ajinde, o si maa je elerii lori won. agbega ipo gege bi eyi t’o jeyo ninu surah Al-’a‘rof; 7:176 ati surah Moryam; 19:57) tabi ki o tumo si agbega tara (iyen gbigbe ara kuro lati aye isale si aye oke gege bi eyi t’o jeyo ninu surah Fatir; 35:10). Amo ko ni tabi-sugbon ninu mo pe nigbakigba ti harafi “إلى” ba ti tele “رفع” oke sanmo keje ni Allahu wa nitori pe inu sanmo yii naa ni Anabi wa Muhammad (sollalahu alayhi wa sallam) gun lo lati lo gba irun wakati marun-un wa lodo Allahu (subhanahu wa ta’ala) lasiko irin oru ati igun-sanmo gege bi Allahu se fi rinle ni ibere surah al-’Isro’. Koda tohun ti bi aigbagbo Fir‘aon se gbopon to o kuku gba pe sanmo ni Allahu (subhanahu wa ta’ala) wa. O si be Hamon ni ile giga fiofio ko. O fe yoju wo Allahu! (surah al-Ƙosos; 28:38). Nitori naa |
Nitori abosi lati odo awon ti won di yehudi, A se awon nnkan daadaa kan ni eewo fun won, eyi ti won se ni eto fun won (tele. A se e ni eewo fun won se) nipa bi won se n seri opolopo kuro loju ona (esin) Allahu |
Ati gbigba ti won n gba owo ele, ti A si ti ko o fun won, ati jije ti won n je dukia awon eniyan lona eru. A si ti pese iya eleta-elero sile de awon alaigbagbo |
Sugbon awon agba ninu imo ninu won ati awon onigbagbo ododo, won gbagbo ninu ohun ti A sokale fun o ati ohun ti A sokale siwaju re, (won tun gbagbo ninu awon molaika) t’o n kirun. (Awon wonyen) ati awon t’o n yo Zakah ati awon t’o gbagbo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin, awon wonyen ni A maa fun ni esan nla |
Dajudaju Awa (fi imisi) ranse si o gege bi A se fi ranse si (Anabi) Nuh ati awon Anabi (miiran) leyin re. A fi imisi ranse si (awon Anabi) ’Ibrohim, ’Ismo‘il, ’Ishaƙ, Ya‘ƙub ati awon aromodomo (re), ati (Anabi) ‘Isa, ’Ayyub, Yunus, Harun ati Sulaemon. A si fun (Anabi) Dawud ni Zabur |
Ati awon Ojise kan ti A ti so itan won fun o siwaju pelu awon Ojise kan ti A ko so itan won fun o. Allahu si ba (Anabi) Musa soro taara |
(A se won ni) Ojise, oniroo idunnu ati olukilo nitori ki awijare ma le wa fun awon eniyan lodo Allahu leyin (ti) awon Ojise (ti jise). Allahu si n je Alagbara, Ologbon |
Sugbon Allahu n jerii si ohun ti O sokale fun o. O so o kale pelu imo Re. Awon molaika naa n jerii (si i). Allahu si to ni Elerii |
إِنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا وَصَدُّوا عَن سَبِيلِ اللَّهِ قَدْ ضَلُّوا ضَلَالًا بَعِيدًا(167) Dajudaju awon t’o sai gbagbo, ti won si seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Allahu, won kuku ti sina ni isina t’o jinna |
Dajudaju awon t’o sai gbagbo, ti won tun sabosi, Allahu ko nii fori jin won, ko si nii fi oju-ona mo won |
إِلَّا طَرِيقَ جَهَنَّمَ خَالِدِينَ فِيهَا أَبَدًا ۚ وَكَانَ ذَٰلِكَ عَلَى اللَّهِ يَسِيرًا(169) Ayafi oju-ona ina Jahanamo. Olusegbere ni won ninu re titi laelae. Iyen si n je irorun fun Allahu |
Eyin eniyan, dajudaju Ojise naa ti de ba yin pelu ododo lati odo Oluwa yin. Nitori naa, ki e gba a gbo l’o dara julo fun yin. Ti e ba si sai gbagbo, dajudaju ti Allahu ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ile. Allahu si n je Onimo, Ologbon |
Eyin ahlul-kitab, e ma se tayo enu-ala ninu esin yin, ki e si ma so ohun kan nipa Allahu afi ododo. Ojise Allahu ni Mosih ‘Isa omo Moryam. Oro Re (kun fayakun) ti O so ranse si Moryam l’O si fi seda re. Emi kan (ti Allahu seda) lati odo Re si ni (Mosih ‘Isa omo Moryam). Nitori naa, e gbagbo ninu Allahu ati awon Ojise Re. E ye so meta (lokan) mo. Ki e jawo nibe lo je oore fun yin. Allahu nikan ni Olohun, Okan soso (ti ijosin to si). O mo tayo ki O ni omo. TiRe ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile. Allahu si to ni Alamojuuto |
Mosih ko ko lati je eru fun Allahu. Bee naa ni awon molaika ti won sunmo Allahu. Enikeni ti o ba ko lati josin fun Un, ti o tun segberaga, (Allahu) yoo ko won jo papo patapata si odo Re |
Ni ti awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si sise rere, (Allahu) yoo san won ni esan rere won. O si maa se alekun fun won ninu oore ajulo Re. Ni ti awon t’o ba si ko (lati josin fun Allahu), ti won si segberaga, (Allahu) yoo je won niya eleta-elero. Won ko si nii ri alatileyin tabi alaranse kan leyin Allahu |
Eyin eniyan, dajudaju eri oro ti de ba yin lati odo Oluwa yin. A si tun so imole t’o yanju kale fun yin |
Ni ti awon t’o gbagbo ninu Allahu, ti won si duro sinsin ti I, O maa fi won sinu ike ati ola kan lati odo Re. O si maa fi won mo ona taara si odo Re |
Won n bi o leere ibeere, so pe: “Allahu n fun yin ni idajo nipa eni ti ko ni obi, ko si ni omo. Ti eniyan kan ba ku, ti ko ni omo laye, ti o si ni arabinrin kan, idaji ni tire ninu ohun ti o fi sile. (Arakunrin) l’o maa je gbogbo ogun arabinrin re, ti ko ba ni omo laye. Ti arabinrin ba si je meji, ida meji ninu ida meta ni tiwon ninu ohun ti o fi sile. Ti won ba si je arakunrin (pupo) lokunrin ati lobinrin, ti okunrin kan ni ipin obinrin meji. Allahu n se alaye fun yin ki e ma baa sina. Allahu si ni Onimo nipa gbogbo nnkan |
Больше сур в Йоруба:
Скачать суру An-Nisa с голосом самых известных рекитаторов Корана:
Сура An-Nisa mp3: выберите рекитатора, чтобы прослушать и скачать главу An-Nisa полностью в высоком качестве
Ahmed Al Ajmy
Bandar Balila
Khalid Al Jalil
Saad Al Ghamdi
Saud Al Shuraim
Abdul Basit
Abdul Rashid Sufi
Abdullah Basfar
Abdullah Al Juhani
Fares Abbad
Maher Al Muaiqly
Al Minshawi
Al Hosary
Mishari Al-afasi
Yasser Al Dosari
Помолитесь за нас хорошей молитвой