Surah As-Saff ni Arabic ati Yorùbá

Ka Surah As-Saff pẹlu itumọ pipe ni Yorùbá ati iṣẹ́-ohun. Itumọ ẹsẹ kọọkan. (14 Ẹsẹ — مدنية). As-Saff Gbọ, As-Saff Itumọ, As-Saff mp3, As-Saff pdf.

Ka ati Gbọ Surah As-Saff

🎧 Ẹsẹ
M Mishary Rashid Alafasy
M Mahmoud Khalil Al-Husary
A Abdurrahman As-Sudais
M Mohamed Siddiq Al-Minshawi
A Abdul Basit Abdul Samad
A Ali Al-Hudhaify
A Ahmed ibn Ali al-Ajamy
A Abu Bakr Ash-Shaatree
M Muhammad Ayyoub
A Abdullah Basfar
A Abdullah Al-Juhani
M Maher Al Muaiqly
x1
سَبَّحَ لِلَّهِ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ ۖ وَهُوَ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ ۝١
📖 Itumọ Ẹsẹ 1
Ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile n safomo fun Allahu. Oun si ni Alagbara, Ologbon
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لِمَ تَقُولُونَ مَا لَا تَفْعَلُونَ ۝٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 2
Eyin ti e gbagbo ni ododo, nitori ki ni e se n so ohun ti e o nii se nise
كَبُرَ مَقْتًا عِندَ اللَّهِ أَن تَقُولُوا مَا لَا تَفْعَلُونَ ۝٣
📖 Itumọ Ẹsẹ 3
O je ohun ibinu t’o tobi ni odo Allahu pe ki e so ohun ti e o nii se
إِنَّ اللَّهَ يُحِبُّ الَّذِينَ يُقَاتِلُونَ فِي سَبِيلِهِ صَفًّا كَأَنَّهُم بُنْيَانٌ مَّرْصُوصٌ ۝٤
📖 Itumọ Ẹsẹ 4
Dajudaju Allahu feran awon t’o n jagun fun esin Re (ti won to ni) owoowo bi eni pe ogiri ile ti won le po mora won ni won
وَإِذْ قَالَ مُوسَىٰ لِقَوْمِهِ يَا قَوْمِ لِمَ تُؤْذُونَنِي وَقَد تَّعْلَمُونَ أَنِّي رَسُولُ اللَّهِ إِلَيْكُمْ ۖ فَلَمَّا زَاغُوا أَزَاغَ اللَّهُ قُلُوبَهُمْ ۚ وَاللَّهُ لَا يَهْدِي الْقَوْمَ الْفَاسِقِينَ ۝٥
📖 Itumọ Ẹsẹ 5
(Ranti) nigba ti (Anabi) Musa so fun ijo re pe: "Eyin ijo mi, nitori ki ni e oo se fi inira kan mi. E si kuku mo pe dajudaju Ojise Allahu ni emi je si yin." Nigba ti won si ye (kuro nibi ododo), Allahu ye okan won. Allahu ko si nii fi ona mo ijo obileje
وَإِذْ قَالَ عِيسَى ابْنُ مَرْيَمَ يَا بَنِي إِسْرَائِيلَ إِنِّي رَسُولُ اللَّهِ إِلَيْكُم مُّصَدِّقًا لِّمَا بَيْنَ يَدَيَّ مِنَ التَّوْرَاةِ وَمُبَشِّرًا بِرَسُولٍ يَأْتِي مِن بَعْدِي اسْمُهُ أَحْمَدُ ۖ فَلَمَّا جَاءَهُم بِالْبَيِّنَاتِ قَالُوا هَٰذَا سِحْرٌ مُّبِينٌ ۝٦
📖 Itumọ Ẹsẹ 6
(Ranti) nigba ti ‘Isa omo Moryam so pe: "Eyin omo ’Isro’il, dajudaju emi ni Ojise Allahu si yin. Mo n fi ohun t’o je ododo rinle nipa eyi t’o siwaju mi ninu Taorah. Mo si n mu iro-idunnu wa nipa Ojise kan t’o n bo leyin mi. Oruko re ni ’Ahmod." Nigba ti o ba si wa ba won pelu awon eri t’o yanju, won a wi pe: "Idan ponnbele ni eyi
وَمَنْ أَظْلَمُ مِمَّنِ افْتَرَىٰ عَلَى اللَّهِ الْكَذِبَ وَهُوَ يُدْعَىٰ إِلَى الْإِسْلَامِ ۚ وَاللَّهُ لَا يَهْدِي الْقَوْمَ الظَّالِمِينَ ۝٧
📖 Itumọ Ẹsẹ 7
Ta si ni o sabosi t’o tayo eni ti o da adapa iro mo Allahu, ti won si n pe e sinu ’Islam! Allahu ko si nii fi ona mo ijo alabosi
يُرِيدُونَ لِيُطْفِئُوا نُورَ اللَّهِ بِأَفْوَاهِهِمْ وَاللَّهُ مُتِمُّ نُورِهِ وَلَوْ كَرِهَ الْكَافِرُونَ ۝٨
📖 Itumọ Ẹsẹ 8
Won n gbero lati fi (oro) enu won pa imole Allahu. Allahu yo si mu imole Re tan kari, awon alaigbagbo ibaa korira re
هُوَ الَّذِي أَرْسَلَ رَسُولَهُ بِالْهُدَىٰ وَدِينِ الْحَقِّ لِيُظْهِرَهُ عَلَى الدِّينِ كُلِّهِ وَلَوْ كَرِهَ الْمُشْرِكُونَ ۝٩
📖 Itumọ Ẹsẹ 9
(Allahu) Oun ni Eni ti O fi imona ati esin ododo (’Islam) ran Ojise Re nitori ki O le fi bori esin (miiran), gbogbo re patapata, awon osebo ibaa korira re
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا هَلْ أَدُلُّكُمْ عَلَىٰ تِجَارَةٍ تُنجِيكُم مِّنْ عَذَابٍ أَلِيمٍ ۝١٠
📖 Itumọ Ẹsẹ 10
Eyin ti e gbagbo ni ododo, se ki Ng toka yin si okowo kan ti o maa gba yin la ninu iya eleta-elero
تُؤْمِنُونَ بِاللَّهِ وَرَسُولِهِ وَتُجَاهِدُونَ فِي سَبِيلِ اللَّهِ بِأَمْوَالِكُمْ وَأَنفُسِكُمْ ۚ ذَٰلِكُمْ خَيْرٌ لَّكُمْ إِن كُنتُمْ تَعْلَمُونَ ۝١١
📖 Itumọ Ẹsẹ 11
E gbagbo ninu Allahu ati Ojise Re, e jagun soju ona (esin) Allahu pelu awon dukia yin ati emi yin. Iyen loore julo fun yin ti e ba mo
يَغْفِرْ لَكُمْ ذُنُوبَكُمْ وَيُدْخِلْكُمْ جَنَّاتٍ تَجْرِي مِن تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ وَمَسَاكِنَ طَيِّبَةً فِي جَنَّاتِ عَدْنٍ ۚ ذَٰلِكَ الْفَوْزُ الْعَظِيمُ ۝١٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 12
(Allahu) maa fori ese yin jin yin. O si maa mu yin wo inu awon Ogba Idera, ti awon odo n san ni isale re ati awon ibugbe t’o dara ninu awon Ogba Idera gbere. Iyen ni erenje nla
وَأُخْرَىٰ تُحِبُّونَهَا ۖ نَصْرٌ مِّنَ اللَّهِ وَفَتْحٌ قَرِيبٌ ۗ وَبَشِّرِ الْمُؤْمِنِينَ ۝١٣
📖 Itumọ Ẹsẹ 13
Ati nnkan miiran ti e tun nifee si; (iyen,) aranse lati odo Allahu ati isegun t’o sunmo. Ki o si fun awon onigbagbo ododo ni iro idunnu
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا كُونُوا أَنصَارَ اللَّهِ كَمَا قَالَ عِيسَى ابْنُ مَرْيَمَ لِلْحَوَارِيِّينَ مَنْ أَنصَارِي إِلَى اللَّهِ ۖ قَالَ الْحَوَارِيُّونَ نَحْنُ أَنصَارُ اللَّهِ ۖ فَآمَنَت طَّائِفَةٌ مِّن بَنِي إِسْرَائِيلَ وَكَفَرَت طَّائِفَةٌ ۖ فَأَيَّدْنَا الَّذِينَ آمَنُوا عَلَىٰ عَدُوِّهِمْ فَأَصْبَحُوا ظَاهِرِينَ ۝١٤
📖 Itumọ Ẹsẹ 14
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e je alaranse fun esin Allahu gege bi (Anabi) ‘Isa omo Moryam se so fun awon omoleyin re pe: "Ta ni o maa se iranlowo fun mi nipa esin Allahu?" Awon omoleyin re so pe: "Awa ni alaranse fun esin Allahu." Igun kan ninu awon omo ’Isro’il gba a gbo ni ododo nigba naa, igun kan si sai gbagbo ninu re. A si fun awon t’o gbagbo lagbara lori awon ota won; won si di olubori
← 60 As-Saff (61/114) 62 →
Kika Surah As-Saff ni Yorùbá – Itumọ ati Ohun

61الصف As-Saff 📚 14 Ẹsẹ مدنية

Ẹsẹ kọọkan – Surah As-Saff — 14 Ẹsẹ




Al-Kur'an


Tuesday, August 18, 2026

Don't forget us in your sincere prayers