La sourate Al-Maidah en Yoruba

  1. mp3 sourate
  2. Plus
  3. Yoruba
Le Saint Coran | Traduction du Coran | Langue Yoruba | Sourate Al-Maida | - Nombre de versets 120 - Le numéro de la sourate dans le mushaf: 5 - La signification de la sourate en English: The Table.

يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا أَوْفُوا بِالْعُقُودِ ۚ أُحِلَّتْ لَكُم بَهِيمَةُ الْأَنْعَامِ إِلَّا مَا يُتْلَىٰ عَلَيْكُمْ غَيْرَ مُحِلِّي الصَّيْدِ وَأَنتُمْ حُرُمٌ ۗ إِنَّ اللَّهَ يَحْكُمُ مَا يُرِيدُ(1)

 Eyin ti e gbagbo ni ododo, e mu awon adehun se. Won se awon eran-osin ni eto fun yin afi eyi ti won ba n ka fun yin (ni eewo), lai nii so idode eranko di eto nigba ti e ba wa ninu aso hurumi. Dajudaju Allahu n se idajo ohun ti O ba fe

يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا تُحِلُّوا شَعَائِرَ اللَّهِ وَلَا الشَّهْرَ الْحَرَامَ وَلَا الْهَدْيَ وَلَا الْقَلَائِدَ وَلَا آمِّينَ الْبَيْتَ الْحَرَامَ يَبْتَغُونَ فَضْلًا مِّن رَّبِّهِمْ وَرِضْوَانًا ۚ وَإِذَا حَلَلْتُمْ فَاصْطَادُوا ۚ وَلَا يَجْرِمَنَّكُمْ شَنَآنُ قَوْمٍ أَن صَدُّوكُمْ عَنِ الْمَسْجِدِ الْحَرَامِ أَن تَعْتَدُوا ۘ وَتَعَاوَنُوا عَلَى الْبِرِّ وَالتَّقْوَىٰ ۖ وَلَا تَعَاوَنُوا عَلَى الْإِثْمِ وَالْعُدْوَانِ ۚ وَاتَّقُوا اللَّهَ ۖ إِنَّ اللَّهَ شَدِيدُ الْعِقَابِ(2)

 Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se ru ofin awon nnkan arisami ti Allahu gbe kale fun esin Re. E ma se so osu owo di eto (fun ogun esin), E ma se idiwo fun awon eran ore (ti won ko sami si lorun) ati (awon eran ore) ti won sami si lorun. E ma se idiwo fun awon t’o n gbero lati lo si Ile Haram, ti won n wa oore ajulo ati iyonu lati odo Oluwa won. Ti e ba si ti tura sile ninu aso hurumi, nigba naa e (le) dode (eranko). E ma se je ki ikorira awon eniyan kan ti yin lati tayo enu-ala nitori pe won se yin lori kuro ni Mosalasi Haram. E ran ara yin lowo lori ise rere ati iberu Allahu. E ma se ran ara yin lowo lori (iwa) ese ati itayo enu-ala. E beru Allahu. Dajudaju Allahu le (nibi) iya

حُرِّمَتْ عَلَيْكُمُ الْمَيْتَةُ وَالدَّمُ وَلَحْمُ الْخِنزِيرِ وَمَا أُهِلَّ لِغَيْرِ اللَّهِ بِهِ وَالْمُنْخَنِقَةُ وَالْمَوْقُوذَةُ وَالْمُتَرَدِّيَةُ وَالنَّطِيحَةُ وَمَا أَكَلَ السَّبُعُ إِلَّا مَا ذَكَّيْتُمْ وَمَا ذُبِحَ عَلَى النُّصُبِ وَأَن تَسْتَقْسِمُوا بِالْأَزْلَامِ ۚ ذَٰلِكُمْ فِسْقٌ ۗ الْيَوْمَ يَئِسَ الَّذِينَ كَفَرُوا مِن دِينِكُمْ فَلَا تَخْشَوْهُمْ وَاخْشَوْنِ ۚ الْيَوْمَ أَكْمَلْتُ لَكُمْ دِينَكُمْ وَأَتْمَمْتُ عَلَيْكُمْ نِعْمَتِي وَرَضِيتُ لَكُمُ الْإِسْلَامَ دِينًا ۚ فَمَنِ اضْطُرَّ فِي مَخْمَصَةٍ غَيْرَ مُتَجَانِفٍ لِّإِثْمٍ ۙ فَإِنَّ اللَّهَ غَفُورٌ رَّحِيمٌ(3)

 A se e ni eewo fun yin eran okunbete, ati eje, ati eran elede, ati eyi ti won pa pelu oruko ti ki i se Allahu, ati eran ti won fun lorun pa, ati eran ti won lu pa, ati eran ti o re lule ku, ati eran ti won kan pa ati eyi ti eranko abijawara je ku afi eyi ti e ba ri du (siwaju ki o to ku) ati eyi ti won pa sidii orisa. Eewo si ni fun yin lati yese wo. Iwonyi ni ibaje. Lonii ni awon t’o sai gbagbo soreti nu nipa esin yin. Nitori naa, e ma se paya won. E paya Mi. Mo pari esin yin fun yin lonii. Mo si se asepe idera Mi fun yin. Mo si yonu si ’Islam ni esin fun yin. Nitori naa, enikeni ti won ba ko sinu inira ebi (lati je eran eewo), yato si olufinnufindo-dese, dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun

يَسْأَلُونَكَ مَاذَا أُحِلَّ لَهُمْ ۖ قُلْ أُحِلَّ لَكُمُ الطَّيِّبَاتُ ۙ وَمَا عَلَّمْتُم مِّنَ الْجَوَارِحِ مُكَلِّبِينَ تُعَلِّمُونَهُنَّ مِمَّا عَلَّمَكُمُ اللَّهُ ۖ فَكُلُوا مِمَّا أَمْسَكْنَ عَلَيْكُمْ وَاذْكُرُوا اسْمَ اللَّهِ عَلَيْهِ ۖ وَاتَّقُوا اللَّهَ ۚ إِنَّ اللَّهَ سَرِيعُ الْحِسَابِ(4)

 Won n bi o leere pe: "Ki ni Won se ni eto fun won?" So pe: “Won se awon nnkan daadaa ni eto fun yin ati (eran ti e pa nipase) eyi ti e ko ni eko (idode) ninu awon eranko ati eye ti n dode. E ko awon aja lekoo idode, ki e ko won ninu ohun ti Allahu fi mo yin. Nitori naa, e je ninu ohun ti won ba pa fun yin, ki e si se bismillah si i . E beru Allahu. Dajudaju Allahu ni Oluyara nibi isiro-ise

الْيَوْمَ أُحِلَّ لَكُمُ الطَّيِّبَاتُ ۖ وَطَعَامُ الَّذِينَ أُوتُوا الْكِتَابَ حِلٌّ لَّكُمْ وَطَعَامُكُمْ حِلٌّ لَّهُمْ ۖ وَالْمُحْصَنَاتُ مِنَ الْمُؤْمِنَاتِ وَالْمُحْصَنَاتُ مِنَ الَّذِينَ أُوتُوا الْكِتَابَ مِن قَبْلِكُمْ إِذَا آتَيْتُمُوهُنَّ أُجُورَهُنَّ مُحْصِنِينَ غَيْرَ مُسَافِحِينَ وَلَا مُتَّخِذِي أَخْدَانٍ ۗ وَمَن يَكْفُرْ بِالْإِيمَانِ فَقَدْ حَبِطَ عَمَلُهُ وَهُوَ فِي الْآخِرَةِ مِنَ الْخَاسِرِينَ(5)

 Won se awon nnkan daadaa ni eto fun yin lonii. Ati ounje awon ti A fun ni tira, eto ni fun yin.1 Ounje tiyin naa, eto ni fun won. (Eto ni fun yin lati fe) awon olominira ninu awon onigbagbo ododo lobinrin ati awon olominira lobinrin ninu awon ti A fun ni tira siwaju yin, nigba ti e ba ti fun won ni sodaaki won; e fe won ni fife (bi ’Islam se ni ki e fe iyawo), lai nii ba won se sina (siwaju yigi) lai si nii yan won lale.2 Enikeni ti o ba lodi si igbagbo ododo, ise re ti baje. Ni Ojo Ikeyin, o si maa wa ninu awon eni ofo. orisa ibere ati idawole kan ti awon oyinbo aborisa n pe ni Janus ni won fi gbe osu ati odun January kale. Awon kristieni si tewo gba a lowo won. Musulumi yo si maa je musulumi lori gbigba oro Allahu gbo ni ododo. Ti iru musulumi yii ba tun wa ba awon kristieni da si odun January lai si siju wo awon ewu nla ti ko se e janiyan t’o tun ro mo igbeyawo. Dandan si ni fun wa lati lo ayah papo mora won ni ona ti ko fi nii ja si pe musulumi tele itumo oju-oro nikan ni iyapa si itumo oju oro miiran. Ni akoko na ninu surah al-Baƙorah

يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا إِذَا قُمْتُمْ إِلَى الصَّلَاةِ فَاغْسِلُوا وُجُوهَكُمْ وَأَيْدِيَكُمْ إِلَى الْمَرَافِقِ وَامْسَحُوا بِرُءُوسِكُمْ وَأَرْجُلَكُمْ إِلَى الْكَعْبَيْنِ ۚ وَإِن كُنتُمْ جُنُبًا فَاطَّهَّرُوا ۚ وَإِن كُنتُم مَّرْضَىٰ أَوْ عَلَىٰ سَفَرٍ أَوْ جَاءَ أَحَدٌ مِّنكُم مِّنَ الْغَائِطِ أَوْ لَامَسْتُمُ النِّسَاءَ فَلَمْ تَجِدُوا مَاءً فَتَيَمَّمُوا صَعِيدًا طَيِّبًا فَامْسَحُوا بِوُجُوهِكُمْ وَأَيْدِيكُم مِّنْهُ ۚ مَا يُرِيدُ اللَّهُ لِيَجْعَلَ عَلَيْكُم مِّنْ حَرَجٍ وَلَٰكِن يُرِيدُ لِيُطَهِّرَكُمْ وَلِيُتِمَّ نِعْمَتَهُ عَلَيْكُمْ لَعَلَّكُمْ تَشْكُرُونَ(6)

 Eyin ti e gbagbo ni ododo, nigba ti e ba fe kirun, e we oju yin ati owo yin titi de igunpa. E fi omi pa ori yin. E we ese yin titi de kokose mejeeji. Ti e ba ni jannaba lara, e we iwe imora. Ti e ba je alaisan, tabi e n be lori irin-ajo tabi eni kan ninu yin de lati ile igbonse, tabi e sunmo obinrin, ti e o ba ri omi, nigba naa ki e fi erupe mimo se tayamomu. E fi pa oju yin ati owo yin lara re. Allahu ko fe lati ko wahala ba yin, sugbon O fe lati fo yin mo. O si fe se asepe idera Re fun yin nitori ki e le dupe

وَاذْكُرُوا نِعْمَةَ اللَّهِ عَلَيْكُمْ وَمِيثَاقَهُ الَّذِي وَاثَقَكُم بِهِ إِذْ قُلْتُمْ سَمِعْنَا وَأَطَعْنَا ۖ وَاتَّقُوا اللَّهَ ۚ إِنَّ اللَّهَ عَلِيمٌ بِذَاتِ الصُّدُورِ(7)

 E ranti idera ti Allahu se fun yin ati adehun Re, eyi ti O ba yin se, nigba ti eyin so pe: “A gbo, a si tele e.” E beru Allahu. Dajudaju Allahu ni Onimo nipa ohun ti n be ninu igba-aya eda

يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا كُونُوا قَوَّامِينَ لِلَّهِ شُهَدَاءَ بِالْقِسْطِ ۖ وَلَا يَجْرِمَنَّكُمْ شَنَآنُ قَوْمٍ عَلَىٰ أَلَّا تَعْدِلُوا ۚ اعْدِلُوا هُوَ أَقْرَبُ لِلتَّقْوَىٰ ۖ وَاتَّقُوا اللَّهَ ۚ إِنَّ اللَّهَ خَبِيرٌ بِمَا تَعْمَلُونَ(8)

 Eyin ti e gbagbo ni ododo, nitori ti Allahu e je oluduro sinsin lori ododo nigba ti e ba n jerii. E ma se je ki ikorira awon eniyan kan ti yin lati ma se deede. E se deede, ohun l’o sunmo iberu Allahu julo. Ki e si beru Allahu. Dajudaju Allahu ni Alamotan nipa ohun ti e n se nise

وَعَدَ اللَّهُ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ ۙ لَهُم مَّغْفِرَةٌ وَأَجْرٌ عَظِيمٌ(9)

 Allahu se adehun fun awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si sise rere (pe) aforijin ati esan nla n be fun won

وَالَّذِينَ كَفَرُوا وَكَذَّبُوا بِآيَاتِنَا أُولَٰئِكَ أَصْحَابُ الْجَحِيمِ(10)

 Awon t’o sai gbagbo, ti won si pe awon ayah Wa niro, awon wonyen ni ero inu ina Jehim

يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا اذْكُرُوا نِعْمَتَ اللَّهِ عَلَيْكُمْ إِذْ هَمَّ قَوْمٌ أَن يَبْسُطُوا إِلَيْكُمْ أَيْدِيَهُمْ فَكَفَّ أَيْدِيَهُمْ عَنكُمْ ۖ وَاتَّقُوا اللَّهَ ۚ وَعَلَى اللَّهِ فَلْيَتَوَكَّلِ الْمُؤْمِنُونَ(11)

 Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ranti idera ti Allahu se fun yin; nigba ti ijo kan gbero lati nawo ija si yin, (Allahu) si ko won lowo ro fun yin. E beru Allahu. Ati pe Allahu ni ki awon onigbagbo ododo gbarale

۞ وَلَقَدْ أَخَذَ اللَّهُ مِيثَاقَ بَنِي إِسْرَائِيلَ وَبَعَثْنَا مِنْهُمُ اثْنَيْ عَشَرَ نَقِيبًا ۖ وَقَالَ اللَّهُ إِنِّي مَعَكُمْ ۖ لَئِنْ أَقَمْتُمُ الصَّلَاةَ وَآتَيْتُمُ الزَّكَاةَ وَآمَنتُم بِرُسُلِي وَعَزَّرْتُمُوهُمْ وَأَقْرَضْتُمُ اللَّهَ قَرْضًا حَسَنًا لَّأُكَفِّرَنَّ عَنكُمْ سَيِّئَاتِكُمْ وَلَأُدْخِلَنَّكُمْ جَنَّاتٍ تَجْرِي مِن تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ ۚ فَمَن كَفَرَ بَعْدَ ذَٰلِكَ مِنكُمْ فَقَدْ ضَلَّ سَوَاءَ السَّبِيلِ(12)

 Dajudaju Allahu gba adehun lowo awon omo ’Isro’il. A si gbe ijoye mejila dide ninu won. Allahu si so fun won pe: “Dajudaju Mo n be pelu yin, ti e ba n kirun, ti e ba n yo Zakah, ti e ba n gba awon Ojise Mi gbo, ti e ba n ran won lowo, ti e ba n ya Allahu ni dukia t’o dara. Dajudaju Mo maa pa awon asise yin re. Dajudaju Mo maa mu yin wo inu awon Ogba Idera kan, ti odo n san ni isale re. Amo enikeni ti o ba sai gbagbo leyin iyen ninu yin, o ti sina kuro loju ona.”

فَبِمَا نَقْضِهِم مِّيثَاقَهُمْ لَعَنَّاهُمْ وَجَعَلْنَا قُلُوبَهُمْ قَاسِيَةً ۖ يُحَرِّفُونَ الْكَلِمَ عَن مَّوَاضِعِهِ ۙ وَنَسُوا حَظًّا مِّمَّا ذُكِّرُوا بِهِ ۚ وَلَا تَزَالُ تَطَّلِعُ عَلَىٰ خَائِنَةٍ مِّنْهُمْ إِلَّا قَلِيلًا مِّنْهُمْ ۖ فَاعْفُ عَنْهُمْ وَاصْفَحْ ۚ إِنَّ اللَّهَ يُحِبُّ الْمُحْسِنِينَ(13)

 Nitori yiye ti won funra won ye adehun won ni A fi sebi le won. A si mu okan won le koko (nitori pe) won n gbe awon oro kuro ni awon aye re, won si gbagbe ipin kan ninu oore ti A fi se iranti fun won. O o nii ye ri onijanba laaarin won afi die ninu won. Nitori naa, se amojukuro fun won, ki o si fori jin won. Dajudaju Allahu feran awon oluse-rere

وَمِنَ الَّذِينَ قَالُوا إِنَّا نَصَارَىٰ أَخَذْنَا مِيثَاقَهُمْ فَنَسُوا حَظًّا مِّمَّا ذُكِّرُوا بِهِ فَأَغْرَيْنَا بَيْنَهُمُ الْعَدَاوَةَ وَالْبَغْضَاءَ إِلَىٰ يَوْمِ الْقِيَامَةِ ۚ وَسَوْفَ يُنَبِّئُهُمُ اللَّهُ بِمَا كَانُوا يَصْنَعُونَ(14)

 Ati pe lodo awon t’o wi pe: “Dajudaju nasara ni awa.”, A gba adehun lowo won, won si gbagbe ipin kan ninu oore ti A fi se iranti fun won. Nitori naa, A gbin ota ati ote saaarin won titi di Ojo Ajinde. Laipe Allahu maa fun won ni iro ohun ti won n se nise

يَا أَهْلَ الْكِتَابِ قَدْ جَاءَكُمْ رَسُولُنَا يُبَيِّنُ لَكُمْ كَثِيرًا مِّمَّا كُنتُمْ تُخْفُونَ مِنَ الْكِتَابِ وَيَعْفُو عَن كَثِيرٍ ۚ قَدْ جَاءَكُم مِّنَ اللَّهِ نُورٌ وَكِتَابٌ مُّبِينٌ(15)

 Eyin ahlul-kitab, dajudaju Ojise Wa ti wa ba yin. O n salaye opolopo ohun ti e fi pamo ninu tira fun yin. O si n samojukuro nibi opolopo. Imole ati Tira t’o yanju kuku ti de ba yin lati odo Allahu

يَهْدِي بِهِ اللَّهُ مَنِ اتَّبَعَ رِضْوَانَهُ سُبُلَ السَّلَامِ وَيُخْرِجُهُم مِّنَ الظُّلُمَاتِ إِلَى النُّورِ بِإِذْنِهِ وَيَهْدِيهِمْ إِلَىٰ صِرَاطٍ مُّسْتَقِيمٍ(16)

 Allahu n fi (al-Ƙur’an) se imona fun enikeni ti o ba tele (awon nnkan) ti Allahu yonu si, awon ona alaafia. (Allahu) yo si mu won jade lati inu awon okunkun wa sinu imole pelu iyonda Re. O si maa to won si ona taara (’Islam)

لَّقَدْ كَفَرَ الَّذِينَ قَالُوا إِنَّ اللَّهَ هُوَ الْمَسِيحُ ابْنُ مَرْيَمَ ۚ قُلْ فَمَن يَمْلِكُ مِنَ اللَّهِ شَيْئًا إِنْ أَرَادَ أَن يُهْلِكَ الْمَسِيحَ ابْنَ مَرْيَمَ وَأُمَّهُ وَمَن فِي الْأَرْضِ جَمِيعًا ۗ وَلِلَّهِ مُلْكُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَمَا بَيْنَهُمَا ۚ يَخْلُقُ مَا يَشَاءُ ۚ وَاللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ(17)

 Won kuku ti di keferi, awon t’o wi pe: “Dajudaju Allahu ni Mosih omo Moryam.” So pe: “Ta si l’o ni ikapa kini kan lodo Allahu ti (Allahu) ba fe pa Mosih omo Moryam, ati iya re ati awon t’o n be lori ile aye run patapata?” Ti Allahu ni ijoba awon sanmo, ile ati ohunkohun ti n be laaarin awon mejeeji. (Allahu) n sedaa ohunkohun ti O ba fe. Allahu si ni Alagbara lori gbogbo nnkan

وَقَالَتِ الْيَهُودُ وَالنَّصَارَىٰ نَحْنُ أَبْنَاءُ اللَّهِ وَأَحِبَّاؤُهُ ۚ قُلْ فَلِمَ يُعَذِّبُكُم بِذُنُوبِكُم ۖ بَلْ أَنتُم بَشَرٌ مِّمَّنْ خَلَقَ ۚ يَغْفِرُ لِمَن يَشَاءُ وَيُعَذِّبُ مَن يَشَاءُ ۚ وَلِلَّهِ مُلْكُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَمَا بَيْنَهُمَا ۖ وَإِلَيْهِ الْمَصِيرُ(18)

 Awon yehudi ati nasara wi pe: "Awa ni omo Allahu ati ololufe Re." So pe: “Ki ni idi ti O se n fi iya ese yin je yin nigba naa?” Rara (ko ri bi e se wi, amo) abara ni yin ninu awon ti O seda. O n saforijin fun eni ti O ba fe. O si n je eni ti O ba fe niya. Ti Allahu ni ijoba awon sanmo, ile ati ohunkohun ti n be laaarin awon mejeeji. Odo Re si ni abo eda

يَا أَهْلَ الْكِتَابِ قَدْ جَاءَكُمْ رَسُولُنَا يُبَيِّنُ لَكُمْ عَلَىٰ فَتْرَةٍ مِّنَ الرُّسُلِ أَن تَقُولُوا مَا جَاءَنَا مِن بَشِيرٍ وَلَا نَذِيرٍ ۖ فَقَدْ جَاءَكُم بَشِيرٌ وَنَذِيرٌ ۗ وَاللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ(19)

 Eyin ahlul-kitab, dajudaju Ojise Wa ti de ba yin, ti o n se alaye (oro) fun yin leyin asiko ti A ti da awon Ojise duro, nitori ki e ma baa wi pe: “Ko si oniroo idunnu tabi olukilo kan ti o de ba wa.” Nitori naa, dajudaju oniroo idunnu ati olukilo kan ti de ba yin. Allahu si ni Alagbara lori gbogbo nnkan

وَإِذْ قَالَ مُوسَىٰ لِقَوْمِهِ يَا قَوْمِ اذْكُرُوا نِعْمَةَ اللَّهِ عَلَيْكُمْ إِذْ جَعَلَ فِيكُمْ أَنبِيَاءَ وَجَعَلَكُم مُّلُوكًا وَآتَاكُم مَّا لَمْ يُؤْتِ أَحَدًا مِّنَ الْعَالَمِينَ(20)

 Nigba ti (Anabi) Musa so fun ijo re pe: "Eyin ijo mi, e ranti idera ti Allahu se fun yin, nigba ti O fi awon Anabi saaarin yin, ti O se yin ni oba, ti O tun fun yin ni nnkan ti ko fun eni kan ri ni agbaye (lasiko tiyin)

يَا قَوْمِ ادْخُلُوا الْأَرْضَ الْمُقَدَّسَةَ الَّتِي كَتَبَ اللَّهُ لَكُمْ وَلَا تَرْتَدُّوا عَلَىٰ أَدْبَارِكُمْ فَتَنقَلِبُوا خَاسِرِينَ(21)

 Eyin ijo mi, e wo ori ile mimo ti Allahu ko mo yin. E ma se pada seyin, nitori ki e ma baa pada di eni ofo

قَالُوا يَا مُوسَىٰ إِنَّ فِيهَا قَوْمًا جَبَّارِينَ وَإِنَّا لَن نَّدْخُلَهَا حَتَّىٰ يَخْرُجُوا مِنْهَا فَإِن يَخْرُجُوا مِنْهَا فَإِنَّا دَاخِلُونَ(22)

 Won wi pe: "Musa, dajudaju ijo ajeni-nipa wa ninu ilu naa. Dajudaju awa ko si nii wo inu re titi won yoo fi jade kuro ninu re. Ti won ba jade kuro ninu re, awa maa wo inu re nigba naa

قَالَ رَجُلَانِ مِنَ الَّذِينَ يَخَافُونَ أَنْعَمَ اللَّهُ عَلَيْهِمَا ادْخُلُوا عَلَيْهِمُ الْبَابَ فَإِذَا دَخَلْتُمُوهُ فَإِنَّكُمْ غَالِبُونَ ۚ وَعَلَى اللَّهِ فَتَوَكَّلُوا إِن كُنتُم مُّؤْمِنِينَ(23)

 Awon okunrin meji kan ninu awon ti n paya (Allahu) - Allahu si ke awon mejeeji - won so pe: "E gba enu bode wo inu ilu to won. Ti e ba wo inu ilu to won, dajudaju e maa bori won. Allahu si ni ki e gbarale, ti e ba je onigbagbo ododo

قَالُوا يَا مُوسَىٰ إِنَّا لَن نَّدْخُلَهَا أَبَدًا مَّا دَامُوا فِيهَا ۖ فَاذْهَبْ أَنتَ وَرَبُّكَ فَقَاتِلَا إِنَّا هَاهُنَا قَاعِدُونَ(24)

 Won wi pe: "Iwo Musa, dajudaju awa ko nii wo inu ilu naa laelae niwon igba ti won ba si wa ninu re. Nitori naa, ki iwo ati Oluwa re lo. Ki eyin mejeeji ja won logun. Dajudaju ibi yii ni awa yoo jokoo si na

قَالَ رَبِّ إِنِّي لَا أَمْلِكُ إِلَّا نَفْسِي وَأَخِي ۖ فَافْرُقْ بَيْنَنَا وَبَيْنَ الْقَوْمِ الْفَاسِقِينَ(25)

 O so pe: "Oluwa mi, dajudaju emi ko ni ikapa lori eni kan bi ko se (lori) ara mi ati arakunrin mi. Nitori naa, ya awa ati ijo obileje si otooto

قَالَ فَإِنَّهَا مُحَرَّمَةٌ عَلَيْهِمْ ۛ أَرْبَعِينَ سَنَةً ۛ يَتِيهُونَ فِي الْأَرْضِ ۚ فَلَا تَأْسَ عَلَى الْقَوْمِ الْفَاسِقِينَ(26)

 (Allahu) so pe: “Dajudaju o ti di eewo fun won (lati wo inu ilu naa) fun ogoji odun ti won yoo fi maa rin rin rin lori ile. Nitori naa, ma se banuje nitori ijo obileje.”

۞ وَاتْلُ عَلَيْهِمْ نَبَأَ ابْنَيْ آدَمَ بِالْحَقِّ إِذْ قَرَّبَا قُرْبَانًا فَتُقُبِّلَ مِنْ أَحَدِهِمَا وَلَمْ يُتَقَبَّلْ مِنَ الْآخَرِ قَالَ لَأَقْتُلَنَّكَ ۖ قَالَ إِنَّمَا يَتَقَبَّلُ اللَّهُ مِنَ الْمُتَّقِينَ(27)

 Ka oro awon omo (Anabi) Adam mejeeji fun won pelu ododo. (Ranti) nigba ti awon mejeeji se itore ase (lati fi sunmo Allahu). Won gba ti okan ninu awon mejeeji, Won ko si gba ti ikeji. (Eni ti Won ko gba tire) wi pe: “Dajudaju emi yoo pa o.” (Ikeji) si so pe: "(Ore) tawon oluberu nikan ni Allahu maa gba

لَئِن بَسَطتَ إِلَيَّ يَدَكَ لِتَقْتُلَنِي مَا أَنَا بِبَاسِطٍ يَدِيَ إِلَيْكَ لِأَقْتُلَكَ ۖ إِنِّي أَخَافُ اللَّهَ رَبَّ الْعَالَمِينَ(28)

 Dajudaju ti o ba na owo re si mi lati pa mi, emi ko si nii na owo mi si o lati pa o, nitori pe emi n beru Allahu, Oluwa gbogbo eda

إِنِّي أُرِيدُ أَن تَبُوءَ بِإِثْمِي وَإِثْمِكَ فَتَكُونَ مِنْ أَصْحَابِ النَّارِ ۚ وَذَٰلِكَ جَزَاءُ الظَّالِمِينَ(29)

 Dajudaju emi fe ki o pada (si odo Allahu ni Ojo Ajinde) pelu ese (bi o se pa) mi ati ese tire nitori ki o le je okan ninu awon ero inu Ina. Iyen si ni esan awon alabosi

فَطَوَّعَتْ لَهُ نَفْسُهُ قَتْلَ أَخِيهِ فَقَتَلَهُ فَأَصْبَحَ مِنَ الْخَاسِرِينَ(30)

 Emi re si gba fun un lati pa arakunrin re. O pa a. O si di okan ninu awon eni ofo

فَبَعَثَ اللَّهُ غُرَابًا يَبْحَثُ فِي الْأَرْضِ لِيُرِيَهُ كَيْفَ يُوَارِي سَوْءَةَ أَخِيهِ ۚ قَالَ يَا وَيْلَتَا أَعَجَزْتُ أَنْ أَكُونَ مِثْلَ هَٰذَا الْغُرَابِ فَأُوَارِيَ سَوْءَةَ أَخِي ۖ فَأَصْبَحَ مِنَ النَّادِمِينَ(31)

 Allahu si gbe eye kannakanna kan dide. O si n fi ese wa ile nitori ki o le fi bi o se maa bo oku arakunrin re mo inu ile han an. O wi pe: “Temi baje o! Mo kagara lati da bi iru eye kannakanna yii, ki ng si le bo oku arakunrin mi mole.” O si di ara awon alabaamo

مِنْ أَجْلِ ذَٰلِكَ كَتَبْنَا عَلَىٰ بَنِي إِسْرَائِيلَ أَنَّهُ مَن قَتَلَ نَفْسًا بِغَيْرِ نَفْسٍ أَوْ فَسَادٍ فِي الْأَرْضِ فَكَأَنَّمَا قَتَلَ النَّاسَ جَمِيعًا وَمَنْ أَحْيَاهَا فَكَأَنَّمَا أَحْيَا النَّاسَ جَمِيعًا ۚ وَلَقَدْ جَاءَتْهُمْ رُسُلُنَا بِالْبَيِّنَاتِ ثُمَّ إِنَّ كَثِيرًا مِّنْهُم بَعْدَ ذَٰلِكَ فِي الْأَرْضِ لَمُسْرِفُونَ(32)

 Nitori iyen, A si se e ni ofin fun awon omo ’Isro’il pe dajudaju enikeni ti o ba pa emi (eniyan) kan laije nitori pipa emi (eniyan) kan tabi sise ibaje kan lori ile, o da bi eni ti o pa gbogbo eniyan patapata. Enikeni ti o ba si mu emi (eniyan) semi, o da bi eni ti o mu gbogbo eniyan semi patapata. Awon Ojise Wa si ti wa ba won pelu awon eri t’o yanju. Leyin naa, dajudaju opolopo ninu won leyin iyen ni alakoyo lori ile

إِنَّمَا جَزَاءُ الَّذِينَ يُحَارِبُونَ اللَّهَ وَرَسُولَهُ وَيَسْعَوْنَ فِي الْأَرْضِ فَسَادًا أَن يُقَتَّلُوا أَوْ يُصَلَّبُوا أَوْ تُقَطَّعَ أَيْدِيهِمْ وَأَرْجُلُهُم مِّنْ خِلَافٍ أَوْ يُنفَوْا مِنَ الْأَرْضِ ۚ ذَٰلِكَ لَهُمْ خِزْيٌ فِي الدُّنْيَا ۖ وَلَهُمْ فِي الْآخِرَةِ عَذَابٌ عَظِيمٌ(33)

 Esan awon t’o n gbogun ti Allahu ati Ojise Re, ti won si n se ibaje lori ile ni pe, ki e pa won tabi ki e kan won mo igi agbelebuu tabi ki e ge owo won ati ese won ni ipasipayo tabi ki e le won kuro ninu ilu. Iyen ni iyepere fun won nile aye. Iya nla si n be fun won ni orun

إِلَّا الَّذِينَ تَابُوا مِن قَبْلِ أَن تَقْدِرُوا عَلَيْهِمْ ۖ فَاعْلَمُوا أَنَّ اللَّهَ غَفُورٌ رَّحِيمٌ(34)

 Ayafi awon t’o ronu piwada siwaju ki e to lagbara lori won. Nitori naa, e mo pe dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun

يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا اتَّقُوا اللَّهَ وَابْتَغُوا إِلَيْهِ الْوَسِيلَةَ وَجَاهِدُوا فِي سَبِيلِهِ لَعَلَّكُمْ تُفْلِحُونَ(35)

 Eyin ti e gbagbo ni ododo, e beru Allahu, ki e si wa ategun si odo Re (pelu ise rere). E jagun fun esin Re nitori ki e le jere

إِنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا لَوْ أَنَّ لَهُم مَّا فِي الْأَرْضِ جَمِيعًا وَمِثْلَهُ مَعَهُ لِيَفْتَدُوا بِهِ مِنْ عَذَابِ يَوْمِ الْقِيَامَةِ مَا تُقُبِّلَ مِنْهُمْ ۖ وَلَهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ(36)

 Dajudaju awon t’o sai gbagbo, ti o ba je pe gbogbo ohun ti n be lori ile aye patapata je tiwon ati iru re pelu re lati fi gba ara won sile nibi iya Ojo Ajinde, A o nii gba a ni owo won. Iya eleta-elero si wa fun won

يُرِيدُونَ أَن يَخْرُجُوا مِنَ النَّارِ وَمَا هُم بِخَارِجِينَ مِنْهَا ۖ وَلَهُمْ عَذَابٌ مُّقِيمٌ(37)

 Won yoo fe jade kuro ninu Ina, won ko si nii le jade kuro ninu re. Iya gbere si wa fun won

وَالسَّارِقُ وَالسَّارِقَةُ فَاقْطَعُوا أَيْدِيَهُمَا جَزَاءً بِمَا كَسَبَا نَكَالًا مِّنَ اللَّهِ ۗ وَاللَّهُ عَزِيزٌ حَكِيمٌ(38)

 Ole lokunrin ati ole lobinrin, e ge owo awon mejeeji. (O je) esan fun ise owo awon mejeeji. (O si je) ijiya lati odo Allahu. Allahu si ni Alagbara, Ologbon

فَمَن تَابَ مِن بَعْدِ ظُلْمِهِ وَأَصْلَحَ فَإِنَّ اللَّهَ يَتُوبُ عَلَيْهِ ۗ إِنَّ اللَّهَ غَفُورٌ رَّحِيمٌ(39)

 Enikeni ti o ba ronu piwada leyin abosi (owo) re, ti o si se atunse, dajudaju Allahu yoo gba ironupiwada re. Dajudaju Allahu ni Alaforijin, Alaaanu

أَلَمْ تَعْلَمْ أَنَّ اللَّهَ لَهُ مُلْكُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ يُعَذِّبُ مَن يَشَاءُ وَيَغْفِرُ لِمَن يَشَاءُ ۗ وَاللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ(40)

 Se o o mo pe dajudaju ti Allahu ni ijoba awon sanmo ati ile? O maa je eni ti O ba fe niya. O si maa fori jin eni ti O ba fe. Allahu si ni Alagbara lori gbogbo nnkan

۞ يَا أَيُّهَا الرَّسُولُ لَا يَحْزُنكَ الَّذِينَ يُسَارِعُونَ فِي الْكُفْرِ مِنَ الَّذِينَ قَالُوا آمَنَّا بِأَفْوَاهِهِمْ وَلَمْ تُؤْمِن قُلُوبُهُمْ ۛ وَمِنَ الَّذِينَ هَادُوا ۛ سَمَّاعُونَ لِلْكَذِبِ سَمَّاعُونَ لِقَوْمٍ آخَرِينَ لَمْ يَأْتُوكَ ۖ يُحَرِّفُونَ الْكَلِمَ مِن بَعْدِ مَوَاضِعِهِ ۖ يَقُولُونَ إِنْ أُوتِيتُمْ هَٰذَا فَخُذُوهُ وَإِن لَّمْ تُؤْتَوْهُ فَاحْذَرُوا ۚ وَمَن يُرِدِ اللَّهُ فِتْنَتَهُ فَلَن تَمْلِكَ لَهُ مِنَ اللَّهِ شَيْئًا ۚ أُولَٰئِكَ الَّذِينَ لَمْ يُرِدِ اللَّهُ أَن يُطَهِّرَ قُلُوبَهُمْ ۚ لَهُمْ فِي الدُّنْيَا خِزْيٌ ۖ وَلَهُمْ فِي الْآخِرَةِ عَذَابٌ عَظِيمٌ(41)

 Iwo Ojise, ma se je ki o ba o ninu je awon t’o n yara lo sinu aigbagbo ninu awon t’o fi enu ara won wi pe: “A gbagbo.” – ti okan won ko si gbagbo ni ododo - ati awon t’o di yehudi, ti won n teti si iro, ti won si n teti si oro fun awon eniyan miiran ti ko wa si odo re, ti won n yi oro pada kuro ni awon aye re, won si n wi pe: “Ti won ba fun yin ni eyi e gba a. Ti won ko ba si fun yin e sora.” Enikeni ti Allahu ba fe fooro re, o o ni ikapa kini kan lodo Allahu fun un. Awon wonyen ni awon ti Allahu ko fe fo okan won mo. Idojuti n be fun won ni aye. Iya nla si n be fun won ni orun

سَمَّاعُونَ لِلْكَذِبِ أَكَّالُونَ لِلسُّحْتِ ۚ فَإِن جَاءُوكَ فَاحْكُم بَيْنَهُمْ أَوْ أَعْرِضْ عَنْهُمْ ۖ وَإِن تُعْرِضْ عَنْهُمْ فَلَن يَضُرُّوكَ شَيْئًا ۖ وَإِنْ حَكَمْتَ فَاحْكُم بَيْنَهُم بِالْقِسْطِ ۚ إِنَّ اللَّهَ يُحِبُّ الْمُقْسِطِينَ(42)

 Won n teti gbo iro, won si n je nnkan eewo. Nitori naa, ti won ba wa ba o, sedajo laaarin won tabi ki o seri kuro lodo won. Ti o ba seri kuro lodo won, won ko le ko inira kan kan ba o. Ti o ba si fe dajo, se idajo laaarin won pelu deede. Dajudaju Allahu nifee awon onideede

وَكَيْفَ يُحَكِّمُونَكَ وَعِندَهُمُ التَّوْرَاةُ فِيهَا حُكْمُ اللَّهِ ثُمَّ يَتَوَلَّوْنَ مِن بَعْدِ ذَٰلِكَ ۚ وَمَا أُولَٰئِكَ بِالْمُؤْمِنِينَ(43)

 Bawo ni won a se fi o se adajo, nigba ti o je pe Taorah wa lodo won. Idajo Allahu si wa ninu re. Leyin naa, won n peyin da leyin iyen. Awon wonyen ki i si se onigbagbo ododo

إِنَّا أَنزَلْنَا التَّوْرَاةَ فِيهَا هُدًى وَنُورٌ ۚ يَحْكُمُ بِهَا النَّبِيُّونَ الَّذِينَ أَسْلَمُوا لِلَّذِينَ هَادُوا وَالرَّبَّانِيُّونَ وَالْأَحْبَارُ بِمَا اسْتُحْفِظُوا مِن كِتَابِ اللَّهِ وَكَانُوا عَلَيْهِ شُهَدَاءَ ۚ فَلَا تَخْشَوُا النَّاسَ وَاخْشَوْنِ وَلَا تَشْتَرُوا بِآيَاتِي ثَمَنًا قَلِيلًا ۚ وَمَن لَّمْ يَحْكُم بِمَا أَنزَلَ اللَّهُ فَأُولَٰئِكَ هُمُ الْكَافِرُونَ(44)

 Dajudaju Awa so Taorah kale. Imona ati imole n be ninu re. Awon Anabi ti won je musulumi n fi se idajo fun awon t’o di yehudi. Bee naa ni awon alufaa ati awon amofin (n fi se idajo) nitori ohun ti A ni ki won so ninu tira Allahu. Won si je elerii lori re. Nitori naa, ma se paya eniyan. E paya Mi. E ma se ta awon ayah Mi ni owo kekere. Enikeni ti ko ba sedajo pelu ohun ti Allahu sokale, awon wonyen ni alaigbagbo

وَكَتَبْنَا عَلَيْهِمْ فِيهَا أَنَّ النَّفْسَ بِالنَّفْسِ وَالْعَيْنَ بِالْعَيْنِ وَالْأَنفَ بِالْأَنفِ وَالْأُذُنَ بِالْأُذُنِ وَالسِّنَّ بِالسِّنِّ وَالْجُرُوحَ قِصَاصٌ ۚ فَمَن تَصَدَّقَ بِهِ فَهُوَ كَفَّارَةٌ لَّهُ ۚ وَمَن لَّمْ يَحْكُم بِمَا أَنزَلَ اللَّهُ فَأُولَٰئِكَ هُمُ الظَّالِمُونَ(45)

 A si se e ni ofin sinu re pe dajudaju emi fun emi, oju fun oju, imu fun imu, eti fun eti ati eyin fun eyin. Ofin esan gbigba si wa fun oju-ogbe. Enikeni ti o ba si yonda igbesan, o si maa je ipesere fun un. Enikeni ti ko ba sedajo pelu ohun ti Allahu sokale, awon wonyen ni alabosi

وَقَفَّيْنَا عَلَىٰ آثَارِهِم بِعِيسَى ابْنِ مَرْيَمَ مُصَدِّقًا لِّمَا بَيْنَ يَدَيْهِ مِنَ التَّوْرَاةِ ۖ وَآتَيْنَاهُ الْإِنجِيلَ فِيهِ هُدًى وَنُورٌ وَمُصَدِّقًا لِّمَا بَيْنَ يَدَيْهِ مِنَ التَّوْرَاةِ وَهُدًى وَمَوْعِظَةً لِّلْمُتَّقِينَ(46)

 A fi ‘Isa omo Moryam tele oripa won (iyen, awon Anabi ti won je musulumi); ti o n fi ohun t’o je ododo rinle nipa eyi t’o siwaju re ninu Taorah. A si fun un ni ’Injil. Imona ati imole wa ninu re, ti o n fi ohun t’o je ododo rinle nipa eyi t’o siwaju re ninu Taorah. (O je) imona ati waasi fun awon oluberu (Allahu ni asiko tire)

وَلْيَحْكُمْ أَهْلُ الْإِنجِيلِ بِمَا أَنزَلَ اللَّهُ فِيهِ ۚ وَمَن لَّمْ يَحْكُم بِمَا أَنزَلَ اللَّهُ فَأُولَٰئِكَ هُمُ الْفَاسِقُونَ(47)

 Ki awon ti A fun ni ’Injil sedajo pelu ohun ti Allahu sokale ninu re. Enikeni ti ko ba sedajo pelu ohun ti Allahu sokale, awon wonyen ni obileje

وَأَنزَلْنَا إِلَيْكَ الْكِتَابَ بِالْحَقِّ مُصَدِّقًا لِّمَا بَيْنَ يَدَيْهِ مِنَ الْكِتَابِ وَمُهَيْمِنًا عَلَيْهِ ۖ فَاحْكُم بَيْنَهُم بِمَا أَنزَلَ اللَّهُ ۖ وَلَا تَتَّبِعْ أَهْوَاءَهُمْ عَمَّا جَاءَكَ مِنَ الْحَقِّ ۚ لِكُلٍّ جَعَلْنَا مِنكُمْ شِرْعَةً وَمِنْهَاجًا ۚ وَلَوْ شَاءَ اللَّهُ لَجَعَلَكُمْ أُمَّةً وَاحِدَةً وَلَٰكِن لِّيَبْلُوَكُمْ فِي مَا آتَاكُمْ ۖ فَاسْتَبِقُوا الْخَيْرَاتِ ۚ إِلَى اللَّهِ مَرْجِعُكُمْ جَمِيعًا فَيُنَبِّئُكُم بِمَا كُنتُمْ فِيهِ تَخْتَلِفُونَ(48)

 A so Tira (al-Ƙur’an) kale fun o pelu ododo. O n jerii si eyi t’o je ododo ninu eyi t’o siwaju re ninu Tira. O n wa aabo fun awon ofin inu re. Nitori naa, fi ohun ti Allahu sokale dajo laaarin won. Ma se tele ife-inu won t’o yapa si ohun ti o de ba o ninu ododo. Olukuluku ninu yin ni A ti se ofin ati ilana fun. Ati pe ti o ba je pe Allahu ba fe, iba se yin ni ijo kan soso (sinu ’Islam), sugbon nitori ki O le dan yin wo ninu ohun ti O fun yin ni. Nitori naa, e gbawaju nibi ise rere. Odo Allahu ni ibupadasi gbogbo yin patapata. O si maa fun yin ni iro nipa ohun ti e n yapa enu si

وَأَنِ احْكُم بَيْنَهُم بِمَا أَنزَلَ اللَّهُ وَلَا تَتَّبِعْ أَهْوَاءَهُمْ وَاحْذَرْهُمْ أَن يَفْتِنُوكَ عَن بَعْضِ مَا أَنزَلَ اللَّهُ إِلَيْكَ ۖ فَإِن تَوَلَّوْا فَاعْلَمْ أَنَّمَا يُرِيدُ اللَّهُ أَن يُصِيبَهُم بِبَعْضِ ذُنُوبِهِمْ ۗ وَإِنَّ كَثِيرًا مِّنَ النَّاسِ لَفَاسِقُونَ(49)

 Ati pe ki o fi ohun ti Allahu sokale se idajo laaarin won. Ma se tele ife-inu won. Sora fun won ki won ma baa fooro re kuro nibi apa kan ohun ti Allahu sokale fun o. Ti won ba si gbunri, mo pe Allahu kan fe fi adanwo kan won ni nitori apa kan ese won. Ati pe dajudaju opolopo ninu eniyan ni obileje

أَفَحُكْمَ الْجَاهِلِيَّةِ يَبْغُونَ ۚ وَمَنْ أَحْسَنُ مِنَ اللَّهِ حُكْمًا لِّقَوْمٍ يُوقِنُونَ(50)

 Se idajo igba aimokan ni won n wa ni? Ta ni eni ti o dara ju Allahu lo nibi idajo fun ijo t’o ni amodaju (nipa Re)

۞ يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا تَتَّخِذُوا الْيَهُودَ وَالنَّصَارَىٰ أَوْلِيَاءَ ۘ بَعْضُهُمْ أَوْلِيَاءُ بَعْضٍ ۚ وَمَن يَتَوَلَّهُم مِّنكُمْ فَإِنَّهُ مِنْهُمْ ۗ إِنَّ اللَّهَ لَا يَهْدِي الْقَوْمَ الظَّالِمِينَ(51)

 Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se mu awon yehudi ati nasara ni ore ayo. Apa kan won lore apa kan. Enikeni ti o ba mu won ni ore ayo ninu yin, dajudaju o ti di ara won. Dajudaju Allahu ko nii fi ona mo ijo alabosi

فَتَرَى الَّذِينَ فِي قُلُوبِهِم مَّرَضٌ يُسَارِعُونَ فِيهِمْ يَقُولُونَ نَخْشَىٰ أَن تُصِيبَنَا دَائِرَةٌ ۚ فَعَسَى اللَّهُ أَن يَأْتِيَ بِالْفَتْحِ أَوْ أَمْرٍ مِّنْ عِندِهِ فَيُصْبِحُوا عَلَىٰ مَا أَسَرُّوا فِي أَنفُسِهِمْ نَادِمِينَ(52)

 Nitori naa, o maa ri awon ti aare wa ninu okan won, ti won yoo maa yara lo saaarin won. Won yoo maa wi pe: “A n beru pe ki apadasi igba ma baa kan wa ni.” O sunmo ki Allahu mu isegun tabi ase kan wa lati odo Re. Won yo si di alabaamo lori ohun ti won fi pamo sinu okan won

وَيَقُولُ الَّذِينَ آمَنُوا أَهَٰؤُلَاءِ الَّذِينَ أَقْسَمُوا بِاللَّهِ جَهْدَ أَيْمَانِهِمْ ۙ إِنَّهُمْ لَمَعَكُمْ ۚ حَبِطَتْ أَعْمَالُهُمْ فَأَصْبَحُوا خَاسِرِينَ(53)

 Awon t’o gbagbo ni ododo si maa so pe: "Se awon (yehudi) wonyi ko ni awon t’o fi Allahu bura ti ibura won si lagbara gan-an pe dajudaju awon n be pelu eyin (munafiki)?" Ise won ti baje. Nitori naa, won si di eni ofo

يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا مَن يَرْتَدَّ مِنكُمْ عَن دِينِهِ فَسَوْفَ يَأْتِي اللَّهُ بِقَوْمٍ يُحِبُّهُمْ وَيُحِبُّونَهُ أَذِلَّةٍ عَلَى الْمُؤْمِنِينَ أَعِزَّةٍ عَلَى الْكَافِرِينَ يُجَاهِدُونَ فِي سَبِيلِ اللَّهِ وَلَا يَخَافُونَ لَوْمَةَ لَائِمٍ ۚ ذَٰلِكَ فَضْلُ اللَّهِ يُؤْتِيهِ مَن يَشَاءُ ۚ وَاللَّهُ وَاسِعٌ عَلِيمٌ(54)

 Eyin ti e gbagbo ni ododo, enikeni ti o ba peyinda nibi esin re ninu yin, laipe Allahu maa mu awon eniyan kan wa; O maa nifee won, awon naa maa nifee Re. Won yoo ro fun awon onigbagbo ododo. Won yo si le mo awon alaigbagbo. Won yoo maa jagun esin fun Allahu. Won ko si nii beru eebu eleeebu. Iyen ni oore ajulo Allahu. O n fun eni ti O ba fe. Allahu si ni Olugbooro, Onimo

إِنَّمَا وَلِيُّكُمُ اللَّهُ وَرَسُولُهُ وَالَّذِينَ آمَنُوا الَّذِينَ يُقِيمُونَ الصَّلَاةَ وَيُؤْتُونَ الزَّكَاةَ وَهُمْ رَاكِعُونَ(55)

 Allahu ati Ojise Re ati awon t’o gbagbo ni ododo nikan ni ore yin, awon t’o n kirun, ti won si n yo Zakah, awon si ni oludawote-orunkun (lori irun)

وَمَن يَتَوَلَّ اللَّهَ وَرَسُولَهُ وَالَّذِينَ آمَنُوا فَإِنَّ حِزْبَ اللَّهِ هُمُ الْغَالِبُونَ(56)

 Enikeni ti o ba mu Allahu ati Ojise Re ati awon onigbagbo ododo ni ore; dajudaju ijo Allahu, awon ni olubori

يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا تَتَّخِذُوا الَّذِينَ اتَّخَذُوا دِينَكُمْ هُزُوًا وَلَعِبًا مِّنَ الَّذِينَ أُوتُوا الْكِتَابَ مِن قَبْلِكُمْ وَالْكُفَّارَ أَوْلِيَاءَ ۚ وَاتَّقُوا اللَّهَ إِن كُنتُم مُّؤْمِنِينَ(57)

 Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se mu awon t’o so esin yin di nnkan yeye ati ere sise ni ore ninu awon ti A fun ni tira siwaju yin ati awon alaigbagbo. E beru Allahu ti e ba je onigbagbo ododo

وَإِذَا نَادَيْتُمْ إِلَى الصَّلَاةِ اتَّخَذُوهَا هُزُوًا وَلَعِبًا ۚ ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمْ قَوْمٌ لَّا يَعْقِلُونَ(58)

 Nigba ti e ba pepe sibi irun kiki, won yoo so o di nnkan yeye ati ere sise. Iyen nitori pe dajudaju awon ni ijo ti ko se laakaye

قُلْ يَا أَهْلَ الْكِتَابِ هَلْ تَنقِمُونَ مِنَّا إِلَّا أَنْ آمَنَّا بِاللَّهِ وَمَا أُنزِلَ إِلَيْنَا وَمَا أُنزِلَ مِن قَبْلُ وَأَنَّ أَكْثَرَكُمْ فَاسِقُونَ(59)

 So pe: “Eyin ahlul-kitab, nje e tako kini kan lara wa bi ko se pe a gbagbo ninu Allahu ati ohun ti Won sokale fun wa ati ohun ti Won sokale siwaju?” Dajudaju opolopo yin ni obileje

قُلْ هَلْ أُنَبِّئُكُم بِشَرٍّ مِّن ذَٰلِكَ مَثُوبَةً عِندَ اللَّهِ ۚ مَن لَّعَنَهُ اللَّهُ وَغَضِبَ عَلَيْهِ وَجَعَلَ مِنْهُمُ الْقِرَدَةَ وَالْخَنَازِيرَ وَعَبَدَ الطَّاغُوتَ ۚ أُولَٰئِكَ شَرٌّ مَّكَانًا وَأَضَلُّ عَن سَوَاءِ السَّبِيلِ(60)

 So pe: “Se ki ng fun yin ni iro awon ti iya won buru ju iyen lo ni odo Allahu?” (Oun ni) eni ti Allahu sebi le, ti O si binu si, ti O si so awon kan ninu won di obo, elede ati aborisa. Awon wonyen ni ipo won buru julo, awon si ni won sina julo

وَإِذَا جَاءُوكُمْ قَالُوا آمَنَّا وَقَد دَّخَلُوا بِالْكُفْرِ وَهُمْ قَدْ خَرَجُوا بِهِ ۚ وَاللَّهُ أَعْلَمُ بِمَا كَانُوا يَكْتُمُونَ(61)

 Nigba ti won ba wa si odo yin, won a wi pe: “A gbagbo.” Dajudaju won wole (ti yin) pelu aigbagbo, won si ti jade pelu re. Allahu si nimo julo nipa ohun ti won n fi pamo

وَتَرَىٰ كَثِيرًا مِّنْهُمْ يُسَارِعُونَ فِي الْإِثْمِ وَالْعُدْوَانِ وَأَكْلِهِمُ السُّحْتَ ۚ لَبِئْسَ مَا كَانُوا يَعْمَلُونَ(62)

 O maa ri opolopo ninu won, ti won n yara ko sinu ese, itayo enu-ala ati jije ti won n je owo eru. Dajudaju ohun ti won n se nise buru

لَوْلَا يَنْهَاهُمُ الرَّبَّانِيُّونَ وَالْأَحْبَارُ عَن قَوْلِهِمُ الْإِثْمَ وَأَكْلِهِمُ السُّحْتَ ۚ لَبِئْسَ مَا كَانُوا يَصْنَعُونَ(63)

 Ki ni ko je ki awon alufaa ati awon amofin maa ko fun won nipa oro enu won (ti o je) ese ati jije ti won n je owo eru! Dajudaju ohun ti won n se nise buru

وَقَالَتِ الْيَهُودُ يَدُ اللَّهِ مَغْلُولَةٌ ۚ غُلَّتْ أَيْدِيهِمْ وَلُعِنُوا بِمَا قَالُوا ۘ بَلْ يَدَاهُ مَبْسُوطَتَانِ يُنفِقُ كَيْفَ يَشَاءُ ۚ وَلَيَزِيدَنَّ كَثِيرًا مِّنْهُم مَّا أُنزِلَ إِلَيْكَ مِن رَّبِّكَ طُغْيَانًا وَكُفْرًا ۚ وَأَلْقَيْنَا بَيْنَهُمُ الْعَدَاوَةَ وَالْبَغْضَاءَ إِلَىٰ يَوْمِ الْقِيَامَةِ ۚ كُلَّمَا أَوْقَدُوا نَارًا لِّلْحَرْبِ أَطْفَأَهَا اللَّهُ ۚ وَيَسْعَوْنَ فِي الْأَرْضِ فَسَادًا ۚ وَاللَّهُ لَا يُحِبُّ الْمُفْسِدِينَ(64)

 Awon yehudi wi pe: "Owo Allahu wa ni didi pa." A di owo won pa. A si sebi le won nitori ohun ti won wi. Amo owo Re mejeeji wa ni tite sile. O si n tore bi O se fe. Ohun ti won sokale fun o lati odo Oluwa Re yoo kuku je ki opolopo won lekun ni igberaga ati aigbagbo ni. A si ju ota ati ikorira saaarin won titi di Ojo Ajinde. Igbakigba ti won ba dana ogun, Allahu si maa pana re. Won si n se ibaje lori ile. Allahu ko si nifee awon obileje

وَلَوْ أَنَّ أَهْلَ الْكِتَابِ آمَنُوا وَاتَّقَوْا لَكَفَّرْنَا عَنْهُمْ سَيِّئَاتِهِمْ وَلَأَدْخَلْنَاهُمْ جَنَّاتِ النَّعِيمِ(65)

 Ti o ba je pe dajudaju awon ahlul-kitab gbagbo ni ododo, ki won si beru (Allahu), Awa iba pa awon aida won re fun won, Awa iba si mu won wo inu awon Ogba Idera

وَلَوْ أَنَّهُمْ أَقَامُوا التَّوْرَاةَ وَالْإِنجِيلَ وَمَا أُنزِلَ إِلَيْهِم مِّن رَّبِّهِمْ لَأَكَلُوا مِن فَوْقِهِمْ وَمِن تَحْتِ أَرْجُلِهِم ۚ مِّنْهُمْ أُمَّةٌ مُّقْتَصِدَةٌ ۖ وَكَثِيرٌ مِّنْهُمْ سَاءَ مَا يَعْمَلُونَ(66)

 Ti o ba je pe dajudaju won lo at-Taorah ati al-’Injil ati ohun ti A sokale fun won lati odo Oluwa won (iyen, al-Ƙur’an), won iba maa je lati oke won ati lati isale ese won. Ijo kan n be ninu won t’o duro deede, (amo) ohun ti opolopo ninu won n se nise buru

۞ يَا أَيُّهَا الرَّسُولُ بَلِّغْ مَا أُنزِلَ إِلَيْكَ مِن رَّبِّكَ ۖ وَإِن لَّمْ تَفْعَلْ فَمَا بَلَّغْتَ رِسَالَتَهُ ۚ وَاللَّهُ يَعْصِمُكَ مِنَ النَّاسِ ۗ إِنَّ اللَّهَ لَا يَهْدِي الْقَوْمَ الْكَافِرِينَ(67)

 Iwo Ojise, fi gbogbo ohun ti won sokale fun o lati odo Oluwa re jise. Ti o o ba si se bee, o o jise pe. Allahu yo si daabo bo o lodo awon eniyan. Dajudaju Allahu ko nii fi ona mo ijo alaigbagbo (lati se o ni aburu)

قُلْ يَا أَهْلَ الْكِتَابِ لَسْتُمْ عَلَىٰ شَيْءٍ حَتَّىٰ تُقِيمُوا التَّوْرَاةَ وَالْإِنجِيلَ وَمَا أُنزِلَ إِلَيْكُم مِّن رَّبِّكُمْ ۗ وَلَيَزِيدَنَّ كَثِيرًا مِّنْهُم مَّا أُنزِلَ إِلَيْكَ مِن رَّبِّكَ طُغْيَانًا وَكُفْرًا ۖ فَلَا تَأْسَ عَلَى الْقَوْمِ الْكَافِرِينَ(68)

 So pe: “Eyin ahlul-kitab, e o ri kini kan se (ninu esin) titi e maa fi lo at-Taorah ati al-’Injil ati ohun ti A sokale fun yin lati odo Oluwa yin (iyen, al-Ƙur’an).” Ohun ti won sokale fun o lati odo Oluwa Re yoo kuku je ki opolopo won lekun ni igberaga ati aigbagbo ni. Nitori naa, ma se banuje nitori ijo alaigbagbo

إِنَّ الَّذِينَ آمَنُوا وَالَّذِينَ هَادُوا وَالصَّابِئُونَ وَالنَّصَارَىٰ مَنْ آمَنَ بِاللَّهِ وَالْيَوْمِ الْآخِرِ وَعَمِلَ صَالِحًا فَلَا خَوْفٌ عَلَيْهِمْ وَلَا هُمْ يَحْزَنُونَ(69)

 Dajudaju awon t’o gbagbo ni ododo ati awon t’o di yehudi, - awon sobi’un ati awon kristieni, - enikeni ti o ba ni igbagbo ododo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin, ti o si sise rere, ko nii si iberu fun won. Won ko si nii banuje

لَقَدْ أَخَذْنَا مِيثَاقَ بَنِي إِسْرَائِيلَ وَأَرْسَلْنَا إِلَيْهِمْ رُسُلًا ۖ كُلَّمَا جَاءَهُمْ رَسُولٌ بِمَا لَا تَهْوَىٰ أَنفُسُهُمْ فَرِيقًا كَذَّبُوا وَفَرِيقًا يَقْتُلُونَ(70)

 A kuku gba adehun lowo awon omo ’Isro’il. A si ran awon Ojise kan si won. Igbakigba ti Ojise kan ba de ba won pelu ohun ti emi won ko fe, won pe igun kan ni opuro, won si n pa igun kan

وَحَسِبُوا أَلَّا تَكُونَ فِتْنَةٌ فَعَمُوا وَصَمُّوا ثُمَّ تَابَ اللَّهُ عَلَيْهِمْ ثُمَّ عَمُوا وَصَمُّوا كَثِيرٌ مِّنْهُمْ ۚ وَاللَّهُ بَصِيرٌ بِمَا يَعْمَلُونَ(71)

 Won si lero pe ko nii si ifooro; won foju, won si diti (si ododo). Leyin naa, Allahu gba ironupiwada won. Leyin naa, won foju, won tun diti (si ododo); opolopo ninu won (lo se bee). Allahu si ni Oluriran nipa ohun ti won n se nise

لَقَدْ كَفَرَ الَّذِينَ قَالُوا إِنَّ اللَّهَ هُوَ الْمَسِيحُ ابْنُ مَرْيَمَ ۖ وَقَالَ الْمَسِيحُ يَا بَنِي إِسْرَائِيلَ اعْبُدُوا اللَّهَ رَبِّي وَرَبَّكُمْ ۖ إِنَّهُ مَن يُشْرِكْ بِاللَّهِ فَقَدْ حَرَّمَ اللَّهُ عَلَيْهِ الْجَنَّةَ وَمَأْوَاهُ النَّارُ ۖ وَمَا لِلظَّالِمِينَ مِنْ أَنصَارٍ(72)

 Won kuku ti di keferi, awon t’o wi pe: “Dajudaju Allahu, Oun ni Mosih omo Moryam.” Mosih si so pe: "Eyin omo ’Isro’il, e josin fun Allahu, Oluwa mi ati Oluwa yin. Dajudaju enikeni ti o ba ba Allahu wa akegbe, Allahu ti se Ogba Idera ni eewo fun un. Ina si ni ibugbe re. Ko si nii si alaranse kan fun awon alabosi

لَّقَدْ كَفَرَ الَّذِينَ قَالُوا إِنَّ اللَّهَ ثَالِثُ ثَلَاثَةٍ ۘ وَمَا مِنْ إِلَٰهٍ إِلَّا إِلَٰهٌ وَاحِدٌ ۚ وَإِن لَّمْ يَنتَهُوا عَمَّا يَقُولُونَ لَيَمَسَّنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا مِنْهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ(73)

 Won kuku ti di keferi, awon t’o wi pe: “Dajudaju Allahu ni Iketa (awon) meta.” Ko si si olohun kan ti ijosin to si afi Olohun, Okan soso. Ti won ko ba jawo nibi ohun ti won n wi, dajudaju iya eleta elero l’o maa je awon t’o di keferi ninu won

أَفَلَا يَتُوبُونَ إِلَى اللَّهِ وَيَسْتَغْفِرُونَهُ ۚ وَاللَّهُ غَفُورٌ رَّحِيمٌ(74)

 Nitori naa, se won ko nii ronu piwada sodo Allahu, ki won si toro aforijin lodo Re? Allahu si ni Alaforijin, Asake-orun

مَّا الْمَسِيحُ ابْنُ مَرْيَمَ إِلَّا رَسُولٌ قَدْ خَلَتْ مِن قَبْلِهِ الرُّسُلُ وَأُمُّهُ صِدِّيقَةٌ ۖ كَانَا يَأْكُلَانِ الطَّعَامَ ۗ انظُرْ كَيْفَ نُبَيِّنُ لَهُمُ الْآيَاتِ ثُمَّ انظُرْ أَنَّىٰ يُؤْفَكُونَ(75)

 Ki ni Mosih bi ko se Ojise kan. Awon Ojise si ti lo siwaju re. Olododo si ni iya re. Awon mejeeji maa n je ounje. Wo bi A se n salaye awon ayah naa. Leyin naa, wo bi won se n seri won kuro nibi ododo

قُلْ أَتَعْبُدُونَ مِن دُونِ اللَّهِ مَا لَا يَمْلِكُ لَكُمْ ضَرًّا وَلَا نَفْعًا ۚ وَاللَّهُ هُوَ السَّمِيعُ الْعَلِيمُ(76)

 So pe: “Se e n josin fun leyin Allahu ohun ti ko ni ikapa inira ati anfaani kan fun yin? Allahu, Oun si ni Olugbo, Onimo.”

قُلْ يَا أَهْلَ الْكِتَابِ لَا تَغْلُوا فِي دِينِكُمْ غَيْرَ الْحَقِّ وَلَا تَتَّبِعُوا أَهْوَاءَ قَوْمٍ قَدْ ضَلُّوا مِن قَبْلُ وَأَضَلُّوا كَثِيرًا وَضَلُّوا عَن سَوَاءِ السَّبِيلِ(77)

 So pe: "Eyin ahlul-kitab, e ma se tayo enu-ala ninu esin yin, ti ki i se (esin) ododo. E ma si se tele ife-inu ijo kan t’o ti sina siwaju (iyen, awon yehudi). Won si opolopo lona. Won si sina kuro ni oju ona taara

لُعِنَ الَّذِينَ كَفَرُوا مِن بَنِي إِسْرَائِيلَ عَلَىٰ لِسَانِ دَاوُودَ وَعِيسَى ابْنِ مَرْيَمَ ۚ ذَٰلِكَ بِمَا عَصَوا وَّكَانُوا يَعْتَدُونَ(78)

 A sebi le awon t’o sai gbagbo ninu awon omo ’Isro’il lori ahon (Anabi) Dawud ati ‘Isa omo Moryam. Iyen nitori pe, won yapa (ase Allahu), won si n tayo enu-ala

كَانُوا لَا يَتَنَاهَوْنَ عَن مُّنكَرٍ فَعَلُوهُ ۚ لَبِئْسَ مَا كَانُوا يَفْعَلُونَ(79)

 Won ki i ko iwa ibaje ti won n se nise laaarin ara won. Ohun ti won n se nise si buru

تَرَىٰ كَثِيرًا مِّنْهُمْ يَتَوَلَّوْنَ الَّذِينَ كَفَرُوا ۚ لَبِئْسَ مَا قَدَّمَتْ لَهُمْ أَنفُسُهُمْ أَن سَخِطَ اللَّهُ عَلَيْهِمْ وَفِي الْعَذَابِ هُمْ خَالِدُونَ(80)

 O maa ri opolopo ninu won t’o n sore awon t’o sai gbagbo. Ohun ti emi won ti siwaju fun won si buru to bee ge ti Allahu fi binu si won. Olusegbere si ni won ninu Iya

وَلَوْ كَانُوا يُؤْمِنُونَ بِاللَّهِ وَالنَّبِيِّ وَمَا أُنزِلَ إِلَيْهِ مَا اتَّخَذُوهُمْ أَوْلِيَاءَ وَلَٰكِنَّ كَثِيرًا مِّنْهُمْ فَاسِقُونَ(81)

 Ti o ba je pe won gbagbo ninu Allahu ati Anabi (sollalahu alayhi wa sallam), ati ohun ti A sokale fun un, won ko nii mu won ni ore ayo, sugbon opolopo ninu won ni obileje

۞ لَتَجِدَنَّ أَشَدَّ النَّاسِ عَدَاوَةً لِّلَّذِينَ آمَنُوا الْيَهُودَ وَالَّذِينَ أَشْرَكُوا ۖ وَلَتَجِدَنَّ أَقْرَبَهُم مَّوَدَّةً لِّلَّذِينَ آمَنُوا الَّذِينَ قَالُوا إِنَّا نَصَارَىٰ ۚ ذَٰلِكَ بِأَنَّ مِنْهُمْ قِسِّيسِينَ وَرُهْبَانًا وَأَنَّهُمْ لَا يَسْتَكْبِرُونَ(82)

 Dajudaju o maa ri i pe awon eniyan ti ota won le julo si awon t’o gbagbo ni ododo ni awon yehudi ati awon osebo. Dajudaju o si maa ri i pe awon eniyan t’o sunmo awon t’o gbagbo ni ododo julo ni ife ni awon t’o wi pe: “Dajudaju nasara ni awa.” Iyen nitori pe awon alufaa ati olufokansin n be laaarin won. Ati pe dajudaju won ko nii segberaga (si ododo)

وَإِذَا سَمِعُوا مَا أُنزِلَ إِلَى الرَّسُولِ تَرَىٰ أَعْيُنَهُمْ تَفِيضُ مِنَ الدَّمْعِ مِمَّا عَرَفُوا مِنَ الْحَقِّ ۖ يَقُولُونَ رَبَّنَا آمَنَّا فَاكْتُبْنَا مَعَ الشَّاهِدِينَ(83)

 Nigba ti won ba gbo ohun ti A sokale fun Ojise naa, o maa ri eyinju won ti o maa damije nitori ohun ti won ti mo ninu ododo. Won a si so pe: "Oluwa wa, a gbagbo ni ododo, ko wa mo ara awon olujerii (ododo)

وَمَا لَنَا لَا نُؤْمِنُ بِاللَّهِ وَمَا جَاءَنَا مِنَ الْحَقِّ وَنَطْمَعُ أَن يُدْخِلَنَا رَبُّنَا مَعَ الْقَوْمِ الصَّالِحِينَ(84)

 Ki ni o maa di wa lowo ti a o fi nii gbagbo ninu Allahu ati ohun ti o de ba wa ninu ododo (iyen, al-Ƙur’an), ti a si n jerankan pe ki Oluwa fi wa sinu awon eni-ire

فَأَثَابَهُمُ اللَّهُ بِمَا قَالُوا جَنَّاتٍ تَجْرِي مِن تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ خَالِدِينَ فِيهَا ۚ وَذَٰلِكَ جَزَاءُ الْمُحْسِنِينَ(85)

 Nitori naa, nitori ohun ti won so, Allahu san won ni esan pelu awon Ogba Idera, ti awon odo n san ni isale re. Olusegbere ni won ninu re. Iyen si ni esan fun awon oluse-rere

وَالَّذِينَ كَفَرُوا وَكَذَّبُوا بِآيَاتِنَا أُولَٰئِكَ أَصْحَابُ الْجَحِيمِ(86)

 Awon t’o si sai gbagbo, ti won pe awon ayah Wa niro, awon wonyen ni ero inu ina Jehim

يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا تُحَرِّمُوا طَيِّبَاتِ مَا أَحَلَّ اللَّهُ لَكُمْ وَلَا تَعْتَدُوا ۚ إِنَّ اللَّهَ لَا يُحِبُّ الْمُعْتَدِينَ(87)

 Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se so awon nnkan daadaa ti Allahu se ni eto fun yin di eewo. E si ma se tayo enu-ala. Dajudaju Allahu ko feran awon olutayo enu-ala

وَكُلُوا مِمَّا رَزَقَكُمُ اللَّهُ حَلَالًا طَيِّبًا ۚ وَاتَّقُوا اللَّهَ الَّذِي أَنتُم بِهِ مُؤْمِنُونَ(88)

 E je nnkan eto t’o dara ninu ohun ti Allahu se ni arisiki fun yin. Ati pe e beru Allahu, Eni ti eyin gbagbo ninu Re

لَا يُؤَاخِذُكُمُ اللَّهُ بِاللَّغْوِ فِي أَيْمَانِكُمْ وَلَٰكِن يُؤَاخِذُكُم بِمَا عَقَّدتُّمُ الْأَيْمَانَ ۖ فَكَفَّارَتُهُ إِطْعَامُ عَشَرَةِ مَسَاكِينَ مِنْ أَوْسَطِ مَا تُطْعِمُونَ أَهْلِيكُمْ أَوْ كِسْوَتُهُمْ أَوْ تَحْرِيرُ رَقَبَةٍ ۖ فَمَن لَّمْ يَجِدْ فَصِيَامُ ثَلَاثَةِ أَيَّامٍ ۚ ذَٰلِكَ كَفَّارَةُ أَيْمَانِكُمْ إِذَا حَلَفْتُمْ ۚ وَاحْفَظُوا أَيْمَانَكُمْ ۚ كَذَٰلِكَ يُبَيِّنُ اللَّهُ لَكُمْ آيَاتِهِ لَعَلَّكُمْ تَشْكُرُونَ(89)

 Allahu ko nii fi ibura ti o bo lenu yin bi yin, sugbon O maa fi awon ibura ti e finnufindo mu wa bi yin. Nitori naa, itanran re ni bibo talika mewaa pelu ounje ti o wa ni iwontun-wonsi ti e n fi bo ara ile yin, tabi ki e raso fun won, tabi ki e tu eru onigbagbo ododo kan sile loko eru. Enikeni ti ko ba ri (eyi se), o maa gba aawe ojo meta. Iyen ni itanran ibura yin nigba ti e ba bura. E so ibura yin. Bayen ni Allahu se n salaye awon ayah Re fun yin, nitori ki e le dupe

يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا إِنَّمَا الْخَمْرُ وَالْمَيْسِرُ وَالْأَنصَابُ وَالْأَزْلَامُ رِجْسٌ مِّنْ عَمَلِ الشَّيْطَانِ فَاجْتَنِبُوهُ لَعَلَّكُمْ تُفْلِحُونَ(90)

 Eyin ti e gbagbo ni ododo, dajudaju oti, tete, awon orisa ati ise yiyewo, egbin ninu ise Esu ni. Nitori naa, e jinna si i nitori ki e le jere

إِنَّمَا يُرِيدُ الشَّيْطَانُ أَن يُوقِعَ بَيْنَكُمُ الْعَدَاوَةَ وَالْبَغْضَاءَ فِي الْخَمْرِ وَالْمَيْسِرِ وَيَصُدَّكُمْ عَن ذِكْرِ اللَّهِ وَعَنِ الصَّلَاةِ ۖ فَهَلْ أَنتُم مُّنتَهُونَ(91)

 Ohun ti Esu n fe ni pe o maa da ota ati ikorira sile laaarin yin nibi oti ati tete. O si fe se yin lori kuro nibi iranti Allahu ati nibi irun kiki. Se eyin ko nii jawo (nibi ise Esu) ni

وَأَطِيعُوا اللَّهَ وَأَطِيعُوا الرَّسُولَ وَاحْذَرُوا ۚ فَإِن تَوَلَّيْتُمْ فَاعْلَمُوا أَنَّمَا عَلَىٰ رَسُولِنَا الْبَلَاغُ الْمُبِينُ(92)

 E tele ti Allahu, e tele ti Ojise. Ki e si sora. Nitori naa, ti e ba gbunri, ki e mo pe ise-jije ponnbele lojuse awon Ojise Wa

لَيْسَ عَلَى الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ جُنَاحٌ فِيمَا طَعِمُوا إِذَا مَا اتَّقَوا وَّآمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ ثُمَّ اتَّقَوا وَّآمَنُوا ثُمَّ اتَّقَوا وَّأَحْسَنُوا ۗ وَاللَّهُ يُحِبُّ الْمُحْسِنِينَ(93)

 Ko si ibawi fun awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si sise rere nipa ohun ti won je (ninu ounje siwaju ofin) nigba ti won ba ti beru Allahu, ti won si gbagbo ni ododo, ti won tun sise rere, leyin naa, ti won beru Allahu, ti won si gbagbo ni ododo, leyin naa, ti won beru Allahu, ti won tun sise rere. Allahu si feran awon oluse-rere

يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَيَبْلُوَنَّكُمُ اللَّهُ بِشَيْءٍ مِّنَ الصَّيْدِ تَنَالُهُ أَيْدِيكُمْ وَرِمَاحُكُمْ لِيَعْلَمَ اللَّهُ مَن يَخَافُهُ بِالْغَيْبِ ۚ فَمَنِ اعْتَدَىٰ بَعْدَ ذَٰلِكَ فَلَهُ عَذَابٌ أَلِيمٌ(94)

 Eyin ti e gbagbo ni ododo, dajudaju Allahu yoo fi kini kan dan yin wo nibi eran-igbe ti owo yin ati oko yin ba (ninu aso hurumi) nitori ki Allahu le safi han eni t’o n paya Re ni ikoko. Enikeni ti o ba tayo enu-ala leyin iyen, iya eleta-elero n be fun un

يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا تَقْتُلُوا الصَّيْدَ وَأَنتُمْ حُرُمٌ ۚ وَمَن قَتَلَهُ مِنكُم مُّتَعَمِّدًا فَجَزَاءٌ مِّثْلُ مَا قَتَلَ مِنَ النَّعَمِ يَحْكُمُ بِهِ ذَوَا عَدْلٍ مِّنكُمْ هَدْيًا بَالِغَ الْكَعْبَةِ أَوْ كَفَّارَةٌ طَعَامُ مَسَاكِينَ أَوْ عَدْلُ ذَٰلِكَ صِيَامًا لِّيَذُوقَ وَبَالَ أَمْرِهِ ۗ عَفَا اللَّهُ عَمَّا سَلَفَ ۚ وَمَنْ عَادَ فَيَنتَقِمُ اللَّهُ مِنْهُ ۗ وَاللَّهُ عَزِيزٌ ذُو انتِقَامٍ(95)

 Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se pa eran-igbe nigba ti e ba wa ninu aso hurumi. Enikeni ti o ba si moomo pa a ninu yin, itanran re ni (pe o maa pa) iru ohun ti o pa ninu eran osin. Awon onideede meji ninu yin l’o si maa se idajo (osuwon) re (fun un. O je) eran itanran ti o maa mu de Kaaba. Tabi ki o fi bibo awon talika se itanran. Tabi aaro iyen ni aawe, nitori ki o le to bi oran re se lagbara to wo. Allahu ti moju kuro nibi ohun t’o re koja. Enikeni ti o ba tun pada (moomo dode ninu aso hurumi), Allahu yoo gbesan lara re re. Allahu si ni Alagbara, Olugbesan

أُحِلَّ لَكُمْ صَيْدُ الْبَحْرِ وَطَعَامُهُ مَتَاعًا لَّكُمْ وَلِلسَّيَّارَةِ ۖ وَحُرِّمَ عَلَيْكُمْ صَيْدُ الْبَرِّ مَا دُمْتُمْ حُرُمًا ۗ وَاتَّقُوا اللَّهَ الَّذِي إِلَيْهِ تُحْشَرُونَ(96)

 Won se odo dide ati jije ounje (okunbete) inu re ni eto fun yin. Nnkan igbadun ni fun eyin ati awon onirin-ajo. Won si se igbe dide ni eewo fun yin nigba ti e ba wa ninu aso hurumi. E beru Allahu, Eni ti won maa ko yin jo si odo Re

۞ جَعَلَ اللَّهُ الْكَعْبَةَ الْبَيْتَ الْحَرَامَ قِيَامًا لِّلنَّاسِ وَالشَّهْرَ الْحَرَامَ وَالْهَدْيَ وَالْقَلَائِدَ ۚ ذَٰلِكَ لِتَعْلَمُوا أَنَّ اللَّهَ يَعْلَمُ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ وَأَنَّ اللَّهَ بِكُلِّ شَيْءٍ عَلِيمٌ(97)

 Allahu se Kaaba, Ile Haram, ni aye aabo fun awon eniyan. (Nnkan aabo naa ni) awon osu owo, awon eran ore (ti won ko sami si lorun) ati (awon eran ore) ti won sami si lorun. Iyen ri bee ki e le mo pe dajudaju Allahu mo ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile. Ati pe dajudaju Allahu ni Onimo nipa gbogbo nnkan

اعْلَمُوا أَنَّ اللَّهَ شَدِيدُ الْعِقَابِ وَأَنَّ اللَّهَ غَفُورٌ رَّحِيمٌ(98)

 E mo pe dajudaju Allahu le nibi iya. Ati pe dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun

مَّا عَلَى الرَّسُولِ إِلَّا الْبَلَاغُ ۗ وَاللَّهُ يَعْلَمُ مَا تُبْدُونَ وَمَا تَكْتُمُونَ(99)

 Ko si ojuse kan fun Ojise naa bi ko se ise-jije. Allahu si mo ohun ti e n safi han re ati ohun ti e n fi pamo

قُل لَّا يَسْتَوِي الْخَبِيثُ وَالطَّيِّبُ وَلَوْ أَعْجَبَكَ كَثْرَةُ الْخَبِيثِ ۚ فَاتَّقُوا اللَّهَ يَا أُولِي الْأَلْبَابِ لَعَلَّكُمْ تُفْلِحُونَ(100)

 So pe: “Ohun buruku ati ohun daadaa ko dogba, pupo ohun buruku ibaa jo o loju”. Nitori naa, e beru Allahu, eyin onilaakaye, nitori ki e le jere.”

يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا تَسْأَلُوا عَنْ أَشْيَاءَ إِن تُبْدَ لَكُمْ تَسُؤْكُمْ وَإِن تَسْأَلُوا عَنْهَا حِينَ يُنَزَّلُ الْقُرْآنُ تُبْدَ لَكُمْ عَفَا اللَّهُ عَنْهَا ۗ وَاللَّهُ غَفُورٌ حَلِيمٌ(101)

 Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se maa beere nipa awon nnkan sa. Ti A ba fi han yin, o maa ko ipalara ba yin. Ti e ba si beere nipa (awon nnkan t’o ye lati beere nipa esin) nigba ti A n so al-Ƙur’an kale lowo, A maa fi han yin. Allahu ti se amojukuro nipa re. Allahu ni Alaforijin, Alafarada

قَدْ سَأَلَهَا قَوْمٌ مِّن قَبْلِكُمْ ثُمَّ أَصْبَحُوا بِهَا كَافِرِينَ(102)

 Ijo kan kuku ti beere re siwaju yin. Leyin naa, won si di alaigbagbo nipase re

مَا جَعَلَ اللَّهُ مِن بَحِيرَةٍ وَلَا سَائِبَةٍ وَلَا وَصِيلَةٍ وَلَا حَامٍ ۙ وَلَٰكِنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا يَفْتَرُونَ عَلَى اللَّهِ الْكَذِبَ ۖ وَأَكْثَرُهُمْ لَا يَعْقِلُونَ(103)

 Allahu ko fi eran bahirah, eran sa’ibah, eran wasilah ati eran ham lole. Sugbon awon t’o sai gbagbo n da adapa iro mo Allahu ni. Opolopo won ni ko se laakaye

وَإِذَا قِيلَ لَهُمْ تَعَالَوْا إِلَىٰ مَا أَنزَلَ اللَّهُ وَإِلَى الرَّسُولِ قَالُوا حَسْبُنَا مَا وَجَدْنَا عَلَيْهِ آبَاءَنَا ۚ أَوَلَوْ كَانَ آبَاؤُهُمْ لَا يَعْلَمُونَ شَيْئًا وَلَا يَهْتَدُونَ(104)

 Nigba ti won ba so fun won pe: “E maa bo wa sibi ohun ti Allahu sokale. (E maa bo wa) si odo Ojise naa.” Won a wi pe: “Ohun ti a ba awon baba wa lori re ti to wa.” Se pelu bi o se je pe awon baba won ko nimo kan kan, ti won ko si mona

يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا عَلَيْكُمْ أَنفُسَكُمْ ۖ لَا يَضُرُّكُم مَّن ضَلَّ إِذَا اهْتَدَيْتُمْ ۚ إِلَى اللَّهِ مَرْجِعُكُمْ جَمِيعًا فَيُنَبِّئُكُم بِمَا كُنتُمْ تَعْمَلُونَ(105)

 Eyin ti e gbagbo ni ododo, emi ara yin dowo yin. Eni ti o ti sina ko le ko inira ba yin nigba ti e ba ti mona. Odo Allahu ni ibupadasi gbogbo yin patapata. Nigba naa, O maa fun yin ni iro ohun ti e n se nise

يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا شَهَادَةُ بَيْنِكُمْ إِذَا حَضَرَ أَحَدَكُمُ الْمَوْتُ حِينَ الْوَصِيَّةِ اثْنَانِ ذَوَا عَدْلٍ مِّنكُمْ أَوْ آخَرَانِ مِنْ غَيْرِكُمْ إِنْ أَنتُمْ ضَرَبْتُمْ فِي الْأَرْضِ فَأَصَابَتْكُم مُّصِيبَةُ الْمَوْتِ ۚ تَحْبِسُونَهُمَا مِن بَعْدِ الصَّلَاةِ فَيُقْسِمَانِ بِاللَّهِ إِنِ ارْتَبْتُمْ لَا نَشْتَرِي بِهِ ثَمَنًا وَلَوْ كَانَ ذَا قُرْبَىٰ ۙ وَلَا نَكْتُمُ شَهَادَةَ اللَّهِ إِنَّا إِذًا لَّمِنَ الْآثِمِينَ(106)

 Eyin ti e gbagbo ni ododo, (e wa) eri jije laaarin yin nigba ti (ipokaka) iku ba de ba eni kan ninu yin ti o fe so asoole. (E wa) onideede meji ninu yin. Tabi awon meji miiran yato si yin ti eyin ba wa lori irin-ajo ti ajalu iku ba fe sele si yin. E da awon mejeeji duro leyin irun, ki won fi Allahu bura, ti e ba seyemeji (si ododo won, ki won si so pe:) "A o nii ta ibura wa ni iye kan kan, koda ko je ebi. A o si nii fi eri jije ti Allahu (pa lase) pamo. (Bi bee ko) nigba naa, dajudaju awa wa ninu awon elese

فَإِنْ عُثِرَ عَلَىٰ أَنَّهُمَا اسْتَحَقَّا إِثْمًا فَآخَرَانِ يَقُومَانِ مَقَامَهُمَا مِنَ الَّذِينَ اسْتَحَقَّ عَلَيْهِمُ الْأَوْلَيَانِ فَيُقْسِمَانِ بِاللَّهِ لَشَهَادَتُنَا أَحَقُّ مِن شَهَادَتِهِمَا وَمَا اعْتَدَيْنَا إِنَّا إِذًا لَّمِنَ الظَّالِمِينَ(107)

 Ti won ba si ri i pe awon mejeeji da ese (nipa yiyi asoole pada), ki awon meji miiran ninu awon ti awon mejeeji akoko se abosi si (iyen, ebi oku) ropo won. Ki awon naa si fi Allahu bura pe: "Dajudaju eri jije tiwa je ododo ju eri jije ti awon mejeeji (akoko). A o si nii tayo enu-ala. (Bi bee ko) nigba naa, dajudaju a ti wa ninu awon alabosi

ذَٰلِكَ أَدْنَىٰ أَن يَأْتُوا بِالشَّهَادَةِ عَلَىٰ وَجْهِهَا أَوْ يَخَافُوا أَن تُرَدَّ أَيْمَانٌ بَعْدَ أَيْمَانِهِمْ ۗ وَاتَّقُوا اللَّهَ وَاسْمَعُوا ۗ وَاللَّهُ لَا يَهْدِي الْقَوْمَ الْفَاسِقِينَ(108)

 Iyen sunmo julo lati mu eri jije wa ni oju-ponna re tabi lati (le la ninu) ipaya pe won yoo da ibura kan nu leyin ibura tiwon. E beru Allahu, ki e si gboran. Allahu ki i fi ona mo ijo obileje

۞ يَوْمَ يَجْمَعُ اللَّهُ الرُّسُلَ فَيَقُولُ مَاذَا أُجِبْتُمْ ۖ قَالُوا لَا عِلْمَ لَنَا ۖ إِنَّكَ أَنتَ عَلَّامُ الْغُيُوبِ(109)

 Ni ojo ti Allahu yoo ko awon Ojise jo, O si maa so pe: “Ki ni esi ti won fun yin?” Won a so pe: “Ko si imo kan fun wa (nipa re). Dajudaju Iwo, Iwo ni Onimo nipa awon ikoko.”

إِذْ قَالَ اللَّهُ يَا عِيسَى ابْنَ مَرْيَمَ اذْكُرْ نِعْمَتِي عَلَيْكَ وَعَلَىٰ وَالِدَتِكَ إِذْ أَيَّدتُّكَ بِرُوحِ الْقُدُسِ تُكَلِّمُ النَّاسَ فِي الْمَهْدِ وَكَهْلًا ۖ وَإِذْ عَلَّمْتُكَ الْكِتَابَ وَالْحِكْمَةَ وَالتَّوْرَاةَ وَالْإِنجِيلَ ۖ وَإِذْ تَخْلُقُ مِنَ الطِّينِ كَهَيْئَةِ الطَّيْرِ بِإِذْنِي فَتَنفُخُ فِيهَا فَتَكُونُ طَيْرًا بِإِذْنِي ۖ وَتُبْرِئُ الْأَكْمَهَ وَالْأَبْرَصَ بِإِذْنِي ۖ وَإِذْ تُخْرِجُ الْمَوْتَىٰ بِإِذْنِي ۖ وَإِذْ كَفَفْتُ بَنِي إِسْرَائِيلَ عَنكَ إِذْ جِئْتَهُم بِالْبَيِّنَاتِ فَقَالَ الَّذِينَ كَفَرُوا مِنْهُمْ إِنْ هَٰذَا إِلَّا سِحْرٌ مُّبِينٌ(110)

 (Ranti) nigba ti Allahu so pe: “‘Isa omo Moryam, ranti idera Mi lori re ati lori iya re, nigba ti Mo fi emi Mimo (molaika Jibril) ran o lowo, ti o si n ba awon eniyan soro lori ite ni oponlo ati nigba ti o dagba. (Ranti) nigba ti Mo fun o ni imo Tira, ijinle oye, at-Taorah ati al-’Injil. (Ranti) nigba ti o n mo nnkan lati inu amo bi irisi eye, ti o n fe ategun sinu re, ti o n di eye pelu iyonda Mi. O n wo afoju ati adete san pelu iyonda. (Ranti) nigba ti o n mu awon oku jade (ni alaaye lati inu saree) pelu iyonda Mi. (Ranti) nigba ti Mo ko awon omo ’Isro’il lowo ro, nigba ti o mu awon eri t’o yanju wa ba won. Awon t’o sai gbagbo ninu won si wi pe: “Ki ni eyi bi ko se idan ponnbele.”

وَإِذْ أَوْحَيْتُ إِلَى الْحَوَارِيِّينَ أَنْ آمِنُوا بِي وَبِرَسُولِي قَالُوا آمَنَّا وَاشْهَدْ بِأَنَّنَا مُسْلِمُونَ(111)

 (Ranti) nigba ti Mo fi mo awon omoleyin re ninu okan won pe ki won gbagbo ninu Emi ati Ojise Mi. Won so pe: “A gbagbo. Ki o si jerii pe dajudaju musulumi ni wa.”

إِذْ قَالَ الْحَوَارِيُّونَ يَا عِيسَى ابْنَ مَرْيَمَ هَلْ يَسْتَطِيعُ رَبُّكَ أَن يُنَزِّلَ عَلَيْنَا مَائِدَةً مِّنَ السَّمَاءِ ۖ قَالَ اتَّقُوا اللَّهَ إِن كُنتُم مُّؤْمِنِينَ(112)

 (Ranti) nigba ti awon omoleyin re so pe: “‘Isa omo Moryam, nje Oluwa re le so opon ounje kan kale lati sanmo?” O so pe: "E beru Allahu ti e ba je onigbagbo ododo

قَالُوا نُرِيدُ أَن نَّأْكُلَ مِنْهَا وَتَطْمَئِنَّ قُلُوبُنَا وَنَعْلَمَ أَن قَدْ صَدَقْتَنَا وَنَكُونَ عَلَيْهَا مِنَ الشَّاهِدِينَ(113)

 Won so pe: “A fe je ninu re, a si fe ki okan wa bale, ki a si le mo pe o ti so ododo fun wa. A si maa wa ninu awon olujerii.”

قَالَ عِيسَى ابْنُ مَرْيَمَ اللَّهُمَّ رَبَّنَا أَنزِلْ عَلَيْنَا مَائِدَةً مِّنَ السَّمَاءِ تَكُونُ لَنَا عِيدًا لِّأَوَّلِنَا وَآخِرِنَا وَآيَةً مِّنكَ ۖ وَارْزُقْنَا وَأَنتَ خَيْرُ الرَّازِقِينَ(114)

 ‘Isa omo Moryam so pe: "Allahu, Oluwa wa, so opon ounje kan kale fun wa lati inu sanmo, ki o je odun fun eni akoko wa ati eni ikeyin wa.1 Ki o si je ami kan lati odo Re. Pese fun wa, Iwo si loore julo ninu awon olupese

قَالَ اللَّهُ إِنِّي مُنَزِّلُهَا عَلَيْكُمْ ۖ فَمَن يَكْفُرْ بَعْدُ مِنكُمْ فَإِنِّي أُعَذِّبُهُ عَذَابًا لَّا أُعَذِّبُهُ أَحَدًا مِّنَ الْعَالَمِينَ(115)

 Allahu so pe: “Dajudaju Emi yoo so o kale fun yin. Sugbon enikeni ti o ba sai gbagbo leyin naa ninu yin, dajudaju Mo maa je e niya kan ti Mi o fi je eni kan ri ninu gbogbo eda.”

وَإِذْ قَالَ اللَّهُ يَا عِيسَى ابْنَ مَرْيَمَ أَأَنتَ قُلْتَ لِلنَّاسِ اتَّخِذُونِي وَأُمِّيَ إِلَٰهَيْنِ مِن دُونِ اللَّهِ ۖ قَالَ سُبْحَانَكَ مَا يَكُونُ لِي أَنْ أَقُولَ مَا لَيْسَ لِي بِحَقٍّ ۚ إِن كُنتُ قُلْتُهُ فَقَدْ عَلِمْتَهُ ۚ تَعْلَمُ مَا فِي نَفْسِي وَلَا أَعْلَمُ مَا فِي نَفْسِكَ ۚ إِنَّكَ أَنتَ عَلَّامُ الْغُيُوبِ(116)

 (Ranti) nigba ti Allahu so pe: “‘Isa omo Moryam, se iwo l’o so fun awon eniyan pe: "E mu emi ati iya mi ni olohun meji ti e oo maa josin fun leyin Allahu?" O so pe: "Mimo ni fun O, ko to fun mi lati so ohun ti emi ko letoo (si lati so). Ti mo ba so bee, O kuku ti mo. O mo ohun ti n be ninu emi mi. Ng o si mo ohun ti n be ninu emi Re. Dajudaju Iwo ni Onimo nipa awon ikoko

مَا قُلْتُ لَهُمْ إِلَّا مَا أَمَرْتَنِي بِهِ أَنِ اعْبُدُوا اللَّهَ رَبِّي وَرَبَّكُمْ ۚ وَكُنتُ عَلَيْهِمْ شَهِيدًا مَّا دُمْتُ فِيهِمْ ۖ فَلَمَّا تَوَفَّيْتَنِي كُنتَ أَنتَ الرَّقِيبَ عَلَيْهِمْ ۚ وَأَنتَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ شَهِيدٌ(117)

 Emi ko so ohun kan fun won bi ko se ohun ti O pa mi lase re pe: "E josin fun Allahu, Oluwa mi ati Oluwa yin." Mo si je elerii lori won niwon igba ti mo n be laaarin won. Sugbon nigba ti O gba mi kuro lowo won, Iwo ni Oluso lori won. Iwo si ni Arinu-rode gbogbo nnkan

إِن تُعَذِّبْهُمْ فَإِنَّهُمْ عِبَادُكَ ۖ وَإِن تَغْفِرْ لَهُمْ فَإِنَّكَ أَنتَ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ(118)

 Ti O ba je won niya, dajudaju eru Re ni won. Ti O ba si fori jin won, dajudaju Iwo, Iwo ni Alagbara, Ologbon

قَالَ اللَّهُ هَٰذَا يَوْمُ يَنفَعُ الصَّادِقِينَ صِدْقُهُمْ ۚ لَهُمْ جَنَّاتٌ تَجْرِي مِن تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ خَالِدِينَ فِيهَا أَبَدًا ۚ رَّضِيَ اللَّهُ عَنْهُمْ وَرَضُوا عَنْهُ ۚ ذَٰلِكَ الْفَوْزُ الْعَظِيمُ(119)

 Allahu so pe: “Eyi ni ojo ti ododo awon olododo yoo se won ni anfaani. Awon Ogba Idera kan ti awon odo n san ni isale re n be fun won. Olusegbere ni won ninu re titi laelae. Allahu yonu si won. Won si yonu si (ohun ti Allahu fun won). Iyen ni erenje nla

لِلَّهِ مُلْكُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَمَا فِيهِنَّ ۚ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ(120)

 Ti Allahu ni ijoba awon sanmo ati ile ati ohunkohun t’o wa ninu won. Oun si ni Alagbara lori gbogbo nnkan


Plus de sourates en Yoruba :


Al-Baqarah Al-'Imran An-Nisa'
Al-Ma'idah Yusuf Ibrahim
Al-Hijr Al-Kahf Maryam
Al-Hajj Al-Qasas Al-'Ankabut
As-Sajdah Ya Sin Ad-Dukhan
Al-Fath Al-Hujurat Qaf
An-Najm Ar-Rahman Al-Waqi'ah
Al-Hashr Al-Mulk Al-Haqqah
Al-Inshiqaq Al-A'la Al-Ghashiyah

Téléchargez la sourate avec la voix des récitants du Coran les plus célèbres :

Téléchargez le fichier mp3 de la sourate Al-Maidah : choisissez le récitateur pour écouter et télécharger la sourate Al-Maidah complète en haute qualité.


surah Al-Maidah Ahmed El Agamy
Ahmed Al Ajmy
surah Al-Maidah Bandar Balila
Bandar Balila
surah Al-Maidah Khalid Al Jalil
Khalid Al Jalil
surah Al-Maidah Saad Al Ghamdi
Saad Al Ghamdi
surah Al-Maidah Saud Al Shuraim
Saud Al Shuraim
surah Al-Maidah Abdul Basit Abdul Samad
Abdul Basit
surah Al-Maidah Abdul Rashid Sufi
Abdul Rashid Sufi
surah Al-Maidah Abdullah Basfar
Abdullah Basfar
surah Al-Maidah Abdullah Awwad Al Juhani
Abdullah Al Juhani
surah Al-Maidah Fares Abbad
Fares Abbad
surah Al-Maidah Maher Al Muaiqly
Maher Al Muaiqly
surah Al-Maidah Muhammad Siddiq Al Minshawi
Al Minshawi
surah Al-Maidah Al Hosary
Al Hosary
surah Al-Maidah Al-afasi
Mishari Al-afasi
surah Al-Maidah Yasser Al Dosari
Yasser Al Dosari


Sunday, December 22, 2024

Donnez-nous une invitation valide