Maide suresi çevirisi Yoruba
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e mu awon adehun se. Won se awon eran-osin ni eto fun yin afi eyi ti won ba n ka fun yin (ni eewo), lai nii so idode eranko di eto nigba ti e ba wa ninu aso hurumi. Dajudaju Allahu n se idajo ohun ti O ba fe |
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se ru ofin awon nnkan arisami ti Allahu gbe kale fun esin Re. E ma se so osu owo di eto (fun ogun esin), E ma se idiwo fun awon eran ore (ti won ko sami si lorun) ati (awon eran ore) ti won sami si lorun. E ma se idiwo fun awon t’o n gbero lati lo si Ile Haram, ti won n wa oore ajulo ati iyonu lati odo Oluwa won. Ti e ba si ti tura sile ninu aso hurumi, nigba naa e (le) dode (eranko). E ma se je ki ikorira awon eniyan kan ti yin lati tayo enu-ala nitori pe won se yin lori kuro ni Mosalasi Haram. E ran ara yin lowo lori ise rere ati iberu Allahu. E ma se ran ara yin lowo lori (iwa) ese ati itayo enu-ala. E beru Allahu. Dajudaju Allahu le (nibi) iya |
A se e ni eewo fun yin eran okunbete, ati eje, ati eran elede, ati eyi ti won pa pelu oruko ti ki i se Allahu, ati eran ti won fun lorun pa, ati eran ti won lu pa, ati eran ti o re lule ku, ati eran ti won kan pa ati eyi ti eranko abijawara je ku afi eyi ti e ba ri du (siwaju ki o to ku) ati eyi ti won pa sidii orisa. Eewo si ni fun yin lati yese wo. Iwonyi ni ibaje. Lonii ni awon t’o sai gbagbo soreti nu nipa esin yin. Nitori naa, e ma se paya won. E paya Mi. Mo pari esin yin fun yin lonii. Mo si se asepe idera Mi fun yin. Mo si yonu si ’Islam ni esin fun yin. Nitori naa, enikeni ti won ba ko sinu inira ebi (lati je eran eewo), yato si olufinnufindo-dese, dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun |
Won n bi o leere pe: "Ki ni Won se ni eto fun won?" So pe: “Won se awon nnkan daadaa ni eto fun yin ati (eran ti e pa nipase) eyi ti e ko ni eko (idode) ninu awon eranko ati eye ti n dode. E ko awon aja lekoo idode, ki e ko won ninu ohun ti Allahu fi mo yin. Nitori naa, e je ninu ohun ti won ba pa fun yin, ki e si se bismillah si i . E beru Allahu. Dajudaju Allahu ni Oluyara nibi isiro-ise |
Won se awon nnkan daadaa ni eto fun yin lonii. Ati ounje awon ti A fun ni tira, eto ni fun yin.1 Ounje tiyin naa, eto ni fun won. (Eto ni fun yin lati fe) awon olominira ninu awon onigbagbo ododo lobinrin ati awon olominira lobinrin ninu awon ti A fun ni tira siwaju yin, nigba ti e ba ti fun won ni sodaaki won; e fe won ni fife (bi ’Islam se ni ki e fe iyawo), lai nii ba won se sina (siwaju yigi) lai si nii yan won lale.2 Enikeni ti o ba lodi si igbagbo ododo, ise re ti baje. Ni Ojo Ikeyin, o si maa wa ninu awon eni ofo. orisa ibere ati idawole kan ti awon oyinbo aborisa n pe ni Janus ni won fi gbe osu ati odun January kale. Awon kristieni si tewo gba a lowo won. Musulumi yo si maa je musulumi lori gbigba oro Allahu gbo ni ododo. Ti iru musulumi yii ba tun wa ba awon kristieni da si odun January lai si siju wo awon ewu nla ti ko se e janiyan t’o tun ro mo igbeyawo. Dandan si ni fun wa lati lo ayah papo mora won ni ona ti ko fi nii ja si pe musulumi tele itumo oju-oro nikan ni iyapa si itumo oju oro miiran. Ni akoko na ninu surah al-Baƙorah |
Eyin ti e gbagbo ni ododo, nigba ti e ba fe kirun, e we oju yin ati owo yin titi de igunpa. E fi omi pa ori yin. E we ese yin titi de kokose mejeeji. Ti e ba ni jannaba lara, e we iwe imora. Ti e ba je alaisan, tabi e n be lori irin-ajo tabi eni kan ninu yin de lati ile igbonse, tabi e sunmo obinrin, ti e o ba ri omi, nigba naa ki e fi erupe mimo se tayamomu. E fi pa oju yin ati owo yin lara re. Allahu ko fe lati ko wahala ba yin, sugbon O fe lati fo yin mo. O si fe se asepe idera Re fun yin nitori ki e le dupe |
E ranti idera ti Allahu se fun yin ati adehun Re, eyi ti O ba yin se, nigba ti eyin so pe: “A gbo, a si tele e.” E beru Allahu. Dajudaju Allahu ni Onimo nipa ohun ti n be ninu igba-aya eda |
Eyin ti e gbagbo ni ododo, nitori ti Allahu e je oluduro sinsin lori ododo nigba ti e ba n jerii. E ma se je ki ikorira awon eniyan kan ti yin lati ma se deede. E se deede, ohun l’o sunmo iberu Allahu julo. Ki e si beru Allahu. Dajudaju Allahu ni Alamotan nipa ohun ti e n se nise |
وَعَدَ اللَّهُ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ ۙ لَهُم مَّغْفِرَةٌ وَأَجْرٌ عَظِيمٌ(9) Allahu se adehun fun awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si sise rere (pe) aforijin ati esan nla n be fun won |
وَالَّذِينَ كَفَرُوا وَكَذَّبُوا بِآيَاتِنَا أُولَٰئِكَ أَصْحَابُ الْجَحِيمِ(10) Awon t’o sai gbagbo, ti won si pe awon ayah Wa niro, awon wonyen ni ero inu ina Jehim |
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ranti idera ti Allahu se fun yin; nigba ti ijo kan gbero lati nawo ija si yin, (Allahu) si ko won lowo ro fun yin. E beru Allahu. Ati pe Allahu ni ki awon onigbagbo ododo gbarale |
Dajudaju Allahu gba adehun lowo awon omo ’Isro’il. A si gbe ijoye mejila dide ninu won. Allahu si so fun won pe: “Dajudaju Mo n be pelu yin, ti e ba n kirun, ti e ba n yo Zakah, ti e ba n gba awon Ojise Mi gbo, ti e ba n ran won lowo, ti e ba n ya Allahu ni dukia t’o dara. Dajudaju Mo maa pa awon asise yin re. Dajudaju Mo maa mu yin wo inu awon Ogba Idera kan, ti odo n san ni isale re. Amo enikeni ti o ba sai gbagbo leyin iyen ninu yin, o ti sina kuro loju ona.” |
Nitori yiye ti won funra won ye adehun won ni A fi sebi le won. A si mu okan won le koko (nitori pe) won n gbe awon oro kuro ni awon aye re, won si gbagbe ipin kan ninu oore ti A fi se iranti fun won. O o nii ye ri onijanba laaarin won afi die ninu won. Nitori naa, se amojukuro fun won, ki o si fori jin won. Dajudaju Allahu feran awon oluse-rere |
Ati pe lodo awon t’o wi pe: “Dajudaju nasara ni awa.”, A gba adehun lowo won, won si gbagbe ipin kan ninu oore ti A fi se iranti fun won. Nitori naa, A gbin ota ati ote saaarin won titi di Ojo Ajinde. Laipe Allahu maa fun won ni iro ohun ti won n se nise |
Eyin ahlul-kitab, dajudaju Ojise Wa ti wa ba yin. O n salaye opolopo ohun ti e fi pamo ninu tira fun yin. O si n samojukuro nibi opolopo. Imole ati Tira t’o yanju kuku ti de ba yin lati odo Allahu |
Allahu n fi (al-Ƙur’an) se imona fun enikeni ti o ba tele (awon nnkan) ti Allahu yonu si, awon ona alaafia. (Allahu) yo si mu won jade lati inu awon okunkun wa sinu imole pelu iyonda Re. O si maa to won si ona taara (’Islam) |
Won kuku ti di keferi, awon t’o wi pe: “Dajudaju Allahu ni Mosih omo Moryam.” So pe: “Ta si l’o ni ikapa kini kan lodo Allahu ti (Allahu) ba fe pa Mosih omo Moryam, ati iya re ati awon t’o n be lori ile aye run patapata?” Ti Allahu ni ijoba awon sanmo, ile ati ohunkohun ti n be laaarin awon mejeeji. (Allahu) n sedaa ohunkohun ti O ba fe. Allahu si ni Alagbara lori gbogbo nnkan |
Awon yehudi ati nasara wi pe: "Awa ni omo Allahu ati ololufe Re." So pe: “Ki ni idi ti O se n fi iya ese yin je yin nigba naa?” Rara (ko ri bi e se wi, amo) abara ni yin ninu awon ti O seda. O n saforijin fun eni ti O ba fe. O si n je eni ti O ba fe niya. Ti Allahu ni ijoba awon sanmo, ile ati ohunkohun ti n be laaarin awon mejeeji. Odo Re si ni abo eda |
Eyin ahlul-kitab, dajudaju Ojise Wa ti de ba yin, ti o n se alaye (oro) fun yin leyin asiko ti A ti da awon Ojise duro, nitori ki e ma baa wi pe: “Ko si oniroo idunnu tabi olukilo kan ti o de ba wa.” Nitori naa, dajudaju oniroo idunnu ati olukilo kan ti de ba yin. Allahu si ni Alagbara lori gbogbo nnkan |
Nigba ti (Anabi) Musa so fun ijo re pe: "Eyin ijo mi, e ranti idera ti Allahu se fun yin, nigba ti O fi awon Anabi saaarin yin, ti O se yin ni oba, ti O tun fun yin ni nnkan ti ko fun eni kan ri ni agbaye (lasiko tiyin) |
Eyin ijo mi, e wo ori ile mimo ti Allahu ko mo yin. E ma se pada seyin, nitori ki e ma baa pada di eni ofo |
Won wi pe: "Musa, dajudaju ijo ajeni-nipa wa ninu ilu naa. Dajudaju awa ko si nii wo inu re titi won yoo fi jade kuro ninu re. Ti won ba jade kuro ninu re, awa maa wo inu re nigba naa |
Awon okunrin meji kan ninu awon ti n paya (Allahu) - Allahu si ke awon mejeeji - won so pe: "E gba enu bode wo inu ilu to won. Ti e ba wo inu ilu to won, dajudaju e maa bori won. Allahu si ni ki e gbarale, ti e ba je onigbagbo ododo |
Won wi pe: "Iwo Musa, dajudaju awa ko nii wo inu ilu naa laelae niwon igba ti won ba si wa ninu re. Nitori naa, ki iwo ati Oluwa re lo. Ki eyin mejeeji ja won logun. Dajudaju ibi yii ni awa yoo jokoo si na |
O so pe: "Oluwa mi, dajudaju emi ko ni ikapa lori eni kan bi ko se (lori) ara mi ati arakunrin mi. Nitori naa, ya awa ati ijo obileje si otooto |
(Allahu) so pe: “Dajudaju o ti di eewo fun won (lati wo inu ilu naa) fun ogoji odun ti won yoo fi maa rin rin rin lori ile. Nitori naa, ma se banuje nitori ijo obileje.” |
Ka oro awon omo (Anabi) Adam mejeeji fun won pelu ododo. (Ranti) nigba ti awon mejeeji se itore ase (lati fi sunmo Allahu). Won gba ti okan ninu awon mejeeji, Won ko si gba ti ikeji. (Eni ti Won ko gba tire) wi pe: “Dajudaju emi yoo pa o.” (Ikeji) si so pe: "(Ore) tawon oluberu nikan ni Allahu maa gba |
Dajudaju ti o ba na owo re si mi lati pa mi, emi ko si nii na owo mi si o lati pa o, nitori pe emi n beru Allahu, Oluwa gbogbo eda |
Dajudaju emi fe ki o pada (si odo Allahu ni Ojo Ajinde) pelu ese (bi o se pa) mi ati ese tire nitori ki o le je okan ninu awon ero inu Ina. Iyen si ni esan awon alabosi |
فَطَوَّعَتْ لَهُ نَفْسُهُ قَتْلَ أَخِيهِ فَقَتَلَهُ فَأَصْبَحَ مِنَ الْخَاسِرِينَ(30) Emi re si gba fun un lati pa arakunrin re. O pa a. O si di okan ninu awon eni ofo |
Allahu si gbe eye kannakanna kan dide. O si n fi ese wa ile nitori ki o le fi bi o se maa bo oku arakunrin re mo inu ile han an. O wi pe: “Temi baje o! Mo kagara lati da bi iru eye kannakanna yii, ki ng si le bo oku arakunrin mi mole.” O si di ara awon alabaamo |
Nitori iyen, A si se e ni ofin fun awon omo ’Isro’il pe dajudaju enikeni ti o ba pa emi (eniyan) kan laije nitori pipa emi (eniyan) kan tabi sise ibaje kan lori ile, o da bi eni ti o pa gbogbo eniyan patapata. Enikeni ti o ba si mu emi (eniyan) semi, o da bi eni ti o mu gbogbo eniyan semi patapata. Awon Ojise Wa si ti wa ba won pelu awon eri t’o yanju. Leyin naa, dajudaju opolopo ninu won leyin iyen ni alakoyo lori ile |
Esan awon t’o n gbogun ti Allahu ati Ojise Re, ti won si n se ibaje lori ile ni pe, ki e pa won tabi ki e kan won mo igi agbelebuu tabi ki e ge owo won ati ese won ni ipasipayo tabi ki e le won kuro ninu ilu. Iyen ni iyepere fun won nile aye. Iya nla si n be fun won ni orun |
Ayafi awon t’o ronu piwada siwaju ki e to lagbara lori won. Nitori naa, e mo pe dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun |
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e beru Allahu, ki e si wa ategun si odo Re (pelu ise rere). E jagun fun esin Re nitori ki e le jere |
Dajudaju awon t’o sai gbagbo, ti o ba je pe gbogbo ohun ti n be lori ile aye patapata je tiwon ati iru re pelu re lati fi gba ara won sile nibi iya Ojo Ajinde, A o nii gba a ni owo won. Iya eleta-elero si wa fun won |
يُرِيدُونَ أَن يَخْرُجُوا مِنَ النَّارِ وَمَا هُم بِخَارِجِينَ مِنْهَا ۖ وَلَهُمْ عَذَابٌ مُّقِيمٌ(37) Won yoo fe jade kuro ninu Ina, won ko si nii le jade kuro ninu re. Iya gbere si wa fun won |
Ole lokunrin ati ole lobinrin, e ge owo awon mejeeji. (O je) esan fun ise owo awon mejeeji. (O si je) ijiya lati odo Allahu. Allahu si ni Alagbara, Ologbon |
Enikeni ti o ba ronu piwada leyin abosi (owo) re, ti o si se atunse, dajudaju Allahu yoo gba ironupiwada re. Dajudaju Allahu ni Alaforijin, Alaaanu |
Se o o mo pe dajudaju ti Allahu ni ijoba awon sanmo ati ile? O maa je eni ti O ba fe niya. O si maa fori jin eni ti O ba fe. Allahu si ni Alagbara lori gbogbo nnkan |
Iwo Ojise, ma se je ki o ba o ninu je awon t’o n yara lo sinu aigbagbo ninu awon t’o fi enu ara won wi pe: “A gbagbo.” – ti okan won ko si gbagbo ni ododo - ati awon t’o di yehudi, ti won n teti si iro, ti won si n teti si oro fun awon eniyan miiran ti ko wa si odo re, ti won n yi oro pada kuro ni awon aye re, won si n wi pe: “Ti won ba fun yin ni eyi e gba a. Ti won ko ba si fun yin e sora.” Enikeni ti Allahu ba fe fooro re, o o ni ikapa kini kan lodo Allahu fun un. Awon wonyen ni awon ti Allahu ko fe fo okan won mo. Idojuti n be fun won ni aye. Iya nla si n be fun won ni orun |
Won n teti gbo iro, won si n je nnkan eewo. Nitori naa, ti won ba wa ba o, sedajo laaarin won tabi ki o seri kuro lodo won. Ti o ba seri kuro lodo won, won ko le ko inira kan kan ba o. Ti o ba si fe dajo, se idajo laaarin won pelu deede. Dajudaju Allahu nifee awon onideede |
Bawo ni won a se fi o se adajo, nigba ti o je pe Taorah wa lodo won. Idajo Allahu si wa ninu re. Leyin naa, won n peyin da leyin iyen. Awon wonyen ki i si se onigbagbo ododo |
Dajudaju Awa so Taorah kale. Imona ati imole n be ninu re. Awon Anabi ti won je musulumi n fi se idajo fun awon t’o di yehudi. Bee naa ni awon alufaa ati awon amofin (n fi se idajo) nitori ohun ti A ni ki won so ninu tira Allahu. Won si je elerii lori re. Nitori naa, ma se paya eniyan. E paya Mi. E ma se ta awon ayah Mi ni owo kekere. Enikeni ti ko ba sedajo pelu ohun ti Allahu sokale, awon wonyen ni alaigbagbo |
A si se e ni ofin sinu re pe dajudaju emi fun emi, oju fun oju, imu fun imu, eti fun eti ati eyin fun eyin. Ofin esan gbigba si wa fun oju-ogbe. Enikeni ti o ba si yonda igbesan, o si maa je ipesere fun un. Enikeni ti ko ba sedajo pelu ohun ti Allahu sokale, awon wonyen ni alabosi |
A fi ‘Isa omo Moryam tele oripa won (iyen, awon Anabi ti won je musulumi); ti o n fi ohun t’o je ododo rinle nipa eyi t’o siwaju re ninu Taorah. A si fun un ni ’Injil. Imona ati imole wa ninu re, ti o n fi ohun t’o je ododo rinle nipa eyi t’o siwaju re ninu Taorah. (O je) imona ati waasi fun awon oluberu (Allahu ni asiko tire) |
Ki awon ti A fun ni ’Injil sedajo pelu ohun ti Allahu sokale ninu re. Enikeni ti ko ba sedajo pelu ohun ti Allahu sokale, awon wonyen ni obileje |
A so Tira (al-Ƙur’an) kale fun o pelu ododo. O n jerii si eyi t’o je ododo ninu eyi t’o siwaju re ninu Tira. O n wa aabo fun awon ofin inu re. Nitori naa, fi ohun ti Allahu sokale dajo laaarin won. Ma se tele ife-inu won t’o yapa si ohun ti o de ba o ninu ododo. Olukuluku ninu yin ni A ti se ofin ati ilana fun. Ati pe ti o ba je pe Allahu ba fe, iba se yin ni ijo kan soso (sinu ’Islam), sugbon nitori ki O le dan yin wo ninu ohun ti O fun yin ni. Nitori naa, e gbawaju nibi ise rere. Odo Allahu ni ibupadasi gbogbo yin patapata. O si maa fun yin ni iro nipa ohun ti e n yapa enu si |
Ati pe ki o fi ohun ti Allahu sokale se idajo laaarin won. Ma se tele ife-inu won. Sora fun won ki won ma baa fooro re kuro nibi apa kan ohun ti Allahu sokale fun o. Ti won ba si gbunri, mo pe Allahu kan fe fi adanwo kan won ni nitori apa kan ese won. Ati pe dajudaju opolopo ninu eniyan ni obileje |
أَفَحُكْمَ الْجَاهِلِيَّةِ يَبْغُونَ ۚ وَمَنْ أَحْسَنُ مِنَ اللَّهِ حُكْمًا لِّقَوْمٍ يُوقِنُونَ(50) Se idajo igba aimokan ni won n wa ni? Ta ni eni ti o dara ju Allahu lo nibi idajo fun ijo t’o ni amodaju (nipa Re) |
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se mu awon yehudi ati nasara ni ore ayo. Apa kan won lore apa kan. Enikeni ti o ba mu won ni ore ayo ninu yin, dajudaju o ti di ara won. Dajudaju Allahu ko nii fi ona mo ijo alabosi |
Nitori naa, o maa ri awon ti aare wa ninu okan won, ti won yoo maa yara lo saaarin won. Won yoo maa wi pe: “A n beru pe ki apadasi igba ma baa kan wa ni.” O sunmo ki Allahu mu isegun tabi ase kan wa lati odo Re. Won yo si di alabaamo lori ohun ti won fi pamo sinu okan won |
Awon t’o gbagbo ni ododo si maa so pe: "Se awon (yehudi) wonyi ko ni awon t’o fi Allahu bura ti ibura won si lagbara gan-an pe dajudaju awon n be pelu eyin (munafiki)?" Ise won ti baje. Nitori naa, won si di eni ofo |
Eyin ti e gbagbo ni ododo, enikeni ti o ba peyinda nibi esin re ninu yin, laipe Allahu maa mu awon eniyan kan wa; O maa nifee won, awon naa maa nifee Re. Won yoo ro fun awon onigbagbo ododo. Won yo si le mo awon alaigbagbo. Won yoo maa jagun esin fun Allahu. Won ko si nii beru eebu eleeebu. Iyen ni oore ajulo Allahu. O n fun eni ti O ba fe. Allahu si ni Olugbooro, Onimo |
Allahu ati Ojise Re ati awon t’o gbagbo ni ododo nikan ni ore yin, awon t’o n kirun, ti won si n yo Zakah, awon si ni oludawote-orunkun (lori irun) |
وَمَن يَتَوَلَّ اللَّهَ وَرَسُولَهُ وَالَّذِينَ آمَنُوا فَإِنَّ حِزْبَ اللَّهِ هُمُ الْغَالِبُونَ(56) Enikeni ti o ba mu Allahu ati Ojise Re ati awon onigbagbo ododo ni ore; dajudaju ijo Allahu, awon ni olubori |
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se mu awon t’o so esin yin di nnkan yeye ati ere sise ni ore ninu awon ti A fun ni tira siwaju yin ati awon alaigbagbo. E beru Allahu ti e ba je onigbagbo ododo |
Nigba ti e ba pepe sibi irun kiki, won yoo so o di nnkan yeye ati ere sise. Iyen nitori pe dajudaju awon ni ijo ti ko se laakaye |
So pe: “Eyin ahlul-kitab, nje e tako kini kan lara wa bi ko se pe a gbagbo ninu Allahu ati ohun ti Won sokale fun wa ati ohun ti Won sokale siwaju?” Dajudaju opolopo yin ni obileje |
So pe: “Se ki ng fun yin ni iro awon ti iya won buru ju iyen lo ni odo Allahu?” (Oun ni) eni ti Allahu sebi le, ti O si binu si, ti O si so awon kan ninu won di obo, elede ati aborisa. Awon wonyen ni ipo won buru julo, awon si ni won sina julo |
Nigba ti won ba wa si odo yin, won a wi pe: “A gbagbo.” Dajudaju won wole (ti yin) pelu aigbagbo, won si ti jade pelu re. Allahu si nimo julo nipa ohun ti won n fi pamo |
O maa ri opolopo ninu won, ti won n yara ko sinu ese, itayo enu-ala ati jije ti won n je owo eru. Dajudaju ohun ti won n se nise buru |
Ki ni ko je ki awon alufaa ati awon amofin maa ko fun won nipa oro enu won (ti o je) ese ati jije ti won n je owo eru! Dajudaju ohun ti won n se nise buru |
Awon yehudi wi pe: "Owo Allahu wa ni didi pa." A di owo won pa. A si sebi le won nitori ohun ti won wi. Amo owo Re mejeeji wa ni tite sile. O si n tore bi O se fe. Ohun ti won sokale fun o lati odo Oluwa Re yoo kuku je ki opolopo won lekun ni igberaga ati aigbagbo ni. A si ju ota ati ikorira saaarin won titi di Ojo Ajinde. Igbakigba ti won ba dana ogun, Allahu si maa pana re. Won si n se ibaje lori ile. Allahu ko si nifee awon obileje |
Ti o ba je pe dajudaju awon ahlul-kitab gbagbo ni ododo, ki won si beru (Allahu), Awa iba pa awon aida won re fun won, Awa iba si mu won wo inu awon Ogba Idera |
Ti o ba je pe dajudaju won lo at-Taorah ati al-’Injil ati ohun ti A sokale fun won lati odo Oluwa won (iyen, al-Ƙur’an), won iba maa je lati oke won ati lati isale ese won. Ijo kan n be ninu won t’o duro deede, (amo) ohun ti opolopo ninu won n se nise buru |
Iwo Ojise, fi gbogbo ohun ti won sokale fun o lati odo Oluwa re jise. Ti o o ba si se bee, o o jise pe. Allahu yo si daabo bo o lodo awon eniyan. Dajudaju Allahu ko nii fi ona mo ijo alaigbagbo (lati se o ni aburu) |
So pe: “Eyin ahlul-kitab, e o ri kini kan se (ninu esin) titi e maa fi lo at-Taorah ati al-’Injil ati ohun ti A sokale fun yin lati odo Oluwa yin (iyen, al-Ƙur’an).” Ohun ti won sokale fun o lati odo Oluwa Re yoo kuku je ki opolopo won lekun ni igberaga ati aigbagbo ni. Nitori naa, ma se banuje nitori ijo alaigbagbo |
Dajudaju awon t’o gbagbo ni ododo ati awon t’o di yehudi, - awon sobi’un ati awon kristieni, - enikeni ti o ba ni igbagbo ododo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin, ti o si sise rere, ko nii si iberu fun won. Won ko si nii banuje |
A kuku gba adehun lowo awon omo ’Isro’il. A si ran awon Ojise kan si won. Igbakigba ti Ojise kan ba de ba won pelu ohun ti emi won ko fe, won pe igun kan ni opuro, won si n pa igun kan |
Won si lero pe ko nii si ifooro; won foju, won si diti (si ododo). Leyin naa, Allahu gba ironupiwada won. Leyin naa, won foju, won tun diti (si ododo); opolopo ninu won (lo se bee). Allahu si ni Oluriran nipa ohun ti won n se nise |
Won kuku ti di keferi, awon t’o wi pe: “Dajudaju Allahu, Oun ni Mosih omo Moryam.” Mosih si so pe: "Eyin omo ’Isro’il, e josin fun Allahu, Oluwa mi ati Oluwa yin. Dajudaju enikeni ti o ba ba Allahu wa akegbe, Allahu ti se Ogba Idera ni eewo fun un. Ina si ni ibugbe re. Ko si nii si alaranse kan fun awon alabosi |
Won kuku ti di keferi, awon t’o wi pe: “Dajudaju Allahu ni Iketa (awon) meta.” Ko si si olohun kan ti ijosin to si afi Olohun, Okan soso. Ti won ko ba jawo nibi ohun ti won n wi, dajudaju iya eleta elero l’o maa je awon t’o di keferi ninu won |
أَفَلَا يَتُوبُونَ إِلَى اللَّهِ وَيَسْتَغْفِرُونَهُ ۚ وَاللَّهُ غَفُورٌ رَّحِيمٌ(74) Nitori naa, se won ko nii ronu piwada sodo Allahu, ki won si toro aforijin lodo Re? Allahu si ni Alaforijin, Asake-orun |
Ki ni Mosih bi ko se Ojise kan. Awon Ojise si ti lo siwaju re. Olododo si ni iya re. Awon mejeeji maa n je ounje. Wo bi A se n salaye awon ayah naa. Leyin naa, wo bi won se n seri won kuro nibi ododo |
So pe: “Se e n josin fun leyin Allahu ohun ti ko ni ikapa inira ati anfaani kan fun yin? Allahu, Oun si ni Olugbo, Onimo.” |
So pe: "Eyin ahlul-kitab, e ma se tayo enu-ala ninu esin yin, ti ki i se (esin) ododo. E ma si se tele ife-inu ijo kan t’o ti sina siwaju (iyen, awon yehudi). Won si opolopo lona. Won si sina kuro ni oju ona taara |
A sebi le awon t’o sai gbagbo ninu awon omo ’Isro’il lori ahon (Anabi) Dawud ati ‘Isa omo Moryam. Iyen nitori pe, won yapa (ase Allahu), won si n tayo enu-ala |
كَانُوا لَا يَتَنَاهَوْنَ عَن مُّنكَرٍ فَعَلُوهُ ۚ لَبِئْسَ مَا كَانُوا يَفْعَلُونَ(79) Won ki i ko iwa ibaje ti won n se nise laaarin ara won. Ohun ti won n se nise si buru |
O maa ri opolopo ninu won t’o n sore awon t’o sai gbagbo. Ohun ti emi won ti siwaju fun won si buru to bee ge ti Allahu fi binu si won. Olusegbere si ni won ninu Iya |
Ti o ba je pe won gbagbo ninu Allahu ati Anabi (sollalahu alayhi wa sallam), ati ohun ti A sokale fun un, won ko nii mu won ni ore ayo, sugbon opolopo ninu won ni obileje |
Dajudaju o maa ri i pe awon eniyan ti ota won le julo si awon t’o gbagbo ni ododo ni awon yehudi ati awon osebo. Dajudaju o si maa ri i pe awon eniyan t’o sunmo awon t’o gbagbo ni ododo julo ni ife ni awon t’o wi pe: “Dajudaju nasara ni awa.” Iyen nitori pe awon alufaa ati olufokansin n be laaarin won. Ati pe dajudaju won ko nii segberaga (si ododo) |
Nigba ti won ba gbo ohun ti A sokale fun Ojise naa, o maa ri eyinju won ti o maa damije nitori ohun ti won ti mo ninu ododo. Won a si so pe: "Oluwa wa, a gbagbo ni ododo, ko wa mo ara awon olujerii (ododo) |
Ki ni o maa di wa lowo ti a o fi nii gbagbo ninu Allahu ati ohun ti o de ba wa ninu ododo (iyen, al-Ƙur’an), ti a si n jerankan pe ki Oluwa fi wa sinu awon eni-ire |
Nitori naa, nitori ohun ti won so, Allahu san won ni esan pelu awon Ogba Idera, ti awon odo n san ni isale re. Olusegbere ni won ninu re. Iyen si ni esan fun awon oluse-rere |
وَالَّذِينَ كَفَرُوا وَكَذَّبُوا بِآيَاتِنَا أُولَٰئِكَ أَصْحَابُ الْجَحِيمِ(86) Awon t’o si sai gbagbo, ti won pe awon ayah Wa niro, awon wonyen ni ero inu ina Jehim |
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se so awon nnkan daadaa ti Allahu se ni eto fun yin di eewo. E si ma se tayo enu-ala. Dajudaju Allahu ko feran awon olutayo enu-ala |
E je nnkan eto t’o dara ninu ohun ti Allahu se ni arisiki fun yin. Ati pe e beru Allahu, Eni ti eyin gbagbo ninu Re |
Allahu ko nii fi ibura ti o bo lenu yin bi yin, sugbon O maa fi awon ibura ti e finnufindo mu wa bi yin. Nitori naa, itanran re ni bibo talika mewaa pelu ounje ti o wa ni iwontun-wonsi ti e n fi bo ara ile yin, tabi ki e raso fun won, tabi ki e tu eru onigbagbo ododo kan sile loko eru. Enikeni ti ko ba ri (eyi se), o maa gba aawe ojo meta. Iyen ni itanran ibura yin nigba ti e ba bura. E so ibura yin. Bayen ni Allahu se n salaye awon ayah Re fun yin, nitori ki e le dupe |
Eyin ti e gbagbo ni ododo, dajudaju oti, tete, awon orisa ati ise yiyewo, egbin ninu ise Esu ni. Nitori naa, e jinna si i nitori ki e le jere |
Ohun ti Esu n fe ni pe o maa da ota ati ikorira sile laaarin yin nibi oti ati tete. O si fe se yin lori kuro nibi iranti Allahu ati nibi irun kiki. Se eyin ko nii jawo (nibi ise Esu) ni |
E tele ti Allahu, e tele ti Ojise. Ki e si sora. Nitori naa, ti e ba gbunri, ki e mo pe ise-jije ponnbele lojuse awon Ojise Wa |
Ko si ibawi fun awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si sise rere nipa ohun ti won je (ninu ounje siwaju ofin) nigba ti won ba ti beru Allahu, ti won si gbagbo ni ododo, ti won tun sise rere, leyin naa, ti won beru Allahu, ti won si gbagbo ni ododo, leyin naa, ti won beru Allahu, ti won tun sise rere. Allahu si feran awon oluse-rere |
Eyin ti e gbagbo ni ododo, dajudaju Allahu yoo fi kini kan dan yin wo nibi eran-igbe ti owo yin ati oko yin ba (ninu aso hurumi) nitori ki Allahu le safi han eni t’o n paya Re ni ikoko. Enikeni ti o ba tayo enu-ala leyin iyen, iya eleta-elero n be fun un |
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se pa eran-igbe nigba ti e ba wa ninu aso hurumi. Enikeni ti o ba si moomo pa a ninu yin, itanran re ni (pe o maa pa) iru ohun ti o pa ninu eran osin. Awon onideede meji ninu yin l’o si maa se idajo (osuwon) re (fun un. O je) eran itanran ti o maa mu de Kaaba. Tabi ki o fi bibo awon talika se itanran. Tabi aaro iyen ni aawe, nitori ki o le to bi oran re se lagbara to wo. Allahu ti moju kuro nibi ohun t’o re koja. Enikeni ti o ba tun pada (moomo dode ninu aso hurumi), Allahu yoo gbesan lara re re. Allahu si ni Alagbara, Olugbesan |
Won se odo dide ati jije ounje (okunbete) inu re ni eto fun yin. Nnkan igbadun ni fun eyin ati awon onirin-ajo. Won si se igbe dide ni eewo fun yin nigba ti e ba wa ninu aso hurumi. E beru Allahu, Eni ti won maa ko yin jo si odo Re |
Allahu se Kaaba, Ile Haram, ni aye aabo fun awon eniyan. (Nnkan aabo naa ni) awon osu owo, awon eran ore (ti won ko sami si lorun) ati (awon eran ore) ti won sami si lorun. Iyen ri bee ki e le mo pe dajudaju Allahu mo ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile. Ati pe dajudaju Allahu ni Onimo nipa gbogbo nnkan |
اعْلَمُوا أَنَّ اللَّهَ شَدِيدُ الْعِقَابِ وَأَنَّ اللَّهَ غَفُورٌ رَّحِيمٌ(98) E mo pe dajudaju Allahu le nibi iya. Ati pe dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun |
مَّا عَلَى الرَّسُولِ إِلَّا الْبَلَاغُ ۗ وَاللَّهُ يَعْلَمُ مَا تُبْدُونَ وَمَا تَكْتُمُونَ(99) Ko si ojuse kan fun Ojise naa bi ko se ise-jije. Allahu si mo ohun ti e n safi han re ati ohun ti e n fi pamo |
So pe: “Ohun buruku ati ohun daadaa ko dogba, pupo ohun buruku ibaa jo o loju”. Nitori naa, e beru Allahu, eyin onilaakaye, nitori ki e le jere.” |
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se maa beere nipa awon nnkan sa. Ti A ba fi han yin, o maa ko ipalara ba yin. Ti e ba si beere nipa (awon nnkan t’o ye lati beere nipa esin) nigba ti A n so al-Ƙur’an kale lowo, A maa fi han yin. Allahu ti se amojukuro nipa re. Allahu ni Alaforijin, Alafarada |
قَدْ سَأَلَهَا قَوْمٌ مِّن قَبْلِكُمْ ثُمَّ أَصْبَحُوا بِهَا كَافِرِينَ(102) Ijo kan kuku ti beere re siwaju yin. Leyin naa, won si di alaigbagbo nipase re |
Allahu ko fi eran bahirah, eran sa’ibah, eran wasilah ati eran ham lole. Sugbon awon t’o sai gbagbo n da adapa iro mo Allahu ni. Opolopo won ni ko se laakaye |
Nigba ti won ba so fun won pe: “E maa bo wa sibi ohun ti Allahu sokale. (E maa bo wa) si odo Ojise naa.” Won a wi pe: “Ohun ti a ba awon baba wa lori re ti to wa.” Se pelu bi o se je pe awon baba won ko nimo kan kan, ti won ko si mona |
Eyin ti e gbagbo ni ododo, emi ara yin dowo yin. Eni ti o ti sina ko le ko inira ba yin nigba ti e ba ti mona. Odo Allahu ni ibupadasi gbogbo yin patapata. Nigba naa, O maa fun yin ni iro ohun ti e n se nise |
Eyin ti e gbagbo ni ododo, (e wa) eri jije laaarin yin nigba ti (ipokaka) iku ba de ba eni kan ninu yin ti o fe so asoole. (E wa) onideede meji ninu yin. Tabi awon meji miiran yato si yin ti eyin ba wa lori irin-ajo ti ajalu iku ba fe sele si yin. E da awon mejeeji duro leyin irun, ki won fi Allahu bura, ti e ba seyemeji (si ododo won, ki won si so pe:) "A o nii ta ibura wa ni iye kan kan, koda ko je ebi. A o si nii fi eri jije ti Allahu (pa lase) pamo. (Bi bee ko) nigba naa, dajudaju awa wa ninu awon elese |
Ti won ba si ri i pe awon mejeeji da ese (nipa yiyi asoole pada), ki awon meji miiran ninu awon ti awon mejeeji akoko se abosi si (iyen, ebi oku) ropo won. Ki awon naa si fi Allahu bura pe: "Dajudaju eri jije tiwa je ododo ju eri jije ti awon mejeeji (akoko). A o si nii tayo enu-ala. (Bi bee ko) nigba naa, dajudaju a ti wa ninu awon alabosi |
Iyen sunmo julo lati mu eri jije wa ni oju-ponna re tabi lati (le la ninu) ipaya pe won yoo da ibura kan nu leyin ibura tiwon. E beru Allahu, ki e si gboran. Allahu ki i fi ona mo ijo obileje |
Ni ojo ti Allahu yoo ko awon Ojise jo, O si maa so pe: “Ki ni esi ti won fun yin?” Won a so pe: “Ko si imo kan fun wa (nipa re). Dajudaju Iwo, Iwo ni Onimo nipa awon ikoko.” |
(Ranti) nigba ti Allahu so pe: “‘Isa omo Moryam, ranti idera Mi lori re ati lori iya re, nigba ti Mo fi emi Mimo (molaika Jibril) ran o lowo, ti o si n ba awon eniyan soro lori ite ni oponlo ati nigba ti o dagba. (Ranti) nigba ti Mo fun o ni imo Tira, ijinle oye, at-Taorah ati al-’Injil. (Ranti) nigba ti o n mo nnkan lati inu amo bi irisi eye, ti o n fe ategun sinu re, ti o n di eye pelu iyonda Mi. O n wo afoju ati adete san pelu iyonda. (Ranti) nigba ti o n mu awon oku jade (ni alaaye lati inu saree) pelu iyonda Mi. (Ranti) nigba ti Mo ko awon omo ’Isro’il lowo ro, nigba ti o mu awon eri t’o yanju wa ba won. Awon t’o sai gbagbo ninu won si wi pe: “Ki ni eyi bi ko se idan ponnbele.” |
(Ranti) nigba ti Mo fi mo awon omoleyin re ninu okan won pe ki won gbagbo ninu Emi ati Ojise Mi. Won so pe: “A gbagbo. Ki o si jerii pe dajudaju musulumi ni wa.” |
(Ranti) nigba ti awon omoleyin re so pe: “‘Isa omo Moryam, nje Oluwa re le so opon ounje kan kale lati sanmo?” O so pe: "E beru Allahu ti e ba je onigbagbo ododo |
Won so pe: “A fe je ninu re, a si fe ki okan wa bale, ki a si le mo pe o ti so ododo fun wa. A si maa wa ninu awon olujerii.” |
‘Isa omo Moryam so pe: "Allahu, Oluwa wa, so opon ounje kan kale fun wa lati inu sanmo, ki o je odun fun eni akoko wa ati eni ikeyin wa.1 Ki o si je ami kan lati odo Re. Pese fun wa, Iwo si loore julo ninu awon olupese |
Allahu so pe: “Dajudaju Emi yoo so o kale fun yin. Sugbon enikeni ti o ba sai gbagbo leyin naa ninu yin, dajudaju Mo maa je e niya kan ti Mi o fi je eni kan ri ninu gbogbo eda.” |
(Ranti) nigba ti Allahu so pe: “‘Isa omo Moryam, se iwo l’o so fun awon eniyan pe: "E mu emi ati iya mi ni olohun meji ti e oo maa josin fun leyin Allahu?" O so pe: "Mimo ni fun O, ko to fun mi lati so ohun ti emi ko letoo (si lati so). Ti mo ba so bee, O kuku ti mo. O mo ohun ti n be ninu emi mi. Ng o si mo ohun ti n be ninu emi Re. Dajudaju Iwo ni Onimo nipa awon ikoko |
Emi ko so ohun kan fun won bi ko se ohun ti O pa mi lase re pe: "E josin fun Allahu, Oluwa mi ati Oluwa yin." Mo si je elerii lori won niwon igba ti mo n be laaarin won. Sugbon nigba ti O gba mi kuro lowo won, Iwo ni Oluso lori won. Iwo si ni Arinu-rode gbogbo nnkan |
Ti O ba je won niya, dajudaju eru Re ni won. Ti O ba si fori jin won, dajudaju Iwo, Iwo ni Alagbara, Ologbon |
Allahu so pe: “Eyi ni ojo ti ododo awon olododo yoo se won ni anfaani. Awon Ogba Idera kan ti awon odo n san ni isale re n be fun won. Olusegbere ni won ninu re titi laelae. Allahu yonu si won. Won si yonu si (ohun ti Allahu fun won). Iyen ni erenje nla |
لِلَّهِ مُلْكُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَمَا فِيهِنَّ ۚ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ(120) Ti Allahu ni ijoba awon sanmo ati ile ati ohunkohun t’o wa ninu won. Oun si ni Alagbara lori gbogbo nnkan |
Yoruba diğer sureler:
En ünlü okuyucuların sesiyle Maide Suresi indirin:
Surah Al-Maidah mp3: yüksek kalitede dinlemek ve indirmek için okuyucuyu seçerek
Ahmed El Agamy
Saad Al Ghamdi
Saud Al Shuraim
Abdul Basit
Abdullah Basfar
Abdullah Al Juhani
Ali Al Hudhaifi
Fares Abbad
Maher Al Muaiqly
Muhammad Jibril
Al Minshawi
Al Hosary
Mishari Al-afasi
Nasser Al Qatami
Yasser Al Dosari
Bizim için dua et, teşekkürler