Surah Al-Isra
PDF —
Built right in your browser — download starts automatically
Surah Al-Isra pdf — Gbà (Yorùbá)
Surah Al-Isra pdf Yorùbá — Gbà Surah Al-Isra Itumọ. Al-Isra (Meccan) 111 Ẹsẹ.
Related
- Al-Isra ItumọYorùbá
- Al-Isra mp3Gbọ
- Quran Index Yorùbá114
More Surah PDF
Surah Al-Isra

ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧ
Mimo ni fun Eni ti O mu erusin Re se irin-ajo ni ale lati Mosalasi Haram si Mosalasi Aƙso ti A fi ibukun yi ka, nitori ki A le fi ninu awon ami Wa han an. Dajudaju Allahu, Oun ni Olugbo, Oluriran
ﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴ
A fun (Anabi) Musa ni Tira. A si se e ni imona fun awon omo ’Isro’il. (A si so) pe: “E ma se mu alaabo kan leyin Mi.”
ﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿ
(E je) aromodomo awon ti A gbe gun oko oju-omi pelu (Anabi) Nuh. Dajudaju (Nuh) je erusin, oludupe
ﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍ
A si fi mo awon omo ’Isro’il ninu Tira pe: “Dajudaju e maa sebaje lori ile nigba meji. Dajudaju e tun maa segberaga t’o tobi.”
ﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠ
Nitori naa, nigba ti adehun fun akoko ninu mejeeji ba sele, A maa gbe awon erusin Wa kan, ti won lagbara gan-an, dide si yin. Won yoo da rogbodiyan sile laaarin ilu (yin). O je adehun kan ti A maa mu se
ﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬ
Leyin naa, A da isegun lori won pada fun yin. A si fi awon dukia ati awon omo se idera fun yin. A si se yin ni ijo t’o po julo
ﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧ
Ti e ba se rere, e se rere fun emi ara yin. Ti e ba si se aburu, fun emi ara yin ni. Nigba ti adehun ikeyin ba de, (A oo gbe omo ogun miiran dide) nitori ki won le ko ibanuje ba yin ati nitori ki won le wo inu Mosalasi gege bi won se wo o nigba akoko ati nitori ki won le pa ohun ti (awon omo ’Isro’il) joba lori re run patapata
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞ
O le je pe Oluwa yin maa saanu yin. Ti e ba si pada (sibi ese), A maa pada (sibi esan). A si se ina Jahanamo ni ewon fun awon alaigbagbo
ﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯ
Dajudaju al-Ƙur’an yii, o n fini mona si ona taara, o si n fun awon onigbagbo ododo t’o n se awon ise rere ni iro idunnu pe dajudaju esan t’o tobi wa fun won
ﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹ
Dajudaju awon ti ko gba Ojo Ikeyin gbo, A ti pese iya eleta-elero sile de won
ﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃ
Eniyan n toro aburu bi o se n toro ohun rere; eniyan si je olukanju
ﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝ
A se ale ati osan ni ami meji; A pa ami ale re, A si se ami osan ni iriran1 nitori ki e le wa oore ajulo lati odo Oluwa yin ati nitori ki e le mo onka awon odun ati isiro. Gbogbo nnkan ni A ti salaye re ni ifosiwewe
ﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬ
Eniyan kookan ni A ti la ayanmo ati iwe ise re bo lorun. A si maa mu iwe kan jade fun un ni Ojo Ajinde. O maa pade re ni sisi sile
ﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕ
Ka iwe (ise) re. Iwo ti to ni olusiro fun emi ara re lonii
ﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮ
Enikeni t’o ba mona, o mona fun emi ara re. Enikeni t’o ba si sina, o n sina fun emi ara re. Eleru-ese kan ko nii ru ese elomiiran. A o si nii je awon eda niya titi A fi maa gbe ojise kan dide (si won)
ﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽ
Nigba ti A ba si gbero lati pa ilu kan run, A maa pa awon onigbedemuke ilu naa lase (rere). Amo won maa sebaje sinu ilu. Oro naa yo si ko le won lori. A o si pa won re patapata
ﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆﰇﰈﰉﰊﰋﰌ
Meloo meloo ninu awon iran ti A ti parun leyin (Anabi) Nuh! Oluwa re to ni Alamotan, Oluriran nipa awon ese erusin Re
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣ
Eni ti o ba n gbero (oore) aye yii (nikan), A maa taari ohun ti A ba fe si i ninu re ni kiakia fun eni ti A ba fe. Leyin naa, A maa se ina Jahanamo fun un; o maa wo inu re ni eni yepere, eni eko
ﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰ
Eni ti o ba si gbero (oore) orun, ti o si se ise re, o si je onigbagbo ododo, awon wonyen, ise won maa je atewogba (pelu esan rere)
ﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾ
Awon wonyi (t’o n gbero oore aye) ati awon wonyi (t’o n gbero oore orun), gbogbo won ni A n se oore aye fun lati inu ore Oluwa re. Won ko nii di ore Oluwa re lowo (fun ikini keji nile aye)
ﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋ
Wo bi A se fun apa kan won loore ajulo lori apa kan (nile aye). Dajudaju torun tun tobi julo ni ipo, o si tobi julo loore ajulo
ﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕ
Ma se mu olohun miiran mo Allahu nitori ki o ma baa jokoo (sinu Ina) ni eni abuku, eni ti won maa da isoro re da
ﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱ
Oluwa re pase pe: “E ma se josin fun eni kan ayafi Oun. Ki e si se daadaa si awon obi (yin) mejeeji. Ti okan ninu awon mejeeji tabi ikini keji won ba dagba si o lodo, ma se sio si won, ma se jagbe mo won. Maa ba awon mejeeji so oro aponle
ﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟ
Ki o si re apa re nile lati fi bowo fun awon mejeeji nipa sise aanu won. Ki o si so pe: "Oluwa Eledaa mi, ke awon mejeeji gege bi won se re mi ni kekere
ﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭ
Oluwa yin nimo julo nipa ohun ti n be ninu emi yin, ti e ba je eni rere. Dajudaju O n je Alaforijin fun awon oluronupiwada
ﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸ
E fun ebi ni eto re. (E fun) mekunnu ati onirin-ajo ti agara da (ni nnkan). Ki e si ma se na dukia yin ni ina-apa
ﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃ
Dajudaju awon apa, won je omo iya Esu. Alaimoore si ni Esu je si Oluwa re
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝ
Ti o ba seri kuro lodo won (iyen awon alaini) lati wa ike kan ti o n reti lati odo Oluwa re, ba won soro ele
ﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫ
Ma di owo re mo orun re (ma ya ahun), ma si te e sile tan patapata (ma ya apa), ki o ma baa jokoo kale ni eni eebu (ti o ba je ahun), eni ti ko nii si lowo re mo (ti o ba je apa)
ﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹ
Dajudaju Oluwa re l’O n te arisiki sile fun eni ti O ba fe. O si n diwon re (fun elomiiran). Dajudaju O n je Onimo-ikoko, Oluriran nipa awon erusin Re
ﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉ
E ma pa awon omo yin nitori ipaya osi. Awa l’A n pese fun awon ati eyin. Dajudaju pipa won je ese t’o tobi
ﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓ
E ma se sunmo agbere. Dajudaju o je iwa buruku. O si buru ni oju ona
ﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬ
E ma pa emi ti Allahu se (pipa re) ni eewo ayafi ni ona eto. Eni ti won ba pa ni ipa abosi, dajudaju A ti fun alamojuuto re ni agbara (lati gbesan). Nitori naa, ki enikeni ma se tayo enu- ala nibi ipaniyan (nitori pe) dajudaju A maa ran (ebi oku) lowo (lati gbesan)
ﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡ
E ma se sunmo dukia omo orukan, ayafi ni ona t’o dara julo, titi o fi maa dagba. Ki e si mu adehun se. Dajudaju adehun je ohun ti A o beere nipa re
ﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮ
E won osuwon kun nigba ti e ba won on. E fi iwon t’o to won on. Iyen loore julo, o si dara julo ni ikangun
ﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀ
Ma se tele ohun ti iwo ko nimo nipa re. Dajudaju igboro, iriran ati okan; ikookan iwonyen ni A oo beere nipa re
ﰁﰂﰃﰄﰅﰆﰇﰈﰉﰊﰋﰌﰍﰎﰏ
Ma se rin lori ile pelu igberaga; dajudaju iwo ko le da ile lu, iwo ko si le ga to apata
ﰐﰑﰒﰓﰔﰕﰖﰗ
Gbogbo iyen, aburu re je ohun ikorira lodo Oluwa re
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤ
Iyen wa ninu ohun ti Oluwa re fi ranse si o ninu ijinle ogbon (al-Ƙur’an). Ma se mu olohun miiran mo Allahu ki won ma baa ju o sinu ina Jahanamo ni eni abuku, eni eko
ﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱ
Se Oluwa yin fi awon omokunrin sa yin lesa, Oun wa mu awon omobinrin ninu awon molaika (ni tiRe)? Dajudaju e ma n so oro nla (t’o buru)
ﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼ
Dajudaju A ti se alaye sinu al- Ƙur’an yii nitori ki won le lo isiti. Sibesibe ko se alekun kan fun won bi ko se sisa (fun iranti)
ﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊ
So pe: “Ti o ba je pe awon olohun kan tun wa pelu Re gege bi won se n wi, won iba wa ona lati sunmo (Allahu) Onitee-ola ni.”
ﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑ
Mimo ni fun Un. O si ga ni giga t’o tobi tayo ohun ti won n wi (ni aida nipa Re)
ﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩ
Awon sanmo mejeeje, ile ati awon ti won wa ninu won n se afomo fun Un. Ko si si kini kan afi ki o se afomo ati idupe fun Un. Sugbon e ko le gbo agboye afomo won. Dajudaju Allahu n je Alafarada, Alaforijin
ﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗ
Nigba ti o ba n ke al-Ƙur’an, A maa fi gaga aabo saaarin iwo ati awon ti ko gba Ojo Ikeyin gbo
ﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬ
A fi ebibo bo okan won nitori ki won ma baa gbo o ye. (A tun fi) edidi sinu eti won. Nigba ti o ba si daruko Oluwa re nikan soso ninu al-Ƙur’an, won maa peyin won da lati sa lo
ﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀ
Awa nimo julo nipa ohun ti won n gbo nigba ti won ba n teti si o ati nigba ti won ba n soro kelekele, nigba ti awon alabosi ba n wi pe: “E ko tele eni kan bi ko se okunrin eleedi kan.”
ﰁﰂﰃﰄﰅﰆﰇﰈﰉﰊ
Wo bi won se fun o ni awon afiwe (buruku)! Nitori naa, won ti sina; won ko si le mona
ﰋﰌﰍﰎﰏﰐﰑﰒﰓﰔ
Won wi pe: “Se nigba ti a ba ti di egungun, ti a ti jera, se Won maa gbe wa dide ni eda titun ni?”
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗ
So pe: "E di okuta tabi irin
ﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵ
Tabi (ki e di) eda kan ninu ohun ti o tobi ninu okan yin." Sibesibe won yoo wi pe: “Ta ni O maa da wa pada (fun ajinde)?” So pe: “Eni ti O pile iseda yin ni igba akoko ni.” Sibesibe won yoo mi ori won si o (ni ti abuku) Nigba naa, won yoo wi pe: “Igba wo ni?” So pe: “O le je pe o ti sunmo.”
ﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿ
Ojo ti Allahu yoo pe yin. E si maa jepe pelu idupe fun Un. E si maa ro pe e ko gbe ile aye bi ko se fun igba die
ﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒ
So fun awon erusin Mi pe ki won so oro eyi t’o dara julo. Dajudaju Esu yoo maa da yanpon-yanrin sile laaarin won. Dajudaju Esu je ota ponnbele fun eniyan
ﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣ
Oluwa yin nimo julo nipa yin. Ti O ba fe, O maa ke yin. Tabi ti O ba si fe, O maa je yin niya. A ko ran o pe ki o je oluso lori won
ﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖ
Oluwa re nimo julo nipa awon t’o n be ninu awon sanmo ati ile. Dajudaju A ti se oore ajulo fun apa kan awon Anabi lori apa kan. A si fun (Anabi) Dawud ni Zabur
ﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤ
So pe: "E pe awon ti e so nipa won lai ni eri lowo pe won je olohun leyin Re, (e maa ri i pe) won ko ni ikapa lati gbe inira kuro tabi lati se iyipada kan fun yin
ﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸ
Awon wonyen ti won n pe (leyin Re) n wa ategun sodo Oluwa won ni! - Ewo ninu won l’o sunmo (Allahu) julo (bayii)? – Awon naa n reti ike Allahu, won si n paya iya Re. Dajudaju iya Oluwa re je ohun ti won gbodo sora fun
ﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆﰇﰈﰉﰊﰋﰌ
Ko si ilu kan (t’o sabosi) afi ki Awa pa a re siwaju Ojo Ajinde tabi ki A je e niya lile. Iyen wa ni kiko sile ninu Tira (Laohul-Mahfuth)
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨ
Ati pe ko si ohun ti o di Wa lowo lati fi awon ami (ise iyanu) ranse bi ko se pe awon eni akoko ti pe e niro. A fun ijo Thamud ni abo rakunmi; (ami) t’o foju han kedere ni. Amo won sabosi si i. A o si nii fi awon ami ranse bi ko se fun ideruba
ﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄ
(Ranti) nigba ti A so fun o pe: “Dajudaju Oluwa re yi awon eniyan po (pelu agbara Re). Ati pe A ko se iran (wiwo) ti A fi han o ati igi (zaƙum) ti A sebi le ninu al-Ƙur’an ni kini kan bi ko se pe (o je) adanwo fun awon eniyan. A n deru ba won, amo ko se alekun kan fun won bi ko se iwa agbere t’o tobi
ﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒ
(Ranti) nigba ti A so fun awon molaika pe: "E fori kanle ki (Anabi) Adam." Won si fori kanle ki i afi ’Iblis. O wi pe: “Se ki ng fori kanle ki eni ti O fi amo seda re ni?”
ﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢ
O wi pe: "So fun mi nipa eyi ti O gbe aponle fun lori mi, (nitori ki ni?) Dajudaju ti O ba le lo mi lara di Ojo Ajinde, dajudaju mo maa jegaba lori awon aromodomo re afi awon die
ﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭ
(Allahu) so pe: "Maa lo. Enikeni ti o ba tele o ninu won, dajudaju ina Jahanamo ni esan yin. (O si je) esan t’o kun keke
ﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣ
Fi ohun re ko eni ti agbara re ba ka ninu won laya je. Fi awon omo ogun elesin re ati omo ogun elese re pe won (sinu isina). Kopa pelu won ninu awon dukia ati awon omo. Ki o si se ileri fun won." Esu ko si nii se ileri fun won bi ko se etan
ﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮ
Dajudaju awon erusin Mi, ko si agbara kan fun o lori won. Oluwa re si to ni Oluso
ﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾ
Oluwa yin ni Eni t’O n mu oko oju-omi rin fun yin nitori ki e le wa ninu oore ajulo Re. Dajudaju O n je Alaaanu fun yin
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥ
Nigba ti inira ba fowo ba yin loju omi, eni ti e n pe yo si dofo (mo yin lowo) afi Oun nikan (Allahu). Nigba ti O ba si gba yin la (ti e) gunle, e n gbunri (kuro lodo Re). Eniyan si je alaimoore
ﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵ
Se e fokan bale pe (Allahu) ko le mu apa kan ile ri mo yin lese ni? Tabi pe ko le fi okuta ina ranse si yin? Leyin naa, e o si nii ri oluso kan ti o maa gba yin la
ﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌ
Tabi e fokan bale pe (Allahu) ko nii pada mu yin wa si (ori omi) nigba miiran ni; ti O maa ran iji ategun si yin, ti O si maa te yin ri (sinu omi) nitori pe e sai moore? Leyin naa, e o si nii ri oluranlowo kan t’o maa ba yin gbesan lara Wa
ﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟ
Dajudaju A se aponle fun awon omo (Anabi) Adam; A gbe won rin lori ile ati lori omi; A fun won ni ije-imu ninu awon nnkan daadaa; A si soore ajulo fun won gan-an lori opolopo ninu awon ti A da
ﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰ
Ni ojo ti A oo maa pe gbogbo eniyan pelu asiwaju won . Nigba naa, enikeni ti A ba fun ni iwe (ise) re ni owo otun re, awon wonyen ni won yoo maa ka iwe (ise) won. A o si nii sabosi bin-intin si won
ﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝ
Enikeni ti o ba je afoju (nipa ’Islam) nile aye yii, oun ni afoju ni orun. O si (ti) sina julo
ﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬ
Won fee ko iyonu ba o nipa nnkan ti A mu wa fun o ni imisi nitori ki o le hun nnkan miiran t’o yato si i nipa Wa. Nigba naa, won iba mu o ni ore ayo
ﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶ
Ti ko ba je pe A fi ese re rinle ni, dajudaju o fee fi nnkan die te si odo won
ﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃ
Nigba naa, Awa iba je ki o to ilopo (iya) isemi aye ati ilopo (iya leyin) iku wo. Leyin naa, iwo ko nii ri oluranlowo kan ti o maa gba o sile nibi iya Wa
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟ
Won fee ko o laya je ninu ilu nitori ki won le le o jade kuro ninu re. Nigba naa, awon naa ko nii wa ninu re leyin re tayo igba die
ﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬ
(Eyi je) ise (Allahu) lori awon ti A ti ran nise ninu awon Ojise Wa siwaju re. O o si nii ri iyipada kan fun ise Wa
ﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼ
Gbe irun kiki duro ni (igba ti) oorun ba yetari titi di igba ti ale yoo fi le. Ati pe irun Subh, dajudaju irun Subh je ohun ti (awon molaika ale ati osan) yoo jerii si
ﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉ
Ati pe ninu oru, fi kike al-Ƙur’an (lori irun) sai sun. (Eyi je) ise asegbore fun o. Laipe, Oluwa re yoo gbe o si aye ope
ﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘ
So pe: “Oluwa mi, mu mi wo inu ilu ni iwolu ona ododo. Mu mi jade kuro ninu ilu ni ijade ona ododo. Ki O si fun mi ni aranse t’o lagbara lati odo Re
ﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣ
So pe: “Ododo de. Iro si sa lo. Dajudaju iro je ohun ti o maa sa lo.”
ﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱ
A n so ohun ti o je iwosan ati ike kale sinu al-Ƙur’an fun awon onigbagbo ododo. (al-Ƙur’an) ko si salekun fun awon alabosi bi ko se ofo
ﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟ
Nigba ti A ba sedera fun eniyan, o maa gbunri (kuro nibi ododo), o si maa segberaga. Nigba ti aburu ba si fowo ba a, o maa di olusoretinu
ﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫ
So pe: "Eni kookan n sise lori adamo re. Sugbon Oluwa yin nimo julo nipa eni ti o mona
ﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻ
Won n bi o leere nipa emi. So pe: “Emi n be ninu ase Oluwa mi. A o si fun yin ninu imo bi ko se die.”
ﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆﰇﰈﰉ
Ati pe dajudaju ti A ba fe ni, A iba kuku gba imisi ti A fi ranse si o (kuro ni odo re). Leyin naa, iwo ko nii ri alaabo kan ti o maa la o lodo Wa
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛ
Ayafi ike lati odo Oluwa re (ni ko fi se bee). Dajudaju oore ajulo Re lori re tobi
ﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯ
So pe: “Dajudaju ti awon eniyan ati alujannu ba para po lati mu iru al-Ƙur’an yii wa, won ko le mu iru re wa, apa kan won ibaa je oluranlowo fun apa kan
ﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾ
Dajudaju A ti fi akawe kookan salaye (orisirisi) fun awon eniyan sinu al-Ƙur’an yii. Sibesibe opolopo eniyan ko lati gba afi atako sa
ﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉ
Won si wi pe: “A ko nii gba o gbo titi o maa fi mu omi iseleru se yo fun wa
ﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕ
Tabi ki o ni ogba oko dabinu ati ogba oko ajara, ti o si maa je ki awon odo san ko ja daadaa laaarin won
ﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢ
Tabi ki o je ki sanmo ja lu wa ni kelekele gege bi o se so (pe Allahu le se bee). Tabi ki o mu Allahu ati awon molaika wa (ba wa) ni ojukoju
ﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟ
Tabi ki o ni ile wura kan, tabi ki o gun oke sanmo lo. A ko si nii gba gigun-sanmo re gbo titi o fi maa so tira kan ti a oo maa ke kale fun wa.” So pe: “Mimo ni fun Oluwa mi, nje mo je kini kan bi ko se Ojise abara?”
ﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯ
Ko si ohun ti o ko fun awon eniyan lati gbagbo ni ododo nigba ti imona de ba won afi ki won wi pe: “Se Allahu ran Ojise abara nise ni?”
ﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾ
So pe: “Ti o ba je pe awon molaika wa lori ile aye, ti won n rin kiri, (ti won n gbe lori ile) pelu ifayabale, A iba so molaika kan kale fun won lati inu sanmo (lati je) Ojise.”
ﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆﰇﰈﰉﰊﰋ
So pe: “Allahu to ni Elerii laaarin emi ati eyin. Dajudaju O n je Onimo-ikoko, Oluriran nipa awon erusin Re.”
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰ
Enikeni ti Allahu ba fi mona (’Islam), oun ni olumona. Enikeni ti O ba si lona, o o nii ri awon oluranlowo kan fun won leyin Re. Ati pe A maa ko won jo ni Ojo Ajinde ni idojubole. (Won yoo di) afoju, ayaya ati odi. Ina Jahanamo ni ibugbe won. Nigbakigba ti Ina ba jo loole, A maa salekun jijo (re) fun won
ﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿ
Iyen ni esan won nitori pe, won sai gbagbo ninu awon ayah Wa. Won si wi pe: “Se nigba ti a ba ti di egungun, ti a si ti jera, se won tun maa gbe wa dide ni eda titun ni?”
ﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘ
Se won ko ri i pe dajudaju Allahu, Eni ti O seda awon sanmo ati ile lagbara lati seda iru won (miiran)? O si maa fun won ni gbedeke akoko kan, ti ko si iyemeji ninu re. Sibesibe awon alabosi ko lati gba afi atako sa
ﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨ
So pe: “Ti o ba je pe eyin l’e ni ikapa lori awon ile oro ike Oluwa mi ni, nigba naa eyin iba diwo mo on ni ti iberu osi. Eniyan si je ahun
ﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝ
Dajudaju A fun (Anabi) Musa ni awon ami mesan-an t’o yanju. Bi awon omo ’Isro’il leere wo. Ranti, nigba ti o de odo won, Fir‘aon wi fun un pe: “Dajudaju emi lero pe eleedi ni o, Musa.”
ﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭ
(Anabi Musa) so pe: “O kuku mo pe ko si eni ti o so awon (ami) wonyi kale bi ko se Oluwa awon sanmo ati ile; (o si je) ami t’o yanju. Dajudaju emi naa lero pe eni iparun ni o, Fir‘aon.”
ﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷ
Nitori naa, (Fir‘aon) fe ko won laya je lori ile. A si te oun ati awon t’o wa pelu re ri patapata
ﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆ
A si so fun awon omo ’Isro’il leyin (iku) re pe: “E maa gbe ori ile naa. Sugbon nigba ti Adehun Ikeyin ba de, A oo mu gbogbo yin wa ni apapo (ni ojo esan)
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛ
A so al-Ƙur’an kale pelu ododo. O si sokale pelu ododo. A ko si ran o nise bi ko se pe (ki o je) oniroo-idunnu ati olukilo
ﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥ
Ati pe al-Ƙur’an, A salaye re (fun o) nitori ki o le ke e fun awon eniyan pelu pelepele. A si so o kale diedie. orisi isokale meji l’o wa fun al-Ƙur’an. Isokale kiini ni isokale olodidi lati inu Laohul-Mahfuth sinu sanmo ile aye. Isokale yii l’o sele ninu oru Laelatul-ƙodr. Eyi l’o jeyo ninu surah al-Baƙorah; 2:185 surah ad-Dukan; 44:3 ati surah al-Ƙodr’ 97:1. Isokale keji ni isokale onidiedie lati inu sanmo ile aye sori ile aye. Eyi sele fun onka odun metalelogun. Isokale yii ni ayah yii n so nipa re
ﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹ
So pe: “E gba al-Ƙur’an gbo tabi e o gba a gbo, dajudaju awon ti A fun ni imo siwaju (isokale) re, nigba ti won ba n ke e fun won, won yoo doju bole, ti won n fori kanle (fun Allahu)
ﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂ
Won n so pe: “Mimo ni fun Oluwa wa. Dajudaju adehun Oluwa wa maa wa si imuse ni.”
ﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉ
Won n doju bole, ti won n sunkun (fun Allahu. Al-Ƙur’an) si n salekun iteriba fun won
ﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢ
So pe: “E pe Allahu tabi e pe ar-Rahmon (Ajoke-aye).” Eyikeyii ti e ba fi pe E (ninu re), sebi tiRe ni awon oruko t’o dara julo. Ma se kigbe lori irun (ati adua) re. Ma si se wa ni idake roro. Wa ona saaarin mejeeji yen
ﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚ
Ki o si so pe: "Gbogbo ope n je ti Allahu, Eni ti ko fi eni kan se omo. Ko si ni akegbe ninu ijoba. Ko yepere ambosibosi pe O maa wa bukata si oluranlowo.” Gbe titobi fun Un gan-an
Al-Kur'an
Tuesday, August 18, 2026
Don't forget us in your sincere prayers







