Surah Muhammad pdf — Gbà (Yorùbá)
Surah Muhammad pdf Yorùbá — Gbà Surah Muhammad Itumọ. Surah Muhammad (Medinan) 38 Ẹsẹ.
Related
- Surah Muhammad ItumọYorùbá
- Surah Muhammad mp3Gbọ
- Quran Index Yorùbá114
More Surah PDF
Surah Muhammad

ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙ
47:1
Awon t’o sai gbagbo, ti won tun seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Allahu, (Allahu) maa so ise won dofo
ﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬ
47:2
Awon t’o gbagbo ni ododo, ti won se awon ise rere, ti won tun gbagbo ninu ohun ti Won sokale fun (Anabi) Muhammad, ohun si ni ododo lati odo Oluwa won, (Allahu) maa pa awon (ise) aburu won re, O si maa se atunse oro won si daadaa
ﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀ
47:3
Iyen nitori pe dajudaju awon t’o sai gbagbo tele iro. Ati pe dajudaju awon t’o gbagbo tele ododo lati odo Oluwa won. Bayen ni Allahu se n fi apejuwe won lele fun awon eniyan
ﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪ
47:4
Nitori naa, nigba ti e ba pade awon t’o sai gbagbo (loju ogun esin), e maa be won lorun nso titi di igba ti e maa fi bori won. (Ti e ba segun) ki e de won nigbekun. Leyin naa, e le tu won sile ni ofe tabi ki e tu won sile pelu owo itusile titi (okunfa) ogun esin yoo fi kase nile. Iyen (wa bee). Ti o ba je pe Allahu ba fe, iba gbesan funra Re (lai nii la ogun jija lo), sugbon nitori ki O le dan apa kan yin wo lara apa kan ni. Awon musulumi ti won si pa si oju ogun esin, Allahu ko nii so ise won dofo
ﮫﮬﮭﮮ
47:5
O maa to won sona. O si maa tun oro won se si daadaa
ﮯﮰﮱﯓﯔ
47:6
O maa fi won wo inu Ogba Idera, eyi ti O ti fi mo won
ﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞ
47:7
Eyin ti e gbagbo ni ododo, ti e ba ran (esin) Allahu lowo, (Allahu) maa ran yin lowo. O si maa mu ese yin duro sinsin
ﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥ
47:8
Awon t’o sai gbagbo, egbe ni fun won. (Allahu) si maa ba ise won je
ﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮ
47:9
Iyen nitori pe dajudaju won korira ohun ti Allahu sokale. Nitori naa, (Allahu) si ba ise won je
ﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂ
47:10
Se won ko rin kiri lori ile ki won wo bi ikangun awon t’o siwaju won se ri? Allahu pa won re. Iru re tun wa fun awon alaigbagbo
ﰃﰄﰅﰆﰇﰈﰉﰊﰋﰌﰍﰎ
47:11
Iyen nitori pe dajudaju Allahu ni Oluranlowo awon t’o gbagbo ni ododo. Dajudaju awon alaigbagbo, ko si oluranlowo kan fun won
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨ
47:12
Dajudaju Allahu yoo fi awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere wo inu awon Ogba Idera, eyi ti awon odo n san ni isale re. Awon t’o si sai gbagbo, awon n gbadun, won si n je (kiri) gege bi awon eran-osin se n je (kiri). Ina si ni ibugbe fun won
ﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷ
47:13
Meloo meloo ninu awon (ara) ilu ti o lagbara ju (ara) ilu re, ti o le o jade, ti A si ti pa won re. Ko si si alaranse kan fun won
ﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅ
47:14
Nje eni ti o wa lori eri t’o yanju lati odo Oluwa re, se o da bi eni ti won se ise aburu re ni oso fun, ti won si tele ife-inu won
ﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖ
47:15
Apejuwe Ogba Idera eyi ti Won se ni adehun fun awon oluberu Allahu (niyi): awon omi odo wa ninu re ti ko nii yi pada ati awon odo wara ti adun re ko nii yi pada ati awon odo oti didun fun awon t’o maa mu un ati awon odo oyin mimo. Awon oniruuru eso wa fun won ninu re ati aforijin lati odo Oluwa won. (Se eni ti o wa ninu Ogba Idera yii) da bi olusegbere ninu Ina bi, ti won n fun won ni omi gbigbona mu, ti o si maa ja awon ifun won putuputu
ﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰ
47:16
O wa ninu won, eni ti o teti si oro re titi di igba ti won ba jade kuro ni odo re tan, won yo si wi fun awon onimo-esin pe: "Ki l’o so leee kan na?" Awon wonyen ni awon ti Allahu ti di okan won pa. Won si tele ife-inu won
ﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷ
47:17
Awon t’o si tele imona, (Allahu) salekun imona fun won. O si maa fun won ni iberu won (ninu Allahu)
ﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆﰇﰈﰉ
47:18
Se won n reti kini kan bi ko se Akoko naa, ti o maa de ba won ni ojiji? Awon ami re kuku ti de. Nitori naa, bawo ni iranti (yo se wulo fun) won nigba ti o ba de ba won
ﰊﰋﰌﰍﰎﰏﰐﰑﰒﰓﰔﰕﰖﰗﰘﰙ
47:19
Nitori naa, mo pe dajudaju ko si olohun ti ijosin to si afi Allahu. Ki o si toro aforijin fun ese re ati fun awon onigbagbo ododo lokunrin ati awon onigbagbo ododo lobinrin. Allahu mo lilo-bibo yin ati ibusinmi yin
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮ
47:20
Awon t’o gbagbo ni ododo n so pe: "Ki ni ko je ki Won so surah kan kale?" Nigba ti won ba so surah alainipon-na kale, ti won si so oro ija ogun esin ninu re, iwo yoo ri awon ti arun wa ninu okan won, ti won yoo maa wo o ni wiwo bi eni pe won ti daku lo ponrangandan. Ohun ti o si dara julo fun won
ﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼ
47:21
ni itele ase (Allahu) ati (siso) oro rere. Nigba ti ogun esin si ti di dandan, won iba ni igbagbo ododo ninu Allahu, iba dara julo fun won
ﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇ
47:22
Nje ko sunmo ti eyin (alaisan okan wonyi) ba de’po ase, pe e o nii sebaje lori ile ati pe e o nii ja okun-ibi yin
ﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏ
47:23
Awon wonyen ni awon ti Allahu ti sebi le. Nitori naa, O di won leti pa. O si fo iriran won
ﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗ
47:24
Se won ko nii ronu nipa al-Ƙur’an ni tabi awon agadagodo ti wa lori okan won ni
ﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨ
47:25
Dajudaju awon t’o peyin da (si ’Islam) leyin ti imona ti foju han si won, Esu lo se isina ni oso fun won. O si fun won ni ireti asan nipa emi gigun
ﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚ
47:26
Iyen nitori pe (awon alaisan okan) n so fun awon t’o korira ohun ti Allahu sokale pe: "Awa yoo tele yin ninu apa kan oro naa." Allahu si mo asiri won
ﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢ
47:27
Bawo ni (o se maa ri) nigba ti awon molaika ba gba emi won, ti won yo si maa gba oju won ati eyin won
ﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭ
47:28
Iyen nitori pe dajudaju won tele ohun ti o bi Allahu ninu. Won si tun korira iyonu Re. Nitori naa, Allahu ti ba awon ise won je
ﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹ
47:29
Tabi awon ti arun wa ninu okan won n lero pe Allahu ko nii se afihan adisokan buruku won ni
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟ
47:30
Ati pe ti A ba fe Awa iba fi won han o, iwo iba si mo won pelu ami won. Dajudaju iwo yoo mo won nipa ipekoro-soro (won). Allahu si mo awon ise (owo) yin
ﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨ
47:31
Dajudaju A maa dan yin wo titi A fi maa safi han awon olujagun-esin ati awon onisuuru ninu yin. A si maa gbidanwo awon iro yin
ﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾ
47:32
Dajudaju awon t’o sai gbagbo, ti won si seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Allahu, ti won tun ko inira ba Ojise Allahu leyin ti imona ti foju han si won, won ko le ko inira kini kan ba Allahu. (Allahu) yo si ba ise won je
ﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊ
47:33
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e tele (oro) Allahu, e tele (oro) Ojise naa, ki e si ma se ba awon ise yin je
ﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚ
47:34
Dajudaju awon t’o sai gbagbo, ti won si seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Allahu, leyin naa ti won ku nigba ti won je alaigbagbo, Allahu ko nii forijin won
ﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧ
47:35
E ma se kaaare, ki e si ma se pepe fun kosogunmo, nigba ti e ba n leke lowo. Allahu wa pelu yin; ko si nii ko adinku ba esan awon ise yin
ﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗ
47:36
Ere ati iranu ni isemi aye. (Amo) ti e ba gbagbo (ninu Allahu), ti e si beru (Re), O maa fun yin ni awon esan yin. Ko si nii beere awon dukia yin (pe ki e fi gbogbo re yo Zakah)
ﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞ
47:37
Ti (Allahu) ba beere re ni owo yin (pe ki e fi gbogbo re yo Zakah), ti O si wonkoko mo yin, e maa sahun. O si maa mu arun okan yin jade (asiri yin yo si tu sita)
ﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿ
47:38
Eyin naa ma niwonyi ti won n pe lati nawo fun esin Allahu. Sugbon eni t’o n sahun wa ninu yin. Enikeni ti o ba sahun, o se e fun emi ara re. Allahu ni Oloro. Eyin si ni alaini. Ti e ba gbunri, (Allahu) maa fi ijo miiran paaro yin. Leyin naa, won ko si nii da bi iru yin
Al-Kur'an
Wednesday, September 9, 2026
Don't forget us in your sincere prayers







