PDF —
29 Ẹsẹ Medinan PDF
Built right in your browser — download starts automatically

Surah Al-Hadid pdf — Gbà (Yorùbá)

Surah Al-Hadid pdf Yorùbá — Gbà Surah Al-Hadid Itumọ. Surah Al-Hadid (Medinan) 29 Ẹsẹ.



29 Ẹsẹ · Medinan · Yorùbá
bismillah
ﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥ
57:1 Ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ile n safomo fun Allahu. Oun si ni Alagbara, Ologbon
ﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳ
57:2 TiRe ni ijoba awon sanmo ati ile. O n so eda di alaaye. O si n so eda di oku. Oun ni Alagbara lori gbogbo nnkan
ﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾ
57:3 Oun ni Akoko ati Ikeyin. O han (pelu ami bibe Re). O si pamo (fun gbogbo oju nile aye). Oun ni Onimo nipa gbogbo nnkan
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸ
57:4 Oun ni Eni ti O seda awon sanmo ati ile fun ojo mefa. Leyin naa, O gunwa si ori Ite-ola. O mo nnkan t’o n wo inu ile ati nnkan t’o n jade lati inu re, ati nnkan t’o n sokale lati inu sanmo ati nnkan t’o n gunke sinu re. Ati pe O wa pelu yin ni ibikibi ti e ba wa (pelu imo Re). Allahu si ni Oluriran nipa ohun ti e n se nise
ﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂ
57:5 TiRe ni ijoba awon sanmo ati ile. Odo Allahu si ni won maa seri awon oro eda pada si
ﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐ
57:6 O n ti oru bo inu osan. O si n ti osan bo inu oru. Oun si ni Onimo nipa ohun t’o wa ninu igba-aya eda
ﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡ
57:7 E gbagbo ninu Allahu ati Ojise Re. Ki e si na ninu ohun ti O fi yin se arole lori re. Nitori naa, awon t’o gbagbo ni ododo ninu yin, ti won si nawo (si oju ona esin), esan t’o tobi wa fun won
ﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱ
57:8 Ki ni o mu yin ti eyin ko fi nii gba Allahu gbo ni ododo? Ojise si n pe yin nitori ki e le gba Oluwa yin gbo. Allahu si ti gba adehun lowo yin, ti eyin ba je onigbagbo ododo
ﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥ
57:9 Oun ni Eni t’O n so awon ayah t’o yanju kale fun erusin Re nitori ki o le mu yin kuro ninu awon okunkun wa sinu imole. Dajudaju Allahu ni Alaaanu, Asake-orun fun yin
ﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆﰇﰈﰉﰊﰋﰌﰍﰎﰏ
57:10 Ki ni o mu yin ti eyin ko fi nii nawo fun esin Allahu? Ti Allahu si ni ogun awon sanmo ati ile. Eni ti o nawo siwaju sisi ilu Mokkah, ti o tun jagun esin, ko dogba laaarin yin (si awon miiran). Awon wonyen ni esan won tobi julo si ti awon t’o nawo leyin igba naa, ti won tun jagun esin. Eni kookan si ni Allahu s’adehun esan rere fun. Allahu si ni Alamotan nipa ohun ti e n se nise
ﰐﰑﰒﰓﰔﰕﰖﰗﰘﰙﰚﰛﰜ
57:11 Ta ni eni ti o maa ya Allahu ni dukia t’o dara, O si maa sadipele re fun un. Esan alapon-onle si tun wa fun un
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩ
57:12 Ni ojo ti o maa ri awon onigbagbo ododo lokunrin ati onigbagbo ododo lobinrin, ti imole won yoo maa tan niwaju won ati ni owo otun won, (A oo so pe:) "Iro idunnu yin ni oni ni awon Ogba Idera kan ti awon odo n san ni isale re." Olusegbere ni yin ninu re. Iyen si ni erenje nla
ﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆ
57:13 Ni ojo ti awon sobe-selu musulumi lokunrin ati awon sobe-selu musulumi lobinrin yoo wi fun awon t’o gbagbo pe: "E duro fun wa na, e je ki a mu ninu imole yin." A oo so fun won pe: "E pada s’eyin yin, ki e lo mu imole.” Won si maa fi ogiri kan, t’o ni ilekun saarin won. Ike wa ninu re, iya si wa ni ode re ni owo iwaju re
ﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜ
57:14 (Awon sobe-selu musulumi) yoo pe (awon onigbagbo ododo) pe: "Se awa ko ti wa pelu yin ni?" Won so pe: "Rara, sugbon e ko iyonu ba emi ara yin (nipa isobe-selu), e reti iparun (wa), e si siyemeji (si ododo). Awon ife-okan ati iro oro si tan yin je titi ase Allahu fi de. Ati pe (Esu) eletan si tan yin je nipa Allahu
ﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯ
57:15 Nitori naa, ni oni Awa ko nii gba itanran kan ni owo eyin ati awon t’o sai gbagbo. Ina ni ibugbe yin. Ohun l’o to si yin. Ikangun naa si buru
ﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯ
57:16 Se akoko ko ti i to fun awon t’o gbagbo ni ododo pe ki okan won ro fun iranti Allahu ati ohun t’o sokale ninu ododo (iyen, al-Ƙur’an). Ki won si ma se da bi awon ti A fun ni Tira ni isaaju; igba pe lori won, okan won ba le. Opolopo ninu won si ni obileje
ﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾ
57:17 E mo pe dajudaju Allahu l’O n so ile di aye leyin ti ile ti ku. A kuku ti salaye awon ayah naa nitori ki e le se laakaye
ﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆﰇﰈﰉﰊﰋ
57:18 Dajudaju awon olutore lokunrin ati awon olutore lobinrin, ti won tun ya Allahu ni dukia t’o dara, (Allahu) yoo sadipele re fun won. Esan alapon-onle si wa fun won
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧ
57:19 Awon t’o gbagbo ninu Allahu ati Ojise Re, awon wonyen ni awon olododo ati elerii ni odo Oluwa won. Esan won ati imole won wa fun won. Awon t’o si sai gbagbo, ti won tun pe awon ayah Wa niro, awon wonyen ni ero inu ina Jehim
ﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒ
57:20 E mo pe dajudaju isemi aye yii je ere, iranu, oso, sise iyanran laaarin ara yin ati wiwa opo dukia ati omo. (Iwonyi) da bi ojo (t’o mu irugbin jade). Irugbin re si n jo awon alaigbagbo loju. Leyin naa, o maa gbe. O si maa ri i ni pipon. Leyin naa, o maa di rirun (ti ategun maa fe danu). Iya lile ati aforijin pelu iyonu lati odo Allahu si wa ni orun. Ki si ni isemi aye yii bi ko se igbadun etan
ﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮ
57:21 E yara lo sibi aforijin lati odo Oluwa yin ati Ogba Idera ti fife re da bi fife sanmo ati ile. Won pa a lese sile de awon t’o gbagbo ninu Allahu ati awon Ojise Re. Iyen ni oore ajulo Allahu ti O n fun eni ti O ba fe. Allahu si ni Oloore nla
ﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦ
57:22 Adanwo kan ko nii sele ni ori ile tabi (ki o sele) si eyin ayafi ki o ti wa ninu Tira siwaju ki A t’o da eda. Dajudaju iyen rorun fun Allahu
ﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷ
57:23 (Isele n to kadara leyin) nitori ki e ma se banuje lori ohun ti o ba bo fun yin ati nitori ki e ma se yo ayoju lori ohun ti O ba fun yin. Allahu ko si nifee si gbogbo onigbeeraga, onifaari
ﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅ
57:24 Awon t’o n sahun, ti won si n pa awon eniyan lase ahun sise (ki won mo pe) enikeni ti o ba peyinda (ti ko nawo fun esin), dajudaju Allahu, Oun ni Oloro, Olope
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯ
57:25 Dajudaju A fi awon eri t’o yanju ran awon Ojise Wa. A so Tira kale fun won ati osuwon nitori ki awon eniyan le ri deede se (laaarin ara won). A tun so irin kale. Ohun ijagun t’o lagbara ati awon anfaani wa ninu re fun awon eniyan nitori ki Allahu le safi han eni t’o n ran (esin) Re ati Ojise Re lowo ni ikoko. Dajudaju Allahu ni Alagbara, Olubori
ﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀ
57:26 Dajudaju A fi ise ran (Anabi) Nuh ati (Anabi) ’Ibrohim. A fi ipo Anabi sinu awon aromodomo awon mejeeji pelu Tira (ti A fun won). Olumona wa ninu won. Opolopo ninu won si ni obileje
ﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬ
57:27 Leyin naa, A fi awon Ojise Wa tele oripa won. A si mu ‘Isa omo Moryam tele won. A fun un ni al-’Injil. A fi aanu ati ike sinu okan awon t’o tele e. Asa adawa (lai loko tabi lai laya) won se adadaale re ni. A o se e ni oran-anyan le won lori. (Won ko si se adawa fun kini kan) bi ko se lati fi wa iyonu Allahu. Won ko si ri i so bi o se ye ki won so o. Nitori naa, A fun awon t’o gbagbo ni ododo ninu won ni esan won. Opolopo ninu won si ni obileje
ﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤ
57:28 Eyin ti e gbagbo ni ododo, e beru Allahu, ki e si gba Ojise Re gbo ni ododo, nitori ki (Allahu) le fun yin ni ilopo meji ninu ike Re ati nitori ki O le fun yin ni imole ti e oo maa fi rin ati nitori ki O le fori jin yin. Allahu si ni Alaforijin, Asake-orun
ﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼ
57:29 (Allahu se bee fun yin) nitori ki awon ahlu-l-kitab le mo pe awon ko ni agbara lori kini kan ninu oore ajulo Allahu. Ati pe dajudaju oore ajulo, owo Allahu l’o wa. O si n fun eni ti O ba fe. Allahu si ni Oloore nla

Al-Kur'an


Wednesday, September 9, 2026

Don't forget us in your sincere prayers