La sourate Saad en Yoruba
Sod. (Allahu bura pelu) al-Ƙur’an, tira iranti |
Sibesibe awon t’o sai gbagbo wa ninu igberaga ati iyapa (ododo) |
كَمْ أَهْلَكْنَا مِن قَبْلِهِم مِّن قَرْنٍ فَنَادَوا وَّلَاتَ حِينَ مَنَاصٍ(3) Meloo meloo ninu awon iran ti A ti pare siwaju won. Nigba naa, won kigbe too nigba ti ko si ibusasi kan |
وَعَجِبُوا أَن جَاءَهُم مُّنذِرٌ مِّنْهُمْ ۖ وَقَالَ الْكَافِرُونَ هَٰذَا سَاحِرٌ كَذَّابٌ(4) Won seemo pe olukilo kan ninu won wa ba won. Awon alaigbagbo si wi pe: "Eyi ni opidan, opuro |
أَجَعَلَ الْآلِهَةَ إِلَٰهًا وَاحِدًا ۖ إِنَّ هَٰذَا لَشَيْءٌ عُجَابٌ(5) Se o maa so awon orisa di Olohun Okan soso ti A oo maa josin fun ni? Dajudaju eyi ma ni nnkan iyanu |
Awon asiwaju ninu won si lo (kaakiri lati wi fun awon omoleyin won) pe: "E maa ba (iborisa) lo, ki e si duro sinsin ti awon orisa yin. Dajudaju eyi (jije okan soso Allahu) ni nnkan ti won n gba lero (lati fi pa awon orisa yin run) |
مَا سَمِعْنَا بِهَٰذَا فِي الْمِلَّةِ الْآخِرَةِ إِنْ هَٰذَا إِلَّا اخْتِلَاقٌ(7) Awa ko gbo eyi ninu esin ikeyin (iyen, esin kristieniti) . Eyi ko je kini kan bi ko se adapa iro |
Se Won so Iranti kale fun un laaarin wa ni?" Rara, won wa ninu iyemeji nipa Iranti Mi (ti Mo sokale ni). Rara, won ko ti i to iya Mi wo ni |
أَمْ عِندَهُمْ خَزَائِنُ رَحْمَةِ رَبِّكَ الْعَزِيزِ الْوَهَّابِ(9) Tabi (se) awon ni won ni awon apoti oro Oluwa re, Alagbara, Olore |
أَمْ لَهُم مُّلْكُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَمَا بَيْنَهُمَا ۖ فَلْيَرْتَقُوا فِي الْأَسْبَابِ(10) Tabi tiwon ni ijoba awon sanmo ati ile ati ohun ti n be laaarin mejeeji? Ti o ba ri bee, ki won wa awon ona lati fi gunke wa (ba Wa) |
A maa segun omo ogun t’o wa nibe yen ninu omo ogun onijo |
كَذَّبَتْ قَبْلَهُمْ قَوْمُ نُوحٍ وَعَادٌ وَفِرْعَوْنُ ذُو الْأَوْتَادِ(12) Awon ijo Nuh, ijo ‘Ad ati Fir‘aon, eleekan, won pe ododo niro siwaju won |
وَثَمُودُ وَقَوْمُ لُوطٍ وَأَصْحَابُ الْأَيْكَةِ ۚ أُولَٰئِكَ الْأَحْزَابُ(13) Ijo Thamud, ijo Lut ati awon ara ’Aekah, awon wonyen (tun ni) awon ijo (t’o pe ododo niro) |
Ko si eni kan ninu won ti ko pe awon Ojise ni opuro. Nitori naa, iya Mi si ko le won lori |
وَمَا يَنظُرُ هَٰؤُلَاءِ إِلَّا صَيْحَةً وَاحِدَةً مَّا لَهَا مِن فَوَاقٍ(15) Awon wonyi ko reti kini kan tayo igbe eyo kan, ti ko nii si idapada (tabi idaduro) kan fun un (t’o ba de) |
وَقَالُوا رَبَّنَا عَجِّل لَّنَا قِطَّنَا قَبْلَ يَوْمِ الْحِسَابِ(16) Won wi pe: "Oluwa wa, yara fi iwe ise wa (ati esan wa) le wa lowo siwaju Ojo isiro-ise |
اصْبِرْ عَلَىٰ مَا يَقُولُونَ وَاذْكُرْ عَبْدَنَا دَاوُودَ ذَا الْأَيْدِ ۖ إِنَّهُ أَوَّابٌ(17) Se suuru lori nnkan ti won n so. Ki o si seranti itan erusin Wa, (Anabi) Dawud, alagbara. Dajudaju o je oluronupiwada |
إِنَّا سَخَّرْنَا الْجِبَالَ مَعَهُ يُسَبِّحْنَ بِالْعَشِيِّ وَالْإِشْرَاقِ(18) Dajudaju Awa te awon apata lori ba ti won n se afomo pelu re (fun Allahu) ni asale ati nigba ti oorun ba yo |
Ati awon eye naa, A ko won jo fun un. Ikookan (won) n tele ase re (lati safomo fun Allahu) |
وَشَدَدْنَا مُلْكَهُ وَآتَيْنَاهُ الْحِكْمَةَ وَفَصْلَ الْخِطَابِ(20) Ati pe A fun ijoba re ni agbara. A si fun un ni ipo Anabi ati eko oro ati idajo |
۞ وَهَلْ أَتَاكَ نَبَأُ الْخَصْمِ إِذْ تَسَوَّرُوا الْمِحْرَابَ(21) Nje iro awon onija ti de odo re; nigba ti won pon ogiri ile ijosin |
Nigba ti won wole to (Anabi) Dawud, eru ba a lati ara won. Won so pe: "Ma se beru. Onija meji (ni wa). Apa kan wa tayo enu-ala si apa kan. Nitori naa, dajo laaarin wa pelu ododo. Ma sabosi. Ki o si to wa si ona taara |
Dajudaju eyi ni arakunrin mi. O ni abo ewure mokandin-logorun-un. Emi si ni abo ewure eyo kan. O si so pe: "Fa a le mi lowo. O si bori mi ninu oro |
(Anabi Dawud) so pe: "O ti sabosi si o nipa bibeere abo ewure tire mo awon abo ewure tire. Dajudaju opolopo ninu awon olubada-nnkanpo, apa kan won maa n tayo enu-ala lori apa kan afi awon t’o ba gbagbo ni ododo, ti won si se ise rere. Die si ni won. (Anabi) Dawud si mo daju pe A kan fi (ibeere naa) sadanwo fun oun ni. Nitori naa, o toro aforijin lodo Oluwa re (nipa aiteti gbo oro lenu eni- afesunkan). O doju bole lati fori kanle. O si ronu piwada (sodo Allahu). onka iyawo won le po ni onka ki i se ni ti igbadun adun-ara bi ko se pe Allahu (subhanahu wa ta’ala) fe ko Anabi Dawud (’alaehi-ssolatu wa-ssalam) ni eko igbejo nitori pe Allahu (subhanahu wa ta’ala) fe fi se adajo laaarin awon ijo re. Aiteti gbo oro lenu eni-afesunkan ni asise t’o sele si Anabi Dawud (’alaehi-ssolatu wa-ssalam). Eyi naa si ni ohun ti o toro aforijin Olohun fun |
فَغَفَرْنَا لَهُ ذَٰلِكَ ۖ وَإِنَّ لَهُ عِندَنَا لَزُلْفَىٰ وَحُسْنَ مَآبٍ(25) Nitori naa, A saforijin iyen fun un. Dajudaju isunmo (Wa) ati abo rere si wa fun un lodo Wa |
(Anabi) Dawud, dajudaju Awa se o ni arole lori ile. Nitori naa, dajo laaarin awon eniyan pelu ododo. Ma se tele ife-inu nitori ki o ma baa sina kuro loju ona (esin) Allahu. Dajudaju awon t’o n sonu kuro ninu esin Allahu, iya lile wa fun won nitori pe won gbagbe Ojo isiro-ise |
A ko seda sanmo, ile ati ohunkohun t’o wa laaarin mejeeji pelu iro. (Iro), iyen ni ero awon t’o sai gbagbo. Nitori naa, egbe ni fun awon t’o sai gbagbo ninu Ina |
Se ki A se awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere bi (A o ti se) awon obileje lori ile? Tabi se ki A se awon oluberu (Mi bi A o ti se) awon asebi |
كِتَابٌ أَنزَلْنَاهُ إِلَيْكَ مُبَارَكٌ لِّيَدَّبَّرُوا آيَاتِهِ وَلِيَتَذَكَّرَ أُولُو الْأَلْبَابِ(29) (Eyi ni) Tira ibukun ti A so kale fun o nitori ki won le ronu jinle nipa awon ayah re ati nitori ki awon onilaakaye le lo iranti |
وَوَهَبْنَا لِدَاوُودَ سُلَيْمَانَ ۚ نِعْمَ الْعَبْدُ ۖ إِنَّهُ أَوَّابٌ(30) A fi (Anabi) Sulaemon ta (Anabi) Dawud lore. Erusin rere ni. Dajudaju oluseri sodo (Allahu) ni (nipa ironupiwada) |
إِذْ عُرِضَ عَلَيْهِ بِالْعَشِيِّ الصَّافِنَاتُ الْجِيَادُ(31) (Ranti) nigba ti won ko awon esin akawooja-leri asaretete wa ba a ni irole |
فَقَالَ إِنِّي أَحْبَبْتُ حُبَّ الْخَيْرِ عَن ذِكْرِ رَبِّي حَتَّىٰ تَوَارَتْ بِالْحِجَابِ(32) o so pe: "Dajudaju emi feran ife ohun rere (iyen, awon esin naa) dipo iranti Oluwa Mi (iyen, irun ‘Asr) titi oorun fi wo |
رُدُّوهَا عَلَيَّ ۖ فَطَفِقَ مَسْحًا بِالسُّوقِ وَالْأَعْنَاقِ(33) E da won pada sodo mi. "O si bere si i fi ida ge won ni ese ati ni orun |
وَلَقَدْ فَتَنَّا سُلَيْمَانَ وَأَلْقَيْنَا عَلَىٰ كُرْسِيِّهِ جَسَدًا ثُمَّ أَنَابَ(34) Dajudaju A dan (Anabi) Sulaemon wo. A ju abara kan sori aga re. Leyin naa, (Anabi Sulaemon) seri pada (pelu ironupiwada). Anabi Sulaemon (’alaehi-ssolatu wa-ssalam) ni iyawo t’o to ogorun-un labe ofin eto (iyen ni pe Allahu s.w.t. l’O se e ni eto fun un). Anabi Sulaemon (’alaehi-ssolatu wa-ssalam) si fi Allahu bura ni ojo kan pe ki i se ara oruka Anabi Sulaemon (’alaehi-ssolatu wa-ssalam) ni awo Anabi Sulaemon wa. Bawo wa ni o se maa je pe nipase oruka Anabi Sulaemon ni awo re fi maa kuro lara re si ara esu alujannu nigba ti Anabi Sulaemon ki i se opidan? Anabi Sulaemon ko si fi oruka joba ambosibosi pe nigba ti ko ba si oruka re lowo re l’o maa fun elomiiran ni aye lati di oba! E tun wo itose-oro fun surah al-Baƙorah; 2:102. W-Allahu ’a‘lam |
O so pe: "Oluwa mi, fori jin mi. Ki O si ta mi ni ore ijoba kan eyi ti ko nii to si eni kan kan mo leyin mi. Dajudaju Iwo, Iwo ni Olore |
فَسَخَّرْنَا لَهُ الرِّيحَ تَجْرِي بِأَمْرِهِ رُخَاءً حَيْثُ أَصَابَ(36) Nitori naa, A te ategun ba fun un. O n fe pelu ase re ni irorun sibi ti o ba fe |
Ati awon esu alujannu; gbogbo awon omole ati awon awakusa (ni A te ba fun un) |
Ati awon (alujannu) miiran ti won fi ewon de mole (A te won ba fun un) |
هَٰذَا عَطَاؤُنَا فَامْنُنْ أَوْ أَمْسِكْ بِغَيْرِ حِسَابٍ(39) Eyi ni ore Wa. Nitori naa, fi tore tabi ki o mu un dani lai la isiro lo (lorun) |
Dajudaju isunmo (Wa) ati abo rere si wa fun un ni odo Wa |
وَاذْكُرْ عَبْدَنَا أَيُّوبَ إِذْ نَادَىٰ رَبَّهُ أَنِّي مَسَّنِيَ الشَّيْطَانُ بِنُصْبٍ وَعَذَابٍ(41) Seranti erusin Wa, (Anabi) ’Ayyub. Nigba ti o pe Oluwa re (pe): "Dajudaju Esu ti ko inira (aisan) ati iya ba mi |
ارْكُضْ بِرِجْلِكَ ۖ هَٰذَا مُغْتَسَلٌ بَارِدٌ وَشَرَابٌ(42) (Molaika so fun un pe): "Fi ese re janle. Eyi ni omi iwe tutu ati omi mimu (fun iwosan re) |
وَوَهَبْنَا لَهُ أَهْلَهُ وَمِثْلَهُم مَّعَهُمْ رَحْمَةً مِّنَّا وَذِكْرَىٰ لِأُولِي الْأَلْبَابِ(43) A si ta a lore awon ara ile re (pada) ati iru won pelu won. (O je) ike lati odo Wa ati iranti fun awon onilaakaye |
Fi owo re mu idi igi koriko tutu ki o fi lu (iyawo) re. Ma se yapa ibura re. Dajudaju Awa ri (’Ayyub) ni onisuuru. Erusin rere ni. Dajudaju oluseri si odo Allahu ni (nipa ironupiwada) |
وَاذْكُرْ عِبَادَنَا إِبْرَاهِيمَ وَإِسْحَاقَ وَيَعْقُوبَ أُولِي الْأَيْدِي وَالْأَبْصَارِ(45) Seranti awon erusin Wa, (Anabi) ’Ibrohim, ’Ishaƙ ati Ya‘ƙub; awon alagbara, oluriran (nipa esin) |
Dajudaju Awa sa won lesa pelu esa kan; iranti Ile Ikeyin |
وَإِنَّهُمْ عِندَنَا لَمِنَ الْمُصْطَفَيْنَ الْأَخْيَارِ(47) Dajudaju won wa ninu awon eni esa, eni rere julo ni odo Wa |
وَاذْكُرْ إِسْمَاعِيلَ وَالْيَسَعَ وَذَا الْكِفْلِ ۖ وَكُلٌّ مِّنَ الْأَخْيَارِ(48) Seranti (awon Anabi) ’Ismo‘il, al-Yasa‘ ati Thul-Kifl. Ikookan won wa ninu awon eni rere julo |
Eyi ni iranti. Ati pe dajudaju abo rere wa fun awon oluberu (Allahu) |
Awon Ogba Idera gbere (ni). Won si maa si awon ilekun re sile fun won |
مُتَّكِئِينَ فِيهَا يَدْعُونَ فِيهَا بِفَاكِهَةٍ كَثِيرَةٍ وَشَرَابٍ(51) Won yoo rogboku ninu re. Won yoo maa beere fun awon eso pupo ati ohun mimu ninu re |
Awon obinrin ti ki i wo elomiiran, ti ojo ori won ko jura won lo yo si wa ni odo won |
Eyi ni ohun ti Won n se ni adehun fun yin fun Ojo isiro-ise |
Dajudaju eyi ni arisiki Wa. Ko si nii tan |
Eyi (ri bee). Ati pe dajudaju abo buruku ni ti awon alagbeere (si Allahu) |
Ina Jahanamo ni won yo wo. O si buru ni ibugbe |
Eyi (ri bee). Nitori naa, ki won to o wo; omi gbigbona ati awoyunweje |
Orisirisi (iya) miiran bi iru re (tun wa fun won) |
هَٰذَا فَوْجٌ مُّقْتَحِمٌ مَّعَكُمْ ۖ لَا مَرْحَبًا بِهِمْ ۚ إِنَّهُمْ صَالُو النَّارِ(59) Eyi ni ijo kan t’o maa wo inu Ina pelu yin. (Awon asiwaju ninu Ina si maa wi pe:) "Ko si maawole-maarora fun won." Dajudaju won yoo wo inu Ina ni |
قَالُوا بَلْ أَنتُمْ لَا مَرْحَبًا بِكُمْ ۖ أَنتُمْ قَدَّمْتُمُوهُ لَنَا ۖ فَبِئْسَ الْقَرَارُ(60) (Awon omoleyin ninu Ina) maa wi pe: "Rara, eyin naa ko si maawole-maarora fun yin. Eyin l’e pe wa sibi eyi (t’o bi Ina)." O si buru ni ibugbe |
قَالُوا رَبَّنَا مَن قَدَّمَ لَنَا هَٰذَا فَزِدْهُ عَذَابًا ضِعْفًا فِي النَّارِ(61) Won (tun) wi pe: "Oluwa wa, eni ti o pe wa (sibi iya) yii, se alekun adipele iya fun un ninu Ina |
وَقَالُوا مَا لَنَا لَا نَرَىٰ رِجَالًا كُنَّا نَعُدُّهُم مِّنَ الْأَشْرَارِ(62) Won tun wi pe: "Ki lo sele si wa ti a o ri awon okunrin kan, awon ti a n ka mo awon eni buruku |
أَتَّخَذْنَاهُمْ سِخْرِيًّا أَمْ زَاغَتْ عَنْهُمُ الْأَبْصَارُ(63) Sebi a fi won se yeye tabi awon oju ti fo won ni (l’a o fi ri won ninu Ina) |
Dajudaju iyen, ariyanjiyan awon ero inu Ina, ododo ma ni |
قُلْ إِنَّمَا أَنَا مُنذِرٌ ۖ وَمَا مِنْ إِلَٰهٍ إِلَّا اللَّهُ الْوَاحِدُ الْقَهَّارُ(65) So pe: "Emi ni olukilo. Ati pe ko si olohun ti ijosin to si ayafi Allahu, Okan soso, Olubori |
رَبُّ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَمَا بَيْنَهُمَا الْعَزِيزُ الْغَفَّارُ(66) Oluwa awon sanmo ati ile ati ohunkohun t’o wa laaarin mejeeji, Alagbara, Alaforijin |
So pe: "(al-Ƙur’an) ni iro nla |
Eyin si n gbunri kuro nibe |
مَا كَانَ لِيَ مِنْ عِلْمٍ بِالْمَلَإِ الْأَعْلَىٰ إِذْ يَخْتَصِمُونَ(69) Emi ko si nimo nipa awon molaika ti o wa ni aye giga nigba ti won n saroye |
إِن يُوحَىٰ إِلَيَّ إِلَّا أَنَّمَا أَنَا نَذِيرٌ مُّبِينٌ(70) Ki ni won fi ranse si mi bi ko se pe emi ni olukilo ponnbele |
إِذْ قَالَ رَبُّكَ لِلْمَلَائِكَةِ إِنِّي خَالِقٌ بَشَرًا مِّن طِينٍ(71) (Ranti) nigba ti Oluwa re so fun awon molaika pe: "Dajudaju Emi yoo da abara kan lati inu erupe |
فَإِذَا سَوَّيْتُهُ وَنَفَخْتُ فِيهِ مِن رُّوحِي فَقَعُوا لَهُ سَاجِدِينَ(72) Nigba ti Mo ba se e t’o dogba jale tan, ti Mo si fe ninu ategun emi ti Mo da sinu re, nigba naa e doju bole fun un ni oluforikanle-kini |
Gbogbo awon molaika patapata si fori kanle ki i |
Ayafi ’Iblis, ti o segberaga. O si wa ninu awon alaigbagbo |
(Allahu) so pe: "’Iblis, ki l’o ko fun o lati fori kanle ki ohun ti Mo fi owo Mi mejeeji da? Se o segberaga ni tabi o wa ninu awon eni giga |
قَالَ أَنَا خَيْرٌ مِّنْهُ ۖ خَلَقْتَنِي مِن نَّارٍ وَخَلَقْتَهُ مِن طِينٍ(76) O wi pe: "Emi loore julo si oun; O da emi lati ara ina. O si da oun lati ara erupe amo |
(Allahu) so pe: "Jade kuro ninu (Ogba Idera) nitori pe dajudaju iwo ni eni eko |
Ati pe dajudaju egun Mi yoo wa lori re titi di Ojo esan |
(Esu) wi pe: "Oluwa mi, lo mi lara titi di ojo ti Won yoo gbe eda dide |
(Allahu) so pe: "Dajudaju iwo wa ninu awon ti won maa lo lara |
titi di ojo akoko ti A ti mo |
(Esu) wi pe: "Mo fi agbara Re bura, dajudaju emi yoo ko gbogbo won sinu isina |
afi awon erusin Re, awon eni esa ninu won |
(Allahu) so pe: "Ododo (ni ibura Mi), ododo si ni Emi n so, (pe) |
لَأَمْلَأَنَّ جَهَنَّمَ مِنكَ وَمِمَّن تَبِعَكَ مِنْهُمْ أَجْمَعِينَ(85) dajudaju Mo maa fi iwo ati gbogbo awon t’o ba tele o ninu won kun inu ina Jahanamo |
قُلْ مَا أَسْأَلُكُمْ عَلَيْهِ مِنْ أَجْرٍ وَمَا أَنَا مِنَ الْمُتَكَلِّفِينَ(86) So pe: "Emi ko bi yin leere owo-oya kan lori re. Emi ko si si ninu awon onitan-aroso |
Ki ni al-Ƙur’an bi ko se iranti fun gbogbo eda |
Ati pe dajudaju e maa mo iro re (si ododo) laipe |
Plus de sourates en Yoruba :
Téléchargez la sourate avec la voix des récitants du Coran les plus célèbres :
Téléchargez le fichier mp3 de la sourate Saad : choisissez le récitateur pour écouter et télécharger la sourate Saad complète en haute qualité.
Ahmed Al Ajmy Bandar Balila Khalid Al Jalil Saad Al Ghamdi Saud Al Shuraim Abdul Basit Abdul Rashid Sufi Abdullah Basfar Abdullah Al Juhani Fares Abbad Maher Al Muaiqly Al Minshawi Al Hosary Mishari Al-afasi Yasser Al Dosari
Donnez-nous une invitation valide