PDF —
118 Ẹsẹ Meccan PDF
Built right in your browser — download starts automatically

Surah Al-Mu'minun pdf — Gbà (Yorùbá)

Surah Al-Mu'minun pdf Yorùbá — Gbà Surah Al-Mu'minun Itumọ. Surah Al-Mu'minun (Meccan) 118 Ẹsẹ.

← Al-HajjSurah Al-Mu'minun An-Nur →


118 Ẹsẹ · Meccan · Yorùbá
bismillah
ﭑﭒﭓﭔ
23:1 Dajudaju awon onigbagbo ododo ti jere
ﭕﭖﭗﭘﭙﭚ
23:2 Awon t’o n paya (Allahu) ninu irun won
ﭛﭜﭝﭞﭟﭠ
23:3 ati awon t’o n seri kuro nibi isokuso
ﭡﭢﭣﭤﭥ
23:4 ati awon t’o n yo Zakah
ﭦﭧﭨﭩﭪ
23:5 ati awon t’o n so abe won
ﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵ
23:6 afi ni odo awon iyawo won ati erubinrin won. Dajudaju won ki i se eni eebu (ti won ba sunmo won)
ﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽ
23:7 nitori naa, enikeni ti o ba wa omiran (sunmo) leyin iyen, awon wonyen ni awon olutayo enu-ala
ﭾﭿﮀﮁﮂﮃ
23:8 ati awon t’o n so agbafipamo won ati adehun won
ﮄﮅﮆﮇﮈﮉ
23:9 ati awon t’o n so irun won
ﮊﮋﮌﮍ
23:10 awon wonyen ni awon olujogun
ﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔ
23:11 awon t’o maa jogun ogba idera Firdaos. Olusegbere ni won ninu re
ﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜ
23:12 Dajudaju A ti se eda eniyan lati inu ohun ti A mo jade lati inu erupe amo
ﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣ
23:13 Leyin naa, A se e ni ato sinu aye aabo (iyen, ile-omo)
ﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛ
23:14 Leyin naa, A so ato di eje didi. Leyin naa, A so eje didi di baasi eran. Leyin naa, A so baasi eran di eegun. Leyin naa, A fi eran bo eegun. Leyin naa, A so o di eda miiran.1 Nitori naa, ibukun ni fun Allahu, Eni t’O dara julo ninu awon eledaa (onise-ona)
ﯜﯝﯞﯟﯠﯡ
23:15 Leyin naa, leyin iyen, dajudaju eyin yo si di oku
ﯢﯣﯤﯥﯦﯧ
23:16 Leyin naa, dajudaju ni Ojo Ajinde Won maa gbe yin dide
ﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲ
23:17 Dajudaju A da awon sanmo meje si oke yin. Awa ko si nii dagunla si awon eda
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟ
23:18 A n so omi kale lati sanmo niwon niwon. Leyin naa, A n mu un duro sinu ile. Dajudaju Awa kuku lagbara lati mu un lo
ﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭ
23:19 Leyin naa, A da awon ogba oko dabinu ati ajara fun yin; opolopo eso wa ninu re fun yin, e si n je ninu re
ﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷ
23:20 Ati igi kan t’o n hu jade nibi apata Sina’; o n mu epo ati nnkan isebe jade fun awon t’o n je e
ﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈ
23:21 Ati pe dajudaju ariwoye wa fun yin lara awon eran-osin; A n fun yin mu ninu ohun ti o wa ninu ikun won. Awon anfaani opolopo (miiran) tun wa fun yin lara won, e si n je ninu re
ﮉﮊﮋﮌﮍ
23:22 E si n ko eru si ori awon eran osin ati oko oju-omi
ﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟ
23:23 Dajudaju A ran (Anabi) Nuh nise si ijo re. O si so pe: “Eyin ijo mi, e josin fun Allahu. E o ni olohun miiran leyin Re. Se e o nii beru (Re) ni?”
ﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛ
23:24 Awon olori ti won sai gbagbo ninu awon eniyan re so pe: “Ki ni eyi bi ko se abara kan bi iru yin, ti o fe gbe ajulo fun ara re lori yin. Ati pe ti o ba je pe Allahu ba fe (ranse si wa ni), iba so molaika kan kale ni. A ko si gbo eyi ri lodo awon baba wa, awon eni akoko
ﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦ
23:25 Ko je kini kan bi ko se okunrin kan ti alujannu n be lara re. Nitori naa, e maa reti (ikangun) re titi di igba kan na.”
ﯧﯨﯩﯪﯫﯬ
23:26 (Anabi) Nuh so pe: "Oluwa mi, saranse fun mi nitori pe won pe mi ni opuro
ﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆﰇﰈﰉﰊﰋﰌﰍﰎ
23:27 Nitori naa, A fi imisi ranse si i pe: "Se oko oju-omi ni oju Wa (bayii) pelu imisi Wa. Nigba ti ase Wa ba de, ti omi ba se yo ni oju aro, nigba naa ni ki o ko sinu oko oju-omi gbogbo nnkan ni orisi meji tako-tabo ati ara ile re, ayafi eni ti oro naa ko le lori ninu won (fun iparun). Ma se ba Mi soro nipa awon t’o sabosi; dajudaju A oo te won ri sinu omi ni
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠ
23:28 Nigba ti o ba jokoo sinu oko oju-omi naa, iwo ati awon t’o wa pelu re, so pe: Ope ni fun Allahu, Eni ti O gba wa la lowo ijo alabosi
ﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩ
23:29 So pe: “Oluwa mi, so mi kale si ibuso ibukun. Iwo si loore julo ninu awon amunigunle.”
ﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱ
23:30 Dajudaju awon ami wa ninu iyen. Awa si ni A n dan eda wo
ﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸ
23:31 Leyin naa, A mu awon iran miiran wa leyin won
ﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈ
23:32 A tun ran Ojise kan si won laaarin ara won (lati jise) pe: “E josin fun Allahu. E o ni olohun miiran leyin Re. Nitori naa, se e o nii beru (Re) ni?”
ﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢ
23:33 Awon olori t’o sai gbagbo ninu ijo re, awon t’o pe ipade Ojo Ikeyin niro, awon ti A se gbedemuke fun ninu isemi aye yii, won wi pe: "Ki ni eyi bi ko se abara kan bi iru yin; o n je ninu ohun ti e n je, o si n mu ninu ohun ti e n mu
ﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪ
23:34 Ti e ba fi le tele abara kan bi iru yin, dajudaju e ma ti di eni ofo niyen
ﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕ
23:35 Se o n se adehun fun yin pe nigba ti e ba ku, ti e si di erupe ati egungun tan, dajudaju Won yoo mu yin jade (ni alaaye)
ﯖﯗﯘﯙﯚﯛ
23:36 Ohun ti Won n se ni adehun fun yin (yii) jinna tefetefe (si ododo)
ﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦ
23:37 Ko si isemi aye kan mo ayafi eyi ti a n lo yii; awa kan n ku, awa kan n waye. Ko si si pe Won yoo gbe wa dide mo
ﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳ
23:38 (Ojise naa) ko je kini kan bi ko se okunrin kan ti o da adapa iro mo Allahu. Awa ko si nii gba a gbo
ﯴﯵﯶﯷﯸﯹ
23:39 (Ojise naa) so pe: "Oluwa mi, saranse fun mi nitori pe won pe mi ni opuro
ﯺﯻﯼﯽﯾﯿ
23:40 (Allahu) so pe: “Laipe nse ni won yoo di alabaamo.”
ﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆﰇﰈﰉ
23:41 Nitori naa, ohun igbe mu won lona eto. A si so won di panti. Nitori naa, ki ijinna si ike wa fun ijo alabosi
ﰊﰋﰌﰍﰎﰏﰐ
23:42 Leyin naa, A tun mu awon iran miiran wa leyin won
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘ
23:43 Ijo kan ko nii lo siwaju akoko (iparun) re, won ko si nii sun (iparun won) siwaju
ﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯ
23:44 Leyin naa, A ran awon Ojise Wa nise ni telentele. Igbakigba ti Ojise ijo kan ba de, won n pe e ni opuro. A si mu apa kan won tele apa kan ninu iparun. A tun so won di itan. Nitori naa, ki ijinna si ike wa fun ijo ti ko gbagbo lododo
ﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸ
23:45 Leyin naa, A ran (Anabi) Musa ati omo-iya re (Anabi) Harun nise pelu awon ami Wa ati eri ponnbele
ﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀ
23:46 (A ran won nise) si Fir‘aon ati awon ijoye re. Sugbon won segberaga, won si je ijo olujegaba
ﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈ
23:47 Won wi pe: “Se ki a gba abara meji bi iru wa gbo, nigba ti o je pe eru wa ni awon eniyan won?”
ﮉﮊﮋﮌﮍ
23:48 Nitori naa, won pe awon mejeeji ni opuro. Won si wa ninu awon eni- iparun
ﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔ
23:49 Dajudaju A fun (Anabi) Musa ni Tira nitori ki won le mona
ﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠ
23:50 A se omo Moryam ati iya re ni ami kan. A si se ibugbe fun awon mejeeji si ibi giga kan, t’o ni ibugbe, t’o si ni omi iseleru
ﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭ
23:51 Eyin Ojise, e je ninu awon nnkan daadaa, ki e si se ise rere. Dajudaju Emi ni Onimo nipa ohun ti e n se nise
ﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗ
23:52 Ati pe dajudaju (’Islam) yii ni esin yin. (O je) esin kan soso. Emi si ni Oluwa yin. Nitori naa, e beru Mi
ﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢ
23:53 Sugbon won ge oro esin won laaarin ara won si kelekele. Ijo kookan si n yo si ohun t’o n be ni odo won
ﯣﯤﯥﯦﯧﯨ
23:54 Nitori naa, fi won sile sinu isina won titi di igba kan na
ﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰ
23:55 Se won n lero pe (bi) A se n fi dukia ati omo nikan se iranlowo fun won
ﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹ
23:56 ni A oo se maa yara ti awon oore si odo won lo (titi laelae). Rara, won ko fura ni
ﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁ
23:57 Dajudaju awon t’o n paya (isiro-ise) fun ipaya won ninu Oluwa won
ﰂﰃﰄﰅﰆﰇ
23:58 ati awon t’o n gba awon ayah Oluwa won gbo
ﰈﰉﰊﰋﰌﰍ
23:59 ati awon ti ki i sebo si Oluwa won
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛ
23:60 ati awon t’o n se ohun rere (ninu ise) ti won se, pelu iberu ninu okan won pe dajudaju awon yoo pada si odo Oluwa won
ﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣ
23:61 awon wonyen ni won n yara se awon ise rere. Awon si ni asiwaju ninu (awon esan) ise naa
ﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱ
23:62 Ati pe A ko labo emi kan lorun afi iwon agbara re. Tira kan t’o n so ododo (nipa ise eda) n be lodo Wa. A o si nii sabosi si won
ﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀ
23:63 Amo okan awon alaigbagbo wa ninu ifonufora nipa (al-Ƙur’an) yii. Ati pe won ni awon ise kan lowo, ti o yato si ise rere yen. Won si n se ise naa
ﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉ
23:64 titi di igba ti A maa gba awon onigbedemuke ninu won mu pelu iya. Nigba naa ni won maa ke gbajari
ﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒ
23:65 E ma kee gbajari lonii. Dajudaju ko si eni ti o maa ran yin lowo lodo Wa
ﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜ
23:66 Won kuku n ka awon ayah Mi fun yin. Amo nse ni e n fa seyin (nibi ododo)
ﮝﮞﮟﮠﮡ
23:67 E si n fi Kaaba segberaga, e tun n fi oru yin so isokuso (nipa al-Ƙur’an)
ﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬ
23:68 Se won ko ronu si oro naa ni? Tabi ohun t’o de ba won je ohun ti ko de ba awon baba won akoko ri ni
ﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕ
23:69 Tabi won ko mo Ojise won mo ni won fi di alatako re
ﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡ
23:70 Tabi won n wi pe alujannu kan n be lara re ni? Rara o. O mu ododo wa ba won ni. Amo opolopo won si je olukorira ododo
ﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳ
23:71 Ti o ba je pe (Allahu), Oba Ododo tele ife-inu won ni, awon sanmo ati ile ati awon t’o wa ninu won iba kuku ti baje. Sugbon A mu isiti nipa oro ara won wa fun won ni, won si n gbunri kuro nibi isiti (ti A mu wa fun) won
ﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾ
23:72 Tabi o n beere owo-oya kan lowo won ni? Owo-oya Oluwa re loore julo. Ati pe Oun l’oore julo ninu awon olupese
ﯿﰀﰁﰂﰃﰄ
23:73 Ati pe dajudaju o n pe won soju ona taara ni
ﰅﰆﰇﰈﰉﰊﰋﰌﰍ
23:74 Awon ti ko si gba Ojo Ikeyin gbo ni won n seri kuro loju ona naa
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝ
23:75 Ti o ba je pe A ke won (nile aye), ti A si gbe gbogbo isoro ara won kuro fun won, won iba tun wonkoko mo itayo enu-ala won, ti won yoo maa pa ridarida (ninu isina)
ﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦ
23:76 Dajudaju A fi iya je won. Amo won ko teriba fun Oluwa won, won ko si rawo rase si I
ﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳ
23:77 titi di igba ti A fi silekun iya lile fun won; nigba naa ni won soreti nu
ﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿ
23:78 (Allahu), Oun ni Eni ti O se igboro, iriran ati okan fun yin, idupe yin si kere
ﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇ
23:79 Oun ni Eni ti O da yin sori ile, odo Re si ni won yoo ko yin jo si
ﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓ
23:80 Oun ni Eni t’O n so eda di alaaye, O n so eda di oku, tiRe si ni itelentele ati iyato oru ati osan, se e o nii se laakaye ni
ﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚ
23:81 Rara (won ko nii se laakaye, sebi) iru ohun ti awon eni akoko wi ni awon naa wi
ﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣ
23:82 Won wi pe: “Se nigba ti a ba ti ku, ti a ti di erupe ati egungun, se won yoo gbe wa dide ni
ﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰ
23:83 Won kuku ti se adehun yii fun awa ati awon baba wa teletele. Eyi ko je kini kan bi ko se akosile alo awon eni akoko.”
ﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚ
23:84 So pe: “Ta ni Eni ti O ni ile ati eni ti o wa ni ori re ti e ba mo?”
ﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡ
23:85 Won a wi pe: “Ti Allahu ni.” So pe: “Se e o nii lo iranti ni?”
ﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪ
23:86 So pe: “Ta ni Oluwa awon sanmo mejeeje ati Oluwa Ite nla?”
ﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱ
23:87 Won a wi pe: “Ti Allahu ni.” So pe: “Se e o nii beru (Re) ni?”
ﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀ
23:88 So pe: “Ta ni Eni ti ijoba gbogbo nnkan wa ni owo Re, (Eni ti) O n gba eda la ninu iya, (ti) ko si si eni ti o le gba eda la nibi iya Re ti e ba mo?” So pe: “Ta ni Eni ti ijoba gbogbo nnkan wa ni owo Re, (Eni ti) O n gba eda la ninu iya, (ti) ko si si eni ti o le gba eda la nibi iya Re ti e ba mo?”
ﰁﰂﰃﰄﰅﰆﰇ
23:89 Won a wi pe: “Ti Allahu ni.” So pe: “Nitori naa, bawo ni won se n dan yin?”
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖ
23:90 Amo sa, ododo ni A mu wa ba won. Dajudaju awon si ni opuro
ﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱ
23:91 Allahu ko fi eni kan kan se omo, ko si si olohun kan pelu Re. (Ti ko ba ri bee) nigba naa, olohun kookan iba ti ko eda t’o da lo, apa kan won iba si bori apa kan. Mimo ni fun Allahu tayo ohun ti won n fi royin (Re nipa omo bibi)
ﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸ
23:92 (Allahu) Onimo-ikoko ati gbangba. Nitori naa, O ga tayo nnkan ti won fi n sebo si I
ﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿ
23:93 So pe: “Oluwa mi, O see se ki O fi ohun ti won n se ni adehun fun won han mi
ﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆ
23:94 Oluwa mi, ma se fi mi sinu ijo alabosi.”
ﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎ
23:95 Dajudaju Awa lagbara lati fi ohun ti A se ni ileri fun won han o
ﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙ
23:96 Fi eyi t’o dara ti aidara danu. Awa nimo julo nipa ohun ti won fi n royin (Wa)
ﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡ
23:97 So pe: "Oluwa mi, mo n sadi O nibi royiroyi t’awon esu
ﮢﮣﮤﮥﮦﮧ
23:98 Mo n sadi O, Oluwa mi, nibi ki won wa ba mi
ﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰ
23:99 (Won n semi lo) titi di igba ti iku fi maa de ba okan ninu won. O si maa wi pe: “Oluwa mi, E da mi pada (sile aye)
ﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥ
23:100 nitori ki ng le se ise rere ninu eyi ti mo gbe ju sile. Ko ri bee rara, dajudaju o je oro kan ti o kan n wi ni, (amo) gaga ti wa ni eyin won titi di ojo ti A oo gbe won dide. ayeta okigbe
ﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰ
23:101 Nigba ti won ba fon fere oniwo fun ajinde, ko nii si ibatan laaarin won ni ojo yen, won ko si nii bira won leere ibeere
ﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷ
23:102 Enikeni ti osuwon (ise rere) re ba tewon, awon wonyen ni olujere
ﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂ
23:103 Enikeni ti osuwon (ise rere) re ba fuye, awon wonyen ni awon t’o se emi ara won lofo. Olusegbere si ni won ninu ina Jahanamo
ﰃﰄﰅﰆﰇﰈﰉ
23:104 Ina yoo maa jo won loju. Won yo si wa ninu re, ti Ina yoo ti ba won loju je
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙ
23:105 Se won ki i ka awon ayah Mi fun yin ni, amo ti e n pe e niro
ﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢ
23:106 Won wi pe: "Oluwa wa, ori buruku l’o kolu wa; awa si je ijo olusina
ﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪ
23:107 Oluwa wa, mu wa jade kuro ninu Ina. Ti a ba fi le pada (sibi ise ibi nile aye), dajudaju nigba naa alabosi ni awa
ﭫﭬﭭﭮﭯﭰ
23:108 (Allahu) so pe: “E teri sinu re. E ma se ba Mi soro.”
ﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿ
23:109 Dajudaju igun kan wa ninu awon erusin Mi, ti won n so pe: “Oluwa wa, a gbagbo ni ododo. Nitori naa, forijin wa, ki O si ke wa. Iwo si l’oore julo ninu awon alaaanu.”
ﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈ
23:110 Sugbon e so won di oniyeye to bee ge ti awon yeye (yin) fi mu yin gbagbe iranti Mi. Eyin si n fi won rerin-in
ﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑ
23:111 Dajudaju Mo san won ni esan ni oni nitori suuru won; dajudaju awon, awon ni olujere
ﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙ
23:112 (Allahu) so pe: "Odun meloo ni eyin (alaigbagbo) lo lori ile aye
ﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢ
23:113 Won wi pe: “A lo ojo kan tabi abala ojo kan, bi awon olusiro-ojo leere wo.”
ﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭ
23:114 (Allahu) so pe: “E ko gbe ile aye bi ko se fun igba die, ti o ba je pe e mo.”
ﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗ
23:115 Se e lero pe A kan seda yin fun iranu ni, ati pe dajudaju won o nii da yin pada sodo Wa?”
ﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤ
23:116 Nitori naa, Allahu Oba Ododo ga. Ko si olohun ti ijosin to si afi Oun, Oluwa Ite alapon-onle
ﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸ
23:117 Eni ti o ba pe olohun miiran pelu Allahu, ko ni eri lowo lori re. Dajudaju isiro-ise re si wa lodo Oluwa re. Dajudaju awon alaigbagbo ko nii jere
ﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀ
23:118 So pe: “Oluwa mi, saforijin, ki O si ke (mi). Iwo si l’oore julo ninu awon alaaanu.”

Al-Kur'an


Wednesday, September 9, 2026

Don't forget us in your sincere prayers