Surah Al-Anbiya
PDF —
112 Ẹsẹ Meccan PDF
Built right in your browser — download starts automatically

Surah Al-Anbiya pdf — Gbà (Yorùbá)

Surah Al-Anbiya pdf Yorùbá — Gbà Surah Al-Anbiya Itumọ. Al-Anbiya (Meccan) 112 Ẹsẹ.



Surah Al-Anbiya
112 Ẹsẹ · Meccan · Yorùbá
bismillah
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘ
Isiro-ise sunmo fun awon eniyan, won si wa ninu ifonufora, ti won n gbunri (kuro nibi ododo)
ﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤ
Ko si iranti titun kan ti o maa de ba won lati odo Oluwa won afi ki won gbo o pelu ere sise
ﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶ
Won fonufora ni. Awon t’o sabosi si fi oro ikoko (aarin ara won) pamo pe: "Se eyi tayo abara bi iru yin ni? Se e maa tele idan ni, nigba ti eyin naa riran
ﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂ
O so pe: “Oluwa mi mo oro t’o n be ninu sanmo ati ile. Oun ni Olugbo, Onimo.”
ﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑ
Rara, won tun wi pe: “Awon ala ti itumo re lopo mora won ni (al-Ƙur’an.” Won tun wi pe): “Rara, o hun un ni.” (Won tun wi pe): “Rara, elewi ni. Bi bee ko ki o mu ami kan wa fun wa gege bi won se fi ran awon eni akoko.”
ﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛ
Ko si awon t’o gbagbo siwaju won ninu awon ilu ti A ti pare (leyin isokale ami). Se awon si maa gbagbo (nigba ti ami ba de)
ﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫ
A o ran eni kan ni ise-ojise siwaju re afi awon okunrin ti A n fi imisi ranse si. Nitori naa, e beere lodo awon oniran-anti ti eyin ko ba mo
ﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖ
A ko si se won ni abara ti ko nii jeun. Won ko si je olusegbere (nile aye). abara ni ki i se olohun. Allahu awon oku ko le gbo oro kan kan mo lati odo awon alaaye ni ibamu si surah an-Naml; 27:80 surah ar-Rum; 30:52 ati surah Fatir; 35:22. Anabi wa Muhammad (sollalahu alayhi wa sallam) si pada di oku ti won bo mo inu saree ninu ilu Modinah Onimoole ni ibamu si surah az-Zumor; 39:30. Ko si si ayah taara kan ninu al-Ƙur’an ti o yo Anabi wa Muhammad (sollalahu alayhi wa sallam) sile ninu awon oku ti ko le gbo oro kan kan mo lati odo awon alaaye. Amo hadith t’o fese rinle wa ti o n fi rinle pe “Ko si eni kan ti o maa salamo si mi afi ki Allahu da emi mi pada si mi lara titi mo maa fi da salamo naa pada fun un.” Abu Daud l’o gba a wa labe akole: bab ziyaratul-ƙubur. Seek al-Baniy so pe “hadith naa dara”. Hadith yii tun wa ninu musnad ’Ahmad ati sunan Baehaƙiy. Ojise Allahu (sollalahu alayhi wa sallam) so pe “Dajudaju ojo Jum‘ah wa ninu awon ojo yin t’o loore julo; Won seda Anabi Adam (’alaehi-ssolatu wa-ssalam) ninu re ni isele t’o tayo oye wa amo ti o tenu Anabi wa Muhammad olododo (sollalahu alayhi wa sallam) jade ti o si dari yin pelu ohun ti n be lodo yin.” Eni kan ninu awon t’o gba hadith yii wa so pe “Ki ni itumo “ti o si dari yin pelu ohun ti n be lodo yin”? Tabi ki ni itumo “ti ohun ti o maa fi dari yin si maa wa lati odo yin?” Ibnu Abi Thanb si fesi pe
ﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟ
Leyin naa, A mu adehun Wa se fun won. A si gba awon Ojise ati awon ti A ba fe la. A si pa awon olutayo enu-ala run
ﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩ
Dajudaju A ti so tira kan kale fun yin, ti iranti nipa oro ara yin wa ninu re. Nitori naa, se e o se laakaye ni
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛ
Meloo meloo ninu ilu ti A ti pare, ti o je alabosi! A si gbe awon ijo miiran dide leyin won
ﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣ
Nigba ti won ri iya Wa (t’o n bo), won si n sa lo fun un
ﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮ
E ma se sa lo. E pada sibi nnkan ti A fi se gbedemuke fun yin ati awon ibugbe yin nitori ki A le bi yin ni ibeere
ﭯﭰﭱﭲﭳﭴ
Won wi pe: “Egbe wa o! Dajudaju awa je alabosi.”
ﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽ
Igbe won yii ko duro titi A fi so won di koriko ti won ge, won si doku kale
ﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅ
Awa ko da sanmo ati ile ati ohun ti n be laaarin awon mejeeji pelu ere sise
ﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑ
Ti o ba je pe A gbero lati sere ni, odo Wa ni A kuku ti maa se e ti A ba je oluse-(ere)
ﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠ
Rara o! A n so ododo lu iro (mole ni). Ododo si maa fo agbari iro. Iro si maa poora. Egbe si ni fun yin nipa ohun ti e n fi royin (Re ni ti iro)
ﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯ
TiRe ni awon t’o wa ninu awon sanmo ati ile. Ati pe awon t’o n be lodo Re, won ki i segberaga nibi ijosin Re. Ati pe won ko kole
ﮰﮱﯓﯔﯕﯖ
Won n safomo ni oru ati ni osan; ko si re won
ﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞ
Tabi won ni awon olohun kan ti won mu jade lati ara ile, ti won n ji oku dide ni
ﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭ
Ti o ba je pe awon olohun kan wa ninu sanmo ati ile leyin Allahu, sanmo ati ile iba ti baje. Mimo ni fun Allahu, Oluwa Ite-ola, tayo ohun ti won n fi royin (Re)
ﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴ
Won ko nii bi (Allahu) ni ibeere nipa nnkan ti O n se. Awon ni won maa bi ni ibeere (nipa ise owo won)
ﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆﰇﰈﰉﰊﰋﰌﰍﰎﰏ
Tabi won so awon kan di olohun leyin Allahu ni? So pe: “E mu eri oro yin wa.” (Al-Ƙur’an) yii ni iranti nipa awon t’o wa pelu mi ati iranti nipa awon t’o siwaju mi. Sugbon opolopo won ko mo ododo; won si n gbunri kuro nibe
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠ
A ko ran ojise kan nise siwaju re afi ki A fi imisi ranse si i pe: “Dajudaju ko si olohun ti ijosin to si afi Emi (Allahu). Nitori naa, e josin fun Mi.”
ﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫ
Won wi pe: “Ajoke-aye so eni kan di omo.” Mimo ni fun Un – Ko ri bee; erusin alapon-onle ni won
ﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲ
Won ki i siwaju Allahu soro. Won si n sise pelu ase Re
ﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂ
(Allahu) mo ohun t’o n be niwaju won ati ohun t’o n be leyin won. Won ko si nii sipe (eni kan) afi eni ti (Allahu) ba yonu si. Won tun n paya fun iberu Re
ﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒ
Ati pe enikeni ninu won ti o ba wi pe: “Dajudaju emi ni olohun leyin Re.” Nitori iyen si ni A oo fi san an ni esan ina Jahanamo. Bayen si ni A se n san awon alabosi ni esan
ﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧ
Se awon t’o sai gbagbo ko ri i pe dajudaju awon sanmo le po ati ile naa le po tele ni, A si ya won si otooto, A si se gbogbo nnkan ni abemi lati inu omi? Nitori naa, se won ko nii gbagbo ni? lile-papo” itumo “fatƙ” si ni “ela
ﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖ
A si fi awon apata t’o duro gbagidi sinu ile ki o ma fi le mi mo won lese. A si fi awon ona fife saaarin awon apata nitori ki won le ri ona to
ﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠ
A tun se sanmo ni aja ti won n so (nibi jijabo). Sibesibe won n gbunri kuro nibi awon ami re
ﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭ
Oun ni Eni ti O da oru ati osan pelu oorun ati osupa. Ikookan (oorun ati osupa) wa ni opopona roboto t’o n to
ﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹ
A ko se bibe gbere fun abara kan siwaju re. Nje ti o ba ku, awon si ni olusegbere bi
ﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆ
Emi kookan l’o maa to iku wo. A si maa fi aburu ati rere sadanwo fun yin. Odo Wa si ni won yoo da yin pada si
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢ
Nigba ti awon t’o sai gbagbo ba ri o, won ko si nii ka o kun kini kan bi ko se oniyeye pe: “Se eyi ni eni t’o n soro nipa awon olohun yin?” Alaigbagbo si ni awon naa nipa iranti Ajoke-aye
ﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬ
Won fi ikanju se eniyan. Mo maa fi awon ami Mi han yin. Nitori naa, e ma se kan Mi loju
ﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴ
Won si n wi pe: “Igba wo ni ileri yii yoo se na, ti e ba je olododo?”
ﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅ
Ti o ba je pe awon t’o sai gbagbo mo igba ti won ko nii da Ina duro niwaju won ati ni eyin won, ti A o si nii ran won lowo, (won iba ti wa iya pelu ikanju)
ﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐ
Sugbon (iya Ina) yoo ba won ni ojiji, nigba naa o maa ko idaamu ba won; won ko si nii le da a pada. A o si nii sun (iya naa) siwaju fun won
ﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞ
Won kuku ti fi awon Ojise kan se yeye siwaju re! Nitori naa, ohun ti won n fi se yeye si diya t’o yi awon t’o n fi won se yeye po
ﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭ
So pe: "Ta ni eni ti o n so yin ni oru ati ni osan nibi iya Ajoke-aye?" Amo nse ni won n gbunri kuro nibi iranti Ajoke-aye
ﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞ
Tabi won ni awon olohun kan t’o maa gba won sile leyin Wa ni? Won ko le ran ara won lowo. Won ko si le gba won sile lodo Wa
ﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳ
Bee ni, A fun awon wonyi ati awon baba won ni igbadun titi isemi aye won fi gun. Se won ko ri i pe dajudaju Awa l’A n mu ile dinku (mo awon alaigbagbo lowo) lati awon eti ilu (wonu ilu nipa fifun awon musulumi ni isegun lori won). Nitori naa, se awon ni olubori ni
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝ
So pe: “Imisi ni mo fi n kilo fun yin. Awon aditi ko si nii gbo ipe nigba ti won ba n kilo fun won.”
ﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩ
Ati pe dajudaju ti abala kan ninu iya Oluwa re ba fowo ba won, dajudaju won a wi pe: “Egbe wa o; dajudaju awa je alabosi.”
ﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀ
A maa gbe awon osuwon deede kale ni Ojo Ajinde. Nitori naa, won ko nii se abosi kini kan fun emi kan. Ki (ise) je iwon eso kardal (bin-intin), A maa mu un wa. A si to ni Olusiro
ﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉ
Dajudaju A fun (Anabi) Musa ati (Anabi) Harun ni oro-ipinya (ohun t’o n sopinya laaarin ododo ati iro), imole ati iranti fun awon oluberu (Allahu)
ﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒ
(Awon ni) awon t’o n paya Oluwa won ni ikoko. Olupaya si ni won nipa Akoko naa
ﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛ
Eyi si ni iranti onibukun ti A sokale. Se eyin yoo tako o ni
ﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦ
Dajudaju A ti fun (Anabi) ’Ibrohim ni imona tire siwaju (ki o to dagba). Awa si n je Onimo nipa re
ﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓ
(Ranti) nigba ti o so fun baba re ati ijo re pe: “Ki ni awon ere wonyi ti e n duro ti lorun se je na?”
ﯔﯕﯖﯗﯘﯙ
Won wi pe: “A ba awon baba wa ti won n josin fun won ni.”
ﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢ
O so pe: “Dajudaju eyin ati awon baba yin ti wa ninu isina ponnbele.”
ﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪ
Won wi pe: “Se o mu ododo wa fun wa ni tabi iwo wa lara awon elefe.”
ﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸ
O so pe: "Rara. Oluwa yin ni Oluwa awon sanmo ati ile; Eni ti O pile iseda won. Emi si wa ninu awon elerii lori iyen
ﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀ
Ati pe mo fi Allahu bura, dajudaju mo maa dete si awon orisa yin leyin ti e ba peyin da, ti e lo
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙ
O si fo won si wewe afi agba (orisa) won nitori ki won le pada de ba a
ﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢ
Won wi pe: “Ta ni o se eyi pelu awon olohun wa? Dajudaju onitoun wa ninu awon alabosi.”
ﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪ
Won wi pe: “A gbo ti odokunrin kan n bu enu ate lu won. Won n pe (omo naa) ni ’Ibrohim.”
ﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳ
Won wi pe: “E mu un wa han awon eniyan ki won le jerii le e lori.”
ﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺ
Won wi pe: “Se iwo l’o se eyi pelu awon olohun wa, ’Ibrohim?”
ﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄ
O so pe: “Rara o, agba won yii l’o se (won bee). Nitori naa, e bi won leere wo ti won ba maa n soro.”
ﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌ
Nigba naa, won yiju sira won, won si wi pe: “Dajudaju eyin ni alabosi.”
ﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖ
Leyin naa, won sori ko (won si wi pe): “Iwo naa kuku mo pe awon wonyi ki i soro.”
ﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢ
O so pe: "Se eyin yoo maa josin fun nnkan ti ko le se yin ni anfaani, ti ko si le ko inira ba yin leyin Allahu
ﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭ
Sio eyin ati nnkan ti e n josin fun leyin Allahu, se eyin ko nii se laakaye ni
ﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖ
Won wi pe: “E dana sun un; ki e si ran awon olohun yin lowo, ti eyin ba nikan-an se.”
ﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞ
A so pe: “Ina, di tutu ati alaafia lara ’Ibrohim.”
ﯟﯠﯡﯢﯣﯤ
Won gbero ete si i, sugbon A se won ni olofo julo
ﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭ
A si gba oun ati Lut la sori ile ti A fi ibukun si fun gbogbo eda
ﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷ
A ta a ni ore omo, ’Is-haƙ ati Ya‘ƙub ti o je alekun (iyen, omoomo). Olukuluku (won) ni A se ni eni rere
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡ
A se won ni asiwaju t’o n to awon eniyan si ona pelu ase Wa. A si fi imisi ranse si won nipa sise ise rere, irun kiki ati Zakah yiyo. Won si je olujosin fun Wa
ﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳ
(E ranti Anabi) Lut. A fun un ni ipo Anabi ati imo. A si gba a la ninu ilu ti won ti n se awon ise buruku. Dajudaju won je ijo buruku, obileje
ﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻ
A si mu un wo inu ike Wa. Dajudaju o wa ninu awon eni rere
ﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈ
(E ranti Anabi) Nuh, nigba ti o pe ipe siwaju (yin). A si da a lohun. A si gba oun ati awon eniyan re la ninu ibanuje nla
ﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖ
A si saranse fun un lori awon eniyan t’o pe awon ayah Wa niro. Dajudaju won je ijo buruku. A si te won ri patapata
ﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥ
(E ranti Anabi) Dawud ati (Anabi) Sulaemon, nigba ti awon mejeeji n se idajo lori (oro) oko, nigba ti agutan ijo kan jeko wo inu oko naa. Awa si je Olujerii si idajo won
ﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘ
A si fun (Anabi) Sulaemon ni agboye re. Ati pe ikookan (won) ni A fun ni ipo Anabi ati imo. A si te awon apata ati eye ba; won n se afomo (fun Allahu) pelu (Anabi) Dawud. Awa l’A se won bee
ﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤ
A tun fun un ni imo nipa sise ewu irin fun yin nitori ki o le je odi iso fun yin nibi ogun yin. Nitori naa, nje oludupe (fun Allahu) ni eyin bi
ﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴ
A si te ategun lile lori ba fun (Anabi) Sulaemon. O n gbe e lo pelu ase re sori ile ti A fi ibukun si. A si n je Onimo nipa gbogbo nnkan
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞ
Ninu awon esu, awon t’o n wa kusa okun tun wa fun un. Won tun n se ise miiran yato si iyen. Awa si n je Oluso fun won
ﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪ
(E ranti Anabi) ’Ayyub, nigba ti o pe Oluwa re pe: "Dajudaju owo inira ti kan mi. Iwo si ni Alaaanu julo ninu awon alaaanu
ﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼ
A si je ipe re. A mu gbogbo inira re kuro fun un. A tun fun un ni awon ebi re (pada) ati iru won pelu won; (o je) ike lati odo Wa ati iranti fun awon olujosin (fun Wa)
ﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅ
(E ranti Anabi) ’Ismo‘il ati (Anabi) ’Idris ati (Anabi) Thul-Kifl; eni kookan (won) wa ninu awon onisuuru
ﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍ
A si fi won sinu ike Wa. Dajudaju won wa ninu awon eni rere
ﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥ
(E ranti) eleja, nigba ti o ba ibinu lo, o si lero pe A o nii gba oun mu. O si pe (Oluwa re) ninu awon okunkun (inu eja) pe: "Ko si olohun ti ijosin to si afi Iwo (Allahu). Mimo ni fun O. Dajudaju emi je okan ninu awon alabosi
ﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯ
A je ipe re. A si gba a la ninu ibanuje. Bayen ni A se n gba awon onigbagbo ododo la
ﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜ
(E ranti Anabi) Zakariyya nigba ti o pe Oluwa re pe: “Oluwa mi, ma fi mi sile ni emi nikan (ti ko nii bimo). Iwo si loore julo ninu awon olujogun.”
ﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲ
A je ipe re. A si ta a lore omo, (Anabi) Yahya. A si se atunse iyawo re fun un. Dajudaju won n yara gaga nibi awon ise rere. Won n pe Wa pelu ireti ati ipaya. Won si je oluteriba fun Wa
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜ
(E ranti obinrin) eyi ti o so abe re. A si fe ategun ninu awon ategun emi ti A da si i lara. A si se oun ati omokunrin re ni ami fun gbogbo eda
ﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥ
Dajudaju (’Islam) yii ni esin yin. (O je) esin kan soso. Emi si ni Oluwa yin. Nitori naa, e josin fun Mi
ﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭ
(Awon yehudi ati nasara), won si da oro (esin) won si kelekele laaarin ara won; eni kookan (won) si maa pada si odo Wa
ﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺ
Nitori naa, enikeni ti o ba se ninu awon ise rere, ti o si je onigbagbo ododo, ko si kiko fun ise re. Ati pe dajudaju Awa maa se akosile re fun un
ﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂ
Eewo ni fun ara ilu kan ti A ti pare (pe ki o tun pada si aye); dajudaju won ko nii pada mo (si ile aye)
ﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍ
(Won yoo wa ninu barsaku) titi A oo fi si awon Ya’juj ati Ma’juj sile. Awon (wonyi) yo si maa sare jade lati inu gbogbo aye giga
ﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡ
Adehun ododo naa sunmo pekipeki. Nigba naa, awon t’o sai gbagbo yoo maa ranju kale rangandan, (won yo si wi pe): “Egbe ni fun wa! Dajudaju awa ti wa ninu igbagbera nipa eyi. Rara, awa je alabosi ni.”
ﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭ
Dajudaju eyin ati nnkan ti e n josin fun leyin Allahu ni ikona Jahanamo; eyin yo si wo inu re
ﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙ
Ti o ba je pe awon wonyi ni olohun ni, won iba ti wo inu Ina. Olusegbere si ni eni kookan won ninu re
ﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡ
Ina yoo maa kun yun-un si won leti; won ko si nii gbo (oro miiran)
ﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫ
Dajudaju awon ti rere ti siwaju fun lati odo Wa, awon wonyen ni A oo gbe jinna si Ina
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛ
Won ko si nii gbo kikun re. Olusegbere si ni won ninu igbadun ti emi won n fe
ﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧ
Ipaya t’o tobi julo ko nii ba won ninu je. Awon molaika yoo maa pade won, (won yoo so pe): “Eyi ni ojo yin ti A n se ni adehun fun yin.”
ﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻ
(Ojo naa ni) ojo ti A maa ka sanmo bi kika ewe tira. Gege bi A ti se bere iseda eda ni ibere pepe (ibe naa ni) A oo da a pada si. (O je) adehun ti A se. Dajudaju Awa maa se bee
ﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈ
Ati pe A ti ko o sinu awon ipin-ipin Tira (ti A sokale) leyin (eyi ti o wa ninu) Tira Ipile (iyen, Laohul-Mahfuth) pe dajudaju ile (Ogba Idera), awon erusin Mi, awon eni rere, ni won yoo jogun re
ﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏ
Dajudaju ohun t’o to mu ni gunle sinu Ogba Idera ti wa ninu (al-Ƙur’an) yii fun ijo olujosin (fun Mi)
ﮐﮑﮒﮓﮔﮕ
A ko si fi ise imisi ran o bi ko se pe ki o le je ike fun gbogbo eda
ﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢ
So pe: “Ohun ti Won n fi ranse si mi ni imisi ni pe, Olohun yin, Olohun Okan soso ni. Nitori naa, se eyin maa di musulumi?”
ﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱ
Ti won ba gbunri, so nigba naa pe: "Emi n fi to yin leti pe emi ati eyin di jo da duro fun ogun esin (ti o maa sele laaarin wa bayii). Emi ko si mo boya ohun ti Won n se ni adehun fun yin ti sunmo tabi o si jinna
ﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛ
Dajudaju (Allahu) mo ohun ti o han ninu oro. O si mo ohun ti e n fi pamo
ﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤ
Emi ko si mo boya (lilo yin lara) maa je adanwo ati igbadun fun yin titi di igba die
ﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰ
O so pe: “Oluwa mi, sedajo pelu ododo. Oluwa wa ni Ajoke-aye, Oluranlowo lori ohun ti e n fi royin (Re).”

Al-Kur'an


Tuesday, August 18, 2026

Don't forget us in your sincere prayers