PDF —
34 Ẹsẹ Meccan PDF
Built right in your browser — download starts automatically

Surah Luqman pdf — Gbà (Yorùbá)

Surah Luqman pdf Yorùbá — Gbà Surah Luqman Itumọ. Surah Luqman (Meccan) 34 Ẹsẹ.



34 Ẹsẹ · Meccan · Yorùbá
bismillah
ﭑﭒ
31:1 ’Alif lam mim
ﭓﭔﭕﭖﭗ
31:2 Iwonyi ni awon ayah Tira ogbon
ﭘﭙﭚﭛ
31:3 (O je) imona ati ike fun awon oluse-rere
ﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥ
31:4 awon t’o n kirun, ti won n yo zakah. Awon si ni won ni amodaju nipa Ojo Ikeyin
ﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯ
31:5 Awon wonyen wa lori imona lati odo Oluwa won. Awon wonyen si ni awon olujere
ﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃ
31:6 O wa ninu awon eniyan, eni t’o n ra iranu-oro lati fi si awon eniyan lona kuro loju ona (esin) Allahu pelu ainimo ati nitori ki o le so esin di yeye. Awon wonyen si ni iya ti i yepere eda wa fun
ﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕ
31:7 Ati pe nigba ti won ba n ke awon ayah Wa fun un, o maa peyinda ni ti igberaga, afi bi eni pe ko gbo o, afi bi eni pe edidi wa ninu eti re mejeeji. Nitori naa, fun un ni iro iya eleta-elero
ﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞ
31:8 Dajudaju awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se ise rere, awon Ogba Idera n be fun won
ﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩ
31:9 Olusegbere ni won ninu re. (O je) adehun ti Allahu se ni ti ododo. Oun si ni Alagbara, Ologbon
ﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨ
31:10 O da awon sanmo lai ni opo ti e le ri. O si ju awon apata t’o duro gbagidi sinu ile ki o ma fi le mi mo yin lese. O fon gbogbo nnkan abemi ka sori ile. A tun so omi kale lati sanmo, A si fi mu gbogbo orisirisi eso daadaa hu jade lati inu ile
ﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸ
31:11 Eyi ni eda ti Allahu. Nitori naa, e fi ohun ti awon miiran leyin Re da han mi! Rara o! Awon alabosi wa ninu isina ponnbele ni
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥ
31:12 Dajudaju A ti fun Luƙmon ni ogbon, pe: “Dupe fun Allahu.” Enikeni ti o ba dupe, o n dupe fun emi ara re ni. Enikeni ti o ba si sai moore, dajudaju Allahu ni Oloro, Olope (ti ope to si)
ﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵ
31:13 (Ranti) nigba ti Luƙmon so fun omo re nigba ti o n se waasi fun un, pe: “Omo mi, ma se sebo si Allahu. Dajudaju ebo sise ni abosi nla
ﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇ
31:14 Ati pe A pa a ni ase fun eniyan nipa awon obi re mejeeji - iya re gbe e ka (ninu oyun) pelu ailera lori ailera, o si gba omu lenu re laaarin odun meji – (A so) pe: “Dupe fun Emi ati awon obi re mejeeji.” Odo Mi si ni abo eda
ﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨ
31:15 Ti awon mejeeji ba si ja o logun pe ki o fi ohun ti iwo ko ni imo nipa re sebo si Mi, ma se tele awon mejeeji.1 Fi daadaa ba awon mejeeji lo po ni ile aye.2 Ki o si tele oju ona eni ti o ba seri pada si odo Mi (ni ti ironupiwada). Leyin naa, odo Mi ni ibupadasi yin. Nitori naa, Mo maa fun yin ni iro ohun ti e n se nise. nnkan daadaa ni. Iketa: ohunkohun ti asa ati ise eya eda kookan ba pe ni daadaa nnkan daadaa ni ni odiwon igba ti ayah kan tabi hadith kan ko ba ti lodi si irufe nnkan naa. Bi apeere
ﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣ
31:16 Omo mi, dajudaju ti o ba je pe odiwon eso kardal kan lo wa ninu apata, tabi ninu awon sanmo, tabi ninu ile, Allahu yoo mu un wa. Dajudaju Allahu ni Alaaanu, Alamotan
ﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶ
31:17 Omo mi, kirun, p’ase rere, ko aburu, ki o si se suuru lori ohun ti o ba sele si o. Dajudaju iyen wa ninu awon ipinnu oro t’o pon dandan
ﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆﰇﰈ
31:18 Ma se ko parike re si eniyan. Ma si se rin lori ile pelu faari. Dajudaju Allahu ko feran gbogbo onigbeeraga, onifaari
ﰉﰊﰋﰌﰍﰎﰏﰐﰑﰒﰓﰔﰕ
31:19 Je ki irin ese re wa ni iwontun-wonsi, ki o si re ohun re nile. Dajudaju ohun t’o buru julo ma ni ohun ketekete.”
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰ
31:20 Se e o ri i pe dajudaju Allahu ro ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile fun yin, O si pe awon ike Re fun yin ni gbangba ati ni koro? O si wa ninu awon eniyan eni t’o n jiyan nipa Allahu lai ni imo (al-Ƙur’an) ati imona (ninu sunnah Anabi s.a.w.) ati tira (onimo-esin) t’o n tan imole (si oro esin)
ﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇ
31:21 Nigba ti won ba si so fun won pe: “E tele ohun ti Allahu sokale.” Won a wi pe: “Rara! A maa tele ohun ti a ba lowo awon baba wa ni.” (Se won yoo tele awon baba won) t’ohun ti bi Esu se n pe won sibi iya Ina t’o n jo fofo
ﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙ
31:22 Enikeni ti o ba jura re sile fun Allahu, ti o je oluse-rere, dajudaju onitoun ti diro mo okun t’o fokan bale julo. Ati pe odo Allahu ni ikangun awon oro (eda)
ﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫ
31:23 Enikeni ti o ba si sai gbagbo, ma se je ki aigbagbo re ko ibanuje ba o. Odo Wa ni ibupadasi won. Nigba naa, A maa fun won ni iro ohun ti won se nise. Dajudaju Allahu ni Onimo nipa ohun ti n be ninu igba-aya eda
ﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔ
31:24 A maa fun won ni igbadun die. Leyin naa, A maa taari won sinu iya t’o nipon
ﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦ
31:25 Dajudaju ti o ba bi won leere pe: “Ta ni O da awon sanmo ati ile?”, dajudaju won a wi pe: “Allahu ni.” So pe: “Gbogbo ope n je ti Allahu, sugbon opolopo won ko mo
ﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲ
31:26 Ti Allahu ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ile. Dajudaju Allahu, Oun ni Oloro, Olope
ﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆﰇﰈﰉ
31:27 Ti o ba je pe kikida ohun t’o n be lori ile ni igi ni gege ikowe, ki agbami odo je tadaa re, agbami odo meje (tun wa) leyin re (t’o maa kun un), awon oro Allahu ko nii tan (leyin ti awon nnkan ikowe wonyi ba tan nile). Dajudaju Allahu ni Alagbara, Ologbon
ﰊﰋﰌﰍﰎﰏﰐﰑﰒﰓﰔﰕﰖ
31:28 Iseda yin ati ajinde yin ko tayo bi (iseda ati ajinde) emi eyo kan. Dajudaju Allahu ni Olugbo, Oluriran
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫ
31:29 Se o o ri i pe dajudaju Allahu l’O n ti oru bo inu osan, O n ti osan bo inu oru, O si ro oorun ati osupa? Ikookan won si n rin titi di gbedeke akoko kan. Ati pe (se o o ri i pe) dajudaju Allahu ni Alamotan nipa ohun ti e n se nise
ﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼ
31:30 Iyen nitori pe, dajudaju Allahu, Oun ni Ododo. Ati pe dajudaju ohun ti won n pe leyin Re ni iro. Dajudaju Allahu, O ga, O tobi
ﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑ
31:31 Se o o ri i pe dajudaju oko oju-omi n rin ni oju omi pelu idera Re, (sebi) nitori ki (Allahu) le fi han yin ninu awon ami Re ni? Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun gbogbo onisuuru, oludupe
ﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩ
31:32 Nigba ti igbi omi ba bo won mole daru bi awon apata ati esujo, won a pe Allahu (gege bi) olusafomo-adua fun Un. Nigba ti O ba si gba won la sori ile, onideede si maa wa ninu won. Ko si si eni t’o maa tako awon ayah Wa afi gbogbo odale, alaimoore
ﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫ
31:33 Eyin eniyan, e beru Oluwa yin. Ki e si paya ojo kan ti obi kan ko nii sanfaani fun omo re; ati pe omo kan, oun naa ko nii sanfaani kini kan fun obi re. Dajudaju adehun Allahu ni ododo. Nitori naa, isemi aye yii ko gbodo tan yin je. (Esu) eletan ko si gbodo tan yin je nipa Allahu
ﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆﰇﰈﰉﰊ
31:34 Dajudaju Allahu, odo Re ni imo Akoko naa wa. O n so ojo kale. O mo ohun t’o wa ninu apoluke. Emi kan ko si mo ohun ti o maa se nise ni ola. Emi kan ko si mo ile wo l’o maa ku si. Dajudaju Allahu ni Onimo, Alamotan

Al-Kur'an


Wednesday, September 9, 2026

Don't forget us in your sincere prayers