PDF —
37 Ẹsẹ Meccan PDF
Built right in your browser — download starts automatically

Surah Al-Jathiyah pdf — Gbà (Yorùbá)

Surah Al-Jathiyah pdf Yorùbá — Gbà Surah Al-Jathiyah Itumọ. Surah Al-Jathiyah (Meccan) 37 Ẹsẹ.

← Ad-DukhanSurah Al-Jathiyah Al-Ahqaf →


37 Ẹsẹ · Meccan · Yorùbá
bismillah
ﭑﭒ
45:1 Ha mim
ﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙ
45:2 Tira naa sokale lati odo Allahu, Alagbara, Ologbon
ﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠ
45:3 Dajudaju ninu awon sanmo ati ile awon ami wa (ninu won) fun awon onigbagbo ododo
ﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪ
45:4 Awon ami wa ninu iseda yin ati ohun ti Allahu n fonka (sori ile) ninu awon nnkan abemi; (ami wa ninu won) fun ijo t’o ni amodaju
ﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿ
45:5 (Ninu) itelentele ati iyato oru ati osan, ati ohun ti Allahu n sokale ni arisiki, ti O n fi so ile di aye leyin t’o ti ku ati iyipada ategun, awon ami tun wa (ninu won) fun ijo t’o ni laakaye
ﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍ
45:6 Iwonyi ni awon ayah Allahu ti A n ke (ni keu) fun o pelu ododo. Nitori naa, oro wo leyin (oro) Allahu ati awon ami Re ni won yoo tun gbagbo
ﮎﮏﮐﮑﮒ
45:7 Egbe ni fun aladaapaaro, elese
ﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢ
45:8 t’o n gbo awon ayah Allahu, ti won n ke e fun un, leyin naa, ti o (tun) taku ni ti igberaga bi eni pe ko gbo o. Fun un ni iro iya eleta-elero
ﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯ
45:9 Nigba ti o ba nimo nipa kini kan ninu awon ayah Wa, o maa mu un ni nnkan yeye. Awon wonyen ni iya ti i yepere eda n be fun
ﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦ
45:10 Ina Jahanamo wa niwaju won. Ohun ti won se nise ati ohun ti won mu ni alaabo leyin Allahu ko si nii ro won loro kan nibi iya. Iya nla si wa fun won
ﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳ
45:11 Eyi ni imona. Awon t’o si sai gbagbo ninu awon ayah Oluwa won, iya elegbin eleta-elero wa fun won
ﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃ
45:12 Allahu ni Eni ti O ro agbami odo fun yin nitori ki awon oko oju-omi le rin ninu re pelu ase Re ati nitori ki e tun le wa ninu oore Re ati nitori ki e le dupe (fun Un)
ﰄﰅﰆﰇﰈﰉﰊﰋﰌﰍﰎﰏﰐﰑﰒﰓﰔﰕ
45:13 O tun ro ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile patapata fun yin lati odo ara Re. Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun ijo t’o ni arojinle
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟ
45:14 So fun awon t’o gbagbo ni ododo pe ki won samoju kuro fun awon ti ko reti awon ojo (ti) Allahu (yoo se aranse fun awon onigbagbo ododo) nitori ki O le san esan fun ijo kan nipa ohun ti won n se nise
ﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭ
45:15 Enikeni ti o ba se ise rere, fun emi ara re ni. Enikeni ti o ba si se ise aburu, fun emi ara re ni. Leyin naa, odo Oluwa yin ni won yoo da yin pada si
ﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻ
45:16 Dajudaju A fun awon omo ’Isro’il ni Tira ati idajo sise pelu ipo Anabi. A si se arisiki fun won ninu awon nnkan daadaa. A si soore ajulo fun won lori awon eda (asiko won)
ﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖ
45:17 A tun fun won ni awon eri t’o yanju nipa oro naa. Nitori naa, won ko pin si ijo otooto afi leyin ti imo (’Islam) de ba won. (Won se bee) nipase ote aarin won (si awon Anabi). Dajudaju Oluwa re l’O maa se idajo laaarin won ni Ojo Ajinde nipa nnkan ti won n yapa enu si
ﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤ
45:18 Leyin naa, A fi o si oju ona kan ninu oro (esin ’Islam). Nitori naa, tele e. Ki o si ma se tele ife-inu awon ti ko nimo
ﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗ
45:19 Dajudaju won ko le ro o loro kini kan nibi iya ni odo Allahu. Ati pe dajudaju awon alabosi, apa kan won lore apa kan. Allahu si ni Ore awon oluberu (Re)
ﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟ
45:20 Eyi ni itosona fun awon eniyan. Imona ati ike ni fun ijo t’o ni amodaju
ﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲ
45:21 Tabi awon t’o n se ise aburu lero pe A maa se won gege bi (A ti se) awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere, ki isemi aye won ati iku won ri bakan naa? Ohun ti won n da lejo buru
ﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀ
45:22 Allahu seda awon sanmo ati ile pelu ododo ati nitori ki A le san emi kookan ni esan nnkan ti o se nise. A o si nii se abosi si won
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪ
45:23 So fun mi nipa eni ti o so ife-inu re di olohun re, ti Allahu si si i lona pelu imo , ti O si fi edidi di igboro re ati okan re, ti O tun fi ebibo bo oju re! Ta ni o maa fi ona mo on leyin Allahu? Se e o nii lo iranti ni
ﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂ
45:24 Won wi pe: "Ko si isemi kan mo bi ko se isemi aye wa yii; a n ku, a si n semi. Ati pe ko si nnkan t’o n pa wa bi ko se igba." Won ko si ni imo kan nipa iyen; won ko se kini kan bi ko se pe won n ro erokero
ﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓ
45:25 Ati pe nigba ti won ba n ke awon ayah Wa t’o yanju fun won, awijare won ko je kini kan tayo ki won wi pe: "E mu awon baba wa wa ti e ba je olododo
ﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦ
45:26 So pe: "Allahu l’O n so yin di alaaye. Leyin naa, O maa so yin di oku. Leyin naa, O maa ko yin jo ni Ojo Ajinde, ko si iyemeji ninu re, sugbon opolopo eniyan ni ko mo
ﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓ
45:27 Ati pe ti Allahu ni ijoba awon sanmo ati ile. (Ranti) ojo ti Akoko naa maa sele; ojo yen ni awon t’o n tele iro yoo sofo
ﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣ
45:28 O si maa ri gbogbo ijo lori ikunle. Won yo si maa pe ijo kookan sibi iwe ise won. Ni oni ni A oo san yin ni esan ohun ti e n se nise
ﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰ
45:29 Eyi ni iwe akosile Wa, ti o n so ododo nipa yin. Dajudaju Awa n se akosile ohun ti e n se nise
ﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿ
45:30 Ni ti awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere, Oluwa won yoo fi won sinu ike Re. Iyen ni erenje ponnbele
ﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆﰇﰈﰉﰊﰋﰌ
45:31 Ni ti awon t’o si sai gbagbo, (A oo bi won leere pe:) "Nje won ki i ke awon ayah Mi fun yin bi?" Sugbon e segberaga. E si je ijo elese
ﰍﰎﰏﰐﰑﰒﰓﰔﰕﰖﰗﰘﰙﰚﰛﰜﰝﰞﰟﰠﰡﰢﰣ
45:32 Nigba ti won ba so pe: "Dajudaju adehun Allahu ni ododo. Ati pe Akoko naa, ko si iyemeji ninu re." Eyin n wi pe: "Awa ko mo ohun ti Akoko naa je. Awa ko si ro o si kini kan bi ko se erokero; awa ko si ni amodaju (nipa re)
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜ
45:33 Awon aburu ohun ti won se nise si han si won. Ati pe ohun ti won n fi se yeye si diya t’o yi won po
ﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫ
45:34 Won si maa so pe: "Ni oni, Awa yoo gbagbe yin (sinu Ina) gege bi eyin naa se gbagbe ipade ojo yin (oni) yii. Ina si ni ibugbe yin. Ati pe ko nii si awon oluranlowo fun yin
ﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽ
45:35 Bayen ni nitori pe, e so awon ayah Allahu di nnkan yeye. Ati pe isemi aye tan yin je. Nitori naa, ni oni won ko nii mu won jade kuro ninu Ina. Won ko si nii fun won ni aye lati se ohun ti won yoo fi ri iyonu Allahu
ﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆ
45:36 Nitori naa, gbogbo ope n je ti Allahu, Oluwa awon sanmo ati ile, Oluwa gbogbo eda
ﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐ
45:37 TiRe ni titobi ninu awon sanmo ati ile. Oun si ni Alagbara, Ologbon

Al-Kur'an


Wednesday, September 9, 2026

Don't forget us in your sincere prayers