PDF —
11 Ẹsẹ Medinan PDF
Built right in your browser — download starts automatically

Surah Al-Munafiqun pdf — Gbà (Yorùbá)

Surah Al-Munafiqun pdf Yorùbá — Gbà Surah Al-Munafiqun Itumọ. Surah Al-Munafiqun (Medinan) 11 Ẹsẹ.

← Al-Jumu'ahSurah Al-Munafiqun At-Taghabun →


11 Ẹsẹ · Medinan · Yorùbá
bismillah
ﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢ
63:1 Nigba ti awon sobe-selu musulumi ba wa si odo re, won a wi pe: “A n jerii pe dajudaju iwo, Ojise Allahu ni o.” Allahu si mo pe dajudaju iwo, Ojise Re ni o. Allahu si n jerii pe dajudaju awon sobe-selu musulumi, opuro ni won
ﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰ
63:2 Won fi awon ibura won se aabo (fun emi ara won), won si seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Allahu; dajudaju ohun ti won n se nise buru
ﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝ
63:3 (Won se) iyen nitori pe won gbagbo, leyin naa won sai gbagbo. Nitori naa, A ti fi edidi di okan won; won ko si nii gbo agboye
ﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻ
63:4 Nigba ti o ba ri won, irisi won yoo jo o loju. Ti won ba n soro, iwo yoo teti gbo oro won. Won si da bi igi ti won gbe ti ogiri. Won si n lero pe gbogbo igbe (ibosi) n be lori won (nipa isobe-selu won). Ota ni won. Nitori naa, sora fun won. Allahu ti sebi le won. Bawo ni won se n seri won kuro nibi ododo
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟ
63:5 Ati pe nigba ti won ba so fun won pe: “E wa ki Ojise ba yin toro aforijin.” Won a gbunri. O si maa ri won ti won yoo maa gbunri lo, ti won yoo maa segberaga
ﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳ
63:6 Bakan naa ni fun won; yala o ba won toro aforijin tabi o o ba won toro aforijin. Allahu ko nii forijin won. Dajudaju Allahu ko nii fi ona mo ijo obileje
ﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉ
63:7 Awon ni awon t’o n wi pe: “Eyin ko gbodo na owo fun awon t’o wa lodo Ojise Allahu titi won yoo fi fonka. Ti Allahu si ni awon apoti-oro sanmo ati ile, sugbon awon sobe-selu musulumi ko nii gbo agboye
ﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜ
63:8 Won n wi pe: “Dajudaju ti a ba pada de sinu ilu Modinah, nse ni awon alagbara (ilu) yoo yo awon eni yepere jade kuro ninu ilu." Agbara si n je ti Allahu, ati ti Ojise Re ati awon onigbagbo ododo, sugbon awon sobe-selu musulumi ko mo
ﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯ
63:9 Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se je ki awon dukia yin ati awon omo yin ko airoju ba yin nibi iranti Allahu. Enikeni ti o ba ko sinu (airoju) yen, awon wonyen, awon ni eni ofo
ﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦ
63:10 E na ninu ohun ti A pese fun yin siwaju ki iku to de ba eni kan yin, ki o wa wi pe: "Oluwa mi, ki o si je pe O lo mi lara si i titi di igba kan to sunmo, emi iba si le maa tore, emi iba si wa lara awon eni rere
ﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳ
63:11 Allahu ko si nii lo emi kan lara nigba ti ojo iku re ba de. Allahu si ni Alamotan nipa ohun ti e n se nise

Al-Kur'an


Wednesday, September 9, 2026

Don't forget us in your sincere prayers