Surah Al-Jumu'ah pdf — Gbà (Yorùbá)
Surah Al-Jumu'ah pdf Yorùbá — Gbà Surah Al-Jumu'ah Itumọ. Surah Al-Jumu'ah (Medinan) 11 Ẹsẹ.
Related
More Surah PDF
Surah Al-Jumu'ah

ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝ
62:1
Ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun to wa ninu ile n se afomo fun Allahu, Oba eda, Eni-Mimo julo, Alagbara, Ologbon
ﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳ
62:2
Oun ni Eni ti O gbe dide laaarin awon alaimoonkomoonka (alainitira) Ojise kan lara won. O n ke awon ayah Re fun won. O n fo won mo (ninu ese). O si n ko won ni Tira ati ogbon ijinle (iyen, sunnah), bi o tile je pe teletele won ti wa ninu isina ponnbele
ﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽ
62:3
(Ise jije re tun wa fun) awon miiran ti won maa wa ninu awon (omoleyin re), amo ti won ko ti i rin kan won. (Allahu) Oun ni Alagbara, Ologbon
ﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉ
62:4
Iyen ni oore ajulo Allahu. O n fun eni ti O ba fe. Allahu si ni Oloore-ajulo nla
ﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣ
62:5
Apejuwe ijo ti A fun ni Taorah, leyin naa ti won ko tele e, o da bi apejuwe ketekete ti o ru eru awon tira. Aburu ni apejuwe awon t’o pe awon ayah Allahu niro. Allahu ko si nii fi ona mo ijo alabosi
ﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖ
62:6
So pe: "Eyin yehudi, ti e ba lero pe dajudaju eyin ni ore Allahu dipo awon eniyan (yooku), e toro iku nigba naa ti e ba je olododo
ﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡ
62:7
Won ko nii toro re laelae nitori ohun ti owo won ti ti siwaju. Allahu si ni Onimo nipa awon alabosi
ﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵ
62:8
So pe: "Dajudaju iku ti e n sa fun, dajudaju o maa pade yin. Leyin naa, won yoo da yin pada si odo Onimo-ikoko ati gbangba. O si maa fun yin ni iro ohun ti e n se nise
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧ
62:9
Eyin ti e gbagbo ni ododo, nigba ti won ba pe irun ni ojo Jum‘ah, e yara lo sibi iranti Allahu, ki e si pa kata-kara ti. Iyen loore julo fun yin ti e ba mo
ﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷ
62:10
Nigba ti won ba si pari irun, e tuka si ori ile, ki e si maa wa ninu oore Allahu. E ranti Allahu ni opolopo nitori ki e le jere
ﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏ
62:11
Nigba ti won ba ri oja kan tabi iranu kan, won yoo da lo sibe. Won yo si fi o sile lori iduro. So pe: "Nnkan ti o wa ni odo Allahu l’oore ju iranu ati oja lo. Allahu si l’oore julo ninu awon olupese
Al-Kur'an
Wednesday, September 9, 2026
Don't forget us in your sincere prayers







