Перевод суры Та Ха на Йоруба язык
طه(1) To ha |
A ko so al-Ƙur’an kale fun o lati ko wahala ba o |
Bi ko se pe o je iranti fun eni t’o n paya (Allahu) |
تَنزِيلًا مِّمَّنْ خَلَقَ الْأَرْضَ وَالسَّمَاوَاتِ الْعُلَى(4) (O je) imisi t’o sokale lati odo Eni ti O da ile ati awon sanmo giga |
Ajoke-aye gunwa sori Ite-ola |
لَهُ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ وَمَا بَيْنَهُمَا وَمَا تَحْتَ الثَّرَىٰ(6) TiRe ni ohunkohun t’o wa ninu |
وَإِن تَجْهَرْ بِالْقَوْلِ فَإِنَّهُ يَعْلَمُ السِّرَّ وَأَخْفَى(7) Ti o ba so oro jade, dajudaju (Allahu) mo ikoko ati ohun ti o (tun) pamo julo |
اللَّهُ لَا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ ۖ لَهُ الْأَسْمَاءُ الْحُسْنَىٰ(8) Allahu, ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. TiRe ni awon oruko t’o dara julo |
Nje oro (Anabi) Musa de odo re |
(Ranti) nigba ti o ri ina kan, o so fun awon ara ile re pe: “E duro sibi. Dajudaju emi ri ina kan. O see se ki ng ri ogunna mu wa fun yin ninu re tabi ki ng ri oju ona kan nitosi ina naa.” |
Nigba ti o de ibe, A pe e "Musa |
إِنِّي أَنَا رَبُّكَ فَاخْلَعْ نَعْلَيْكَ ۖ إِنَّكَ بِالْوَادِ الْمُقَدَّسِ طُوًى(12) Dajudaju Emi ni Oluwa re. Nitori naa, bo bata re mejeeji sile. Dajudaju iwo wa ni afonifoji mimo, Tuwa |
Ati pe Emi sa o lesa. Nitori naa, fi eti si ohun ti A maa fi ranse si o ninu imisi |
إِنَّنِي أَنَا اللَّهُ لَا إِلَٰهَ إِلَّا أَنَا فَاعْبُدْنِي وَأَقِمِ الصَّلَاةَ لِذِكْرِي(14) Dajudaju Emi ni Allahu. Ko si olohun ti ijosin to si afi Emi. Nitori naa, josin fun Mi. Ki o si kirun fun iranti Mi |
إِنَّ السَّاعَةَ آتِيَةٌ أَكَادُ أُخْفِيهَا لِتُجْزَىٰ كُلُّ نَفْسٍ بِمَا تَسْعَىٰ(15) Dajudaju Akoko naa n bo. O sunmo ki Ng safi han re (pelu awon ami. Akoko naa wa fun) ki A le san emi kookan ni esan nnkan ti o se nise |
فَلَا يَصُدَّنَّكَ عَنْهَا مَن لَّا يُؤْمِنُ بِهَا وَاتَّبَعَ هَوَاهُ فَتَرْدَىٰ(16) Nitori naa, eni ti ko gba a gbo, ti o si tele ife-inu re, ma se je ki o seri re kuro nibe, ki o ma baa parun |
Ki ni iyen lowo otun re, Musa |
O so pe: “Opa mi ni. Mo n fi rogboku. Mo tun n fi ja ewe fun awon agutan mi. Mo si tun n lo o fun awon bukata miiran.” |
(Allahu) so pe: “Ju u sile, Musa.” |
Nigba naa, o ju u sile. O si di ejo t’o n sare |
قَالَ خُذْهَا وَلَا تَخَفْ ۖ سَنُعِيدُهَا سِيرَتَهَا الْأُولَىٰ(21) (Allahu) so pe: "Mu un dani, ma si se beru. A maa da a pada si irisi re akoko |
وَاضْمُمْ يَدَكَ إِلَىٰ جَنَاحِكَ تَخْرُجْ بَيْضَاءَ مِنْ غَيْرِ سُوءٍ آيَةً أُخْرَىٰ(22) Fi owo re mo (abe) apa re, o maa jade ni funfun, ti ki i se taburu. (O tun je) ami miiran |
Ki A le fi eyi t’o tobi ninu awon ami Wa han o |
Lo si odo Fir‘aon. Dajudaju o ti tayo enu-ala |
(Anabi Musa) so pe: “Oluwa mi, si okan mi paya fun mi |
Soro mi dirorun fun mi |
Tu koko ori ahon mi |
ki won maa gbo oro mi ye |
Ati pe fun mi ni amugbalegbee kan ninu awon ara ile mi |
هَارُونَ أَخِي(30) Harun, arakunrin mi ni |
Fi kun mi lowo |
Fi sakegbe mi ninu ise mi |
ki a le safomo (oruko) Re ni opolopo |
ki a tun le seranti Re ni opolopo |
Dajudaju Iwo n ri wa.” |
(Allahu) so pe: "Dajudaju A ti fun o ni ibeere re, Musa |
Ati pe dajudaju A ti se oore fun o nigba kan ri |
(Ranti) nigba ti A sipaya ohun ti A sipaya fun iya re |
pe: “Ju Musa sinu apoti. Ki o si gbe e ju sinu agbami odo. Odo yo si gbe e ju si eti odo. Ota Mi ati ota re si maa gbe e.” Mo si da ife lati odo Mi bo o nitori ki won le toju re loju Mi.” |
(Ranti) nigba ti arabinrin re n rin lo, o si so pe: “Se ki ng juwe eni ti o maa gba a to (fun yin)?” A si da o pada sodo iya re nitori ki o le ni itutu oju, ko si nii banuje. Ati pe o pa emi eni kan. A si mu o kuro ninu ibanuje. A tun mu awon adanwo kan ba o. O tun lo awon odun kan lodo awon ara Modyan. Leyin naa, o de (ni akoko) ti o ti wa ninu kadara, Musa |
Mo si sa o lesa fun (ise) Mi |
اذْهَبْ أَنتَ وَأَخُوكَ بِآيَاتِي وَلَا تَنِيَا فِي ذِكْرِي(42) Lo, iwo ati arakunrin re, pelu awon ami (ise iyanu) Mi. Ki e si ma se kole ninu iranti Mi |
E lo ba Fir‘aon. Dajudaju o ti tayo enu-ala |
فَقُولَا لَهُ قَوْلًا لَّيِّنًا لَّعَلَّهُ يَتَذَكَّرُ أَوْ يَخْشَىٰ(44) E so oro ele fun un. O see se ki o lo isiti tabi ki o paya (Mi) |
قَالَا رَبَّنَا إِنَّنَا نَخَافُ أَن يَفْرُطَ عَلَيْنَا أَوْ أَن يَطْغَىٰ(45) Awon mejeeji so pe: “Oluwa wa, dajudaju awa n paya pe o ma yara je wa niya tabi pe o ma tayo enu-ala.” |
قَالَ لَا تَخَافَا ۖ إِنَّنِي مَعَكُمَا أَسْمَعُ وَأَرَىٰ(46) (Allahu) so pe: “E ma se paya. Dajudaju Emi wa pelu eyin mejeeji; Mo n gbo (yin), Mo si n ri (yin).” |
Nitori naa, e lo ba a, ki e so fun un pe: “Dajudaju Ojise Oluwa re ni awa mejeeji. Nitori naa, je ki awon omo ’Isro’il maa ba wa lo. Ma se fiya je won. Dajudaju a ti mu ami kan wa ba o lati odo Oluwa re. Ki alaafia si maa ba eni ti o ba tele imona |
إِنَّا قَدْ أُوحِيَ إِلَيْنَا أَنَّ الْعَذَابَ عَلَىٰ مَن كَذَّبَ وَتَوَلَّىٰ(48) Dajudaju Won ti fi imisi ranse si wa pe dajudaju iya n be fun eni ti o ba pe ododo niro, ti o si keyin si i |
(Fir‘aon) wi pe: “Ta ni Oluwa eyin mejeeji, Musa?” |
قَالَ رَبُّنَا الَّذِي أَعْطَىٰ كُلَّ شَيْءٍ خَلْقَهُ ثُمَّ هَدَىٰ(50) (Anabi Musa) so pe: “Oluwa wa ni Eni ti O fun gbogbo nnkan ni iseda re. Leyin naa, O to o si ona.” |
(Fir‘aon) wi pe: “Ki l’o mu awon iran akoko (ti won ko fi mona)?” |
قَالَ عِلْمُهَا عِندَ رَبِّي فِي كِتَابٍ ۖ لَّا يَضِلُّ رَبِّي وَلَا يَنسَى(52) (Anabi Musa) so pe: "Imo re wa ninu tira kan lodo Oluwa mi. Oluwa mi ko nii sasise. Ko si nii gbagbe |
(Oun ni) Eni ti O te ile ni perese fun yin. O si la awon ona sinu re fun yin. O si so omi kale lati sanmo. A si fi mu orisirisi jade ninu awon irugbin ni otooto |
كُلُوا وَارْعَوْا أَنْعَامَكُمْ ۗ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَاتٍ لِّأُولِي النُّهَىٰ(54) E je, ki e si fi bo awon eran-osin yin. Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun awon onilaakaye |
۞ مِنْهَا خَلَقْنَاكُمْ وَفِيهَا نُعِيدُكُمْ وَمِنْهَا نُخْرِجُكُمْ تَارَةً أُخْرَىٰ(55) Lati ara erupe ni A ti da yin. Inu re si ni A oo da yin pada si. Lati inu re si ni A oo ti mu yin jade pada nigba miiran |
وَلَقَدْ أَرَيْنَاهُ آيَاتِنَا كُلَّهَا فَكَذَّبَ وَأَبَىٰ(56) Dajudaju A ti fi awon ami Wa han an, gbogbo re. Amo o pe e niro. O si ko jale |
قَالَ أَجِئْتَنَا لِتُخْرِجَنَا مِنْ أَرْضِنَا بِسِحْرِكَ يَا مُوسَىٰ(57) O wi pe: "Se o wa ba wa nitori ki o le mu wa jade kuro lori ile wa pelu idan re ni, Musa |
Dajudaju a maa mu idan iru re wa ba o. Nitori naa, mu akoko ipade laaarin awa ati iwo, ti awa ati iwo ko si nii yapa re, (ki o si mu) aye kan t’o teju |
قَالَ مَوْعِدُكُمْ يَوْمُ الزِّينَةِ وَأَن يُحْشَرَ النَّاسُ ضُحًى(59) (Anabi Musa) so pe: “Akoko ipade yin ni ojo Oso (iyen, ojo odun). Ki won si ko awon eniyan jo ni iyaleta.” |
Fir‘aon peyin da. O si sa ete re jo mora won. Leyin naa, o de (sibe) |
(Anabi Musa) so pe: “Egbe yin o! E ma se da adapa iro mo Allahu nitori ki O ma baa fi iya pa yin re. Ati pe dajudaju enikeni ti o ba da adapa iro (mo Allahu) ti sofo.” |
فَتَنَازَعُوا أَمْرَهُم بَيْنَهُمْ وَأَسَرُّوا النَّجْوَىٰ(62) Won foro jomi toro oro laaarin ara won. Won si te soro |
Won wi pe: "Dajudaju awon mejeeji yii, opidan ni won o. Won fe mu yin jade kuro lori ile yin pelu idan won ni. Won si (fe) gba oju ona yin t’o dara julo mo yin lowo |
فَأَجْمِعُوا كَيْدَكُمْ ثُمَّ ائْتُوا صَفًّا ۚ وَقَدْ أَفْلَحَ الْيَوْمَ مَنِ اسْتَعْلَىٰ(64) Nitori naa, e ko ete yin jo papo mora won. Leyin naa, ki e to wa ni owoowo. Dajudaju eni ti o ba bori ni oni ti jere |
قَالُوا يَا مُوسَىٰ إِمَّا أَن تُلْقِيَ وَإِمَّا أَن نَّكُونَ أَوَّلَ مَنْ أَلْقَىٰ(65) (Awon opidan) wi pe: “Musa, iwo ni o maa koko ju (opa sile ni) tabi awa ni a oo koko ju u sile.” |
(Musa) so pe: “E ju (tiyin) sile (na).” Nigba naa ni awon okun won ati opa won ba n yira pada loju re nipase idan won, bi eni pe dajudaju won n sare |
(Anabi) Musa si pa eru inu okan re mora |
A so pe: "Ma se paya. Dajudaju iwo, iwo lo maa leke |
Ju ohun ti n be ni owo otun re sile. O si maa gbe ohun ti won se kale mi kalo. Dajudaju ohun ti won se kale, ete opidan ni. Opidan ko si nii jere ni ibikibi ti o ba de |
فَأُلْقِيَ السَّحَرَةُ سُجَّدًا قَالُوا آمَنَّا بِرَبِّ هَارُونَ وَمُوسَىٰ(70) Nitori naa, ise iyanu (Anabi Musa) mu awon opidan doju bole ni oluforikanle (fun Allahu). Won wi pe: "A gbagbo ninu Oluwa Harun ati Musa |
(Fir‘aon) wi pe: "Se e ti gba a gbo siwaju ki ng to yonda fun yin? Dajudaju oun ni agba yin ti o ko yin ni idan pipa. Nitori naa, dajudaju mo maa ge awon owo yin ati ese yin ni ipasipayo. Dajudaju mo tun maa kan yin mo awon igi dabinu. Dajudaju eyin yoo mo ewo ninu wa ni iya (re) yoo le julo, ti o si maa pe julo |
(Awon opidan) so pe: "Awa ko nii gbola fun o lori ohun ti o de ba wa ninu awon eri t’o daju, (a o si nii gbola fun o lori) Eni ti O seda wa. Nitori naa, da ohun ti o ba fe da lejo. Ile aye yii nikan ni o ti le dajo |
Dajudaju awa gba Oluwa wa gbo nitori ki O le se aforijin awon ese wa fun wa ati ohun ti o je wa nipa se ninu idan pipa. Allahu loore julo, O si maa wa titi laelae |
إِنَّهُ مَن يَأْتِ رَبَّهُ مُجْرِمًا فَإِنَّ لَهُ جَهَنَّمَ لَا يَمُوتُ فِيهَا وَلَا يَحْيَىٰ(74) Dajudaju enikeni ti o ba wa ba Oluwa re ni (ipo) elese, dajudaju ina Jahanamo ti wa fun un. Ko nii ku sinu re, ko si nii wa laaye |
وَمَن يَأْتِهِ مُؤْمِنًا قَدْ عَمِلَ الصَّالِحَاتِ فَأُولَٰئِكَ لَهُمُ الدَّرَجَاتُ الْعُلَىٰ(75) Enikeni ti o ba si wa ba A (gege bi) onigbagbo ododo, ti o si ti se ise rere, awon wonyen ni awon ipo giga n be fun |
(Ohun ni) awon Ogba Idera gbere ti awon odo n san ni isale re. Olusegbere ni won ninu re. Iyen si ni esan fun enikeni ti o ba safomo (ise re) |
Ati pe dajudaju A ti fi imisi ranse si (Anabi) Musa bayii pe: “Mu awon erusin Mi rin ni oru. Fi (opa re) na omi fun won (ki o di) oju ona gbigbe ninu omi okun. Ma se beru aleba, ma si se paya (iteri sinu omi okun).” |
فَأَتْبَعَهُمْ فِرْعَوْنُ بِجُنُودِهِ فَغَشِيَهُم مِّنَ الْيَمِّ مَا غَشِيَهُمْ(78) Fir‘aon si tele won pelu awon omo ogun re. Ohun ti o bo won mole daru ninu agbami odo si bo won mole daru |
Fir‘aon si awon eniyan re lona; oun (naa) ko si mona |
Eyin omo ’Isro’il, dajudaju A ti gba yin la lowo ota yin. A si ba yin se adehun egbe otun apata. A si so ohun mimu monu ati ohun jije salwa kale fun yin |
E je ninu awon nnkan daadaa ti A pa lese fun yin. E ma si koja enu ala ninu re nitori ki ibinu Mi ma baa ko le yin lori. Enikeni ti ibinu Mi ba si ko le lori, dajudaju o ti jabo (sinu iparun) |
وَإِنِّي لَغَفَّارٌ لِّمَن تَابَ وَآمَنَ وَعَمِلَ صَالِحًا ثُمَّ اهْتَدَىٰ(82) Dajudaju Emi ni Alaforijin fun enikeni ti o ba ronu piwada, ti o gbagbo ni ododo, ti o si se ise rere, leyin naa ti o tun tele imona |
Ki ni o mu o kanju ya awon eniyan re sile, Musa |
قَالَ هُمْ أُولَاءِ عَلَىٰ أَثَرِي وَعَجِلْتُ إِلَيْكَ رَبِّ لِتَرْضَىٰ(84) O so pe: “Awon niwonyi ti won n to oripa mi bo (leyin mi). Emi si kanju wa sodo Re nitori ki O le yonu si mi ni, Oluwa mi.” |
قَالَ فَإِنَّا قَدْ فَتَنَّا قَوْمَكَ مِن بَعْدِكَ وَأَضَلَّهُمُ السَّامِرِيُّ(85) (Allahu) so pe: "Dajudaju Awa ti dan ijo re wo leyin re. Ati pe Samiriy si won lona |
(Anabi) Musa si pada sodo ijo re pelu ibinu ati ibanuje. O so pe: "Eyin ijo mi, se Oluwa yin ko ti ba yin se adehun daadaa ni? Se adehun ti pe ju loju yin ni tabi e fe ki ibinu ko le yin lori lati odo Oluwa yin ni e fi yapa adehun mi |
Won wi pe: “Awa ko finnufindo yapa adehun funra wa, sugbon won di eru oso awon eniyan (Misro) ru wa lorun. A si ju u sinu ina (pelu ase Samiriyy). Bayen naa si ni Samiriyy se ju tire.” |
O si (fi mo) omo maalu oborogidi kan jade fun won, t’o n dun (bii maalu). Won si wi pe: "Eyi ni olohun yin ati olohun Musa. Amo o ti gbagbe (re) |
أَفَلَا يَرَوْنَ أَلَّا يَرْجِعُ إِلَيْهِمْ قَوْلًا وَلَا يَمْلِكُ لَهُمْ ضَرًّا وَلَا نَفْعًا(89) Se won ko ri i pe ko le da esi oro kan pada fun won ni, ko si ni agbara lati ko inira tabi anfaani kan ba won |
Ati pe dajudaju Harun ti so fun won siwaju pe: “Eyin ijo mi, won kan fi se adanwo fun yin ni. Dajudaju Oluwa yin ni Ajoke-aye. Nitori naa, e tele mi. Ki e si tele ase mi.” |
قَالُوا لَن نَّبْرَحَ عَلَيْهِ عَاكِفِينَ حَتَّىٰ يَرْجِعَ إِلَيْنَا مُوسَىٰ(91) Won wi pe: “A o nii ye duro sodo re titi (Anabi) Musa yoo fi pada sodo wa.” |
قَالَ يَا هَارُونُ مَا مَنَعَكَ إِذْ رَأَيْتَهُمْ ضَلُّوا(92) (Anabi) Musa so pe: "Harun, ki ni o ko fun o nigba ti o ri won ti won sina |
lati to mi wa? Se o yapa ase mi ni |
(Anabi Harun) so pe: “Omo iya mi, ma se fi irungbon mi tabi ori mi fa mi (mora). Dajudaju emi paya pe o maa so pe: O da opinya sile laaarin awon omo ’Isro’il. O o si so oro mi |
(Anabi Musa) so pe: “Ki ni oro tire ti je, Samiriyy?” |
(Samiriyy) wi pe: “Mo ri ohun ti won ko ri. Mo si bu ekunwo kan nibi (erupe) oju ese (esin) Ojise (iyen, molaika Jibril). Mo si da a sile (lati fi mo ere). Bayen ni emi mi se (aburu) ni oso fun mi.” |
(Anabi Musa) so pe: “Nitori naa, maa lo. Dajudaju (ijiya) re nile aye yii ni ki o maa wi pe, “Ma fi ara kan mi”. Ati pe dajudaju ojo iya kan n be fun o ti Won ko nii gbe fo o. Ki o si wo olohun re, eyi ti o taku ti lorun, dajudaju a maa dana sun un. Leyin naa, dajudaju a maa ku eeru re danu patapata sinu agbami odo |
إِنَّمَا إِلَٰهُكُمُ اللَّهُ الَّذِي لَا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ ۚ وَسِعَ كُلَّ شَيْءٍ عِلْمًا(98) Olohun yin ni Allahu nikan, ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. O fi imo gbooro ju gbogbo nnkan |
كَذَٰلِكَ نَقُصُّ عَلَيْكَ مِنْ أَنبَاءِ مَا قَدْ سَبَقَ ۚ وَقَدْ آتَيْنَاكَ مِن لَّدُنَّا ذِكْرًا(99) Bayen ni A se n so itan fun o ninu awon iro ti o ti siwaju. Lati odo Wa si ni A kuku ti fun o ni iranti (iyen, al-Ƙur’an) |
مَّنْ أَعْرَضَ عَنْهُ فَإِنَّهُ يَحْمِلُ يَوْمَ الْقِيَامَةِ وِزْرًا(100) Enikeni ti o ba gbunri kuro nibe, dajudaju o maa ru eru ese ni Ojo Ajinde |
خَالِدِينَ فِيهِ ۖ وَسَاءَ لَهُمْ يَوْمَ الْقِيَامَةِ حِمْلًا(101) Olusegbere ni won ninu (iya) re. (Eru ese) si buru fun won lati ru ni Ojo Ajinde |
يَوْمَ يُنفَخُ فِي الصُّورِ ۚ وَنَحْشُرُ الْمُجْرِمِينَ يَوْمَئِذٍ زُرْقًا(102) Ni ojo ti won a fon fere oniwo fun ajinde. A si maa ko awon elese jo ni ojo yen, oju won yo si dudu batakun |
يَتَخَافَتُونَ بَيْنَهُمْ إِن لَّبِثْتُمْ إِلَّا عَشْرًا(103) Won yo si maa soro ni jeeje laaarin ara won pe: "Eyin ko gbe ile aye tayo (ojo) mewaa |
نَّحْنُ أَعْلَمُ بِمَا يَقُولُونَ إِذْ يَقُولُ أَمْثَلُهُمْ طَرِيقَةً إِن لَّبِثْتُمْ إِلَّا يَوْمًا(104) Awa nimo julo nipa ohun ti won n wi nigba ti eni-abiyi julo ninu won wi pe: “E ko gbe ile aye tayo ojo kan.” |
وَيَسْأَلُونَكَ عَنِ الْجِبَالِ فَقُلْ يَنسِفُهَا رَبِّي نَسْفًا(105) Won n bi o leere nipa awon apata. So pe: “Oluwa mi yoo ku won danu tan raurau |
Nigba naa, O maa fi won sile ni petele gbansasa |
O o si nii ri ogbun tabi gelemo kan ninu re |
Ni ojo yen, awon eniyan yoo tele olupepe naa, ko nii si yiya kuro leyin re. Awon ohun yo si palolo fun Ajoke-aye. Nitori naa, o o nii gbo ohun kan bi ko se girigiri ese |
يَوْمَئِذٍ لَّا تَنفَعُ الشَّفَاعَةُ إِلَّا مَنْ أَذِنَ لَهُ الرَّحْمَٰنُ وَرَضِيَ لَهُ قَوْلًا(109) Ni ojo yen, isipe ko nii se anfaani afi eni ti Ajoke-aye ba yonda fun, ti O si yonu si oro fun un |
يَعْلَمُ مَا بَيْنَ أَيْدِيهِمْ وَمَا خَلْفَهُمْ وَلَا يُحِيطُونَ بِهِ عِلْمًا(110) (Allahu) mo ohun ti n be niwaju won ati ohun ti n be ni eyin won. Awon ko si fi imo rokiri ka Re |
۞ وَعَنَتِ الْوُجُوهُ لِلْحَيِّ الْقَيُّومِ ۖ وَقَدْ خَابَ مَنْ حَمَلَ ظُلْمًا(111) Awon oju yo si wole fun Alaaye, Alamojuuto-eda. Dajudaju enikeni ti o ba di abosi meru ti pofo |
وَمَن يَعْمَلْ مِنَ الصَّالِحَاتِ وَهُوَ مُؤْمِنٌ فَلَا يَخَافُ ظُلْمًا وَلَا هَضْمًا(112) Enikeni ti o ba se ninu awon ise rere, ti o si je onigbagbo ododo, ki o ma se paya abosi tabi ireje kan (lati odo Allahu) |
Bayen ni A se so (iranti) kale ni ohun kike pelu ede Larubawa. A si se alaye oniran-anran ileri sinu re nitori ki won le sora (fun iya) tabi nitori ki o le je iranti fun won |
Nitori naa, Allahu Oba Ododo ga julo. Ma se kanju pelu al-Ƙur’an siwaju ki won to pari imisi re fun o. Ki o si so pe: “Oluwa mi, salekun imo fun mi.” |
وَلَقَدْ عَهِدْنَا إِلَىٰ آدَمَ مِن قَبْلُ فَنَسِيَ وَلَمْ نَجِدْ لَهُ عَزْمًا(115) Dajudaju A se adehun fun (Anabi) Adam siwaju. Sugbon o gbagbe. A ko si ba a pelu ipinnu okan |
وَإِذْ قُلْنَا لِلْمَلَائِكَةِ اسْجُدُوا لِآدَمَ فَسَجَدُوا إِلَّا إِبْلِيسَ أَبَىٰ(116) Nigba ti A so fun awon molaika pe: “E fori kanle ki Adam. Won si fori kanle ki i afi ’Iblis, (ti) o ko.” |
Nitori naa, A so pe: "Adam, dajudaju eyi ni ota fun iwo ati iyawo re. Nitori naa, ko gbodo mu eyin mejeeji jade kuro ninu Ogba Idera nitori ki o ma baa daamu (fun ije-imu) |
Dajudaju ebi ko nii pa o, o o si nii rin hoho ninu re |
Ati pe dajudaju ongbe ko nii gbe o ninu re, oorun ko si nii pa o |
Sugbon Esu ko royiroyi ba a; o wi pe: “Adam, nje mo le juwe re si igi gbere ati ijoba ti ko nii tan?” |
Nitori naa, awon mejeeji je ninu (eso) re. Ihoho awon mejeeji si han sira won; awon mejeeji si bere si da ewe Ogba Idera bo ara won. Adam yapa ase Oluwa re. O si sina |
Leyin naa, Oluwa re sa a lesa; O gba ironupiwada re, O si to o si ona |
(Allahu) so pe: "Eyin mejeeji, e jade kuro ninu re patapata. Apa kan yin si je ota si apa kan - eyin ati Esu. Nigba ti imona ba si de ba yin lati odo Mi, enikeni ti o ba tele imona Mi, ko nii sina, ko si nii daamu |
وَمَنْ أَعْرَضَ عَن ذِكْرِي فَإِنَّ لَهُ مَعِيشَةً ضَنكًا وَنَحْشُرُهُ يَوْمَ الْقِيَامَةِ أَعْمَىٰ(124) Enikeni ti o ba si seri kuro nibi iranti Mi, dajudaju isemi inira maa wa fun un nile aye. A si maa gbe e dide ni afoju ni Ojo Ajinde.” |
قَالَ رَبِّ لِمَ حَشَرْتَنِي أَعْمَىٰ وَقَدْ كُنتُ بَصِيرًا(125) (O) maa wi pe: “Oluwa mi, nitori ki ni O fi gbe mi dide ni afoju? Mo ti je oluriran tele!” |
قَالَ كَذَٰلِكَ أَتَتْكَ آيَاتُنَا فَنَسِيتَهَا ۖ وَكَذَٰلِكَ الْيَوْمَ تُنسَىٰ(126) (Allahu) so pe: "Bayen ni awon ayah Wa se de ba o, o si gbagbe re (o pa a ti). Ni oni, bayen ni won se maa gbagbe iwo naa (sinu Ina) |
Ati pe bayen ni A se n san esan fun enikeni ti o ba se aseju, ti ko si gbagbo ninu awon ayah Oluwa re. Dajudaju iya Ojo Ikeyin le julo. O si maa wa titi laelae |
Se ko han si won pe meloo meloo ninu awon iran ti A ti parun siwaju won, ti (awon wonyi naa) si n rin koja ni ibugbe won! Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun awon oloye |
وَلَوْلَا كَلِمَةٌ سَبَقَتْ مِن رَّبِّكَ لَكَانَ لِزَامًا وَأَجَلٌ مُّسَمًّى(129) Ti ko ba je pe oro kan t’o siwaju ati gbedeke akoko kan lodo Oluwa re (iya ese won) iba ti di dandan |
Nitori naa, se suuru lori ohun ti won n wi, ki o si se afomo pelu ope fun Oluwa Re siwaju yiyo oorun ati siwaju wiwo re. Se afomo (fun Allahu) ni awon asiko ale ati ni awon abala osan, ki o reti (esan) ti o maa yonu si |
Ma se feju re si ohun ti A fi se igbadun t’o je ododo isemi ile aye fun awon iran-iran kan ninu won. (A fun won) nitori ki A le fi se adanwo fun won ni. Arisiki Oluwa re loore julo. O si maa wa titi laelae |
Pa ara ile re lase irun kiki, ki o si se suuru lori re. A o nii beere ese kan lowo re; Awa l’A n pese fun o. Igbeyin rere si wa fun iberu (Allahu) |
Won wi pe: “Nitori ki ni ko fi mu ami kan wa fun wa lati odo Oluwa re?” Se eri t’o yanju t’o wa ninu awon takada akoko ko de ba won ni |
Ti o ba je pe dajudaju A ti fi iya kan pa won run siwaju re ni, won iba wi pe: "Oluwa wa nitori ki ni O o se ran Ojise kan si wa, awa iba tele awon ayah Re siwaju ki a to yepere, (ki a si to) kabuku |
So pe: “Eni kookan ni olureti (ikangun).” Nitori naa, e maa reti (re). E maa mo ta ni ero ona taara ati eni t’o mona |
Больше сур в Йоруба:
Скачать суру Ta-Ha с голосом самых известных рекитаторов Корана:
Сура Ta-Ha mp3: выберите рекитатора, чтобы прослушать и скачать главу Ta-Ha полностью в высоком качестве
Ahmed Al Ajmy
Bandar Balila
Khalid Al Jalil
Saad Al Ghamdi
Saud Al Shuraim
Abdul Basit
Abdul Rashid Sufi
Abdullah Basfar
Abdullah Al Juhani
Fares Abbad
Maher Al Muaiqly
Al Minshawi
Al Hosary
Mishari Al-afasi
Yasser Al Dosari
Помолитесь за нас хорошей молитвой