📖 0/604 oju-iwe ti a ka
📄 518
Surah Qaf

Surah Qaf

50:2
بَلۡ عَجِبُوٓاْ أَن جَآءَهُم مُّنذِرٌ مِّنۡهُمۡ فَقَالَ ٱلۡكَٰفِرُونَ هَٰذَا شَيۡءٌ عَجِيبٌ ٢
Sugbon won seemo nitori pe olukilo kan wa ba won lati aarin ara won. Awon alaigbagbo si wi pe: "Eyi ni ohun iyanu
50:3
أَءِذَا مِتۡنَا وَكُنَّا تُرَابًاۖ ذَٰلِكَ رَجۡعُۢ بَعِيدٌ ٣
Se nigba ti a ba ti ku, ti a ti di erupe (ni a oo tun ji dide pada). Iyen ni idapada to jinna (si nnkan ti o le sele)
50:4
قَدۡ عَلِمۡنَا مَا تَنقُصُ ٱلۡأَرۡضُ مِنۡهُمۡۖ وَعِندَنَا كِتَٰبٌ حَفِيظُۢ ٤
Dajudaju A ti mo ohun ti ile n mu je ninu won. Tira (ise eda ) ti won n so si wa ni odo Wa
50:5
بَلۡ كَذَّبُواْ بِٱلۡحَقِّ لَمَّا جَآءَهُمۡ فَهُمۡ فِيٓ أَمۡرٍ مَّرِيجٍ ٥
Sibesibe won pe ododo (al-Ƙur’an) ni iro nigba ti o de ba won. Nitori naa, won ti wa ninu idaamu
50:6
أَفَلَمۡ يَنظُرُوٓاْ إِلَى ٱلسَّمَآءِ فَوۡقَهُمۡ كَيۡفَ بَنَيۡنَٰهَا وَزَيَّنَّٰهَا وَمَا لَهَا مِن فُرُوجٍ ٦
Se won ko wo sanmo oke won bi A ti se mo on pa ati (bi) A ti se e ni oso, ti ko si si alafo sisan kan lara re
50:7
وَٱلۡأَرۡضَ مَدَدۡنَٰهَا وَأَلۡقَيۡنَا فِيهَا رَوَٰسِيَ وَأَنۢبَتۡنَا فِيهَا مِن كُلِّ زَوۡجِۭ بَهِيجٍ ٧
Ati pe ile, A te e perese. A si ju awon apata t’o duro gbagidi sinu re. A si mu orisirisi irugbin t’o dara hu jade lati inu re
50:8
تَبۡصِرَةً وَذِكۡرَىٰ لِكُلِّ عَبۡدٍ مُّنِيبٍ ٨
(O je) ariwoye ati iranti fun gbogbo erusin to n seri pada (sibi ododo)
50:9
وَنَزَّلۡنَا مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءً مُّبَٰرَكًا فَأَنۢبَتۡنَا بِهِۦ جَنَّٰتٍ وَحَبَّ ٱلۡحَصِيدِ ٩
A n so omi ibukun kale lati sanmo. A si n fi mu awon ogba oko ati awon eso ti won maa kaje hu jade
50:10
وَٱلنَّخۡلَ بَاسِقَٰتٍ لَّهَا طَلۡعٌ نَّضِيدٌ ١٠
(A tun mu) igi dabinu hu ga, ti awon eso ori re so jigbinni
50:11
رِّزۡقًا لِّلۡعِبَادِۖ وَأَحۡيَيۡنَا بِهِۦ بَلۡدَةً مَّيۡتًاۚ كَذَٰلِكَ ٱلۡخُرُوجُ ١١
Arisiki ni fun awon eru (Allahu). A si n fi so oku ile di aye. Bayen ni ijade eda (lati inu saree yo se ri)
50:12
كَذَّبَتۡ قَبۡلَهُمۡ قَوۡمُ نُوحٍ وَأَصۡحَٰبُ ٱلرَّسِّ وَثَمُودُ ١٢
Awon eniyan (Anabi) Nuh, awon eniyan Rass ati awon (eniyan) Thamud pe ododo niro siwaju won
50:13
وَعَادٌ وَفِرۡعَوۡنُ وَإِخۡوَٰنُ لُوطٍ ١٣
Ati awon ‘Ad, Fir‘aon ati awon omo iya (Anabi) Lut
50:14
وَأَصۡحَٰبُ ٱلۡأَيۡكَةِ وَقَوۡمُ تُبَّعٍۚ كُلٌّ كَذَّبَ ٱلرُّسُلَ فَحَقَّ وَعِيدِ ١٤
ati awon ara ’Aekah ati awon ijo Tubba‘u; gbogbo won pe awon Ojise ni opuro. Nitori naa, ileri Mi si di eto (lori won)
50:15
أَفَعَيِينَا بِٱلۡخَلۡقِ ٱلۡأَوَّلِۚ بَلۡ هُمۡ فِي لَبۡسٍ مِّنۡ خَلۡقٍ جَدِيدٍ ١٥
Nje iseda akoko ko agara ba Wa bi? Rara, won wa ninu iyemeji nipa iseda (won) ni titun ni
العربيةEnglishBahasa IndonesiaTürkçeРусскийفارسیFrançaisاردوবাংলাDeutschEspañol中文हिन्दीPortuguêsItalianoภาษาไทยPolskiNederlandsShqipKiswahiliO'zbekதமிழ்MelayuBosanskiSoomaaliAzərbaycanکوردی한국어日本語SvenskaDanskNorskپښتوമലയാളംසිංහලTamazightHausaአማርኛБългарскиТоҷикӣҚазақшаFilipinoسنڌيYorùbáFulfuldeТатарчаئۇيغۇرچەКыргызчаਪੰਜਾਬੀJawaతెలుగుမြန်မာગુજરાતીOromoमराठीTiếng ViệtMalagasyНохчийнWolofދިވެހިಕನ್ನಡУкраїнськаΕλληνικάქართულიខ្មែរدریQafar afMaranaoनेपाली
Al-Kur'an
Sunday, August 30, 2026
Don't forget us in your sincere prayers







