Surah An-Nur
PDF —
Built right in your browser — download starts automatically
Surah An-Nur pdf — Gbà (Yorùbá)
Surah An-Nur pdf Yorùbá — Gbà Surah An-Nur Itumọ. An-Nur (Medinan) 64 Ẹsẹ.
Related
- An-Nur ItumọYorùbá
- An-Nur mp3Gbọ
- Quran Index Yorùbá114
More Surah PDF
Surah An-Nur

ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚ
(Eyi ni) Surah kan ti A sokale. A se e ni ofin. A si so awon ayah t’o yanju kale sinu re nitori ki e le lo iranti
ﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷ
Onisina lobinrin ati onisina lokunrin, e na enikookan ninu awon mejeeji ni ogorun-un koboko. E ma se je ki aanu won se yin nipa idajo Allahu ti e ba ni igbagbo ododo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin. Ki igun kan ninu awon onigbagbo ododo si jerii si iya awon mejeeji. ti o ba di oyun ti oko re ko si mo won ko nii fun won letoo si oorun ife miiran mo tori pe ko si itakoko yigi laaarin won. Bi o tile je pe a ri ninu awon onimo esin t’o ni won le se itakoko yigi obinrin naa fun arakunrin t’o se zina pelu re lori oyun zina naa nitori ki won le maa je igbadun ara won lo ni ona eto eyi ti o dara julo ni pe
ﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋ
Onisina lokunrin ko nii se sina pelu eni kan bi ko se onisina lobinrin (egbe re) tabi osebo lobinrin. Onisina lobinrin, eni kan ko nii ba a se sina bi ko se onisina lokunrin (egbe re) tabi osebo lokunrin. A si se iyen ni eewo fun awon onigbagbo ododo
ﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠ
Awon t’o n fi esun sina kan awon omoluabi lobinrin, leyin naa ti won ko mu awon elerii merin wa, e na won ni ogorin koboko. E ma se gba eri won mo laelae; awon wonyen si ni obileje
ﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬ
Ayafi awon t’o ronu piwada leyin iyen, ti won si se atunse. Dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun
ﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟ
Awon t’o n fi esun sina kan awon iyawo won, ti ko si si elerii fun won afi awon funra won, eri eni kookan won ni ki o fi Allahu jerii ni ee merin pe dajudaju oun wa ninu awon olododo
ﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩ
Ee karun-un si ni pe ki ibi dandan Allahu maa ba oun, ti oun ba wa ninu awon opuro
ﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵ
Ohun ti o maa ye iya fun iyawo ni pe ki o fi Allahu jerii ni ee merin pe dajudaju oko oun wa ninu awon opuro
ﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿ
Ee karun-un si ni pe ki ibinu Allahu maa ba oun, ti oko oun ba wa ninu awon olododo
ﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆﰇﰈﰉ
Ti ki i ba se oore ajulo Allahu ati ike Re lori yin ni (Allahu iba maa tu asiri yin ni). Dajudaju Allahu ni Olugba-ironupiwada, Ologbon
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱ
Dajudaju awon t’o mu adapa iro wa je ijo kan ninu yin. E ma se lero pe aburu ni fun yin. Rara o, oore ni fun yin. Eni kookan ninu won ti ni ohun ti o da ni ese. Ati pe eni ti o da (ese) julo ninu won, iya nla ni tire
ﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾ
Nigba ti e gbo o, ki ni ko je ki awon onigbagbo ododo lokunrin ati awon onigbagbo ododo lobinrin ro daadaa rora won, ki won si so pe: “Eyi ni adapa iro ponnbele.”
ﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎ
Ki ni ko je ki won mu elerii merin wa lori re? Nitori naa, nigba ti won ko ti mu awon elerii wa, awon wonyen, awon ni opuro lodo Allahu
ﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞ
Ti ki i ba se ti oore ajulo Allahu ati ike Re lori yin ni ile aye ati ni orun ni, dajudaju iya nla iba fowo ba yin nipa ohun ti e n so kiri ni isokuso
ﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯ
(E ranti) nigba ti e n gba a (laaarin ara yin) pelu ahon yin, ti e si n fi enu yin so ohun ti e o nimo nipa re; e lero pe nnkan t’o fuye ni, nnkan nla si ni lodo Allahu
ﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟ
Nigba ti e gbo o, ki ni ko je ki e so pe: “Ki i se eto fun wa pe ki a so eyi. Mimo ni fun O (Allahu)! Eyi ni iparo-moni t’o tobi.”
ﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩ
Allahu n se waasi fun yin pe ki e ma se pada sibi iru re mo laelae ti e ba je onigbagbo ododo
ﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲ
Allahu n salaye awon ayah naa. Allahu si ni Onimo, Ologbon
ﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆﰇﰈ
Dajudaju awon t’o nifee si ki (oro) ibaje maa tan kale nipa awon t’o gbagbo ni ododo, iya eleta-elero n be fun won ni aye ati ni orun. Allahu nimo, eyin ko si nimo
ﰉﰊﰋﰌﰍﰎﰏﰐﰑﰒ
Ti ki i ba se oore ajulo Allahu ati ike Re lori yin ni (Allahu iba tete fiya je yin ni). Dajudaju Allahu ni Alaaanu, Asake-orun
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se tele awon oju-ese Esu. Enikeni ti o ba si tele awon oju-ese Esu, dajudaju (Esu) yoo pase iwa ibaje ati aburu (fun un). Ti ki i ba se oore ajulo Allahu ati ike Re lori yin ni, eni kan iba ti mo ninu yin laelae. Sugbon Allahu n safomo eni ti O ba fe. Allahu si ni Olugbo, Onimo
ﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕ
Ki awon t’o ni ola ati igbalaaye ninu yin ma se bura pe awon ko nii se daadaa si awon ibatan, awon mekunnu ati awon t’o gbe ilu won ju sile nitori esin Allahu. Ki won saforijin, ki won si samojukuro. Se e o fe ki Allahu forijin yin ni? Allahu si ni Alaforijin, Asake-orun
ﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣ
Dajudaju awon t’o n paro sina mo awon omoluabi l’obinrin, awon ti sina ko si lori okan won, awon onigbagbo ododo lobinrin, A ti sebi le won ni aye ati ni orun. Iya nla si wa fun won
ﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭ
Ni ojo ti awon ahon won, owo won ati ese won yoo maa jerii tako won nipa ohun ti won n se nise
ﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚ
ni ojo yen ni Allahu yoo san won ni esan won ti o to si won. Won yo si mo pe dajudaju Allahu, Oun ni Ododo ponnbele
ﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮ
Awon obinrin buruku wa fun awon okunrin buruku. Awon okunrin buruku si wa fun awon obinrin buruku. Awon obinrin rere wa fun awon okunrin rere. Awon okunrin rere si wa fun awon obinrin rere. Awon (eni rere) wonyi mowo-mose ninu (aidaa) ti won n so si won. Aforijin ati ese alapon-onle n be fun won
ﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se wo awon ile kan yato si awon ile yin titi e maa fi toro iyonda ati (titi) e maa fi salamo si awon ara inu ile naa. Iyen loore julo fun yin nitori ki e le lo iranti
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪ
Ti e o ba si ba eni kan kan ninu ile naa, e ma se wo inu re titi won yoo fi yonda fun yin. Ti won ba si so fun yin pe ki e pada, nitori naa e pada. Ohun l’o fo yin mo julo. Allahu si ni Onimo nipa ohun ti e n se nise
ﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽ
Ko si ese fun yin lati wo inu awon ile kan ti ki i se ibugbe, ti anfaani wa ninu re fun yin . Allahu mo ohun ti e n safi han re ati ohun ti e n fi pamo
ﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏ
So fun awon onigbagbo ododo lokunrin pe ki won re oju won nile, ki won si so abe won. Iyen fo won mo julo. Dajudaju Allahu ni Alamotan nipa ohun ti won n se nise
ﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃ
So fun awon onigbagbo ododo lobinrin pe ki won re oju won nile, ki won si so abe won. Ki won ma safi han oso won afi eyi ti o ba han ninu re.1 Ki won fi ibori won bo igba-aya won.2 Ati pe ki won ma safi han oso won afi fun awon oko won tabi awon baba won tabi awon baba oko won tabi awon omokunrin won tabi awon omokunrin oko won tabi awon arakunrin won tabi awon omokunrin arakunrin won tabi awon omokunrin arabinrin won tabi awon obinrin (egbe) won tabi awon erukunrin won tabi awon t’o n tele obinrin fun ise riran, ti won je okunrin akura tabi awon omode ti ko ti i da ihoho awon obinrin mo (si nnkan kan). Ki won ma se fi ese won rin irin-kokoka nitori ki awon (eniyan) le mo ohun ti won fi pamo (sara) ninu oso won. Ki gbogbo yin si ronu piwada sodo Allahu, eyin onigbagbo ododo nitori ki e le jere
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤ
E fi iyawo fun awon apon ninu yin ati awon eni ire ninu awon erukunrin yin. (Ki e si wa oko rere fun) awon erubinrin yin. Ti won ba je alaini, Allahu yoo ro won loro ninu ola Re. Allahu si ni Olugbaaye, Onimo
ﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙ
Ki awon ti ko ri (owo lati fe) iyawo mu oju won kuro nibi isekuse titi Allahu yoo fi ro won loro ninu ola Re.1 Awon t’o n wa iwe ominira ninu awon eru yin, e ko iwe ominira fun won ti e ba mo ohun rere nipa won. Ki e si fun won ninu dukia Allahu ti O fun yin. (Nitori dukia aye ti e n wa), e ma se je awon erubinrin yin nipa lati lo se sina, ti won ba fe so abe won nibi isekuse.2 Enikeni ti o ba je won nipa, dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun leyin ti e ti je won nipa
ﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧ
Dajudaju A ti so awon ami t’o yanju, itan awon t’o ti lo siwaju yin ati waasi fun awon oluberu (Allahu) kale fun yin
ﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁ
Allahu ni Olutan-imole sinu awon sanmo ati ile. Apejuwe imole Re da bi opo atupa kan ti atupa wa ninu re. Atupa naa si wa ninu dingi. Dingi naa da bi irawo kan t’o n tan yanranyanran. Won n tan (imole naa) lati ara igi ibukun kan, igi zaetun. Ki i gba imole nigba ti oorun ba n yo jade tabi nigba ti oorun ba n wo. Epo (imole) re fee da mu imole wa, ina ibaa ma de ibe. Imole lori imole ni. Allahu n to enikeni ti O ba fe si (ona) imole Re. Allahu n fi awon akawe lele fun awon eniyan. Allahu si ni Onimo nipa gbogbo nnkan
ﰂﰃﰄﰅﰆﰇﰈﰉﰊﰋﰌﰍﰎﰏﰐ
(Awon atupa ibukun naa wa) ninu awon ile kan (iyen awon mosalasi) eyi ti Allahu yonda pe ki won gbega,1 ki won si maa daruko Re ninu re. (Awon eniyan) yo si maa safomo fun Un ninu re ni aaro ati asale
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤ
Awon okunrin ti owo ati kara-kata ko di lowo nibi iranti Allahu, irun kiki ati Zakah yiyo, awon t’o n paya ojo kan ti awon okan ati oju yoo maa yi si otun yi si osi
ﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴ
(Won se rere wonyi) nitori ki Allahu le fi eyi t’o dara ninu ohun ti won se nise san won ni esan rere ati nitori ki O le se alekun fun won ninu oore ajulo Re. Ati pe Allahu n pese arisiki fun eni ti O ba fe lai la isiro lo
ﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌ
Awon t’o sai gbagbo, awon ise won da bi ahunpeena t’o wa ni papa, ti eni ti ongbe n gbe si lero pe omi ni titi di igba ti o de sibe, ko si ba kini kan nibe. O si ba Allahu nibi (ise) re (ni orun). (Allahu) si se asepe isiro-ise re fun un. Allahu ni Oluyara nibi isiro-ise
ﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰ
Tabi (ise awon alaigbagbo) da bi awon okunkun kan ninu ibudo jijin, ti igbi omi n bo o mole, ti igbi omi miiran tun wa ni oke re, ti esujo si wa ni oke re; awon okunkun biribiri ti apa kan won wa lori apa kan (niyi). Nigba ti o ba nawo ara re jade, ko ni fee ri i. Enikeni ti Allahu ko ba fun ni imole, ko le si imole kan fun un
ﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩ
Se o o ri i pe dajudaju Allahu ni gbogbo eni t’o n be ninu awon sanmo ati lori ile n se afomo fun? Awon eye naa (n se bee) nigba ti won ba n na iye apa won? Ikookan won kuku ti mo bi o se maa kirun re ati bi o se maa se afomo re (fun Un). Allahu si ni Onimo nipa ohun ti won n se nise
ﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲ
Ti Allahu ni ijoba awon sanmo ati ile. Odo Allahu si ni abo eda
ﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆﰇﰈﰉﰊﰋﰌﰍﰎﰏﰐﰑﰒﰓﰔﰕﰖﰗﰘﰙﰚ
Se o o ri i pe dajudaju Allahu n da esujo kaakiri ni? Leyin naa O n ko o jo mora won. Leyin naa, O n gbe won gun ara won, nigba naa ni o maa ri ojo ti o maa jade lati aarin re. Lati inu sanmo, O si n so awon yiyin kan (t’o da bi) awon apata kale si ori ile aye. O n mu un kolu eni ti O ba fe. O si n seri re kuro fun eni ti O ba fe. Kiko yanranyanran monamona inu esujo si fee le fo awon oju
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜ
Allahu n mu oru ati osan tele ara won ni telentele. Dajudaju ariwoye wa ninu iyen fun awon t’o ni oju iriran
ﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿ
Allahu seda gbogbo abemi lati inu omi. O wa ninu won, eyi t’o n fi aya re wo. O wa ninu won, eyi t’o n fi ese meji rin. O si wa ninu won, eyi t’o n fi merin rin. Allahu n seda ohun ti O ba fe. Dajudaju Allahu ni Alagbara lori gbogbo nnkan
ﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌ
Dajudaju A ti so awon ayah t’o n yanju oro kale. Allahu si n to enikeni ti O ba fe si ona taara (’Islam)
ﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝ
Won n wi pe: “A gbagbo ninu Allahu ati Ojise Re. A si tele (ase Won).” Leyin naa, igun kan ninu won n peyin da leyin iyen. Awon wonyen ki i se onigbagbo ododo
ﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩ
Ati pe nigba ti won ba pe won si ti Allahu ati ti Ojise Re nitori ki o le sedajo laaarin won, nigba naa ni igun kan ninu won yoo maa gbunri
ﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱ
Ti o ba si je pe awon ni won ni eto (are) ni, won yoo wa ba o ni tokan-tara
ﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤ
Se arun wa ninu okan won ni tabi won seyemeji? Tabi won n paya pe Allahu ati Ojise Re yoo fi ejo won segbe ni? Rara o. Awon wonyen, awon ni alabosi
ﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸ
Ohun ti o maa je oro awon onigbagbo ododo nigba ti won ba pe won si ti Allahu ati ti Ojise Re nitori ki o le sedajo laaarin won, ni pe won a so pe: “A gbo (ase), a si tele (ase).” Awon wonyen, awon ni olujere
ﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃ
Enikeni ti o ba tele ti Allahu ati ti Ojise Re, ti o n paya Allahu, ti o si n beru Re, awon wonyen, awon ni olujere
ﰄﰅﰆﰇﰈﰉﰊﰋﰌﰍﰎﰏﰐﰑﰒﰓﰔﰕﰖﰗﰘﰙ
Won si fi Allahu bura ti ibura won si ni agbara pe: "Dajudaju ti o ba pase fun awon, dajudaju awon yoo jade." So pe: “E ma se bura mo. Titele ase (pelu ibura iro enu yin) ti di ohun mimo (fun wa).” Dajudaju Allahu ni Alamotan nipa ohun ti e n se nise
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫ
So pe: "E tele ti Allahu. Ki e si tele ti Ojise naa. Ti won ba peyin da, ohun ti A gbe ka a lorun l’o n be lorun re, ohun ti A si gbe ka yin lorun l’o n be lorun yin. Ti e ba si tele e, e maa mona taara. Ko si si ojuse kan fun Ojise bi ko se ise-jije ponnbele
ﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔ
Allahu sadehun fun awon t’o gbagbo ni ododo ninu yin, ti won si se awon ise rere pe dajudaju O maa fi won se arole lori ile gege bi O se fi awon t’o siwaju won se arole. Dajudaju O maa fi aye gba esin won fun won, eyi ti O yonu si fun won. Leyin iberu won, dajudaju O maa fi ifayabale dipo re fun won. Won n josin fun Mi, won ko si fi nnkan kan sebo si Mi. Enikeni ti o ba si sai moore leyin iyen, awon wonyen, awon ni obileje
ﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝ
E kirun. E yo Zakah. E tele Ojise naa nitori ki A le ke yin
ﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫ
Ma se lero pe awon t’o sai gbagbo mori bo ninu iya lori ile. Ina ni ibugbe won. Ikangun naa si buru
ﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, ki awon eru yin ati awon ti ko ti i balaga ninu yin maa gba iyonda lodo yin nigba meta (wonyi): siwaju irun Subh, nigba ti e ba n bo aso yin sile fun oorun osan ati leyin irun ale. (Igba) meta fun iborasile yin (niyi). Ko si ese fun eyin ati awon leyin (asiko) naa pe ki won wole to yin; ki apa kan yin wole to apa kan. Bayen ni Allahu se n se alaye awon ayah naa fun yin. Allahu si ni Onimo, Ologbon
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦ
Nigba ti awon omode yin ba si balaga, ki awon naa maa gba iyonda gege bi awon t’o siwaju won se gba iyonda. Bayen ni Allahu se n se alaye awon ayah Re fun yin. Allahu si ni Onimo, Ologbon
ﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀ
Awon t’o ti dagba koja omo bibi ninu awon obinrin, awon ti ko reti ibalopo oorun ife mo, ko si ese fun won lati bo awon aso jilbab won sile, ti won ko si nii se afihan oso kan sita. Ki won si maa wo aso jilbab won lo bee loore julo fun won. Allahu si ni Olugbo, Onimo
ﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱ
Ko si ese fun afoju, ko si ese fun aro, ko si ese fun alaisan, ko si si ese fun eyin naa lati jeun ninu ile yin, tabi ile awon baba yin, tabi ile awon iya yin, tabi ile awon arakunrin yin, tabi ile awon arabinrin yin, tabi ile awon arakunrin baba yin, tabi ile awon arabinrin baba yin, tabi ile awon arakunrin iya yin, tabi ile awon arabinrin iya yin, tabi (ile) ti e ni ikapa lori kokoro re, tabi (ile) ore yin. Ko si ese fun yin lati jeun papo tabi ni otooto. Nitori naa, ti e ba wo awon inu ile kan, e salamo sira yin. (Eyi je) ikini ibukun t’o dara lati odo Allahu. Bayen ni Allahu se n salaye awon ayah naa fun yin nitori ki e le se laakaye
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻ
Awon onigbagbo ni awon t’o gbagbo ninu Allahu ati Ojise Re. Nigba ti won ba si wa pelu re lori oro kan ti o kan gbogbogbo, won ko nii lo titi won yoo fi gba iyonda lodo re. Dajudaju awon t’o n gba iyonda lodo re, awon wonyen ni awon t’o gbagbo ninu Allahu ati Ojise Re. Nitori naa, ti won ba gba iyonda lodo re fun apa kan oro ara won, fun eni ti o ba fe ni iyonda ninu won, ki o si ba won toro aforijin lodo Allahu. Dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun
ﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙ
E ma se ladisokan pe ipe Ojise laaarin yin da bi ipe apa kan fun apa kan. Allahu kuku ti mo awon t’o n yo sa lo ninu yin. Nitori naa, ki awon t’o n yapa ase re sora nitori ki idaamu ma baa de ba won, tabi nitori ki iya eleta-elero ma baa je won
ﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓ
Gbo! Dajudaju ti Allahu ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ile. O si ti mo ohun ti e wa lori re. (Ranti) ojo ti won yo da won pada si odo Re, O si maa fun won ni iro ohun ti won se nise. Allahu si ni Onimo nipa gbogbo nnkan
Al-Kur'an
Tuesday, August 18, 2026
Don't forget us in your sincere prayers







