La sourate Ar-Rahman en Yoruba
الرَّحْمَٰنُ(1) Ajoke-aye |
O fi imo al-Ƙur’an mo (eni ti O fe) |
O seda eniyan |
O si fi alaye (oro siso) mo on |
Oorun ati osupa (n rin) fun isiro (ojo aye) |
Awon itakun ile ati igi n fori kanle (fun Allahu) |
Ati sanmo, Allahu gbe e soke. O si fi osuwon ofin deede lele (fun eda) |
pe ki e ma se tayo enu-ala nibi osuwon |
وَأَقِيمُوا الْوَزْنَ بِالْقِسْطِ وَلَا تُخْسِرُوا الْمِيزَانَ(9) E gbe osuwon naa duro pelu dogbadogba. Ki e si ma se din osuwon ku |
Ile, (Allahu) te e sile fun awon eda |
Eso ati dabinu alapo wa lori (ile) |
Ati eso koro onipoporo ati elewe dudu (wa lori ile) |
Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro |
(Allahu) seda eniyan lati ara amo gbigbe t’o n dun kokoko bi ikoko amo |
O si seda alujannu lati ara ahon ina ti ko ni eefin |
Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro |
Oluwa ibuyo oorun mejeeji ati ibuwo oorun mejeeji |
Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro |
(Allahu) mu odo meji (odo oniyo ati odo aladun) san pade ara won |
Gaga kan si wa laaarin awon mejeeji ti won ko si le tayo enu-ala (re laaarin ara won) |
Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro |
Okuta oniyebiye ati ileke iyun n jade ninu awon (odo) mejeeji naa |
Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro |
وَلَهُ الْجَوَارِ الْمُنشَآتُ فِي الْبَحْرِ كَالْأَعْلَامِ(24) Ti (Allahu) ni awon oko oju-omi gogoro t’o n rin ninu agbami odo (ti won da) bi apata giga |
Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro |
Gbogbo eni t’o wa lori ile maa tan |
Oju Oluwa re, Atobi, Alapon-onle si maa wa titi laelae |
Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro |
يَسْأَلُهُ مَن فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۚ كُلَّ يَوْمٍ هُوَ فِي شَأْنٍ(29) Awon t’o wa ninu awon sanmo ati ile n beere (nnkan) lodo Re; O si wa lori ise lojoojumo |
Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro |
A oo mu tiyin gbo (lojo esan), eyin eniyan ati alujannu |
Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro |
Eyin awujo alujannu ati eniyan, ti e ba lagbara lati sa jade ninu awon agbegbe sanmo ati ile, e sa jade. E o le sa jade afi pelu agbara |
Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro |
يُرْسَلُ عَلَيْكُمَا شُوَاظٌ مِّن نَّارٍ وَنُحَاسٌ فَلَا تَنتَصِرَانِ(35) Won maa ju eta-para ina ati eta-para ide le eyin mejeeji lori, eyin mejeeji ko si le ran’ra yin lowo |
Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro |
فَإِذَا انشَقَّتِ السَّمَاءُ فَكَانَتْ وَرْدَةً كَالدِّهَانِ(37) Nitori naa, nigba ti sanmo ba faya perepere, o si maa pon wa we bi epo pupa |
Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro |
فَيَوْمَئِذٍ لَّا يُسْأَلُ عَن ذَنبِهِ إِنسٌ وَلَا جَانٌّ(39) Nitori naa, ni ojo yen Won o nii bi eniyan ati alujannu kan leere nipa ese re; (o ti wa ni akosile ni odo Wa) |
Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro |
يُعْرَفُ الْمُجْرِمُونَ بِسِيمَاهُمْ فَيُؤْخَذُ بِالنَّوَاصِي وَالْأَقْدَامِ(41) Won maa mo awon elese pelu ami ara won. Won si maa fi aaso ori ati ese gba won mu |
Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro |
هَٰذِهِ جَهَنَّمُ الَّتِي يُكَذِّبُ بِهَا الْمُجْرِمُونَ(43) Eyi ni ina Jahanamo ti awon elese n pe niro |
Won yoo maa rin lo rin bo laaarin Ina ati omi t’o gbona pari |
Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro |
Ogba Idera meji n be fun eni t’o ba paya iduro re niwaju Oluwa re |
Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro |
(Awon Ogba Idera mejeeji ni) awon eka igi gigun |
Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro |
Odo meji t’o n san wa ninu ogba mejeeji |
Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro |
Orisi meji meji ni eso kookan t’o wa ninu ogba mejeeji |
Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro |
مُتَّكِئِينَ عَلَىٰ فُرُشٍ بَطَائِنُهَا مِنْ إِسْتَبْرَقٍ ۚ وَجَنَى الْجَنَّتَيْنِ دَانٍ(54) Won yoo rogboku lori ite, ti awon ite inu re je aran t’o nipon. Awon eso ogba mejeeji si wa ni arowoto |
Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro |
فِيهِنَّ قَاصِرَاتُ الطَّرْفِ لَمْ يَطْمِثْهُنَّ إِنسٌ قَبْلَهُمْ وَلَا جَانٌّ(56) Awon obinrin ti ki i wo okunrin miiran wa ninu Ogba Idera. Eniyan ati alujannu kan ko si fowo kan won ri siwaju won |
Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro |
Won da bii ileke segi ati ileke iyun |
Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro |
Nje esan miiran wa fun sise rere bi ko se (esan) rere |
Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro |
Ogba meji kan tun n be yato si meji (akoko yen) |
Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro |
مُدْهَامَّتَانِ(64) Alawo eweko (ni Ogba mejeeji naa) |
Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro |
Awon odo meji t’o n tu omi jade lai dawo duro wa (ninu ogba mejeeji naa) |
Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro |
Eso ipanu, dabinu ati eso rumon wa ninu ogba mejeeji |
Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro |
Awon obinrin rere, arewa wa ninu awon Ogba Idera |
Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro |
Awon eleyinju-ege kan (ni won), ti A fi pamo sinu ile-oso |
Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro |
Eniyan ati alujannu kan ko fowo kan won ri siwaju won |
Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro |
مُتَّكِئِينَ عَلَىٰ رَفْرَفٍ خُضْرٍ وَعَبْقَرِيٍّ حِسَانٍ(76) Won yoo rogboku lori awon timutimu alawo eweko ati ite t’o dara |
Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro |
Ibukun ni fun oruko Oluwa re, Atobi, Alapon-onle |
Plus de sourates en Yoruba :
Téléchargez la sourate avec la voix des récitants du Coran les plus célèbres :
Téléchargez le fichier mp3 de la sourate Ar-Rahman : choisissez le récitateur pour écouter et télécharger la sourate Ar-Rahman complète en haute qualité.

Donnez-nous une invitation valide