Surah An-Naml
PDF —
Built right in your browser — download starts automatically
Surah An-Naml pdf — Gbà (Yorùbá)
Surah An-Naml pdf Yorùbá — Gbà Surah An-Naml Itumọ. An-Naml (Meccan) 93 Ẹsẹ.
Related
- An-Naml ItumọYorùbá
- An-Naml mp3Gbọ
- Quran Index Yorùbá114
More Surah PDF
Surah An-Naml

ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘ
To sin. Iwonyi ni awon ayah al-Ƙur’an ati (awon ayah) Tira t’o n yanju oro eda
ﭙﭚﭛﭜ
(O je) imona ati iro idunnu fun awon onigbagbo ododo
ﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦ
awon t’o n kirun, ti won n yo zakah. Awon si ni won ni amodaju nipa Ojo Ikeyin
ﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱ
Dajudaju awon ti ko gba Ojo Ikeyin gbo, A ti se awon ise (aburu owo) won ni oso fun won, Nitori naa, won yo si maa pa ridarida
ﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼ
Awon wonyen ni awon ti iya buruku wa fun. Awon si ni eni ofo julo ni Ojo Ikeyin
ﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄ
Dajudaju o n gba al-Ƙur’an lati odo Ologbon, Onimo
ﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕ
(Ranti) nigba ti (Anabi) Musa so fun awon eniyan re pe: “Dajudaju mo ri ina kan. Mo si maa lo mu iro kan wa fun yin lati ibe, tabi ki ng mu ogunna kan t’o n tanna wa fun yin nitori ki e le yena
ﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤ
Nigba ti o de ibe, A pepe pe ki ibukun maa be fun eni ti o wa nibi ina naa ati eni ti o wa ni ayika re. Mimo si ni fun Allahu, Oluwa gbogbo eda
ﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫ
Musa, dajudaju Emi ni Allahu, Alagbara, Ologbon
ﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢ
Ju opa re sile. (O si se bee.) Amo nigba ti o ri i t’o n yira pada bi eni pe ejo ni, Musa peyin da, o n sa lo. Ko si pada. (Allahu so pe:) Musa, ma se paya. Dajudaju awon Ojise ki i paya lodo Mi
ﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮ
Ayafi eni ti o ba sabosi, leyin naa ti o yi i pada si rere leyin aburu. Dajudaju Emi ni Alaforijin, Asake-orun
ﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄ
Ti owo re bo (abiya lati ibi) orun ewu re. O si maa jade ni funfun, ti ki i se ti aburu. (Eyi wa) ninu awon ami mesan-an (ti o maa mu lo) ba Fir‘aon ati awon eniyan re. Dajudaju won je ijo obileje
ﰅﰆﰇﰈﰉﰊﰋﰌﰍ
Nigba ti awon ami Wa, t’o foju han kedere, si de ba won, won wi pe: “Eyi ni idan ponnbele.”
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝ
Won tako o pelu abosi ati igberaga, emi won si ni amodaju pe ododo ni. Nitori naa, woye si bi atubotan awon obileje ti ri
ﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮ
Dajudaju A fun (Anabi) Dawud ati (Anabi) Sulaemon ni imo. Awon mejeeji si so pe: "Ope ni fun Allahu, Eni ti O fun wa ni oore ajulo lori opolopo ninu awon erusin Re, awon onigbagbo ododo
ﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃ
(Anabi) Sulaemon si jogun (Anabi) Dawud. O so pe: "Eyin eniyan, Won fi ohun eye mo wa. Won si fun wa ni gbogbo nnkan. Dajudaju eyi, ohun ni oore ajulo ponnbele
ﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍ
A si ko jo fun (Anabi) Sulaemon, awon omo ogun re ninu alujannu, eniyan ati eye. A si n ko won jo papo mora won
ﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡ
titi won fi de afonifoji awon awurebe. Awurebe kan si wi pe: "Eyin awurebe, e wo inu ile yin lo, ki (Anabi) Sulaemon ati awon omo ogun re ma baa te yin re mole. Won ko si nii fura
ﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛ
Nigba naa, (Anabi Sulaemon) rerin-in muse, erin pa a nitori oro (awurebe naa). O so pe: “Oluwa mi, fi mo mi bi mo se maa dupe idera Re, eyi ti O fi se idera fun emi ati awon obi mi mejeeji. (Fi mo mi) bi mo se maa se ise rere, eyi ti O yonu si. Pelu aanu Re fi mi saaarin awon erusin Re, awon eni rere.”
ﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨ
O sabewo awon eye, o si so pe: “Nitori ki ni mi o se ri eye hudhuda? Abi o je okan ninu awon ti ko wa ni
ﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲ
Dajudaju mo maa je e niya lile, tabi ki ng dunbu re, tabi ki o mu eri t’o yanju wa fun mi.”
ﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁ
(Anabi Sulaemon) ko duro pe (titi o fi de), o si wi pe: "Mo mo nnkan ti o o mo. Mo si mu iro kan t’o daju wa ba o lati ilu Saba’i
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜ
Dajudaju emi ba obinrin kan (nibe), t’o n se ijoba le won lori. Won fun un ni gbogbo nnkan. O si ni ite nla kan
ﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮ
Mo si ba oun ati awon eniyan re ti won n fori kanle fun oorun leyin Allahu. Esu si se awon ise won ni oso fun won. O seri won kuro loju ona (ododo). Nitori naa, won ko si mona
ﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽ
lati fori kanle fun Allahu, Eni t’O n mu oro t’o pamo sinu awon sanmo ati ile jade, O si mo ohun ti e n fi pamo ati ohun ti e n safi han
ﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇ
Allahu, ko si olohun ti ijosin to si afi Oun, Oluwa Ite nla
ﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐ
O so pe: "A maa woye boya ododo l’o so ni tabi o wa ninu awon opuro
ﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜ
Mu iwe mi yii lo, ki o ju u si won. Leyin naa, ki o takete si won, ki o si wo ohun ti won yoo da pada (ni esi)
ﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥ
(Bilƙis) so pe: “Eyin ijoye, dajudaju won ti ju iwe alapon-onle kan si mi
ﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮ
Dajudaju o wa lati odo (Anabi) Sulaemon. Dajudaju o (so pe) “Ni oruko Allahu, Ajoke-aye, Asake-orun
ﮯﮰﮱﯓﯔﯕ
Ki e ma segberaga si mi, ki e si wa si odo mi (lati di) musulumi.”
ﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢ
(Bilƙis) so pe: “Eyin ijoye, e gba mi ni imoran nipa oro mi. Emi ki i gbe igbese lori oro kan titi e maa fi jerii si i.”
ﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯ
Won wi pe: “Alagbara ni awa. Akoni ogun si tun ni wa. Odo re ni oro wa. Nitori naa, woye si ohun ti o maa pa lase.”
ﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾ
(Bilƙis) wi pe: “Dajudaju awon oba, nigba ti won ba wo inu ilu kan, won yoo ba a je. Won yo si so awon eni abiyi ibe di eni yepere. Bayen ni won maa n se
ﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆﰇ
Dajudaju mo maa fi ebun kan ranse si won. Mo si maa woye si ohun ti awon iranse yoo mu pada (ni esi).”
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢ
Nigba ti (iranse) de odo (Anabi) Sulaemon, o so pe: “Se e maa fi owo ran mi lowo ni? Ohun ti Allahu fun mi loore julo si ohun ti e fun mi. Sibesibe, eyin tun n yo lori ebun yin
ﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰ
Pada si odo won. Dajudaju a n bo wa ba won pelu awon omo ogun ti won ko le koju re. Dajudaju a maa mu won jade kuro ninu (ilu won) ni eni abuku. Won yo si di eni yepere.”
ﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻ
(Anabi Sulaemon) so pe: “Eyin ijoye, ewo ninu yin l’o maa gbe ite (Bilƙis) wa ba mi, siwaju ki won to wa ba mi (lati di) musulumi.”
ﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍ
‘Ifrit ninu awon alujannu so pe: “Emi yoo gbe wa fun o siwaju ki o to dide kuro ni aye re. Dajudaju emi ni alagbara, olufokantan lori re.”
ﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘ
Eni ti imo kan lati inu tira wa ni odo re so pe: “Emi yoo gbe e wa fun o siwaju ki o to seju.” Nigba ti o ri i ti o de si odo re, o so pe: “Eyi wa ninu oore ajulo Oluwa mi, lati fi dan mi wo boya mo maa dupe tabi mo maa sai moore. Enikeni ti o ba dupe (fun Allahu), o dupe fun emi ara re. Enikeni ti o ba si saimoore, dajudaju Oluwa mi ni Oloro, Alapon-onle.”
ﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥ
O so pe: “E se iyipada irisi ite re fun un, ki a wo o boya o maa da a mo tabi o maa wa ninu awon ti ko nii da a mo.”
ﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶ
Nigba ti (Bilƙis) de, won so fun un pe: “Se bi ite re se ri niyi?” O wi pe: "O da bi eni pe ohun ni." (Anabi Sulaemon si so pe): “Won ti fun wa ni imo siwaju Bilƙis. A si je musulumi.”
ﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄ
Ohun t’o n josin fun leyin Allahu si seri re (kuro nibi ijosin fun Allahu). Dajudaju o wa ninu ijo alaigbagbo
ﰅﰆﰇﰈﰉﰊﰋﰌﰍﰎﰏﰐﰑﰒﰓﰔﰕﰖﰗﰘﰙﰚﰛﰜﰝﰞﰟﰠﰡﰢﰣﰤ
Won so fun un pe: “Wo inu aafin.” Nigba ti o ri i, o se bi ibudo ni. O si ka aso kuro ni ojugun re mejeeji. (Anabi Sulaemon) so pe: “Dajudaju aafin ti a se rigidin pelu dingi ni.” (Bilƙis) so pe: "Oluwa mi, dajudaju mo sabosi si emi ara mi. Mo si di musulumi pelu (Anabi) Sulaemon, fun Allahu, Oluwa gbogbo eda
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞ
Dajudaju A ti ranse si ijo Thamud. (A ran) arakunrin won, Solih (nise si won), pe: "E josin fun Allahu." Nigba naa ni won pin si ijo meji, t’o n bara won jiyan
ﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬ
O so pe: “Eyin ijo mi, nitori ki ni e se n wa (iya) aburu pelu ikanju siwaju (ohun) rere (t’o ye ki e mu se nise)? E o se toro aforijin lodo Allahu nitori ki Won le saanu yin?”
ﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼ
Won wi pe: “A ri ami aburu lati odo re ati awon t’o wa pelu re.” (Anabi Solih) so pe: “Ami aburu yin wa (ninu kadara yin) lodo Allahu. Ko si ri bi e se ro o amo ijo aladan-anwo ni yin ni.”
ﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇ
Awon eniyan mesan-an kan si wa ninu ilu, ti won n sebaje lori ile, ti won ko si se rere
ﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖ
Won wi (funra won) pe: “Ki a dijo fi Allahu bura pe dajudaju a maa pa oun ati awon eniyan re ni oru. Leyin naa, dajudaju a maa so fun ebi re pe iparun awon eniyan re ko soju wa. Dajudaju olododo si ni awa.”
ﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞ
Won dete gan-an, Awa naa si dete gan-an, won ko si fura
ﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨ
Wo bi atubotan ete won ti ri. Dajudaju A pa awon ati ijo won run patapata
ﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖ
Nitori naa, iwonyen ni ile won. O ti di ile ahoro nitori pe won sabosi. Dajudaju ami wa ninu iyen fun ijo t’o nimo
ﯗﯘﯙﯚﯛﯜ
A gba awon t’o gbagbo ni ododo la, ti won si n beru (Allahu)
ﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥ
(A tun fi ise imisi ran Anabi) Lut. (Ranti) nigba ti o so fun ijo re pe: "Se ise aburu ni e oo maa se ni, e si riran
ﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲ
Se dajudaju eyin (okunrin) yoo maa lo je adun (ibalopo) lara awon okunrin (egbe yin ni) dipo awon obinrin? Ani se, ope eniyan ni yin
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢ
Ko si ohun kan ti ijo re fo ni esi tayo pe won wi pe: “E le awon eniyan Lut jade kuro ninu ilu yin. Dajudaju won je eniyan t’o n fora won mo (nibi ese).”
ﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪ
Nitori naa, A gba oun ati ebi re la afi iyawo re; A ti ko o pe o maa wa ninu awon t’o maa seku leyin sinu iparun
ﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲ
A ro ojo le won lori taara. Ojo awon ti A kilo fun si buru
ﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀ
So pe: "Gbogbo ope n je ti Allahu. Ki alaafia maa ba awon erusin Re, awon ti O sa lesa. Se Allahu l’O loore julo ni tabi nnkan ti won n so di akegbe Re
ﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞ
(Se iborisa l’o loore julo ni) tabi (jijosin fun) Eni ti O da awon sanmo ati ile, ti O so omi kale fun yin lati sanmo, ti A si fi omi naa hu awon ogba oko ti o dara jade? Ko si si agbara fun yin lati mu igi re hu jade. Se olohun kan tun wa pelu Allahu ni? Rara, ijo t’o n sebo si Allahu ni won ni
ﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗ
(Se iborisa l’o dara julo ni) tabi (jijosin fun) Eni ti O se ile ni ibugbe, ti O fi awon odo saaarin re, ti O fi awon apata t’o duro sinsin sinu ile, ti O si fi gaga saaarin ibudo mejeeji? Se olohun kan tun wa pelu Allahu ni? Sibesibe opolopo won ni ko mo
ﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪ
(Se iborisa l’o dara julo ni) tabi (jijosin fun) Eni ti O n jepe eni ti ara n ni nigba ti o ba pe E, ti O si maa gbe aburu kuro fun un, ti O si n se yin ni arole lori ile? Se olohun kan tun wa pelu Allahu ni? Die ni ohun ti e n lo ninu iranti
ﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁ
(Se iborisa l’o dara julo ni) tabi (jijosin fun) Eni ti O n to yin sona ninu awon okunkun ori ile ati inu ibudo, ti O tun n fi ategun ranse ni iro idunnu siwaju ike Re? Se olohun kan tun wa pelu Allahu ni? Allahu ga tayo nnkan ti won n fi sebo si I
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦ
(Se iborisa l’o dara julo ni) tabi (jijosin fun) Eni ti O pile iseda eda, leyin naa, ti O maa da a pada (leyin iku), ti O si n pese fun yin lati sanmo ati ile? Se olohun kan tun wa pelu Allahu ni? So pe: "E mu eri yin wa ti e ba je olododo
ﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶ
So pe: “Awon t’o wa ninu awon sanmo ati ile ko nimo ikoko afi Allahu. Ati pe won ko si mo asiko wo ni A maa gbe awon oku dide.”
ﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇ
Bee ni, ni orun ni imo won maa to mo Ojo Ikeyin (loran). Bee ni, won wa ninu iyemeji nipa re (bayii). Bee ni, won ti fonu-fora nipa re
ﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑ
Awon t’o sai gbagbo wi pe: “Se nigba ti awa ati awon baba wa ba ti di erupe, se (nigba naa ni) won yoo mu wa jade
ﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞ
Won kuku ti se adehun eyi fun awa ati awon baba wa teletele. Eyi ko je kini kan bi ko se akosile alo awon eni akoko.”
ﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨ
So pe: “E rin kiri lori ile, ki e wo bi atubotan awon elese se ri.”
ﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓ
Ma se banuje nitori won. Ma si je ki ohun ti won n da ni ete ko inira ba o
ﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛ
Won n wi pe: “Igba wo ni adehun yii yoo se ti e ba je olododo.”
ﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥ
So pe: “O le je pe apa kan ohun ti e n wa pelu ikanju ti sunmo yin tan.”
ﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰ
Dajudaju Oluwa re ma ni Olola lori awon eniyan, sugbon opolopo won ki i dupe (fun Un)
ﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹ
Dajudaju Oluwa re, O kuku mo ohun ti igba-aya won n gbe pamo ati ohun ti won n safi han re
ﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄ
Ati pe ko si ohun ikoko kan ninu sanmo ati ile afi ki o wa ninu akosile t’o han kedere
ﰅﰆﰇﰈﰉﰊﰋﰌﰍﰎﰏﰐﰑ
Dajudaju al-Ƙur’an yii yoo maa salaye oro fun awon omo ’Isro’il nipa opolopo ohun ti won n yapa enu si
ﭑﭒﭓﭔﭕ
Ati pe dajudaju imona ati ike ni fun awon onigbagbo ododo
ﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟ
Dajudaju Oluwa re maa se idajo laaarin won pelu idajo Re. Oun ni Alagbara, Onimo
ﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨ
Nitori naa, gbarale Allahu. Dajudaju iwo wa lori ododo ponnbele
ﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴ
Dajudaju iwo ko l’o maa mu awon oku gboro. O o si nii mu awon aditi gbo ipe nigba ti won ba keyin si o, ti won n lo
ﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄ
Iwo ko l’o maa fi ona mo awon afoju nibi isina won. Ko si eni ti o maa mu gbo oro afi eni ti o ba gba awon ayah Wa gbo nitori pe awon ni (musulumi) olujupa-juse-sile fun Allahu
ﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖ
Nigba ti oro naa ba ko le won lori, A maa mu eranko kan jade fun won lati inu ile, ti o maa ba won soro pe: “Dajudaju awon eniyan ki i nimo amodaju nipa awon ayah Wa.”
ﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢ
Ati pe (ranti) ojo ti A oo ko ijo kan jo ninu ijo kookan ninu awon t’o n pe awon ayah Wa niro. A o si ko won jo papo mora won
ﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰ
Titi (di) igba ti won ba de (tan), (Allahu) yoo so pe: "Se e pe awon ayah Mi niro, ti eyin ko si ni imo kan nipa re (ti e le fi ja a niro)? Tabi ki ni e n se nise (nile aye)
ﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚ
Oro naa si ko le won lori nitori pe won sabosi. Won ko si nii soro
ﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫ
Se won ko ri i pe dajudaju Awa l’A da oru nitori ki won le sinmi ninu re, (A si da) osan (nitori ki won le) riran? Dajudaju ami wa ninu iyen fun ijo onigbagbo ododo
ﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿ
(Ranti) ojo ti won a fon fere oniwo, gbogbo eni ti o wa ninu sanmo ati ile yo si jaya afi eni ti Allahu ba fe. Gbogbo eda l’o si maa yepere wa ba Allahu
ﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆﰇﰈﰉﰊﰋﰌﰍﰎﰏﰐﰑﰒﰓﰔ
O si maa ri awon apata, ti o lero pe nnkan gbagidi t’o duro soju kan naa ni, ti o maa rin irin esujo. (Iyen je) ise Allahu, Eni ti O se gbogbo nnkan ni daadaa. Dajudaju O mo ikoko ohun ti e n se nise
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜ
Enikeni ti o ba mu ise rere wa, tire ni rere t’o loore julo si eyi t’o mu wa. Awon si ni olufayabale ninu ijaya ojo yen
ﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪ
Enikeni ti o ba si mu (ise) aburu wa, A si maa da oju won bole ninu Ina. Nje A oo san yin ni esan kan bi ko se ohun ti e n se nise
ﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽ
Ohun ti won pa mi ni ase re ni pe ki ng josin fun Oluwa Ilu yii, Eni ti O se e ni aye owo. TiRe si ni gbogbo nnkan. Won si pa mi ni ase pe ki ng wa ninu awon musulumi
ﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏ
Ati pe ki ng maa ke al-Ƙur’an. Nitori naa, enikeni ti o ba mona, o mona fun emi ara re. Enikeni ti o ba si sina, so pe: “Dajudaju emi wa ninu awon olukilo.”
ﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜ
So pe: “Gbogbo ope n je ti Allahu.” (Allahu) yoo fi awon ami Re han yin. Eyin yo si mo won. Oluwa re ko si gbagbe ohun ti e n se nise
Al-Kur'an
Tuesday, August 18, 2026
Don't forget us in your sincere prayers







