PDF —
227 Ẹsẹ Meccan PDF
Built right in your browser — download starts automatically

Surah Ash-Shu'ara pdf — Gbà (Yorùbá)

Surah Ash-Shu'ara pdf Yorùbá — Gbà Surah Ash-Shu'ara Itumọ. Surah Ash-Shu'ara (Meccan) 227 Ẹsẹ.

← Al-FurqanSurah Ash-Shu'ara An-Naml →


227 Ẹsẹ · Meccan · Yorùbá
bismillah
ﭑﭒ
26:1 To sin mim
ﭓﭔﭕﭖﭗ
26:2 Iwonyi ni awon ayah Tira t’o n yanju oro eda
ﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞ
26:3 Nitori ki ni o se maa para re pe won ko je onigbagbo ododo
ﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪ
26:4 Ti A ba fe, A maa so ami kan kale fun won lati sanmo. Awon orun won ko si nii ye teriba fun un
ﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶ
26:5 Ko si iranti kan ti o maa de ba won ni titun lati odo Ajoke-aye afi ki won je olugbunri kuro nibe
ﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿ
26:6 Dajudaju won ti pe (ayah Wa) niro. Nitori naa, awon iro ohun ti won n fi se yeye n bo wa ba won
ﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋ
26:7 Se won ko ri ile pe meloo meloo ninu gbogbo orisirisi nnkan alapon-onle ti A mu hu jade lati inu re
ﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕ
26:8 Dajudaju ami wa ninu iyen. Sibesibe opolopo won ko je onigbagbo ododo
ﮖﮗﮘﮙﮚﮛ
26:9 Dajudaju Oluwa re, Oun ma ni Alagbara, Asake-orun
ﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤ
26:10 (Ranti) nigba ti Oluwa re pe (Anabi) Musa pe: "Lo ba ijo alabosi
ﮥﮦﮧﮨﮩﮪ
26:11 ijo Fir‘aon (ki o si so fun won) pe Se won ko nii beru (Allahu) ni
ﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱ
26:12 O so pe: "Oluwa mi, dajudaju emi n beru pe won maa pe mi ni opuro
ﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛ
26:13 O si maa je inira fun mi (ti won ba pe mi ni opuro). Ahon mi ko si ja gaaraga. Nitori naa, ranse si Harun
ﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢ
26:14 Ati pe mo ni ese kan lorun lodo won. Nitori naa, mo n beru pe won maa pa mi
ﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬ
26:15 (Allahu) so pe: "Rara (won ko le pa o). Nitori naa, ki eyin mejeeji mu awon ami (ise iyanu) Wa lo (ba won). Dajudaju Awa n be pelu yin; A n gbo (oro yin)
ﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴ
26:16 Eyin mejeeji, e lo ba Fir‘aon. Ki e so fun un pe: Dajudaju awa ni Ojise Oluwa gbogbo eda
ﯵﯶﯷﯸﯹﯺ
26:17 (A n so fun o) pe ki o je ki awon omo ’Isro’il maa ba wa lo
ﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅ
26:18 (Fir‘aon) wi pe: “Se ki i se ni aarin wa ni a ti to o ni kekere ni, ti o si gbe ni odo wa fun odun pupo ninu isemi aye re
ﰆﰇﰈﰉﰊﰋﰌﰍ
26:19 O si se ise owo re ti o se (si wa). Iwo si wa ninu awon alaimoore.”
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗ
26:20 (Anabi Musa) so pe: "Mo se e nigba naa nigba ti mo wa ninu awon alaimokan ni
ﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣ
26:21 Mo si sa fun yin nigba ti mo beru yin. Nitori naa, Allahu ti ta mi lore ipo Anabi. O si se mi ni (okan) ninu awon Ojise
ﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬ
26:22 Ati pe iyen ni idera ti o n se iregun re le mi lori. Pe o so awon omo ’Isro’il di eru (nko)
ﭭﭮﭯﭰﭱﭲ
26:23 Fir‘aon wi pe: “Ki ni Oluwa gbogbo eda?”
ﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽ
26:24 (Anabi Musa) so pe: “(Allahu ni)
ﭾﭿﮀﮁﮂﮃ
26:25 (Fir‘aon) wi fun awon t’o wa ni ayika re pe: “Se e e gbo oro (t’o n so ni)?”
ﮄﮅﮆﮇﮈﮉ
26:26 (Anabi Musa) so pe: “(Allahu ni) Oluwa yin ati Oluwa awon baba yin, awon eni akoko.”
ﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑ
26:27 (Fir‘aon) wi pe: “Dajudaju Ojise yin eyi ti won ran si yin, were ma ni.”
ﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜ
26:28 (Anabi Musa) so pe: “(Allahu ni) Oluwa ibuyo oorun, ibuwo oorun ati ohunkohun t’o n be laaarin awon mejeeji, ti e ba maa n se laakaye.”
ﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥ
26:29 (Fir‘aon) wi pe: “Dajudaju ti o ba fi le josin fun olohun kan yato si mi, dajudaju mo maa so o di ara awon elewon.”
ﮦﮧﮨﮩﮪﮫ
26:30 (Anabi Musa) so pe: “Ti o ba je pe mo mu kini kan t’o yanju wa fun o nko?”
ﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔ
26:31 (Fir‘aon) wi pe: “Mu un wa nigba naa ti iwo ba wa ninu awon olododo.”
ﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛ
26:32 Nitori naa, o ju opa re sile, o si di ejo ponnbele
ﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢ
26:33 O tun fa owo re yo sita, o si di funfun fun awon oluworan
ﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪ
26:34 (Fir‘aon) wi fun awon ijoye ti won wa ni ayika re pe: “Dajudaju eyi ni onimo nipa idan pipa
ﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳ
26:35 O fe ko yin kuro lori ile yin ni. Ki ni ohun ti e maa mu wa ni imoran?”
ﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻ
26:36 Won wi pe: "Da oun ati arakunrin re duro na, ki o si ran awon akonijo si awon ilu
ﯼﯽﯾﯿﰀ
26:37 (pe) ki gbogbo onimo nipa idan pipa wa ba o
ﰁﰂﰃﰄﰅﰆ
26:38 Won si ko awon opidan jo ni asiko ti won fi adehun si ni ojo ti (gbogbo ilu) ti mo
ﰇﰈﰉﰊﰋﰌ
26:39 Won si wi fun awon eniyan pe: "Se eyin maa ko jo (sibe) bi
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘ
26:40 Nitori ki a le tele awon opidan ti o ba je pe awon ni olubori
ﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥ
26:41 Nigba ti awon opidan de, won wi fun Fir‘aon pe: “Nje owo-oya kan wa fun wa, ti o ba je pe awa gan-an la je olubori?”
ﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬ
26:42 (Fir‘aon) wi pe: “Bee ni, dajudaju nigba naa e maa wa ninu awon alasun-unmo (mi).”
ﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴ
26:43 (Anabi) Musa so fun won pe: “E ju ohun ti e fe ju sile.”
ﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾ
26:44 Won si ju awon okun won ati opa won sile. Won wi pe: “Pelu ogo Fir‘aon, dajudaju awa, awa ni olubori.”
ﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇ
26:45 Nigba naa, (Anabi) Musa ju opa re sile. O si n gbe ohun ti won pa niro kale mi kalokalo
ﮈﮉﮊﮋ
26:46 Nitori naa, ise iyanu (Anabi Musa) mu awon opidan wo lule, ti won fori kanle (fun Allahu)
ﮌﮍﮎﮏﮐ
26:47 Won so pe: "A gbagbo ninu Oluwa gbogbo eda
ﮑﮒﮓﮔ
26:48 Oluwa (Anabi) Musa ati Harun
ﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬ
26:49 Fir‘aon wi pe: “E gba A gbo siwaju ki ng to yonda fun yin! Dajudaju oun ni agba yin ti o ko yin ni idan pipa. Laipe e n bo wa mo. Dajudaju mo maa ge owo yin ati ese yin ni ipasipayo. Leyin naa, dajudaju mo maa kan gbogbo yin mogi.”
ﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖ
26:50 (Awon opidan) so pe: “Ko si inira fun wa! Dajudaju awa yo si fabo si odo Oluwa wa
ﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢ
26:51 Dajudaju awa n reti pe Oluwa wa yoo se aforijin awon asise wa fun wa nitori pe awa je eni akoko (ti o je) onigbagbo ododo.”
ﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬ
26:52 A fi imisi ranse si (Anabi) Musa pe: “Mu awon erusin Mi rin ni oru (nitori pe) dajudaju won yoo lepa yin.”
ﯭﯮﯯﯰﯱﯲ
26:53 Fir‘aon si ran awon akonijo sinu awon ilu (lati so pe)
ﯳﯴﯵﯶﯷ
26:54 Dajudaju awon (omo ’Isro’il) wonyi, ijo perete die ni won
ﯸﯹﯺﯻ
26:55 Ati pe dajudaju won ti se ohun t’o n bi wa ninu
ﯼﯽﯾﯿ
26:56 Dajudaju gbogbo wa ni ki a si wa tifura-tifura
ﰀﰁﰂﰃﰄ
26:57 Nitori naa, A mu (ijo Fir‘aon) jade kuro ninu awon ogba oko ati iseleru omi
ﰅﰆﰇﰈ
26:58 ati awon apoti-oro ati ibujokoo aponle
ﰉﰊﰋﰌﰍﰎ
26:59 Bayen (loro ri). A si jogun re fun awon omo ’Isro’il
ﰏﰐﰑ
26:60 Won si lepa won ni asiko ti oorun yo
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙ
26:61 Nigba ti ijo mejeeji rira won, awon ijo (Anabi) Musa so pe: “Dajudaju won yoo le wa ba.”
ﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡ
26:62 (Anabi) Musa so pe: “Rara, dajudaju Oluwa mi n be pelu mi. O si maa fi ona mo mi.”
ﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰ
26:63 A si fi imisi ranse si (Anabi) Musa pe: “Fi opa re na agbami okun.” (O fi na a). O si pin (si ona mejila). Ipin kookan si da bi apata nla
ﭱﭲﭳﭴ
26:64 A si mu ijo keji (iyen, ijo Fir‘aon) sunmo ibe yen
ﭵﭶﭷﭸﭹﭺ
26:65 A gba (Anabi) Musa ati gbogbo awon t’o n be pelu re la patapata
ﭻﭼﭽﭾ
26:66 Leyin naa, A te ijo keji ri (sinu agbami)
ﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈ
26:67 Dajudaju ami wa ninu iyen. Sibesibe opolopo won ko je onigbagbo ododo
ﮉﮊﮋﮌﮍﮎ
26:68 Dajudaju Oluwa re, Oun ma ni Alagbara, Asake-orun
ﮏﮐﮑﮒﮓ
26:69 Ka iroyin (Anabi) ’Ibrohim fun won
ﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚ
26:70 Nigba ti o so fun baba re ati awon eniyan re pe: “Ki ni nnkan ti e n josin fun na?”
ﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡ
26:71 Won wi pe: “A n josin fun awon ere kan ni. A o si nii ye taku ti won lorun.”
ﮢﮣﮤﮥﮦﮧ
26:72 (Anabi ’Ibrohim) so pe: “Nje won n gbo oro yin nigba ti e ba n pe won
ﮨﮩﮪﮫﮬ
26:73 Tabi (se) won le se yin ni oore tabi won le fi inira kan yin?”
ﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔ
26:74 Won wi pe: “Rara o! A ba awon baba wa, ti won n se bee ni”
ﯕﯖﯗﯘﯙﯚ
26:75 (Anabi ’Ibrohim) so pe: " E so fun mi, ki ni nnkan ti e n josin fun
ﯛﯜﯝﯞ
26:76 eyin ati awon baba yin isaaju
ﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥ
26:77 Dajudaju awon ni ota fun mi ayafi Oluwa gbogbo eda
ﯦﯧﯨﯩﯪ
26:78 (Oun ni) Eni ti O seda mi. Nitori naa, O maa fi ona mo mi
ﯫﯬﯭﯮﯯ
26:79 Eni t’O n fun mi ni jije, t’O n fun mi ni mimu
ﯰﯱﯲﯳﯴ
26:80 Ati pe nigba ti ara mi ko ba ya, Oun l’O n wo mi san
ﯵﯶﯷﯸﯹ
26:81 Eni ti O maa pa mi, leyin naa, O maa so mi di alaaye
ﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂ
26:82 Eni ti mo ni ireti si pe O maa fori awon asise mi jin mi ni Ojo Esan
ﰃﰄﰅﰆﰇﰈﰉ
26:83 Oluwa mi, ta mi ni ore ipo Anabi. Da mi po mo awon eni rere
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗ
26:84 Je ki awon t’o n bo leyin (mi) maa soro mi pelu daadaa
ﭘﭙﭚﭛﭜﭝ
26:85 Se mi ni okan ninu awon olujogun Ogba Idera
ﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤ
26:86 Ki O si forijin baba mi. Dajudaju o je okan ninu awon olusina
ﭥﭦﭧﭨﭩ
26:87 Ma se doju ti mi ni ojo ti won yoo gbe eda dide
ﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰ
26:88 Ojo ti dukia kan tabi awon omo ko nii sanfaani
ﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷ
26:89 Ayafi eni ti o ba de odo Allahu pelu okan mimo
ﭸﭹﭺﭻ
26:90 A maa mu Ogba Idera sunmo awon oluberu (Allahu)
ﭼﭽﭾﭿ
26:91 Won si maa fi ina Jehim han awon olusina
ﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆ
26:92 won yo si so fun won pe: “Nibo ni nnkan ti e n josin fun wa?”
ﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎ
26:93 (Nnkan ti e n josin fun) leyin Allahu, se won le ran yin lowo tabi se won le ran ara won lowo
ﮏﮐﮑﮒﮓ
26:94 Won si maa taari gbogbo won sinu Ina; awon ati esu won
ﮔﮕﮖﮗ
26:95 ati awon omo ogun ’Iblis patapata
ﮘﮙﮚﮛﮜ
26:96 (Awon alaigbagbo), nigba ti won ba n ba ara won jiyan ninu Ina, won a wi pe
ﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣ
26:97 A fi Allahu bura, dajudaju awa kuku ti wa ninu isina ponnbele
ﮤﮥﮦﮧﮨ
26:98 nigba ti a fi yin se akegbe fun Oluwa gbogbo eda
ﮩﮪﮫﮬﮭ
26:99 Ko si ohun ti o si wa lona bi ko se awon (esu) elese
ﮮﮯﮰﮱﯓ
26:100 Ko si si awon olusipe kan fun wa
ﯔﯕﯖﯗ
26:101 Ko tun si ore imule kan (fun wa)
ﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟ
26:102 Ti o ba je pe ipada si ile aye wa fun wa ni, nigba naa awa iba wa ninu awon onigbagbo ododo
ﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩ
26:103 Dajudaju ami wa ninu iyen. Sibesibe opolopo won ni ko si je onigbagbo ododo
ﯪﯫﯬﯭﯮﯯ
26:104 Dajudaju Oluwa re, Oun ma ni Alagbara, Asake-orun
ﯰﯱﯲﯳﯴ
26:105 Ijo (Anabi) Nuh pe awon Ojise ni opuro
ﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼ
26:106 Nigba ti arakunrin won, (Anabi) Nuh, so pe: “Se e o nii beru (Allahu) ni
ﯽﯾﯿﰀﰁ
26:107 Dajudaju emi ni Ojise olufokantan fun yin
ﰂﰃﰄﰅ
26:108 Nitori naa, e beru Allahu, ki e si tele mi
ﰆﰇﰈﰉﰊﰋﰌﰍﰎﰏﰐﰑﰒ
26:109 Emi ko si beere owo-oya kan ni owo yin lori re. Ko si esan mi lodo eni kan afi lodo Oluwa gbogbo eda
ﰓﰔﰕﰖ
26:110 Nitori naa, e beru Allahu, ki e si tele mi.”
ﰗﰘﰙﰚﰛﰜﰝ
26:111 Won wi pe: “Se ki a gba o gbo nigba ti o je pe awon eniyan yepere l’o n tele o!?”
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗ
26:112 O so pe: “Emi ko nimo si ohun ti won n se (leyin mi)
ﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠ
26:113 Ko si isiro-ise won lodo eni kan bi ko se lodo Oluwa mi, ti o ba je pe e ba fura
ﭡﭢﭣﭤﭥ
26:114 Emi ko si nii le awon onigbagbo ododo danu
ﭦﭧﭨﭩﭪﭫ
26:115 Emi ko si je kini kan bi ko se olukilo ponnbele.”
ﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴ
26:116 Won wi pe: “Dajudaju ti iwo Nuh ko ba jawo (nibi ipepe re) dajudaju o maa wa ninu awon ti a maa ju loko.”
ﭵﭶﭷﭸﭹﭺ
26:117 O so pe: “Oluwa mi, dajudaju awon eniyan mi ti pe mi ni opuro
ﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄ
26:118 Nitori naa, sedajo taara laaarin emi ati awon. Ki o si la emi ati awon t’o wa pelu mi ninu awon onigbagbo ododo.”
ﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋ
26:119 A la oun ati awon t’o wa pelu re ninu oko oju-omi t’o kun keke
ﮌﮍﮎﮏﮐ
26:120 Leyin naa, A te awon t’o seku ri sinu omi
ﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚ
26:121 Dajudaju ami wa ninu iyen. Opolopo won ni ko si je onigbagbo ododo
ﮛﮜﮝﮞﮟﮠ
26:122 Dajudaju Oluwa re, Oun ma ni Alagbara, Asake-orun
ﮡﮢﮣﮤ
26:123 Awon iran ‘Ad pe awon Ojise ni opuro
ﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬ
26:124 Nigba ti arakunrin won, (Anabi) Hud, so pe: “Se e o nii beru (Allahu) ni
ﮭﮮﮯﮰﮱ
26:125 Dajudaju emi ni Ojise olufokantan fun yin
ﯓﯔﯕﯖ
26:126 Nitori naa, e beru Allahu, ki e si tele mi
ﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣ
26:127 Emi ko si beere owo-oya kan ni owo yin lori re. Ko si esan mi lodo eni kan afi lodo Oluwa gbogbo eda
ﯤﯥﯦﯧﯨﯩ
26:128 Se e oo maa ko ile nla nla si awon aye giga (ki e le) maa fi awon olurekoja sefe
ﯪﯫﯬﯭﯮ
26:129 E si n ko awon ile nla nla bi eni pe e maa se gbere (nile aye yii)
ﯯﯰﯱﯲﯳ
26:130 Nigba ti e ba si gba (eniyan mu lati fiya je won), e n gba won mu ni igbamu alailoju-aanu
ﯴﯵﯶﯷ
26:131 Nitori naa, e beru Allahu, ki e si tele mi
ﯸﯹﯺﯻﯼﯽ
26:132 E beru Eni ti O ran yin lowo pelu ohun ti e mo
ﯾﯿﰀﰁ
26:133 O ran yin lowo pelu awon eran-osin ati awon omo
ﰂﰃﰄ
26:134 ati awon ogba oko pelu awon iseleru omi
ﰅﰆﰇﰈﰉﰊﰋ
26:135 Dajudaju emi n paya iya ojo nla fun yin.”
ﰌﰍﰎﰏﰐﰑﰒﰓﰔﰕ
26:136 Won wi pe: “Bakan naa ni fun wa; yala o kilo fun wa tabi o o si ninu awon olukilo
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖ
26:137 Eyi ko je kini kan bi ko se iwa awon eni akoko
ﭗﭘﭙﭚ
26:138 Won ko si nii je wa niya.”
ﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧ
26:139 Nitori naa, won pe e ni opuro. A si pa won run. Dajudaju ami wa ninu iyen. Opolopo won ni ko si je onigbagbo ododo
ﭨﭩﭪﭫﭬﭭ
26:140 Dajudaju Oluwa re, Oun ma ni Alagbara, Asake-orun
ﭮﭯﭰﭱ
26:141 Awon iran Thamud pe awon Ojise ni opuro
ﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹ
26:142 Nigba ti arakunrin won, (Anabi) Solih, so pe: “Se e o nii beru (Allahu) ni
ﭺﭻﭼﭽﭾ
26:143 Dajudaju emi ni Ojise olufokantan fun yin
ﭿﮀﮁﮂ
26:144 Nitori naa, e beru Allahu, ki e si tele mi
ﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏ
26:145 Emi ko si beere owo-oya kan ni owo yin lori re. Ko si esan mi lodo eni kan afi lodo Oluwa gbogbo eda
ﮐﮑﮒﮓﮔﮕ
26:146 Se ki won fi yin sile sibi nnkan ti o wa (nile aye) nibi yii (ninu igbadun aye, ki e je) olufokanbale
ﮖﮗﮘﮙ
26:147 ninu awon ogba oko ati iseleru omi
ﮚﮛﮜﮝﮞ
26:148 ati oko irugbin pelu igi dabinu ti ogomo re tutu
ﮟﮠﮡﮢﮣﮤ
26:149 E si n gbe awon ile sinu awon apata (gege bi) akose-mose
ﮥﮦﮧﮨ
26:150 Nitori naa, e beru Allahu, ki e si tele mi
ﮩﮪﮫﮬﮭ
26:151 Ki e si ma se tele ase awon alaseju
ﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕ
26:152 awon t’o n sebaje lori ile, ti won ko si se rere.”
ﯖﯗﯘﯙﯚﯛ
26:153 Won wi pe: “Iwo kuku wa ninu awon eleedi
ﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧ
26:154 Iwo ko si je kini kan bi ko se abara bi iru wa. Nitori naa, mu ami kan wa ti o ba wa ninu awon olododo.”
ﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱ
26:155 O so pe: “Eyi ni abo rakunmi kan. Omi wa fun ohun, omi si wa fun eyin naa ni ojo ti a ti mo
ﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹ
26:156 E ma se fi aburu kan kan an nitori ki iya ojo nla ma baa je yin.”
ﯺﯻﯼﯽ
26:157 Won si gun un pa. Nitori naa, won si di alabaamo
ﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆﰇﰈﰉﰊ
26:158 Iya naa je won. Dajudaju ami wa ninu iyen. Opolopo won ni ko si je onigbagbo ododo
ﰋﰌﰍﰎﰏﰐ
26:159 Dajudaju Oluwa re, Oun ma ni Alagbara, Asake-orun
ﭑﭒﭓﭔﭕ
26:160 Ijo Lut pe awon Ojise ni opuro
ﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝ
26:161 Nigba ti arakunrin won, (Anabi) Lut, so pe: “Se e o nii beru (Allahu) ni
ﭞﭟﭠﭡﭢ
26:162 Dajudaju emi ni Ojise olufokantan fun yin
ﭣﭤﭥﭦ
26:163 Nitori naa, e beru Allahu, ki e si tele mi
ﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳ
26:164 Emi ko si beere owo-oya kan ni owo yin lori re. Ko si esan mi lodo eni kan afi lodo Oluwa gbogbo eda
ﭴﭵﭶﭷﭸ
26:165 Se awon okunrin ninu eda ni eyin okunrin yoo lo maa ba (fun adun ibalopo)
ﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅ
26:166 E si n pa ohun ti Oluwa yin da fun yin ti ninu awon iyawo yin! Ani se, ijo alakoyo ni eyin.”
ﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎ
26:167 Won wi pe: “Ti iwo Lut ko ba jawo (nibi ipepe re) dajudaju o maa wa ninu awon ti a maa le jade kuro ninu ilu.”
ﮏﮐﮑﮒﮓﮔ
26:168 O so pe: "Dajudaju emi wa ninu awon olubinu si ise (aburu) owo yin
ﮕﮖﮗﮘﮙﮚ
26:169 Oluwa mi, la emi ati awon eniyan mi nibi ohun ti won n se nise (aburu)
ﮛﮜﮝﮞ
26:170 Nitori naa, A la oun ati awon eniyan re patapata
ﮟﮠﮡﮢﮣ
26:171 Afi arugbobinrin kan ti o wa ninu awon t’o se ku leyin (laaarin awon ti A pare)
ﮤﮥﮦﮧ
26:172 Leyin naa, A pa awon yooku run
ﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯ
26:173 A ro ojo le won lori taara. Ojo awon ti A kilo fun si buru
ﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚ
26:174 Dajudaju ami wa ninu iyen. Opolopo won ni ko si je onigbagbo ododo
ﯛﯜﯝﯞﯟﯠ
26:175 Dajudaju Oluwa re, Oun ma ni Alagbara, Asake-orun
ﯡﯢﯣﯤﯥ
26:176 Awon ara ’Aekah pe awon Ojise ni opuro
ﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬ
26:177 Nigba ti arakunrin won, (Anabi) Su‘aeb, so pe: “Se eyin ko nii beru (Allahu) ni
ﯭﯮﯯﯰﯱ
26:178 Dajudaju emi ni Ojise olufokantan fun yin
ﯲﯳﯴﯵ
26:179 Nitori naa, e beru Allahu, ki e si tele mi
ﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂ
26:180 Emi ko si beere owo-oya kan ni owo yin lori re. Ko si esan mi lodo eni kan afi lodo Oluwa gbogbo eda
ﰃﰄﰅﰆﰇﰈﰉﰊ
26:181 E won osuwon kun. Ki e si ma se wa ninu awon oludosuwonku
ﰋﰌﰍﰎ
26:182 E fi iwon t’o to won nnkan
ﰏﰐﰑﰒﰓﰔﰕﰖﰗﰘ
26:183 E ma se din nnkan awon eniyan ku. Ki e si ma se huwa aburu lori ile ni ti obileje
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖ
26:184 Ki e si beru Eni ti O da yin ati awon iran akoko.”
ﭗﭘﭙﭚﭛﭜ
26:185 Won wi pe: “Iwo kuku wa ninu awon eleedi
ﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦ
26:186 Iwo ko si je kini kan bi ko se abara bi iru wa. Ati pe a o ro o si kini kan bi ko se pe o wa ninu awon opuro
ﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰ
26:187 Nitori naa, je ki apa kan ninu sanmo ya lu wa mole, ti o ba wa ninu awon olododo.”
ﭱﭲﭳﭴﭵﭶ
26:188 O so pe: “Oluwa mi nimo julo nipa ohun ti e n se nise
ﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂ
26:189 Won si pe e ni opuro. Nitori naa, iya ojo esujo si je won. Dajudaju o je iya ojo nla
ﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌ
26:190 Dajudaju ami wa ninu iyen. Opolopo won ni ko si je onigbagbo ododo
ﮍﮎﮏﮐﮑﮒ
26:191 Dajudaju Oluwa re, Oun ma ni Alagbara, Asake-orun
ﮓﮔﮕﮖﮗ
26:192 Dajudaju al-Ƙur’an, won so o kale ni lati odo Oluwa gbogbo eda
ﮘﮙﮚﮛﮜ
26:193 Molaika Jibril, olufokantan l’o so o kale
ﮝﮞﮟﮠﮡﮢ
26:194 sinu okan re nitori ki o le wa ninu awon olukilo
ﮣﮤﮥﮦ
26:195 pelu ede Larubawa ponnbele
ﮧﮨﮩﮪﮫ
26:196 Dajudaju (oro nipa re) ti wa ninu ipin-ipin Tira awon eni akoko
ﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖ
26:197 Se ko je ami kan fun won pe awon onimo (ninu) awon omo ’Isro’il nimo (si asoole nipa) re (ninu tira owo won)
ﯗﯘﯙﯚﯛﯜ
26:198 Ti o ba je pe A so o kale fun apa kan awon elede miiran ni
ﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣ
26:199 ti o si ke e fun won, won ko nii gba a gbo ni ododo
ﯤﯥﯦﯧﯨﯩ
26:200 Bayen ni A se mu (atako) wo inu okan awon elese
ﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱ
26:201 Won ko nii gba a gbo ni ododo titi won yoo fi ri iya eleta-elero
ﯲﯳﯴﯵﯶﯷ
26:202 (Iya naa) yoo de ba won ni ojiji; won ko si nii fura
ﯸﯹﯺﯻﯼ
26:203 Nigba naa ni won yoo wi pe: "Nje won le lo wa lara bi
ﯽﯾﯿ
26:204 Se iya Wa ni won n wa pelu ikanju
ﰀﰁﰂﰃﰄ
26:205 So fun Mi ti A ba fun won ni igbadun aye fun odun gbooro
ﰅﰆﰇﰈﰉﰊ
26:206 Leyin naa, ki ohun ti A n se ni adehun fun won de ba won
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗ
26:207 Ohun ti A se ni igbadun fun won ko si nii ro won loro
ﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟ
26:208 A o si pa ilu kan run afi ki won ti ni awon olukilo
ﭠﭡﭢﭣﭤ
26:209 Iranti (de fun won se). Ati pe Awa ki i se alabosi
ﭥﭦﭧﭨﭩ
26:210 Ki i se awon esu ni won so (al-Ƙur’an) kale
ﭪﭫﭬﭭﭮﭯ
26:211 Ko ye fun won. Won ko si lagbara re
ﭰﭱﭲﭳﭴ
26:212 Dajudaju A ti mu won takete si gbigbo re (lati oju sanmo)
ﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾ
26:213 Nitori naa, ma se pe olohun miiran mo Allahu, nitori ki iwo ma baa wa ninu awon ti A maa je niya
ﭿﮀﮁﮂ
26:214 Ki o si kilo fun awon ebi re, t’o sunmo julo
ﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉ
26:215 Ki o si re apa re nile fun awon t’o tele o ninu awon onigbagbo ododo
ﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑ
26:216 Ti won ba si yapa (ase) re, so pe: “Dajudaju emi yowo yose ninu ohun ti e n se (nise aburu).”
ﮒﮓﮔﮕﮖ
26:217 Ki o si gbarale Alagbara, Asake-orun
ﮗﮘﮙﮚﮛ
26:218 Eni t’O n ri o nigba ti o n dide naro (fun irun kiki)
ﮜﮝﮞﮟ
26:219 ati iyirapada re (fun rukuu ati iforikanle) laaarin awon oluforikanle
ﮠﮡﮢﮣﮤ
26:220 Dajudaju Oun ma ni Olugbo, Onimo
ﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫ
26:221 Se ki ng so eni ti awon esu n sokale wa ba
ﮬﮭﮮﮯﮰﮱ
26:222 Won n sokale wa ba gbogbo awon opuro, elese
ﯓﯔﯕﯖﯗ
26:223 (Awon esu) n deti (si iro sanmo). Opolopo won si ni opuro
ﯘﯙﯚﯛ
26:224 Awon elewi, awon olusina l’o n tele won
ﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣ
26:225 Se o o ri i pe gbogbo ogbun oro ni won n tenu bo ni
ﯤﯥﯦﯧﯨﯩ
26:226 Ati pe dajudaju won n so ohun ti won ko nii se
ﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾ
26:227 Afi awon t’o gbagbo ni ododo, ti won se ise rere, ti won ranti Allahu ni opolopo, ti won si jaja gbara leyin ti won ti sabosi si won. Awon t’o sabosi si maa mo iru ikangun ti won maa gunle si

Al-Kur'an


Wednesday, September 9, 2026

Don't forget us in your sincere prayers