سوره توبه به زبان یوروبا
بَرَاءَةٌ مِّنَ اللَّهِ وَرَسُولِهِ إِلَى الَّذِينَ عَاهَدتُّم مِّنَ الْمُشْرِكِينَ(1) (Eyi ni) iyowo-yose lati odo Allahu ati Ojise Re si awon ti e se adehun fun ninu awon osebo |
Nitori naa, (eyin osebo) e rin (kiri) lori ile fun osu merin. Ki e si mo pe dajudaju eyin ko le moribo (ninu iya) Allahu. Ati pe dajudaju Allahu yoo doju ti awon alaigbagbo |
Ikede kan lati odo Allahu ati Ojise Re si awon eniyan ni ojo Hajj Nla ni pe, “Dajudaju Allahu yowoyose (ninu oro) awon osebo. Ojise Re naa (yowoyose). Ti e ba ronu piwada, o si loore julo fun yin. Ti e ba gbunri, e mo pe dajudaju e o le moribo ninu (iya) Allahu.” Ki o si fun awon t’o sai gbagbo ni iro iya eleta-elero |
Ayafi awon ti e ba se adehun ninu awon osebo, leyin naa, ti won ko si fi ona kan kan ye adehun yin, ti won ko si satileyin fun eni kan kan le yin lori. Nitori naa, e pe adehun won fun won titi di asiko won. Dajudaju Allahu nifee awon oluberu (Re) |
Nitori naa, nigba ti awon osu owo ba lo tan , e pa awon osebo nibikibi ti e ba ti ba won. E mu won, e sede mo won, ki e si ba de won ni gbogbo ibuba. Ti won ba si ronu piwada, ti won n kirun, ti won si n yo Zakah, e yago fun won loju ona. Dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun |
Ti eni kan ninu awon osebo ba wa eto aabo wa sodo re, s’eto aabo fun un titi o fi maa gbo oro Allahu. Leyin naa, mu u de aye ifokanbale re. Iyen nitori pe dajudaju awon ni ijo ti ko nimo |
Bawo ni adehun kan yoo se wa fun awon osebo lodo Allahu ati lodo Ojise Re yato si awon ti e ba se adehun nitosi Mosalasi Haram? Nitori naa, ti won ba duro deede pelu yin, e duro deede pelu won. Dajudaju Allahu nifee awon oluberu (Re) |
Bawo (ni adehun kan yoo se wa fun won) nigba ti o je pe ti won ba bori yin, won ko nii so okun ibi ati adehun. Won n fi enu won wi pe awon yonu si yin, okan won si ko o. Opolopo won si ni obileje |
Won ta awon ayah Allahu ni owo pooku, won si seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Re. Dajudaju awon (wonyi), ohun ti won n se nise buru |
لَا يَرْقُبُونَ فِي مُؤْمِنٍ إِلًّا وَلَا ذِمَّةً ۚ وَأُولَٰئِكَ هُمُ الْمُعْتَدُونَ(10) Awon osebo ko nii so okun ibi ati adehun kan fun onigbagbo ododo kan. Awon wonyen, awon si ni olutayo enu-ala |
Nitori naa, ti won ba ronu piwada, ti won n kirun, ti won si n yo Zakah, nigba naa omo-iya yin ninu esin ni won. A n salaye awon ayah naa fun ijo t’o nimo |
Ti won ba ru ibura won leyin adehun won, ti won si n soro aidara si esin yin, nigba naa e ja awon olori alaigbagbo logun - dajudaju ibura won ko ni itumo kan si won – ki won le jawo (nibi aburu) |
Se e o nii gbogun ti ijo kan t’o ru ibura won, ti won si gbero lati le Ojise kuro (ninu ilu); awon si ni won ko bere si gbogun ti yin ni igba akoko? Se e n paya won ni? Allahu l’O ni eto julo si pe ki e paya Re ti e ba je onigbagbo ododo |
E ja won logun. Allahu yoo je won niya lati owo yin. O maa yepere won. O maa ran yin lowo lori won. O si maa wo okan ijo onigbagbo ododo san |
وَيُذْهِبْ غَيْظَ قُلُوبِهِمْ ۗ وَيَتُوبُ اللَّهُ عَلَىٰ مَن يَشَاءُ ۗ وَاللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٌ(15) O tun maa ko ibinu okan won lo. O si maa gba ironupiwada lowo eni t’O ba fe. Allahu si ni Onimo, Ologbon |
Tabi e lero pe A oo fi yin sile lai je pe Allahu ti safi han awon t’o maa jagun esin ninu yin, ti won ko si ni ore ayo kan leyin Allahu, Ojise Re ati awon onigbagbo ododo? Allahu ni Alamotan nipa ohun ti e n se nise |
Ko letoo fun awon osebo lati se amojuto awon mosalasi Allahu, nigba ti won je elerii si aigbagbo lori ara won. Awon wonyen ni ise won ti baje. Olusegbere si ni won ninu Ina |
Eni ti o maa samojuto awon mosalasi Allahu ni eni t’o gbagbo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin, t’o si n kirun, t’o n yo Zakah, ko si paya (orisa kan) leyin Allahu. Awon wonyen ni won kuku wa ninu awon olumona |
Se e maa se fifun alalaaji ni omi mu ati sise amojuto Mosalasi Haram ni ohun t’o dogba si eni t’o gbagbo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin, t’o si jagun soju ona (esin) Allahu? Won ko dogba lodo Allahu. Allahu ko nii fi ona mo ijo alabosi |
Awon t’o gbagbo ni ododo, ti won gbe ilu won ju sile, ti won si fi dukia won ati emi won jagun fun esin Allahu, won tobi julo ni ipo lodo Allahu. Awon wonyen, awon si ni olujere |
يُبَشِّرُهُمْ رَبُّهُم بِرَحْمَةٍ مِّنْهُ وَرِضْوَانٍ وَجَنَّاتٍ لَّهُمْ فِيهَا نَعِيمٌ مُّقِيمٌ(21) Oluwa won n fun won ni iro idunnu nipa ike lati odo Re pelu iyonu ati awon Ogba Idera kan ti idera gbere wa fun won ninu re |
خَالِدِينَ فِيهَا أَبَدًا ۚ إِنَّ اللَّهَ عِندَهُ أَجْرٌ عَظِيمٌ(22) Olusegbere ni won ninu re titi laelae. Dajudaju Allahu, odo Re ni esan nla wa |
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se mu awon baba yin ati awon arakunrin yin ni ore ayo bi won ba gbola fun aigbagbo lori igbagbo ododo. Enikeni t’o ba mu won ni ore ayo ninu yin, awon wonyen, awon ni alabosi |
So pe: “Ti o ba je pe awon baba yin, awon omokunrin yin, awon arakunrin yin, awon iyawo yin ati awon ibatan yin pelu awon dukia kan ti e ti ko jo ati okowo kan ti e n beru pe ki o ma kuta ati awon ibugbe ti e yonu si, (ti iwonyi) ba wu yin ju Allahu ati Ojise Re pelu jija ogun soju ona (esin) Re, e maa reti (ikangun) nigba naa titi Allahu yoo fi mu ase Re wa. Allahu ko nii fi ona mo ijo obileje |
Dajudaju Allahu ti se aranse fun yin ni opolopo oju ogun ati ni ojo (ogun) Hunaen, nigba ti pipo yin jo yin loju, (amo) ko ro yin loro kan kan; ile si fun mo yin tohun ti bi o se fe to. Leyin naa, e peyin da, e si n sa seyin |
Leyin naa, Allahu so ifayabale Re kale fun Ojise Re ati fun awon onigbagbo ododo. O tun so awon omo ogun kan kale, ti e o foju ri won. O si je awon t’o sai gbagbo niya. Iyen si ni esan awon alaigbagbo |
ثُمَّ يَتُوبُ اللَّهُ مِن بَعْدِ ذَٰلِكَ عَلَىٰ مَن يَشَاءُ ۗ وَاللَّهُ غَفُورٌ رَّحِيمٌ(27) Leyin naa, Allahu yoo gba ironupiwada lowo eni t’O ba fe leyin iyen. Allahu si ni Alaforijin, Asake-orun |
Eyin ti e gbagbo ni ododo, dajudaju egbin ni awon osebo. Nitori naa, won ko gbodo sunmo Mosalasi Haram leyin odun won yii. Ti e ba n beru osi, laipe Allahu maa ro yin loro ninu ola Re, ti O ba fe. Dajudaju Allahu ni Onimo, Ologbon |
E gbogun ti awon ti ko gbagbo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin, awon ti ko se ni eewo ohun ti Allahu ati Ojise Re se ni eewo ati awon ti ko se esin ododo ninu awon ti A fun ni tira. (E gbogun ti won) titi won yoo fi maa fi owo ara won san owo-ori ni eni yepere |
Awon yehudi wi pe: "‘Uzaer ni omo Allahu." Awon nasara si wi pe: "Mosih ni omo Allahu." Iyen ni oro won ni enu won. Won n fi jo oro awon t’o sai gbagbo siwaju (won). Allahu fi won gegun-un. Bawo ni won se n seri won kuro nibi ododo |
Won mu awon alufaa won (ninu yehudi) ati awon alufaa won (ninu nasara) ni oluwa leyin Allahu. (Won tun mu) Mosih omo Moryam (ni oluwa leyin Allahu). Bee si ni A o pa won lase kan tayo jijosin fun Olohun, Okan soso. Ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. O mo tayo nnkan ti won n fi sebo si I |
Won fe fi enu won pa imole (esin) Allahu, Allahu yo si ko (fun won) titi O fi maa pe imole (esin) Re, awon alaigbagbo ibaa korira re |
(Allahu) Oun ni Eni ti O fi imona ati esin ododo (esin ’Islam) ran Ojise Re nitori ki O le fi bori esin (miiran), gbogbo re patapata, awon osebo ibaa korira re |
Eyin ti e gbagbo ni ododo, opolopo ninu awon alufaa (ninu yehudi) ati awon alufaa (ninu nasara), won kuku n fi ona eru je dukia awon eniyan ni, won si n seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Allahu. Awon t’o si n ko wura ati fadaka jo, won ko si na an fun esin Allahu, fun won ni iro iya eleta-elero |
Ni ojo ti A oo maa yo (wura ati fadaka naa) ninu ina Jahanamo, A o si maa fi jo iwaju won, egbe won ati eyin won. (A si maa so pe): "Eyi ni ohun ti e ko jo fun emi ara yin. Nitori naa, e to ohun ti e ko jo wo |
Dajudaju onka awon osu lodo Allahu n je osu mejila ninu akosile ti Allahu ni ojo ti O ti da awon sanmo ati ile. Merin ni osu owo ninu re. Iyen ni esin t’o fese rinle. Nitori naa, e ma sabosi si ara yin ninu awon osu owo. Ki gbogbo yin si gbogun ti awon osebo gege bi gbogbo won se n gbogun ti yin. Ki e si mo pe dajudaju Allahu wa pelu awon oluberu (Re) |
Alekun ninu aigbagbo ni didajo si awon osu owo (lati owo awon osebo). Won n fi ko isina ba awon t’o sai gbagbo (nipa pe) won n se osu owo kan ni osu eto (fun ogun jija) ninu odun kan, won si n bu owo fun osu (ti ki i se osu owo) ninu odun (miiran, won ko si nii jagun ninu re) nitori ki won le yo onka osu ti Allahu se ni owo sira won. Won si tipase bee se ni eto ohun ti Allahu se ni eewo. Won se ise aburu won ni oso fun won. Allahu ko nii fi ona mo ijo alaigbagbo |
Eyin ti e gbagbo ni ododo, ki ni o mu yin ti o fi je pe nigba ti A ba so fun yin pe ki e jade (lati jagun) loju ona (esin) Allahu, (igba naa ni) e maa kandi mole! Se e yonu si isemi aye (yii) ju ti orun ni? Igbadun isemi aye (yii) ko si je kini kan ninu ti orun afi die |
Afi ki e tu jade (sogun esin) ni Allahu ko fi nii je yin niya eleta-elero ati pe ni ko fi nii fi ijo to yato si yin paaro yin. E ko si le fi kini kan ko inira ba (Allahu). Allahu si ni Alagbara lori gbogbo nnkan |
Afi ki e ran an lowo, Allahu kuku ti ran an lowo nigba ti awon t’o sai gbagbo le e jade (kuro ninu ilu). O si je okan ninu awon meji.1 Nigba ti awon mejeeji wa ninu ogbun, ti (Anabi) si n so fun olubarin re pe: "Ma se banuje, dajudaju Allahu wa pelu wa."2 Nigba naa, Allahu so ifayabale Re kale fun un. O fi awon omo ogun kan ti e o foju ri ran an lowo. O si mu oro awon t’o sai gbagbo wale. Oro Allahu, ohun l’o si leke. Allahu si ni Alagbara, Ologbon |
E tu jade (fun ogun esin) pelu okun ati iroju. Ki e si fi awon dukia yin ati emi yin jagun fun esin Allahu. Iyen loore julo fun yin ti e ba mo |
Ti o ba je pe nnkan igbadun (oro ogun) arowoto ati irin-ajo ti ko jinna (l’o pe won si ni), won iba tele o. Sugbon irin-ajo ogun Tabuk jinna loju won. Won yo si maa fi Allahu bura pe: “Ti o ba je pe a lagbara ni, awa iba jade (fun ogun esin) pelu yin.” – Won si n ko iparun ba emi ara won (nipa sise isobe-selu.) – Allahu si mo pe dajudaju opuro ni won |
Allahu ti samojukuro fun o. Ki lo mu o yonda fun won (pe ki won duro sile? Iwo iba ma se bee) titi oro awon t’o sododo yoo fi han si o kedere. Iwo yo si mo awon opuro |
Awon t’o gbagbo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin ko nii toro iyonda lodo re lati ma fi dukia won ati emi won jagun fun esin Allahu. Allahu si ni Onimo nipa awon oluberu (Re) |
Awon t’o n toro iyonda lodo re (lati jokoo sile, dipo lilo si oju-ogun) ni awon ti ko gbagbo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin; okan won si n seyemeji. Nitori naa, won n daamu kiri nibi iseye-meji won |
Ti o ba je pe won gbero ijade fun ogun esin ni, won iba se ipalemo fun un. Sugbon Allahu korira idide won fun ogun esin, O si ko ifaseyin ba won. Won si so fun won pe: "E jokoo pelu awon olujokoo sile |
Ti o ba je pe won jade pelu yin, won ko nii kun yin afi pelu ibaje. Won yo si sare maa da rukerudo sile laaarin yin, ti won yoo maa ko yin sinu iyonu. Ati pe won ni olugboro fun won laaarin yin. Allahu si ni Onimo nipa awon alabosi |
Won kuku ti da iyonu sile teletele. Won si doju awon oro ru fun o titi ododo fi de, ti ase Allahu si foju han kedere; emi won si ko o |
O wa ninu won, eni ti n wi pe: “Yonda fun mi (ki ng jokoo sile); ma se ko mi sinu adanwo.” Inu adanwo (sisa fogun esin) ma ni won ti subu si yii. Dajudaju ina Jahanamo yo si kuku yi awon alaigbagbo po |
Ti daadaa ba sele si o, o maa ba won ninu je. Ti aida ba si sele si o, won a wi pe: “A kuku ti gba ase tiwa siwaju (lati jokoo sile.)” Won a peyin da; won yo si maa dunnu |
So pe: “Ko si ohun kan t’o maa sele si wa ayafi ohun ti Allahu ko mo wa. Oun ni Alaabo wa.” Allahu si ni ki awon onigbagbo ododo gbarale |
So pe: "Se e n reti kini kan pelu wa ni bi ko se okan ninu daadaa meji (iku ogun tabi isegun)? Awa naa n reti pelu yin pe ki Allahu mu iya kan wa ba yin lati odo Re tabi lati owo wa. Nitori naa, e maa reti, dajudaju awa naa wa pelu yin ti a n reti |
قُلْ أَنفِقُوا طَوْعًا أَوْ كَرْهًا لَّن يُتَقَبَّلَ مِنكُمْ ۖ إِنَّكُمْ كُنتُمْ قَوْمًا فَاسِقِينَ(53) So pe: "E finnu-findo nawo ni tabi pelu tipatipa, A o nii gba a lowo yin (nitori pe) dajudaju eyin je ijo obileje |
Ko si si ohun kan ti ko je ki A gba inawo won lowo won bi ko se pe dajudaju won sai gbagbo ninu Allahu ati Ojise Re. Won ko nii wa kirun afi ki won je oroju alainikan-anse. Won ko si nii nawo fesin afi ki emi won ko o |
Nitori naa, ma se je ki awon dukia won ati awon omo won ya o lenu; Allahu kan fe fi je won niya ninu isemi aye (yii) ni. Emi yo si bo lara won, ti won maa wa nipo alaigbagbo |
وَيَحْلِفُونَ بِاللَّهِ إِنَّهُمْ لَمِنكُمْ وَمَا هُم مِّنكُمْ وَلَٰكِنَّهُمْ قَوْمٌ يَفْرَقُونَ(56) Won n fi Allahu bura pe dajudaju awon kuku wa lara yin. Won ko si si lara yin, sugbon dajudaju won je ijo kan t’o n beru |
لَوْ يَجِدُونَ مَلْجَأً أَوْ مَغَارَاتٍ أَوْ مُدَّخَلًا لَّوَلَّوْا إِلَيْهِ وَهُمْ يَجْمَحُونَ(57) Ti o ba je pe won ri ibusasi kan, tabi awon iho apata kan, tabi ibusawo kan, won iba seri sibe ni werewere |
O tun wa ninu won, eni ti n da o lebi nibi (pipin) awon ore. Ti A ba fun won ninu re, won a yonu (si i). Ti A o ba si fun won ninu re, nigba naa ni won yoo maa binu |
Ati pe (iba loore fun won) ti o ba je pe dajudaju won yonu si ohun ti Allahu ati Ojise Re fun won, ki won si so pe: "Allahu to wa. Allahu yo si fun wa ninu oore ajulo Re ati pe Ojise Re (si maa pin ore) , dajudaju odo Allahu si ni awa n wa oore si |
Awon ti ore (Zakah) wa fun ni awon alaini, awon mekunnu, awon osise Zakah, awon ti okan won fe gba ’Islam, awon eru (fun gbigba ominira), awon onigbese, awon t’o wa loju ogun (esin) Allahu ati onirin-ajo (ti agara da). Oran-anyan ni lati odo Allahu. Allahu si ni Onimo, Ologbon |
Awon t’o n ko inira ba Anabi wa ninu won, ti won si n wi pe: “Eleti-ofe ni." So pe: "Eleti-ofe rere ni fun yin; o gbagbo ninu Allahu. O si gba awon onigbagbo ododo gbo. Ike ni fun awon onigbagbo ododo ninu Ojise Allahu, iya eleta-elero n be fun won.” |
Won n fi Allahu bura fun yin lati wa iyonu yin. Allahu ati Ojise Re l’o si ye ki won wa iyonu Re ti won ba je onigbagbo ododo |
Se won ko mo pe enikeni t’o ba n tako Allahu ati Ojise Re, dajudaju ina Jahanamo ti wa fun un ni? Olusegbere si ni ninu re. Iyen si ni abuku nla |
Awon sobe-selu musulumi n beru pe ki A ma se so surah kan kale nipa won, ti o maa fun won ni iro ohun ti n be ninu okan won. So pe: "E maa se yeye lo. Dajudaju Allahu yoo safi han ohun ti e n beru |
Ti o ba kuku bi won leere, dajudaju won a wi pe: "Awa kan n rojo lasan ni, a si n sawada ni." So pe: "Se Allahu, awon ayah Re ati Ojise Re ni e n fi se yeye |
E ma se mu awawi wa. Dajudaju e ti sai gbagbo leyin igbagbo yin. Ti A ba se amojukuro fun apa kan ninu yin, A oo fiya je apa kan nitori pe won je elese |
Awon sobe-selu musulumi lokunrin ati awon sobe-selu musulumo lobinrin, iru kan-un ni won; won n pase ohun buruku, won n ko ohun rere, won si n kawo gbera (lati nawo fesin). Won gbagbe Allahu. Nitori naa, Allahu gbagbe won. Dajudaju awon sobe-selu musulumi, awon ni obileje |
Allahu si ti se adehun ina Jahanamo fun awon sobe-selu musulumi lokunrin ati awon sobe-selu musulumo lobinrin ati awon alaigbagbo. Olusegbere ni won ninu re. Ina maa to won. Allahu si ti sebi le won. Iya gbere si wa fun won |
(Awon sobe-selu musulumi da) gege bi awon t’o siwaju yin; won le ju yin lo ni agbara, won si po (ju yin lo) ni awon dukia ati awon omo. Nigba naa, won je igbadun ipin tiwon (ninu oore aye). Eyin (sobe-selu wonyii naa yoo) je igbadun ipin tiyin gege bi awon t’o siwaju yin se je igbadun ipin tiwon. Eyin naa si sosokuso bi eyi ti awon naa so ni isokuso. Awon wonyen, awon ise won ti baje ni aye ati ni orun. Awon wonyen, awon si ni eni ofo |
Se iroyin awon t’o siwaju won ko ti i de ba won ni? (Iroyin) ijo (Anabi) Nuh, iran ‘Ad, iran Thamud, ijo (Anabi) ’Ibrohim, awon ara Modyan ati awon ilu ti A doju re bole (ijo Anabi Lut); awon Ojise won wa ba won pelu awon eri t’o yanju. Nitori naa, Allahu ko se abosi si won, sugbon emi ara won ni won sabosi si |
Awon onigbagbo ododo lokunrin ati awon onigbagbo ododo lobinrin, apa kan won lore apa kan; won n pase ohun rere, won n ko ohun buruku, won n kirun, won n yo Zakah, won si n tele ti Allahu ati Ojise Re. Awon wonyen ni Allahu yoo sake. Dajudaju Allahu ni Alagbara, Ologbon |
Allahu se adehun awon Ogba Idera fun awon onigbagbo ododo lokunrin ati awon onigbagbo ododo lobinrin, eyi ti awon odo n san ni isale re. Olusegbere ni won ninu re. (O tun se adehun) awon ibugbe t’o dara ninu awon ogba idera ‘Adni (fun won). Iyonu lati odo Allahu l’o si tobi julo (fun won). Iyen, ohun ni erenje nla |
Iwo Anabi, gbogun ti awon alaigbagbo ati awon sobe-selu musulumi. Ki o si le mo won. Ina Jahanamo ni ibugbe won. Ikangun naa si buru |
Won n fi Allahu bura pe awon ko soro (buruku). Won si kuku ti so oro aigbagbo, won si sai gbagbo leyin ti won ti gba ’Islam. Won tun gberokero si nnkan ti owo won ko nii ba. Won ko tako kini kan bi ko se nitori pe Allahu ati Ojise Re ro awon (Sohabah) loro ninu ola Re. Ti won ba ronu piwada, o maa dara fun won. Ti won ba si koyin (si yin), Allahu yoo je won niya eleta-elero ni aye ati ni orun. Ko si nii si alaabo ati alaranse kan fun won lori ile aye |
O wa ninu won, eni t’o ba Allahu se adehun pe: "Ti O ba fun wa ninu oore-ajulo Re, dajudaju a oo maa tore, dajudaju a o si wa ninu awon eni ire |
فَلَمَّا آتَاهُم مِّن فَضْلِهِ بَخِلُوا بِهِ وَتَوَلَّوا وَّهُم مُّعْرِضُونَ(76) Amo nigba ti O fun won ninu oore-ajulo Re, won sahun si I. Won peyin da, won si n gbunri (lati nawo fesin) |
Nitori naa, ahun won mu oro won kangun si isobe-selu ninu okan won titi di ojo ti won yoo pade Allahu nitori pe won ye adehun ti won ba Allahu se ati nitori pe won n paro |
أَلَمْ يَعْلَمُوا أَنَّ اللَّهَ يَعْلَمُ سِرَّهُمْ وَنَجْوَاهُمْ وَأَنَّ اللَّهَ عَلَّامُ الْغُيُوبِ(78) Se won ko mo pe Allahu mo asiri won ati oro ateso won, ati pe dajudaju Allahu ni Onimo nipa awon ikoko |
Awon t’o n bu awon olutore-aanu ninu awon onigbagbo ododo lori ore tita ati awon ti ko ri nnkan kan tayo iwon agbara won, won si n fi won se yeye, Allahu fi awon naa se yeye. Iya eleta-elero si wa fun won |
Yala o toro aforijin fun won tabi o o toro aforijin fun won – koda ki o toro aforijin fun won nigba aadorin – Allahu ko nii forijin won. Iyen nitori pe dajudaju won sai gbagbo ninu Allahu ati Ojise Re. Allahu ko nii fi ona mo ijo obileje |
Awon olusaseyin fun ogun esin dunnu si jijokoo sinu ile won leyin Ojise Allahu. Won si korira lati fi dukia won ati emi won jagun loju ona (esin) Allahu. Won tun wi pe: “E ma lo jagun ninu ooru gbigbona.” So pe: “Ina Jahanamo le julo ni gbigbona, ti o ba je pe won gbo agboye oro.” |
فَلْيَضْحَكُوا قَلِيلًا وَلْيَبْكُوا كَثِيرًا جَزَاءً بِمَا كَانُوا يَكْسِبُونَ(82) Nitori naa, ki won rerin-in die, ki won si sunkun pupo; (o je) esan (fun) ohun ti won n se nise |
Ti Allahu ba mu o dele ba igun kan ninu won, ti won ba wa n gbase lodo re fun jijade fun ogun esin, so nigba naa pe: “Eyin ko le jade fun ogun esin mo pelu mi. Eyin ko si le ja ota kan logun mo pelu mi, nitori pe e ti yonu si ijokoo sile ni igba akoko. Nitori naa, e jokoo sile ti awon olusaseyin fun ogun esin.” |
Laelae, o o gbodo kirun si eni kan kan lara ninu won, ti o ba ku, o o si gbodo duro nibi saree re, nitori pe won sai gbagbo ninu Allahu ati Ojise Re. Won si ku nigba ti won wa nipo obileje |
Ma se je ki awon dukia won ati awon omo won ya o lenu; Allahu kan fe fi je won niya ninu isemi aye (yii) ni. (O si fe ki) emi bo lara won, nigba ti won ba wa nipo alaigbagbo |
Nigba ti A ba so surah kan kale pe ki won gbagbo ninu Allahu, ki won si jagun pelu Ojise Re, (nigba naa ni) awon oloro ninu won yoo maa toro iyonda lodo re, won a si wi pe: “Fi wa sile ki a wa pelu awon olujokoo sile.” |
رَضُوا بِأَن يَكُونُوا مَعَ الْخَوَالِفِ وَطُبِعَ عَلَىٰ قُلُوبِهِمْ فَهُمْ لَا يَفْقَهُونَ(87) Won yonu si ki won maa wa pelu awon olusaseyin fun ogun esin. A ti fi edidi di okan won pa; nitori naa, won ko nii gbo agboye |
Sugbon Ojise ati awon t’o gbagbo ni ododo pelu re, won fi dukia won ati emi won jagun esin. Awon wonyen, awon oore n be fun won. Awon wonyen, awon si ni olujere |
Allahu ti pese sile de won awon Ogba Idera kan ti odo n san ni isale re. Olusegbere ni won ninu re. Iyen ni erenje nla |
Awon alawaawi ninu awon Larubawa oko wa (ba o) nitori ki won le yonda (ijokoo sile) fun won. Awon t’o si pe oro Allahu ati oro Ojise niro naa jokoo sile. Iya eleta-elero yo si fowo ba awon t’o sai gbagbo ninu won |
Ko si ese fun awon alailagbara, awon alaisan ati awon ti ko ri ohun ti won maa na ni owo (lati fi jagun esin) nigba ti won ba ti ni otito si Allahu ati Ojise Re. Ko si ibawi kan fun awon olotiito-inu se. Allahu si ni Alaforijin, Asake-orun |
Ko tun si ese fun awon ti (o je pe) nigba ti won ba wa ba o pe ki o fun awon ni nnkan ti awon yoo gun (lo soju ogun), ti o si so pe, “Ng o ri nnkan ti mo le fun yin gun (lo soju ogun), won maa pada pelu oju won ti yoo maa damije ni ti ibanuje pe won ko ri nnkan ti won maa na (lo soju ogun esin) |
Awon ti ibawi wa fun ni awon t’o n toro iyonda lodo re (lati jokoo sile, ti) won si je oloro, ti won yonu si ki won wa pelu awon olusaseyin fun ogun esin. Allahu ti fi edidi di okan won pa; nitori naa, won ko si mo |
Won yoo mu awawi wa fun yin nigba ti e ba dari de ba won. So pe: "E ma se mu awawi wa; a o nii gba yin gbo. Allahu kuku ti so awon oro yin fun wa. Allahu ati Ojise Re yo si ri ise (owo) yin. Leyin naa, A oo da yin pada si odo Onimo-ikoko ati gbangba. Nigba naa, O maa fun yin ni iro ohun ti e n se nise |
Won yoo maa fi Allahu bura fun yin nigba ti e ba dari de ba won, nitori ki e le pa won ti. Nitori naa, e pa won ti; dajudaju egbin ni won. Ina Jahanamo si ni ibugbe won. (O je) esan nitori ohun ti won n se nise |
Won yoo maa bura fun yin nitori ki e le yonu si won. Ti e ba yonu si won, dajudaju Allahu ko nii yonu si ijo obileje |
Awon Larubawa oko le ninu aigbagbo ati isobe-selu. O si sunmo pe won ko mo awon enu-ala ohun ti Allahu sokale fun Ojise Re. Allahu si ni Onimo, Ologbon |
Ati pe o wa ninu awon Larubawa oko eni ti o ka inawo t’o n na (fun esin) si owo oran. O si n reti apadasi aburu fun yin. Awon si ni apadasi aburu yoo de ba. Allahu si ni Olugbo, Onimo |
O tun wa ninu awon Larubawa oko, eni ti o gbagbo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin, ti o si so inawo t’o n na (fun esin) di awon isunmo Allahu ati (gbigba) adua (lodo) Ojise. Kiye si i, dajudaju ohun ni isunmo Allahu fun won. Allahu yo si fi won sinu ike Re. Dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun |
Awon asiwaju, awon eni akoko ninu awon Muhajirun ati awon ’Ansor pelu awon t’o fi daadaa tele won, Allahu yonu si won. Won si yonu si (ohun ti Allahu fun won). O tun pa lese sile de won awon Ogba Idera ti odo n san ni isale re. Olusegbere ni won ninu re titi laelae. Iyen ni erenje nla |
Awon sobe-selu musulumi kan n be ninu awon ti o wa ni ayika yin ninu awon Larubawa oko ati ninu awon ara ilu Modinah, ti won wonkoko mo isobe-selu. O o mo won, Awa l’A mo won. A oo je won niya ni ee meji. Leyin naa, A oo da won pada sinu iya nla |
Awon miiran jewo ese won. Won da ise rere po mo ise miiran t’o buru. Boya Allahu yoo gba ironupiwada won. Dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun |
Gba ore (Zakah) ninu dukia won, ki o fi so won di eni mimo, ki o si fi se afomo fun won. Se adua fun won. Dajudaju adua re ni ifayabale fun won. Allahu si ni Olugbo, Onimo |
Se won ko mo pe dajudaju Allahu Oun l’O n gba ironupiwada lowo awon erusin Re, O si n gba awon ore, ati pe dajudaju Allahu, Oun ni Olugba-ironupiwada, Asake-orun |
So pe: "E sise. Allahu a ri ise yin, Ojise Re ati awon onigbagbo ododo naa (maa ri i). Won si maa da yin pada sodo Onimo-ikoko-ati-gbangba. O si maa fun yin ni iro ohun ti e n se nise |
Won so oro awon yooku ro na fun ase Allahu; yala ki O je won niya tabi ki O gba ironupiwada won. Allahu si ni Onimo, Ologbon |
Awon t’o ko mosalasi lati fi da inira ati aigbagbo sile ati lati fi se opinya laaarin awon onigbagbo ododo ati lati fi se ibuba fun awon t’o gbogun ti Allahu ati Ojise Re ni isaaju – dajudaju won n bura pe “A o gbero kini kan bi ko se ohun rere.” – Allahu si n jerii pe dajudaju opuro ni won |
Ma se duro (kirun) ninu re laelae. Dajudaju mosalasi ti won ba fi ipile re lele lori iberu Allahu lati ojo akoko l’o letoo julo pe ki o duro (kirun) ninu re. Awon eniyan t’o nifee lati maa se imora wa ninu re. Allahu si feran awon olusemora |
Nje eni ti o fi ipile ile mimo tire lele lori iberu Allahu ati iyonu (Re) l’o loore julo ni tabi eni ti o fi ipile ile mimo tire lele ni egbe kan leti ogbun t’o maa ye lule, ti o si maa ye e lese sinu ina Jahanamo? Allahu ko nii fi ona mo ijo alabosi |
Ile won ti won mo kale ko nii ye ko iyemeji sinu okan won titi okan won yoo fi ja kelekele. Allahu si ni Onimo, Ologbon |
Dajudaju Allahu ra emi awon onigbagbo ododo ati dukia won nitori pe dajudaju tiwon ni Ogba Idera. Won n jagun loju ona (esin) Allahu; won n pa ota esin, won si n pa awon naa. (O je) adehun lodo Allahu. (O je) ododo ninu at-Taorah, al-’Injil ati al-Ƙur’an. Ta si ni o le mu adehun re se ju Allahu? Nitori naa, e dunnu si okowo yin ti e (fi emi ati dukia yin) se. Iyen, ohun si ni erenje nla |
Awon oluronupiwada, awon olujosin (fun Allahu), awon oludupe (fun Allahu), awon alaaawe, awon oludawote-orunkun (lori irun), awon oluforikanle (fun Allahu), awon olupase-ohun rere, awon oluko-ohun buruku ati awon oluso-enu-ala ti Allahu gbekale, fun awon onigbagbo ododo (wonyi) ni iro idunnu (Ogba Idera) |
Ko ye fun Anabi ati awon t’o gbagbo lododo lati toro aforijin fun awon osebo, won ibaa je ebi, leyin ti o ti han si won pe dajudaju ero inu ina Jehim ni won |
Ati pe aforijin ti (Anabi) ’Ibrohim toro fun baba re ko si je kini kan bi ko se nitori adehun t’o se fun un. Sugbon nigba ti o han si i pe dajudaju ota Allahu ni (baba re), o yowo yose kuro ninu re. Dajudaju (Anabi) ’Ibrohim ni oluraworase, olufarada |
Allahu ki i mu isina ba ijo kan, leyin igba ti O ti to won sona, titi (Allahu) yoo fi se alaye nnkan ti won maa sora fun fun won. Dajudaju Allahu ni Onimo nipa gbogbo nnkan |
Dajudaju Allahu l’o ni ijoba awon sanmo ati ile. O n so eda di alaaye. O si n so eda di oku. Ko si si alaabo ati alaranse kan fun yin leyin Allahu |
Dajudaju Allahu ti gba ironupiwada Anabi, awon Muhajirun ati awon ’Ansor, awon t’o tele e ni akoko isoro leyin ti okan igun kan ninu won fee yi pada, (amo) leyin naa, Allahu gba ironupiwada won. Dajudaju Oun ni Alaaanu, Asake-orun fun won |
(O tun gba ironupiwada) awon meta ti A (so oro won ro ninu awon olusaseyin fun ogun Tabuk. Awon musulumi si deye si won) titi ile fi ha mo won tohun ti bi o se feju to. Oro ara won si su ara won. Won si mo (ni amodaju) pe ko si ibusasi kan ti awon fi le sa mo Allahu lowo afi ki won sa si odo Re. Leyin naa, Allahu gba ironupiwada won nitori ki won le maa ronu piwada. Dajudaju Allahu, Oun ni Olugba-ironupiwada, Asake-orun |
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا اتَّقُوا اللَّهَ وَكُونُوا مَعَ الصَّادِقِينَ(119) Eyin ti e gbagbo ni ododo, e beru Allahu, ki e si wa pelu awon olododo |
Ko letoo fun awon ara ilu Modinah ati eni ti o wa ni ayika won ninu awon Larubawa oko lati sa seyin fun Ojise Allahu (nipa ogun esin. Ko si letoo fun won) lati feran emi ara won ju emi re. Iyen nitori pe dajudaju ongbe, inira tabi ebi kan ko nii sele si won loju ogun loju ona (esin) Allahu, tabi won ko nii te ona kan ti n bi awon alaigbagbo ninu, tabi owo won ko nii ba kini kan lara ota afi ki A fi ko ise rere sile fun won. Dajudaju Allahu ko nii fi esan awon oluse-rere rare |
Won ko si nii na owo kekere tabi pupo (fun ogun esin), tabi ki won la afonifoji kan ko ja afi ki A ko o sile fun won nitori ki Allahu le san won ni esan t’o dara julo nipa ohun ti won n se nise |
Gbogbo awon musulumi ko si gbodo da lo si oju ogun esin. Iba suwon ki igun kan ninu won ninu iko kookan jade lati wa agboye nipa esin, ki won si maa se ikilo fun awon eniyan won nigba ti won ba pada sodo won boya won yo le sora se |
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e gbogun ti awon t’o sunmo yin ninu awon alaigbagbo; ki won ri ilekoko lara yin. Ki e si mo pe dajudaju Allahu wa pelu awon oluberu (Re) |
Nigba ti A ba si so surah kan kale, o n be ninu won eni ti o maa wi pe: “Ta ni ninu yin ni eyi le igbagbo (re) kun?” Ni ti awon t’o gbagbo ni ododo, (ayah naa) yo si le igbagbo (won) kun. Won yo si maa dunnu |
Ni ti awon ti aisan si wa ninu okan won, (ayah naa) yo si se alekun egbin si egbin won. Won yo si ku si ipo alaigbagbo |
Se won ko ri i pe A n dan won wo ni ee kan tabi ee meji ni odoodun. Leyin naa, won ko ronu piwada, won ko si lo iranti |
Ati pe nigba ti A ba so surah kan kale, apa kan won yoo wo apa kan loju (won yo si wi pe): “Se eni kan n wo yin bi?” Leyin naa, won maa peyinda. Allahu si pa okan won da (sodi) nitori pe dajudaju awon ni ijo kan ti ko gbo agboye |
Dajudaju Ojise kan ti wa ba yin lati aarin yin. Ohun ti o maa ko inira ba yin lagbara lara re. O n se akolekan (oore orun) fun yin; alaaanuati onikee ni fun awon oni gbagbo ododo |
Nitori naa, ti won ba peyinda, so pe: “Allahu to fun mi. Ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. Oun ni mo gbarale. Oun si ni Oluwa Ite nla |
سورهای بیشتر به زبان یوروبا:
دانلود سوره توبه با صدای معروفترین قراء:
انتخاب خواننده برای گوش دادن و دانلود کامل سوره توبه با کیفیت بالا.
أحمد العجمي
ابراهيم الاخضر
بندر بليلة
خالد الجليل
حاتم فريد الواعر
خليفة الطنيجي
سعد الغامدي
سعود الشريم
الشاطري
صلاح بوخاطر
عبد الباسط
عبدالرحمن العوسي
عبد الرشيد صوفي
عبدالعزيز الزهراني
عبد الله بصفر
عبد الله الجهني
علي الحذيفي
علي جابر
غسان الشوربجي
فارس عباد
ماهر المعيقلي
محمد أيوب
محمد المحيسني
محمد جبريل
المنشاوي
الحصري
مشاري العفاسي
ناصر القطامي
وديع اليمني
ياسر الدوسري
به قرآن کریم چنگ بزنید