Surah Taha pdf — Gbà (Yorùbá)
Surah Taha pdf Yorùbá — Gbà Surah Taha Itumọ. Surah Taha (Meccan) 135 Ẹsẹ.
Related
- Surah Taha ItumọYorùbá
- Surah Taha mp3Gbọ
- Quran Index Yorùbá114
More Surah PDF
Surah Taha

ﭵﭶ
20:1
To ha
ﭷﭸﭹﭺﭻﭼ
20:2
A ko so al-Ƙur’an kale fun o lati ko wahala ba o
ﭽﭾﭿﮀﮁ
20:3
Bi ko se pe o je iranti fun eni t’o n paya (Allahu)
ﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈ
20:4
(O je) imisi t’o sokale lati odo Eni ti O da ile ati awon sanmo giga
ﮉﮊﮋﮌﮍ
20:5
Ajoke-aye gunwa sori Ite-ola
ﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚ
20:6
TiRe ni ohunkohun t’o wa ninu
ﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢ
20:7
Ti o ba so oro jade, dajudaju (Allahu) mo ikoko ati ohun ti o (tun) pamo julo
ﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬ
20:8
Allahu, ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. TiRe ni awon oruko t’o dara julo
ﮭﮮﮯﮰﮱ
20:9
Nje oro (Anabi) Musa de odo re
ﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥ
20:10
(Ranti) nigba ti o ri ina kan, o so fun awon ara ile re pe: “E duro sibi. Dajudaju emi ri ina kan. O see se ki ng ri ogunna mu wa fun yin ninu re tabi ki ng ri oju ona kan nitosi ina naa.”
ﯦﯧﯨﯩﯪ
20:11
Nigba ti o de ibe, A pe e "Musa
ﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴ
20:12
Dajudaju Emi ni Oluwa re. Nitori naa, bo bata re mejeeji sile. Dajudaju iwo wa ni afonifoji mimo, Tuwa
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖ
20:13
Ati pe Emi sa o lesa. Nitori naa, fi eti si ohun ti A maa fi ranse si o ninu imisi
ﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢ
20:14
Dajudaju Emi ni Allahu. Ko si olohun ti ijosin to si afi Emi. Nitori naa, josin fun Mi. Ki o si kirun fun iranti Mi
ﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭ
20:15
Dajudaju Akoko naa n bo. O sunmo ki Ng safi han re (pelu awon ami. Akoko naa wa fun) ki A le san emi kookan ni esan nnkan ti o se nise
ﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸ
20:16
Nitori naa, eni ti ko gba a gbo, ti o si tele ife-inu re, ma se je ki o seri re kuro nibe, ki o ma baa parun
ﭹﭺﭻﭼﭽ
20:17
Ki ni iyen lowo otun re, Musa
ﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋ
20:18
O so pe: “Opa mi ni. Mo n fi rogboku. Mo tun n fi ja ewe fun awon agutan mi. Mo si tun n lo o fun awon bukata miiran.”
ﮌﮍﮎﮏ
20:19
(Allahu) so pe: “Ju u sile, Musa.”
ﮐﮑﮒﮓﮔﮕ
20:20
Nigba naa, o ju u sile. O si di ejo t’o n sare
ﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞ
20:21
(Allahu) so pe: "Mu un dani, ma si se beru. A maa da a pada si irisi re akoko
ﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪ
20:22
Fi owo re mo (abe) apa re, o maa jade ni funfun, ti ki i se taburu. (O tun je) ami miiran
ﮫﮬﮭﮮﮯ
20:23
Ki A le fi eyi t’o tobi ninu awon ami Wa han o
ﮰﮱﯓﯔﯕﯖ
20:24
Lo si odo Fir‘aon. Dajudaju o ti tayo enu-ala
ﯗﯘﯙﯚﯛﯜ
20:25
(Anabi Musa) so pe: “Oluwa mi, si okan mi paya fun mi
ﯝﯞﯟﯠ
20:26
Soro mi dirorun fun mi
ﯡﯢﯣﯤﯥ
20:27
Tu koko ori ahon mi
ﯦﯧﯨ
20:28
ki won maa gbo oro mi ye
ﯩﯪﯫﯬﯭﯮ
20:29
Ati pe fun mi ni amugbalegbee kan ninu awon ara ile mi
ﯯﯰﯱ
20:30
Harun, arakunrin mi ni
ﯲﯳﯴﯵ
20:31
Fi kun mi lowo
ﯶﯷﯸﯹ
20:32
Fi sakegbe mi ninu ise mi
ﯺﯻﯼﯽ
20:33
ki a le safomo (oruko) Re ni opolopo
ﯾﯿﰀ
20:34
ki a tun le seranti Re ni opolopo
ﰁﰂﰃﰄﰅ
20:35
Dajudaju Iwo n ri wa.”
ﰆﰇﰈﰉﰊﰋ
20:36
(Allahu) so pe: "Dajudaju A ti fun o ni ibeere re, Musa
ﰌﰍﰎﰏﰐﰑ
20:37
Ati pe dajudaju A ti se oore fun o nigba kan ri
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗ
20:38
(Ranti) nigba ti A sipaya ohun ti A sipaya fun iya re
ﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯ
20:39
pe: “Ju Musa sinu apoti. Ki o si gbe e ju sinu agbami odo. Odo yo si gbe e ju si eti odo. Ota Mi ati ota re si maa gbe e.” Mo si da ife lati odo Mi bo o nitori ki won le toju re loju Mi.”
ﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕ
20:40
(Ranti) nigba ti arabinrin re n rin lo, o si so pe: “Se ki ng juwe eni ti o maa gba a to (fun yin)?” A si da o pada sodo iya re nitori ki o le ni itutu oju, ko si nii banuje. Ati pe o pa emi eni kan. A si mu o kuro ninu ibanuje. A tun mu awon adanwo kan ba o. O tun lo awon odun kan lodo awon ara Modyan. Leyin naa, o de (ni akoko) ti o ti wa ninu kadara, Musa
ﮖﮗﮘ
20:41
Mo si sa o lesa fun (ise) Mi
ﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡ
20:42
Lo, iwo ati arakunrin re, pelu awon ami (ise iyanu) Mi. Ki e si ma se kole ninu iranti Mi
ﮢﮣﮤﮥﮦﮧ
20:43
E lo ba Fir‘aon. Dajudaju o ti tayo enu-ala
ﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰ
20:44
E so oro ele fun un. O see se ki o lo isiti tabi ki o paya (Mi)
ﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜ
20:45
Awon mejeeji so pe: “Oluwa wa, dajudaju awa n paya pe o ma yara je wa niya tabi pe o ma tayo enu-ala.”
ﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥ
20:46
(Allahu) so pe: “E ma se paya. Dajudaju Emi wa pelu eyin mejeeji; Mo n gbo (yin), Mo si n ri (yin).”
ﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽ
20:47
Nitori naa, e lo ba a, ki e so fun un pe: “Dajudaju Ojise Oluwa re ni awa mejeeji. Nitori naa, je ki awon omo ’Isro’il maa ba wa lo. Ma se fiya je won. Dajudaju a ti mu ami kan wa ba o lati odo Oluwa re. Ki alaafia si maa ba eni ti o ba tele imona
ﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆﰇﰈ
20:48
Dajudaju Won ti fi imisi ranse si wa pe dajudaju iya n be fun eni ti o ba pe ododo niro, ti o si keyin si i
ﰉﰊﰋﰌﰍ
20:49
(Fir‘aon) wi pe: “Ta ni Oluwa eyin mejeeji, Musa?”
ﰎﰏﰐﰑﰒﰓﰔﰕﰖﰗ
20:50
(Anabi Musa) so pe: “Oluwa wa ni Eni ti O fun gbogbo nnkan ni iseda re. Leyin naa, O to o si ona.”
ﰘﰙﰚﰛﰜﰝ
20:51
(Fir‘aon) wi pe: “Ki l’o mu awon iran akoko (ti won ko fi mona)?”
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝ
20:52
(Anabi Musa) so pe: "Imo re wa ninu tira kan lodo Oluwa mi. Oluwa mi ko nii sasise. Ko si nii gbagbe
ﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱ
20:53
(Oun ni) Eni ti O te ile ni perese fun yin. O si la awon ona sinu re fun yin. O si so omi kale lati sanmo. A si fi mu orisirisi jade ninu awon irugbin ni otooto
ﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼ
20:54
E je, ki e si fi bo awon eran-osin yin. Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun awon onilaakaye
ﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆ
20:55
Lati ara erupe ni A ti da yin. Inu re si ni A oo da yin pada si. Lati inu re si ni A oo ti mu yin jade pada nigba miiran
ﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍ
20:56
Dajudaju A ti fi awon ami Wa han an, gbogbo re. Amo o pe e niro. O si ko jale
ﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕ
20:57
O wi pe: "Se o wa ba wa nitori ki o le mu wa jade kuro lori ile wa pelu idan re ni, Musa
ﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤ
20:58
Dajudaju a maa mu idan iru re wa ba o. Nitori naa, mu akoko ipade laaarin awa ati iwo, ti awa ati iwo ko si nii yapa re, (ki o si mu) aye kan t’o teju
ﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭ
20:59
(Anabi Musa) so pe: “Akoko ipade yin ni ojo Oso (iyen, ojo odun). Ki won si ko awon eniyan jo ni iyaleta.”
ﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕ
20:60
Fir‘aon peyin da. O si sa ete re jo mora won. Leyin naa, o de (sibe)
ﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦ
20:61
(Anabi Musa) so pe: “Egbe yin o! E ma se da adapa iro mo Allahu nitori ki O ma baa fi iya pa yin re. Ati pe dajudaju enikeni ti o ba da adapa iro (mo Allahu) ti sofo.”
ﯧﯨﯩﯪﯫﯬ
20:62
Won foro jomi toro oro laaarin ara won. Won si te soro
ﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺ
20:63
Won wi pe: "Dajudaju awon mejeeji yii, opidan ni won o. Won fe mu yin jade kuro lori ile yin pelu idan won ni. Won si (fe) gba oju ona yin t’o dara julo mo yin lowo
ﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆ
20:64
Nitori naa, e ko ete yin jo papo mora won. Leyin naa, ki e to wa ni owoowo. Dajudaju eni ti o ba bori ni oni ti jere
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜ
20:65
(Awon opidan) wi pe: “Musa, iwo ni o maa koko ju (opa sile ni) tabi awa ni a oo koko ju u sile.”
ﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪ
20:66
(Musa) so pe: “E ju (tiyin) sile (na).” Nigba naa ni awon okun won ati opa won ba n yira pada loju re nipase idan won, bi eni pe dajudaju won n sare
ﭫﭬﭭﭮﭯﭰ
20:67
(Anabi) Musa si pa eru inu okan re mora
ﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷ
20:68
A so pe: "Ma se paya. Dajudaju iwo, iwo lo maa leke
ﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊ
20:69
Ju ohun ti n be ni owo otun re sile. O si maa gbe ohun ti won se kale mi kalo. Dajudaju ohun ti won se kale, ete opidan ni. Opidan ko si nii jere ni ibikibi ti o ba de
ﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓ
20:70
Nitori naa, ise iyanu (Anabi Musa) mu awon opidan doju bole ni oluforikanle (fun Allahu). Won wi pe: "A gbagbo ninu Oluwa Harun ati Musa
ﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰ
20:71
(Fir‘aon) wi pe: "Se e ti gba a gbo siwaju ki ng to yonda fun yin? Dajudaju oun ni agba yin ti o ko yin ni idan pipa. Nitori naa, dajudaju mo maa ge awon owo yin ati ese yin ni ipasipayo. Dajudaju mo tun maa kan yin mo awon igi dabinu. Dajudaju eyin yoo mo ewo ninu wa ni iya (re) yoo le julo, ti o si maa pe julo
ﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧ
20:72
(Awon opidan) so pe: "Awa ko nii gbola fun o lori ohun ti o de ba wa ninu awon eri t’o daju, (a o si nii gbola fun o lori) Eni ti O seda wa. Nitori naa, da ohun ti o ba fe da lejo. Ile aye yii nikan ni o ti le dajo
ﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷ
20:73
Dajudaju awa gba Oluwa wa gbo nitori ki O le se aforijin awon ese wa fun wa ati ohun ti o je wa nipa se ninu idan pipa. Allahu loore julo, O si maa wa titi laelae
ﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅ
20:74
Dajudaju enikeni ti o ba wa ba Oluwa re ni (ipo) elese, dajudaju ina Jahanamo ti wa fun un. Ko nii ku sinu re, ko si nii wa laaye
ﰆﰇﰈﰉﰊﰋﰌﰍﰎﰏﰐ
20:75
Enikeni ti o ba si wa ba A (gege bi) onigbagbo ododo, ti o si ti se ise rere, awon wonyen ni awon ipo giga n be fun
ﰑﰒﰓﰔﰕﰖﰗﰘﰙﰚﰛﰜﰝﰞ
20:76
(Ohun ni) awon Ogba Idera gbere ti awon odo n san ni isale re. Olusegbere ni won ninu re. Iyen si ni esan fun enikeni ti o ba safomo (ise re)
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣ
20:77
Ati pe dajudaju A ti fi imisi ranse si (Anabi) Musa bayii pe: “Mu awon erusin Mi rin ni oru. Fi (opa re) na omi fun won (ki o di) oju ona gbigbe ninu omi okun. Ma se beru aleba, ma si se paya (iteri sinu omi okun).”
ﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬ
20:78
Fir‘aon si tele won pelu awon omo ogun re. Ohun ti o bo won mole daru ninu agbami odo si bo won mole daru
ﭭﭮﭯﭰﭱﭲ
20:79
Fir‘aon si awon eniyan re lona; oun (naa) ko si mona
ﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁ
20:80
Eyin omo ’Isro’il, dajudaju A ti gba yin la lowo ota yin. A si ba yin se adehun egbe otun apata. A si so ohun mimu monu ati ohun jije salwa kale fun yin
ﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔ
20:81
E je ninu awon nnkan daadaa ti A pa lese fun yin. E ma si koja enu ala ninu re nitori ki ibinu Mi ma baa ko le yin lori. Enikeni ti ibinu Mi ba si ko le lori, dajudaju o ti jabo (sinu iparun)
ﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞ
20:82
Dajudaju Emi ni Alaforijin fun enikeni ti o ba ronu piwada, ti o gbagbo ni ododo, ti o si se ise rere, leyin naa ti o tun tele imona
ﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥ
20:83
Ki ni o mu o kanju ya awon eniyan re sile, Musa
ﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯ
20:84
O so pe: “Awon niwonyi ti won n to oripa mi bo (leyin mi). Emi si kanju wa sodo Re nitori ki O le yonu si mi ni, Oluwa mi.”
ﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚ
20:85
(Allahu) so pe: "Dajudaju Awa ti dan ijo re wo leyin re. Ati pe Samiriy si won lona
ﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷ
20:86
(Anabi) Musa si pada sodo ijo re pelu ibinu ati ibanuje. O so pe: "Eyin ijo mi, se Oluwa yin ko ti ba yin se adehun daadaa ni? Se adehun ti pe ju loju yin ni tabi e fe ki ibinu ko le yin lori lati odo Oluwa yin ni e fi yapa adehun mi
ﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆﰇ
20:87
Won wi pe: “Awa ko finnufindo yapa adehun funra wa, sugbon won di eru oso awon eniyan (Misro) ru wa lorun. A si ju u sinu ina (pelu ase Samiriyy). Bayen naa si ni Samiriyy se ju tire.”
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝ
20:88
O si (fi mo) omo maalu oborogidi kan jade fun won, t’o n dun (bii maalu). Won si wi pe: "Eyi ni olohun yin ati olohun Musa. Amo o ti gbagbe (re)
ﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪ
20:89
Se won ko ri i pe ko le da esi oro kan pada fun won ni, ko si ni agbara lati ko inira tabi anfaani kan ba won
ﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼ
20:90
Ati pe dajudaju Harun ti so fun won siwaju pe: “Eyin ijo mi, won kan fi se adanwo fun yin ni. Dajudaju Oluwa yin ni Ajoke-aye. Nitori naa, e tele mi. Ki e si tele ase mi.”
ﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆ
20:91
Won wi pe: “A o nii ye duro sodo re titi (Anabi) Musa yoo fi pada sodo wa.”
ﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎ
20:92
(Anabi) Musa so pe: "Harun, ki ni o ko fun o nigba ti o ri won ti won sina
ﮏﮐﮑﮒﮓﮔ
20:93
lati to mi wa? Se o yapa ase mi ni
ﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨ
20:94
(Anabi Harun) so pe: “Omo iya mi, ma se fi irungbon mi tabi ori mi fa mi (mora). Dajudaju emi paya pe o maa so pe: O da opinya sile laaarin awon omo ’Isro’il. O o si so oro mi
ﮩﮪﮫﮬﮭ
20:95
(Anabi Musa) so pe: “Ki ni oro tire ti je, Samiriyy?”
ﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟ
20:96
(Samiriyy) wi pe: “Mo ri ohun ti won ko ri. Mo si bu ekunwo kan nibi (erupe) oju ese (esin) Ojise (iyen, molaika Jibril). Mo si da a sile (lati fi mo ere). Bayen ni emi mi se (aburu) ni oso fun mi.”
ﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿ
20:97
(Anabi Musa) so pe: “Nitori naa, maa lo. Dajudaju (ijiya) re nile aye yii ni ki o maa wi pe, “Ma fi ara kan mi”. Ati pe dajudaju ojo iya kan n be fun o ti Won ko nii gbe fo o. Ki o si wo olohun re, eyi ti o taku ti lorun, dajudaju a maa dana sun un. Leyin naa, dajudaju a maa ku eeru re danu patapata sinu agbami odo
ﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆﰇﰈﰉﰊﰋﰌﰍ
20:98
Olohun yin ni Allahu nikan, ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. O fi imo gbooro ju gbogbo nnkan
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟ
20:99
Bayen ni A se n so itan fun o ninu awon iro ti o ti siwaju. Lati odo Wa si ni A kuku ti fun o ni iranti (iyen, al-Ƙur’an)
ﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨ
20:100
Enikeni ti o ba gbunri kuro nibe, dajudaju o maa ru eru ese ni Ojo Ajinde
ﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱ
20:101
Olusegbere ni won ninu (iya) re. (Eru ese) si buru fun won lati ru ni Ojo Ajinde
ﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻ
20:102
Ni ojo ti won a fon fere oniwo fun ajinde. A si maa ko awon elese jo ni ojo yen, oju won yo si dudu batakun
ﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂ
20:103
Won yo si maa soro ni jeeje laaarin ara won pe: "Eyin ko gbe ile aye tayo (ojo) mewaa
ﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏ
20:104
Awa nimo julo nipa ohun ti won n wi nigba ti eni-abiyi julo ninu won wi pe: “E ko gbe ile aye tayo ojo kan.”
ﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗ
20:105
Won n bi o leere nipa awon apata. So pe: “Oluwa mi yoo ku won danu tan raurau
ﮘﮙﮚﮛ
20:106
Nigba naa, O maa fi won sile ni petele gbansasa
ﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢ
20:107
O o si nii ri ogbun tabi gelemo kan ninu re
ﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱ
20:108
Ni ojo yen, awon eniyan yoo tele olupepe naa, ko nii si yiya kuro leyin re. Awon ohun yo si palolo fun Ajoke-aye. Nitori naa, o o nii gbo ohun kan bi ko se girigiri ese
ﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟ
20:109
Ni ojo yen, isipe ko nii se anfaani afi eni ti Ajoke-aye ba yonda fun, ti O si yonu si oro fun un
ﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪ
20:110
(Allahu) mo ohun ti n be niwaju won ati ohun ti n be ni eyin won. Awon ko si fi imo rokiri ka Re
ﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶ
20:111
Awon oju yo si wole fun Alaaye, Alamojuuto-eda. Dajudaju enikeni ti o ba di abosi meru ti pofo
ﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂ
20:112
Enikeni ti o ba se ninu awon ise rere, ti o si je onigbagbo ododo, ki o ma se paya abosi tabi ireje kan (lati odo Allahu)
ﰃﰄﰅﰆﰇﰈﰉﰊﰋﰌﰍﰎﰏﰐﰑ
20:113
Bayen ni A se so (iranti) kale ni ohun kike pelu ede Larubawa. A si se alaye oniran-anran ileri sinu re nitori ki won le sora (fun iya) tabi nitori ki o le je iranti fun won
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤ
20:114
Nitori naa, Allahu Oba Ododo ga julo. Ma se kanju pelu al-Ƙur’an siwaju ki won to pari imisi re fun o. Ki o si so pe: “Oluwa mi, salekun imo fun mi.”
ﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰ
20:115
Dajudaju A se adehun fun (Anabi) Adam siwaju. Sugbon o gbagbe. A ko si ba a pelu ipinnu okan
ﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺ
20:116
Nigba ti A so fun awon molaika pe: “E fori kanle ki Adam. Won si fori kanle ki i afi ’Iblis, (ti) o ko.”
ﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇ
20:117
Nitori naa, A so pe: "Adam, dajudaju eyi ni ota fun iwo ati iyawo re. Nitori naa, ko gbodo mu eyin mejeeji jade kuro ninu Ogba Idera nitori ki o ma baa daamu (fun ije-imu)
ﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏ
20:118
Dajudaju ebi ko nii pa o, o o si nii rin hoho ninu re
ﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖ
20:119
Ati pe dajudaju ongbe ko nii gbe o ninu re, oorun ko si nii pa o
ﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤ
20:120
Sugbon Esu ko royiroyi ba a; o wi pe: “Adam, nje mo le juwe re si igi gbere ati ijoba ti ko nii tan?”
ﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖ
20:121
Nitori naa, awon mejeeji je ninu (eso) re. Ihoho awon mejeeji si han sira won; awon mejeeji si bere si da ewe Ogba Idera bo ara won. Adam yapa ase Oluwa re. O si sina
ﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝ
20:122
Leyin naa, Oluwa re sa a lesa; O gba ironupiwada re, O si to o si ona
ﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲ
20:123
(Allahu) so pe: "Eyin mejeeji, e jade kuro ninu re patapata. Apa kan yin si je ota si apa kan - eyin ati Esu. Nigba ti imona ba si de ba yin lati odo Mi, enikeni ti o ba tele imona Mi, ko nii sina, ko si nii daamu
ﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿ
20:124
Enikeni ti o ba si seri kuro nibi iranti Mi, dajudaju isemi inira maa wa fun un nile aye. A si maa gbe e dide ni afoju ni Ojo Ajinde.”
ﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆﰇﰈ
20:125
(O) maa wi pe: “Oluwa mi, nitori ki ni O fi gbe mi dide ni afoju? Mo ti je oluriran tele!”
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚ
20:126
(Allahu) so pe: "Bayen ni awon ayah Wa se de ba o, o si gbagbe re (o pa a ti). Ni oni, bayen ni won se maa gbagbe iwo naa (sinu Ina)
ﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨ
20:127
Ati pe bayen ni A se n san esan fun enikeni ti o ba se aseju, ti ko si gbagbo ninu awon ayah Oluwa re. Dajudaju iya Ojo Ikeyin le julo. O si maa wa titi laelae
ﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻ
20:128
Se ko han si won pe meloo meloo ninu awon iran ti A ti parun siwaju won, ti (awon wonyi naa) si n rin koja ni ibugbe won! Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun awon oloye
ﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅ
20:129
Ti ko ba je pe oro kan t’o siwaju ati gbedeke akoko kan lodo Oluwa re (iya ese won) iba ti di dandan
ﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛ
20:130
Nitori naa, se suuru lori ohun ti won n wi, ki o si se afomo pelu ope fun Oluwa Re siwaju yiyo oorun ati siwaju wiwo re. Se afomo (fun Allahu) ni awon asiko ale ati ni awon abala osan, ki o reti (esan) ti o maa yonu si
ﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯ
20:131
Ma se feju re si ohun ti A fi se igbadun t’o je ododo isemi ile aye fun awon iran-iran kan ninu won. (A fun won) nitori ki A le fi se adanwo fun won ni. Arisiki Oluwa re loore julo. O si maa wa titi laelae
ﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠ
20:132
Pa ara ile re lase irun kiki, ki o si se suuru lori re. A o nii beere ese kan lowo re; Awa l’A n pese fun o. Igbeyin rere si wa fun iberu (Allahu)
ﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯ
20:133
Won wi pe: “Nitori ki ni ko fi mu ami kan wa fun wa lati odo Oluwa re?” Se eri t’o yanju t’o wa ninu awon takada akoko ko de ba won ni
ﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃ
20:134
Ti o ba je pe dajudaju A ti fi iya kan pa won run siwaju re ni, won iba wi pe: "Oluwa wa nitori ki ni O o se ran Ojise kan si wa, awa iba tele awon ayah Re siwaju ki a to yepere, (ki a si to) kabuku
ﰄﰅﰆﰇﰈﰉﰊﰋﰌﰍﰎﰏﰐ
20:135
So pe: “Eni kookan ni olureti (ikangun).” Nitori naa, e maa reti (re). E maa mo ta ni ero ona taara ati eni t’o mona
Al-Kur'an
Wednesday, September 9, 2026
Don't forget us in your sincere prayers







