سورة الأنعام باليوربا
Gbogbo ope n je ti Allahu, Eni ti O da awon sanmo ati ile. O tun da okunkun ati imole. Sibesibe awon t’o sai gbagbo n ba Oluwa won wa akegbe |
Oun ni Eni ti O da yin lati inu erupe amo. Leyin naa, O fi gbedeke igba kan si (isemi aye yin). Ati pe gbedeke akoko kan (tun wa fun aye) lodo Re. Leyin naa, e tun n seyemeji |
Oun ni Allahu ninu awon sanmo ati ninu ile. O mo ikoko yin ati gbangba yin. O si mo ohun ti e n se nise |
وَمَا تَأْتِيهِم مِّنْ آيَةٍ مِّنْ آيَاتِ رَبِّهِمْ إِلَّا كَانُوا عَنْهَا مُعْرِضِينَ(4) Ko si ami kan ti o maa de ba won ninu awon ami Oluwa won, afi ki won maa gbunri kuro nibe |
Won kuku pe ododo niro nigba ti o de ba won. Nitori naa, laipe awon iro ohun ti won maa n fi se yeye n bo wa ba won |
Se won ko ri i pe meloo meloo ninu awon iran ti A ti pare siwaju won? Awon ti A fun ni ipo lori ile, (iru) ipo ti A ko fun eyin. A si ro omi ojo pupo fun won lati sanmo. A si se awon odo ti n san si isale (ile) won. Leyin naa, A pa won re nitori ese won. A si da awon iran miiran leyin won |
Ti o ba je pe A so tira kan ti A ko sinu takada kale fun o, ki won si fi owo won gba a mu (bayii), dajudaju awon t’o sai gbagbo iba wi pe: “Ki ni eyi bi ko se idan ponnbele.” |
Won si wi pe: “Nitori ki ni Won ko se so molaika kan kale fun un?” Ti o ba je pe A so molaika kan kale, oro iba ti yanju. Leyin naa, A o si nii lo won lara mo |
وَلَوْ جَعَلْنَاهُ مَلَكًا لَّجَعَلْنَاهُ رَجُلًا وَلَلَبَسْنَا عَلَيْهِم مَّا يَلْبِسُونَ(9) Ti o ba je pe A se e ni molaika ni, Awa iba se e ni okunrin. Ati pe Awa iba tun fi ohun ti won n daru mora won loju ru won loju |
Won kuku ti fi awon Ojise kan se yeye siwaju re! Nitori naa, ohun ti won n fi se yeye si diya t’o yi awon t’o n fi won se yeye po |
قُلْ سِيرُوا فِي الْأَرْضِ ثُمَّ انظُرُوا كَيْفَ كَانَ عَاقِبَةُ الْمُكَذِّبِينَ(11) So pe: “E rin ori ile lo, leyin naa ki e wo bawo ni atubotan awon t’o n pe ododo niro se ri.” |
So pe: “Ti ta ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ile?” So pe: “Ti Allahu ni.” O se aanu ni oran-anyan lera Re lori. Dajudaju O maa ko yin jo ni Ojo Ajinde, ko si iyemeji ninu re. Awon t’o se emi won lofo (sinu aigbagbo), won ko nii gbagbo |
۞ وَلَهُ مَا سَكَنَ فِي اللَّيْلِ وَالنَّهَارِ ۚ وَهُوَ السَّمِيعُ الْعَلِيمُ(13) TiRe ni ohunkohun t’o n be ninu oru ati osan. Oun si ni Olugbo, Onimo |
So pe: “Se ki ng mu oluranlowo kan yato si Allahu, Eledaa awon sanmo ati ile? Oun si ni O n bo (eda), won ki i bo O.” So pe: “Dajudaju Won pa mi lase pe ki ng je eni akoko ti o maa se ’Islam (ni asiko temi).” Iwo ko si gbodo wa ninu awon osebo. ofin Re ati ilana Re. Eyi ni awon kan mo si “sise ife-Olohun”. Ewo ninu awon Anabi Olohun ati Ojise Re ni ko juwo-juse sile patapata fun ase Allahu ofin Re ati ilana Re? Ewo ninu won se ni ko se ife-Olohun? Ko si. Idi niyi ti gbogbo won fi je musulumi gege bi Allahu (subhanahu wa ta’ala) se fi rinle ninu surah al-Baƙorah; 2:128-141. ofin Re ati ilana Re. Amo ninu ijo re oun ni eni akoko ti o koko se bee |
قُلْ إِنِّي أَخَافُ إِنْ عَصَيْتُ رَبِّي عَذَابَ يَوْمٍ عَظِيمٍ(15) So pe: “Dajudaju emi n paya iya Ojo Nla, ti mo ba fi le yapa Oluwa mi.” |
مَّن يُصْرَفْ عَنْهُ يَوْمَئِذٍ فَقَدْ رَحِمَهُ ۚ وَذَٰلِكَ الْفَوْزُ الْمُبِينُ(16) Enikeni ti A ba dari re kuro nibi (iya) ni Ojo yen, (Allahu) ti saanu re. Iyen si ni erenje ponnbele |
Ti Allahu ba fi inira kan kan o, ko si eni ti o le mu un kuro afi Oun naa. Ti O ba si mu oore kan ba o, Oun si ni Alagbara lori gbogbo nnkan |
وَهُوَ الْقَاهِرُ فَوْقَ عِبَادِهِ ۚ وَهُوَ الْحَكِيمُ الْخَبِيرُ(18) Oun si ni Olubori t’O wa loke awon eru Re. Oun ni Ologbon, Onimo-ikoko |
So pe: “Ki ni ohun ti o tobi julo ni eri?” So pe: “Allahu ni Elerii laaarin emi ati eyin.” O si fi imisi al-Ƙur’an yii ranse si mi, nitori ki ng le fi se ikilo fun eyin ati enikeni ti (al-Ƙur’an) ba de eti igbo re. Se dajudaju eyin n jerii pe awon olohun miiran tun wa pelu Allahu ni? So pe: “Emi ko nii jerii bee.” So pe: “Oun nikan ni Olohun Okan soso ti ijosin to si. Ati pe dajudaju emi yowo yose ninu ohun ti e n fi sebo (si Allahu).” |
Awon ti A fun ni Tira, won mo on gege bi won se mo awon omo won. Awon t’o se emi won lofo (sinu aigbagbo), won ko si nii gbagbo |
Ta l’o si sabosi ju eni ti o da adapa iro mo Allahu tabi (eni ti) o pe awon ayah Re niro? Dajudaju awon alabosi ko nii jere |
Ati pe (ranti) Ojo ti A oo ko gbogbo won jo patapata, leyin naa A oo so fun awon t’o ba (Allahu) wa akegbe pe: “Nibo ni awon orisa yin wa, awon ti e n so nipa won lai ni eri lowo pe won je akegbe Allahu?” |
ثُمَّ لَمْ تَكُن فِتْنَتُهُمْ إِلَّا أَن قَالُوا وَاللَّهِ رَبِّنَا مَا كُنَّا مُشْرِكِينَ(23) Leyin naa, ifooro won (lori ibeere naa) ko je kini kan tayo pe won a wi pe: “A fi Allahu, Oluwa wa bura, awa ki i se osebo.” |
انظُرْ كَيْفَ كَذَبُوا عَلَىٰ أَنفُسِهِمْ ۚ وَضَلَّ عَنْهُم مَّا كَانُوا يَفْتَرُونَ(24) Wo bi won se paro mora won. Ohun ti won n da ni adapa iro si dofo mo won lowo |
Eni ti n gbo oro ni odo re n be ninu won. A si fi ebibo bo okan won ki won ma baa gbo agboye re. (A tun fi) edidi sinu eti won. Ti won ba ri gbogbo ami, won ko nii gba a gbo debi pe nigba ti won ba wa ba o, won yo si maa ba o jiyan; awon t’o sai gbagbo si maa wi pe: “Ki ni eyi bi ko se akosile alo awon eni akoko.” |
Awon ni won n ko (fun awon eniyan lati tele Anabi s.a.w.), awon naa si n takete si i. Won ko si ko iparun ba enikeni bi ko se emi ara won; won ko si fura |
Ti o ba je pe o ri (won ni) nigba ti A ba da won duro sibi Ina, won si maa wi pe: “Yee! Ki won si da wa pada (sile aye), awa ko si nii pe awon ayah Oluwa wa niro (mo), a si maa wa ninu awon onigbagbo ododo.” |
Ko ri bee, ohun ti won n fi pamo siwaju ti han si won ni. Ti o ba je pe A ba da won pada (sile aye), won yoo kuku pada sibi ohun ti A ko fun won. Dajudaju opuro ma ni won |
وَقَالُوا إِنْ هِيَ إِلَّا حَيَاتُنَا الدُّنْيَا وَمَا نَحْنُ بِمَبْعُوثِينَ(29) Won wi pe: "Ki ni (o tun je isemi orun) bi ko se isemi wa nile aye; Won ko si nii gbe wa dide (ni orun) |
Ti o ba je pe o ri (won ni) nigba ti won ba da won duro si odo Oluwa won, O si maa so pe: “Se eyi ki i se ododo bi?” Won a si wi pe: “Rara (ododo ni), Oluwa wa.” (Allahu) so pe: “Nitori naa, e to Iya wo nitori pe e maa n sai gbagbo.” |
Dajudaju awon t’o pe pipade Allahu (lorun) niro ti sofo debi pe nigba ti Akoko naa ba de ba won lojiji, won a wi pe: “A ka abamo lori ohun ti a fi jafira.” Won si maa ru ese won seyin won. Kiye si i, ohun ti won yoo ru lese si buru |
Isemi aye ko si je kini kan bi ko se ere ati iranu. Ogba Ikeyin si loore julo fun awon t’o n beru (Allahu). Se e o se laakaye ni |
A kuku ti mo pe ohun ti won n wi yoo ba o ninu je. Dajudaju won ko le pe o ni opuro, sugbon awon alabosi n tako awon ayah Allahu ni |
Won kuku ti pe awon Ojise kan lopuro siwaju re. Won si se suuru lori nnkan ti won fi pe won ni opuro. Won si fi inira kan won titi di igba ti aranse Wa fi de ba won. Ko si si alayiipada kan fun awon oro Allahu. Dajudaju iro awon Ojise ti de ba o |
Ti o ba si je pe gbigbunri won lagbara lara re, nigba naa ti o ba lagbara lati wa iho kan sinu (aja) ile, tabi akaba kan sinu sanmo (se bee) ki o le mu ami kan wa fun won. Ati pe ti o ba je pe Allahu ba fe, dajudaju iba ko won jo sinu imona (’Islam). Nitori naa, o o gbodo wa lara awon alaimokan |
Awon t’o n gboro ni awon t’o n jepe. Awon oku, Allahu yo si gbe won dide. Leyin naa, odo Re ni won yoo da won pada si |
Won tun wi pe: “Nitori ki ni Won ko se so ami kan kale fun un lati odo Oluwa re?” So pe: “Dajudaju Allahu lagbara lati so ami kan kale, sugbon opolopo won ni ko mo.” |
Ko si ohun abemi kan (t’o n rin) lori ile, tabi eye kan t’o n fo pelu apa re mejeeji bi ko se awon eda kan (bi) iru yin. A ko fi kini kan sile (lai sakosile re) sinu Tira (iyen, ummul-kitab). Leyin naa, odo Oluwa won ni won yoo ko won jo si |
Awon t’o pe awon ayah Wa niro, aditi ati ayaya t’o wa ninu awon okunkun ni won. Enikeni ti Allahu ba fe, O maa si i lona. Enikeni ti O ba si fe, O maa fi soju ona taara (’Islam) |
So pe: "E so fun mi, ti iya Allahu ba de ba yin tabi ti Akoko naa ba de ba yin, se nnkan miiran leyin Allahu ni eyin maa pe, ti e ba je olododo |
بَلْ إِيَّاهُ تَدْعُونَ فَيَكْشِفُ مَا تَدْعُونَ إِلَيْهِ إِن شَاءَ وَتَنسَوْنَ مَا تُشْرِكُونَ(41) Rara, Oun (nikan) l’e n pe. O si maa mu (inira) ti e n pe E si kuro (fun yin), ti O ba fe. Eyin yo si gbagbe ohun ti e n fi sebo si I |
Dajudaju A ti ranse si awon ijo kan siwaju re. A si fi iponju ati ailera gba won mu nitori ki won le rawo rase (si Allahu) |
Won ko se rawo rase (si Wa) nigba ti iya Wa de ba won! Sugbon okan won ti le koko. Esu si se ohun ti won n se nise ni oso fun won |
Nitori naa, nigba ti won gbagbe ohun ti A fi se iranti fun won, A si awon ona gbogbo nnkan sile fun won, titi di igba ti won yo ayoporo si ohun ti A fun won (ninu oore aye.), A si mu won lojiji. Won si di olusoretinu |
فَقُطِعَ دَابِرُ الْقَوْمِ الَّذِينَ ظَلَمُوا ۚ وَالْحَمْدُ لِلَّهِ رَبِّ الْعَالَمِينَ(45) Nitori naa, A pa ijo t’o sabosi run patapata. Gbogbo ope si n je ti Allahu, Oluwa gbogbo eda |
So pe: " E so fun mi, ti Allahu ba gba igboro yin ati iriran yin, ti O si di okan yin pa, olohun wo leyin Allahu ni o maa mu un wa fun yin? Wo bi A se n mu awon ayah wa loniran-anran ona. Leyin naa, won si n gbunri |
So pe: “E so fun mi, ti iya Allahu ba de ba yin ni ojiji tabi ni ojukoju, se won maa pa eni kan run bi ko se ijo alabosi!” |
A ko ran awon Ojise naa nise bi ko se pe (ki won je) oniroo idunnu ati olukilo. Nitori naa, enikeni ti o ba gbagbo ni ododo, ti o si se atunse (ise re), ko nii si iberu fun won, won ko si nii banuje |
وَالَّذِينَ كَذَّبُوا بِآيَاتِنَا يَمَسُّهُمُ الْعَذَابُ بِمَا كَانُوا يَفْسُقُونَ(49) Awon t’o si pe awon ayah Wa niro, owo iya yoo te won nitori pe won maa n sebaje |
So pe: “Emi ko so fun yin pe awon ile-owo Allahu wa lodo mi, emi ko si nimo ikoko. Emi ko si so fun yin pe molaika kan ni mi. Emi ko tele kini kan ayafi ohun ti Won fi ranse si mi ni imisi.” So pe: "Nje afoju ati oluriran dogba bi? Se e o ronu jinle ni |
Fi (al-Ƙur’an) se ikilo fun awon t’o n paya pe Won maa ko awon jo si odo Oluwa won, ko si nii si alaabo tabi olusipe kan fun won leyin Re. (Kilo fun won) ki won le beru (Allahu) |
Ma se le awon t’o n pe Oluwa won ni owuro ati ni asale danu; won n fe Oju rere Re ni. Isiro-ise won ko si ni orun re ni ona kan kan. Ko si si isiro-ise tire naa ni orun won ni ona kan kan. Ti o ba le won danu, o si maa wa ninu awon alabosi |
Bayen ni A se fi apa kan won se adanwo fun apa kan nitori ki (awon alaigbagbo) le wi pe: “Se awon (musulumi alaini) wonyi naa ni Allahu se idera (imona) fun laaarin wa!?” Se Allahu ko l’O nimo julo nipa awon oludupe ni |
Nigba ti awon t’o gba awon ayah Wa gbo ba wa ba o, so (fun won) pe: "Ki alaafia maa ba yin. Oluwa yin se aanu ni oran-anyan lera Re lori pe, dajudaju enikeni ninu yin ti o ba se ise aburu pelu aimokan, leyin naa, ti o ronu piwada leyin re, ti o si se atunse, dajudaju Oun ni Alaforijin, Asake-orun |
وَكَذَٰلِكَ نُفَصِّلُ الْآيَاتِ وَلِتَسْتَبِينَ سَبِيلُ الْمُجْرِمِينَ(55) Bayen ni A se n salaye awon ayah nitori ki ona awon elese le foju han kedere |
So pe: “Dajudaju Won ko fun mi lati josin fun awon ti e n pe leyin Allahu.” So pe: “Emi ko nii tele ife-inu yin. Bi bee ko nigba naa, mo ti sina (ti mo ba tele ife-inu yin). Emi ko si si ninu awon olumona.” |
So pe: “Dajudaju mo wa lori eri t’o yanju lati odo Oluwa mi, eyin si pe e niro. Ko si ohun ti e n wa pelu ikanju ni odo mi. Ko si idajo naa (fun enikeni) ayafi fun Allahu, Eni ti n so (idajo) ododo. O si loore julo ninu awon oludajo.” |
So pe: “Ti o ba je pe dajudaju ohun ti e n wa pelu ikanju n be ni odo mi ni, Won iba ti se idajo oro naa laaarin emi ati eyin. Allahu si nimo julo nipa awon alabosi.” |
Odo Re si ni awon kokoro ikoko wa. Ko si eni t’o nimo re afi Oun. O nimo ohun ti n be ninu ile ati odo. Ewe kan ko si nii ja bo afi ki O nimo re. Ko si si koro eso kan ninu okunkun (inu) ile, ko si ohun tutu tabi gbigbe kan afi ki o wa ninu akosile t’o yanju |
Oun ni Eni t’O n kun yin ni oorun ni ale. O si nimo nipa ohun ti e se nise ni osan. Leyin naa, O n gbe yin dide (fun ije-imu) ni (osan) nitori ki won le pari gbedeke akoko kan. Leyin naa, odo Re ni ibupadasi yin. Leyin naa, O maa fun yin ni iro ohun ti e n se nise |
Oun ni Olubori t’O wa loke awon eru Re. O si n ran awon eso kan si yin titi di igba ti iku yoo fi de ba eni kookan yin. Awon Ojise wa yo si gba emi re, won ko si nii jafira |
Leyin naa, won yoo da won pada si odo Allahu, Oluwa won, Ododo. Kiye si i, tiRe ni idajo. Oun si yara julo ninu awon olusiro |
So pe: “Ta ni eni t’o n gba yin la ninu okunkun ile ati ibudo, Eni ti e n pe pelu iraworase ati ni ikoko pe: "Dajudaju ti O ba gba wa la ninu eyi, dajudaju awa yoo wa ninu awon oludupe (fun Un) |
قُلِ اللَّهُ يُنَجِّيكُم مِّنْهَا وَمِن كُلِّ كَرْبٍ ثُمَّ أَنتُمْ تُشْرِكُونَ(64) So pe: “Allahu l’O n gba yin la ninu re ati ninu gbogbo ibanuje. Leyin naa, e tun n sebo.” |
So pe: “O lagbara lati fi iya ranse si yin lati oke yin tabi lati isale ese yin, tabi ki O da yin po mo oniruuru ijo, nitori ki O le mu apa kan yin finira kan apa kan. Wo bi A se n mu awon ayah wa loniran-anran ona nitori ki won le gbo agboye.” |
وَكَذَّبَ بِهِ قَوْمُكَ وَهُوَ الْحَقُّ ۚ قُل لَّسْتُ عَلَيْكُم بِوَكِيلٍ(66) Awon eniyan re pe al-Ƙur’an niro! (Amo) ododo ni. So pe: “Emi ki i se oluso lori yin.” |
Gbogbo asotele l’o ni akoko (isele). Laipe e maa mo |
Nigba ti o ba ri awon t’o n so isokuso nipa awon ayah Wa, nigba naa seri kuro ni odo won titi won yoo fi bo sinu oro miiran. Ti Esu ba n mu o gbagbe (tele), ni bayii leyin iranti ma se jokoo ti ijo alabosi |
Kini kan ninu isiro-ise won ko si lorun awon t’o n beru (Allahu), sugbon isiti ni nitori ki won le sora (fun Ina) |
Pa awon t’o so esin won di ere sise ati iranu ti. Isemi aye si tan won je. Fi (al-Ƙur’an) se isiti nitori ki won ma baa fa emi kale sinu iparun nipase ohun ti o se nise (aburu). Ko si si alaabo tabi olusipe kan fun un leyin Allahu. Ti o ba si fi gbogbo aaro serapada, A o nii gba a lowo re. Awon wonyen ni awon ti won fa kale fun iparun nipase ohun ti won se nise. Ohun mimu gbigbona ati iya eleta elero n be fun won nitori pe won maa n sai gbagbo |
So pe: “Se a oo maa pe leyin Allahu, ohun ti ko le se wa ni anfaani, ti ko si le ko inira ba wa; (se) ki won tun da wa pada si ese-aaro wa leyin igba ti Allahu ti fi ona mo wa (ki a le da) bi eni ti Esu mu tele ife-inu re lori ile aye, ti idaamu de ba? O (si) ni awon ore kan ti won n pe e sibi imona (pe), “Maa bo ni odo wa.” So pe: “Dajudaju imona ti Allahu (’Islam), ohun ni imona. Won si pa wa lase pe ki a gba esin ’Islam nitori ti Oluwa gbogbo eda.” |
وَأَنْ أَقِيمُوا الصَّلَاةَ وَاتَّقُوهُ ۚ وَهُوَ الَّذِي إِلَيْهِ تُحْشَرُونَ(72) Ati pe ki e kirun, ki e si beru Allahu. Oun ni Eni ti won yoo ko yin jo si odo Re |
Oun si ni Eni ti O seda awon sanmo ati ile pelu ododo. Ati pe (ranti) ojo ti (Allahu maa yi ile ati sanmo pada si nnkan miiran), O si maa so pe: "Je bee." O si maa je bee. Ododo ni oro Re. TiRe si ni ijoba ni ojo ti won a fon fere oniwo fun ajinde. Onimo-ikoko ati gbangba ni. Oun si ni Ologbon, Alamotan |
(Ranti) nigba ti ’Ibrohim so fun baba re, Azar, (pe): “Se o maa so awon ere orisa di olohun ni? Dajudaju emi ri iwo ati awon eniyan re ninu isina ponnbele.” |
وَكَذَٰلِكَ نُرِي إِبْرَاهِيمَ مَلَكُوتَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَلِيَكُونَ مِنَ الْمُوقِنِينَ(75) Bayen ni won se fi (awon ami) ijoba Allahu ti n be ninu awon sanmo ati ile han (Anabi) ’Ibrohim nitori ki o le wa ninu awon alamodaju |
Nigba ti okunkun ale bo o mole, o ri irawo kan, o so pe: “Eyi ni oluwa mi.” Nigba ti o wo, o so pe: “Emi ko nifee si awon (oluwa) t’o n wookun.” |
Nigba ti o ri osupa t’o yo, o so pe: “Eyi ni oluwa mi.” Nigba ti o wo, o so pe: “Dajudaju ti Oluwa mi ko ba to mi sona, dajudaju mo maa wa ninu awon olusina eniyan.” |
Nigba ti o ri oorun t’o yo, o so pe: “Eyi ni oluwa mi; eyi tobi julo.” Nigba t’o wo, o so pe: “Eyin eniyan mi, dajudaju emi yowo yose ninu ohun ti e n fi sebo (si Allahu) |
Dajudaju emi doju mi ko Eni ti O pile iseda awon sanmo ati ile, (mo) duro deede (sinu ’Islam fun Un). Emi ko si si ninu awon osebo.” |
Awon eniyan re si ja a niyan. O so pe: "Se eyin yoo ja mi niyan nipa Allahu, O si ti fi ona mo mi? Emi ko si paya (awon orisa) ti e so di akegbe fun Un, afi bi Allahu ba fe kini kan (pe ko sele). Oluwa mi fi imo gbooro ju gbogbo nnkan. Nitori naa, se e o nii lo iranti ni |
Bawo ni emi yoo se paya (awon orisa) ti e so di akegbe fun Allahu, ti eyin ko si paya pe e n ba Allahu wa akegbe pelu ohun ti ko so eri kan kale fun yin lori re? Ewo ninu iko mejeeji l’o letoo julo si ifokanbale ti e ba nimo |
Awon t’o gbagbo ni ododo, ti won ko si da igbagbo won po mo abosi (iborisa), awon wonyen ni ifokanbale n be fun. Awon si ni olumona |
Iyen ni awijare Wa ti A fun (Anabi) ’Ibrohim lori awon eniyan re. A n se agbega ipo fun eni ti A ba fe. Dajudaju Oluwa re ni Ologbon, Onimo |
Ati pe A ta a lore (Anabi) ’Ishaƙ ati Ya‘ƙub (ti o je omo ’Ishaƙ). Ikookan won ni A fi mona. A si fi (Anabi) Nuh mona siwaju. Ati pe ninu aromodomo (Anabi ’Ibrohim ti A fi mona ni awon Anabi) Dawud, Sulaemon, ’Ayyub, Yusuf, Musa ati Harun. Bayen ni A se n san awon oluse-rere ni esan (rere) |
وَزَكَرِيَّا وَيَحْيَىٰ وَعِيسَىٰ وَإِلْيَاسَ ۖ كُلٌّ مِّنَ الصَّالِحِينَ(85) Ati (Anabi) Zakariyya, Yahya, ‘Isa ati ’Ilyas; gbogbo won wa ninu awon eni rere |
وَإِسْمَاعِيلَ وَالْيَسَعَ وَيُونُسَ وَلُوطًا ۚ وَكُلًّا فَضَّلْنَا عَلَى الْعَالَمِينَ(86) Ati ’Ismo‘il, al-Yasa‘, Yunus ati Lut; ikookan won ni A soore ajulo fun lori awon eda (asiko won) |
Ati pe ninu awon baba won, aromodomo won ati awon arakunrin won, A sa won lesa. A si fi won mona taara (’Islam) |
Iyen ni imona Allahu. O si n fi to eni ti O ba fe si ona ninu awon eru Re. Ti won ba fi le sebo ni, dajudaju ohun ti won n se nise (rere) iba baje mo won lowo |
Awon wonyen ni awon ti A fun ni Tira, ijinle oye (iyen, sunnah) ati (ipo) Anabi. Nitori naa, ti awon wonyi ba sai gbagbo ninu re, dajudaju A ti gbe e le awon eniyan kan lowo, ti won ko nii sai gbagbo ninu re |
Awon wonyen ni awon ti Allahu to si ona. Nitori naa, ona won ni ki o tele. So pe: “Emi ko bi yin ni owo-oya kan lori re. Ki si ni al-Ƙur’an bi ko se iranti fun gbogbo eda.” |
Won ko fun Allahu ni iyi ti o to si I, nigba ti won wi pe: “Allahu ko so nnkan kan kale fun abara kan.” So pe: "Ta ni O so tira ti (Anabi) Musa mu wa kale, (eyi t’o je) imole ati imona fun awon eniyan, eyi ti e sakosile re sinu iwe ajako, ti e n se afihan re, ti e si n fi opolopo re pamo, A si fi ohun ti e o mo mo yin, eyin ati awon baba yin?" So pe: "Allahu ni." Leyin naa, fi won sile sinu isokuso won, ki won maa sere |
Eyi (al-Ƙur’an) tun ni Tira ibukun ti A sokale; o n jerii si eyi t’o je ododo ninu eyi t’o siwaju re ati pe nitori ki o le se ikilo fun ’Ummul-Ƙuro (iyen, ara ilu Mokkah) ati enikeni ti o ba wa ni ayika re (iyen, ara ilu yooku). Awon t’o gbagbo ninu Ojo Ikeyin, won gbagbo ninu re. Awon si ni won n so irun won |
Ta l’o sabosi ju eni ti o da adapa iro mo Allahu tabi eni ti o wi pe won fi imisi ranse si mi - A o si fi kini kan ranse si i - ati eni ti o wi pe "Emi naa yoo so iru ohun ti Allahu sokale kale."? Ti o ba je pe iwo ri i nigba ti awon alabosi ba wa ninu ipokaka iku, ti awon molaika nawo won (si won pe) “E mu emi yin jade wa. Lonii ni Won yoo san yin ni esan abuku iya nitori ohun ti e maa n so nipa Allahu ni aito. E si maa n se igberaga si awon ayah Re.” |
Dajudaju e ti wa ba wa ni ikookan gege bi A se seda yin nigba akoko. E si ti fi ohun ti A fun yin sile si eyin yin. A o ma ri awon olusipe yin pelu yin, awon ti e so lai ni eri pe dajudaju laaarin yin awon ni akegbe (fun Allahu). Dajudaju asepo aarin yin ti ja patapata. Ati pe ohun ti e n so nipa won (lai ni eri lowo lori isipe yin) ti dofo mo yin lowo |
Dajudaju Allahu l’O n mu koro eso irugbin ati koro eso dabinu hu jade. O n mu alaaye jade lati ara oku. O si n mu oku jade lati ara alaaye. Iyen ni Allahu. Nitori naa, bawo ni won se n se yin lori kuro nibi ododo |
O n mu ojumo mo. O se oru ni isinmi. (O n mu) oorun ati osupa (rin) fun isiro (ojo aye). Iyen ni eto Alagbara, Onimo |
Oun ni Eni ti O fi awon irawo se (imole) fun yin ki e le fi riran ninu okunkun ile ati ibudo. A kuku ti salaye awon ayah fun awon eniyan t’o nimo |
Oun ni Eni ti O seda yin lati ara emi eyo kan. Nitori naa, ibugbe (nile aye) ati ibupadasi (ni orun wa fun yin). A kuku ti salaye awon ayah fun awon eniyan t’o ni agboye |
Oun ni Eni t’O n so omi kale lati sanmo. A fi mu gbogbo nnkan ogbin jade. A tun mu eweko t’o n dan logbologbo jade lati inu re. A tun n mu siri eso jade ninu re. (A si n mu jade) lati ara igi dabinu, lati ara eso akoyo re, eso t’o sujo mora won t’o ro dede wale. (A n se) awon ogba oko eso ajara, eso zaetun ati eso rummon (ni awon eso t’o) jora ati (awon eyi ti) ko jora. E wo eso re nigba ti o ba so ati (nigba ti o ba) pon. Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun ijo onigbagbo ododo |
Won si fi awon alujannu se akegbe fun Allahu. Oun si l’O sedaa won! Won tun paro mo On (pe) O bi omokunrin ati omobinrin, lai nimo kan (nipa Re). Mimo ni fun Un. O si ga tayo ohun ti won n fi royin (Re) |
Olupileda awon sanmo ati ile ni. Bawo ni O se ni omo nigba ti ko ni aya. O da gbogbo nnkan. Oun si ni Onimo nipa gbogbo nnkan |
Iyen ni Allahu, Oluwa yin; ko si olohun kan ti ijosin to si afi Oun, Eledaa gbogbo nnkan. Nitori naa, e josin fun Un. Oun si ni Oluso lori gbogbo nnkan |
لَّا تُدْرِكُهُ الْأَبْصَارُ وَهُوَ يُدْرِكُ الْأَبْصَارَ ۖ وَهُوَ اللَّطِيفُ الْخَبِيرُ(103) Awon oju (eda) ko le ka Allahu. Oun si ka awon oju. Oun si ni Alaaanu, Alamotan |
Awon eri t’o daju kuku ti de ba yin lati odo Oluwa yin. Nitori naa, enikeni t’o ba riran, fun emi ara re ni. Enikeni t’o ba si foju, fun emi ara re ni. Emi ki i se oluso lori yin |
وَكَذَٰلِكَ نُصَرِّفُ الْآيَاتِ وَلِيَقُولُوا دَرَسْتَ وَلِنُبَيِّنَهُ لِقَوْمٍ يَعْلَمُونَ(105) Bayen ni A se n mu awon ayah wa loniran-anran ona nitori ki won le wi pe: "O kekoo (re lodo awon eniyan ni." Dipo ki won wi pe: "Won so o kale fun o ni." ati nitori ki A le se alaye re fun awon eniyan t’o nimo) |
Tele ohun ti won fi ran o ni imisi lati odo Oluwa re. Ko si eni ti ijosin to si afi Oun. Ki o si seri kuro ni odo awon osebo |
Ti o ba je pe Allahu ba fe (imona fun won), won iba ti sebo. A o si fi o se oluso lori won. Ati pe iwo ko ni alamojuuto won |
E ma se bu awon (orisa) ti won n pe leyin Allahu, ki awon (aborisa) ma baa bu Allahu ni ti abosi ati ainimo. Bayen ni A ti se ise ijo kookan ni oso fun won. Leyin naa, odo Oluwa won ni ibupadasi won. Nitori naa, O maa fun won ni iro ohun ti won maa n se nise |
Won si fi Allahu bura ti ibura won si lagbara gan-an pe, dajudaju ti ami (iyanu) kan ba de ba awon, awon gbodo gba a gbo. So pe: "Odo Allahu nikan ni awon ami (iyanu) wa." Ki si ni o maa mu yin fura mo pe dajudaju nigba ti o ba de (ba won) won maa gba a gbo |
A maa yi okan won ati oju won sodi ni; (won ko nii gba a gbo) gege bi won ko se gbagbo ninu (eyi t’o siwaju ninu awon ami iyanu) nigba akoko. A o si fi won sile sinu agbere won, ti won yoo maa pa ridarida |
Dajudaju ti A ba so awon molaika kale fun won, ti awon oku n ba won soro, ti A tun ko gbogbo nnkan jo siwaju won, won ko nii gbagbo afi ti Allahu ba fe. Sugbon opolopo won ni alaimokan |
Bayen ni A ti se awon esu eniyan ati esu alujannu ni ota fun Anabi kookan; apa kan won n fi odu iro ranse si apa kan ni ti etan. Ti o ba je pe Oluwa re ba fe (lati to won sona ni) won iba ti se bee. Nitori naa, fi won sile tohun ti adapa iro ti won n da |
Ki awon okan ti won ko gba Ojo Ikeyin gbo maa teti beleje si (odu iro Esu), ki won maa yonu si i, ki won si maa da ohun ti won n da lese n so |
Se nnkan miiran ni ki ng wa ni oludajo leyin Allahu ni? Oun si ni Eni ti O so Tira kale fun yin ti won fi salaye idajo. Awon ti A si fun ni tira mo pe, dajudaju won so o kale pelu ododo lati odo Oluwa re. Nitori naa, o o gbodo wa lara awon oniyemeji |
Oro Oluwa re pe ni ododo ati ni deede. Ko si alayiipada kan fun awon oro Re. Oun si ni Olugbo, Onimo |
Ti o ba tele opolopo awon ti n be lori ile, won maa si o lona kuro loju ona (esin) Allahu. Won ko tele kini kan bi ko se aroso. Ki si ni won (n se) bi ko se pe won n paro |
إِنَّ رَبَّكَ هُوَ أَعْلَمُ مَن يَضِلُّ عَن سَبِيلِهِ ۖ وَهُوَ أَعْلَمُ بِالْمُهْتَدِينَ(117) Dajudaju Oluwa re, Oun l’O nimo julo nipa eni t’o sina loju ona (esin) Re. Ati pe, Oun si l’O nimo julo nipa awon olumona |
فَكُلُوا مِمَّا ذُكِرَ اسْمُ اللَّهِ عَلَيْهِ إِن كُنتُم بِآيَاتِهِ مُؤْمِنِينَ(118) Nitori naa, e je ninu ohun ti won ba fi oruko Allahu pa, ti e ba gbagbo ninu awon ayah Re |
Ki ni o maa ko fun yin lati je ninu ohun ti won fi oruko Allahu pa! O kuku ti salaye fun yin ohun ti O se ni eewo fun yin ayafi eyi ti inira (ebi) ba ti yin debe. Dajudaju opolopo ni won n fi ife-inu won pelu ainimo (won) si awon eniyan lona. Dajudaju Oluwa re, O nimo julo nipa awon olutayo enu-ala |
E fi eyi t’o han ninu ese ati eyi t’o pamo ninu re sile. Dajudaju awon t’o n se ise ese, A oo san won ni esan ohun ti won n da lese |
Eyin ko si gbodo je ninu ohun ti won ko fi oruko Allahu pa. Dajudaju ibaje ni. Ati pe dajudaju awon esu, won yoo maa fi irande odu iro ranse si awon eni won, nitori ki won le tako yin. Ti e ba fi le tele won, dajudaju e ti di osebo |
Nje eni ti (afiwe re) je oku (iyen, alaigbagbo), ti A so di alaaye (nipa pe o gba ’Islam), ti A si fun un ni imole (iyen, imo esin), ti o si n lo o laaarin awon eniyan, (nje) o da bi eni ti afiwe tire je (eni ti) n be ninu awon okunkun (aigbagbo), ti ko si jade kuro ninu re? Bayen ni won ti se ni oso fun awon alaigbagbo ohun ti won n se nise |
Bayen ni A se so awon agba kan di odaran ilu ninu ilu kookan, nitori ki won le maa dete nibe. Won ko si dete si enikeni bi ko se si ara won, won ko si fura |
Nigba ti ayah kan ba si de ba won, won a wi pe: “Awa ko nii gba a gbo titi di igba ti won ba to fun awa naa ni iru ohun ti won fun awon Ojise Allahu.” Allahu nimo julo nipa ibi ti O n fi ise-riran Re si. Laipe iyepere ati iya lile lati odo Allahu yoo de ba awon t’o dese nitori ohun ti won n da lete |
Enikeni ti Allahu ba fe fona mo, O maa si igba-aya re paya fun ’Islam. Enikeni ti O ba si fe si lona, O maa fun igba-aya re pa gadigadi bi eni pe o n gunke lo sinu sanmo. Bayen ni Allahu se de wahala asan si awon ti ko gbagbo |
وَهَٰذَا صِرَاطُ رَبِّكَ مُسْتَقِيمًا ۗ قَدْ فَصَّلْنَا الْآيَاتِ لِقَوْمٍ يَذَّكَّرُونَ(126) Eyi ni oju ona Oluwa re (t’o je) ona taara. A kuku ti salaye awon ayah fun ijo t’o n lo iranti |
۞ لَهُمْ دَارُ السَّلَامِ عِندَ رَبِّهِمْ ۖ وَهُوَ وَلِيُّهُم بِمَا كَانُوا يَعْمَلُونَ(127) Ile alaafia n be fun won ni odo Oluwa won. Oun si ni Alatileyin won nipa ohun ti won n se nise |
(Ranti) Ojo ti (Allahu) yoo ko gbogbo won jo patapata, (O maa so pe): “Eyin awujo alujannu, dajudaju e ti ko opolopo eniyan sonu.” Awon ore won ninu awon eniyan yoo wi pe: “Oluwa wa, apa kan wa gbadun apa kan ni. A si ti lo asiko wa ti O bu fun wa (lati lo).” (Allahu) so pe: “Ina ni ibugbe yin; olusegbere ni yin ninu re afi ohun ti Allahu ba fe . Dajudaju Oluwa re ni Ologbon, Onimo |
وَكَذَٰلِكَ نُوَلِّي بَعْضَ الظَّالِمِينَ بَعْضًا بِمَا كَانُوا يَكْسِبُونَ(129) Bayen ni A se fi apa kan awon alabosi sore apa kan (won) nitori ohun ti won n se nise |
Eyin awujo alujannu ati eniyan, se awon Ojise kan laaarin yin ko wa ba yin, ti won n ke awon ayah Mi fun yin, ti won si n fi ipade yin Oni yii sekilo fun yin? Won wi pe: “A jerii lera wa lori (pe won wa).” Isemi aye tan won je. Won si jerii lera won lori pe dajudaju awon je alaigbagbo |
ذَٰلِكَ أَن لَّمْ يَكُن رَّبُّكَ مُهْلِكَ الْقُرَىٰ بِظُلْمٍ وَأَهْلُهَا غَافِلُونَ(131) Iyen nitori pe Oluwa re ko nii pa awon ilu run nipase abosi (owo won), lasiko ti awon ara ilu naa je alaimo (titi Ojise yoo fi de ba won) |
وَلِكُلٍّ دَرَجَاتٌ مِّمَّا عَمِلُوا ۚ وَمَا رَبُّكَ بِغَافِلٍ عَمَّا يَعْمَلُونَ(132) Awon ipo (ike ati ipo iya) n be fun enikookan nipase ohun ti won ba se nise. Oluwa re ki i se onigbagbe nipa nnkan ti won n se nise |
Oluwa re ni Oloro, Alaaanu. Ti O ba fe, O maa ko yin kuro (lori ile). O si maa fi ohun ti O ba fe ropo (yin) leyin (iparun) yin gege bi O ti se mu yin jade leyin (iparun) aromodomo awon ijo miiran |
إِنَّ مَا تُوعَدُونَ لَآتٍ ۖ وَمَا أَنتُم بِمُعْجِزِينَ(134) Dajudaju ohun ti A n se ni adehun fun yin, o kuku n bo wa sele; eyin ko si nii mori bo |
So pe: “Eyin eniyan mi, e duro sori ona yin, dajudaju emi naa yoo duro (sori ona mi), laipe e maa mo eni ti Ogba (Idera) yoo je ikangun tire. Dajudaju awon alabosi ko nii jere.” |
Won si fi ipin kan fun Allahu ninu ohun ti O da ninu nnkan oko ati eran-osin; won wi pe: "Eyi ni ti Allahu – pelu oro won lai ni eri lowo, - eyi si ni ti awon orisa wa." Nitori naa, ohun ti o ba je ti awon orisa ko nii dapo mo ti Allahu. Ohun ti o ba si je ti Allahu, o n dapo mo ti awon orisa won; ohun ti won n da lejo buru |
Bayen ni awon orisa won se pipa awon omo won ni oso fun opolopo ninu awon osebo nitori ki won le pa won run ati nitori ki won le d’oju esin won ru mo won lowo. Ti o ba je pe Allahu ba fe, won iba ti se (bee). Nitori naa, fi won sile tohun ti ohun ti won n da ni adapa iro |
Won tun wi pe: "Eewo ni awon eran-osin ati nnkan oko wonyi. Eni kan ko gbodo je e afi eni ti a ba fe, pelu oro won lai ni eri lowo." - Awon eran-osin kan tun n be ti won se eyin won ni eewo (fun gigun ati eru riru), awon eran kan tun n be ti won ki i fi oruko Allahu pa. (Won fi awon nnkan wonyi) da adapa iro mo Allahu ni. O si maa san won ni esan ohun ti won n da ni adapa iro |
Won tun wi pe: "Ohun ti n be ninu ikun awon eran-osin wonyi je ti awon okunrin wa nikan soso, o si je eewo fun awon obinrin wa." Ti o ba si je oku omo-eran, akegbe si ni won ninu (ipin) re. (Allahu) yoo san won ni esan iro (enu) won. Dajudaju Oun ni Ologbon, Onimo |
Awon t’o fi ago ati aimo pa awon omo won kuku ti sofo; won tun se ohun ti Allahu pa lese fun won ni eewo, ni ti dida adapa iro mo Allahu. Won kuku ti sina, won ko si je olumona |
(Allahu) Oun ni Eni ti O seda awon nnkan ogba oko eyi ti e n fowo ara yin gbin ati eyi t’o n lale hu ati dabinu ati irugbin ti (adun) jije re yato sira won, ati eso zaetun ati eso rummon t’o jora won ati eyi ti ko jora won. E je ninu eso re nigba ti o ba so, ki e si yo Zakah re ni ojo ikore re. Ki e si ma yapa. Dajudaju (Allahu) ko nifee awon apa |
O si n be ninu awon eran-osin, eyi t’o le ru eru ati eyi ti ko le ru eru. E je ninu ohun ti Allahu pa lese fun yin. Ki e si ma se tele awon oju-ese Esu; dajudaju oun ni ota ponnbele fun yin |
(Allahu da eran) mejo ni tako-tabo; meji ninu agutan (tako-tabo), meji ninu ewure (tako-tabo). So pe: "Se awon ako mejeeji ni Allahu se ni eewo ni tabi abo mejeeji, tabi ohun ti n be ninu apo-ibimo awon abo eran mejeeji. E fun mi ni iro pelu imo ti e ba je olododo |
Meji ninu rakunmi (tako-tabo) ati meji ninu maalu (tako-tabo). So pe: "Se awon ako mejeeji ni Allahu se ni eewo ni tabi abo mejeeji, tabi ohun ti n be ninu apo-ibimo awon abo eran mejeeji. Tabi se eyin wa nibe nigba ti Allahu pa yin lase eyi ni?" Nitori naa, ta ni o se abosi t’o tun tayo eni t’o da adapa iro mo Allahu lati le si awon eniyan lona pelu ainimo. Dajudaju Allahu ko nii fi ona mo ijo alabosi |
So pe: "Emi ko ri ninu ohun ti Won fi ranse si mi ti Won se jije re ni eewo fun eni ti o n je e afi ohun ti o ba je eran okunbete tabi eje sisan,1 tabi eran elede nitori pe dajudaju egbin ni, tabi eran iyapa (ase Allahu) ti won pa pelu oruko t’o yato si Allahu. Nitori naa, enikeni ti inira (ebi) ba mu je e, yato si eni t’o n wa eewo kiri ati olutayo-enu-ala, dajudaju Oluwa re ni Alaforijin, Asake-orun |
A se e ni eewo fun awon t’o di yehudi gbogbo eran eleeekanna (tabi onipatako t’o supo mora won). Ninu eran maalu ati agutan, A tun se ora awon mejeeji ni eewo fun won afi eyi ti o ba le mo eyin won tabi ifun tabi eyi ti o ba ropo mo eegun. Iyen ni A fi san won ni esan nitori abosi owo won. Dajudaju Awa si ni Olododo |
Ti won ba si pe o ni opuro, so nigba naa pe: "Oluwa yin ni Onikee to gbooro. Ko si si eni t’o le gbe iya Re kuro lori ijo elese |
Awon t’o n sebo yoo wi pe: "Ti ko ba je pe Allahu ba fe ni awa ati awon baba wa iba ti sebo, ati pe awa iba ti se nnkan kan leewo." Bayen ni awon t’o siwaju won se pe oro Allahu niro titi won fi to iya Wa wo. So pe: "Nje imo kan n be ni odo yin, ki e mu un jade fun wa?" Eyin ko tele kini kan bi ko se aroso. Ki si ni e n so bi ko se pe e n paro |
قُلْ فَلِلَّهِ الْحُجَّةُ الْبَالِغَةُ ۖ فَلَوْ شَاءَ لَهَدَاكُمْ أَجْمَعِينَ(149) So pe: "Ti Allahu ni eri t’o pe perepere." Nitori naa, ti O ba fe ni, iba fi gbogbo yin mona patapata |
So pe: "E mu awon elerii yin jade, awon t’o maa jerii pe dajudaju Allahu l’o se eyi leewo." Ti won ba jerii (siro), iwo ma se ba won jerii (si i). Ma si se tele ife-inu awon t’o pe awon ayah Wa niro ati awon ti ko gba Ojo Ikeyin gbo. Awon si ni won n ba Oluwa won wa akegbe |
So pe: "E wa ki ng ka ohun ti Oluwa yin se ni eewo fun yin; pe ki e ma se fi nnkan kan sebo si I, (ki e si se) daadaa si awon obi (yin) mejeeji, ki e si ma se pa awon omo yin nitori (iberu) osi, – Awa ni A n pese fun eyin ati awon – ki e si ma se sunmo awon iwa ibaje – eyi t’o han ninu re ati eyi t’o pamo, - ati pe ki e si ma se pa emi (eniyan) ti Allahu se ni eewo ayafi ni ona eto. Iyen l’O pa lase fun yin nitori ki e le se laakaye |
E ma se sunmo dukia omo orukan ayafi ni ona t’o dara julo titi o fi maa dagba. E won kongo ati osuwon pe daadaa. A ko labo emi kan lorun ayafi iwon agbara re. Ti e ba soro, e se deede, ibaa je ibatan. Ki e si pe adehun Allahu. Iyen l’O pa lase fun yin nitori ki e le lo iranti |
Ati pe dajudaju eyi ni ona Mi (ti o je ona) taara. Nitori naa, e tele e. E ma se tele awon oju ona (miiran) nitori ki o ma baa mu yin yapa oju ona (esin) Re. Iyen l’O pa lase fun yin nitori ki e le beru (Re) |
Leyin naa, A fun (Anabi) Musa ni Tira ni pipe perepere fun eni ti o maa se daadaa. (O je) alaye fun gbogbo nnkan. (O tun je) imona ati ike nitori ki won le ni igbagbo ninu ipade Oluwa won |
وَهَٰذَا كِتَابٌ أَنزَلْنَاهُ مُبَارَكٌ فَاتَّبِعُوهُ وَاتَّقُوا لَعَلَّكُمْ تُرْحَمُونَ(155) Eyi ni Tira ibukun ti A sokale. Nitori naa, e tele e. Ki e si beru (Allahu) nitori ki A le ke yin |
Nitori ki e ma se wi pe: “Owo ijo meji ti o siwaju wa ni Won so Tira kale fun. A si je alainimo nipa eko won.” |
Tabi ki e ma baa wi pe: “Dajudaju Won iba so Tira kale fun wa ni, awa iba mona ju won lo.” Eri t’o yanju, imona ati ike kuku ti de ba yin lati odo Oluwa yin. Nitori naa, ta ni o se abosi ju eni t’o pe awon ayah Allahu niro, t’o tun gbunri kuro nibe? A maa san awon t’o n gbunri kuro nibi awon ayah Wa ni (esan) iya buruku nitori pe won n gbunri (kuro nibe) |
Se won n reti nnkan (miiran) bi ko se pe ki awon molaika wa ba won tabi ki Oluwa re wa ba won tabi ki apa kan awon ami Oluwa re wa ba won? Ni ojo ti apa kan awon ami Oluwa re ba wa ba won, igbagbo (ti) emi kan ko ti i gbagbo teletele tabi ise rere (ti) emi kan ko ti i fi igbagbo re se (teletele) ko nii se e ni anfaani (lasiko naa). So pe: “E maa reti, dajudaju Awa naa n reti (Ojo naa) |
Dajudaju awon t’o ya esin won si otooto, ti won si di ijo-ijo, iwo ko ni nnkan kan se po pelu won. Oro won si n be ni odo Allahu. Leyin naa, O maa fun won ni iro ohun ti won n se nise |
Enikeni t’o ba mu ise daadaa wa, (esan) mewaa iru re l’o maa wa fun un. Enikeni t’o ba si mu ise aburu wa, A o nii san an ni esan ayafi iru re. A o si nii sabosi si won |
So pe: “Dajudaju Oluwa mi ti fi ona taara (’Islam) mo mi, esin t’o fese rinle, esin (Anabi) ’Ibrohim, oluduro-deede-ninu-esin, ko si si ninu awon osebo.” |
قُلْ إِنَّ صَلَاتِي وَنُسُكِي وَمَحْيَايَ وَمَمَاتِي لِلَّهِ رَبِّ الْعَالَمِينَ(162) So pe: "Dajudaju irun mi, eran (pipa) mi, isemi aye mi ati iku mi n je ti Allahu, Oluwa gbogbo eda |
لَا شَرِيكَ لَهُ ۖ وَبِذَٰلِكَ أُمِرْتُ وَأَنَا أَوَّلُ الْمُسْلِمِينَ(163) Ko si akegbe fun Un. Iyen ni Won pa lase fun mi. Emi si ni eni-akoko awon musulumi (ni asiko temi) |
So pe: "Se emi yoo tun wa oluwa kan yato si Allahu ni, nigba ti o je pe Oun ni Oluwa gbogbo nnkan. Emi kan ko si nii se ise kan afi fun emi ara re. Eleru-ese kan ko si nii ru ese elomiiran. Leyin naa, odo Oluwa yin ni ibupadasi yin. O si maa fun yin ni iro ohun ti e n yapa enu si.” |
Oun ni Eni ti O se yin ni arole lori ile. O si fi awon ipo gbe yin ga ju ara yin lo nitori ki O le dan yin wo ninu ohun ti O fun yin. Dajudaju Oluwa re ni Oluyara nibi iya. Dajudaju Oun si ni Alaforijin, Asake-orun |
المزيد من السور باللغة اليوربا:
تحميل سورة الأنعام بصوت أشهر القراء :
قم باختيار القارئ للاستماع و تحميل سورة الأنعام كاملة بجودة عالية
أحمد العجمي
خالد الجليل
سعد الغامدي
سعود الشريم
عبد الباسط
عبد الله الجهني
علي الحذيفي
فارس عباد
ماهر المعيقلي
محمد جبريل
المنشاوي
الحصري
مشاري العفاسي
ناصر القطامي
ياسر الدوسري
Wednesday, January 22, 2025
لا تنسنا من دعوة صالحة بظهر الغيب