📖 0/604 oju-iwe ti a ka
📄 496
Surah Ad-Dukhan

Surah Ad-Dukhan

44:3
إِنَّآ أَنزَلۡنَٰهُ فِي لَيۡلَةٍ مُّبَٰرَكَةٍۚ إِنَّا كُنَّا مُنذِرِينَ ٣
Dajudaju Awa so o kale ninu oru ibukun. Dajudaju Awa n je Olukilo
44:4
فِيهَا يُفۡرَقُ كُلُّ أَمۡرٍ حَكِيمٍ ٤
Ninu oru naa ni won ti maa yanju gbogbo oro ti ko nii tase (lori eda)
44:5
أَمۡرًا مِّنۡ عِندِنَآۚ إِنَّا كُنَّا مُرۡسِلِينَ ٥
Ase kan ni lati odo Wa. Dajudaju Awa l’A n ran awon Ojise nise
44:6
رَحۡمَةً مِّن رَّبِّكَۚ إِنَّهُۥ هُوَ ٱلسَّمِيعُ ٱلۡعَلِيمُ ٦
Ike kan ni lati odo Oluwa re. Dajudaju Allahu, Oun ni Olugbo, Onimo
44:7
رَبِّ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَمَا بَيۡنَهُمَآۖ إِن كُنتُم مُّوقِنِينَ ٧
Oluwa awon sanmo ati ile ati ohunkohun ti n be laaarin mejeeji ti eyin ba je alamodaju
44:8
لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ يُحۡيِۦ وَيُمِيتُۖ رَبُّكُمۡ وَرَبُّ ءَابَآئِكُمُ ٱلۡأَوَّلِينَ ٨
Ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. O n so eda di alaaye. O si n so eda di oku. Oluwa yin ati Oluwa awon baba yin, awon eni akoko
44:10
فَٱرۡتَقِبۡ يَوۡمَ تَأۡتِي ٱلسَّمَآءُ بِدُخَانٍ مُّبِينٍ ١٠
Nitori naa, maa reti ojo ti sanmo yoo mu eefin ponnbele wa
44:11
يَغۡشَى ٱلنَّاسَۖ هَٰذَا عَذَابٌ أَلِيمٌ ١١
O maa bo awon eniyan mole. Eyi ni iya eleta-elero
44:12
رَّبَّنَا ٱكۡشِفۡ عَنَّا ٱلۡعَذَابَ إِنَّا مُؤۡمِنُونَ ١٢
(Awon eniyan yoo wi pe): Oluwa wa, gbe iya naa kuro fun wa, dajudaju awa yoo gbagbo ni ododo
44:13
أَنَّىٰ لَهُمُ ٱلذِّكۡرَىٰ وَقَدۡ جَآءَهُمۡ رَسُولٌ مُّبِينٌ ١٣
Bawo ni iranti se le wulo fun won (lasiko iya)? Ojise ponnbele kuku ti de ba won
44:14
ثُمَّ تَوَلَّوۡاْ عَنۡهُ وَقَالُواْ مُعَلَّمٌ مَّجۡنُونٌ ١٤
Leyin naa, won gbunri kuro ni odo re. Won si wi pe: "Were ti eniyan kan n ko ni eko ni
44:15
إِنَّا كَاشِفُواْ ٱلۡعَذَابِ قَلِيلًاۚ إِنَّكُمۡ عَآئِدُونَ ١٥
Dajudaju Awa maa gbe iya naa kuro fun igba die. Dajudaju eyin yoo tun pada (sinu aigbagbo)
44:16
يَوۡمَ نَبۡطِشُ ٱلۡبَطۡشَةَ ٱلۡكُبۡرَىٰٓ إِنَّا مُنتَقِمُونَ ١٦
Ojo ti A oo gba (won mu) ni igbamu t’o tobi julo; dajudaju Awa yoo gba esan iya (lara won)
44:17
۞ وَلَقَدۡ فَتَنَّا قَبۡلَهُمۡ قَوۡمَ فِرۡعَوۡنَ وَجَآءَهُمۡ رَسُولٌ كَرِيمٌ ١٧
Dajudaju A dan awon eniyan Fir‘aon wo siwaju won. Ojise alapon-onle si de wa ba won
44:18
أَنۡ أَدُّوٓاْ إِلَيَّ عِبَادَ ٱللَّهِۖ إِنِّي لَكُمۡ رَسُولٌ أَمِينٌ ١٨
(O so pe): “E ko awon erusin Allahu le mi lowo. Dajudaju emi ni Ojise olufokantan fun yin
العربيةEnglishBahasa IndonesiaTürkçeРусскийفارسیFrançaisاردوবাংলাDeutschEspañol中文हिन्दीPortuguêsItalianoภาษาไทยPolskiNederlandsShqipKiswahiliO'zbekதமிழ்MelayuBosanskiSoomaaliAzərbaycanکوردی한국어日本語SvenskaDanskNorskپښتوമലയാളംසිංහලTamazightHausaአማርኛБългарскиТоҷикӣҚазақшаFilipinoسنڌيYorùbáFulfuldeТатарчаئۇيغۇرچەКыргызчаਪੰਜਾਬੀJawaతెలుగుမြန်မာગુજરાતીOromoमराठीTiếng ViệtMalagasyНохчийнWolofދިވެހިಕನ್ನಡУкраїнськаΕλληνικάქართულიខ្មែរدریQafar afMaranaoनेपाली
Al-Kur'an
Sunday, August 30, 2026
Don't forget us in your sincere prayers







