PDF —
52 Ẹsẹ Meccan PDF
Built right in your browser — download starts automatically

Surah Al-Qalam pdf — Gbà (Yorùbá)

Surah Al-Qalam pdf Yorùbá — Gbà Surah Al-Qalam Itumọ. Surah Al-Qalam (Meccan) 52 Ẹsẹ.

← Al-MulkSurah Al-Qalam Al-Haqqah →


52 Ẹsẹ · Meccan · Yorùbá
bismillah
ﮉﮊﮋﮌﮍﮎ
68:1 Nun. (Allahu bura pelu) gege ikowe ati ohun ti awon molaika n ko sile
ﮏﮐﮑﮒﮓﮔ
68:2 Iwo ki i se were nipa idera Oluwa re
ﮕﮖﮗﮘﮙﮚ
68:3 Ati pe dajudaju esan ti ko nii dawo duro ti wa fun o
ﮛﮜﮝﮞﮟ
68:4 Dajudaju iwo si wa lori iwa aponle
ﮠﮡﮢ
68:5 Laipe iwo yoo ri i, awon naa yo si ri i
ﮣﮤﮥ
68:6 ewo ninu yin ni were
ﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱ
68:7 Dajudaju Oluwa re, O nimo julo nipa eni t’o sina kuro loju ona Re. O si nimo julo nipa awon olumona
ﯓﯔﯕﯖ
68:8 Nitori naa, ma se tele awon olupe-ododo-niro
ﯗﯘﯙﯚﯛ
68:9 Ati pe won fe ki o dewo, ki awon naa si dewo
ﯜﯝﯞﯟﯠﯡ
68:10 Ma se tele gbogbo eni ti ibura re po, eni yepere
ﯢﯣﯤﯥ
68:11 abuni, alarinka t’o n sofofo kiri
ﯦﯧﯨﯩﯪ
68:12 oludena ise rere, alakoyo, elese
ﯫﯬﯭﯮﯯ
68:13 odaju. Leyin iyen, asawo ni
ﯰﯱﯲﯳﯴﯵ
68:14 Nitori pe o ni dukia ati awon omokunrin
ﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽ
68:15 nigba ti won ba n ke awon ayah Wa fun un, o maa wi pe: “Akosile alo awon eni akoko (niwonyi)”
ﯾﯿﰀﰁ
68:16 A maa fi ami si i ni gongori imu
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛ
68:17 Dajudaju Awa dan won wo gege bi A se dan awon ologba wo nigba ti won bura pe dajudaju awon yoo ka gbogbo eso ogba naa ni owuro kutukutu
ﭜﭝﭞ
68:18 Won ko si se ayafi pe "ti Allahu ba fe
ﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦ
68:19 Adanwo t’o n yi nnkan po lati odo Oluwa re si yi ogba naa po, nigba ti won sun lo
ﭧﭨﭩ
68:20 O si da bi oko agedanu (ti won ti resun)
ﭪﭫﭬ
68:21 Won n pera won ni owuro kutukutu
ﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴ
68:22 pe e ji lo si oko yin ti e ba fe ka eso
ﭵﭶﭷﭸ
68:23 Won lo, won si n fi ohun jeeje bara won soro
ﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿ
68:24 pe ni oni mekunnu kan ko gbodo wonu re wa ba yin
ﮀﮁﮂﮃﮄ
68:25 Won ji lo lori ero-okan kan (pe) awon lagbara
ﮅﮆﮇﮈﮉﮊ
68:26 Nigba ti won ri i, won wi pe: "Dajudaju awa ti sina
ﮋﮌﮍﮎ
68:27 Rara o, won se ikore oko leewo fun wa ni
ﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖ
68:28 Eni t’o duro deede julo ninu won so pe: "Se emi ko so fun yin pe eyin ko se safomo fun Allahu (pe "a maa kore oko wa, ’in sa ’Allahu)
ﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝ
68:29 Won wi pe: "Mimo ni fun Oluwa wa, dajudaju awa je alabosi
ﮞﮟﮠﮡﮢﮣ
68:30 Apa kan won koju si apa kan; won si n dara won lebi
ﮤﮥﮦﮧﮨﮩ
68:31 Won wi pe: "Egbe wa o! Dajudaju awa je olutayo-enu ala
ﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕ
68:32 O see se ki Oluwa wa fi eyi t’o dara ju eyi lo paaro re fun wa. Dajudaju odo Oluwa wa ni awa n rokan oore si
ﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠ
68:33 Bayen ni iya naa se ri (fun won). Iya orun si tobi julo, ti o ba je pe won mo
ﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧ
68:34 Dajudaju awon Ogba Idera wa fun awon oluberu lodo Oluwa won
ﯨﯩﯪﯫ
68:35 Se A maa se awon musulumi bi (A se maa se) awon elese bi
ﯬﯭﯮﯯﯰ
68:36 Ki l’o n se yin ti e fi n dajo bayii na
ﯱﯲﯳﯴﯵﯶ
68:37 Tabi tira kan wa fun yin ti e n kekoo ninu re
ﯷﯸﯹﯺﯻﯼ
68:38 pe dajudaju eyin le ni ohun ti e ba n sa lesa ninu idajo
ﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆﰇﰈﰉ
68:39 Nje e ni awon adehun kan lodo wa ti o maa wa titi di Ojo Ajinde pe: "Dajudaju tiyin ni idajo ti e ba ti mu wa
ﰊﰋﰌﰍﰎ
68:40 Bi won leere wo pe ewo ninu won l’o le fowo iyen soya
ﰏﰐﰑﰒﰓﰔﰕﰖﰗ
68:41 Tabi won ni awon orisa kan? Ki won mu awon orisa won wa nigba naa ti won ba je olododo
ﰘﰙﰚﰛﰜﰝﰞﰟﰠﰡ
68:42 Ni ojo ti A maa si ojugun sile, A si maa pe won sibi iforikanle, won ko si nii le se e
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝ
68:43 Oju won yoo wale. Iyepere maa bo won mole. Won kuku ti pe won sibi iforikanle nigba ti won ni alaafia (won ko si kirun)
ﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩ
68:44 Nitori naa, fi Emi ati eni t’o n pe oro yii niro sile. A oo maa de won leke lati je won niya ni aye ti won ko mo
ﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰ
68:45 Mo n lora fun won ni. Dajudaju ete Mi lagbara
ﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸ
68:46 Tabi o n beere owo-oya kan lodo won, ni gbese fi wo won lorun
ﭹﭺﭻﭼﭽﭾ
68:47 Tabi lodo won ni (walaa) ikoko wa ni won ba n ko o (sita)
ﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊ
68:48 Nitori naa, se suuru fun idajo Oluwa re. Ki iwo ma si se da bi eleja (iyen, Anabi Yunus) nigba ti o pe (Allahu) pelu ibanuje
ﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕ
68:49 Ti ko ba je pe ike kan lati odo Oluwa re le e ba, won iba ju u sori ile gbansasa (lati inu eja) ni eni-eebu
ﮖﮗﮘﮙﮚﮛ
68:50 Nitori naa, Oluwa re sa a lesa. O si se e ni ara awon eni rere
ﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨ
68:51 Awon t’o sai gbagbo fee fi oju won gbe o subu nigba ti won gbo iranti naa. Won si n wi pe: "Dajudaju were ma ni
ﮩﮪﮫﮬﮭﮮ
68:52 Ki si ni al-Ƙur’an bi ko se iranti fun gbogbo eda

Al-Kur'an


Wednesday, September 9, 2026

Don't forget us in your sincere prayers