La sourate Al-Waqiah en Yoruba
Nigba ti Isele (Ajinde) ba sele |
ko si iro kan nipa isele re-E |
o maa mu (awon kan) wale (sinu Ina), o si maa gbe (awon kan) soke (ninu Ogba Idera) |
Nigba ti won ba mi ile titi ni mimititi |
ati nigba ti Won ba fo awon apata ni fifo womuwomu |
won si maa di eruku afedanu - E |
eyin si maa je orisi meta |
ijo osi ati ijo asiwaju. Amo ninu surah al-Balad; 90:18-19 ati surah az-Zalzalah; 99:6-8 Allahu (subhanahu wa ta’ala) pin won si ijo meji. Ijo meji kuku ni gbogbo eda ni orun 8 Awon ero owo otun, ki ni (o maa ti dara to fun) awon ero owo otun |
Awon ero owo osi, ki ni (o maa ti buru to fun) awon ero owo osi |
Awon asiwaju si ni awon asiwaju |
Awon wonyen ni alasun-unmo (Allahu) |
ninu Ogba Idera |
Won po ninu awon eni akoko |
Won si kere ninu awon eni Ikeyin |
(Won yoo wa) lori ite ti won fi goolu hun |
Won yoo rogboku sori re, won si maa doju kora won |
Awon odokunrin ti ko nii darugbo yo si maa lo bo laaarin won |
pelu awon ife omi, ohun iromi fenfe ati ife oti aladun |
Ko nii fo won lori; ko si nii mu won hunrira |
Eso ti won yoo maa sesa ninu re (tun wa fun won) |
Ati eran eye, eyi ti won n fe (yo wa fun won) |
وَحُورٌ عِينٌ(22) Awon obinrin eleyinju ege (tun wa fun won) |
Won da bi okuta olowo-iyebiye ti won fi pamo |
(Iwonyi ni) esan fun ohun ti won n se nise |
Won ko nii gbo isokuso ati oro ese ninu Ogba Idera |
Ayafi oro alaafia, alaafia |
Awon ero owo otun, ki ni (o maa ti dara to fun) awon ero owo otun |
(Won yoo wa) ni idi igi ti ko ni egun |
ati ogede t’o so jigbinni |
ati iboji t’o gbooro |
ati omi t’o n san lai dawo duro |
ati opolopo eso |
ti ko nii ja (ni odo won), ko si nii deewo (fun won) |
(Won maa wa lori) ite ti won gbe soke |
Dajudaju Awa tun (awon obinrin won) da ni eda otun |
A si se won ni wundia |
ololufe oko. Won si dogba ni ojo ori |
(Won wa) fun awon ero owo otun |
Won po ninu awon eni akoko |
Won tun po ninu awon eni Ikeyin |
Awon ero owo osi, ki ni (o maa ti buru to fun) awon ero owo osi |
(Won yoo wa) ninu ategun gbigbona ati omi gbigbona |
ati ni abe iboji eleeefin dudu |
ko tutu, ko si dara |
Dajudaju won ti je onigbedemuke siwaju iyen |
Won si maa n sorikunkun lori ese nla |
وَكَانُوا يَقُولُونَ أَئِذَا مِتْنَا وَكُنَّا تُرَابًا وَعِظَامًا أَإِنَّا لَمَبْعُوثُونَ(47) Won si maa n wi pe: "Se nigba ti a ba di oku, ti a si di erupe ati egungun, nje Won yoo tun gbe wa dide ni |
Se ati awon baba wa, awon eni akoko |
So pe: "Dajudaju awon eni akoko ati awon eni Ikeyin |
dajudaju A oo ko won jo papo ni akoko ojo kan ti A ti mo |
Leyin naa, dajudaju eyin olusina, olupe-ododo-niro |
dajudaju eyin maa je ninu igi zaƙƙum (igi iwo) |
Ikun yin si maa kun bamubamu fun (jije) igi naa |
Eyin yo si maa mu omi gbigbona le e lori |
Eyin yoo maa mu un ni imumi rakunmi ti ongbe n gbe |
Eyi ni nnkan alejo won ni Ojo esan |
Awa l’A seda yin. Ki ni ko je ki e gbagbo lododo |
E so fun Mi nipa ato ti e n da jade (sinu apoluke) |
se eyin le seda re ni tabi Awa l’A seda re |
نَحْنُ قَدَّرْنَا بَيْنَكُمُ الْمَوْتَ وَمَا نَحْنُ بِمَسْبُوقِينَ(60) Awa l’A yan kadara (ojo) iku fun gbogbo yin. Awa ko si le kagara |
عَلَىٰ أَن نُّبَدِّلَ أَمْثَالَكُمْ وَنُنشِئَكُمْ فِي مَا لَا تَعْلَمُونَ(61) lati fi iru yin paaro yin, ki a si tun yin da sinu ohun ti e ko mo |
وَلَقَدْ عَلِمْتُمُ النَّشْأَةَ الْأُولَىٰ فَلَوْلَا تَذَكَّرُونَ(62) E kuku mo iseda akoko, e o se lo iranti |
E so fun Mi nipa nnkan ti e n gbin sinu ile |
se eyin l’e n je ki o hu jade ni tabi Awa l’A n je ki o hu jade |
لَوْ نَشَاءُ لَجَعَلْنَاهُ حُطَامًا فَظَلْتُمْ تَفَكَّهُونَ(65) Ti A ba fe ni, Awa iba so o di gbigbe, eyin yo si maa seemo (ti e oo maa ka abamo) |
(Eyin yo si wi pe:) "Dajudaju awa ti di onigbese |
(Awon miiran yo si wi pe:) "Rara o! Won se ikore oko ni eewo fun wa ni |
E so fun mi nipa omi ti e n mu |
أَأَنتُمْ أَنزَلْتُمُوهُ مِنَ الْمُزْنِ أَمْ نَحْنُ الْمُنزِلُونَ(69) se eyin l’e n so o kale lati inu esujo ni tabi Awa l’A n so o kale |
Ti A ba fe ni, Awa iba se e ni omi t’o moro. E o se maa dupe |
E so fun Mi nipa ina ti e n da |
أَأَنتُمْ أَنشَأْتُمْ شَجَرَتَهَا أَمْ نَحْنُ الْمُنشِئُونَ(72) se eyin l’e seda igi re ni tabi Awa ni Aseda |
نَحْنُ جَعَلْنَاهَا تَذْكِرَةً وَمَتَاعًا لِّلْمُقْوِينَ(73) Awa se ina aye ni iranti (fun Ina orun) ati nnkan elo fun awon onirin-ajo |
Nitori naa, safomo fun oruko Oluwa re, Atobi |
Mo n bura pelu awon ibuso irawo |
Dajudaju ibura nla ni, ti e ba mo |
Dajudaju (al-Ƙur’an) ni nnkan kike alapon-onle |
(t’o wa) ninu Tira aabo (ninu Laohul-Mahfuth) |
Ko si eni to le fowo kan an (ni odo Allahu) afi awon eni mimo (iyen, awon molaika) |
Won so al-Ƙur’an kale lati odo Oluwa gbogbo eda |
Nitori naa, se oro (al-Ƙur’an) yii l’e n pe niro |
E si n so idupe arisiki yin di pe dajudaju e n pe ododo niro |
Ki ni o maa ti ri (fun yin) nigba ti emi (yin) ba de ona ofun |
ti eyin yo si maa woran nigba yen |
وَنَحْنُ أَقْرَبُ إِلَيْهِ مِنكُمْ وَلَٰكِن لَّا تُبْصِرُونَ(85) Awa si sunmo on ju eyin lo, sugbon eyin ko riran |
Eyin ko se je eni ti A o nii gbesan lara re |
ki e si da (emi ti o fe bo) pada, ti e ba je olododo |
Ni ti eni ti o ba wa ninu awon alasun-unmo (Wa) |
isinmi, ese t’o dara ati Ogba Idera (ni tire) |
Ni ti eni ti o ba wa ninu awon ero owo otun |
alaafia ni fun o laaarin awon ero owo otun |
Ni ti eni ti o ba wa ninu awon olupe-ododo-niro, awon olusina |
nnkan alejo (won) ni omi gbigbona |
ati wiwo inu ina Jehim |
Dajudaju eyi, ohun ni ododo t’o daju |
Nitori naa, safomo fun oruko Oluwa re, Atobi |
Plus de sourates en Yoruba :
Téléchargez la sourate avec la voix des récitants du Coran les plus célèbres :
Téléchargez le fichier mp3 de la sourate Al-Waqiah : choisissez le récitateur pour écouter et télécharger la sourate Al-Waqiah complète en haute qualité.















Donnez-nous une invitation valide