Surah Al-Kahf with Yoruba

  1. Surah mp3
  2. More
  3. Yoruba
The Holy Quran | Quran translation | Language Yoruba | Surah Kahf | الكهف - Ayat Count 110 - The number of the surah in moshaf: 18 - The meaning of the surah in English: The Cave.

الْحَمْدُ لِلَّهِ الَّذِي أَنزَلَ عَلَىٰ عَبْدِهِ الْكِتَابَ وَلَمْ يَجْعَل لَّهُ عِوَجًا ۜ(1)

 Gbogbo ope n je ti Allahu, Eni ti O so Tira kale fun erusin Re. Ko si doju oro kan ru ninu re

قَيِّمًا لِّيُنذِرَ بَأْسًا شَدِيدًا مِّن لَّدُنْهُ وَيُبَشِّرَ الْمُؤْمِنِينَ الَّذِينَ يَعْمَلُونَ الصَّالِحَاتِ أَنَّ لَهُمْ أَجْرًا حَسَنًا(2)

 (al-Ƙur’an) fese rinle nitori ki (Anabi) le fi se ikilo iya lile lati odo (Allahu) ati nitori ki (Anabi) le fun awon onigbagbo ododo, awon t’o n se ise rere ni iro idunnu pe dajudaju esan rere n be fun won (ninu Ogba Idera)

مَّاكِثِينَ فِيهِ أَبَدًا(3)

 Won yoo maa gbe ninu re lo titi laelae

وَيُنذِرَ الَّذِينَ قَالُوا اتَّخَذَ اللَّهُ وَلَدًا(4)

 Ati nitori ki (Anabi) le se ikilo fun awon t’o wi pe: “Allahu mu eni kan ni omo.”

مَّا لَهُم بِهِ مِنْ عِلْمٍ وَلَا لِآبَائِهِمْ ۚ كَبُرَتْ كَلِمَةً تَخْرُجُ مِنْ أَفْوَاهِهِمْ ۚ إِن يَقُولُونَ إِلَّا كَذِبًا(5)

 Ko si imo fun awon ati baba won nipa re. Oro t’o n jade lenu won tobi. Dajudaju won ko wi kini kan bi ko se iro

فَلَعَلَّكَ بَاخِعٌ نَّفْسَكَ عَلَىٰ آثَارِهِمْ إِن لَّمْ يُؤْمِنُوا بِهَٰذَا الْحَدِيثِ أَسَفًا(6)

 Nitori naa, nitori ki ni o se maa fi ibanuje para re lori igbese won pe won ko gba oro (al-Ƙur’an) yii gbo

إِنَّا جَعَلْنَا مَا عَلَى الْأَرْضِ زِينَةً لَّهَا لِنَبْلُوَهُمْ أَيُّهُمْ أَحْسَنُ عَمَلًا(7)

 Dajudaju Awa se ohun ti n be lori ile ni oso fun ara-aye nitori ki A le dan won wo (pe) ewo ninu won l’o maa dara julo nibi ise sise (fun esin)

وَإِنَّا لَجَاعِلُونَ مَا عَلَيْهَا صَعِيدًا جُرُزًا(8)

 Ati pe dajudaju Awa maa so nnkan ti n be lori (ile) di erupe gbigbe ti ko nii hu irugbin

أَمْ حَسِبْتَ أَنَّ أَصْحَابَ الْكَهْفِ وَالرَّقِيمِ كَانُوا مِنْ آيَاتِنَا عَجَبًا(9)

 Tabi o lero pe dajudaju awon ara inu iho apata ati walaha oruko won je eemo kan ninu awon ami Wa

إِذْ أَوَى الْفِتْيَةُ إِلَى الْكَهْفِ فَقَالُوا رَبَّنَا آتِنَا مِن لَّدُنكَ رَحْمَةً وَهَيِّئْ لَنَا مِنْ أَمْرِنَا رَشَدًا(10)

 Nigba ti awon odokunrin naa kora won sinu iho apata, won so pe: “Oluwa wa, fun wa ni ike lati odo Re, ki O se imona ni irorun fun wa ninu oro wa.”

فَضَرَبْنَا عَلَىٰ آذَانِهِمْ فِي الْكَهْفِ سِنِينَ عَدَدًا(11)

 A kun won l’oorun asunpiye ninu iho apata f’odun gbooro

ثُمَّ بَعَثْنَاهُمْ لِنَعْلَمَ أَيُّ الْحِزْبَيْنِ أَحْصَىٰ لِمَا لَبِثُوا أَمَدًا(12)

 Leyin naa, A gbe won dide nitori ki A le safi han ewo ninu ijo mejeeji l’o mo gbedeke onka odun t’o lo (ninu iho apata naa)

نَّحْنُ نَقُصُّ عَلَيْكَ نَبَأَهُم بِالْحَقِّ ۚ إِنَّهُمْ فِتْيَةٌ آمَنُوا بِرَبِّهِمْ وَزِدْنَاهُمْ هُدًى(13)

 Awa n so iroyin won fun o pelu ododo. Dajudaju odokunrin ni won. Won gbagbo ninu Oluwa won. A si salekun imona fun won

وَرَبَطْنَا عَلَىٰ قُلُوبِهِمْ إِذْ قَامُوا فَقَالُوا رَبُّنَا رَبُّ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ لَن نَّدْعُوَ مِن دُونِهِ إِلَٰهًا ۖ لَّقَدْ قُلْنَا إِذًا شَطَطًا(14)

 A si ki won lokan nigba ti won dide, ti won so pe: "Oluwa wa ni Oluwa awon sanmo ati ile. A o si nii pe olohun kan leyin Re. (Ti a ba pe olohun kan leyin Re) dajudaju a ti pa iro niyen

هَٰؤُلَاءِ قَوْمُنَا اتَّخَذُوا مِن دُونِهِ آلِهَةً ۖ لَّوْلَا يَأْتُونَ عَلَيْهِم بِسُلْطَانٍ بَيِّنٍ ۖ فَمَنْ أَظْلَمُ مِمَّنِ افْتَرَىٰ عَلَى اللَّهِ كَذِبًا(15)

 Awon ijo wa wonyi so awon kan di olohun leyin Allahu. Ki ni ko je ki won mu eri t’o yanju wa nipa won? Nitori naa, ta ni o se abosi ju eni t’o da adapa iro mo Allahu

وَإِذِ اعْتَزَلْتُمُوهُمْ وَمَا يَعْبُدُونَ إِلَّا اللَّهَ فَأْوُوا إِلَى الْكَهْفِ يَنشُرْ لَكُمْ رَبُّكُم مِّن رَّحْمَتِهِ وَيُهَيِّئْ لَكُم مِّنْ أَمْرِكُم مِّرْفَقًا(16)

 (Awon odokunrin naa so funra won pe:) nigba ti e ba yera fun awon ati nnkan ti won n josin fun leyin Allahu, ti e si wa ibugbe sinu iho apata, Oluwa yin yoo te ninu ike Re sile fun yin. O si maa se oro yin ni irorun fun yin

۞ وَتَرَى الشَّمْسَ إِذَا طَلَعَت تَّزَاوَرُ عَن كَهْفِهِمْ ذَاتَ الْيَمِينِ وَإِذَا غَرَبَت تَّقْرِضُهُمْ ذَاتَ الشِّمَالِ وَهُمْ فِي فَجْوَةٍ مِّنْهُ ۚ ذَٰلِكَ مِنْ آيَاتِ اللَّهِ ۗ مَن يَهْدِ اللَّهُ فَهُوَ الْمُهْتَدِ ۖ وَمَن يُضْلِلْ فَلَن تَجِدَ لَهُ وَلِيًّا مُّرْشِدًا(17)

 O maa ri oorun nigba ti o ba yo, o maa yeba kuro nibi iho won si owo otun. Nigba ti o ba tun wo, o maa fi won sile si owo osi. Won si wa ninu aye ti o feju ninu iho apata. Iyen wa ninu awon ami Allahu. Enikeni ti Allahu ba fi mona (’Islam), oun ni olumona. Enikeni ti O ba si lona, o o si nii ri oluranlowo atoni-sona kan fun un

وَتَحْسَبُهُمْ أَيْقَاظًا وَهُمْ رُقُودٌ ۚ وَنُقَلِّبُهُمْ ذَاتَ الْيَمِينِ وَذَاتَ الشِّمَالِ ۖ وَكَلْبُهُم بَاسِطٌ ذِرَاعَيْهِ بِالْوَصِيدِ ۚ لَوِ اطَّلَعْتَ عَلَيْهِمْ لَوَلَّيْتَ مِنْهُمْ فِرَارًا وَلَمُلِئْتَ مِنْهُمْ رُعْبًا(18)

 O maa lero pe won laju sile ni, oju oorun ni won si wa. A si n yi won legbee pada sotun-un sosi. Aja won si na apa re mejeeji sile ni gbagede apata. Ti o ba je pe o yoju wo won ni, iwo iba peyin da lati ho fun won, iwo iba si kun fun iberu-bojo lati ara won

وَكَذَٰلِكَ بَعَثْنَاهُمْ لِيَتَسَاءَلُوا بَيْنَهُمْ ۚ قَالَ قَائِلٌ مِّنْهُمْ كَمْ لَبِثْتُمْ ۖ قَالُوا لَبِثْنَا يَوْمًا أَوْ بَعْضَ يَوْمٍ ۚ قَالُوا رَبُّكُمْ أَعْلَمُ بِمَا لَبِثْتُمْ فَابْعَثُوا أَحَدَكُم بِوَرِقِكُمْ هَٰذِهِ إِلَى الْمَدِينَةِ فَلْيَنظُرْ أَيُّهَا أَزْكَىٰ طَعَامًا فَلْيَأْتِكُم بِرِزْقٍ مِّنْهُ وَلْيَتَلَطَّفْ وَلَا يُشْعِرَنَّ بِكُمْ أَحَدًا(19)

 Bayen (ni won wa) ti A fi gbe won dide pada nitori ki won le bi ara won leere ibeere. Onsoro kan ninu won so pe: “Igba wo le ti wa nibi?” Won so pe: “A wa nibi fun ojo kan tabi idaji ojo.” Won so pe: “Oluwa yin nimo julo nipa igba ti e ti wa nibi.” Nitori naa, e gbe okan ninu yin dide lo si inu ilu pelu owo fadaka yin yii. Ki o wo ewo ninu ounje ilu l’o mo julo, ki o si mu ase wa fun yin ninu re. Ki o se pelepele, ko si gbodo je ki eni kan kan fura si yin

إِنَّهُمْ إِن يَظْهَرُوا عَلَيْكُمْ يَرْجُمُوكُمْ أَوْ يُعِيدُوكُمْ فِي مِلَّتِهِمْ وَلَن تُفْلِحُوا إِذًا أَبَدًا(20)

 (Nitori pe) dajudaju ti won ba fi le mo nipa yin, won yoo ju yin loko tabi ki won da yin pada sinu esin won. (Ti o ba si fi ri bee) e o nii jere mo laelae niyen

وَكَذَٰلِكَ أَعْثَرْنَا عَلَيْهِمْ لِيَعْلَمُوا أَنَّ وَعْدَ اللَّهِ حَقٌّ وَأَنَّ السَّاعَةَ لَا رَيْبَ فِيهَا إِذْ يَتَنَازَعُونَ بَيْنَهُمْ أَمْرَهُمْ ۖ فَقَالُوا ابْنُوا عَلَيْهِم بُنْيَانًا ۖ رَّبُّهُمْ أَعْلَمُ بِهِمْ ۚ قَالَ الَّذِينَ غَلَبُوا عَلَىٰ أَمْرِهِمْ لَنَتَّخِذَنَّ عَلَيْهِم مَّسْجِدًا(21)

 Bayen ni A se je ki awon eniyan ri won nitori ki won le mo pe dajudaju adehun Allahu ni ododo. Ati pe dajudaju Akoko naa ko si iyemeji ninu re. Ranti (nigba ti awon eniyan) n se ariyanjiyan laaarin ara won nipa oro won. Won so pe: "E mo ile kan le won lori. Oluwa won nimo julo nipa won." Awon t’o bori lori oro won si wi pe: “Dajudaju a maa so ori apata won di mosalasi.”

سَيَقُولُونَ ثَلَاثَةٌ رَّابِعُهُمْ كَلْبُهُمْ وَيَقُولُونَ خَمْسَةٌ سَادِسُهُمْ كَلْبُهُمْ رَجْمًا بِالْغَيْبِ ۖ وَيَقُولُونَ سَبْعَةٌ وَثَامِنُهُمْ كَلْبُهُمْ ۚ قُل رَّبِّي أَعْلَمُ بِعِدَّتِهِم مَّا يَعْلَمُهُمْ إِلَّا قَلِيلٌ ۗ فَلَا تُمَارِ فِيهِمْ إِلَّا مِرَاءً ظَاهِرًا وَلَا تَسْتَفْتِ فِيهِم مِّنْهُمْ أَحَدًا(22)

 Won n wi pe: “Meta ni won. Aja won sikerin won.” Won tun n wi pe: "Marun-un ni won. Aja won sikefa won." Oro t’o pamo fun won (ni won n so). Won tun n wi pe: “Meje ni won. Aja won sikejo won.” So pe: "Oluwa mi nimo julo nipa onka won. Ko si (eni ti) o mo (onka) won afi awon die. Nitori naa, ma se ba won se ariyanjiyan nipa (onka) won afi (ki o fi) ariyanjiyan (naa ti sibi eri) t’o yanju (ti A sokale fun o yii). Ma si se bi eni kan ninu won leere nipa (onka) won

وَلَا تَقُولَنَّ لِشَيْءٍ إِنِّي فَاعِلٌ ذَٰلِكَ غَدًا(23)

 Ma se so nipa kini kan pe: “Dajudaju emi yoo se iyen ni ola.”

إِلَّا أَن يَشَاءَ اللَّهُ ۚ وَاذْكُر رَّبَّكَ إِذَا نَسِيتَ وَقُلْ عَسَىٰ أَن يَهْدِيَنِ رَبِّي لِأَقْرَبَ مِنْ هَٰذَا رَشَدًا(24)

 Ayafi (ki o fi kun un pe) "ti Allahu ba fe." Se iranti Oluwa re nigba ti o ba gbagbe (lati so bee lasiko naa). Ki o si so (fun won) pe: “O rorun ki Oluwa mi to mi sona pelu eyi ti o sunmo ju eyi lo ni imona (fun yin).”

وَلَبِثُوا فِي كَهْفِهِمْ ثَلَاثَ مِائَةٍ سِنِينَ وَازْدَادُوا تِسْعًا(25)

 Won wa ninu iho apata won fun ogorun-un meta odun. Won tun lo alekun odun mesan-an

قُلِ اللَّهُ أَعْلَمُ بِمَا لَبِثُوا ۖ لَهُ غَيْبُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۖ أَبْصِرْ بِهِ وَأَسْمِعْ ۚ مَا لَهُم مِّن دُونِهِ مِن وَلِيٍّ وَلَا يُشْرِكُ فِي حُكْمِهِ أَحَدًا(26)

 So pe: “Allahu nimo julo nipa ohun ti won lo (ninu iho apata). TiRe ni ikoko awon sanmo ati ile. Ki ni ko ri tan, ki si ni ko gbo tan! Ko si alaabo kan fun won leyin Re. Ko si fi eni kan se akegbe ninu idajo Re.”

وَاتْلُ مَا أُوحِيَ إِلَيْكَ مِن كِتَابِ رَبِّكَ ۖ لَا مُبَدِّلَ لِكَلِمَاتِهِ وَلَن تَجِدَ مِن دُونِهِ مُلْتَحَدًا(27)

 Ke ohun ti A fi ranse si o ninu Tira Oluwa re. Ko si eni ti o le yi awon oro Re pada. Iwo ko si le ri ibusasi kan yato si odo Re

وَاصْبِرْ نَفْسَكَ مَعَ الَّذِينَ يَدْعُونَ رَبَّهُم بِالْغَدَاةِ وَالْعَشِيِّ يُرِيدُونَ وَجْهَهُ ۖ وَلَا تَعْدُ عَيْنَاكَ عَنْهُمْ تُرِيدُ زِينَةَ الْحَيَاةِ الدُّنْيَا ۖ وَلَا تُطِعْ مَنْ أَغْفَلْنَا قَلْبَهُ عَن ذِكْرِنَا وَاتَّبَعَ هَوَاهُ وَكَانَ أَمْرُهُ فُرُطًا(28)

 Se suuru fun emi re lati wa pelu awon t’o n pe Oluwa won ni owuro ati ni asale, ti won n wa Oju rere Re. Ma se foju pa won re lati wa oso isemi aye (yii). Ma si se tele eni ti A mu okan re gbagbe iranti Wa. O tele ife-inu re; oro re si je aseju

وَقُلِ الْحَقُّ مِن رَّبِّكُمْ ۖ فَمَن شَاءَ فَلْيُؤْمِن وَمَن شَاءَ فَلْيَكْفُرْ ۚ إِنَّا أَعْتَدْنَا لِلظَّالِمِينَ نَارًا أَحَاطَ بِهِمْ سُرَادِقُهَا ۚ وَإِن يَسْتَغِيثُوا يُغَاثُوا بِمَاءٍ كَالْمُهْلِ يَشْوِي الْوُجُوهَ ۚ بِئْسَ الشَّرَابُ وَسَاءَتْ مُرْتَفَقًا(29)

 So pe: “Ododo (niyi) lati odo Oluwa yin. Nitori naa, eni ti o ba fe ki o gbagbo. Eni ti o ba si fe ki o sai gbagbo. Dajudaju Awa pese Ina sile de awon alabosi, ti ogba re yoo yi won po. Ti won ba n toro omi mimu, A oo fun won ni omi mimu kan t’o da bi oje ide gbigbona, ti (igbona re) yo si maa se awon oju. O buru ni mimu. O si buru ni ibukojo

إِنَّ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ إِنَّا لَا نُضِيعُ أَجْرَ مَنْ أَحْسَنَ عَمَلًا(30)

 Dajudaju awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere, dajudaju Awa ko nii fi esan eni ti o ba se ise rere rare

أُولَٰئِكَ لَهُمْ جَنَّاتُ عَدْنٍ تَجْرِي مِن تَحْتِهِمُ الْأَنْهَارُ يُحَلَّوْنَ فِيهَا مِنْ أَسَاوِرَ مِن ذَهَبٍ وَيَلْبَسُونَ ثِيَابًا خُضْرًا مِّن سُندُسٍ وَإِسْتَبْرَقٍ مُّتَّكِئِينَ فِيهَا عَلَى الْأَرَائِكِ ۚ نِعْمَ الثَّوَابُ وَحَسُنَتْ مُرْتَفَقًا(31)

 Awon wonyen, tiwon ni Ogba Idera gbere, ti awon odo yoo maa san ni isale won. Won yoo maa fi goolu orun se won ni oso ninu re. Won yoo maa wo aso aran alawo eweko (eyi ti o) fele ati (eyi ti) o nipon. Won yo si rogboku lori ibusun ola ninu (Ogba Idera). O dara ni esan. O si dara ni ibukojo

۞ وَاضْرِبْ لَهُم مَّثَلًا رَّجُلَيْنِ جَعَلْنَا لِأَحَدِهِمَا جَنَّتَيْنِ مِنْ أَعْنَابٍ وَحَفَفْنَاهُمَا بِنَخْلٍ وَجَعَلْنَا بَيْنَهُمَا زَرْعًا(32)

 Fi awon okunrin meji kan se apeere fun won; A fun okan ninu won ni ogba eso ajara meji. A si fi awon igi dabinu yi won ka. A tun fi awon igi eleso la won laaarin

كِلْتَا الْجَنَّتَيْنِ آتَتْ أُكُلَهَا وَلَمْ تَظْلِم مِّنْهُ شَيْئًا ۚ وَفَجَّرْنَا خِلَالَهُمَا نَهَرًا(33)

 Ikini keji awon oko mejeeji n so eso won. Awon eso re ki i pe din. A si je ki odo san koja laaarin oko mejeeji

وَكَانَ لَهُ ثَمَرٌ فَقَالَ لِصَاحِبِهِ وَهُوَ يُحَاوِرُهُ أَنَا أَكْثَرُ مِنكَ مَالًا وَأَعَزُّ نَفَرًا(34)

 O ni eso (se). O si so fun ore re nigba ti o n ba a jiyan (bayii) pe: “Emi ni dukia lowo ju o lo. Mo tun lero leyin julo.”

وَدَخَلَ جَنَّتَهُ وَهُوَ ظَالِمٌ لِّنَفْسِهِ قَالَ مَا أَظُنُّ أَن تَبِيدَ هَٰذِهِ أَبَدًا(35)

 O wo inu oko re lo, o si ti sabosi si emi ara re, o wi pe: “Emi ko lero pe eyi maa parun laelae

وَمَا أَظُنُّ السَّاعَةَ قَائِمَةً وَلَئِن رُّدِدتُّ إِلَىٰ رَبِّي لَأَجِدَنَّ خَيْرًا مِّنْهَا مُنقَلَبًا(36)

 Emi ko si lero pe Akoko naa maa sele. Ati pe ti won ba da mi pada si odo Oluwa mi, dajudaju mo tun maa ri ibudesi t’o dara ju eyi lo.”

قَالَ لَهُ صَاحِبُهُ وَهُوَ يُحَاوِرُهُ أَكَفَرْتَ بِالَّذِي خَلَقَكَ مِن تُرَابٍ ثُمَّ مِن نُّطْفَةٍ ثُمَّ سَوَّاكَ رَجُلًا(37)

 Ore re so fun un nigba ti o n ja a niyan (bayii) pe: “Se o maa sai gbagbo ninu Eni ti O seda re lati inu erupe, leyin naa, lati inu ato. Leyin naa, O se o ni okunrin t’o pe ni eda

لَّٰكِنَّا هُوَ اللَّهُ رَبِّي وَلَا أُشْرِكُ بِرَبِّي أَحَدًا(38)

 Sugbon ni temi, Oluwa mi, Oun ni Allahu. Emi ko si nii so eni kan di akegbe fun Oluwa mi

وَلَوْلَا إِذْ دَخَلْتَ جَنَّتَكَ قُلْتَ مَا شَاءَ اللَّهُ لَا قُوَّةَ إِلَّا بِاللَّهِ ۚ إِن تَرَنِ أَنَا أَقَلَّ مِنكَ مَالًا وَوَلَدًا(39)

 Nigba ti o wo inu ogba oko re, ki ni ko mu o so pe: "Ohun ti Allahu ba fe! Ko si agbara kan bi ko se pelu iyonda Allahu. Ti o ba si ri mi pe mo kere si o ni dukia ati omo

فَعَسَىٰ رَبِّي أَن يُؤْتِيَنِ خَيْرًا مِّن جَنَّتِكَ وَيُرْسِلَ عَلَيْهَا حُسْبَانًا مِّنَ السَّمَاءِ فَتُصْبِحَ صَعِيدًا زَلَقًا(40)

 o sunmo ki Oluwa mi fun emi naa ni ogba oko ti o maa dara ju ogba oko tire. (O si sunmo) ki O so iya kan kale sinu ogba oko re lati sanmo; o si maa di ile asale

أَوْ يُصْبِحَ مَاؤُهَا غَوْرًا فَلَن تَسْتَطِيعَ لَهُ طَلَبًا(41)

 Tabi ki omi re gbe. O o si nii le wa omi kan

وَأُحِيطَ بِثَمَرِهِ فَأَصْبَحَ يُقَلِّبُ كَفَّيْهِ عَلَىٰ مَا أَنفَقَ فِيهَا وَهِيَ خَاوِيَةٌ عَلَىٰ عُرُوشِهَا وَيَقُولُ يَا لَيْتَنِي لَمْ أُشْرِكْ بِرَبِّي أَحَدًا(42)

 Won si pa eso re run patapata. O si di eni t’o n fi owo re mejeeji lura won peepe nipa ohun ti o ti na sori re. O ti parun torule-torule re. O si n wi pe: “Yee! Emi iba ti so eni kan kan di akegbe fun Oluwa mi.”

وَلَمْ تَكُن لَّهُ فِئَةٌ يَنصُرُونَهُ مِن دُونِ اللَّهِ وَمَا كَانَ مُنتَصِرًا(43)

 Ko ni ijo kan ti o maa ran an lowo mo leyin Allahu. Ko si le ran ara re lowo

هُنَالِكَ الْوَلَايَةُ لِلَّهِ الْحَقِّ ۚ هُوَ خَيْرٌ ثَوَابًا وَخَيْرٌ عُقْبًا(44)

 Nibe yen, ti Allahu, Oba Ododo ni ijoba. O loore julo ni esan, O si loore julo ni ikangun (rere)

وَاضْرِبْ لَهُم مَّثَلَ الْحَيَاةِ الدُّنْيَا كَمَاءٍ أَنزَلْنَاهُ مِنَ السَّمَاءِ فَاخْتَلَطَ بِهِ نَبَاتُ الْأَرْضِ فَأَصْبَحَ هَشِيمًا تَذْرُوهُ الرِّيَاحُ ۗ وَكَانَ اللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ مُّقْتَدِرًا(45)

 Se akawe ile aye fun won; o da bi omi ti A sokale lati sanmo. Leyin naa, o ropo mo irugbin ile. Leyin naa, (irugbin) di gbigbe, ti ategun n fonka. Allahu si n je Alagbara lori gbogbo nnkan

الْمَالُ وَالْبَنُونَ زِينَةُ الْحَيَاةِ الدُّنْيَا ۖ وَالْبَاقِيَاتُ الصَّالِحَاتُ خَيْرٌ عِندَ رَبِّكَ ثَوَابًا وَخَيْرٌ أَمَلًا(46)

 Oso isemi aye ni dukia ati awon omo. Awon ise rere t’o maa wa titi laelae loore julo ni esan lodo Oluwa re, o si loore julo ni ireti

وَيَوْمَ نُسَيِّرُ الْجِبَالَ وَتَرَى الْأَرْضَ بَارِزَةً وَحَشَرْنَاهُمْ فَلَمْ نُغَادِرْ مِنْهُمْ أَحَدًا(47)

 (Ranti) ojo ti A maa mu awon apata rin lo. O si maa ri ile ni petele. A maa ko won jo. A o si nii fi eni kan sile ninu won

وَعُرِضُوا عَلَىٰ رَبِّكَ صَفًّا لَّقَدْ جِئْتُمُونَا كَمَا خَلَقْنَاكُمْ أَوَّلَ مَرَّةٍ ۚ بَلْ زَعَمْتُمْ أَلَّن نَّجْعَلَ لَكُم مَّوْعِدًا(48)

 Won yo si ko won wa siwaju Oluwa re ni owoowo. Dajudaju e ti wa ba Wa (bayii) gege bi A se da yin nigba akoko. Amo e so lai ni eri lowo pe A o nii mu ojo adehun se fun yin

وَوُضِعَ الْكِتَابُ فَتَرَى الْمُجْرِمِينَ مُشْفِقِينَ مِمَّا فِيهِ وَيَقُولُونَ يَا وَيْلَتَنَا مَالِ هَٰذَا الْكِتَابِ لَا يُغَادِرُ صَغِيرَةً وَلَا كَبِيرَةً إِلَّا أَحْصَاهَا ۚ وَوَجَدُوا مَا عَمِلُوا حَاضِرًا ۗ وَلَا يَظْلِمُ رَبُّكَ أَحَدًا(49)

 A maa gbe iwe ise eda kale (fun won). Nigba naa, o maa ri awon elese ti won yoo maa beru nipa ohun ti n be ninu iwe ise won. Won yoo wi pe: “Egbe wa! Iru iwe wo ni eyi na; ko fi ohun kekere ati nla kan sile lai ko o sile?” Won si ba ohun ti won se nise nibe. Oluwa re ko si nii sabosi si eni kan

وَإِذْ قُلْنَا لِلْمَلَائِكَةِ اسْجُدُوا لِآدَمَ فَسَجَدُوا إِلَّا إِبْلِيسَ كَانَ مِنَ الْجِنِّ فَفَسَقَ عَنْ أَمْرِ رَبِّهِ ۗ أَفَتَتَّخِذُونَهُ وَذُرِّيَّتَهُ أَوْلِيَاءَ مِن دُونِي وَهُمْ لَكُمْ عَدُوٌّ ۚ بِئْسَ لِلظَّالِمِينَ بَدَلًا(50)

 (Ranti) nigba ti A so fun awon molaika pe: “E fori kanle ki (Anabi) Adam.” Won si fori kanle ki i afi ’Iblis, (ti) o je okan ninu awon alujannu. O si safojudi si ase Oluwa re. Nitori naa, se e maa mu oun ati awon aromodomo re ni alafeyinti leyin Mi ni, ota yin si ni won. Pasipaaro t’o buru ni fun awon alabosi

۞ مَّا أَشْهَدتُّهُمْ خَلْقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَلَا خَلْقَ أَنفُسِهِمْ وَمَا كُنتُ مُتَّخِذَ الْمُضِلِّينَ عَضُدًا(51)

 Ng o pe won si dida awon sanmo ati ile, ati dida awon gan-an alara. Ng o si mu awon asinilona ni oluranlowo

وَيَوْمَ يَقُولُ نَادُوا شُرَكَائِيَ الَّذِينَ زَعَمْتُمْ فَدَعَوْهُمْ فَلَمْ يَسْتَجِيبُوا لَهُمْ وَجَعَلْنَا بَيْنَهُم مَّوْبِقًا(52)

 (Ranti) ojo ti (Allahu) yoo so pe: “E pe awon akegbe Mi ti e so nipa won lai ni eri lowo (pe olusipe ni won).” Won pe won. Won ko si da won lohun. A si ti fi koto iparun saaarin won

وَرَأَى الْمُجْرِمُونَ النَّارَ فَظَنُّوا أَنَّهُم مُّوَاقِعُوهَا وَلَمْ يَجِدُوا عَنْهَا مَصْرِفًا(53)

 Awon elese si ri Ina. Won si mo pe awon yoo ko sinu re. Won ko si nii ri ibusasi kan ninu re

وَلَقَدْ صَرَّفْنَا فِي هَٰذَا الْقُرْآنِ لِلنَّاسِ مِن كُلِّ مَثَلٍ ۚ وَكَانَ الْإِنسَانُ أَكْثَرَ شَيْءٍ جَدَلًا(54)

 Dajudaju A ti se alaye oniran-anran sinu al-Ƙur’an fun awon eniyan pelu gbogbo akawe. Eniyan si je alatako pupo ju ohunkohun lo

وَمَا مَنَعَ النَّاسَ أَن يُؤْمِنُوا إِذْ جَاءَهُمُ الْهُدَىٰ وَيَسْتَغْفِرُوا رَبَّهُمْ إِلَّا أَن تَأْتِيَهُمْ سُنَّةُ الْأَوَّلِينَ أَوْ يَأْتِيَهُمُ الْعَذَابُ قُبُلًا(55)

 Ko si ohun t’o di awon eniyan lowo lati gbagbo nigba ti imona de ba won, (ko si si ohun t’o di won lowo lati) toro aforijin Oluwa won, bi ko se pe (won fe) ki ise (Allahu nipa iparun) awon eni akoko de ba awon naa tabi ki iya de ba won ni ojukoju

وَمَا نُرْسِلُ الْمُرْسَلِينَ إِلَّا مُبَشِّرِينَ وَمُنذِرِينَ ۚ وَيُجَادِلُ الَّذِينَ كَفَرُوا بِالْبَاطِلِ لِيُدْحِضُوا بِهِ الْحَقَّ ۖ وَاتَّخَذُوا آيَاتِي وَمَا أُنذِرُوا هُزُوًا(56)

 Ati pe A ko ran awon Ojise nise (lasan) afi ki won je oniroo-idunnu ati olukilo. Awon t’o sai gbagbo si n fi iro satako nitori ki won le fi wo ododo. Won si so awon ayah Mi ati ohun ti A fi sekilo fun won di yeye

وَمَنْ أَظْلَمُ مِمَّن ذُكِّرَ بِآيَاتِ رَبِّهِ فَأَعْرَضَ عَنْهَا وَنَسِيَ مَا قَدَّمَتْ يَدَاهُ ۚ إِنَّا جَعَلْنَا عَلَىٰ قُلُوبِهِمْ أَكِنَّةً أَن يَفْقَهُوهُ وَفِي آذَانِهِمْ وَقْرًا ۖ وَإِن تَدْعُهُمْ إِلَى الْهُدَىٰ فَلَن يَهْتَدُوا إِذًا أَبَدًا(57)

 Ta si l’o sabosi ju eni ti won fi awon ayah Oluwa re seranti fun, ti o gbunri kuro nibe, ti o si gbagbe ohun ti owo re mejeeji ti siwaju? Dajudaju Awa fi ebibo bo okan won nitori ki won ma baa gbo o ye. A si fi edidi sinu eti won. Ti iwo ba pe won sinu imona, nigba naa won ko si nii mona laelae

وَرَبُّكَ الْغَفُورُ ذُو الرَّحْمَةِ ۖ لَوْ يُؤَاخِذُهُم بِمَا كَسَبُوا لَعَجَّلَ لَهُمُ الْعَذَابَ ۚ بَل لَّهُم مَّوْعِدٌ لَّن يَجِدُوا مِن دُونِهِ مَوْئِلًا(58)

 Oluwa re, Alaforijin, Onikee, ti o ba je pe O maa fi ohun ti won se nise mu won ni, iba tete mu iya wa fun won. Sugbon akoko adehun (ajinde) wa fun won. Won ko si nii ri ibusasi kan leyin re

وَتِلْكَ الْقُرَىٰ أَهْلَكْنَاهُمْ لَمَّا ظَلَمُوا وَجَعَلْنَا لِمَهْلِكِهِم مَّوْعِدًا(59)

 Iwonyi ni awon ilu ti A ti pare nigba ti won sabosi. A si fun won ni adehun fun iparun won

وَإِذْ قَالَ مُوسَىٰ لِفَتَاهُ لَا أَبْرَحُ حَتَّىٰ أَبْلُغَ مَجْمَعَ الْبَحْرَيْنِ أَوْ أَمْضِيَ حُقُبًا(60)

 (Ranti) nigba ti (Anabi) Musa so fun omo-odo re pe: "Ng o nii ye rin titi mo maa fi de ibi ti odo meji ti pade tabi (titi) mo maa fi lo opolopo odun

فَلَمَّا بَلَغَا مَجْمَعَ بَيْنِهِمَا نَسِيَا حُوتَهُمَا فَاتَّخَذَ سَبِيلَهُ فِي الْبَحْرِ سَرَبًا(61)

 Nigba ti awon mejeeji si de ibi ti odo meji ti pade, won gbagbe eja won. (Eja naa) si bo si oju ona re (ti o ti di) poro ona ninu odo

فَلَمَّا جَاوَزَا قَالَ لِفَتَاهُ آتِنَا غَدَاءَنَا لَقَدْ لَقِينَا مِن سَفَرِنَا هَٰذَا نَصَبًا(62)

 Nigba ti awon mejeeji re koja (ibi ti odo meji ti pade), o so fun omo-odo re pe: "Fun wa ni ounje osan wa. Dajudaju a ti ko wahala ninu irin-ajo wa yii

قَالَ أَرَأَيْتَ إِذْ أَوَيْنَا إِلَى الصَّخْرَةِ فَإِنِّي نَسِيتُ الْحُوتَ وَمَا أَنسَانِيهُ إِلَّا الشَّيْطَانُ أَنْ أَذْكُرَهُ ۚ وَاتَّخَذَ سَبِيلَهُ فِي الْبَحْرِ عَجَبًا(63)

 (Omo-odo re) so pe: "So (ohun t’o sele) fun mi, nigba ti a wa nibi apata! Dajudaju mo ti gbagbe eja naa (sibe)? Ko si si ohun ti o mu mi gbagbe re bi ko se Esu, ti ko je ki ng ranti re. (Eja naa) si ti mu ona re to lo ninu odo pelu iyanu

قَالَ ذَٰلِكَ مَا كُنَّا نَبْغِ ۚ فَارْتَدَّا عَلَىٰ آثَارِهِمَا قَصَصًا(64)

 (Anabi Musa) so pe: “(Ibi ti eja ti lo) yen ni ohun ti a n wa.” Awon mejeeji si pada seyin lati to oripa ese won bi won se to o wa

فَوَجَدَا عَبْدًا مِّنْ عِبَادِنَا آتَيْنَاهُ رَحْمَةً مِّنْ عِندِنَا وَعَلَّمْنَاهُ مِن لَّدُنَّا عِلْمًا(65)

 Awon mejeeji si ri erusin kan ninu awon erusin Wa, ti A fun ni ike kan lati odo Wa. A si fun un ni imo lati odo Wa

قَالَ لَهُ مُوسَىٰ هَلْ أَتَّبِعُكَ عَلَىٰ أَن تُعَلِّمَنِ مِمَّا عُلِّمْتَ رُشْدًا(66)

 (Anabi) Musa so fun un pe: “Se ki ng tele o nitori ki o le ko mi ninu ohun ti Won fi mo o ni imona.” amo bi musulumi kookan ba se sunmo Allahu to ninu igbagbo ati iberu re nipa lilo ofin esin ’Islam

قَالَ إِنَّكَ لَن تَسْتَطِيعَ مَعِيَ صَبْرًا(67)

 (Kidr) so pe: “Dajudaju o o le se suuru pelu mi

وَكَيْفَ تَصْبِرُ عَلَىٰ مَا لَمْ تُحِطْ بِهِ خُبْرًا(68)

 Ati pe bawo ni o se le se suuru lori ohun ti o o fi imo rokiri ka re?”

قَالَ سَتَجِدُنِي إِن شَاءَ اللَّهُ صَابِرًا وَلَا أَعْصِي لَكَ أَمْرًا(69)

 (Anabi Musa) so pe: “Ti Allahu ba fe, o maa ba mi ni onisuuru. Mi o si nii yapa ase re.”

قَالَ فَإِنِ اتَّبَعْتَنِي فَلَا تَسْأَلْنِي عَن شَيْءٍ حَتَّىٰ أُحْدِثَ لَكَ مِنْهُ ذِكْرًا(70)

 (Kidr) so pe: “Ti o ba tele mi, ma se bi mi ni ibeere nipa nnkan kan titi mo fi maa koko mu iranti wa fun o nipa re.”

فَانطَلَقَا حَتَّىٰ إِذَا رَكِبَا فِي السَّفِينَةِ خَرَقَهَا ۖ قَالَ أَخَرَقْتَهَا لِتُغْرِقَ أَهْلَهَا لَقَدْ جِئْتَ شَيْئًا إِمْرًا(71)

 Nitori naa, awon mejeeji lo titi di igba ti won fi wo inu oko oju-omi. (Kidr) si da oko naa lu. (Anabi Musa) so pe: “O se da a lu, (se) ki awon ero re le te ri ni? Dajudaju o ti se nnkan aburu kan!”

قَالَ أَلَمْ أَقُلْ إِنَّكَ لَن تَسْتَطِيعَ مَعِيَ صَبْرًا(72)

 (Kidr) so pe: “Nje mi o so fun o pe dajudaju o o nii le se suuru pelu mi.”

قَالَ لَا تُؤَاخِذْنِي بِمَا نَسِيتُ وَلَا تُرْهِقْنِي مِنْ أَمْرِي عُسْرًا(73)

 (Anabi Musa) so pe: “Ma se ba mi wi nipa ohun ti mo gbagbe. Ma si se ko inira ba mi ninu oro (irin-ajo) mi (pelu re).”

فَانطَلَقَا حَتَّىٰ إِذَا لَقِيَا غُلَامًا فَقَتَلَهُ قَالَ أَقَتَلْتَ نَفْسًا زَكِيَّةً بِغَيْرِ نَفْسٍ لَّقَدْ جِئْتَ شَيْئًا نُّكْرًا(74)

 Leyin naa, awon mejeeji lo titi di igba ti won fi pade omodekunrin kan. (Kidr) si pa a. (Anabi Musa) so pe: “O se pa emi (eniyan) mimo, lai gba emi? Dajudaju o ti se nnkan t’o buru o.”

۞ قَالَ أَلَمْ أَقُل لَّكَ إِنَّكَ لَن تَسْتَطِيعَ مَعِيَ صَبْرًا(75)

 (Kidr) so pe: “Nje mi o so fun o pe dajudaju o o nii le se suuru pelu mi.”

قَالَ إِن سَأَلْتُكَ عَن شَيْءٍ بَعْدَهَا فَلَا تُصَاحِبْنِي ۖ قَدْ بَلَغْتَ مِن لَّدُنِّي عُذْرًا(76)

 (Anabi Musa) so pe: “Ti mo ba tun bi o nipa kini kan leyin re, ma se ba mi rin mo. Dajudaju o ti mu awawi de opin lodo mi.”

فَانطَلَقَا حَتَّىٰ إِذَا أَتَيَا أَهْلَ قَرْيَةٍ اسْتَطْعَمَا أَهْلَهَا فَأَبَوْا أَن يُضَيِّفُوهُمَا فَوَجَدَا فِيهَا جِدَارًا يُرِيدُ أَن يَنقَضَّ فَأَقَامَهُ ۖ قَالَ لَوْ شِئْتَ لَتَّخَذْتَ عَلَيْهِ أَجْرًا(77)

 Leyin naa, awon mejeeji lo titi di igba ti won de odo awon ara ilu kan. Won toro ounje lodo awon ara ilu naa. Won si ko lati se won ni alejo. Awon mejeeji si ba ogiri kan nibe ti o fe wo. (Kidr) si gbe e dide. (Anabi Musa) so pe: “Ti o ba je pe o ba fe, o o ba si gba owo-oya lori re.”

قَالَ هَٰذَا فِرَاقُ بَيْنِي وَبَيْنِكَ ۚ سَأُنَبِّئُكَ بِتَأْوِيلِ مَا لَمْ تَسْتَطِع عَّلَيْهِ صَبْرًا(78)

 (Kidr) so pe: “Eyi ni opinya laaarin emi ati iwo. Mo si maa fun o ni itumo ohun ti o o le se suuru lori re.”

أَمَّا السَّفِينَةُ فَكَانَتْ لِمَسَاكِينَ يَعْمَلُونَ فِي الْبَحْرِ فَأَرَدتُّ أَنْ أَعِيبَهَا وَكَانَ وَرَاءَهُم مَّلِكٌ يَأْخُذُ كُلَّ سَفِينَةٍ غَصْبًا(79)

 Ni ti oko oju-omi, o je ti awon mekunnu ti won n sise lori omi. Mo si fe lati fi alebu kan an (nitori pe) oba kan wa niwaju won t’o n gba gbogbo oko oju-omi pelu ipa

وَأَمَّا الْغُلَامُ فَكَانَ أَبَوَاهُ مُؤْمِنَيْنِ فَخَشِينَا أَن يُرْهِقَهُمَا طُغْيَانًا وَكُفْرًا(80)

 Ni ti omodekunrin naa, awon obi re mejeeji je onigbagbo ododo. A si n beru pe ki o maa ko itayo enu-ala ati aigbagbo ba awon mejeeji

فَأَرَدْنَا أَن يُبْدِلَهُمَا رَبُّهُمَا خَيْرًا مِّنْهُ زَكَاةً وَأَقْرَبَ رُحْمًا(81)

 Nitori naa, A fe ki Oluwa awon mejeeji paaro re fun won pelu (eyi) t’o loore ju u lo ni ti mimo (ninu ese) ati (eyi) t’o sunmo ju u lo ni ti ike

وَأَمَّا الْجِدَارُ فَكَانَ لِغُلَامَيْنِ يَتِيمَيْنِ فِي الْمَدِينَةِ وَكَانَ تَحْتَهُ كَنزٌ لَّهُمَا وَكَانَ أَبُوهُمَا صَالِحًا فَأَرَادَ رَبُّكَ أَن يَبْلُغَا أَشُدَّهُمَا وَيَسْتَخْرِجَا كَنزَهُمَا رَحْمَةً مِّن رَّبِّكَ ۚ وَمَا فَعَلْتُهُ عَنْ أَمْرِي ۚ ذَٰلِكَ تَأْوِيلُ مَا لَمْ تَسْطِع عَّلَيْهِ صَبْرًا(82)

 Nipa ti ogiri, o je ti awon omodekunrin, omo orukan meji kan ninu ilu naa. Apoti-oro kan si n be fun awon mejeeji labe ogiri naa. Baba awon mejeeji si je eni rere. Nitori naa, Oluwa re fe ki awon mejeeji dagba (ba dukia naa), ki won si hu dukia won jade (ki o le je) ike kan lati odo Oluwa re. Mi o da a se lati odo ara mi; (Allahu l’O pa mi lase re). Iyen ni itumo ohun ti o o le se suuru fun

وَيَسْأَلُونَكَ عَن ذِي الْقَرْنَيْنِ ۖ قُلْ سَأَتْلُو عَلَيْكُم مِّنْهُ ذِكْرًا(83)

 Won n bi o leere nipa Thul-Ƙorneen. So pe: “Mo maa mu oro iranti wa fun yin nipa re.”

إِنَّا مَكَّنَّا لَهُ فِي الْأَرْضِ وَآتَيْنَاهُ مِن كُلِّ شَيْءٍ سَبَبًا(84)

 Dajudaju Awa fun un ni ipo lori ile. A si fun un ni ona t’o le gba se gbogbo nnkan (ti o ba fe se)

فَأَتْبَعَ سَبَبًا(85)

 Nitori naa, o mu ona kan to

حَتَّىٰ إِذَا بَلَغَ مَغْرِبَ الشَّمْسِ وَجَدَهَا تَغْرُبُ فِي عَيْنٍ حَمِئَةٍ وَوَجَدَ عِندَهَا قَوْمًا ۗ قُلْنَا يَا ذَا الْقَرْنَيْنِ إِمَّا أَن تُعَذِّبَ وَإِمَّا أَن تَتَّخِذَ فِيهِمْ حُسْنًا(86)

 titi o fi de ibuwo oorun aye. O ri i ti n wo sinu iseleru petepete dudu kan. O si ba awon eniyan kan nibe. A so fun un pe: “Thul-Ƙorneen, yala ki o je won niya tabi ki o mu ohun rere jade lara won.”

قَالَ أَمَّا مَن ظَلَمَ فَسَوْفَ نُعَذِّبُهُ ثُمَّ يُرَدُّ إِلَىٰ رَبِّهِ فَيُعَذِّبُهُ عَذَابًا نُّكْرًا(87)

 (Allahu) so pe: “Ni ti eni ti o ba sabosi, laipe A maa je e niya. Leyin naa, won maa da a pada si odo Oluwa re. O si maa je e niya t’o buru

وَأَمَّا مَنْ آمَنَ وَعَمِلَ صَالِحًا فَلَهُ جَزَاءً الْحُسْنَىٰ ۖ وَسَنَقُولُ لَهُ مِنْ أَمْرِنَا يُسْرًا(88)

 Sugbon ni ti eni ti o ba gbagbo ni ododo, ti o si se ise rere, tire ni esan rere. A o si soro irorun fun un ninu ase Wa.”

ثُمَّ أَتْبَعَ سَبَبًا(89)

 Leyin naa, o mu ona kan to

حَتَّىٰ إِذَا بَلَغَ مَطْلِعَ الشَّمْسِ وَجَدَهَا تَطْلُعُ عَلَىٰ قَوْمٍ لَّمْ نَجْعَل لَّهُم مِّن دُونِهَا سِتْرًا(90)

 titi o fi de ibuyo oorun aye. O ri i ti n yo lori awon eniyan kan, ti A ko fun ni gaga (aabo) kan nibi oorun

كَذَٰلِكَ وَقَدْ أَحَطْنَا بِمَا لَدَيْهِ خُبْرًا(91)

 Bayen ni (Thul-Ƙorneen se n te siwaju). Dajudaju A rokirika ohun ti n be lodo re pelu imo

ثُمَّ أَتْبَعَ سَبَبًا(92)

 Leyin naa, o mu ona kan to

حَتَّىٰ إِذَا بَلَغَ بَيْنَ السَّدَّيْنِ وَجَدَ مِن دُونِهِمَا قَوْمًا لَّا يَكَادُونَ يَفْقَهُونَ قَوْلًا(93)

 titi o fi de aarin apata meji. O si ba awon eniyan kan niwaju re. Won ko si fee gbo agboye oro kan (ninu ede miiran)

قَالُوا يَا ذَا الْقَرْنَيْنِ إِنَّ يَأْجُوجَ وَمَأْجُوجَ مُفْسِدُونَ فِي الْأَرْضِ فَهَلْ نَجْعَلُ لَكَ خَرْجًا عَلَىٰ أَن تَجْعَلَ بَيْنَنَا وَبَيْنَهُمْ سَدًّا(94)

 Won so pe: “Thul-Ƙorneen, dajudaju (iran) Ya’juj ati Ma’juj n se ibaje lori ile. Se ki a fun o ni owo-ode nitori ki o le ba wa mo odi kan saaarin awa ati awon?”

قَالَ مَا مَكَّنِّي فِيهِ رَبِّي خَيْرٌ فَأَعِينُونِي بِقُوَّةٍ أَجْعَلْ بَيْنَكُمْ وَبَيْنَهُمْ رَدْمًا(95)

 O so pe: "Ohun ti Oluwa mi fun mi ninu ipo loore julo. Nitori naa, e fi agbara ran mi lowo ni nitori ki ng le mo odi saaarin eyin ati awon

آتُونِي زُبَرَ الْحَدِيدِ ۖ حَتَّىٰ إِذَا سَاوَىٰ بَيْنَ الصَّدَفَيْنِ قَالَ انفُخُوا ۖ حَتَّىٰ إِذَا جَعَلَهُ نَارًا قَالَ آتُونِي أُفْرِغْ عَلَيْهِ قِطْرًا(96)

 E maa fun mi ni egige irin titi di igba ti o fi maa ba egbe apata mejeeji dogba." O so pe: "E maa fe ategun ewiri (si i lara) titi di igba ti o maa (pon wee bi) ina." O so pe: "E mu ide wa fun mi ki ng yo o le e lori

فَمَا اسْطَاعُوا أَن يَظْهَرُوهُ وَمَا اسْتَطَاعُوا لَهُ نَقْبًا(97)

 Nitori naa, won ko le gun un, won ko si le da a lu

قَالَ هَٰذَا رَحْمَةٌ مِّن رَّبِّي ۖ فَإِذَا جَاءَ وَعْدُ رَبِّي جَعَلَهُ دَكَّاءَ ۖ وَكَانَ وَعْدُ رَبِّي حَقًّا(98)

 O so pe: “Eyi ni ike kan lati odo Oluwa mi. Nigba ti adehun Oluwa mi ba de, (Allahu) yo si so o di petele. Adehun Oluwa mi si je ododo.”

۞ وَتَرَكْنَا بَعْضَهُمْ يَوْمَئِذٍ يَمُوجُ فِي بَعْضٍ ۖ وَنُفِخَ فِي الصُّورِ فَجَمَعْنَاهُمْ جَمْعًا(99)

 A maa fi awon (eniyan ati alujannu) sile ni ojo yen, ti apa kan won yo si maa dapo mo apa kan. Won a fon fere oniwo fun ajinde. A o si ko gbogbo won jo papo patapata

وَعَرَضْنَا جَهَنَّمَ يَوْمَئِذٍ لِّلْكَافِرِينَ عَرْضًا(100)

 Ni ojo yen, A o si fi ina Jahanamo han awon alaigbagbo kedere

الَّذِينَ كَانَتْ أَعْيُنُهُمْ فِي غِطَاءٍ عَن ذِكْرِي وَكَانُوا لَا يَسْتَطِيعُونَ سَمْعًا(101)

 (Awon ni) awon ti oju won wa ninu ebibo nipa iranti Mi. Won ko si le gboro

أَفَحَسِبَ الَّذِينَ كَفَرُوا أَن يَتَّخِذُوا عِبَادِي مِن دُونِي أَوْلِيَاءَ ۚ إِنَّا أَعْتَدْنَا جَهَنَّمَ لِلْكَافِرِينَ نُزُلًا(102)

 Se awon t’o sai gbagbo lero pe awon yoo mu awon erusin Mi ni oluranlowo leyin Mi ni? Dajudaju Awa pese ina Jahanamo sile ni ibudesi fun awon alaigbagbo

قُلْ هَلْ نُنَبِّئُكُم بِالْأَخْسَرِينَ أَعْمَالًا(103)

 So pe: “Se ki A fun yin ni iro awon eni ofo julo nipa ise (owo won)

الَّذِينَ ضَلَّ سَعْيُهُمْ فِي الْحَيَاةِ الدُّنْيَا وَهُمْ يَحْسَبُونَ أَنَّهُمْ يُحْسِنُونَ صُنْعًا(104)

 (Awon ni) awon ti ise won ti baje ninu isemi aye, (amo ti) won n lero pe dajudaju awon n se ise rere

أُولَٰئِكَ الَّذِينَ كَفَرُوا بِآيَاتِ رَبِّهِمْ وَلِقَائِهِ فَحَبِطَتْ أَعْمَالُهُمْ فَلَا نُقِيمُ لَهُمْ يَوْمَ الْقِيَامَةِ وَزْنًا(105)

 Awon wonyen ni awon t’o sai gbagbo ninu awon ayah Oluwa won ati ipade Re. Awon ise won si baje. Nitori naa, A o nii je ki won jamo nnkan kan lori iwon ni Ojo Ajinde

ذَٰلِكَ جَزَاؤُهُمْ جَهَنَّمُ بِمَا كَفَرُوا وَاتَّخَذُوا آيَاتِي وَرُسُلِي هُزُوًا(106)

 Jahanamo, iyen ni esan won nitori pe won sai gbagbo, won si so awon ayah Mi ati awon Ojise Mi di oniyeye

إِنَّ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ كَانَتْ لَهُمْ جَنَّاتُ الْفِرْدَوْسِ نُزُلًا(107)

 Dajudaju awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere, awon ogba Firdaos ti wa fun won ni ibudesi

خَالِدِينَ فِيهَا لَا يَبْغُونَ عَنْهَا حِوَلًا(108)

 Olusegbere ni won ninu re. Won ko si nii fe kuro ninu re

قُل لَّوْ كَانَ الْبَحْرُ مِدَادًا لِّكَلِمَاتِ رَبِّي لَنَفِدَ الْبَحْرُ قَبْلَ أَن تَنفَدَ كَلِمَاتُ رَبِّي وَلَوْ جِئْنَا بِمِثْلِهِ مَدَدًا(109)

 So pe: “Ti o ba je pe ibudo je tadaa fun awon oro Oluwa Mi, ibudo kuku maa tan siwaju ki awon oro Oluwa Mi to tan, koda ki A tun mu (ibudo) iru re wa ni alekun.”

قُلْ إِنَّمَا أَنَا بَشَرٌ مِّثْلُكُمْ يُوحَىٰ إِلَيَّ أَنَّمَا إِلَٰهُكُمْ إِلَٰهٌ وَاحِدٌ ۖ فَمَن كَانَ يَرْجُو لِقَاءَ رَبِّهِ فَلْيَعْمَلْ عَمَلًا صَالِحًا وَلَا يُشْرِكْ بِعِبَادَةِ رَبِّهِ أَحَدًا(110)

 So pe: “Abara ni emi bi iru yin. Won n fi imisi ranse si mi pe Olohun yin, Olohun Okan soso ni. Nitori naa, enikeni ti o ba n reti ipade Oluwa re, ki o se ise rere. Ko si gbodo fi eni kan kan se akegbe nibi jijosin fun Oluwa re.”


More surahs in Yoruba:


Al-Baqarah Al-'Imran An-Nisa'
Al-Ma'idah Yusuf Ibrahim
Al-Hijr Al-Kahf Maryam
Al-Hajj Al-Qasas Al-'Ankabut
As-Sajdah Ya Sin Ad-Dukhan
Al-Fath Al-Hujurat Qaf
An-Najm Ar-Rahman Al-Waqi'ah
Al-Hashr Al-Mulk Al-Haqqah
Al-Inshiqaq Al-A'la Al-Ghashiyah

Download surah Al-Kahf with the voice of the most famous Quran reciters :

surah Al-Kahf mp3 : choose the reciter to listen and download the chapter Al-Kahf Complete with high quality
surah Al-Kahf Ahmed El Agamy
Ahmed Al Ajmy
surah Al-Kahf Bandar Balila
Bandar Balila
surah Al-Kahf Khalid Al Jalil
Khalid Al Jalil
surah Al-Kahf Saad Al Ghamdi
Saad Al Ghamdi
surah Al-Kahf Saud Al Shuraim
Saud Al Shuraim
surah Al-Kahf Abdul Basit Abdul Samad
Abdul Basit
surah Al-Kahf Abdul Rashid Sufi
Abdul Rashid Sufi
surah Al-Kahf Abdullah Basfar
Abdullah Basfar
surah Al-Kahf Abdullah Awwad Al Juhani
Abdullah Al Juhani
surah Al-Kahf Fares Abbad
Fares Abbad
surah Al-Kahf Maher Al Muaiqly
Maher Al Muaiqly
surah Al-Kahf Muhammad Siddiq Al Minshawi
Al Minshawi
surah Al-Kahf Al Hosary
Al Hosary
surah Al-Kahf Al-afasi
Mishari Al-afasi
surah Al-Kahf Yasser Al Dosari
Yasser Al Dosari


Wednesday, January 22, 2025

لا تنسنا من دعوة صالحة بظهر الغيب